Iṣeto Idile Onifẹẹ Ti Jehofa
“Nititori eyi mo fi awọn eékún mi kúnlẹ̀ fun Baba, ẹni ti olukuluku idile ní ọrun ati lori ilẹ̀-ayé jẹ ní gbèsè orukọ rẹ̀.”—EFESU 3:14, 15, NW.
1, 2. (a) Fun ète wo ni Jehofa ṣe dá ẹka idile? (b) Ipa wo ni idile nilati kó ninu iṣeto Jehofa lonii?
JEHOFA ni ó dá ẹ̀ka idile. Nipasẹ rẹ̀, ó ṣe ju títẹ́ aini eniyan fun ìbákẹ́gbẹ́, itilẹhin, tabi ìṣetímọ́tímọ́ lọ́rùn lọ. (Genesisi 2:18) Idile ni ọ̀nà naa nipasẹ eyi ti ète ológo ti Ọlọrun lati kún ilẹ̀-ayé yoo gbà ní imuṣẹ. Ó sọ fun tọkọtaya oluṣegbeyawo akọkọ pe: “Ẹ maa bí sii, ki ẹ sì maa rẹ̀, ki ẹ sì gbilẹ, ki ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.” (Genesisi 1:28) Ipo-ayika ọlọyaya ati ìtọ́nidàgbà ninu idile yoo ṣanfaani fun ògìdìgbó awọn ọmọ ti Adamu ati Efa ati awọn ìran-àtẹ̀lé wọn yoo bí.
2 Bi o ti wu ki o ri, tọkọtaya akọkọ yẹn, yan ipa-ọna àìgbọràn—pẹlu iyọrisi apanirun fun araawọn ati awọn ọmọ wọn. (Romu 5:12) Igbesi-aye idile lonii tipa bayii jẹ́ ìfèrú yí ohun ti Ọlọrun fẹ́ kí ó jẹ́ po. Sibẹ, idile ń baa lọ lati ní ipo pataki ninu iṣeto Jehofa, ní ṣiṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹ̀ka ipilẹ awujọ Kristian. A kò sọ eyi pẹlu ainimọriri kankan fun iṣẹ rere tí ọpọlọpọ awọn Kristian alaiṣegbeyawo tí wọ́n wà laaarin wa ń ṣe. Kaka bẹẹ, a mọ itilẹhin ribiribi ti awọn idile ń ṣe fun ilera tẹmi ninu eto-ajọ Kristian lodindi pẹlu. Awọn idile alagbara níí di ijọ alagbara. Bi o ti wu ki o ri, bawo, ni idile rẹ ṣe lè gbèrú ni oju awọn ikimọlẹ ode-oni? Ni idahun, ẹ jẹ ki a ṣayẹwo ohun ti Bibeli ní lati sọ nipa iṣeto idile.
Idile ní Awọn Akoko Ti A Kọ Bibeli
3. Ipa wo ni ọkọ ati aya kó ninu idile ti baba awọn Heberu?
3 Adamu ati Efa pawọ́pọ̀ kọ iṣeto ipo-ori Ọlọrun silẹ. Ṣugbọn awọn ọkunrin igbagbọ, bii Noa, Abrahamu, Isaaki, Jakọbu, ati Jobu, fi ẹ̀tọ́ di ipo wọn mú, gẹgẹ bi olori idile. (Heberu 7:4) Idile baba awọn Heberu dabii ijọba kekere kan, ti baba ń ṣe bii aṣaaju isin, olutọni, ati onidaajọ. (Genesisi 8:20; 18:19) Awọn aya pẹlu ní ipa pataki kan, ni ṣiṣiṣẹ kìí ṣe gẹgẹ bi ẹrú bikoṣe gẹgẹ bi igbákejì olùdarí agbo-ile.
