Ayọ Tootọ Ninu Ṣiṣiṣẹsin Jehofa
“Alayọ ni ẹni naa ti ó ni Ọlọrun Jakọbu fun iranlọwọ rẹ̀, ẹni ti ireti rẹ̀ wà ninu Jehofa Ọlọrun rẹ̀.”—SAAMU 146:5, NW.
1, 2. Ki ni a ti sọ nipa itumọ ayọ, ki sì ni ayọ tumọsi fun ọpọ eniyan lonii?
KI NI ayọ? Awọn olùṣèwé asọ̀tumọ̀-ọ̀rọ̀, awọn ọlọgbọn ìmọ̀-ọ̀ràn, ati awọn ẹlẹkọọ-isin ti ń gbiyanju lati sọ itumọ rẹ̀ fun ọpọ ọrundun. Ṣugbọn wọn kò tii pese itumọ ti o tíì ní itẹwọgba onifohunṣọkan. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa Encyclopædia Britannica gbà pe: “Ayọ jẹ́ ọ̀kan lara awọn ọ̀rọ̀ ti ń foniru julọ.” Ó ṣe kedere pe ayọ tumọsi oriṣiriṣi nǹkan fun oriṣiriṣi eniyan, ó sinmi lori bi oju iwoye wọn ti rí nipa igbesi-aye.
2 Fun ọpọlọpọ eniyan, ayọ rọ̀gbà yíká ilera didara, awọn ohun ìní ti ara, ati ipo ibakẹgbẹ gbigbadunmọni. Sibẹ, awọn eniyan ti wọn ni gbogbo iyẹn wà ṣugbọn ti wọn kò layọ. Fun awọn ọkunrin ati obinrin ti a yasimimọ fun Jehofa Ọlọrun, Bibeli pese ipilẹ èro kan fun ayọ ti ó yatọ gédégédé si oju-iwoye gbogbogboo.
Oju-Iwoye Yiyatọ Kan Nipa Ayọ
3, 4. (a) Ta ni Jesu pe ni alayọ? (b) Ki ni a lè ṣakiyesi niti awọn kókó abajọ fun ayọ ti Jesu mẹnukan?
3 Ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke, Jesu Kristi kò sọ pe ayọ sinmi lori ilera didara, awọn ohun ìní, ati iru bẹẹ. Ó pe awọn wọnni “ti aini wọn nipa tẹmi ń jẹ lọkan” ati awọn wọnni “ti ebi ń pa ti oungbẹ sì ń gbẹ fun ododo” ni alayọ nitootọ. Eyi ti ó tan mọ awọn kókó meji ti a nilo fun ayọ tootọ wọnyi ni gbolohun ọrọ Jesu ti o dabi ẹnà pe: “Alayọ ni awọn wọnni ti ń ṣọ̀fọ̀, niwọn bi a o ti tù wọn ninu.” (Matiu 5:3-6, NW) Lọna ti o han gbangba, kì í ṣe pe Jesu ń sọ pe awọn eniyan yoo jẹ́ alayọ lẹṣẹkẹsẹ nigba ti wọn bá padanu ololufẹ kan. Kaka bẹẹ, oun ń sọrọ nipa awọn wọnni ti wọn kẹ́dùn ipo wọn ti o kun fun ẹṣẹ ati awọn abajade rẹ̀.
4 Apọsiteli Pọọlu sọrọ nipa iṣẹda eniyan tí ń kerora labẹ ẹṣẹ lori ipilẹ ireti pe oun ni a o “dá silẹ lominira kuro ninu ìsọnidẹrú si idibajẹ.” (Roomu 8:21, 22, NW) Awọn eniyan ti wọn tẹwọgba ipese aṣètùtù fun ẹṣẹ nipasẹ ẹbọ irapada Kristi ti wọn sì ṣe ifẹ-inu Ọlọrun ni a tù ninu ti a sì sọ di alayọ nitootọ. (Roomu 4:6-8) Ninu Iwaasu lori Oke, Jesu tun pe “awọn ọlọkantutu,” “awọn alaaanu,” “ọlọkan mimọgaara,” ati “ẹni ti ń wá alaafia” ni alayọ. Ó funni ni idaniloju naa pe bi a tilẹ ṣe inunibini sí wọn, iru awọn ọlọkantutu bẹẹ ki yoo padanu ayọ wọn. (Matiu 5:5-11, NW) Ó fanilọkan mọra lati ṣakiyesi pe okunfa ayọ ti a gbega soke wọnyi fi awọn ọlọ́rọ̀ ati talaka sinu ipo kan naa.
