Awọn Iwe Akajọ Òkun Òkú—Àwárí Oniyebiye naa Ti A Buyìn Kún
NI NNKAN bii 15 ibusọ si guusu ila-oorun Jerusalem, Wadi En-Nar, ipa ọna omi gbígbẹ fúrúfúrú kan gba apa ila oorun lọ taarata sinu Okun Òkú. Awọn gegele okuta ti wọn pin kélekèle lọ salalu lẹhin pẹ̀tẹ́lẹ̀ eteeti ebute naa. Lori pẹ̀tẹ́lẹ̀ yii, ní awọn ọjọ ti oorun maa ńmú janjan ati ni awọn òru ti o tutu ni ifiwera ní igba ikore, awọn darandaran ara Arabia [Bedouin] ti Ta‘amireh ntọju agbo ẹran agutan ati awọn ewurẹ wọn.
Ni ọdun 1947, nigba ti wọn ntọju agbo ẹran, ọdọmọde oluṣọ agutan darandaran ara Arabia kan sọ okuta sinu oju iho kekere kan lara oju gegele okuta ti o ti fọ́ kan. Oun ni a mu tagìrì lojiji nipasẹ ariwo ti o mu jade, eyi ti o han gbangba pe o waye nipa fífọ́ ìṣà alámọ̀ kan yángá. Oun salọ nitori ibẹru, ṣugbọn ni ọjọ meji lẹhin naa oun pada wa ti o sì gun nǹkan bii 300 ẹsẹ bata lati wọle sinu iho kan ti o tobi ti o sì ga sii. Gbàrà ti oju rẹ̀ ti riran ninu okunkun naa, ni oun rí awọn ìṣà gàgàrà mẹwaa ti a tò sẹgbẹẹgbẹ ogiri iho okuta naa, ati ọpọ rẹpẹtẹ awọn èfífọ́ ìṣà laaarin awọn okuta ti o ti ya lulẹ ti o wà kaakiri ilẹ̀.
Ọpọ julọ ninu awọn ìṣà naa wà lófo, ṣugbọn ọkan ni iwe akajọ mẹta ninu, meji ni a fi aṣọ wé. Oun mú awọn iwe afọwọkọ naa lọ si abule awọn darandaran ará Arabia ó sì fi wọn silẹ sibẹ fun nǹkan bii oṣu kan, ni síso wọn rọ̀ ninu àpò kan lori òpó àgọ́. Nigbẹhin gbẹhin, awọn darandaran ara Arabia kan mú awọn iwe akajọ naa lọ si Bẹtilẹhẹmu lati ri iye owó ti o lè mu wọle. Awọn darandaran ara Arabia naa ni a fi àìkàsí dá pada ni ile awọn ajẹjẹẹ anikandagbe kan ni sisọ fun wọn pe awọn iwe akajọ naa kò ní iniyelori eyikeyii. Oniṣowo miiran sọ wi pe awọn afọwọkọ naa kò ni ìtóye kankan niti iwalẹpitan, ti o sì fura pe a ti jí wọn kó lati inu sinagọgu awọn Juu. Bawo ni o ṣe ṣaitọna tó! Nigbẹhin gbẹhin, pẹlu oniṣẹ bàtà ara Syria kan ti o duro gẹgẹ bi alágbàtà, ìtóye wọn ni a fidi rẹ̀ mulẹ lọna ti o tọna. Laipẹ, awọn iwe afọwọkọ miiran ni a diwọn iniyelori wọn.
Diẹ ninu awọn ikọwe ìgbà atijọ wọnyi ṣi ọna ijinlẹ oye titun patapata silẹ sinu igbokegbodo awọn awujọ onisin Juu ni kete ṣaaju akoko Kristi. Ṣugbọn iwe afọwọkọ Bibeli kan ti asọtẹlẹ Aisaya ni o ru aye soke. Eeṣe?
Ohun Oniyebiye Nla Naa
Iwe akajọ ti Aisaya ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí naa jẹ nǹkan bii 25 ẹsẹ bata ni gígùn ni ipilẹṣẹ. O papọ jẹ 17 awọn abala awọ ẹran ti a fi tiṣọratiṣọra ṣe, eyi ti a ti fẹrẹẹ mú dán gẹgẹ bi iwe awọ. Bi a ti ṣeto kikọ rẹ̀ si òpó ìlà ọ̀rọ̀ 54 ti ọkọọkan ni tó ìlà 30 ni ipindọgba, awọn ila rẹ̀ ni a ti farabalẹ fà. Lori awọn ila wọnyi ni ọjafafa onkọwe kọ awọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ iwe naa si, ti a pin si ipinrọ.—Wo fọ́tò.