4. Bawo ni igbesi-aye idile ṣe yipada labẹ Ofin Mose, ṣugbọn ipa wo ni awọn òbí ń baa lọ lati kó?
4 Nigba ti Israeli di orilẹ-ede kan ni 1513 B.C.E., ofin idile di eyi ti ó wà labẹ Ofin orilẹ-ede ti a fi funni nipasẹ Mose. (Eksodu 24:3-8) Ọla-aṣẹ lati pinnu, titikan awọn ọ̀ràn ti ó la ikú-àti-ìyè lọ, ni a fifun awọn onidaajọ ti a yànsípò nisinsinyi. (Eksodu 18:13-26) Ipo alufaa ti Lefi ń rí sí ìhà ti irubọ ninu ijọsin. (Lefitiku 1:2-5) Bi o tilẹ ri bẹẹ, baba ń baa lọ lati kó ipa pataki. Mose gba awọn baba niyanju pe: “Ati ọ̀rọ̀ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ ni oni, ki o maa wà [ni] àyà rẹ: Ki iwọ ki o sì maa fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o sì maa fi wọn ṣe ọ̀rọ̀ ísọ nigba ti iwọ ba jokoo ninu ile rẹ, ati nigba ti iwọ bá ń rìn ni ọ̀nà, ati nigba ti iwọ bá dubulẹ, ati nigba ti iwọ bá dide.” (Deuteronomi 6:6, 7) Awọn ìyá ní agbara-idari ti ó jọjú. Owe 1:8 paṣẹ fun awọn ọ̀dọ́ pe: “Ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má sì kọ ofin ìyá rẹ silẹ.” Bẹẹni, ninu iṣeto ọla-aṣẹ ọkọ rẹ̀, aya Heberu naa lè ṣe—ki ó sì fi ipá mú—ofin idile ṣẹ. Oun ni awọn ọmọ rẹ̀ nilati bọla fun àní lẹhin ti ó bá ti darugbo paapaa.—Owe 23:22.
5. Bawo ni Ofin Mose ṣe mú ipo awọn ọmọ ṣe kedere ninu iṣeto idile?
5 Ipo awọn ọmọ ni Ofin Ọlọrun tún mú ṣe kedere pẹlu. Deuteronomi 5:16 wi pe: “Bọ̀wọ̀ fun baba ati ìyá rẹ, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ: ki ọjọ rẹ ki o lè pẹ́, ati kí ó lè dara fun ọ, ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.” Àìbọ̀wọ̀ fun òbí ẹni jẹ́ ẹṣẹ kan ti ó wúwo julọ labẹ Ofin Mose. (Eksodu 21:15, 17) “Ẹnikẹni tí ó bá fi baba tabi ìyá rẹ̀ ré,” ni Ofin sọ, “pípa ni a ó pa á.” (Lefitiku 20:9) Iṣọtẹ lodisi òbí ẹni ni ó rí bakan naa pẹlu iṣọtẹ lodisi Ọlọrun fúnraarẹ̀.
Ipa ti Awọn Kristian Ọkọ
6, 7. Eeṣe ti awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Efesu 5:23-29 fi dabi ìyípìlẹ̀ pada patapata fun awọn onkawe rẹ̀ ọrundun kìn-ín-ní?
6 Isin Kristian tan ìmọ́lẹ̀ sori iṣeto idile, ni pataki sori ipa ti ọkọ. Lẹhin òde ijọ Kristian, ó jẹ́ àṣà fun awọn ọkọ ni ọrundun kìn-ín-ní lati bá awọn aya wọn lò ni ọ̀nà rírorò, ati atẹniloriba. Awọn obinrin ni a fi awọn ẹ̀tọ́ pataki ati ọlá dù. The Expositor’s Bible sọ pe: “Ọ̀mọ̀wé naa ti o jẹ́ Griki ń fẹ́ aya fun bíbí ọmọ. Awọn ẹ̀tọ́ aya kò gbé ìkálọ́wọ́kò kari ìfẹ́-ọkàn rẹ̀. Kò sí ifẹ ninu adehun igbeyawo naa. . . . Ẹrúbìnrin naa kò ní ẹ̀tọ́ kankan. Ara rẹ̀ wà ni ìkáwọ́ olówó rẹ̀.”
