Iwọ Ha Ranti bi?
Iwọ ha ti mọriri kíka awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà aipẹ yii bi? Ó dara, wò ó boya iwọ lè dahun awọn ibeere ti o tẹle e yii:
▫ Ki ni afikun anfaani iṣẹ-isin ti a fifun awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin awọn iranṣẹ Solomoni nigba ti wọn pada dé lati igbekun ni Babiloni lè jẹ́ ojiji iṣaaju fun bakan-naa? Lonii, bi aṣẹku Israeli tẹmi lori ilẹ̀-ayé ti ń baa lọ ni dídínkù, awọn agutan miiran ń baa lọ ni pipọ sii. Diẹ lara awọn ẹni bi agutan wọnyi, gẹgẹ bi awọn Netinimu ati awọn ọmọkunrin iranṣẹ Solomoni, ni a ti fun ni awọn ẹrù-iṣẹ́ wiwuwo nisinsinyi labẹ abojuto awọn aṣẹku naa. (Isaiah 61:5)—4/15, oju-iwe 16 si 17.
▫ Ki ni wolii Sefaniah ni lọ́kàn nigba ti o sọ pe: “Boya a o pa yin mọ́ ni ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW]”? (Sefaniah 2:2, 3) Fun ẹnikan lati di ẹni ti a daabobo nigba “ipọnju nla” ti o ń bọ̀ naa, kì í ṣe ọ̀ràn igbala lẹẹkan, igbala ni gbogbo ìgbà. (Matteu 24:13, 21) Didi ẹni ti a pamọ ni ọjọ yẹn yoo sinmile bibaa lọ ẹnikan lati ṣe awọn ohun mẹta: Ó gbọdọ wá Jehofa, wá ododo, ki o sì wá iwapẹlẹ.—5/1, oju-iwe 15 si 16.
▫ Ni èrò itumọ wo ni Mikaeli gbà “dide duro” ni “akoko ikẹhin”? (Danieli 12:1, 4) Lati ìgbà fifi si ipo gẹgẹ bi Ọba ni 1914, Mikaeli ti ń dide duro nititori awọn eniyan Jehofa. Ṣugbọn laipẹ Mikaeli maa “dide duro” ni ero itumọ akanṣe—gẹgẹ bi Aṣoju Jehofa lati mú gbogbo iwa ibi kuro lori ilẹ̀-ayé ati gẹgẹ bi Oludande awọn eniyan Ọlọrun.—5/1, oju-iwe 17.
▫ Lori ki ni ayọ tootọ sinmle? Ayọ tootọ sinmile ipo ibatan oniyebiye wa pẹlu Jehofa, itẹwọgba rẹ̀ ati ibukun rẹ̀. (Owe 10:22) Nigba naa, ayọ tootọ ni ọwọ́ kò lè tẹ̀ ayafi ni ṣiṣegbọran si Jehofa ati fifi tayọtayọ juwọsilẹ fun ifẹ-inu rẹ̀. (Luku 11:28)—5/15, oju-iwe 16, 19.
▫ Nigba ti Jesu ṣe awọn iṣẹ iyanu imularada rẹ̀, igbagbọ ha pọndandan niha ọdọ ẹni naa ti o wosan bi? Ìwọ̀n igbagbọ kan ni a nilo niha ọdọ ọpọlọpọ ki wọn baa lè wá sọdọ Jesu fun imularada. (Matteu 8:13) Bi o ti wu ki o ri, kò si ijẹwọ igbagbọ kankan ti Jesu beere fun lati lè ṣe awọn iṣẹ iyanu rẹ̀, bii iru ìgbà ti o mu ọkunrin arọ kan ti kò mọ ẹni ti Jesu jẹ larada. (Johannu 5:5-13) Jesu tilẹ mú etí iranṣẹ olori alufaa ti a ti gé danu padabọsipo, ẹni ti ó wà lara awujọ awọn ọ̀tá Jesu. (Luku 22:50, 51) Awọn iṣẹ iyanu wọnyi ni a ṣe pẹlu agbara ẹmi mimọ Ọlọrun, kì í ṣe nitori igbagbọ awọn alaisan naa.—6/1, oju-iwe 3.
