Jija Àjàbọ́ Kuro Ninu Isin Èké
“‘Ẹ jade kuro laaarin wọn, . . .’ ni Jehofa wi, ‘ẹ si jawọ ninu fifi ọwọ kan ohun aimọ . . .’ ‘emi yoo si gba yin wọle.’”—2 KỌRINTI 6:17, New World Translation.
1. Ki ni ìdúnàádúrà ti Satani gbiyanju lati ṣe pẹlu Jesu, awọn nǹkan meji wo si ni ṣiṣe ifilọni rẹ̀ yii fi kọ́ wa?
“GBOGBO nǹkan wọnyi ni emi yoo fi fun ọ bi iwọ ba wólẹ̀ ti o si ṣe iṣe ijọsin kan fun mi.” Bi o tilẹ jẹ pe ifilọni yii ni a ṣe ni ẹgbẹrun ọdun lẹhin ibẹrẹ ijọsin èké, o pese kọkọrọ naa lati loye ẹni ti o wa lẹhin ijọsin èké ati ohun ti ète rẹ̀ jẹ́. Ni apa ti ó kẹhin ninu ọdun 29 C.E., Eṣu fi gbogbo ijọba aye lọ Jesu ni paṣipaarọ fun iṣe ijọsin kan. Iṣẹlẹ pataki yii sọ awọn ohun meji fun wa: pe awọn ijọba ayé yii jẹ́ ti Satani lati fifunni ati pe olori gongo ète isin èké ni ijọsin Eṣu.—Matiu 4:8, 9, NW.
2. Ki ni a kẹkọọ rẹ̀ lati inu awọn ọrọ Jesu ni Matiu 4:10?
2 Nipa idahunpada rẹ̀, kii ṣe kiki pe Jesu kọ̀ ijọsin èké sílẹ̀ nikan ni ṣugbọn oun pẹlu fi ohun ti isin tootọ mulọwọ han. Oun polongo pe: “Lọ kuro, Satani! Nitori a ti kọ ọ pe, ‘Jehofa Ọlọrun rẹ ni iwọ gbọdọ jọsin, oun nikanṣoṣo ni iwọ si gbọdọ ṣe iṣẹ-isin mimọ fun.’” (Matiu 4:10, NW) Nitori naa, ète ijọsin tootọ, ni ijọsin Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, Jehofa. O mu igbagbọ ati igbọran, ṣiṣe ifẹ inu Jehofa lọwọ.
Ipilẹṣẹ Ijọsin Èké
3. (a) Nigba wo ati bawo ni isin èké ṣe bẹrẹ lori ilẹ-aye? (b) Ki ni iṣarasihuwa aifayegba ero igbgbọ isin ti kò baramu ti a kọ́kọ́ kọsilẹ, bawo sì ni inunibini isin ṣe nbaa lọ lati ìgbà naa wá?
3 Ijọsin èké bẹrẹ lori ilẹ-aye nigba ti awọn eniyan akọkọ ṣaigbọran si Ọlọrun ti wọn sì tẹwọgba ipetepero Ejo naa lati pinnu “rere ati buburu” fun araawọn. (Jẹnẹsisi 3:5) Ni ṣiṣe bẹẹ wọn kọ̀ ipo ọba alaṣẹ ododo ti Jehofa silẹ ti wọn sì pa ijọsin ti o tọ́ tì, isin tootọ. Wọn jẹ́ eniyan akọkọ “ti o yi otitọ Ọlọrun pada si èké, wọn si bọ, wọn si sin ẹ̀dá ju Ẹlẹdaa lọ.” (Roomu 1:25) Ẹ̀dá naa ti wọn yan lati jọsin laimọ kii ṣe ẹlomiran ju Satani Eṣu, “ejo laelae nì.” (Iṣipaya 12:9) Ọmọkunrin wọn ti o dagba julọ, Kaini, kọ̀ lati tẹle imọran alaaanu Jehofa ti o si tipa bayii ṣọtẹ lodisi ipo ọba alaṣẹ Rẹ. Yala o mọ̀ọ́mọ̀ tabi bẹẹkọ, Keeni di “ọmọ ẹni buburu naa,” Satani, ati oluṣe ijọsin Eṣu. O pa aburo rẹ̀ Ebẹli, ẹni ti o ṣe ijọsin tootọ, isin tootọ. (1 Johanu 3:12, Revised English Bible; Jẹnẹsisi 4:3-8; Heberu 11:4) Ẹ̀jẹ̀ Ebẹli ni ẹ̀jẹ̀ akọkọ ti a ta silẹ nitori aifayegba ero igbagbọ isin ti ko baramu. Ó banininujẹ lati sọ pe, isin èké ti nbaa lọ lati maa ta ẹ̀jẹ̀ alaiṣẹ silẹ titi di ọjọ oni gan-an.—Wo Matiu 23:29-35; 24:3, 9.
