Ẹ Wà ni Ilera Ninu Igbagbọ!
Awọn Koko Itẹnumọ Lati Inu Titu
AWỌN ijọ Kristian ni erékùsù Mediterranean ti Krete nfẹ àfiyèsí nipa tẹmi. Ta ni o lè ràn wọn lọwọ? Họwu, Titu alábàáṣiṣẹ́pọ̀ apọsteli Pọọlu ni! Oun ni ìgboyà, o tóótun lati kọ́ni, ó ní ìtara fun awọn iṣẹ rere, ó sì wà ni ilera ninu igbagbọ.
Pọọlu bẹ Krete wo láàárín ìfisẹ́wọ̀n rẹ̀ akọkọ ati èkejì ni Roomu. O fi Titu silẹ lẹhin ni erékùsù naa lati ṣàtúnṣe awọn ohun kan ati lati yan awọn alàgbà ìjọ. A o tun késí Titu lati bá awọn olùkọ́ èké wí ati lati fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀. Gbogbo eyi ni a ṣipaya ninu lẹta Pọọlu si Titu, ti o ṣeeṣe ki a fi ranṣẹ lati Masedonia láàárín 61 si 64 C.E. Fifi ìmọ̀ràn apọsteli naa sílò lè ran awọn alábòójútó òde-òní ati awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn lọwọ lati jẹ onígboyà, onítara, ati onílera nipa tẹ̀mí.
Ki Ni A Bèèrè fún Lọ́dọ̀ awọn Alábòójútó?
O pọndandan lati yan awọn alábòójútó lati bójútó awọn iṣoro wíwúwo. (1:1-16) Fun ìyànsípò gẹgẹbi alábòójútó kan, ọkunrin kan nilati jẹ́ aláìlẹ́sùn, àwòfiṣàpẹrẹ gẹgẹ bi ẹnikan ati ninu igbesi-aye ìdílé rẹ̀, olufẹ àlejò ṣiṣe, ẹni ti o wàdéédé, ki o sì ní ìkóra-ẹni nijaanu. Oun nilati kọni ní oun ti o jẹ́ òtítọ́ ki o sì gbaniníyànjú ki o si fi ibawi tọ́ awọn wọnni ti wọn nsọ ojú-ìwòye títakora jade sọna. Ìgboyà ni a nilo nitori pe awọn eniyan oniwa ewèlè ninu ijọ ni a nilati pa lẹ́nu mọ́. Ni pataki ni eyi ri bẹẹ niti awọn wọnni ti wọn ńtòròpinpin mọ ìkọlà, nitori ti wọn ti ṣojú gbogbo agbo ile dé. Ìbáwí mímúná ni yoo pọndandan bi awọn ijọ ba nilati wà ni ilera nipa tẹ̀mí. Lonii, awọn alábòójútó Kristian tun nílò ìgboyà lati baniwi ki wọn sì gbaniníyànjú, pẹlu ete gbígbé ijọ naa ró.
Fi Ẹkọ Onílera Sílò
Titu nilati fi ẹkọ onílera nipa tẹmi kọni. (2:1-15) Awọn àgbà ọkunrin nilati jẹ àwòfiṣàpẹẹrẹ niti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ìwà àgbà, èrò-inú yíyèkooro, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ati ìpamọ́ra. Awọn àgbà obinrin ni wọn nilati jẹ́ “ẹni ọ̀wọ̀ ni ìwà.” Gẹgẹ bi “olùkọ́ni ní ohun rere,” wọn le ran awọn ọdọbinrin lọwọ lati ni oju-iwoye títọ̀nà nipa iṣẹ́ wọn gẹgẹbi aya ati ìyá. Awọn ọ̀dọ́kùnrin nilati ni èrò-inú yíyèkooro, awọn ẹrú sì nilati tẹriba fun awọn olówó wọn ni ọna ti yoo ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun lọ́ṣọ̀ọ́. Gbogbo awọn Kristian ni wọn nilati kọ àìwà-bí-Ọlọ́run silẹ kí wọn sì gbe pẹlu èrò-inú yíyèkooro ninu ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nnkan yìí nigba ti wọn ńdúró de ìfarahàn ológo ti Ọlọrun ati Jesu Kristi, “ẹni ti o fi ara rẹ fun wa, ki oun ki o le ra wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo, ki o si lè wẹ awọn eniyan kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ìní oun tikalaraarẹ awọn onitara [fun] iṣẹ rere.” Nipa fifi iru ìmọ̀ràn onilera bẹẹ silo, ẹ jẹ ki awa pẹlu ‘ṣe ẹkọ Ọlọrun lọ́sọ̀ọ́.’
Ìmọ̀ràn ìparí ọ̀rọ̀ Pọọlu gbe ìlera tẹmi larugẹ. (3:1-15) O pọndandan lati fi ìtẹríba ti o tọna han fun awọn oluṣakoso ati lati mu ìlọ́gbọ́n nínú dàgbà. Awọn Kristian ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, awọn ọrọ Pọọlu sì ni a nilati tẹnumọ lati fun wọn niṣiiri lati maa pa ọkan pọ̀ sori awọn iṣẹ rere. Awọn ibeere òmùgọ̀ ati ìjà lori Ofin ni a nilati yẹra fun, olùṣagbátẹrù ẹ̀ya isin ni a si nilati ṣátì lẹhin ti a bá ti ṣi i leti lẹ́ẹ̀mejì. Bi awọn alagba ba ti nfi iru ìmọ̀ràn bẹẹ silo loni, awọn ati awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn yoo wà ni lera ninu igbagbọ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ki Wọn Maṣe Jẹ́ Ọ̀mùtí: Bi o tilẹ jẹ pe awọn obinrin ko gbọdọ kọ́ awọn ọkunrin lẹ́kọ̀ọ́ ninu ijọ, awọn àgbà arabinrin lè fun awọn ọ̀dọ́bìnrin ni ìtọ́ni ni ìkọ̀kọ̀. Ṣugbọn lati gbéṣẹ́ ni ọna yii, awọn àgbà obinrin gbọdọ kọbiara si awọn ọrọ Pọ́ọ̀lù: “Ki awọn àgbà obinrin jẹ onírònú ni ìwà, ki wọn má jẹ asọrọ ẹni lẹhin, tabi ọ̀mùtí, bíkòṣe olùkọ́ni ni ohun rere.” (Titu 2:1-5; 1 Timoti 2:11-14) Nitori ìjẹ́pàtàkì ọ̀ràn nipa awọn ìyọrísí ọtí mímu, awọn alábòójútó, awọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́, ati awọn àgbà obinrin gbọdọ jẹ oníwọ̀ntunwọ̀nsì, ki wọn maṣe fi ara wọn fun ọtí àmujù. (1 Timoti 3:2, 3, 8, 11) Gbogbo awọn Kristian gbọdọ yàgò fun ìmùtípara wọn sì nilati fàsẹ́hìn kúrò ninu ọti líle nigba ti wọn ba nṣe “iṣẹ́ mimọ” ti wíwàásù ihin rere naa.—Roomu 15:16; Owe 23:20, 21.