Ipilẹ fun Ayọ Gidi
5. Ki ni ipilẹ fun ayọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn ti ṣe iyasimimọ?
5 Orisun ayọ tootọ ni a kò rí ninu ọrọ̀ ti ara. Ọlọgbọn Ọba Solomọni sọ pe: “Ibukun Oluwa [“Jehofa,” NW] ni i mú nií là, kìí sìí fi làálàá pẹlu rẹ̀.” (Owe 10:22) Fun awọn iṣẹda ti wọn jẹwọ ipo ọba-alaṣẹ agbaye ti Jehofa, ayọ tanmọ ibukun Ọlọrun lọna ti kò ṣee yasọtọ. Eniyan kan ti o ti ṣeyasimimọ ti ó ní ti ó sì nimọlara ibukun Jehofa lori rẹ̀ lọkunrin tabi lobinrin jẹ́ alayọ nitootọ. Ti a bá wò ó lọna ti o bá Bibeli mu, ayọ wémọ́ imọlara ẹmi itẹlọrun, itẹlọrun, ati ìkúnjú ìwọ̀n ninu iṣẹ-isin Jehofa.
6. Ki ni a beere fun lọdọ awọn eniyan Jehofa fun wọn lati jẹ alayọ nitootọ?
6 Ayọ tootọ sinmi lori ipo ibatan titọ pẹlu Jehofa. A gbé e kari ifẹ fun Ọlọrun ati iṣotitọ si i. Awọn iranṣẹ Jehofa oluṣeyasimimọ fi tọkantọkan fọwọsi awọn ọrọ Pọọlu pe: “Kò sí ẹni kankan ninu wa, nitootọ, ti o wà nipa ti araarẹ̀ nikan . . . Awa walaaye fun Jehofa . . . Awa jẹ́ ti Jehofa.” (Roomu 14:7, 8, NW) Nitori naa, ayọ tootọ ni ọwọ́ kò le tẹ̀ laisi iṣegbọran si Jehofa ati itẹriba alayọ fun ifẹ-inu rẹ̀. Jesu sọ pe: “Alayọ ni awọn wọnni ti ń gbọ́ ọrọ Ọlọrun ti wọn sì ń pa a mọ́!”—Luuku 11:28, NW.
Awọn Okunfa Ayọ Ti Wọn Lè Yàtọ̀
7, 8. (a) Bawo ni a ṣe lè pín awọn koko abajọ fun ayọ ni ìsọ̀rií-ìsọ̀rí? (b) Ki ni a lè sọ nipa igbeyawo ati ọmọ bíbí?
7 Awọn okunfa ayọ ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tan yii ni a lè pe ni “awọn kókó ìpìlẹ̀,” tabi “awọn nǹkan ti ń ṣẹlẹ nigba gbogbo,” nitori pe wọn lẹsẹ nilẹ ni gbogbo ìgbà fun awọn iranṣẹ Jehofa oluṣeyasimimọ. Ni afikun, awọn ohun ti a lè pè ni awọn ohun ti o lè yàtọ̀ wà, awọn kókó abajọ ti ó lè yọrisi ayọ ni akoko kan ṣugbọn ayọ diẹ tabi ki o má sí rárá ni akoko miiran. Ni awọn sáà akoko olori idile ati ṣaaju akoko Kristẹni, igbeyawo ati ọmọ bíbí ni a kà sí koṣeemani fun ayọ. Eyi ni a gbeyọ ninu ẹ̀bẹ̀ tàánútàánú Rakeli si Jakọbu pe: “Fun mi ni ọmọ, bikoṣe bẹẹ emi yoo kú.” (Jẹnẹsisi 30:1) Iṣarasihuwa yii siha ọmọ bíbí bá ète Jehofa mu fun akoko yẹn.—Jẹnẹsisi 13:14-16; 22:17.
