Didagbasoke Pẹlu Eto-ajọ Jehofa ni South Africa
Gẹgẹ bi a ṣe sọ ọ́ lati ẹnu Frans Muller
NIGBA TI emi ati David ẹ̀gbọ́n mi ń sunmọ ọkọ̀ oju-irin àṣálẹ́ ti a sábà maa ń wọ̀ lati ibudokọ gbogbogboo ti Cape Town, ó yà wá lẹnu lati ri akọle naa “Awọn Alawọ Funfun Nikan.” Ẹgbẹ́ Nationalist Party ti wọle ìbò ni 1948 wọn sì ti ṣe ifilọlẹ ilana-eto kẹlẹyamẹya.
Nitootọ, iyasọtọọtọ ẹya-iran ni a ti ń ṣe fun ìgbà pipẹ ni South Africa, gẹgẹ bi o ṣe rí ni ọpọlọpọ orilẹ-ede ni Africa lakooko ijọba agbókèèrèṣàkóso. Ṣugbọn nisinsinyi a ń fi ipá mú un ṣiṣẹ nipasẹ ofin, a kò sì gbà wá láàyè lati ṣajọpin ọkọ̀ kan-naa mọ́ pẹlu awọn ará South Africa alawọ dudu. Ni ọdun 45 lẹhin naa, kẹlẹyamẹya ni a tú palẹ.
Ni gbogbo akoko kẹlẹyamẹya ti a mú bá ofin mu naa, eyi ti o gbé awọn ipenija kalẹ lati maa baa lọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ wa ni ọ̀nà ti awa ìbá ti fẹ́, mo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ojiṣẹ alakooko kikun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ni lọwọlọwọ, ni ọjọ-ori 65 mo lè wẹhin pada wo idagbasoke agbayanu ti eto-ajọ Jehofa ni iha guusu Africa, mo sì dupẹ fun anfaani didagbasoke pẹlu rẹ̀.
Ogún-ìní Kristian Kan
Nigba ti baba mi wà ni èwe, ọ̀ràn-anyàn ni fun un lati ka Bibeli soke fun baba rẹ̀ loroowurọ kutukutu. Bi akoko ti ń lọ Baba mú ifẹ ti o jinlẹ fun Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dagba. Nigba ti a bí mi ni 1928, baba mi ń ṣiṣẹsin ninu ajọ-igbimọ ṣọọṣi ti Ṣọọṣi Alatunṣe Dutch ni Potgietersrus. Ni ọdun yẹn aburo baba mi fun un ni ẹ̀dà iwe Duru Ọlọrun.
Bi o ti wu ki o ri, Baba mi sọ fun Mama mi lati jó iwe naa, ni sisọ pe ó wá lati inu ẹya-isin kan. Ṣugbọn ó fi pamọ, ati ni ọjọ kan nigba ti o ṣẹlẹ pe Baba mú iwe naa, ó ṣí akori naa “Ọlọrun Ha Ń Dá Ẹnikẹni Loro Bi?” Bi o tilẹ jẹ pe oun mọ̀ daju pe awọn Akẹkọọ Bibeli, bi a ṣe ń pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa, kò tọna, ẹmi itọpinpin rẹ̀ bori rẹ̀, ó sì bẹrẹ sii kawe. Oun kò lè gbé iwe naa jù silẹ. Ni ibẹrẹ awọn wakati owurọ, bi o ti bọ sori ibusun, ó sọ pe: “Onítèmi, mo ń lọ́ra lati gbà á, ṣugbọn wọn ní otitọ naa.”
Ni owurọ ọjọ keji, Baba gun kẹkẹ 50 kilomita lati gba awọn iwe sii lati ọ̀dọ̀ Akẹkọọ Bibeli ti o wà nitosi jù. Ni deedee, oun yoo kawe di ọganjọ òru. Ó tilẹ gbiyanju lati yi ojiṣẹ ṣọọṣi Alatunṣe Dutch lọkan pada nipa awọn otitọ Bibeli ti oun ń kẹkọọ, ni rireti pe ṣọọṣi naa yoo ṣe awọn atunṣebọsipo. Awọn isapa rẹ̀ já sí pàbó, nitori naa ó kọwe fiṣẹ silẹ kuro ninu ṣọọṣi naa ó sì bẹrẹ si fi taratara waasu. Otitọ Bibeli di ohun ti o ṣe pataki julọ ninu igbesi-aye rẹ̀ ati ohun ti o ṣe pataki julọ ninu ile wa. Ninu ipo ayika yii ni mo ti dagba soke.
