Ẹ̀KỌ́ 18
Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
1 Kọ́ríńtì 9:19-23
KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ ohun tó máa mú kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ronú jinlẹ̀, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Ronú nípa ohun táwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Dípò tí wàá kàn fi máa tún ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ sọ, sọ ọ́ lọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n fi ojú tó yàtọ̀ wo ọ̀rọ̀ náà.
Ṣe ìwádìí, kó o sì ṣe àṣàrò. Tó bá ṣeé ṣe, sọ̀rọ̀ nípa nǹkan táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ tàbí kó o fi àwọn ohun tó ń lọ láyé ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì. Ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti bí kókó náà ṣe tan mọ́ àwọn àpẹẹrẹ tó o fẹ́ lò.
Jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ rẹ ṣe pàtàkì. Ṣàlàyé bí àwọn kókó pàtàkì inú Ìwé Mímọ́ ṣe lè ran àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nínú ìgbé ayé wọn ojoojúmọ́. Sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó kan tàbí ohun tẹ́nì kan ṣe tó kan àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.