8 Igbeyawo ati ọmọ bíbí ni a kà sí awọn ibukun ti Ọlọrun fi funni laaarin awọn eniyan Jehofa akoko ijimiji. Bi o ti wu ki o ri, idaamu wépọ̀ mọ iwọnyi ati awọn ipo ayika miiran lakooko elewu ninu ìtàn wọn. (Fiwe Saamu 127, 128 pẹlu Jeremaya 6:12; 11:22; Idaro Jeremaya 2:19; 4:4, 5.) Nitori naa, ó ṣe kedere pe igbeyawo ati ọmọ bíbí kì í ṣe okunfa ayọ wiwa pẹtiti.
Ayọ Laisi Igbeyawo ni Ìgbà Atijọ
9. Eeṣe ti ọmọbinrin Jẹfita fi gba igboriyin ọdọọdun?
9 Ọpọlọpọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ti ri ayọ tootọ laisi igbeyawo. Lati inú ọ̀wọ̀ fun ẹ̀jẹ́ baba rẹ̀, ọmọbinrin Jẹfita wà ní àpọ́n titilọ. Fun akoko kan oun ati awọn ọdọmọbinrin alabaakẹgbẹ rẹ̀ sọkun nitori ipo wíwà ní wundia rẹ̀. Ṣugbọn iru ayọ wo ni ó ni bi o ti ń ṣiṣẹsin fun akoko kikun ninu ile Jehofa, boya laaarin “awọn obinrin ti ń pejọ lati sin ni ẹnu ọna àgọ́-àjọ”! (Ẹkisodu 38:8) Fun eyi, ọdọọdun ni ó ń rí oríyìn gbà.—Onidaajọ 11:37-40.
10. Ki ni Jehofa beere lọwọ Jeremaya, ó ha sì farahan pe oun gbé igbesi-aye alailayọ gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀ bi?
10 Nitori awọn akoko amunijigiri ti wolii Jeremaya gbé ninu rẹ̀, Ọlọrun beere lọwọ rẹ̀ pe ki o fà sẹhin kuro ninu gbigbeyawo ati bíbí awọn ọmọ. (Jeremaya 16:1-4) Ṣugbọn Jeremaya ni iriri ijotiitọ awọn ọrọ Ọlọrun pe: “Ibukun ni fun ẹni ti o gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW], ti o sì fi Oluwa [“Jehofa,” NW] ṣe igbẹkẹle rẹ̀.” (Jeremaya 17:7) Jalẹ iye ti ó ju 40 ọdun ti iṣẹ-isin alasọtẹlẹ, Jeremaya ṣiṣẹsin Ọlọrun pẹlu iṣotitọ gẹgẹ bi ọkunrin àpọ́n kan. Dé ibi ti ìmọ̀ wa mọ, oun kò ṣegbeyawo páàpáà kò sì ni awọn ọmọ. Sibẹ, ta ni ó lè ṣiyemeji pe Jeremaya layọ, bi awọn aṣẹku oluṣotitọ Juu ti wọn ‘di títànyòò lori iṣeun Jehofa’?—Jeremaya 31:12.
11. Ki ni awọn apẹẹrẹ diẹ ti o bá Iwe Mimọ mu ti awọn iranṣẹ Jehofa oluṣotitọ ti wọn layọ bi o tilẹ jẹ pe wọn kò ni alabaaṣegbeyawo kan?
11 Ọpọlọpọ awọn eniyan miiran ti ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu ayọ laisi alabaaṣegbeyawo. Wọn jẹ́ yala àpọ́n, opóbinrin, tabi opókùnrin. Ninu wọn ni wolii obinrin Anna; boya Dọkasi, tabi Tabita; apọsiteli Pọọlu; ati apẹẹrẹ titobi julọ ninu gbogbo wọn—Jesu Kristi wà.
Wọn Jẹ́ Àpọ́n Lonii Sibẹ Wọn Layọ
12. Ki ni awọn kan ninu awọn iranṣẹ alayọ, oluṣeyasimimọ ti Jehofa ti wá àyè fun lonii, eesitiṣe?
12 Lonii, ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọn ń fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Ọlọrun laisi alabaaṣegbeyawo. Awọn kan ni o ti ṣeeṣe fun lati tẹwọgba ikesini Jesu pe: “Ẹni ti ó bá lè gbà á [ẹbun ipò àpọ́n], ki ó gbà á.” Wọn ti ṣe eyi “nitori ijọba ọ̀run.” (Matiu 19:11, 12) Iyẹn ni pe, wọn ti fi ominira ti Ọlọrun fi fun wọn si ìlò rere nipa lilo akoko ati okunra ti ó tubọ pọ sii lati gbe awọn ire Ijọba ga siwaju. Ọpọlọpọ ninu wọn ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun, tabi mẹmba idile Bẹtẹli ni orile-iṣẹ agbaye ti Watch Tower Society tabi ni ọ̀kan lara awọn ẹ̀ka rẹ̀.