Lẹhin naa, Baba di aṣaaju-ọna, tabi ojiṣẹ alakooko kikun. Ó rinrin-ajo ọ̀nà jijin gan-an ninu ọkọ̀ atijọ Model T Ford kan lati waasu. Lẹhin awọn ọdun bii melookan, aini idile wa ti ń gbèrú sii sún un lati dáwọ́ iṣẹ aṣaaju-ọna duro, ṣugbọn ó ń baa lọ lati jẹ́ agbekankanṣiṣẹ ninu iṣẹ wiwaasu. Ni awọn ọjọ Sunday kan awa yoo rinrin-ajo ohun ti o tó 90 kilomita lati waasu pẹlu rẹ̀ ni ilu Pietersburg.
Òwò Alaṣeyọrisirere Kan
Nigbẹhin-gbẹhin Baba mi ṣí ile-itaja gbogbogboo kekere kan. Laipẹ ó di ilọpo meji ni iwọn, ti a sì ṣí ile-itaja keji. Awọn àgbẹ̀ ọlọ́rọ̀ melookan da òwò pọ̀ pẹlu Baba mi, bi akoko sì ti ń lọ wọn pawọpọ ṣí ile-itaja ọja alatunta papọ pẹlu ile-itaja alasokọra mẹfa ti ó wà kaakiri ibi gbigbooro.
Diẹ ninu awọn ẹ̀gbọ́n mi ọkunrin darapọ ninu idawọle okòwò naa ti wọn sì ní ifojusọna didi ọlọ́rọ̀ nisinsinyi. Bi o ti wu ki o ri, ipo tẹmi wa bẹrẹ sii forí fáa. A di ẹni ti awọn ọ̀rẹ́ ati aladuugbo ayé tubọ tẹwọgba, ti wọn ń késí wa si ibi ariya wọn. Ni riri ewu yii, Baba pe ipade idile ó sì pinnu lati ta okòwò naa ki o sì ṣí lọ si Pretoria ki a baa lè ṣe pupọ sii ninu iṣẹ-isin Jehofa. Ó ṣí ile-itaja kanṣoṣo, eyi ti oṣiṣẹ kan ti a ń sanwo fun ń bojuto.
Awọn ẹ̀gbọ́n mi ọkunrin Koos ati David bẹrẹ sii ṣe aṣaaju-ọna, ni titipa bayii darapọ mọ ẹ̀gbọ́n mi obinrin, Lina. Ni oṣu kan ni 1942, idile wa ẹlẹni mẹwaa lo aropọ 1,000 wakati ninu iṣẹ wiwaasu naa. Ni ọdun yẹn mo fami ṣapẹẹrẹ iyasimimọ igbesi-aye mi si Jehofa nipasẹ iribọmi ninu omi.
Idi Ti Mo Fi Fi Ile-ẹkọ Silẹ Kiakia
Ni 1944, nigba ti Ogun Agbaye II wà ni otente rẹ̀, Gert Nel, alaboojuto arinrin-ajo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan, beere lọwọ mi boya mo ń wewee lati wọnu òtú awọn aṣaaju-ọna. “Bẹẹni” ni mo dahun, “ni ọdun meji nigba ti mo bá pari ile-ẹkọ giga.”
Ni gbigbe oju-iwoye ọpọlọpọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni akoko naa yọ, o kilọ pe: “Ṣọra ki Armageddoni má baa bá ọ ni jijokoo lori aga ile-ẹkọ.” Niwọn bi emi kò ti fẹ ki iyẹn ṣẹlẹ, mo pa ile-ẹkọ tì mo sì wọnu iṣẹ aṣaaju-ọna ni January 1, 1945.