7 Ninu iru ipo ayika bẹẹ, Paulu kọ awọn ọ̀rọ̀ Efesu 5:23-29 pe: “Ọkọ níí ṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi tii ṣe ori ijọ eniyan rẹ̀: oun sì ni Olugbala ara. . . . Ẹyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya yin, gẹgẹ bi Kristi sì ti fẹran ijọ, ti o sì fi ara rẹ̀ fun un . . . Bẹẹ ni ó tọ́ ki awọn ọkunrin ki o maa fẹran awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikaraawọn. Ẹni ti ó bá fẹran aya rẹ̀, ó fẹran oun tikaraarẹ̀. Nitori kò si ẹnikan ti ó ti koriira ara rẹ̀; bikoṣe pe ki o maa bọ́ ọ kí ó sì maa ṣìkẹ́ rẹ̀.” Fun awọn onkawe ọrundun kìn-ín-ní, awọn ọ̀rọ̀ wọnyi kò dín sí ìyípìlẹ̀ pada patapata. The Expositor’s Bible sọ pe: “Kò si ohunkohun ninu isin Kristian ti ó tubọ dabii titun ti ó sì tubọ lekoko, ni ifiwera pẹlu ìwà ìkẹ́rabàjẹ́ akoko naa, ju oju ti awọn Kristian fi wo igbeyawo lọ. . . . [Ó] bẹrẹ sanmani titun kan fun araye.”
8, 9. Iṣarasihuwa ti kò dara wo si awọn obinrin ni ó wọ́pọ̀ laaarin awọn ọkunrin, eesitiṣe ti ó fi ṣe pataki pe ki awọn Kristian ọkunrin ṣá iru oju-iwoye bẹẹ tì?
8 Imọran Bibeli fun awọn ọkọ kìí ṣe eyi ti ó kere si ìyípìlẹ̀ pada patapata lonii. Laika gbogbo ọ̀rọ̀ nipa ìjàgbara awọn obinrin sí, awọn obinrin ni ọpọlọpọ ọkunrin ṣì ń wò gẹgẹ bii ohun ìdájúsọ fun títẹ́ ifẹ ibalopọ takọtabo lọ́rùn. Nipa gbígba arosọ-atọwọdọwọ naa gbọ́ pe awọn obinrin niti tootọ ń gbadun jíjẹ́ ẹni ti a jẹ gàba lé lori, ti a ń dari, tabi ẹni ti a ń bú mọ́, ọpọlọpọ awọn ọkunrin ń lo aya wọn ní ilokulo nipa ti ara ati niti ero-imọlara. Yoo ti tinilójú tó fun Kristian ọkunrin kan lati di ẹni ti ironu ayé gbá lọ ati lati maa lo aya rẹ̀ nilokulo! “Ọkọ mi jẹ́ iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan ó sì ń sọ awọn ọ̀rọ̀-àsọyé fun gbogbo eniyan,” ni Kristian obinrin kan sọ. Sibẹ, ó ṣí i paya pe, “Mo jẹ́ aya ti a ń lù.” Ní kedere, iru awọn iṣarasihuwa bẹẹ kò sí ni ibamu pẹlu iṣeto Ọlọrun. Ọkunrin yẹn dáyàtọ̀ lọna ti kò wọ́pọ̀; ó nilati wá iranlọwọ lati bojuto ìhónú rẹ̀ bi ó bá nireti lati rí ojurere Ọlọrun gbà.—Galatia 5:19-21.
9 Awọn ọkọ ni Ọlọrun paṣẹ fun lati maa fẹran awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikaraawọn. Kíkọ̀ lati ṣe bẹẹ jẹ́ iṣọtẹ lodisi iṣeto naa gan-an ti Ọlọrun ṣe ó sì lè jin ipo-ibatan ẹnikan pẹlu Ọlọrun lẹ́sẹ̀. Awọn ọ̀rọ̀ aposteli Peteru ṣe kedere: “Bẹẹ gẹgẹ ẹyin ọkọ, ẹ maa fi òye bá awọn aya yin gbé, ẹ maa fi ọlá fun aya, bi ohun eelo ti kò lagbara, . . . ki adura yin ki o ma baa ni idena.” (1 Peteru 3:7) Bíbá aya ẹni lò lọna rírorò tún lè ní iyọrisi ti ń panirun lori ipo tẹmi rẹ̀ ati ipo tẹmi awọn ọmọ ẹni.