4. Ninu ọran ti Noa, awọn iwe mimọ wo ni wọn ṣapejuwe bi ijọsin tootọ ṣe ri?
4 Ṣaaju Ikun-omi, Satani ṣaṣeyọri ni yiyi eyi ti ó pọ julọ ninu araye kuro ninu isin tootọ. Bi o ti wu ki o ri, Noa, “ri ojurere loju OLUWA [“Jehofa,” NW].” Eeṣe? Nitori pe ó “nba Ọlọrun rin.” Ni ọrọ miiran, oun ṣe ijọsin tootọ. Isin tootọ kii ṣe ti aláyẹyẹ tabi ààtò isin ṣugbọn ọna igbesi-aye kan. Ó ni ninu fifi igbagbọ han ninu Jehofa ati fifi igbọran ṣiṣẹ sin in, ‘biba a rin.’ Noa ṣe eyi.—Jẹnẹsisi 6:8, 9, 22; 7:1; Heberu 11:6, 7.
5. (a) Ki ni Eṣu ngbiyanju lati fidii rẹ̀ mulẹ lẹhin Ikun-omi, bawo sì ni? (b) Bawo ni Jehofa ṣe ké iwewee Eṣu nígbèrí, ki sì ni abajade rẹ̀?
5 Kò pẹ́ pupọ lẹhin Ikun-omi naa, Eṣu lọna ti ó han gbangba lo Nimirọdu, ọkunrin kan ti ó jẹ́ olokiki buruku fun “iṣodisi Jehofa,” ninu isapa lati so gbogbo araye pọ ninu iru ijọsin kan ti yoo tako Jehofa lẹẹkan sii. (Jẹnẹsisi 10:8, 9, NW; 11:2-4) Ìbá ti jẹ́ isin èké oniṣọkan, ijọsin Eṣu ti a sopọṣọkan, ti a gbekalẹ si ilu naa ati ilé-ìsọ́ yẹn ti awọn olujọsin rẹ̀ nwewee lati kọ́. Jehofa ké ipete yii nígbèrí nipa dida “ede kan” ti gbogbo araye nsọ nigba naa rú. (Jẹnẹsisi 11:5-9) Nitori naa, ilu naa wa di eyi ti a pe ni Babeli, ati lẹhin naa Babiloni, awọn orukọ mejeeji ti ó tumọsi “Idarudapọ.” Idarudapọ èdè yii mú ìfọ́nkáàkiri araye si gbogbo ori ilẹ-aye wá.
6. (a) Ki ni awọn ero isin ti a fi sinu awọn olujọsin Satani ni Babiloni ṣaaju ìtúkálọ wọn? (b) Eeṣe ti awọn isin yika agbaye fi ni ero igbagbọ fifarajọra? (c) Ete Satani wo ni Babiloni ṣiṣẹ fun, ki sì ni ilu igbaani yẹn wa di ami iṣapẹẹrẹ fun?