13. Awọn apẹẹrẹ wo ni wọn fihan pe Kristẹni kan lè wà ni àpọ́n ki o sì layọ?
13 Arabinrin ọ̀wọ́n agbalagba kan fun ìtàn igbesi aye rẹ̀ ni akori ti ó fi ododo ọrọ naa han pe “Àpọ́n ati Alayọ gẹgẹ bi Aṣaaju-ọna Kan.” (Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1985, oju-iwe 23 si 26) Arabinrin àpọ́n miiran ti ó lo ohun ti ó ju 50 ọdun lọ ni ṣiṣiṣẹsin ni Bẹtẹli sọ pe: “Emi ni itẹlọrun ni kikun pẹlu igbesi-aye mi ati iṣẹ́ mi. Mo kun fun iṣẹ́ nisinsinyi ju ti atẹhinwa lọ ninu iṣẹ ti mo fi tifẹtifẹ fẹran. Emi kò kabaamọ. Emi yoo ṣe iru ipinnu kan naa lẹẹkan sii.”—Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1982, oju-iwe 15.
14, 15. (a) Gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti wi, ki ni o pọndandan ki a baa lè wà ni àpọ́n titilọ? (b) Eeṣe ti Pọọlu fi sọ pe ẹni ti o wà ni àpọ́n ṣe “daradara ju” ati pe ó “layọ jù”?
14 Kiyesi ọrọ yẹn “ipinnu.” Pọọlu kọwe pe: “Ṣugbọn bi ẹnikẹni bá duroṣinṣin ninu ọkan-aya rẹ̀, ti kò sí àìgbọdọ̀máṣe kankan fun un, ṣugbọn ti ó ní ọla-aṣẹ lori ifẹ-inu rẹ̀, ti o sì ti ṣe ipinnu yii ninu ọkan-aya rẹ̀, lati pa eérú àpọ́n rẹ̀ mọ́ oun yoo ṣe daradara. Nitori naa ẹni naa pẹlu ti kò fi í funni ni igbeyawo yoo ṣe daradara jù.” (1 Kọrinti 7:37, 38, NW) Eeṣe ti o fi ‘dara jù’? Pọọlu ṣalaye pe: “Mo fẹ́ ki ẹ bọ́ lọwọ aniyan. Ọkunrin ti kò gbeyawo ń ṣaniyan fun awọn nǹkan ti Oluwa, bi oun ṣe lè jere ojurere Oluwa. . . . Siwaju sii, obinrin ti kò lọ́kọ, ati wundia, ń ṣaniyan fun awọn nǹkan ti Oluwa . . . Ṣugbọn mo ń wí eyi fun anfaani araayin, . . . lati sún yin si ohun ti o yẹ ati ohun ti o tumọsi wíwà larọọwọto lati ṣiṣẹsin Oluwa nigba gbogbo laisi ìpínyà-ọkàn.—1 Kọrinti 7:32-35, NW.
15 Ǹjẹ́ “wíwà larọọwọto lati ṣiṣẹsin Oluwa nigba gbogbo laisi ìpínyà-ọkàn” pẹlu oju-iwoye lati ‘jere itẹwọgba Oluwa’ ha tan mọ ayọ bi? Ó hàn gbangba pe Pọọlu rò bẹẹ. Ni sisọrọ nipa opóbìnrin Kristẹni kan, o wi pe: “Oun di ominira lati bá ẹni ti o fẹ́ gbeyawo, kìkì ninu Oluwa. Ṣugbọn oun jẹ́ alayọ jù bi ó bá duro bi o ti wà, gẹgẹ bi èrò mi. Dajudaju mo rò pe emi pẹlu ni ẹmi Ọlọrun.”—1 Kọrinti 7:39, 40, NW.
