Títẹ Iwe-Ikẹkọọ Bibeli Nigba Ti A Wà Labẹ Ifofinde
GẸGẸ BI MALCOLM G. VALE ṢE SỌ Ọ́
“Tẹ iwe Children.” Mo gba itọni yiyanilẹnu yii lati ọ̀dọ̀ alaboojuto ẹ̀ka ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Australia nigba Ogun Agbaye II, ni kété lẹhin imujade iwe naa ni apejọpọ St. Louis, Missouri, U.S.A., ni August 10, 1941. Eeṣe ti itọni naa fi yanilẹnu?
ÓDARA, iṣẹ iwaasu wa ni a ti fòfinkàléèwọ̀ ni January 1941, nitori naa iwe títẹ̀ ti ń baa lọ àní ni ọ̀nà kekere kan paapaa yoo jẹ́ ipenija kan. Yatọ si iyẹn, iwe Children jẹ́ iwe oloju-ewe 384 ti o ni awọn aworan mèremère. Ohun-eelo itẹwe wa nilo ìgbéga, bébà ṣọ̀wọ́n, awọn awujọ òṣìṣẹ́ ni a kò sì dálẹ́kọ̀ọ́ fun mímú awọn iwe ẹlẹ́hìn-líle jade.
Ṣaaju ki ń tó ṣapejuwe bi a ṣe kẹsẹjari ninu ìwé-títẹ̀ nigba ti a wà labẹ ifofinde, jẹ ki ń sọ bi mo ṣe wá ṣiṣẹsin ni isopọ pẹlu ọfiisi ẹ̀ka Australia gẹgẹ bi alaboojuto iṣẹ́ ìwé-títẹ̀.
Ipò-Àtilẹ̀wá Ni Ibẹrẹ
Baba mi ní iṣẹ́-òwò ìtẹ̀wé kan ninu ilu-nla aláásìkí ti Ballarat, Victoria, nibi ti a ti bí mi ni 1914. Nitori naa mo kẹkọọ ìwé-títẹ̀ nibi ti mo ti ń ṣiṣẹ ni ile-itẹwe Baba mi. Mo tun ń lọwọ ninu igbokegbodo Church of England, ni kikọrin ninu ẹgbẹ́ akọrin ṣọọṣi naa ati lílu agogo ṣọọṣi. Mo tilẹ wà ni ìlà fun kíkọ́ni ninu ile-ẹkọ Ọjọ-isinmi, ṣugbọn eyi kò rọrun fun mi.
Idi ni pe mo ni awọn ibeere pataki nipa diẹ lara awọn ẹkọ ṣọọṣi. Iwọnyi ní ninu Mẹtalọkan, iná ọrun-apaadi, ati aileeku ọkàn eniyan, kò sì sí ẹni ti o fun mi ni awọn idahun ti ó tẹ́ mi lọrun. Ó tun tojú sú mi pe lati ìgbà de ìgbà, ojiṣẹ wa ń fi ibinu sọrọ nipa awujọ isin kekere kan ti wọn pe araawọn ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo ṣe kayeefi nipa idi ti iru awujọ ti kò jámọ́ nǹkankan bẹẹ yoo fi jẹ́ iru idaamu bẹẹ fun ilu-nla kan ti o ní 40,000 eniyan ninu.
Ni ọjọ Sunday kan, mo wà ni iduro lode ṣọọṣi naa lẹhin isin irọlẹ nigba ti awujọ awọn ọdọmọbinrin diẹ lati inu Ṣọọṣi Mẹtọdiisi rìn kọja. Mo bẹrẹ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu ọ̀kan lara wọn. Orukọ rẹ ni Lucy, ati ni asẹhinwa-asẹhinbọ ó késí mi lọ si ile rẹ̀ lati pade awọn òbí rẹ̀. Ronu nipa iyalẹnu mi nigba ti mo mọ̀ pe ìyá rẹ̀, Vera Clogan, jẹ́ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. A jọ ní ọpọlọpọ ijiroro Bibeli ti o múnilárayá gágá, ohun ti ó sì sọ mú ọgbọ́n dani gan-an ni.