6 Bi o ti wu ki o ri, yoo farahan, lori ipilẹ itan arosọ atọwọdọwọ ati isin, pe ṣaaju ifọnkaakiri araye yii lati ọwọ Jehofa, Satani ti gbin awọn koko pataki isin èké pato kan sinu ero inu awọn olujọsin rẹ̀. Eyi ni ninu igbagbọ onisin ti lilaaja ọkan lẹhin iku, ibẹru awọn oku, ati wíwà ibi ina àjóòkú ninu ilẹ ọba ẹmi kan, papọ pẹlu ijọsin ailonka awọn ọlọrun ati abo ọlọrun, diẹ ninu awọn ẹni ti a kó papọ ni mẹta-mẹta. Iru awọn igbagbọ bẹẹ ni a mu lọ si gbogbo ilẹ-aye nipasẹ oriṣiriṣi awọn awujọ ede. Bi akoko ti nlọ, awọn ero ipilẹ wọnyi bẹrẹsii pín si oriṣiriṣi. Ni gbogbogboo, wọn parapọ di ètò ìgbékalẹ̀ ijọsin èké ni gbogbo apa ilẹ-aye. Bi o tilẹ jẹ pe a ké igbidanwo rẹ̀ nígbèrí lati dá isin oniṣọkan silẹ pẹlu olu ilu agbaye rẹ̀ ni Babiloni, Satani faramọ iru ijọsin èké ti ó pín yẹlẹyẹlẹ, eyi ti ó misi lati Babiloni ti o sì pete rẹ̀ lati yi ijọsin kuro lọdọ Jehofa si araarẹ. Babiloni nbaa lọ fun ọpọ ọrundun lati jẹ́ aarin gbùngbùn agbara idari ti ibọriṣa, idán, iṣẹ-oṣo, ati ìwòràwọ̀sọtẹ́lẹ̀—gbogbo eyi ti ó jẹ́ apa ṣiṣe pataki ti isin èké. Lọna ti kò yanilẹnu, iwe Iṣipaya ṣapẹẹrẹ ilẹ ọba isin èké agbaye bii aṣẹwo oniwa ibajẹ ti a pe ni Babiloni Nla.—Iṣipaya 17:1-5.
Isin Tootọ
7. (a) Eeṣe ti idarudapọ èdè ko fi nipa lori ijọsin tootọ? (b) Ta ni a wá mọ̀ gẹgẹ bii “baba gbogbo awọn ti ó gbagbọ,” eesitiṣe?
7 Lọna ti ó ṣe kedere, isin tootọ ni dídà ti Jehofa dà ọna isọrọ araye rú ni Babeli kò nipa lé lori. Ijọsin tootọ ni awọn ọkunrin ati obinrin oluṣotitọ iru bii Ebẹli, Enoku, Noa, iyawo Noa, ati awọn ọmọkunrin Noa, ati awọn aya ọmọkunrin rẹ̀ ti ṣe ṣaaju Ikun-omi. Lẹhin Ikun-omi naa ijọsin tootọ ni a daabobo ni ila Ṣemu ọmọkunrin Noa. Aburahamu, ọmọ iran Ṣemu, ṣe isin tootọ ti a sì wá mọ ọn gẹgẹ bi “baba gbogbo awọn ti ó gbagbọ.” (Roomu 4:11) Igbagbọ rẹ̀ ni a tìlẹ́hìn nipasẹ awọn iṣẹ. (Jakobu 2:21-23) Ijọsin rẹ̀ jẹ́ ọna igbesi-aye kan.
8. (a) Bawo ni isin èké ṣe ko isin tootọ loju ni ọrundun kẹrindinlogun B.C.E., ki sì ni iyọrisi rẹ? (b) Ki ni iṣeto titun ti Jehofa filọlẹ nipa ijọsin mimọgaara rẹ?
