Àwọn Okùnfà Ibi
ÀLÀYÉ Bibeli nípa ipa-iṣẹ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù nínú alámọ̀rí ènìyàn dáhùn àwọn ìbéèrè ṣíṣekókó tí a kì bá tí rí ìdáhùn si nípa ibi. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò gbólóhùn yìí láti inú ìwé-ìròyìn International Herald Tribune nípa ogun tí ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn ilẹ̀ Balkan: “Ọ̀wọ́ àwọn olùwádìí kan ti Àpapọ̀-Àwùjọ Ilẹ̀ Europe ti parí èrò pé [àwọn ṣójà] ti fipá bá àwọn obìnrin àti ọmọdébìnrin Musulumi tí wọ́n tó 20,000 lòpọ̀ . . . gẹ́gẹ́ bí apákan ìgbékalẹ̀ ìlànà-ètò ìpayà tí wọ́n wéwèé lẹ́sẹẹsẹ láti múniláyàpami, múnisoríkọ́, kí wọ́n sì fipá lé wọn kúrò ní ilé wọn.”
Àròkọ kan nínú ìwé-ìròyìn Time tiraka láti ṣàlàyé ipò-ọ̀ràn náà: “Nígbà mìíràn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin lè fipá bánilòpọ̀ lójú ogun kí wọ́n baà lè tẹ́ àwọn àgbààgbà, àti àwọn ìjòyè-òṣìṣẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọ́n sì jèrè irú ìtẹ́wọ́gbà ti-baba-tọmọ kan. Ìfipá-báni-lòpọ̀ náà jẹ́ ẹ̀rí sí ìdúróṣinṣin aláìyẹhùn rẹ̀ fún ìyewèlè ẹ̀ka-ẹgbẹ́ ológun tirẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó múratán láti ṣe àwọn nǹkan tí ń múnigbọ̀nrìrì ka ẹ̀rí-ọkàn tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan sí èyí tí kò ṣe pàtàkì kí ó baà lè faramọ́ àwọn ète tí àwùjọ náà kìí fi bánidọ́rẹ̀ẹ́. Ọkùnrin kan ń fìdí ìtẹríba rẹ̀ múlẹ̀ nípa ṣíṣìkà.”
Ṣùgbọ́n èéṣe tí “àwọn ète tí àwùjọ náà kìí fi bánidọ́rẹ̀ẹ́” fi rẹlẹ̀níwà sí ẹ̀rí-ọkàn mẹ́ḿbà rẹ̀ kọ̀ọ̀kan? Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé olúkúlùkù ni ó fẹ́ láti máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀. Nítorí náà, èéṣe tí àwọn ènìyàn fi ń fipá bánilòpọ̀, dánilóró, tí wọ́n sì ń pa araawọn ní àkókò ogun? Ìdí pàtàkì kan ni pé àwọn agbo ẹ̀mí-èṣù wà lẹ́nu iṣẹ́.
Lílóye ipa-iṣẹ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù tún ń pèsè ojútùú sí ohun tí àwọn kan pè ní “ìṣòro àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn.” Ìṣòro náà jẹ́ bí wọ́n ṣe lè mú àwọn ìronúdábàá mẹ́ta báramu: (1) Ọlọrun jẹ́ alágbára gbogbo; (2) Ọlọrun jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ó sì dára; àti (3) àwọn nǹkan bíbanilẹ́rù ń ṣẹlẹ̀. Àwọn kan lérò pé ó ṣeéṣe láti mú méjì èyíkéyìí nínú àwọn ìrònúdábàá yìí báramu, ṣùgbọ́n mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò ṣeé mú báramu láé. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnraarẹ̀ fúnni ní ìdáhùn náà, ìdáhùn náà sì wémọ́ àwọn ẹ̀mí àìrí, àwọn okùnfà ibi.