Iṣẹ-ayanfunni mi akọkọ jẹ́ ni Vereeniging, lẹbaa Johannesburg, ti awọn alabaaṣiṣẹpọ mi sì jẹ́ Piet Wentzel ati Danie Otto. Lọpọ ìgbà emi yoo lo ohun ti ó ju 200 wakati ni oṣu kan ni wiwaasu. Bi akoko ti ń lọ Piet ni a tun yàn sí ilu-nla ti Pretoria, ti Danie sì nilati dawọ aṣaaju-ọna duro lati ṣeranwọ fun baba rẹ̀ arugbo loko. Eyi fi mi silẹ gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí kanṣoṣo lati bojuto awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile 23 ni Vereeniging.
Laipẹ laijinna, mo gba lẹta kan lati ẹka ọfiisi ti ó yàn mi si Pretoria. Bi o tilẹ jẹ pe emi kò lóye idi fun iṣẹ-ayanfunni titun naa ni akoko naa, mo mọ̀ lẹhinwa ìgbà naa pe kì bá ti jẹ́ ohun ti o lọgbọn-ninu lati fi ọmọ ọdun 17 ti kò niriiri silẹ ni ohun nikan. Mo ṣì nilo ọpọlọpọ idanilẹkọọ ǹ bá sì ti di ẹni ti a mú rẹwẹsi.
Lẹhin ṣiṣiṣẹsin ni Pretoria ati ni níní iriri ti mo nilo, a késí mi lati di aṣaaju-ọna akanṣe kan. Emi ati Piet Wentzel wa ṣeto lati fun awọn ọ̀dọ́ eniyan ti wọn wá sí Pretoria lati ṣe aṣaaju-ọna ni idanilẹkọọ iṣẹ-ojiṣẹ ti ó gbeṣẹ nigba naa. Nigba naa lọhun-un Piet ni a ti yàn gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo ni adugbo naa. Lẹhinwa ìgbà naa ni ó gbé arabinrin mi Lina niyawo, wọn sì ń ṣiṣẹsin papọ nisinsinyi ni ẹka ọfiisi South Africa.
Lara awọn ti wọn wá lati ṣe aṣaaju-ọna ni Pretoria ni Martie Vos, ọ̀dọ́ obinrin fifanimọra kan ti a ti tọ́ dagba ninu idile Ẹlẹ́rìí kan. Ẹnikinni keji wa ti fa araawa lọkan mọra lọna ti elere-ifẹ, ṣugbọn a ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ sibẹ, ti o kere ju lati gbeyawo. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a gba iṣẹ-ayanfunni si awọn ibomiran, a ṣì ń gburo araawa nipasẹ iwe kikọ.
Iṣẹ-isin Beteli ati Ile-ẹkọ Gilead
Ni 1948, a késí mi lati sin ni ẹka ọfiisi Watch Tower Society ni Cape Town. Ni akoko naa, kò sí ile-gbigbe kanṣoṣo fun gbogbo awa 17 ti a ń ṣiṣẹ ninu awọn ọfiisi mẹta ti wọn ń háyà ati ile-iṣẹ kekere kan ti o wà lẹgbẹẹ rẹ̀. Diẹ ninu wa ni a gbà sinu ile pẹlu awọn idile, ti awọn yooku sì ń gbé ninu ile awọn akẹkọọ.
Ni ọjọ-iṣẹ kọọkan awọn mẹmba 17 ti idile Beteli yoo pade papọ fun ijọsin owurọ ninu yàrá iparọ aṣọ ti ile-iṣẹ kekere naa. Ọpọlọpọ ninu wa nilati ṣeto fun ounjẹ ọ̀sán wa funraawa. Nigba naa, lẹhin iṣẹ odidi ọjọ kan gbáko, awa yoo rinrin-ajo lọ si awọn ile-ibugbe wa ni awọn apa ibi ọtọọtọ ni Cape Town. Ninu ọ̀kan ninu awọn irin-ajo wọnyi, gẹgẹ bi mo ti mẹnu kàn án tẹlẹtẹlẹ, ni ẹnu ya emi ati arakunrin mi David nipa akọle naa ti ń kede pe, “Awọn Alawọ Funfun Nikan.”