Iwe akajọ naa ni a kò wé mọ́ awọn ọ̀pá igi, o sì tubọ dúdú ni aarin nibi ti ọpọlọpọ ọwọ́ ti dì í mú fun kika. O ti gbó tán, pẹlu awọn atunṣe ti a fi oye iṣẹ́ ṣe ati awọn ibi ti a ti ṣàbùlẹ̀ wọn ti o han gbangba. Itọju pamọ rere rẹ̀ jẹ nitori pe a ti fi tiṣọratiṣọra dé e pa sinu ìṣà. Bawo ni o ti niyelori tó fun ọmọwe akẹkọọ Bibeli jinlẹ, ati bi a ba nasẹ rẹ siwaju, fun gbogbo wa?
Iwe afọwọkọ yii ti wolii Aisaya fi nǹkan ti o to ẹgbẹrun ọdun kan lọjọ lori ju ẹ̀dà eyikeyii miiran ti o ṣì wà. Sibẹ awọn ọ̀rọ̀ inu rẹ̀ ni kò yatọ lọna pupọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Millar Burrows, oluyẹwo-ṣatunṣe ọ̀rọ̀ iwe ti a tẹjade ni 1950, naa wi pe: “Ọ̀rọ̀ ẹsẹ iwe Aisaya ninu iwe afọwọkọ yii, pẹlu awọn iyatọ pupọ ninu sípẹ́lì ọ̀rọ̀ ati gírámà ati ọpọlọpọ oniruuru awọn kíkà ti o runi lọkan soke ti o si ni ijẹpataki de aye kan lọna kan ṣaa, jẹ eyi ti a gbekalẹ ninu MT [Masoretic Hebrew Text] lọna ti o pọ julọ lẹhin naa.”a Bakan naa eyi ti o yẹ fun afiyesi ni iṣedeedee rẹ̀ ninu lilo lẹta Heberu mẹrin naa, יהוה, fun orukọ mimọ Ọlọrun, Jehofa.
Awọn Iwe Afọwọkọ Miiran Ti Wọn Niyelori
Orukọ atọrunwa naa tun farahan ninu iwe afọwọkọ miiran lati inu iho àpáta kan naa yii, ti a mọ̀ nisinsinyi gẹgẹ bi Iho Àpáta 1. Ninu ọrọ alaye lori iwe Habakuku, lẹta Heberu mẹrin naa fun orukọ Ọlọrun farahan ni ìgbà mẹrin ninu awọn lẹta Heberu atijọ, ọna ikọwe atijọ kan ti o yatọ si ọna ikọwe onigun mẹrin ti lẹta Heberu ti a tubọ mọ dunju.—Wo alaye eti iwe si Habakuku 1:9, Reference Bible.
Iho àpáta naa mu apa miiran ninu iwe akajọ Aisaya jade, papọ pẹlu awọn ẹ̀búbù awọ lati inu iwe Bibeli ti Daniẹli. Ọkan ninu iwọnyi pa iyipada lati Heberu si Aramaiki mọ́ ni Daniẹli 2:4, gẹgẹ bi a ṣe rí i ninu iwe afọwọkọ ti ẹgbẹrun ọdun lẹhin naa.
Awọn apa kekeke ninu awọn iwe akajọ naa ti a pamọ daradara ni a tẹ́fádà rẹ̀ bayii ni Jerusalẹmu, ninu ilé ti wọn nko ohun iṣẹmbaye pamọ si ti a mọ̀ gẹgẹ bi Ojúbọ Iwe. Ile ti wọn nko ohun iṣẹmbaye si yii wà ni abẹ́ ilẹ̀, nitori naa bi iwọ ṣe nbẹ ibẹ̀ wò, iwọ ni imọlara naa pe iwọ nwọnu iho àpáta kan. Apa òkè ile ti wọn nko ohun iṣẹmbaye pamọ si naa ní ìrísí ìdérí ìṣà alámọ̀ naa ninu eyi ti a ti ri iwe akajọ Okun Òkú ti Aisaya. Sibẹsibẹ, iwọ yoo rí kìkì ẹdaya iwe afọwọkọ Aisaya. Ti ipilẹṣẹ aṣeyebiye naa wà laisewu ninu iyàrá ti wọn nko nǹkan pamọ si lẹba ibẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Diẹ ninu awọn kika rẹ̀ ti o tubọ ṣe pataki ni a tọkasi ninu New World Translation of the Holy Scriptures—With References ni Aisaya 11:1; 12:2; 14:4; 15:2; 18:2; 30:19; 37:20, 28; 40:6; 48:19; 51:19; 56:5; 60:21. Iwe akajọ naa ni a fihan yatọ ninu alaye eti iwe gẹgẹ bi 1QIsa.
[Àwọ̀n àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
Ifọwọsowọpọ Ọlawọ Ibi akojọ Ohun Iṣẹmbaye ti Britain
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]
Alaṣẹ Lori Ohun Iṣẹmbaye Israẹli; Ojubọ Iwe, Ile Akojọ Ohun Iṣẹmbaye ti Israel; Ibudo Awọn Iwe-afọwọkọ Bibeli ti D. Samuel ati Jeanne H. Gottesman