Ọlọ̀tẹ̀ Àkọ́kọ́
Bibeli sọ fún wa pé Ọlọrun fúnraarẹ̀ jẹ́ ẹ̀mí. (Johannu 4:24) Nígbà tí ó yá ó di Ẹlẹ́dàá àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn, àwọn angẹli ọmọkùnrin. Danieli ìránṣẹ́ Ọlọrun rí ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbàárùn-ún àwọn angẹli nínú ìran. Gbogbo àwọn ẹni ẹ̀mí tí Jehofa dá jẹ́ olódodo wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́-inú rẹ̀.—Danieli 7:10; Heberu 1:7.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ọlọrun “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,” àwọn angẹli ọmọkùnrin Ọlọrun wọ̀nyí “jùmọ̀ kọrin pọ̀” wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí “hó ìhó ayọ̀.” (Jobu 38:4-7) Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú wọn mú ìfẹ́-ọkàn kan dàgbà fún araarẹ̀ láti já ìjọsìn tí ó fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ jẹ́ ti Ẹlẹ́dàá gbà. Nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Ọlọrun, angẹli yìí sọ araarẹ̀ di satani (tí ó túmọ̀sí “alátakò”) àti eṣu (tí ó túmọ̀sí “abanijẹ́”).—Fiwé Esekieli 28:13-15.
Ní lílo ejò kan ní Edeni láti bá obìnrin àkọ́kọ́, Efa sọ̀rọ̀, Satani yí i léròpadà láti ṣàìgbọ́ràn sí àṣẹ tí ó ṣe tààràtà tí Ọlọrun fifún wọn láti máṣe jẹ nínú èso igi pàtó kan nínú ọgbà náà. Lẹ́yìn ìgbà náà, ọkọ rẹ̀ darapọ̀ mọ́ ọn. Nípa báyìí, tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ darapọ̀ mọ́ angẹli náà nínú ìṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Jehofa.—Genesisi 2:17; 3:1-6.
Nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní Edeni lè dàbí ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ṣíṣetààràtà kan níti ìgbọràn, àwọn àríyànjiyàn ṣíṣepàtàkì méjì níti ọ̀nà-ìwàhíhù ni Satani gbé dìde níbẹ̀. Èkínní, Satani ṣe ọpẹ́-aláyé níti yálà agbára ìṣàkóso Jehofa lórí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ni ó ń lò lọ́nà òdodo àti fún ire wọn dídára jùlọ. Bóyá àwọn ènìyàn lè ṣe iṣẹ́ sísàn jù kan níti ṣíṣàkóso araawọn. Èkejì, Satani béèrè yálà àwọn ẹ̀dá olóye èyíkéyìí yóò lè dúró bí olùṣòtítọ́ àti adúróṣinṣin níhà ọ̀dọ̀ Ọlọrun nígbà tí ìgbọràn bá dàbí èyí tí kò mú àwọn àǹfààní ti ara kankan wá.a
Òye ṣíṣe kedere nípa àwọn àríyànjiyàn náà tí a gbé dìde ní Edeni, papọ̀ pẹ̀lú mímọ àwọn ànímọ́-ìwà Jehofa, ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ojútùú náà sí “ìṣòro àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn,” ìyẹn ni láti mú wíwà ibi báramu pẹ̀lú àwọn ànímọ́-ìwà Ọlọrun ti agbára àti ìfẹ́. Nígbà tí ó jẹ́ òtítọ́ pé Jehofa ní agbára tí kò ní ààlà tí ó sì jẹ́ pé òun gan-an ni ògidì àpẹẹrẹ ìfẹ́, òun tún jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti onídàájọ́ òdodo. Ó ń lo àwọn ànímọ́-ìwà mẹ́rin wọ̀nyí pẹ̀lú ìwàdéédéé pípé-pérépéré. Nípa báyìí, òun kò lo agbára rẹ̀ tí kò ṣeé takò láti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà run lójú-ẹ̀sẹ̀. Ìyẹn ìbá ti jẹ́ ohun tí ó bá ìdájọ́-òdodo mu ṣùgbọ́n tí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti ọlọ́gbọ́n tàbí onífẹ̀ẹ́. Síwájú síi, òun kò wulẹ̀ dáríjì kí ó sì gbàgbé, ìgbésẹ̀ kan tí àwọn kan ti lè nímọ̀lára pé ìbá ti jẹ́ yíyàn tí ó fi ìfẹ́ hàn. Láti ṣe ìyẹn kì bá tí fi ọgbọ́n tàbí ìdájọ́-òdodo hàn.