▫ Ki ni ohun ti “àwọ̀n-ìpẹja” (awò)” naa ti Jesu sọrọ nipa rẹ̀ ninu àkàwé ni Matteu 13:47-50 duro fun? “Àwọ̀n-ìpẹja” (awò) naa duro fun ohun eelo ti ilẹ̀-ayé ti o fẹnujẹwọ jijẹ ijọ Ọlọrun ti o sì ń kó awọn “ẹja” wọle. Ó ti ní Kristẹndọm ati ijọ awọn Kristian ẹni-ami-ororo ninu, eyi ti a sọ kẹhin yii sì ti ń baa lọ lati kó awọn ‘ẹja rere jọ,’ labẹ idari awọn angẹli, ni ila pẹlu Matteu 13:49.—6/15, oju-iwe 20.
▫ Ki ni diẹ lara awọn ilana ti awọn onidaajọ ni Israeli nilati fisilo ninu mimu awọn iṣẹ ayanfunni wọn ṣẹ? Idajọ ododo dọ́gbandọ́gba fun olowo ati otoṣi, aiṣojuṣaaju mimuna, ati aigba abẹtẹlẹ. (Lefitiku 19:16; Deuteronomi 16:19)—7/1, oju-iwe 13.
▫ Ki ni awọn alagba gbọdọ gbiyanju lati ṣaṣeyọri rẹ̀ nigba ìgbẹ́jọ́? Gongo kan ni lati rídìí otitọ ọ̀ràn naa, ni ṣiṣe eyi pẹlu ifẹ. Gbàrà ti a bá ti mọ eyi, awọn alagba naa gbọdọ ṣe ohunkohun ti o bá yẹ lati daabobo ijọ naa ati lati pa awọn ọ̀pá idiwọn giga ti Jehofa ati iṣiṣẹ deedee ẹmi Ọlọrun mọ́ ninu ijọ. Igbẹjọ naa tun jẹ lati gba ẹlẹṣẹ kan ti o wà ninu ewu là, bi o bá jẹ pe o ṣeese. (Fiwe Luku 15:8-10.)—7/1, oju-iwe 18 si 19.
▫ Eeṣe ti awọn ìrònú-asán ti o jẹmọ́ ibalopọ takotabo ti kò bofinmu fi lè panilara tobẹẹ? Ni oju-iwoye awọn ọ̀rọ̀ Jesu ni Matteu 5:27, 28, gbogbo awọn wọnni ti wọn tẹramọ kikẹrabajẹ ninu irokuro ibalopọ ti kò bofin mu jẹbi didẹṣẹ panṣaga ninu ọkan-aya wọn. Ewu gidi naa sì wà pe iru awọn irokuro bẹẹ lè ṣamọna si iwapalapala.—7/15, oju-iwe 15.
▫ Ni awọn ọ̀nà wo ni Jehofa lè gba ràn wá lọwọ lati wo awọn adanwo wa lọna yíyẹ ki a sì tipa bẹẹ foriti wọn? Iwe Mimọ ni a lè mú wá si afiyesi wa nipasẹ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni tabi nigba ikẹkọọ Bibeli. Awọn ọ̀ràn ti a dari nipasẹ itọsọna Ọlọrun lè ràn wá lọwọ lati ri ohun ti o yẹ ni ṣiṣe. Awọn angẹli lè ṣalabaapin ninu didari wa, tabi a lè ri itọsọna gbà nipasẹ ẹmi mimọ. (Hebreu 1:14)—7/15, oju-iwe 21.
▫ Ǹjẹ́ Igbimọ ti Nicaea ni 325 C.E. fidii ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan mulẹ tabi jẹrii sii bi? Bẹẹkọ, Igbimọ ti Nicaea mú Ọmọkunrin bá Baba dọgba kìkì ninu jíjẹ́ “ọkan-naa” ni. Èrò naa pe Baba, Ọmọ, ati ẹmi mimọ jẹ́ Ọlọrun tootọ lẹnikọọkan—Ọlọrun mẹta-ninu-ọkan—ni igbimọ yẹn tabi awọn onkọwe Ṣọọṣi ijimiji kò mú gbèrú.—8/1, oju-iwe 20.
▫ Jobu nikan ha ni eniyan olododo si Jehofa lakooko ti o fi gbé ayé bi? (Jobu 1:8) Bẹẹkọ, iwe Jobu fúnraarẹ̀ fihàn pe Elihu ṣetẹwọgba lọdọ Ọlọrun. Pẹlupẹlu, nigba ti Jobu gbé ayé, ọpọlọpọ awọn ọmọ Israeli wà ti wọn ń gbé ni Egipti, kò sì sí idi kankan lati ronu pe gbogbo awọn wọnyi jẹ alaiṣododo tabi alaiṣetẹwọgba lọdọ Ọlọrun.—8/1, oju-iwe 31.