8 Ijọsin tootọ ni a nbaa lọ lati maa ṣe ni ila awọn ọmọ iran Aburahamu—Isaaki, Jakọbu (tabi, Isirẹli), ati awọn ọmọkunrin 12 ti Jakọbu, lati inu eyi ti ẹ̀yà Isirẹli 12 ti jade. Ipari ọrundun 16 B.C.E. rí awọn ọmọ iran Aburahamu nipasẹ Isaaki ti wọn njijakadi lati pa isin mimọgaara mọ́ ninu ayika oniṣọta, ati oloriṣa kan—Ijibiti—nibi ti a ti fi wọn sabẹ isinru. Jehofa lo iranṣẹ oluṣotitọ rẹ̀ Mose, ti ẹya Lefi, lati dá awọn olujọsin Rẹ̀ nide kuro labẹ àjàgà Ijibiti, ilẹ kan ti ó ti rin gbingbin ninu isin èké. Nipasẹ Mose, Jehofa pari majẹmu kan pẹlu Isirẹli, ni fifi wọn ṣe eniyan ayanfẹ Rẹ̀. Ni akoko yẹn, Jehofa fi ijọsin rẹ̀ sabẹ awọn ètò ofin ti a kojọ, ni gbigbe e kalẹ fun igba diẹ laaarin ààlà eto awọn irubọ ti a nṣe nipasẹ ẹgbẹ́ alufaa kan ati pẹlu ibujọsin kan ti ó ṣee fojuri, lakọọkọ agọ isin naa ti ó ṣee gbé kaakiri ati lẹhin naa tẹmpili ni Jerusalẹmu.
9. (a) Bawo ni a ṣe nṣe ijọsin tootọ naa ṣaaju majẹmu Ofin? (b) Bawo ni Jesu ṣe fihan pe awọn ẹka ṣiṣeefojuri ti Ofin kò wà pẹtiti?
9 Bi o ti wu ki o ri, a nilati ṣakiyesi, pe awọn ẹka ti o ṣee fojuri wọnyi ni a kò pete lati di apakan isin tootọ naa ti o wa titilọ. Ofin naa jẹ́ “ojiji ohun ti nbọ.” (Kolose 2:17; Heberu 9:8-10; 10:1) Ṣaaju Ofin Mose, ni akoko awọn baba olori idile, ó ṣe kedere pe awọn olori idile ni wọn nṣoju fun agbo idile wọn ni ṣiṣe irubọ lori pẹpẹ ti wọn ti kọ́. (Jẹnẹsisi 12:8; 26:25; 35:2, 3; Joobu 1:5) Ṣugbọn kò sí ẹgbẹ́ alufaa ti a ṣetojọ tabi ètò awọn irubọ, pẹlu awọn ayẹyẹ ati aato isin. Siwaju sii, Jesu funraarẹ fi aiwa pẹtitilọ ijọsin eleto awọn ofin ti a kojọ ti a gbekalẹ si Jerusalẹmu han nigba ti ó sọ fun obinrin ara Samaria kan pe: “Wakati naa nbọ, nigba ti ki yoo ṣe lori oke yii, [Gerisimu, ibi tẹmpili awọn ara Samaria tẹlẹri] tabi ni Jerusalẹmu, ni ẹyin yoo maa sin Baba. . . . Ṣugbọn wakati nbọ, ó sì dé tan nisinsinyi, nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:21-23) Jesu fihan pe isin tootọ ni a gbọdọ ṣe, kii ṣe pẹlu awọn nǹkan ti ara, ṣugbọn pẹlu ẹmi ati otitọ.
Igbekun Babiloni
10. (a) Eeṣe ti Jehofa fi yọọda ki a kó awọn eniyan rẹ̀ nigbekun lọ si Babiloni? (b) Ni awọn ọna meji wo ni Jehofa fi da awọn oluṣotitọ àṣẹ́kù silẹ ni 537 B.C.E., ki si ni ete pataki ipada wọn si Juda?
