Awọn Iṣẹda Titun Ni A Mú Jade!
ỌLỌGBỌN Ọba Solomoni sọ nigba kan ri pe: “Ko si ohun titun labẹ oorun.” (Oniwasu 1:9) Iyẹn jẹ otitọ nipa ayé ti ara eyi ti a ń gbe ninu rẹ̀, ṣugbọn ki ni nipa ti ilẹ-ọba titobi ti iṣẹda tẹmi Jehofa? Ninu ilẹ-ọba yẹn, ẹnikan ti o tobi ju Solomoni lọ, niti gidi, ti o jẹ́ ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí, wá di iṣẹda titun kan ti o tayọ. Bawo ni eyi ṣe ṣẹlẹ?
Ni ọdun 29 ti Sanmani Tiwa, ọkunrin pípé naa, Jesu, yọọda araarẹ fun iribọmi lati ọwọ́ Johannu ni Odò Jordani. “Nigba ti a sì baptisi Jesu tán, o jade lẹsẹ kan-naa lati inu omi wá; sì wo o, ọrun ṣí silẹ fun un, o sì rí ẹmi Ọlọrun sọkalẹ bi adaba, o sì bà lé e: Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wa, ń wi pe, eyi ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹni ti inu mi dun si gidigidi.” (Matteu 3:16, 17) Nipa bayii, ọkunrin naa Kristi Jesu jẹ́ akọkọ ninu iṣẹda titun kan, ẹni ti a fàmì òróró yàn lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Lẹhin naa, lori ipilẹ iku irubọ rẹ̀, Jesu di Olulaja majẹmu titun kan laaarin Ọlọrun ati awujọ awọn eniyan kan ti a ṣayan. Ọkọọkan ninu awọn wọnyi ti di “ẹda titun,” eyi ti a bí nipasẹ ẹmi Ọlọrun fun ireti ti ọrun, pẹlu ifojusọna fun ṣiṣakoso pẹlu Jesu ninu Ijọba rẹ̀ ti ọrun.—2 Korinti 5:17; 1 Timoteu 2:5, 6; Heberu 9:15.
Lati ọpọ ọrundun sẹhin, awọn Kristian ẹni-ami-ororo wọnyi, ni a ti ń kojọpọ ni iṣọkan pẹlu Kristi gẹgẹ bi ijọ Kristian tootọ naa, eyi ti o jẹ́ iṣẹda titun kan ninu araarẹ. Ọlọrun pè é jade lati inu ayé yii fun ète kan, gẹgẹ bi aposteli Peteru ti sọ: “Ṣugbọn ẹyin ni iran ti a yàn, olu-alufaa, orilẹ-ede mimọ, eniyan ọ̀tọ̀; ki ẹyin ki o lè fi ọlá ńlá ẹni ti ó pè yin jade kuro ninu okunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn.” (1 Peteru 2:9) Gẹgẹ bii Kristi Jesu, iṣẹda titun tí Ọlọrun kọkọ dá, iṣẹda titun ti o tẹle e yii ni iṣẹ-aigbọdọmaṣe ti o ṣekoko julọ lati waasu ihinrere naa. (Luku 4:18, 19) Lẹnikọọkan, awọn mẹmba rẹ̀, eyi ti o jẹ́ 144,000 ni paripari rẹ̀, gbọdọ “gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyi ti a dá nipa ti Ọlọrun ni ododo ati ni iwa mimọ otitọ.” (Efesu 4:24; Ìfihàn 14:1, 3) Eyi beere pe ki wọn mú “eso ti ẹmi” dagba, eyi ti a ṣapejuwe ni Galatia 5:22, 23, ki wọn si fi iṣotitọ bojuto iṣẹ́ ìríjú wọn.—1 Korinti 4:2; 9:16.