Àkókò ni a nílò láti yanjú àwọn àríyànjiyàn náà tí Satani gbé dìde. Yóò gba àkókò láti fi ẹ̀rí hàn bóyá àwọn ènìyàn lè ṣàkóso araawọn lọ́nà yíyẹ láìní ọwọ́ Ọlọrun nínú. Nípa fífàyègba àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́ta náà láti máa wàláàyè nìṣó, Jehofa tún mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn ẹ̀dá láti ṣàjọpín nínú fífi ìjẹ́wọ́ Satani hàn gẹ́gẹ́ bí èké nípa fífi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Ọlọrun lábẹ́ àwọn àyíká-ipò tí ó ṣòro.b
Jehofa ti sọ ní kedere fún Adamu àti Efa pé bí wọ́n bá jẹ nínú èso tí a kàléèwọ̀ náà, wọn yóò kú. Wọ́n sì kú nítòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Satani ti mú un dá Efa lójú pé òun kì yóò kú. Satani pẹ̀lú wà lábẹ́ ìdájọ́-ìjìyà ikú; nísinsìnyí ná ó ń báa lọ láti ṣi ìran aráyé lọ́nà. Níti tòótọ́, Bibeli sọ pé: “Gbogbo ayé ni ó wà ní agbára ẹni búburú nì.”—1 Johannu 5:19; Genesisi 2:16, 17; 3:4; 5:5.
Àwọn Angẹli Mìíràn Ṣọ̀tẹ̀
Ní kété lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé ní Edeni, àwọn angẹli mìíràn darapọ̀ nínú ìṣọ̀tẹ̀ náà lòdìsí ipò-ọba-aláṣẹ Jehofa. Bibeli ṣàlàyé pé: “Ó sì ṣe nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síí rẹ̀ lórí ilẹ̀, tí a sì bí ọmọbìnrin fún wọn, ni àwọn ọmọ Ọlọrun rí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn pé, wọ́n lẹ́wà; wọ́n fẹ́ aya fún araawọn nínú gbogbo àwọn tí wọ́n yàn.” Ní èdè mìíràn, àwọn angẹli wọ̀nyí “fi ipò wọn [ní ọ̀run] sílẹ̀” wọ́n sì wá sí ilẹ̀-ayé, wọ́n gbé ara ènìyàn wọ̀, wọ́n sì jadùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara pẹ̀lú àwọn obìnrin.—Genesisi 6:1, 2; Juda 6.
Àkọsílẹ̀ náà ń báa lọ ní Genesisi 6:4: “Àwọn [Nefilimu, NW] wà ní ayé ní ọjọ́ wọnnì; àti lẹ́yìn èyíinì pẹ̀lú, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọrun wọlé tọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lọ, tí wọ́n sì bí ọmọ fún wọn, àwọn náà ni ó di akọni tí ó wà nígbàanì, àwọn ọkùnrin olókìkí.” Àwọn àdàmọ̀dì ọmọkùnrin tí àwọn obìnrin bí tí àwọn angẹli sì jẹ́ baba fún wọ̀nyí lágbára lọ́nà tí ó ṣàjèjì, ‘àwọn akọni.’ Wọ́n jẹ́ àwọn ọkùnrin oníwà-ipá, tàbí Nephi·limʹ, ọ̀rọ̀ Heberu kan tí ó túmọ̀sí “àwọn wọnnì tí ń bi àwọn ẹlòmíràn ṣubú.”
Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni a sọ̀rọ̀ nípa wọn lẹ́yìn náà nínú àwọn àròsọ-àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn àwùjọ ọ̀làjú ìgbàanì. Fún àpẹẹrẹ, ewì-onítàn-akọni ti Babiloni tí ó ti pé 4,000 ọdún ṣàpèjúwe ìkóninífà láti ọwọ́ Gilgamesh tí ó ju ẹ̀dá ènìyàn lọ, ṣènìyàn-ṣọlọ́run kan tí ó lágbára, tí ó sì níwà-ipá ẹni tí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ kò fi wúńdía kankan [sílẹ̀] fún olùfẹ́ rẹ̀.” Àpẹẹrẹ mìíràn, láti inú àròsọ̀-àtọwọ́dọ́wọ́ Griki, ni ti Hercules (tàbí Heracles) tí ó ju ẹ̀dá ènìyàn lọ. A bí i fún Alcmene, tí ó jẹ́ ènìyàn kan, ọlọrun náà Zeus sì ni baba rẹ̀, Hercules mú ọ̀nà ọ̀wọ́ àwọn ìrìn-àjò oníwà-ipá pọ̀n lẹ́yìn tí ó ti pa aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ìrufùfù aṣiwèrè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ìtàn àronúsọ bẹ́ẹ̀ ni a ti fèrúyípo gidigidi bí a ti ń ròyìn wọn láti ìran dé ìran, wọ́n bá ohun tí Bibeli sọ nípa àwọn Nefilimu àti àwọn angẹli ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n jẹ́ baba fún wọn mu.