10. Ki ni awọn ọ̀nà diẹ ti awọn ọkọ lè gbà lo ipo-ori ni ọ̀nà bii ti Kristi?
10 Ẹyin ọkọ, idile yin yoo gbèrú labẹ ipo-ori yin bi ẹ bá lò ó ni ọ̀nà bii ti Kristi. Kristi kò figba kan rí rorò tabi jẹ́ aloninílòkulò lae. Ni ìdàkejì, oun lè sọ pe: “Ẹ sì maa kọ ẹ̀kọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkàn ni emi; ẹyin ó sì rí isinmi fun ọkàn yin.” (Matteu 11:29) Idile rẹ ha lè sọ iyẹn nipa rẹ bi? Kristi bá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lò gẹgẹ bi ọ̀rẹ́ ó sì nigbẹkẹle ninu wọn. (Johannu 15:15) Iwọ ha yọnda ọlá kan-naa fun aya rẹ bi? Bibeli sọ nipa “obinrin oniwa-rere” pe: “Àyà ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹru.” (Owe 31:10, 11) Iyẹn tumọsi fifun un ni iwọn ẹ̀tọ́ ati ominira yíyàn kan, láìsé e mọ́ pẹlu awọn ìkálọ́wọ́kò ti kò bọgbọnmu. Siwaju sii pẹlu, Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni iṣiri lati sọ imọlara ati èrò wọn jade. (Matteu 9:28; 16:13-15) Iwọ ha ń ṣe bakan naa pẹlu aya rẹ bi? Tabi iwọ ha foju wo aifohunṣọkan alailabosi gẹgẹ bii ipenija si ọla-aṣẹ rẹ bi? Nipa gbígba imọlara aya rẹ rò dipo pípa wọn tì, iwọ niti tootọ mú ọ̀wọ̀ rẹ̀ fun ipo-ori rẹ dagba.
11. (a) Bawo ni awọn baba ṣe lè bikita fun aini tẹmi awọn ọmọ wọn? (b) Eeṣe ti awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ fi nilati fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀ ninu bibikita fun idile wọn?
11 Bi iwọ ba jẹ́ baba kan, a tun beere lọwọ rẹ pẹlu lati mú ipo iwaju ninu bibojuto aini awọn ọmọ rẹ nipa tẹmi, ti ero-imọlara, ati nipa ti ara-ìyára. Iyẹn ní ninu níní ọ̀nà-ìgbàṣiṣẹ́ deedee tẹmi ti ó dara fun idile rẹ: bíbá wọn ṣiṣẹ ninu iṣẹ-isin pápá, dídarí ikẹkọọ Bibeli inu ile, jíjíròrò ẹsẹ iwe mimọ ojumọ. Lọna ti o fanilọkanmọra, Bibeli fihàn pe alagba kan tabi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan nilati jẹ́ “ọkunrin kan ti ń ṣakoso agbo-ile ara rẹ̀ ni iru ọ̀nà rere kan.” Awọn ọkunrin tí ń ṣiṣẹsin ninu awọn ipo iṣẹ́ wọnyi nilati tipa bayii jẹ́ awofiṣapẹẹrẹ olori idile. Nigba ti wọn lè gbé ẹrù wiwuwo ti awọn ẹrù-iṣẹ́ ijọ, wọn gbọdọ fun idile tiwọn alára ni ipo akọkọ. Paulu fi idi eyi hàn pe: “Nitootọ bi ọkunrin kan kò bá mọ bi a tií ṣakoso agbo-ile ara rẹ̀, bawo ni yoo ṣe tọju ijọ Ọlọrun?”—1 Timoteu 3:4, 5, 12, NW.