Awọn Anfaani Ipo Aigbeyawo
16. Ki ni awọn anfaani diẹ ti Awọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa ti kò gbeyawo ń gbadun?
16 Yala Kristẹni kan jẹ́ àpọ́n nipasẹ ipinnu ara-ẹni tabi nipasẹ ọ̀ranyàn ipo ayika, ipo aiṣegbeyawo ni ọpọlọpọ anfaani ti ara-ẹni ń bá rìn. Awọn àpọ́n eniyan ni gbogbogboo ni akoko ti o pọ sii lati kẹkọọ Ọrọ Ọlọrun ki wọn sì ronu jinlẹ lori rẹ̀. Bi wọn bá lo anfaani ipo ayika yii, ipo tẹmi wọn yoo jinlẹ sii. Bi wọn kò ti ni alabaaṣegbeyawo ti wọn yoo bá ṣajọpin awọn isoro wọn, ọpọlọpọ kẹkọọ lati tubọ sinmi taratara lé Jehofa ati lati wá idari rẹ̀ ninu gbogbo nǹkan. (Saamu 37:5) Eyi ran wa lọwọ lati jẹ ki ipo ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa wà.
17, 18. (a) Awọn anfaani wo fun pápá iṣẹ-isin ti a mu gbooro ni ó wà larọọwọto fun awọn iranṣẹ Jehofa ti wọn kò gbeyawo? (b) Bawo ni awọn iranṣẹ Jehofa kan ti ko ṣegbeyawo ṣe ṣapejuwe ayọ wọn?
17 Awọn Kristẹni ti kò gbeyawo ni awọn anfaani fun pápá iṣẹ-isin ti a mú gbooro si iyin Jehofa. Idalẹkọọ akanṣe ti a ń fi funni nisinsinyi ni Ile-Ẹkọ Idalẹkọọ Iṣẹ-Ojiṣẹ ni a fi mọ sọdọ awọn arakunrin àpọ́n tabi awọn opókùnrin. Awọn arabinrin ti wọn wà ni àpọ́n pẹlu tubọ lominira lati nàgà fun awọn anfaani ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. Arabinrin agbalagba ti a mẹnukan ṣaaju yọnda lati ṣiṣẹsin ni orilẹ-ede Africa kan nigba ti, lati ṣayọlo ọrọ rẹ̀, oun jẹ́ “obinrin ti ó dabi ohun eelo alailagbara ẹni ti ọjọ-ori rẹ̀ ju 50 ọdun lọ.” Ó sì duro sibẹ, ani nigba ifofinde paapaa, nigba ti a lé gbogbo awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lọ. Ó ṣì ń ṣiṣẹsin nibẹ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan, bi o tilẹ jẹ pe oun ti ju ẹni 80 ọdun lọ nisinsinyi. Ó ha layọ bi? Ninu ìtàn igbesi-aye rẹ̀ ó kọwe pe: “Ó ṣeeṣe fun mi lati lo àlékún ominira ati lílè lọ soke-sodo ti àìṣègbéyàwó yọọda lati mú ki ọwọ́ dí ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa, eyi sì ti mú ayọ titobi wá fun mi. . . . La awọn ọdun já ipo ibatan mi pẹlu Jehofa ti jinlẹ. Gẹgẹ bi obinrin àpọ́n kan ni orilẹ-ede Africa kan, mo ti rí i gẹgẹ bi Oludaabobo kan.”
18 Eyi ti o yẹ fun afiyesi, pẹlu, ni awọn ọrọ arakunrin ti ó ṣiṣẹsin ni orile-iṣẹ Watch Tower Society fun ọpọ ẹwadun. Oun layọ, bi o tilẹ jẹ́ pe kò gbeyawo ati bi o tilẹ jẹ pe oun ni ireti ti ọ̀run ti kò ni ifojusọna fun igbeyawo. Ni ẹni ọdun 79, ó kọwe pe: “Lojoojumọ ni mo ń gbadura si Baba wa ọ̀wọ́n tí ń bẹ ni ọ̀run fun iranlọwọ ati ọgbọ́n lati pa mi mọ́ nipa ti ẹmi ki o sì fun mi ni ilera ati agbara ki emi baa lè maa ba a lọ lati ṣe ifẹ rẹ̀. Ni awọn ọdun mọkandinlaaadọta ti o ti kọja ninu iṣẹ-isin Jehofa, nitootọ mo ti gbadun igbesi-aye alayọ, onibukun ti o sì ni èrè ninu. Pẹlu inurere ti a kò lẹtọọ si lati ọdọ Jehofa wá, mo ń fojusọna fun afikun iṣẹ́ fun ọlá ati ogo rẹ̀ ati fun ibukun awọn eniyan rẹ̀. . . . Ayọ Jehofa ran mi lọwọ lati ja ijà rere ti igbagbọ, ti mo sì ń reti akoko naa nigba ti kò ni sí awọn ọ̀tá Jehofa mọ́ ti gbogbo ayé yoo sì kun fun ogo rẹ̀.”—Numeri 14:21; Nehemaya 8:10; Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1969, oju-iwe 699 si 702.