Nítorí agbára ìdarí àwọn angẹli búburú àti àwọn ọmọkùnrin wọn tí wọ́n ju ẹ̀dá ènìyàn lọ, ilẹ̀-ayé kún fún ìwà-ipá tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Jehofa fi pinnu láti fi ìkún-omi ńlá pa ayé run. Àwọn Nefilimu náà ṣègbé papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn aláìwà-bí-Ọlọ́run; kìkì àwọn ènìyàn tí wọ́n làájá ni Noa olódodo àti ìdílé rẹ̀.—Genesisi 6:11; 7:23.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn angẹli búburú náà kò kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bọ́ ara ènìyàn tí wọ́n gbéwọ̀ sílẹ̀ wọ́n sì padà sí ilẹ̀-ọba ẹ̀mí. Nítorí àìgbọ́ràn wọn, a kò tún gbà wọ́n padà sínú ìdílé Ọlọrun ti àwọn angẹli olódodo mọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni a kò yọ̀ọ̀da fún wọn láti tún gbé ara ènìyàn wọ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ Noa. Síbẹ̀, wọ́n ń lo agbára ìdarí tí ń panirun nínú àwọn àlámọ̀rí ìran-aráyé nìṣó, lábẹ́ ọlá-àṣẹ “olórí àwọn ẹ̀mí-èṣù,” Satani Eṣu.—Matteu 9:34; 2 Peteru 2:4; Juda 6.
Àwọn Ọ̀tá Aráyé
Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù tí sábà máa ń jẹ́ òṣìkàpànìyàn àti oníkà. Ní onírúurú ọ̀nà, Satani gba àwọn ẹran-ọ̀sìn Jobu mọ́ ọn lọ́wọ́ ó sì pa ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pa àwọn ọmọ Jobu mẹ́wàá nípa mímú kí “ẹ̀fúùfù ńláǹlà” wo ilé tí wọ́n wà nínú rẹ̀ palẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, Satani kó ìyọnu bá Jobu nípa sísọ ọ́ ní “oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ lọ dé àtàrí rẹ̀.”—Jobu 1:7-19; 2:3, 7.
Àwọn ẹ̀mí-èṣù ń fi irú ìtẹ̀sí-ìfẹ́-inú kan-náà hàn. Ní ọjọ́ Jesu, wọ́n fi àǹfààní ọ̀rọ̀-sísọ àti ìríran du àwọn ènìyàn. Wọ́n mú kí ọkùnrin kan fi òkúta ya araarẹ̀ lára yánna-yànna. Wọ́n gbé ọmọdékùnrin kan ṣánlẹ̀ wọ́n sì “fi gìrì mú un lọ́nà lílenípá.”—Luku 9:42, NW; Matteu 9:32, 33; 12:22; Marku 5:5.
Àwọn ìròyìn káàkiri ayé fihàn pé Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù ṣì jẹ́ aláìfẹ́nifẹ́rere bí wọ́n ti rí láti ìgbà yìí wá. Wọ́n ń fi àmódi kọlu àwọn ènìyàn kan. Wọ́n fòòró àwọn ẹlòmíràn nípa ṣíṣàìjẹ́ kí wọ́n rí oorun sùn tàbí nípa mímú kí wọ́n lá àwọn àlá bíbanilẹ́rù tàbí nípa fífi ìbálòpọ̀ takọtabo ṣe wọ́n níkà. Síbẹ̀ wọ́n ti sọ àwọn mìíràn di asínwín, sún wọn láti pànìyàn, tàbí mú kí wọ́n fọwọ́ araawọn pa araawọn.