Awọn Kristian Aya Ti Wọn Ń Ṣetilẹhin
12. Ipa wo ni aya ń kó ninu iṣeto Kristian?
12 Iwọ ha jẹ Kristian aya kan bi? Nigba naa iwọ gbọdọ tun kó ipa ṣiṣekoko kan ninu iṣeto idile. Awọn Kristian aya ni a gbàníyànjú “lati fẹran awọn ọkọ wọn, lati fẹran awọn ọmọ wọn, lati jẹ́ alairekọja, mímọ́, oṣiṣẹ nile, ẹni rere, awọn ti ń tẹriba fun awọn ọkọ wọn.” (Titu 2:4, 5) Iwọ nilati tipa bayii lakaka lati jẹ́ awofiṣapẹẹrẹ iyawo-ile, ní pípa ile mímọ́ tonitoni ti ó sì tunilara mọ́ fun idile rẹ. Iṣẹ́ inu ile lè kira nigba miiran, ṣugbọn kò tẹ́nilógo tabi ṣaijamọ nǹkan. Gẹgẹ bi aya, iwọ “ń ṣabojuto agbo-ile kan” o sì lè gbadun ọpọlọpọ ominira yíyàn ni ọ̀nà yii. (1 Timoteu 5:14) “Obinrin oniwarere,” fun apẹẹrẹ, ń ra awọn ipese agbo-ile, ń ṣe ìdúnàádúrà dúkìá ile ati ilẹ, ó tilẹ ń mú owó wọle nipa bibojuto iṣẹ́-òwò kekere kan. Abajọ ti ó fi jere iyin ọkọ rẹ̀! (Owe, ori 31) Lọna ti o bá iwa ẹ̀dá mu, iru awọn ìdánúṣe bẹẹ ni ó ṣe laaarin ìlà ìtọ́ni tí ọkọ rẹ gẹgẹ bi ori rẹ̀ fifun un.
13. (a) Eeṣe ti itẹriba fi lè ṣoro fun awọn obinrin kan? (b) Eeṣe ti ó fi ṣanfaani fun awọn obinrin Kristian lati tẹri araawọn ba fun awọn ọkọ wọn?
13 Bi o ti wu ki o ri, titẹri araarẹ bá fun ọkọ rẹ lè má fi ìgbà gbogbo rọrùn. Kìí ṣe gbogbo ọkunrin ní ń beere fun ọ̀wọ̀ tí ó sì ń rí i gbà. Iwọ sì lè tootun gan-an nigba ti ó bá kan ọ̀ràn bibojuto ọ̀rọ̀ inawo, wíwéwèé, ati ṣiṣeto. Iwọ lè ni iṣẹ́ ounjẹ-oojọ ki o sì maa ṣe itilẹhin ti ó pọ̀ gan-an fun owó tí ń wọle fun idile. Tabi iwọ ti lè jiya lọwọ ijẹgaba awọn ọkunrin ni ọ̀nà kan ṣá ni ìgbà ti ó ti kọja o sì lè rí i pe ó ṣoro lati tẹriba fun ọkunrin kan. Bi o tilẹ ri bẹẹ, fifi “ọ̀wọ̀ jijinlẹ,” tabi “ibẹru” hàn, fun ọkọ rẹ fi ọ̀wọ̀ rẹ fun ipo-ori ti Ọlọrun hàn. (Efesu 5:33, Kingdom Interlinear; 1 Korinti 11:3) Itẹriba pẹlu ṣe kókó fun aṣeyọrisirere idile rẹ; ó ràn ọ́ lọwọ lati yẹra fun fifi igbeyawo rẹ sinu másùnmáwo ati ìgalára ti kò pọndandan.
14. Ki ni aya kan lè ṣe nigba ti kò bá fohunṣọkan pẹlu ipinnu ti ọkọ rẹ ṣe?
14 Bi o ti wu ki o ri, eyi ha tumọsi pe o gbọdọ panumọ nigba ti o bá nimọlara pe ọkọ rẹ ń ṣe ipinnu ti o tako ire didara julọ ti idile rẹ bi? Kò fi dandan rí bẹẹ. Iyawo Abrahamu, Sara kò dakẹjẹẹ nigba ti o foyemọ ewu ti ó wà fun wíwà lalaafia ọmọkunrin rẹ̀, Isaaki. (Genesisi 21:8-10) Bakan naa, iwọ lè nimọlara aigbọdọmaṣe kan lati ṣọ imọlara rẹ jade nigba miiran. Bi o bá ṣe eyi tọwọtọwọ ni “akoko rẹ̀,” Kristian ọkunrin oniwa-bi-Ọlọrun kan yoo fetisilẹ. (Owe 25:11) Ṣugbọn bi a kò bá tẹle idamọran rẹ tí kò sì sí ìtàpá si ilana Bibeli kankan ti ó wémọ́ ọn, ǹjẹ́ lilodisi idaniyan ọkọ rẹ kò ha níí jẹ́ ipara-ẹni láyò bi? Ranti, “ọlọgbọn obinrin níí kọ́ ile rẹ̀: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ́ araarẹ̀ fà á lulẹ.” (Owe 14:1) Ọ̀nà kan lati kọ́ ile rẹ ni lati jẹ́ alatilẹhin fun ipo-ori ọkọ rẹ, ní yiyin awọn aṣeyọri rẹ̀ nigba ti o ń fi suuru bá awọn aṣiṣe rẹ̀ lò laibanujẹ.