Ki ni nipa ti iṣẹda titun yii ni akoko ode-oni? Ni ọdun 1914, gẹgẹ bi iṣetojọ akoko Bibeli ṣe fihàn, ọ̀rọ̀ inu Ìfihàn 11:15 ni a muṣẹ: “Ijọba ayé di ti Oluwa wa [Jehofa], ati ti Kristi rẹ̀; oun o si jọba lae ati laelae.” Igbesẹ akọkọ tí Kristi gbé gẹgẹ bi Ọba titun ti a ṣẹṣẹ fijoye ni lati fi Satani ati awọn angẹli ẹmi eṣu rẹ̀ sọ̀kò lati ọrun jù si gbangba ori ilẹ̀-ayé. Eyi mú “ègbé” wa “fun ayé,” lọna ogun agbaye kin-in-ni ati awọn hilahilo rẹ̀ ti o ba a rìn.—Ìfihàn 12:9, 12, 17.
Eyi tun ṣiṣẹ bakan naa gẹgẹ bi ami akiyesi fun awọn aṣẹku iṣẹda titun naa lori ilẹ̀-ayé pe wọn gbọdọ nipin-in ninu mimu asọtẹlẹ Jesu ṣẹ pe: “A o si waasu ihinrere ijọba [ti a ti gbekalẹ] yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì de.” Ki ni “opin” yẹn? Jesu ń baa lọ lati ṣalaye pe: “Nitori nigba naa ni ipọnju nla yoo wà, iru eyi ti kò sí lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ iwa di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ kì yoo sì sí. Bi kò sì ṣe pe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti ìbá lè la a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ ni a o fi ké ọjọ wọnni kuru.”—Matteu 24:3-14, 21, 22.
Ẹmi Jehofa sun awọn ẹni-ami-ororo ti iṣẹda rẹ̀ titun wọnyẹn lati jẹ́ ki ọwọ wọn di ninu igbetaasi iwaasu gbigbooro julọ naa ti o tii ṣẹlẹ lori ilẹ̀-ayé yii ri. Bẹrẹ pẹlu kìkì ẹgbẹrun diẹ ni 1919, iye awọn akede Ijọba onitara wọnyii ti lọ soke di nǹkan bii 50,000 nigba ti yoo fi di aarin awọn ọdun 1930. Gẹgẹ bi a ṣe sọtẹlẹ, “ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ̀ wọn si opin ilẹ̀-ayé.”—Romu 10:18.
Awọn wọnni ti o ṣẹku lara iṣẹda titun naa yoo ha jẹ kìkì awọn wọnni ti a kojọ fun igbala bi? Bẹẹkọ, nitori asọtẹlẹ ti sọ pe awọn angẹli Ọlọrun yoo di awọn atẹgun ipọnju nla naa mú titi di ìgbà ti a ba pari ikojọ naa kìí ṣe kìkì ti awọn Israeli ti ẹmi ti ọrun wọnyi nikan ni ṣugbọn ti awọn miiran pẹlu, “ọpọlọpọ eniyan ti ẹnikẹni kò lè kà, lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹya, ati eniyan, ati lati inu ede gbogbo wá.” Ki ni yoo jẹ kadara wọn? Họwu, wọn yoo “jade lati inu ipọnju nla” wa laisi ipalara lati gbadun ìyè ayeraye ninu paradise ilẹ̀-ayé!—Ìfihàn 7:1-4, 9, 14.
Lọna ti o munilayọ, ogunlọgọ nla yii, ti a kojọ lati inu nǹkan bii 229 ilẹ, ti gbilẹ dori iye ti o fẹrẹẹ tó 4,500,000 awọn ọjafafa Ẹlẹrii. Ọpọlọpọ ṣì ń bọ̀, gẹgẹ bi a ti fihàn nipa awọn 11,431,171 ti wọn wá sibi Iṣe-iranti iku Jesu ni April 17 ni ọdun ti o kọja. Ninu gbogbo araadọta-ọkẹ wọnyi, kìkì 8,683, ti wọn jẹwọ jíjẹ́ awọn ti o ṣẹku lori ilẹ̀-ayé lara iṣẹda titun naa, ni wọn nipin-in ninu ohun iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti naa. Awọn wọnni ti wọn wà ninu awujọ kekere yii kò lè ṣaṣepari iṣẹ́ iwaasu gbigbooro ti ode-oni lae, funraawọn. Awọn araadọta-ọkẹ ti wọn parapọ di ogunlọgọ nla ń ṣiṣẹ ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu wọn ninu mimu iṣẹ́ naa ṣe nisinsinyi. (Sefaniah 3:9) Ju bẹẹ lọ, awọn mẹmba ogunlọgọ nla naa ti a ti dalẹkọọ gidigidi ń ṣe iṣẹ́ abojuto ati iṣẹ́ wiwulo miiran ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Ẹgbẹ Oluṣakoso Israeli tẹmi ti a fàmì òróró yàn naa, gan-an gẹgẹ bi awọn Netinimu ti wọn kìí ṣe ọmọ Israeli ṣe ṣiṣẹ pẹlu awọn alufaa ti wọn ń tun ogiri Jerusalemu kọ́.—Nehemiah 3:22-26.