Nigba ti mo kọkọ de si ọfiisi Cape Town, mo mọ̀ pe mo ṣì ni ohun pupọ lati kẹkọọ, nitori naa mo beere lọwọ Arakunrin Phillips, alaboojuto ẹka wa pe: “Ki ni ohun ti mo lè ṣe lati mu araami bá ipo mu?”
“Frans,” ni ó dahun, “maṣe ṣaniyan nipa biba ipo mu. Ṣá maa tẹsiwaju!” Mo ti maa ń figba gbogbo gbiyanju lati ṣe iyẹn, mo sì ti kẹkọọ pe nipa titẹsiwaju pẹlu ohun ti eto-ajọ Jehofa bá pese nipa ounjẹ ati idari tẹmi, ẹnikan yoo maa baa lọ lati dagbasoke pẹlu rẹ̀.
Ni 1950, a késí mi lati lọ si kilaasi kẹrindinlogun ti Watch Tower Bible School of Gilead fun idanilẹkọọ ijihin-iṣẹ-Ọlọrun. Ile-ẹkọ naa ni a kọ́ sí South Lansing, New York, nigba naa, nǹkan bi 400 kilomita niha ariwa Brooklyn, New York. Nigba ti mo ń ṣiṣẹ fun ìgbà diẹ ni orile-iṣẹ agbaye ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Brooklyn, mo ṣakiyesi aarin gbungbun eto-ajọ Jehofa ti ó ṣeefojuri funraami. Ifọkansin olotiitọ-inu ti awọn wọnni ti ń mú ipo iwaju nibẹ fi imọriri jijinlẹ fun eto-ajọ Jehofa kún inu mi.
Iṣẹ-ojiṣẹ Mi Ti Ń Baa Lọ
Lẹhin pipada si South Africa, a yàn mi lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo ni iha ariwa Transvaal, nibi ti mo gbé dagba. Lẹhin ti mo ti kọ lẹta fun oṣu mẹfa, emi ati Martie ṣegbeyawo ni December 1952, ó sì darapọ mọ mi ninu iṣẹ arinrin-ajo. Imọriri ti awọn Kristian ara wa ni fun awọn ibẹwo wa jẹ eyi ti ń muni lọkan yọ̀.
Fun apẹẹrẹ, nigbakan ri ti a ń bẹ ijọ kan wò ninu ẹgbẹ́ awujọ awọn àgbẹ̀ aroko kan, a bá idile kan gbé ti wọn tọrọ gafara fun ṣiṣaini miliiki fun tíì tabi kọfi. Laipẹ ni a wá mọ̀ pe wọn ti ta maluu wọn kanṣoṣo ti ń pese wàrà ki wọn baa lè ni owó ti ó tó lati ra epo ọkọ̀ lati mú wa ṣebẹwo si awọn apa ipinlẹ wọn ti o jinna lati waasu fun awọn àgbẹ̀. Ẹ wo bi a ṣe nifẹẹ iru awọn ara bẹẹ tó!
Nigba miiran mo maa ń nimọlara aikaju-oṣunwọn fun iṣẹ ayika, paapaa julọ nigba ti mo bá ń yanju awọn iṣoro ti o ni awọn eniyan ti o dagba ninu. Nigba kan mo nimọlara jijẹ ẹni ti nǹkan ti sú niti ero-imọlara debi pe mo sọ fun Martie pe kò gbọdọ yà á lẹnu bi a bá tún wa yàn si iṣẹ aṣaaju-ọna nitori ainiriiri mi. Ó mú un dá mi loju pe oun yoo layọ lati ṣiṣẹsin ni ipo-aye eyikeyii niwọn bi a bá ti lè maa baa lọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun.