15. Ni awọn ọ̀nà wo ni aya kan lè gbà ṣajọpin ninu ibawi ati ìdánilẹ́kọ̀ọ́ awọn ọmọ rẹ̀?
15 Ọ̀nà miiran lati kọ́ ile rẹ ni lati ṣajọpin ninu bíbá awọn ọmọ rẹ wí ati kíkọ́ wọn. Fun apẹẹrẹ, iwọ lè ṣe ipa tirẹ lati jẹ́ ki ikẹkọọ Bibeli idile maa ṣe deedee ki ó sì gbeniro. “Maṣe dá ọwọ́ rẹ duro” nigba ti ó bá kan ọ̀ràn ṣiṣajọpin otitọ Ọlọrun pẹlu awọn ọmọ rẹ ni gbogbo akoko ti anfaani bá ṣí silẹ—nigba ti o bá ń rinrin-ajo tabi wulẹ ń lọ rajà pẹlu wọn. (Oniwasu 11:6) Ràn wọn lọwọ lati mura ọ̀rọ̀ ilohunsi wọn fun awọn ipade ati apa ti wọn yoo ṣiṣẹ lé lori ninu Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun. Maa kiyesi awọn ẹgbẹ́ ti wọn ń kó. (1 Korinti 15:33) Nigba tí ó bá kan ọ̀ràn awọn ọpa idiwọn ati ibawi ti Ọlọrun, jẹ ki awọn ọmọ rẹ mọ pe iwọ ati ọkọ rẹ wà ni iṣọkan. Maṣe jẹ ki wọn mú ọ forigbari pẹlu ọkọ rẹ lati ṣe ohun ti wọn ń fẹ́.
16. (a) Apẹẹrẹ ti ó bá Bibeli mu wo ni ó ṣiṣẹ lati fun awọn òbí anìkàntọ́mọ ati awọn wọnni ti wọn gbeyawo pẹlu alaigbagbọ niṣiiri? (b) Bawo ni awọn miiran ninu ijọ ṣe lè ṣe iranlọwọ fun iru ẹni bẹẹ?
16 Bi iwọ bá jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ tabi ti o ní alabaaṣegbeyawo ti kìí ṣe onigbagbọ, ó lè beere gidigidi pe ki o mu ipo iwaju nipa tẹmi. Eyi lè ṣoro ati nigba miiran ki o tilẹ jẹ́ akórẹ̀wẹ̀sìbáni paapaa. Ṣugbọn maṣe dawọ duro. Ìyá Timoteu, Eunike, kẹ́sẹjárí ninu kíkọ́ ọ ni Iwe Mimọ “lati ìgbà ọmọde,” laika jijẹ ẹni ti o fẹ́ alaigbagbọ kan sí. (2 Timoteu 1:5; 3:15) Ọpọlọpọ laaarin wa sì ń gbadun aṣeyọrisirere bakan naa. Bi iwọ bá nilo itilẹhin diẹ ninu ọ̀ràn yii, iwọ lè jẹ́ ki awọn aini rẹ di mímọ̀ fun awọn alagba. Wọn lè ṣeto fun ẹnikan lati ràn ọ́ lọwọ lati wá si awọn ipade ki o sì jade ninu iṣẹ-isin pápá. Wọn lè fun awọn ẹlomiran niṣiiri lati fi idile rẹ kún ijadelọ ìgbafẹ́ tabi ikorajọpọ. Tabi wọn lè ṣeto lati jẹ́ ki akede oniriiri kan ràn ọ́ lọwọ lati bẹrẹ ikẹkọọ idile.