Iṣẹda “Awọn Ọrun Titun ati Ayé Titun Kan”
Ẹ wo bi ayọ ti ń ba ikojọpọ yii rìn ti pọ tó! Ṣe ni o ri gan-an gẹgẹ bi Jehofa ṣe sọ pe yoo ri: “Emi o da ọrun titun ati ayé titun: a kì yoo sì ranti awọn ti iṣaaju, bẹẹ ni wọn kì yoo wá sí àyà. Ṣugbọn ki ẹyin ki o yọ̀, ki inu yin ki o sì dun titi lae ninu eyi ti emi o dá: nitori kiyesii, emi o da Jerusalemu ni inudidun, ati awọn eniyan rẹ̀ ni ayọ. Emi o sì ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o sì yọ̀ ninu awọn eniyan mi: a kì yoo sì tun gbọ ohùn ẹkún mọ́ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe.” (Isaiah 65:17-19) Awọn ọrun titun ti iṣẹda Jehofa lakootan yoo parapọ jẹ́ Kristi Jesu ati 144,000 awọn mẹmba iṣẹda titun ti a ji dide awọn ti a ti rà lati inu iran eniyan ni eyi ti o ju ọrundun 19 ti o ti kọja lọ. O lógo fíìfíì, ju ijọba ori ilẹ̀-ayé eyikeyii miiran lọ ti o ṣakoso ni Jerusalemu gidi, àní ti ọjọ Solomoni paapaa. O ni ninu Jerusalemu Titun, ilu-nla ti ọrun, eyi ti a ṣapejuwe ninu ẹwà adángbinrin rẹ̀ ni Ìfihàn ori 21.
Jerusalemu Titun jẹ́ iyawo tẹmi fun Kristi, awọn 144,000 ẹni-ami-ororo ti wọn jẹ́ ọmọlẹhin rẹ̀, ti wọn darapọ mọ Ọkọ-iyawo wọn ni ọrun lẹhin iku ati ajinde wọn nipa tẹmi. Awọn ni a fi aworan ṣapẹẹrẹ ni Ìfihàn 21:1-4 gẹgẹ bi eyi ti “ń ti ọrun sọkalẹ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wa,” iyẹn ni pe, wọn jẹ ẹni ti oun ń lò lati dari awọn ibukun si iran eniyan nihin-in lori ilẹ̀-ayé. Ni ọ̀nà yii asọtẹlẹ naa ni a muṣẹ pe: “Kiyesii, àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, oun o sì maa bá wọn gbe, wọn o sì maa jẹ́ eniyan rẹ̀, ati Ọlọrun tikaraarẹ yoo wà pẹlu wọn yoo sì maa jẹ́ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo sì nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; kì yoo sì sí iku mọ, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkun, bẹẹ ni kì yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”
Ẹ wo bi a ti le kun fun ọpẹ́ to fun dídá ti Ọlọrun dá awọn ọrun titun yẹn! Lai dabi awọn iṣakoso onigba kukuru ati onibajẹ ti o ti yọ iran eniyan lẹnu fun akoko ti o pẹ, iṣeto onijọba ti Ọlọrun yii yoo wà titilọ gbére. Iṣẹda titun naa ati ọmọ wọn nipa tẹmi, ogunlọgọ nla, yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nitori ileri Ọlọrun siwaju sii pe: “Nitori gẹgẹ bi awọn ọrun titun, ati ayé titun, ti emi o ṣe, yoo maa duro niwaju mi, bẹẹ ni iru-ọmọ rẹ ati orukọ rẹ yoo duro, ni Oluwa wi.”—Isaiah 66:22.