Ronuwoye iyalẹnu wa nigba ti a dé ijọ ti o tẹle ti iwe ti a kọ si wa sì ní ninu iṣẹ-ayanfunni kan lati ṣiṣẹsin ninu iṣẹ agbegbe! Fun nǹkan bi ọdun meji, a rinrin-ajo la South Africa ati Namibia, ti a ń pe ni South-West Africa nigba naa ja. Bi o ti wu ki o ri, nitori eto-igbekalẹ kẹlẹyamẹya, iṣẹ wa ni o sábà maa ń nira. Lemọlemọ ni a ń dù wá ni iyọnda lati wọ ilu awọn alawọ dudu ati nigba miiran a kìí fun wa ni iyọnda fun awọn apejọpọ.
Ni 1960, fun apẹẹrẹ, a gba iyọnda lati ṣe apejọpọ agbegbe kan ni Soweto. Awọn ará alawọ dudu lati awọn ijọ jijinna ti ra tikẹẹti ọkọ̀ oju-irin ati ọkọ̀ èrò lati wá, ṣugbọn ijọba gbọ́ nipa iwewee wa ti o sì fagile iyọnda naa. Pẹlu ọgbọ́n, a tọ ọ̀gá oluṣabojuto oniwa bi-ọrẹ kan lọ ni ilu kan ti o jẹ́ 20 kilomita ni iha keji Johannesburg. O fi inurere pese awọn ile lilo ti o tilẹ dara sii fun wa, ti a sì ni apejọpọ agbayanu kan, eyi ti iye ti o ju 12,000 gbadun!
Ẹ wo bi ipo ọ̀ràn naa ti yipada ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́! Nisinsinyi, pẹlu kẹlẹyamẹya ti a ti da oju rẹ̀ dé, a lè padepọ lominira nibikibi ni awọn adugbo alawọ dudu, funfun, ṣàyìnrín, tabi ti awọn ara India. Gbogbo wa, laika ẹya-iran si, lè jokoo papọ ki a sì gbadun ibakẹgbẹ. Kìkì iyatọ niti èdè ni o lè nipa lori ibi ti ẹnikan lè fẹ lati jokoo si.
Ẹkọ Rironilara Kan
Lẹhin lọhun-un ni 1947, baba mi ṣe aṣiṣe ńlá kan. Ile-itaja rẹ̀, eyi ti o wà ni ohun ti o ju 200 kilomita si ibi ti oun ati Mama mi ń gbé, di eyi ti kò mówó wọle wá mọ́ nitori aiṣotitọ ninu ọ̀nà ti a ń gbà ṣabojuto rẹ̀, nitori naa ó kó lọ pada ni oun nikan lati bojuto o funraarẹ. Akoko gigun ti kò fi wà pẹlu Mama yọrisi ṣiṣubu rẹ̀ sinu idanwo. Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, a yọ ọ́ lẹgbẹ.
Eyi tẹ̀ ẹ́ mọ́ mi lọkan lọna ti o ronilara, pe jijẹ onitara fun otitọ Bibeli nikan kò tó. Gbogbo wa nilati rọ̀ mọ́ awọn ọ̀pá idiwọn Bibeli. (1 Korinti 7:5) Lẹhin ọpọlọpọ ọdun, Baba ni a gbà pada gẹgẹ bi apakan ijọ Kristian ti ó sì fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin titi di ìgbà iku rẹ̀ ni 1970. Mama mi ọ̀wọ́n duroṣinṣin titi ti o fi kú ni 1991.
Awọn Ibukun Siwaju Sii
Ni 1958, emi ati Martie lọ si apejọpọ titobi julọ tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tii ṣe rí, ni Yankee Stadium ati Polo Grounds ni New York. A wulẹ kún fun ayọ ni fun jijẹ apakan eto-ajọ agbayanu ti Jehofa. Wiwa pẹlu ogunlọgọ ńlá awọn eniyan ti wọn ju 253,000 lọ ni ọ̀sán ọjọ Sunday jẹ iriri kan ti a kì yoo gbagbe lae. Si wa, nihin-in, ni ijẹgidi ‘ogunlọgọ eniyan lati inu orilẹ-ede gbogbo wa’ ti wọn pejọpọ ni alaafia. (Ìfihàn 7:9, 10) Martie duro ni New York lati lọ si Ile-ẹkọ Gilead, emi sì pada sẹnu iṣẹ agbegbe ni South Africa.