Awọn Ọmọ Onimọriri
17. (a) Bawo ni awọn ọ̀dọ́ ṣe lè dákún wíwàlálàáfíà idile? (b) Apẹẹrẹ wo ni Jesu fi lelẹ ninu ọ̀ràn yii?
17 Awọn Kristian ọ̀dọ́ lè dákún ìwàlálàáfíà idile nipa titẹle imọran Efesu 6:1-3: “Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ ti awọn òbí yin ninu Oluwa: nitori pe eyi ni ó tọ́. [Bọla, NW] fun baba ati ìyá rẹ (eyi tíí ṣe ofin ikinni pẹlu ileri), ki ó lè dara fun ọ, ati ki iwọ ki o lè wà pẹ́ ní ayé.” Nipa fifọwọsowọpọ pẹlu awọn òbí rẹ, iwọ ń ṣàṣefihàn ọ̀wọ̀ rẹ fun Jehofa. Ẹni pípé ni Jesu Kristi ó sì ti lè fi tirọruntirọrun ronu pe ó kéré si ipo ọlá rẹ̀ lati tẹriba fun awọn òbí alaipe. Sibẹ, ó “ń baa lọ lati gbọ́ tiwọn. . . . Jesu sì ń tẹsiwaju ninu ọgbọn ati idagbasoke nipa ti ara ati ninu ojurere-iṣeun lọdọ Ọlọrun ati eniyan.”—Luku 2:51, 52, NW.
18, 19. (a) Ki ni ó tumọsi lati bọla fun òbí ẹni? (b) Bawo ni inu ile ṣe lè di ibi itura kan?
18 Iwọ bakan naa kò ha nilati bọla fun awọn òbí rẹ bi? “Bọlá” nihin-in tumọsi lati mọ ọla-aṣẹ ti a fẹ̀tọ́ gbekalẹ daju. (Fiwe 1 Peteru 2:17.) Ninu awọn ipo ọ̀ràn ti ó wọpọ julọ iru ọlá bẹẹ tọ́ àní bi awọn òbí ẹni kìí bá ṣe onigbagbọ paapaa tabi ti wọn ń kuna lati fi apẹẹrẹ rere lelẹ. Iwọ nilati bọla fun awọn òbí rẹ tobẹẹ ju bẹẹ lọ bi wọn bá jẹ́ Kristian awofiṣapẹẹrẹ. Ranti, pẹlu, pe ibawi ati itọsọna tí awọn òbí rẹ ń fun ọ ni wọn kò pète rẹ̀ lati ká ọ lọ́wọ́ kò lọna ti kò tọ́. Kaka bẹẹ, wọn jẹ́ lati daabobo ọ́ ki o baa lè “yè.”—Owe 7:1, 2.
19 Iru iṣeto onifẹẹ wo, nigba naa, ni idile jẹ́! Nigba ti awọn ọkọ, aya, ati awọn ọmọ lapapọ bá tẹle ofin Ọlọrun fun igbesi-aye idile, inu ile a di ibi aabo kan, ibi itura kan. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn iṣoro ti ó wépọ̀ mọ ijumọsọrọpọ ati ọmọ títọ́ lè dide. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa ti ó kàn jiroro ọ̀nà ti a lè gbà yanju diẹ lara awọn iṣoro wọnyi.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Apẹẹrẹ wo ni awọn ọkọ, aya, ati awọn ọmọ ti wọn bẹru Ọlọrun ni awọn akoko ti a kọ Bibeli fi lelẹ?
◻ Ìmọ́lẹ̀ wo ni isin Kristian tàn sori ipa ti ọkọ?
◻ Ipa wo ni aya nilati kó ninu idile Kristian?
◻ Bawo ni awọn ọ̀dọ́ Kristian ṣe lè dákún wíwàlálàáfíà idile?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
“Kò si ohunkohun ninu isin Kristian ti ó tubọ dabii titun ti ó sì tubọ lekoko, ni ifiwera pẹlu ìwà ìkẹ́rabàjẹ́ akoko naa, ju oju ti awọn Kristian fi wo igbeyawo lọ. . . . [Ó] bẹrẹ sanmani titun kan fun araye.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Awọn Kristian ọkọ ń fun awọn aya wọn niṣiiri lati sọ imọlara wọn jade, ní kika awọn imọlara wọnyi sí