10 Lati ìgbà iṣọtẹ ni Edeni, iṣọta wiwapẹtiti ti wà laaarin isin tootọ ati isin èké. Nigba miiran awọn olujọsin tootọ, ki a sọ ọ lọna iṣapẹẹrẹ, ni a ti mu ni igbekun nipasẹ isin èké, ti Babiloni jẹ apẹẹrẹ fun lati igba Nimirọdu. Ṣaaju ki Jehofa tó yọọda awọn eniyan rẹ̀ lati di awọn ti a kó ni igbekun lọ si Babiloni ni 617 B.C.E. ati 607 B.C.E., wọn ti ṣubu gẹgẹ bi ẹran ìjẹ sinu isin èké Babiloni. (Jeremaya 2:13-23; 15:2; 20:6; Esikiẹli 12:10, 11) Ni 537 B.C.E., awọn oluṣotitọ aṣẹku pada si Juda. (Aisaya 10:21) Wọn kọbiara si ikesini alasọtẹlẹ naa pe: “Ẹ jade kuro ni Babiloni!” (Aisaya 48:20) Eyi ki yoo wulẹ jẹ́ idande nipa ti ara lasan kan. Ó jẹ́ idande nipa tẹmi kan pẹlu kuro ninu ayika eleeeri, ti ijọsin èké onibọriṣa. Awọn aṣẹku oluṣotitọ yii nitori naa ni a pa a laṣẹ fun pe: “Ẹ fasẹhin, ẹ fasẹhin, ẹ jade kuro laaarin rẹ̀; ẹ má fọwọkan ohun aimọ kan; ẹ kuro laaarin rẹ̀, ẹ jẹ́ mímọ́, ẹyin ti ngbe ohun èèlò Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Aisaya 52:11) Ete pataki ti pipada wọn si Juda ni lati tun ijọsin mimọgaara gbekalẹ, isin tootọ.
11. Ni afikun si imupadabọsipo ijọsin mimọgaara ni Juda, ki ni awọn idagbasoke isin titun ti ó ṣẹlẹ ni ọrundun kẹfa B.C.E.?
11 Lọna ti ó muni lọkan yọ̀, ọrundun kẹfa B.C.E. kannaa ṣẹlẹrii awọn akọtun ẹka isin èké laaarin Babiloni Nla. Ó ri ìbí isin Buddha, Confucious, Zoroastrian, ati Jain, ki á má tíì sọ ti imọ-ọran Giriiki agbíyèlé ọgbọn ironu ti ó wa lo agbara idari lọna titobi lẹhin naa lori awọn ṣọọṣi Kristẹndọmu. Nitori naa nigba ti ijọsin mimọgaara di eyi ti a mupadabọsipo ni Juda, olori ọta Ọlọrun npese awọn yiyan gbigbooro sii miiran ninu isin èké.
12. Idande wo kuro ninu igbekun Babiloni ni ó ṣẹlẹ ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., ki sì ni ikilọ ti Pọọlu fifunni?
12 Nigba ti Jesu fi maa farahan ni Isirẹli, eyi ti ó pọ̀ julọ lara awọn Juu nṣe oniruuru isin awọn Juu, iru isin kan ti ó gba ọpọlọpọ ero isin Babiloni wọle. Ó ti so araarẹ mọ Babiloni Nla. Kristi dẹbi fun un ti ó si gba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ silẹ kuro ninu igbekun Babiloni. (Matiu, ori 23; Luuku 4:18) Niwọn bi isin èké ati imọ-ọran Giiriki ti wọpọ kaakiri ni awọn agbegbe ibi ti oun ti waasu, apọsiteli Pọọlu fa ọrọ asọtẹlẹ Aisaya yọ ti ó sì lò ó fun awọn Kristẹni, ti wọn nilati pa ara wọn mọ kuro ninu agbara idari alaimọ ti Babiloni Nla. Oun kọwe pe: “Ifohunṣọkan wo ni tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu awọn oriṣa [Babiloni]? Nitori awa jẹ́ tẹmpili Ọlọrun alaaye; gan-an gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi pe: ‘Emi yoo maa gbe aarin wọn emi yoo sì maa rìn ni aarin wọn, emi yoo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yoo sì jẹ́ eniyan mi.’ ‘“Nitori naa ẹ jade kuro laaarin wọn, ki ẹ sì ya araayin sọtọ,” ni Jehofa wi, “ẹ sì jawọ ninu fifọwọkan ohun aimọ”’; ‘“emi yoo sì gbà yin wọle.”’”—2 Kọrinti 6:16, 17, NW.
