Awọn Adura Ti O Daju Pe A O Dahun
AWỌN adura ti o daju pe a o dahu wà. Awọn koko wọn ni a papọ sinu awokọṣe ti Jesu Kristi fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nigba ti o wi pe: “Ẹyin gbọdọ gbadura, nigba naa, lọna yii: ‘Baba wa ninu awọn ọ̀run, Jẹ ki a sọ orukọ rẹ di mímọ́. Jẹ ki ijọba rẹ de. Je ki ifẹ-inu rẹ di ṣiṣe, gẹgẹ bii ni ọ̀run, lori ilẹ-aye pelu.”—Matiu 6:9-13, NW.
Awọn ọrọ adura awokọṣe Jesu wọnni ni a ti sọ ni asọtunsọ ni ọpọlọpọ araadọta ọkẹ igba. Bi o tilẹ jẹ pe Kristi ko reti pe ki awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ wulẹ ka akasori iru adura bẹẹ, awọn adura ẹbẹ wọn tí nsọ ero ti o farajọra jade ni o daju pe a o dahun. (Matiu 6:7, 8) Nitori naa, ki ni o tumọ si lati sọ orukọ Ọlọrun di mímọ́? Eeṣe ti a fi ngbadura fun Ijọba rẹ̀ pe ki o dé? Eesitiṣe ti a fi nbeere pe ki ifẹ-inu Ọlọrun di ṣiṣe?
“Jẹ Ki A Sọ Orukọ Rẹ Di Mímọ́”
Jehofa, “Ọga ogo lori aye gbogbo,” ni Ẹni naa ti Jesu pe ni “Baba wa ti nbẹ ninu awọn ọrun.” (Saamu 83:18) Ọlọrun ti “jẹ́ baba fún” awọn ọmọ Isirẹli nipa dida wọn silẹ kuro ninu oko-ẹru Ijibiti ati nipa wiwọnu ipo ibatan onimajẹmu pẹlu wọn. (Deutaronomi 32:6, 18, NW; Ẹkisodu 4:22; Aisaya 63:16) Lonii, awọn Kristẹni ẹni ami ororo ni ikasi onifẹẹ fun Jehofa gẹgẹ bi Baba wọn. (Roomu 8:15) Awọn alabaakẹgbẹ wọn pẹlu, ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye, ngbadura si Jehofa Ọlọrun bakan naa gẹgẹ bi Baba wọn.—Johanu 10:16; Iṣipaya 7:1-9.
Ṣugbọn eeṣe ti a fi ngbadura fun ìsọdimímọ́ orukọ Ọlọrun? O dara, lati igba iṣọtẹ eniyan meji akọkọ ninu ọgba Edeni, ẹgan ni a ti mu wa sori orukọ atọrunwa naa. Ni idahun si iru adura bẹẹ, Jehofa yoo mu gbogbo ẹgan ti a ti mu wa sori orukọ manigbagbe rẹ̀ kuro. (Saamu 135:13) Oun yoo ṣe eyi nipa mimu iwa buburu kuro lori ilẹ-aye. Nipa akoko yẹn, Ọlọrun sọ nipasẹ wolii Esikiẹli pe: “Dajudaju emi yoo gbe araami ga lọla emi yoo si sọ araami di mímọ́ ki nsi sọ araami di mímọ̀ niwaju ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede; wọn yoo si nilati mọ pe emi ni Jehofa.”—Esikiẹli 38:23, NW.
Jehofa Ọlọrun jẹ mímọ́ ati alaileeri. Orukọ rẹ̀ ni a nilati sọ di mímọ́ nigba naa, tabi yà sọtọ gẹgẹ bi mímọ́. Oun yoo ṣaṣefihan ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ nipa gbigbegbeesẹ lati sọ araarẹ di mímọ́ niwaju gbogbo iṣẹda. (Esikiẹli 36:23) Awọn wọnni ti wọn nfẹ ojurere rẹ̀ ati iye ayeraye gbọdọ ka Jehofa sí pẹlu ìwárìrì ki wọn si sọ orukọ rẹ̀ di mímọ́ nipa pipa a mọ gẹgẹ bi eyi ti o yatọ sí omiran ti o si ga ju gbogbo wọn lọ. (Lefitiku 22:32; Aisaya 8:13; 29:23) Lọna ti o ba a mu, Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura pe: “Jẹ ki a sọ orukọ rẹ di mímọ́” tabi, “pa a mọ ni mímọ́; ka a si mímọ́.” A le ni idaniloju pe Ọlọrun yoo dahun apa yii ninu adura awokọṣe Jesu.