“Ayé titun” naa bẹrẹ pẹlu ọmọ ti wọn jẹ́ awọn ẹni-ami-ororo ti iṣẹda titun yii. O jẹ ẹgbẹ́ awujọ araye olubẹru Ọlọrun. Ikoriira, iwa-ọdaran, iwa-ipa, idibajẹ, ati ainiwarere ninu ẹgbẹ́ awujọ eniyan lonii dajudaju tẹnumọ aini naa fun iyipada patapata kan si ẹgbẹ́ awujọ ayé titun kan, eyi ti ń ṣiṣẹ labẹ idari aṣenilanfaani ti awọn ọrun titun. Iyẹn ni ohun ti Jehofa pete. Gan-an gẹgẹ bi oun ti dá awọn ọrun titun, bẹẹ ni o ń dá ayé titun nipa kiko awọn ogunlọgọ nla eniyan jọ gẹgẹ bi òpómúléró ẹgbẹ́ awujọ ayé titun alalaafia kan. Ẹgbẹ́ awujọ eniyan yii nikan ni a o gbala láàyè “lati inu ipọnju nla.”—Ìfihàn 7:14.
Ki ni ohun ti a lè reti tẹle ipọnju nla naa? Ni sisọrọ pẹlu awọn aposteli rẹ̀, awọn ẹni akọkọ ti yoo parapọ di awọn ọrun titun ti yoo ṣakoso ilẹ̀-ayé titun naa, Jesu ṣeleri pe: “Loootọ ni mo wi fun yin, pe ẹyin ti ẹ ń tọ̀ mi lẹhin, ni ìgbà atunbi, nigba ti ọmọ eniyan yoo jokoo lori ìtẹ́ ogo rẹ̀, ẹyin o si jokoo pẹlu lori ìtẹ́ mejila, ẹyin ó maa ṣe idajọ awọn ẹya Israeli mejila.” (Matteu 19:28) Gbogbo awọn 144,000 ti Jerusalemu Titun yii yoo nipin-in pẹlu Jesu ninu ṣiṣedajọ iran eniyan. Ifẹ yoo rọpo imọtara-ẹni nikan nigba naa ati ikoriira gẹgẹ bi ipilẹ lori eyi ti a kọ́ ẹgbẹ́ awujọ eniyan lé. Awọn iṣoro ẹ̀yà, iran, ati ti orilẹ-ede ni a o mú kuro patapata. Lọna ti ń tẹsiwaju, ajinde yoo mú awọn ololufẹ wa pada wá. Iran eniyan oluṣotitọ lọna ẹgbẹẹgbẹrun ọkẹ rẹ̀ yoo di idile titobi kan, ti a sopọ ṣọkan, ti a gbe larugẹ si ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayé kan ti a sọ di paradise.
Eyi yoo fi pupọpupọ ju Akoso Aláìlálèébù kan ti a finúrò tabi ibi Mèremère Ẹlẹ́wà inu ìwé lasan kan lọ. Yoo jẹ iṣẹda wíwà titilọ gbére—‘ti awa ń duro de gẹgẹ bi ileri rẹ̀ awọn ọrun titun ati ayé titun, ninu eyi ti ododo ń gbé’! (2 Peteru 3:13) Dajudaju, eyi jẹ ifojusọna agbayanu, ileri ti o gborinlọla ẹni naa ti o sọ pe, “Kiyesii, mo ń sọ ohun gbogbo di ọ̀tun,” ti o si fi ọ̀rọ̀ afungbagbọ lokun yii kun un pe: “Nitori ọ̀rọ̀ wọnyi ododo ati otitọ ni wọn.”—Ìfihàn 21:5.