Jíja Àjàbọ́ Kuro Lọwọ Isin Èké ni Akoko Opin
13. Ki ni awọn ihin-iṣẹ ti Kristi firanṣẹ si awọn ijọ meje ni Asia Kékeré fihan, ki ni ó sì jẹyọ gẹgẹ bi abajade eyi?
13 Awọn ihin-iṣẹ naa ti Kristi fi ranṣẹ si awọn ijọ meje ni Aṣia Kékeré nipasẹ Iṣipaya ti a fifun apọsiteli Johanu fihan kedere pe nigba ti yoo fi di òpin ọrundun kìn-ín-ní C.E., awọn aṣa isin Babiloni ati ẹmi ironu rẹ̀ ti nyọkẹlẹ wọnu ijọ Kristẹni. (Iṣipaya, ori 2 ati 3) Ipẹhinda gbèrú paapaa julọ lati ọrundun keji si ọrundun karun-un C.E., ti ó yọrisi iyọjade afijọ oniwa ibajẹ ti isin Kristẹni mimọgaara. Iru awọn igbagbọ Babiloni bẹẹ gẹgẹ bii aileku ọkan, ọrun apaadi ti ńjó fofo, ati Mẹtalọkan ni a muwọnu awọn ẹkọ isin Kristẹni apẹhinda. Katoliki, Orthodox, ati lẹhin naa awọn ṣọọṣi Protẹstanti ni gbogbo wọn tẹwọgba ẹkọ èké alaijanpata wọnyi, nitori naa, wọn di apakan Babiloni Nla, ilẹ ọba isin èké agbaye Eṣu.
14, 15. (a) Ki ni apejuwe Jesu nipa alikama ati èpò fihan? (b) Ki ni ó ṣẹlẹ niha opin ọrundun kọkandinlogun, ati ni 1914, itẹsiwaju wo ni awọn Kristẹni tootọ ti ni niti ẹkọ igbagbọ?
14 Isin tootọ ni a kò tii fìgbàkanrí parun patapata. Awọn olufẹ otitọ ti fi igba gbogbo wà jalẹ awọn ọrundun, diẹ ninu awọn ẹni ti wọn kú fun iṣotitọ wọn si Jehofa ati Ọrọ rẹ̀, Bibeli. Ṣugbọn gẹgẹ bi apejuwe Jesu ti irugbin rere ati èpò ti fihan, irugbin rere afiṣapẹẹrẹ naa, tabi awọn ẹni ami ororo ọmọkunrin Ijọba naa, ni a o yà sọtọ kuro ninu awọn epo nikan, tabi awọn ọmọkunrin ẹni buburu nì, ni “igbẹhin aye.” (Matiu 13:24-30, 36-43) Bi akoko opin naa—akoko fun iyasọtọ yii lati ṣẹlẹ—ti sunmọle, awọn akẹkọọ Bibeli oloootọ inu ni apa ipari ọrundun kọkandinlogun bẹrẹ sii ja àjàbọ́ kuro labẹ ìdè isin èké.