Laipẹ laijinna, emi ati Lucy fẹ́ra, ati nigba ti o fi maa di 1939 a ń gbé ni Melbourne, olu-ilu Victoria. Bi o tilẹ jẹ pe Lucy ti di ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, emi kò tíì ṣe ipinnu. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Ogun Agbaye II bẹ́ silẹ ni September ọdun yẹn, mo bẹrẹ sii ronu gidigidi nipa ohun ti mo ti kẹkọọ rẹ̀ lati inu Iwe Mimọ. Fifofinde iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni January 1941, ràn mi lọwọ niti gidi lati ṣe ipinnu. Mo ya igbesi-aye mi si mimọ fun Jehofa Ọlọrun mo sì ṣe iribọmi laipẹ lẹhin ìgbà naa.
Awọn Iyipada Amunijigiri Ninu Igbesi-Aye Wa
Ni akoko naa, a ń yá ile gbéetán ti o dẹnilara kan gbé ni Melbourne. Kò-pẹ́-kò-jìnnà, bi o ti wu ki o ri, a késí wa lati ṣí lọ sinu ile kan ti ó ni awọn Ẹlẹ́rìí melookan miiran ninu. A ta gbogbo awọn ohun ìfitolé wa ayafi awọn ohun ìfitoyàrá wa a sì ṣí lọ sinu ile kan ti a pè ni ile aṣaaju-ọna. Mo ń baa lọ lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi atẹ̀wé kan ó sì tipa bayii ṣeeṣe fun mi lati ṣètọrẹ siha awọn inawo lílo ile naa. Awọn ọkọlóbìnrin yooku ṣe bakan naa. Awọn aya wa, gẹgẹ bi iyọrisi, lè nipin-in ninu igbokegbodo iwaasu alakooko kikun, awa ọkunrin sì darapọ mọ wọn ninu iṣẹ ajihinrere naa ati ninu awọn ipade Kristian ni irọlẹ ati ni awọn ipari ọsẹ.
Ni kété lẹhin ìgbà naa, emi ati aya mi gba lẹta kan lati ọfiisi ẹ̀ka Watch Tower Society ti ń késí wa lati wá si Sydney. A ta awọn ohun ìfitoyàrá wa a sì san awọn gbese diẹ ti a jẹ, ṣugbọn lati rí owó ti a o san fun ọkọ oju-irin lọ si Sydney, a nilati ta oruka igbeyawo Lucy!
Nitori awọn ikanilọwọko akoko ogun ati ifofinde ti a pàṣẹ rẹ̀ laipẹ sí ìgbà naa, kò si Bibeli tabi awọn iwe-ikẹkọọ Bibeli ti a lè kó wọle lati òkè òkun. Fun idi yii ọfiisi ẹ̀ka ti Australia pinnu lati dá iṣẹ ìtẹ̀wé abẹ́lẹ̀ kan silẹ lati mú ki ìṣàn ounjẹ tẹmi maa baa lọ, a sì késí mi lati bojuto iṣẹ naa. Mo lanfaani lati ṣiṣẹ pẹlu George Gibb, ara Scotland kan, ẹni ti o ń ṣiṣẹsin ni ile-iṣẹ ìtẹ̀wé ẹ̀ka Australia fun iwọn 60 ọdun.a Ìgbà yẹn ni mo gba itọni naa pe: “Tẹ iwe Children.”
Gbigba Ohun-Eelo Ìtẹ̀wé Pada
Ọpọ ni awọn iriri ti ń runisoke, ti ń dáyàfoni nigba miiran, ti a ní ni awọn ọdun ti ó kun fun iṣẹlẹ ogun wọnyẹn. Fun apẹẹrẹ, lati bẹrẹ iṣẹ ìtẹ̀wé wa, a nilo ohun-eelo. Eyi ti a ń lo tẹlẹ lati tẹ̀wé mímọníwọ̀n ni awọn ọdun ti o ṣaaju ogun ni awọn alaṣẹ ijọba ti fipa gbà, ati nisinsinyi ile ìtẹ̀wé kekere ti Society ni a ti tìpa ti a sì ń ṣọ́. Bawo ni a ṣe lè rí awọn ohun-eelo naa gbé jade lọ si ọgangan ibi ti o yẹ fun ìtẹ̀wé abẹ́lẹ̀?
