Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Eeṣe ti a fi ka 29 C.E. si deeti kan ti o ṣe pataki ninu itan Bibeli dipo 14 C.E., ibẹrẹ iṣakoso Tiberiu Kesari, ẹni ti a mẹnukan ni Luuku 3:1?
Ibẹrẹ iṣakoso Tiberiu ni a kò mẹnukan ninu Bibeli, ṣugbọn iṣẹlẹ kan eyi ti ó nṣẹlẹ ni apa igbẹhin ọdun Kẹẹdogun rẹ̀ ni a mẹnukan. Eyi mu ki awọn akẹkọọ Bibeli lè gbe iṣẹlẹ naa kalẹ gẹgẹ bi eyi ti o ṣẹlẹ ni 29 C.E., eyi ti a lè fojuwo gẹgẹ bi deeti ti ó ṣe pataki ni oju iwoye ti Bibeli.
Iṣakoso olu-ọba Roomu keji naa, Tiberiu Kesari, ni a tẹwọgba daradara ninu itan. The New Encyclopædia Britannica sọ pe: “Ni AD 14, ni August 19, Ọgọsitọsi [olu-ọba akọkọ] kú. Tiberiu, ẹni ti ó tobi julọ nisinsinyi, fi ọgbọn dari Igbimọ aṣofin àgbà fun anfaani araarẹ oun kò si gba a laaye lati sọ oun ni olu-ọba fun eyi ti ó fẹrẹẹ tó oṣu kan, ṣugbọn ni September 17 oun gori ipo iṣakoso titobi julọ.”a
Koko ti a gbekalẹ yii fun ibẹrẹ iṣakoso Tiberiu ni ó baramu ni ibamu pẹlu Bibeli nitori pe Luuku 3:1-3 sọ nipa iṣẹ ojiṣẹ Johanu Arinibọmi pe: “Ni ọdun kẹẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigba ti Pọntiu Pilatu jẹ́ Baalẹ, Judia, . . . ọrọ Ọlọrun tọ Johanu ọmọ Sekaraya wá ni ijù. Ó si wá si gbogbo ilẹ ìhà Jọdani, o nwaasu bamtisimu ironupiwada fun imukuro ẹṣẹ.”
Johanu kò bẹrẹ sii waasu ati lati maa bamtisi nigba ti Tiberiu di olu-ọba ṣugbọn oun ṣe bẹẹ “ni ọdun kẹẹdogun iṣakoso ti Tiberiu Kesari.” Ọdun Kẹẹdogun yẹn jẹ lati igba ìwọ́wé 28 C.E. si igba ìwọ́wé 29 C.E. Bi o ti wu ki o ri, mimọ eyi, kò fun ẹnikan lagbara lati pinnu lọna ti ó ṣe kongẹ kankan igba ti iṣẹ-ojiṣẹ Johanu bẹrẹ ni ọdun yẹn tabi bi a ṣe lè ṣiro awọn iṣẹlẹ ti ó tanmọ ọn.
Ṣugbọn Bibeli funni ni afikun isọfunni ti ó gbeṣẹ. Fun apẹẹrẹ, asọtẹlẹ Daniẹli ti “aadọrin ọsẹ” tọka si 29 C.E. fun ifarahan Mesaya. Ó tun fihan pe iṣẹ-ojiṣẹ Jesu yoo jẹ́ ọdun mẹta ati aabọ ni gigun. (Daniẹli 9:24-27) Fi awọn kulẹkulẹ Bibeli wọnyi kún eyi: A bi Jesu ni oṣu mẹfa lẹhin ìbí Johanu; nigba ti a baptisi Jesu, oun “jẹ́ nǹkan bi ẹni iwọn ọgbọn ọdun”; Jesu sì ku ni igba iruwe 33 C.E. (Akoko Ajọ-irekọja), nigba ti oun jẹ́ ẹni ọdun 33 1/2.—Luuku 1:24-38; 3:23; 22:14-16, 54.b
Pẹlu iru awọn isọfunni Bibeli ti ó ṣe pato bẹẹ, papọ pẹlu awọn kíkà ọjọ ti ayé nipa iṣakoso Tiberiu, awọn akẹkọọ Bibeli lè ṣiro pe iṣẹ-ojiṣẹ Johanu bẹrẹ ni igba iruwe 29 C.E. ati pe oṣu mẹfa lẹhin naa, ní ìgbà ìwọ́wé 29 C.E., Johanu bamtisi Jesu. Fun idi yii, kii ṣe 14 C.E. ṣugbọn 29 C.E. ni a foju wo gẹgẹ bii deeti ti o ṣe pataki ni oju iwoye ti Bibeli.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a September 17 lori kalẹnda Julius ṣe deedee pẹlu September 15 lori kalẹnda Gregory, kalẹnda naa ti a nlo nibi pupọ lonii.
b Fiwe Insight on the Scriptures, Idipọ 1, oju-iwe 458, 463, 467; Idipọ 2, oju-iwe 87, 899 si 902, 1099, 1100, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.