15 Nigba ti ó fi maa di 1914 awọn Kristẹni wọnyi, ti a mọ̀ lonii bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti mu igbagbọ lilagbara dagba ninu irapada naa. Wọn mọ pe wiwanihin-in Kristi gbọdọ jẹ́ alaiṣeefojuri. Wọn loye pe 1914 yoo samisi opin “akoko awọn Keferi.” (Luuku 21:24) Wọn sì loye itumọ ọkàn ati ajinde ni kedere. Wọn tun ni ilaloye nipa iṣina lilekenka niti awọn ẹkọ ṣọọṣi lori ọrun apaadi ati Mẹtalọkan. Wọn kẹkọọ wọn sì bẹrẹ sii lo orukọ atọrunwa naa ti wọn sì lóye aitọ aba ero ori ẹfoluṣọn ati aṣa ibẹmiilo.
16. Ipe wo ni awọn Kristẹni ẹni ami ororo dahun pada si ni 1919?
16 Ibẹrẹ rere ni a ti ṣe nipa jíjá ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ isin èké. Ati ni 1919, Babiloni Nla padanu ijẹgaba rẹ̀ patapata lori awọn eniyan Ọlọrun. Gan-an bi awọn aṣẹku awọn Juu ti di ẹni ti a danide kuro ni Babiloni ni 537 B.C.E., bẹẹ sì ni awọn oluṣotitọ aṣẹku ẹni ami ororo Kristẹni kọbiara si ipe naa lati “jade kuro laaarin rẹ̀ [Babiloni Nla].”—Aisaya 52:11.
17. (a) Ki ni ó gbèrú lati 1922 siwaju, aini wo ni o sì mu ki awọn eniyan Ọlọrun nimọlara oun? (b) Ki ni ipo ti ó yatọ patapata ti a tẹwọgba, eesitiṣe ti a fi lè loye eyi?
17 Lati 1922 siwaju, awọn gbankọgbì otitọ Bibeli ni a tẹjade ti a sì pín kiri ni gbangba, ni titudii aṣiri isin èké Babiloni, paapaa julọ awọn ṣọọṣi Kristẹndọmu. Aini naa ni a rí lati tẹ̀ ẹ́ mọ ọkàn awọn eniyan Ọlọrun ti a ti sọ di mímọ́ pe jíja àjàbọ́ kuro ninu gbogbo oriṣi ijọsin èké nilati jẹ́ patapata. Nipa bayii, fun ọpọlọpọ ọdun, koda ilo ọrọ naa “isin” ni a yẹra fun nigba ti a ba nsọrọ nipa ijọsin mimọgaara. Awọn ọrọ iwuri, iru bii “Isin Jẹ Idẹkun Ati Wàyó,” ni a gbe kaakiri ni awọn opopona ilu nla. Awọn iwe iru bii Government (1928) ati “The Truth Shall Make You Free” (1943) fi iyatọ ti ó han gbangba han laaarin “isin Kristẹni” ati “isin.” Ipo ti ó yatọ de gongo yii ṣee loye, niwọn bi àjàbọ́ kuro patapata ni a nilati ṣe pẹlu gbogbo awọn eto isin Babiloni Nla ti ó ti gbilẹ kaakiri.