Awọn ẹ̀ṣọ́ ti o di ihamọra, ti wọn ń ṣiṣẹ ni àṣegbà, ń ṣọ ohun-ìní Society tọ̀sán-tòru. Bi o ti wu ki o ri, ọ̀kan lara awọn ogiri ẹhinkunle ni o kángun si ọ̀nà oju-irin kan ti a kìí fi bẹẹ lò. Nitori naa ni alẹ́, ni lilo ọgbọ́n ti o rannileti Esekieli 12:5-7, awọn oṣiṣẹ Beteli kan ti wọn nigboya gba inu ogiri naa wọle nipa yíyọ awọn biriki diẹ kuro. Gbàrà ti wọn ti wọle tan, wọn yoo to ẹ̀yọ biriki naa pada sara ogiri ki wọn ma baa ṣawari wọn. Nipa ṣiṣe ìpiyẹ́ òrugànjọ́ wọnyi fun sáà akoko ti o tó nǹkan bi ọsẹ meji, wọn fi tiṣọratiṣọra tú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kekere kan, ẹ̀rọ Linotype kan, ati awọn ẹ̀rọ diẹ miiran. Lẹhin naa wọn rọra kó awọn ẹyọ-ẹyọ naa jade, àní nigba ti awọn ẹ̀ṣọ́ naa ṣì wà lẹnu iṣẹ!
Bi akoko ti ń lọ a gba afikun ohun-eelo lati orisun miiran, ati pe laipẹ a ń bá iṣẹ ìtẹ̀wé abẹ́lẹ̀ lọ loju mejeeji ni oniruuru ibi jakejado Sydney. Nipa bayii, ó ṣeeṣe fun wa lati tẹ̀ ki a sì di kìí ṣe kìkì iwe Children nikan bikoṣe awọn odindi iwe The New World, “The Truth Shall Make You Free,” ati The Kingdom Is At Hand, ati awọn iwe Yearbook of Jehovah’s Witnesses fun ọdun 1942, 1943, 1944, ati 1945 bakan naa. Ni afikun, lakooko ifofinde awọn ọdun ogun wọnni, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jakejado Australia kò tàsé itẹjade Ilé-Ìṣọ̀nà kan rí. Eyi tun mú un dá wa loju ni ọ̀nà ti ara-ẹni pe ọwọ́ Jehofa kò kuru.—Isaiah 59:1.
Kikoju Awọn Ibẹwo Ti A Kò Reti
Nigba iṣayẹwo iwe loju mejeeji ni akoko ogun, awọn ile-iṣẹ ìtẹ̀wé ni awọn oṣiṣẹ olóyè ijọba ti wọn ń yẹ awọn ohun ti a ń tẹ̀ wò sábà maa ń bẹwo lairotẹlẹ. Nitori naa, ọ̀kan lara awọn ile-iṣẹ itẹwe wa ti ó wà labẹ iboju ni a ṣe ẹ̀rọ ikilọ si lara, bọ́tìnì kan ti a ṣe mọ́lẹ̀ wà larọọwọto olùgbàlejòwọlé. Nigbakigba ti ẹnikan ti kò bá mọ̀ tabi ti ó bá fura sí pe o jẹ́ olùbẹ̀wò kan bá wá sẹnu àtẹ̀gùn, oun yoo tẹ bọ́tìnì naa.
Nigba ti o bá tẹ bọ́tìnì naa, ìran awọn arakunrin ti ń gba oju ferese bẹ́ sóde a maa dùn ún wò! Awọn oṣiṣẹ ti a kọ orukọ wọn silẹ gẹgẹ bi awọn ti a gbà síṣẹ́ yoo duro lati da nǹkan bo awọn abala bébà iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà ti a ti tẹ̀ tabi awọn iwe-ikẹkọọ Bibeli miiran ti a ń ṣiṣẹ lé lori. Lati ṣe eyi, wọn yoo lo awọn abala bébà ti o dọ́gba ti a ti tẹ̀ gẹgẹ bi awọn itẹjade miiran ti a ń ṣe fun awọn oníbàárà ti ń ṣòwò.