Ni 1959, lẹhin ti Martie ti pada dé lati kilaasi ikejilelọgbọn ti Ile-ẹkọ Gilead ti o lọ, a késí wa lati ṣiṣẹsin ni ẹka ọfiisi South Africa, eyi ti o wà lẹgbẹẹ Elandsfontein, ni ila-oorun Johannesburg nigba naa. La gbogbo awọn ọdun naa já, mo ti rí itẹsiwaju eto-ajọ naa ni ọpọlọpọ ọ̀nà. Paapaa julọ idagbasoke rẹ̀ ninu ifẹ ati igbatẹniro. Mo ti kẹkọọ pe Jehofa ń dari eto-ajọ rẹ̀ nipasẹ Jesu Kristi ti oun yoo sì lo awọn wọnni ti wọn ba mu araawọn wà larọọwọto.
Ni 1962, mo pada si Brooklyn, New York, lati lọ sibi idanilẹkọọ oloṣu mẹwaa kan nipa ẹka. Eyi jasi iranlọwọ nigba ti, ni 1967, a yàn mi gẹgẹ bi alaboojuto ẹka ti South Africa. Ni 1976, awọn Igbimọ Ẹka ni a yàn, nitori naa nisinsinyi ẹrù-iṣẹ́ naa fun ṣiṣe awọn ipinnu ti o ṣe pataki ni South Africa já lé ejika awọn alagba Kristian oniriri marun-un.
Igbesi-aye Labẹ Kẹlẹyamẹya
Awọn ofin kẹlẹyamẹya nipa lori ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ ẹka wa. Nigba ti a kọ́ Ile Beteli ti Elandsfontein ni 1952, ofin beere fun afikun ile kan ni ẹhin lati fi awọn arakunrin alawọ dudu ati ṣàyìnrín wọ̀ sí. Ofin naa tun beere pe ki wọn maṣe bá awọn alawọ funfun jẹun papọ ni aye-ibugbe awọn ara Africa ti a fẹnu lasan pe bẹẹ. Lẹhin naa, a ṣeto fun wọn lati jẹun ninu ile idana Beteli. Eyi ni iṣeto ounjẹ nigba ti a dé si Beteli ni 1959. Ohun gbogbo ninu mi ń ṣọtẹ lodisi iyasọtọọtọ yii nitori ẹya-iran.
Bi akoko ti ń lọ, ijọba mu iyọnda naa kuro fun awọn arakunrin wa alawọ dudu lati duro ninu ile naa ti o wà lẹhin lajori Ile Beteli. Awọn arakunrin wọnyi nilati duro ninu ile alawọ dudu kan ti o jẹ́ nǹkan bi 20 kilomita si wa. Awọn diẹ ń gbé ninu awọn ile ti a háyà ti awọn miiran sì ń gbé ninu ile awọn akẹkọọ fun awọn àpọ́n ọkunrin. Iru ipo alaitẹnilọrun yii ń baa lọ fun ọpọlọpọ ọdun.
Imugbooro Beteli
Laaarin akoko yii, Beteli ti Elandsfontein ni a nilati mugbooro sii. Lẹhin mimu un gbooro sii ni ilọpo mẹta, a ti dé opin aye-ilẹ wa. Ẹgbẹ́ Oluṣakoso fun wa ni itọni pe a gbọdọ wá ilẹ titun ni agbegbe kan nibi ti a ti nireti pe awọn alaṣẹ adugbo yoo ti gbà wá laaye lati kọ́ ile Beteli kan nibi ti awọn arakunrin wa alawọ dudu pẹlu ti lè duro. Loroowurọ ni idile Beteli maa ń gbadura pe ki Jehofa ṣí ọ̀nà silẹ fun eyi ni ọ̀nà kan ṣáá.