Isin Tootọ ati Èké
18. Ki ni òye titun nipa “isin” ti a fifunni ni 1951, bawo ni a sì ṣe ṣalaye eyi ninu 1975 Yearbook?
18 Lẹhin naa, ni 1951, akoko tó fun Jehofa lati fun awọn eniyan rẹ̀ ni òye mimọgaara bii kristali nipa iyatọ laaarin isin tootọ ati isin èké. Iwe ọdọọdun naa 1975 Yearbook of Jehovah’s Witnesses rohin pe: “Ni 1951, awọn agbẹnusọ fun ijọsin tootọ kẹkọọ ohun kan ti ó ṣe pataki nipa ọrọ ede naa ‘isin.’ Diẹ ninu wọn le ranti 1938 daradara nigba ti, ni awọn ìgbà miiran, wọn ngbe ami amunironujinlẹ naa ‘Isin Jẹ Idẹkun ati Wàyó’ kiri.’ Lati oju iwoye tiwọn nigba naa, gbogbo ‘isin’ kii ṣe ti Kristẹni, ó jẹ́ lati ọdọ Eṣu. Ṣugbọn Ilé-ìṣọ́nà ti March 15, 1951, fọwọsi ìlò awọn ọrọ apọnle naa ‘tootọ’ ati ‘èké’ nipa isin. Siwaju sii, iwe agbafiyesi patapata naa What Has Religion Done for Mankind? (ti a tẹjade ni 1951 ti a sì mujade nigba apejọpọ ‘Ijọsin Mimọ’ ni Papa iṣere Wembley, London, England) ni eyi lati sọ: ‘Ki a mu un ni ọna ti a gba lo o, “isin” ni itumọ rẹ̀ ti ó rọrun julọ tumọsi ijọsin kan, iru ijọsin kan, laika yala ó jẹ́ ijọsin tootọ tabi èké si. Eyi fohunṣọkan pẹlu ọrọ Heberu ti ó wà fun un, ’a·boh·dáh, eyi ti ó tumọ lowuuru si “iṣẹ-isin”, laika ẹni ti a nṣe e fun sí.’ Lẹhin naa, ọrọ naa ‘ijọsin èké’ ati ‘ijọsin tootọ’ wá wọpọ laaarin awọn ẹlẹ́rìí Jehofa.”—Oju-iwe 225.
19, 20. (a) Eeṣe ti ọkan awọn olujọsin tootọ ko fi nilati gbọgbẹ nipa ìlo ọrọ naa “isin” gẹgẹ bi a ṣe lo o fun ijọsin mimọgaara? (b) Ki ni òye titun yii ti mu ki ó ṣeeṣe fun awọn eniyan Jehofa lati ṣe?
19 Ni idahun si ibeere onkọwe kan, Ilé-ìṣọ́nà August 15, 1951, (Gẹẹsi) sọ pe: “Kò si ẹnikẹni ninu wa ti ọkan rẹ̀ gbọdọ gbọgbẹ nipa ìlò ede naa ‘isin’. Nitori pe a nlo o ko fi wa sinu ẹgbẹ ti o wa labẹ ìdè aṣa atọwọdọwọ, bi pipe araawa ni Kristẹni ko ti kó wa pọ̀ mọ awọn Kristẹndọmu.”
20 Bi o ti jẹ pe kii ṣe ijuwọsilẹ rara, òye titun yii nipa ọrọ naa “isin” mu ki ó ṣeeṣe fun awọn eniyan Jehofa lati mu ọgbun nla ti ó wà laaarin ijọsin tootọ ati ti èké gbooro sii, gẹgẹ bi ọrọ-ẹkọ ti ó tẹle e yii yoo ti fihan.
Lati Dán Òye Wa Wò
◻ Nigba wo ati bawo ni isin èké ṣe bẹrẹ lori ilẹ-aye?
◻ Ki ni ohun ti Satani gbiyanju lati gbekalẹ lẹhin Ikun-omi, bawo sì ni a ṣe ké iwewee rẹ̀ nígbèrí?
◻ Ki ni Babiloni di ami iṣapẹẹrẹ fun?
◻ Awọn idande wo ni ó ṣẹlẹ ni 537 B.C.E., ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., ati ni 1919?
◻ Òye titun wo nipa ọrọ naa “isin” ni a fifunni ni 1951, eesitiṣe ti ó fi jẹ́ nigba naa?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Awọn ẹkọ èké ti a gbagbọ yika gbogbo aye ni ipilẹṣẹ wọn ni Babiloni:
◻ Awọn Ọlọrun Mẹtalọkan, tabi mẹta-ninu-ọkan, awọn ọlọrun
◻ Ọkan eniyan nla iku já
◻ Ibẹmiilo—biba “oku” sọrọ
◻ Ilo awọn ère ninu ijọsin
◻ Ilo èèdì lati tù awọn ẹmi Eṣu lójú
◻ Iṣakoso lati ọwọ ẹgbẹ alufaa ti ó lagbara