Ori Ki Ni Ayọ Tootọ Sinmi Lé?
19. Lori ki ni ayọ wa yoo maa sinmi le nigba gbogbo?
19 Ipo ibatan wa ṣiṣeyebiye pẹlu Jehofa, ifọwọsi rẹ̀, ati ibukun rẹ̀—iwọnyi ni awọn kókó ti yoo mu ayọ tootọ wá fun wa titi ayeraye. Pẹlu oju iwoye titọna yii lori ohun ti ń mú ojulowo ayọ wa, ani awọn iranṣẹ Jehofa ti wọn ti ṣegbeyawo paapaa mọ pe igbeyawo wọn kì í ṣe ohun pataki julọ ninu igbesi-aye wọn. Wọn kọbiara si imọran apọsiteli Pọọlu pe: “Eyi ni mo wí, ẹyin ará, akoko ti o kù ti dínkù. Lati isinsinyi lọ jẹ ki awọn wọnni ti wọn ni aya dabi ẹni pe wọn kò ni.” (1 Kọrinti 7:29, NW) Eyi kò tumọsi ṣiṣaibikita fun awọn aya wọn. Awọn ogboṣaṣa Kristẹni ọkọ fi iṣẹ-isin Jehofa sípò akọkọ, bẹẹ sì ni awọn aya wọn oniwa-bi-Ọlọrun, onifẹẹ, ati atinilẹhin, ti diẹ ninu wọn tilẹ ń ṣiṣẹsin fun akoko kikun gẹgẹ bi alabaakẹgbẹ ọkọ wọn.—Owe 31:10-12, 28; Matiu 6:33.
20. Ẹmi ironu titọna wo ni ọpọlọpọ awọn Kristẹni ní siha anfaani igbeyawo wọn?
20 Awọn arakunrin ti wọn ti gbeyawo ti wọn jẹ́ alaboojuto arinrin-ajo, oluyọnda ara-ẹni fun Bẹtẹli, alagba ìjọ—nitootọ, gbogbo awọn Kristẹni ti wọn ti gbeyawo ti wọn fi ire Ijọba ṣe akọkọ—kìí ‘lo ayé dé ẹkunrẹrẹ’; wọn ń ṣiṣẹ lati mú anfaani igbeyawo wọn ba igbesi-aye wọn ti wọn yasimimọ fun iṣẹ-isin Jehofa mu. (1 Kọrinti 7:31) Sibẹ, wọn layọ. Eeṣe? Nitori pe idi ti ó mókè fun ayọ wọn kì í ṣe igbeyawo bikoṣe iṣẹ-isin wọn si Jehofa. Ọpọlọpọ awọn ọkọ ati aya oluṣotitọ—bẹẹni, ati awọn ọmọ wọn pẹlu—sì layọ lati ní i lọna bẹẹ.
21, 22. (a) Lori ipilẹ ohun ti Jeremaya 9:23, 24 wi, ki ni ó gbọdọ fi ayọ kun ọkàn wa? (b) Awọn kókó abajọ wo fun ayọ ni a mẹnukan ni Owe 3:13-18?
21 Wolii Jeremaya kọwe pe: “Bayi ni Oluwa [“Jehofa,” NW] wí, ki ọlọgbọn ki o má ṣogo nitori ọgbọn rẹ̀, bẹẹni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọ́rọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yoo bá maa ṣogo, ki o ṣe é ni ninu eyi pe: Oun ní òye, oun sì mọ mi; pe, emi ni Oluwa [“Jehofa,” NW] ti ń ṣe aanu ati ẹ̀tọ́ ati ododo ni ayé: nitori inu mi dun ninu ohun wọnyi, ni Oluwa [“Jehofa,” NW] wí.”—Jeremaya 9:23, 24.