Ni akoko iru ibẹwo kan bẹẹ, awọn olùbẹ̀wò meji jokoo sori awọn ìwé-àwòrẹ́rìn-ín, ti wọn ṣì wà ni iwọn abala fífẹ̀, ṣugbọn labẹ rẹ̀ ni awọn abala iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà ti a ti tẹ̀ ni alẹ́ àná wà. Ni ile-iṣẹ ìtẹ̀wé kan ni apa ibomiran ninu ilu-nla naa, a tẹ̀wé ṣòwò ni ojúmọmọ a sì ń tẹ awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ni òru ati ni awọn ipari ọsẹ.
Kikaju Awọn Aini Bébà Wa
Rírí bébà fun ìtẹ̀wé jẹ́ iṣoro ńlá kan. Bi o ti wu ki o ri, awọn ile-iṣẹ ìtẹ̀wé ńlá kan ti wọn kò nilo ẹkunrẹrẹ ipin bébà wọn nitori iṣẹ́-ajé ti ó dínkù nigba ogun muratan lati ta eyi ti o lé silẹ—dajudaju, ni iye-owo gegere nigba gbogbo. Ni akoko kan, bi o ti wu ki o ri, a rí bébà gbà lati orisun miiran.
Ọkọ̀ oju-omi akẹ́rù kan ti ń bọ̀ wá si Australia ní ọpọ ẹrù bébà aláwọ̀ ilẹ̀ ninu, ṣugbọn ọkọ̀ oju-omi naa bàjẹ́ soju òkun, omi sì ń ṣẹ wọnu ọpọ julọ lara bébà naa. Gbogbo ẹrù naa ni a pese fun títà ni gbàǹjo, ati si iyalẹnu wa awa nikan ni a gbà lati san owó. Eyi mú ki o ṣeeṣe fun wa lati rà á ni pọ́ọ́kú-lowó-ẹ̀. A sá bébà naa gbẹ ninu oorun, ni titipa bayii mú ọpọ julọ ninu rẹ̀ padabọsipo ìwúlò, a sì gé e si abala-abala ti o yẹ fun ìwé-títẹ̀ wa lẹhin naa.
Bawo ni awa yoo ṣe lo bébà aláwọ̀ ilẹ̀ naa? Lọna ti o tọna, a ronu pe awọn onkawe ìwé-àwòrẹ́rìn-ín yoo sì gbadun awọn ìwé-àwòrẹ́rìn-ín wọn lori bébà aláwọ̀. Nipa bayii, a lo bébà funfun ti a ti yà sọtọ fun awọn ìwé-àwòrẹ́rìn-ín lati tẹ Ilé-Ìṣọ́nà ati awọn ohun-eelo Society miiran.
Ipa Pataki Ti Awọn Obinrin
Ni awọn ọdun ogun, ọpọ awọn Kristian obinrin ni Australia kọ́ nipa iṣẹ ìwé dídì. Ni ọ̀sán ìgbà ẹ̀rùn gbigbona bi ajere kan, diẹ ninu wọn ń dá ṣiṣẹ ninu ibi ìgbọ́kọ̀sí kekere kan ti a ti háyà ni opopona ọwọ́ ẹhin kan ni agbegbe Sydney. Fun ète aabo, wọn ti gbogbo ferese ati ilẹkun pa. Ìkòkò àtè ń mú èéfín gbigbona, ti ń rùn jade, ooru naa sì fẹrẹẹ má ṣee farada. Nitori naa wọn bọ́rasílẹ̀ ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn.
Lojiji, ẹnikan kan ilẹkun. Awọn Kristian arabinrin naa sọrọ soke ni bibeere ẹni ti ó wà nibẹ, oṣiṣẹ olóyè iṣẹ ijọba kan sì dahun. Ó wá lati ẹ̀ka ti ó ni agbara ìgbà ogun lati dari awọn eniyan si agbegbe eyikeyii ti a bá ti nilo iṣẹ́. Awọn arabinrin naa fesipada ketekete pe awọn kò lè jẹ́ ki o wọle nisinsinyi niwọn bi awọn ti ń fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ awọn ṣiṣẹ nitori oru.
