Ẹ̀KỌ́ 44
Ṣé Gbogbo Ayẹyẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?
Jèhófà fẹ́ ká gbádùn ayé wa dáadáa, ó sì fẹ́ ká máa yọ̀. Àmọ́, ṣé gbogbo ayẹyẹ tàbí àjọyọ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí? Tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ayẹyẹ tá à ń ṣe, báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
1. Kí nìdí tí inú Ọlọ́run ò fi dùn sí ọ̀pọ̀ ayẹyẹ táwọn èèyàn ń ṣe?
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ayẹyẹ táwọn èèyàn ń ṣe ló ta ko ohun tí Bíbélì sọ tàbí kó jẹ́ pé àwọn abọ̀rìṣà tàbí àwọn ẹlẹ́sìn èké ló dá wọn sílẹ̀. Irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ lè ní ẹ̀mí òkùnkùn nínú, wọ́n sì lè máa kọ́ni pé ńṣe ni èèyàn máa ń di àkúdàáyà lẹ́yìn tó bá kú. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ayẹyẹ míì máa ń gbé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lárugẹ, wọ́n sì máa ń mú kí àwọn èèyàn nígbàgbọ́ nínú àyànmọ́ àti ọlọ́run oríire. (Àìsáyà 65:11) Jèhófà kìlọ̀ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: ‘Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ ẹ má sì fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́.’—2 Kọ́ríńtì 6:17.a
2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà, tá a bá ń bọlá fáwọn èèyàn ju bó ṣe yẹ lọ?
Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe “gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásánlàsàn.” (Ka Jeremáyà 17:5.) Àwọn ayẹyẹ kan wà tí wọ́n máa fi ń bọlá fáwọn aláṣẹ àtàwọn olókìkí míì. Àwọn míì máa ń ṣe ayẹyẹ láti bọlá fún àmì orílẹ̀-èdè tàbí kí wọ́n máa ṣe ayẹyẹ òmìnira orílẹ̀-èdè. (1 Jòhánù 5:21) Bákan náà, àwọn kan máa ń ṣe ayẹyẹ láti bọlá fún ètò ìṣèlú tàbí ẹgbẹ́ kan táwọn èèyàn dá sílẹ̀. Ṣé inú Jèhófà máa dùn tá a bá ń ṣe ayẹyẹ tí kò yẹ láti bọlá fáwọn èèyàn lásánlàsàn tàbí ẹgbẹ́ kan táwọn èèyàn dá sílẹ̀, ní pàtàkì àwọn ayẹyẹ tí kò bá ìfẹ́ rẹ̀ mu?
3. Àwọn ìwà àti ìṣe wo ló lè mú kí Ọlọ́run kórìíra ayẹyẹ tá à ń ṣe?
Bíbélì sọ pé ‘ọtí àmujù, àríyá aláriwo àti ìdíje ọtí mímu’ kò dáa. (1 Pétérù 4:3) Níbi àwọn ayẹyẹ kan, àwọn èèyàn máa ń hùwà ẹhànnà, wọ́n sì máa ń ṣe ìṣekúṣe. Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ bá wọn ṣe irú àwọn ayẹyẹ ẹlẹ́gbin bẹ́ẹ̀.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ayẹyẹ tó yẹ ká máa ṣe àtàwọn tí kò yẹ ká máa ṣe.
4. Má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ tí kò bọlá fún Jèhófà
Ka Éfésù 5:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn ìwádìí wo ló yẹ ká ṣe ká tó pinnu láti ṣe ayẹyẹ kan?
Àwọn ayẹyẹ wo ni wọ́n sábà máa ń ṣe ládùúgbò yín?
Ṣé o rò pé inú Ọlọ́run dùn sáwọn ayẹyẹ náà?
Bí àpẹẹrẹ, ṣé o rò pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí? Kò sí olùjọsìn Jèhófà kankan tí Bíbélì sọ pé ó ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, àmọ́ ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn méjì tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Ka Jẹ́nẹ́sísì 40:20-22 àti Mátíù 14:6-10. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ló jọra nínú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjèèjì yìí?
Pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kà yìí, ojú wo lo rò pé Jèhófà fi ń wo ayẹyẹ ọjọ́ ìbí?
Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kó o máa béèrè pé, ‘Ṣó tiẹ̀ ṣe pàtàkì sí Jèhófà bóyá mo ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tàbí àwọn ayẹyẹ míì tí kò bá ohun tí Bíbélì sọ mu?’ Ka Ẹ́kísódù 32:1-8. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣèwádìí ká lè mọ ohun tí inú Jèhófà dùn sí?
Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Bá a ṣe lè mọ àwọn ayẹyẹ tínú Ọlọ́run ò dùn sí
Ṣé ayẹyẹ náà kò ta ko ẹ̀kọ́ Bíbélì? Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá kò ta ko ẹ̀kọ́ Bíbélì, ṣèwádìí kó o lè mọ àwọn tó dá ayẹyẹ náà sílẹ̀.
Ṣé wọ́n ń fi ayẹyẹ náà bọlá fáwọn èèyàn kan tàbí ẹgbẹ́ kan lọ́nà tó pọ̀ jù àbí ńṣe ni wọ́n fi ń gbé àmì orílẹ̀-èdè lárugẹ? Jèhófà ni ọlá àti ògo tó ga jù lọ yẹ, òun nìkan la sì gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa yanjú gbogbo ìṣòro tó wà láyé.
Ṣé àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ náà ò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì? Ńṣe ló yẹ ká máa sá fún àwọn ìwà àti ìṣe tínú Ọlọ́run ò dùn sí.
5. Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ò ní báwọn ṣe ayẹyẹ tínú Ọlọ́run ò dùn sí
Táwọn kan bá ní kó o wá báwọn ṣe ayẹyẹ kan tínú Ọlọ́run ò dùn sí, ó lè má rọrùn fún ẹ láti sọ pé o ò ní bá wọn ṣe é. Ńṣe ni kó o fi sùúrù ṣàlàyé fún wọn, kó o má sì kàn wọ́n lábùkù. Kó o lè mọ ọ̀nà tí wàá gbà ṣàlàyé fún wọn, wo FÍDÍÒ yìí.
Ka Mátíù 7:12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ṣé ó yẹ kó o sọ fáwọn èèyàn ẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ayẹyẹ kan?
Kí lo lè ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn ẹ mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò ní báwọn ṣe ayẹyẹ tínú Ọlọ́run ò dùn sí, o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn?
6. Jèhófà fẹ́ ká láyọ̀
Jèhófà fẹ́ káwa àtàwọn èèyàn wa máa láyọ̀ ká sì máa gbádùn ara wa. Ka Oníwàásù 8:15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀?
Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn ẹ̀ máa láyọ̀ ká sì máa gbádùn ara wa. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí àpẹẹrẹ báwọn èèyàn Jèhófà ṣe máa ń gbádùn ara wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àpéjọ àgbáyé.
Ka Gálátíà 6:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé ó dìgbà tá a bá ṣe onírúurú ayẹyẹ táwọn èèyàn máa ń ṣe ká tó lè “ṣe rere” fún gbogbo èèyàn?
Nínú kó o máa fi dandan fún àwọn èèyàn lẹ́bùn torí ayẹyẹ àti kó o máa fi tinútinú fún wọn lẹ́bùn nígbàkigbà, èwo ló máa múnú ẹ dùn jù?
Nígbàkigbà láàárín ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dìídì ṣètò àkókò kan táwọn àtàwọn ọmọ wọn á fi gbádùn ara wọn, tàbí kí wọ́n fún wọn lẹ́bùn tó jọni lójú. Tó o bá láwọn ọmọ, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe fún wọn táá jọ wọ́n lójú?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò pọn dandan kéèyàn máa ṣèwádìí nípa ibi tí ayẹyẹ kan ti wá. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kéèyàn ṣáà ti fàkókò yẹn gbádùn ara ẹ̀ pẹ̀lú tẹbítọ̀rẹ́.”
Kí lèrò tìẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀ ká sì gbádùn ara wa pẹ̀lú àwọn èèyàn wa. Ṣùgbọ́n, kò fẹ́ ká máa ṣe àwọn ayẹyẹ tínú ẹ̀ ò dùn sí.
Kí lo rí kọ́?
Àwọn ìbéèrè wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run kórìíra ayẹyẹ kan?
Ọ̀nà wo la lè gbà ṣàlàyé fáwọn èèyàn wa pé a ò ní báwọn ṣe ayẹyẹ tínú Ọlọ́run ò dùn sí?
Báwo lo ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀ ká sì máa gbádùn ara wa?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn ayẹyẹ kan táwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe.
“Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Ṣe Àwọn Ayẹyẹ Kan?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun mẹ́rin tó mú káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí.
“Kí Nìdí Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fí Ṣe Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun táwọn ọmọdé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè ṣe kí wọ́n lè máa múnú ẹ̀ dùn táwọn èèyàn bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ tínú Jèhófà ò dùn sí.
Àìmọye àwọn Kristẹni ni kì í ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì. Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí wọ́n sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
a Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 5 kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe tí wọ́n bá pè ẹ́ sáwọn ayẹyẹ kan tí inú Ọlọ́run ò dùn sí.