22 Yala a wà ni àpọ́n tabi a ti gbeyawo, orisun ayọ wa titobi julọ nilati jẹ́ ìmọ̀ wa nipa Jehofa ati ìmúdánilójú naa pe a ní itẹwọgba rẹ̀ nitori pe a ń ṣe ifẹ-inu rẹ̀. A tún layọ pẹlu lati ni ijinlẹ òye ninu ohun ti o papọ jẹ́ oṣunwọn fun ìṣèdíyelé, awọn ohun ti Jehofa ní inudidun si. Akóbìnrinjọ Ọba Solomọni kò ka igbeyawo si kọkọrọ kanṣoṣo si ayọ. Ó wi pe: “Ayọ ni fun ọkunrin naa ti o wá ọgbọn rí, ati ọkunrin naa ti ó gba òye. Nitori ti owó rẹ̀ ju owó fadaka lọ, èrè rẹ̀ sì ju ti wura daradara lọ. Ó ṣe iyebiye ju iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ lè fẹ́, kò si eyi ti a lè fi wé e. Ọjọ gigun ń bẹ ni ọwọ ọ̀tún rẹ̀; ati ni ọwọ òsì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀nà rẹ̀, ọ̀nà didun ni, ati gbogbo ipa-ọna rẹ̀, alaafia. Igi ìyè ni i ṣe fun gbogbo awọn ti o di i mu: ibukun [“ayọ,” NW] sì ni fun ẹni ti o dì í mú ṣinṣin.”—Owe 3:13-18.
23, 24. Eeṣe ti a fi lè ni idaniloju pe gbogbo awọn iranṣẹ oluṣotitọ ti Jehofa yoo layọ ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan titun ti Ọlọrun?
23 Ǹjẹ́ ki awọn ti wọn ti gbeyawo ninu wa rí ayọ ayeraye ninu ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Ǹjẹ́ ki awọn arakunrin ati arabinrin wa ọ̀wọ́n ti wọn wà ni àpọ́n nipa yíyàn tabi nipa ipo ayika farada gbogbo adanwo wọn ki wọn sì rí ayọ ati ẹmi itẹlọrun ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa nisinsinyi ati titilae. (Luuku 18:29, 30; 2 Peteru 3:11-13) Ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan ti Ọlọrun ti ń bọ̀, “awọn iwe” ni a o ṣí silẹ. (Iṣipaya 20:12) Iwọnyi yoo ni awọn aṣẹ titun ti ń runi soke ninu ati awọn ilana ti ń fikun ayọ iran araye onigbọran.
24 Dajudaju, a lè ni igbọkanle pe “Ọlọrun alayọ” wa ní agbayanu awọn ohun rere ti yoo yọrisi ayọ patapata fun wa. (1 Timoti 1:11) Ọlọrun yoo maa ba a lọ lati ‘ṣí ọwọ rẹ̀ ki o sì tẹ ifẹ gbogbo ohun alààyè lọrun.’ (Saamu 145:16) Abajọ nigba naa ti ayọ tootọ fi wà ti yoo sì maa wà nigba gbogbo ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahunpada?
◻ Ki ni ipilẹ fun ayọ awọn iranṣẹ Jehofa ti wọn ti ṣe iyasimimọ?
◻ Ni awọn akoko ti a kọ Bibeli, awọn wo ni diẹ lara awọn iranṣẹ alayọ fun Jehofa ti wọn kò gbeyawo?
◻ Eeṣe ti Pọọlu fi damọran ipò àpọ́n, bawo sì ni awọn Kristẹni kan ṣe ri eyi gẹgẹ bi igbesi-aye alayọ kan?
◻ Lori ki ni ayọ wa sinmile nigba gbogbo?
◻ Eeṣe ti a fi gbọdọ ni igbọkanle pe gbogbo awọn oloootọ ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan titun ni yoo layọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọpọlọpọ awọn arabinrin àpọ́n ni wọn ń fi tayọtayọ ṣiṣẹsin Jehofa gẹgẹ bi ojiṣẹ alakooko kikun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ṣiṣiṣẹsin fun awọn ire Jehofa ni orisun pataki julọ fun ayọ