Oṣiṣẹ olóyè naa dakẹ sii fun ìgbà diẹ; lẹhin naa ó sọrọ soke pe oun ni adehun miiran ni agbegbe naa. Ó sọ pe oun yoo pada wá ni ọjọ keji lati ṣe ibẹwo oun. Lọgan ni awọn Kristian obinrin wọnyi késí wa lori tẹlifoonu, a sì fi ọkọ̀-ẹrù kan ranṣẹ ni alẹ́ ọjọ yẹn lati kó gbogbo ìwé fun dídì ti wọn ń ṣiṣẹ lé lori, ni kíkó wọn lọ si apá ibomiran.
Ọpọ julọ ninu awọn wọnni ti wọn ń lọwọ ninu ìwé-títẹ̀ wa lábẹ́lẹ̀ kò ní iriri iṣẹ ìwé-títẹ̀ ṣaaju, nitori naa ohun ti a ṣaṣepari rẹ̀ kò fi iyemeji kankan silẹ ninu ọkàn mi pe ẹmi Jehofa pese iranlọwọ ati idari ti a nilo. Anfaani ńláǹlà kan ni o jẹ́ fun emi ati aya mi, Lucy, ẹni ti o ṣiṣẹ ni ile-iṣẹ ìwé dídì, lati jẹ́ apakan gbogbo rẹ̀.
Bawo ni a ṣe dari iṣẹ wa ni awọn akoko apinnilẹ́mìí wọnni? Alaboojuto ẹ̀ka ti ń ṣiṣẹ fun ìgbà kukuru ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti gba àṣẹ ikalọwọko lati ọ̀dọ̀ ijọba, ti ń sọ fun un lati gbé ninu ilu kan ti o wà ni nǹkan bi 60 ibusọ (100 kilomita) lẹhin-ode Sydney. Àṣẹ naa kà á léèwọ̀ fun un lati maṣe jade lọ ni iwọn ibusọ marun-un (kilomita mẹjọ) siha ibikibi laaarin ilu naa. Epo mọto ni a ń bẹ́ ni iwọn galọọnu kan fun ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ kan loṣu kan. Ṣugbọn awọn arakunrin humọ ọgbọ́n ohun kan ti a mọ̀ si ohun-eelo amáfẹ́fẹ́ jade—agolo olórubu kan ti o wọ̀n tó nǹkan bi ilaji tọọnu, ti a gbé si ẹhin ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ naa. Èédú ni a ń jó ninu eyi, ti ń mú afẹfẹ carbon monoxide jade gẹgẹ bi epo. Ni awọn òru melookan lọsọọsẹ, emi ati awọn arakunrin ti wọn mọ ẹru-iṣẹ niṣẹ miiran ń rinrin-ajo nipasẹ ọ̀nà yii lati pade alaboojuto naa ni oju itọ́-odò gbigbẹ kan ti o sunmọ ilu ìgbèkùn rẹ̀. Nipa bayii, a lè jiroro ọpọ ọ̀ràn ki a tó maa dáná si ohun-eelo ti ń mú afẹfẹ jade naa lẹẹkan sii ki a sì wakọ pada lọ si Sydney ni wakati kutukutu owurọ.
Nikẹhin, ifofinde lori awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá si iwaju Ile-Ẹjọ Giga ti Australia. Adajọ pe ifofinde naa ni “alaidurogbẹjọ, akùgìrì-gbégbèésẹ̀, ati atẹniloriba” ó sì dáre fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa patapata kuro ninu igbokegbodo iṣọtẹ eyikeyii. Gbogbo Ile-Ẹjọ Giga naa ti ipinnu yii lẹhin, debi pe o ṣeeṣe fun wa lati wá soke ilẹ lati maa bá awọn igbokegbodo Ijọba wa ti o bá ofin mu lọ.