Báwo Ni A Ó ti Fàyègbà Wọ́n Pẹ́ Síi Tó?
Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a kì yóò fàyègbà títíláé. Pẹ̀lú ìdí rere, Jehofa ti yọ̀ọ̀da fún wọn láti wà títí di ọjọ́ wa, ṣùgbọ́n nísinsìnyí àkókò wọn kúrú. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ìgbésẹ̀ ṣíṣekókó kan ni a gbé láti pààlà sí àyíká ìgbòkègbodò wọn. Ìwé Ìfihàn ṣàlàyé pé: “Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mikaeli [Jesu Kristi tí a jí dìde náà] àti àwọn angẹli rẹ̀ bá dragoni náà [Satani] jagun; dragoni sì jagun àti àwọn angẹli rẹ̀. Wọn kò sì lè ṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ní ọ̀run. A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ní Eṣu, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ, a sì lé e jù sí ilẹ̀-ayé, a sì lé àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìfihàn 12:7-9.
Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àkọsílẹ̀ náà ń báa lọ pé: “Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.” Àwọn angẹli olódodo lè yọ̀ nítorí pé Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ kò sí ní ọ̀run mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé ń kọ́? Bibeli sọ pé: “Ègbé ni fún ayé àti fún òkun! nítorí Eṣu sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú ṣáá ni òun ní.”—Ìfihàn 12:12.
Nínú ìbínú wọn Satani àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pinnu láti ṣokùnfà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègbé bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó ṣáájú kí ìparun wọn tí ó súnmọ́lé tó dé. Ní ọ̀rúndún yìí, ogun àgbáyé méjì àti 150 àwọn ogun tí kò tó o ti jà láti ìgbà tí ogun àgbáyé kejì ti parí. Àwọn àpólà-ọ̀rọ̀ tí ń fi ìwà-ipá ìran yìí hàn ti wọnú ọ̀rọ̀-èdè wa: “ogun àfi-kòkòrò-àrùn jà,” “Ìparun-Deérú,” “àwọn pápá ìpanípakúpa,” “àwọn àgọ́ ìfipá-báni-lòpọ̀,” “àwọn gbẹ̀mígbẹ̀mí,” àti “bọ́m̀bù.” Ìròyìn ti kún àkúnya fún àwọn ìtàn nípa oògùn, ìṣìkàpànìyàn, jíju bọ́m̀bù, aláìsàn ọpọlọ tí ń jẹ̀nìyàn, ìpani nípakúpa, ìyàn, àti ìdálóró.
Ìhìnrere náà ni pé àwọn nǹkan wọ̀nyí wà fún ìgbà díẹ̀. Ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, Ọlọrun yóò gbégbèésẹ̀ lòdìsí Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi. Ní ṣíṣàpèjúwe ìran kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, aposteli Johannu sọ pé: “Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti ìṣíkà ọ̀gbun nì, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tíí ṣe Eṣu, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má baà tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé.”—Ìfihàn 20:1-3.
Lẹ́yìn ìyẹn, Eṣu àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a óò ‘tú sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,’ kí a tó wà pa wọ́n run títíláé. (Ìfihàn 20:3, 10) Ẹ wo àkókò àgbàyanu tí ìyẹn yóò jẹ́! Pẹ̀lú Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ tí wọ́n ti pòórá títíláé, Jehofa yóò “jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” Olúkúlùkù yóò sì “máa ṣe inúdídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—1 Korinti 15:28, NW; Orin Dafidi 37:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí ni a mú ṣe kedere lẹ́yìn náà nígbà tí Satani sọ nípa Jobu, ìránṣẹ́ Ọlọrun náà pé: “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsìnyí, kí o sì fi tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”—Jobu 2:4, 5.
b Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìjíròrò nípa ìdí tí Ọlọrun fi fàyègba ìwà-burúkú, wo ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ènìyàn nìkan ni ó ha ń fa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bí, tàbí agbára àìrí adámọ̀ràn-ibi kan ha pín nínú ẹ̀bí náà?
[Credit Line]
Àwọn kòtò epo rọ̀bì tí ń jó ní Kuwait, 1991: Chamussy/Sipa Press
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹ wo àkókò àgbàyanu tí yóò jẹ́ nígbà tí àwọn ẹ̀mí-èṣù kò bá fòòró aráyé mọ́!