Ẹ wo iru ọjọ alayọ kan ti o jẹ́ nigba ti a rí ilẹ bibojumu kan lẹhin-ọ-rẹhin ni ẹhin odi ilu Krugersdorp, ni iwọ-oorun Johannesburg! Bi o ti wu ki o ri, a tun beere lọwọ wa lẹẹkan sii lati kọ́ ile kan láàyè ọtọ fun awọn arakunrin wa alawọ dudu. A gbà bẹẹ ṣugbọn a kò ri iyọnda gbà fun iye awọn alawọ dudu ti o ju 20 lọ ti a fẹ lati fiwọ sibẹ. A dupẹ pe, nigba ti yoo fi di aarin awọn ọdun 1980, awọn nǹkan bẹrẹ sii yipada. Ijọba mu ki awọn ofin kẹlẹyamẹya amúbí-iná rẹ̀ dẹjú, a sì kesi awọn arakunrin alawọ dudu, ṣàyìnrín, ati awọn ara India pupọ sii lati ṣiṣẹsin pẹlu wa ni Beteli.
Nisinsinyi a ní idile Beteli alayọ, oniṣọkan, nibi ti awọn eniyan lẹnikọọkan, laika ẹya-iran tabi àwọ̀ sí, ti lè gbé ninu eyikeyii ti wọn bá yàn ninu awọn ile naa. Bakan naa, lẹhin ọpọ ọdun ijijadu, a fun wa ni idanimọ ti o bá ofin mu gẹgẹ bi isin kan lẹhin-ọ-rẹhin. Ètò-ẹgbẹ́ adugbo kan ti o bofinmu ni a ti dasilẹ ti a sì mọ̀ gẹgẹ bi “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti South Africa.” Nisinsinyi a ní awọn arakunrin tiwa pẹlu ọla-aṣẹ lati ṣe igbeyawo funni, ati ni awọn agbegbe ile-gbigbe awọn alawọ dudu, awọn Gbọngan Ijọba ń pọ̀ niye bi olú inu oko.
Ẹ wo bi eto-ajọ Jehofa ti tẹsiwaju lati awọn ọjọ akọkọbẹrẹ nigba ti mo ṣiṣẹsin ni ẹka ọfiisi Cape Town! Lati ori idile kekere ẹlẹni 17 laisi Ile Beteli kan, a ti dagbasoke nisinsinyi dé idile Beteli ti o ni iye ti o rekọja 460, ti a sì ni ọgbà Beteli igbalode kan pẹlu awọn ẹrọ kọmputa didiju, awọn ẹrọ itẹweyipo ati Ile Beteli ẹlẹwa kan! Bẹẹni, mo ti ni anfaani ti didagbasoke pẹlu eto-ajọ Jehofa ni South Africa. A ti lọ soke lati ori akede Ijọba 400 nigba ti mo bẹrẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa ni nǹkan bi 50 ọdun sẹhin de iye ti o fẹrẹẹ tó 55,000 lonii!
Mo dupẹ lọwọ Jehofa pe, mo ti ní aya alatilẹhin kan bẹẹ lẹgbẹẹ mi, fun ọdun 40 ti o ti kọja. “Ago mi sì kún akunwọsilẹ.” (Orin Dafidi 23:5) Emi ati Martie kun fun ọpẹ́ lati jẹ́ apakan eto-ajọ Jehofa ti a ń fi ẹmi dari ti a sì pinnu lati maa baa lọ ni ṣiṣiṣẹsin Jehofa ninu ile rẹ̀, ni Beteli, ati lati mú araawa bá eto-ajọ rẹ̀ ti ń tẹsiwaju mu.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 19]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ANGOLA
ZAMBIA
ZIMBABWE
MOZAMBIQUE
BOTSWANA
NAMIBIA
SWAZILAND
SOUTH AFRICA
LESOTHO
MALAWI
TANZANIA
ZAIRE
Pretoria
Johannesburg
Cape Town
Port Elizabeth
GUUSU ÒKUN ATLANTIC
ÒKUN INDIA
MOZAMBIQUE CHANNEL
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Piet Wentzel ati Frans Muller (lapa òsì) ninu iṣẹ aṣaaju-ọna ni 1945
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Frans ati Martie Muller