Awọn Iṣẹ-Ayanfunni ati Ibukun Siwaju Sii
Lẹhin ogun naa ọpọlọpọ ti wọn ti ṣiṣẹ nibi iṣẹ ìwé-títẹ̀ abẹ́lẹ̀ wa ko wọnu iṣẹ-ojiṣẹ aṣaaju-ọna. Diẹ ninu wọn lọ si Watchtower Bible School of Gilead ni New York lẹhin naa. Emi ati Lucy pẹlu ní gongo yẹn lọkan, ṣugbọn a bí ọmọbinrin kan nigba naa, mo sì pinnu lẹhin naa lati pada lọ sẹnu òwò ìwé-títẹ̀. A gbadura pe ki Jehofa ràn wá lọwọ nigba gbogbo lati fi ire Ijọba naa si ipo kìn-ín-ní, ó sì ti ṣe bẹẹ. Mo ń lọwọ ninu iṣẹ-ayanfunni ti iṣẹ-ojiṣẹ miiran ni ọ̀nà ti o tẹlee yii.
Mo gba ikesini ori tẹlifoonu kan lati ọ̀dọ̀ Lloyd Barry, ẹni ti ń ṣiṣẹsin nisinsinyi gẹgẹ bi mẹmba Ẹgbẹ́ Oluṣakoso ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni Brooklyn, New York. Ni akoko yẹn ó jẹ́ alaboojuto arinrin-ajo ni Sydney. O beere bi mo bá mọ̀ nipa deeti apejọ wa ti ń bọ̀. Nigba ti mo fesipada pe mo mọ̀, ó sọ pe: “A fẹ́ ki o bojuto iṣeto ounjẹ.”
Ọ̀rọ̀ naa yà mi lẹnu fun ìgbà diẹ, mo sì sọ lọna àìdára-ẹni-lójú pe: “Ṣugbọn emi kò tíì ṣe ohunkohun ti o jọ bẹẹ rí ni igbesi-aye mi.”
“Ó dara, Arakunrin,” ni o fèsì lọna ti o fẹrẹẹ jẹ́ ṣeréṣeré, “akoko ti tó fun ọ lati kẹkọọ!” Mo sì kẹkọọ nitootọ, mo sì ń baa lọ lati ní anfaani bibojuto ipese ounjẹ, àní ni awọn apejọpọ ńlá paapaa, fun ohun ti o ju 40 ọdun lọ.
La awọn ọdun já, ile-iṣẹ òwò ìwé-títẹ̀ wa gbòòrò, eyi sì mú ki irin-ajo iṣẹ́-ajé melookan lọ si òkè-òkun pọndandan. Mo sábà maa ń ṣeto eyi bá awọn apejọpọ agbaye ti a ń ṣe ni New York City ati nibomiran ni United States mu. Eyi fun mi ni anfaani lati lo akoko pẹlu awọn wọnni ti wọn ń ṣabojuto oniruuru ẹ̀ka apejọpọ, ni pataki ipese ounjẹ. Nipa bayii, ni ile ni Australia, ó tubọ rọrun fun mi lati ṣiṣẹsin fun aini awọn apejọpọ wa.
Pẹlu awọn ọdun wa ti ń ga sii, emi ati Lucy maa ń ṣe kayeefi nigba miiran boya à bá ti ṣaṣeyọri ohun pupọ sii bi a bá ti bí wá ni ìgbà ti ó pẹ́ diẹ si akoko ti a bi wa. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, bi a ti bí emi ni 1914 ati oun ni 1916, a kà á si anfaani agbayanu lati rí i ti awọn asọtẹlẹ Bibeli di eyi ti ń ṣẹ ni ojú wa kòrókòró. A sì dupẹ lọwọ Jehofa fun ibukun ti a ní ninu bíbá ọpọlọpọ eniyan kẹkọọ ati ríràn wọn lọwọ lati mọ otitọ ati lati rí wọn ti wọn ń ṣiṣẹsin in gẹgẹ bi ojiṣẹ ti a ti baptisi. Adura wa ni pe ki a lè maa baa lọ lati ṣiṣẹsin in titilọ gbére, ni gbígbà titilae pe oun ni Oluṣakoso Ọba-Alaṣẹ ńlá ti agbaye.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ile-Iṣọ Na, March 15, 1979, oju-iwe 14 si 17.
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Idasilẹ ìwé-títẹ̀ ni Beteli Strathfield, 1929 si 1973
George Gibb ti o duro lẹgbẹẹ ọ̀kan lara awọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ti a gbé jade kuro ninu ile-iṣẹ ìtẹ̀wé gba ogiri ẹhinkunle kọja