“Jẹ Ki Ijọba Rẹ De”
Jesu tun sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura pe: “Jẹ ki ijọba rẹ de.” Adura fun dide Ijọba Ọlọrun ni o daju pe a o dahun. Ijọba naa jẹ ipo iṣakoso ọba alaṣẹ ti Jehofa gẹgẹ bi a ti fihan nipasẹ ijọba Mesaya ti ọrun ni ọwọ Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ati “awọn eniyan mímọ́” alabaakẹgbẹ. (Daniẹli 7:13, 14, 18, 22, 27; Aisaya 9:6, 7) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fẹri han tipẹtipẹ lati inu Iwe mimọ pe Jesu ni a gbekari itẹ gẹgẹ bi Ọba ti ọrun ni ọdun 1914. Eeṣe, nigba naa, ti ẹnikan fi nilati gbadura fun Ijọba naa pe ki o “de”?
Gbigbadura fun dide Ijọba naa niti gidi tumọ si bibeere pe ki o wá lodisi gbogbo awọn aṣodi si ipo iṣakoso atọrunwa lori ilẹ-aye. Laipẹ nisinsinyi “ijọba [ti Ọlọrun] . . . yoo si fọ́ gbogbo ijọba wọnyi [ti ilẹ-aye] tuutuu, yoo si pa wọn run; ṣugbọn oun o duro titi laelae.” (Daniẹli 2:44) Iṣẹlẹ yii yoo fikun idalare orukọ mímọ́ ti Jehofa.
“Jẹ Ki Ifẹ-inu Rẹ Di Ṣiṣe”
Siwaju sii Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni itọni lati gbadura pe: “Jẹ ki ifẹ-inu rẹ di ṣiṣe, gẹgẹ bii ni ọ̀run, lori ilẹ-aye pẹlu.” Eyi jẹ ibeere tọwọtọwọ pe ki Jehofa gbegbeesẹ ni ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀ fun ilẹ-aye. O baramu pẹlu ipolongo onisaamu naa pe: “Ohunkohun ti o wu Oluwa [“Jehofa,” NW], ohun ni o ti ṣe ni ọrun, ati ni aye, ni okun, ati ni ọgbun gbogbo. O mu ikuuku goke lati opin ilẹ wá: o dá mọnamọna fun ojo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá. Ẹni ti o kọlu awọn akọbi Ijibiti, ati ti eniyan ati ti ẹranko. Ẹni ti o ran ami ati iṣẹ iyanu si aarin rẹ, iwọ Ijibiti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ẹni ti o kọlu awọn orilẹ-ede pupọ, ti o si pa awọn alagbara ọba.”—Saamu 135:6-10.
Gbigbadura pe ki ifẹ-inu Jehofa di ṣiṣe lori ilẹ-aye jẹ́ ibeere tọwọtọwọ pe ki o mu awọn ete rẹ̀ ṣẹ siha obiri aye yii. Eyi ni ninu imukuro awọn alatako rẹ̀ patapata, ani gẹgẹ bi oun ti mu wọn kuro ni iwọn kekere ni awọn akoko igbaani. (Saamu 83:9-18; Iṣipaya 19:19-21) Awọn adura fun ifẹ-inu Jehofa lati di ṣiṣe jakejado ilẹ-aye ati gbogbo agbaye ni o daju pe a o dahun.
Nigba Ti Ijọba Naa Ba Nṣakoso
Dipo iwa buburu ti o gbalẹ ninu awujọ eniyan isinsinyi, ki ni ohun ti a le reti nigba ti Ijọba Ọlọrun ba nṣakoso ti ifẹ-inu atọrunwa si di ṣiṣe lori ilẹ-aye gẹgẹ bii ni ọrun? Gẹgẹ bi apọsiteli Peteru ti wi, “gẹgẹ bi ileri [Ọlọrun], awa nreti awọn ọrun titun ati aye titun, ninu eyi ti ododo ngbe.” (2 Peteru 3:13) Awọn ọrun titun naa ni agbara iṣakoso ododo ti ẹmi—Jesu Kristi ati 144,000 ajumọjogun ninu Ijọba ti ọrun. (Roomu 8:16, 17; Iṣipaya 14:1-5; 20:4-6) “Aye titun” kii ṣe obiri aye miiran. Kaka bẹẹ, o jẹ awujọ awọn eniyan olododo ti wọn ngbe lori ilẹ-aye.—Fiwe Saamu 96:1.
Labẹ iṣakoso Ijọba, ilẹ-aye ni a o yipada si paradise yika ayé. (Luuku 23:43) Alaafia tootọ ati aasiki ni gbogbo araye onigbọran yoo gbadun nigba naa. (Saamu 72:1-15; Iṣipaya 21:1-5) Iwọ lè wà lara awọn awujọ nla alayọ wọnni bi iwọ ba jẹ agbẹnusọ aduroṣinṣin ti ipo iṣakoso ti Mesaya lori awọn ọmọ abẹ onigbọran ti ilẹ-aye. Awọn agbẹnusọ iru iṣakoso bẹẹ fi tọkantọkan gbadura fun isọdimimọ orukọ Jehofa, fun Ijọba rẹ̀ lati dé, ati fun ifẹ-inu rẹ̀ lati di ṣiṣe. Awọn adura atọkanwa wọn ni a o dahun dajudaju.