Ṣọ́ọ̀ṣì kan Tí Ìyapa Wà—Ó Ha Lè Làájá Bí?
“GBOGBO àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ òtítọ́ Kristi tí ń gbanilà jẹ́ ara Ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ṣeéfojúrí náà. Àwọn ìyapa tí ń bẹ nínú Kristẹndọm—láàárín àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox ti Ìlà-Oòrùn àti ti Ìwọ̀-Oòrùn, àti láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-ún-ṣe—jẹ́ ìyapa láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì kanṣoṣo náà.” (Christians in Communion) Ojú tí òǹkọ̀wé kan fi wo Ìsìn Kristian nìyẹn—gẹ́gẹ́ bí ìdílé àwọn ìsìn kan tí a yànípá káàkiri ibi gbígbòòrò, tí gbogbo wọn ń jẹ́wọ́ irú ìgbàgbọ́ kan nínú Jesu Kristi.
Bí ó ti wù kí ó rí, ó jẹ́ ìdílé kan tí ìyapa wà, pẹ̀lú èrò-ìgbàgbọ́ àti ọ̀pá-ìdíwọ̀n ìhùwà tí ó forígbárí. Olùṣàkíyèsí kan sọ pé, “Ìsìn Kristian ti ọjọ́ wa . . . ní àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n rírẹlẹ̀ fún jíjẹ́ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì ju èyí tí ó wà fún wíwọ bọ́ọ̀sì.” Nígbà náà, báwo ni a ṣe níláti ṣàyẹ̀wò láti mọ ipò tẹ̀mí rẹ̀? Bíṣọ́ọ̀bù Katoliki náà Basil Butler parí èrò pé: “Ìsìn Kristian kan tí ìyapa wà ni àmódi ń ṣe níti gidi.” (The Church and Unity) Báwo ni àmódi náà ṣe bẹ̀rẹ̀? Ìrètí ha wà fún jíjèrè okun padà bí?
“Ọkùnrin Ìwà-Àìlófin”
Aposteli Paulu kìlọ̀ pé àìsí ìṣọ̀kan yóò gbèrú. Sí àwọn Kristian ní Tessalonika tí wọ́n ronú pé wíwàníhìn-ín Kristi ti súnmọ́lé, ó kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí ẹni kankan sún yín dẹ́ṣẹ̀ ní irú-ọ̀nà èyíkéyìí, nitori [ọjọ́ Jehofa] kì yoo dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà kọ́kọ́ dé tí a sì ṣí ọkùnrin ìwà-àìlófin payá, ọmọ ìparun.”—2 Tessalonika 2:3, NW.
“Ọkùnrin ìwà-àìlófin” yìí ni ó mú ìpẹ̀yìndà àti ìṣọ̀tẹ̀ wọ inú ìjọ Kristian. Ta ni òun jẹ́? Kìí ṣe ọkùnrin kanṣoṣo èyíkéyìí ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ́ àwùjọ àlùfáà Kristẹndọm. Ẹgbẹ́ yìí gbé araarẹ̀ sí ipò gíga lórí ìjọ apẹ̀yìndà náà ní kété lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Jesu, àti ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó ń kọ́ni ní àwọn ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn olórìṣà, bíi Mẹ́talọ́kan àti àìlèkú-ọkàn ènìyàn. (Iṣe 20:29, 30; 2 Peteru 2:1-3) Bíi kòkòrò àrùn kan tí ó lè ṣekúpani, ó kó àwọn èrò tí ẹ̀mí-èṣù mísí èyí tí yóò jálẹ̀ sí àìsí ìṣọ̀kan ran ìjọ Kristian aláfẹnujẹ́ láìṣeéyẹ̀sílẹ̀.—Galatia 5:7-10.
Àkóràn náà ti bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ aposteli Paulu. Ó kọ̀wé pé: “Lóòótọ́, ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-àìlófin yii ti wà lẹ́nu iṣẹ́ nísinsìnyí; ṣugbọn kìkì títí di ìgbà tí ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣèdíwọ́ nísinsìnyí gan-an bá kúrò lójú ọ̀nà.” (2 Tessalonika 2:7, NW) Àwọn aposteli ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣèdíwọ́ lòdìsí májèlé ìpẹ̀yìndà. Nígbà ti agbára ìdarí ìmúṣọ̀kan wọn di èyí tí a mú kúrò, ìpẹ̀yìndà tí kò ṣeédílọ́wọ́ gbèèràn bí egbò-kíkẹ̀.—1 Timoteu 4:1-3; 2 Timoteu 2:16-18.
Àwọn ìgbòkègbodò “ọkùnrin ìwà-àìlófin” yìí ń báa lọ láìdáwọ́dúró. Nínú ìròyìn ẹnu àìpẹ́ yìí kan lórí “ṣọ́ọ̀ṣì kan tí ń joró nínú ìbálòpọ̀ àti ẹ̀kọ́-ìsìn,” amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ bíṣọ́ọ̀bù kan ti Ṣọ́ọ̀ṣì England ni a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ tí ó ń ṣàròyé pé: “A kọ àwọn ìdámọ̀ràn tí ń késí àwọn àlùfáà láti máṣe fi ìgbòkègbodò ìbálòpọ̀ lẹ́yìn-òde ìgbéyàwó kẹ́ araawọn bàjẹ́ sílẹ̀. Àwọn tí ń bẹ́yà kan náà lòpọ̀ ni a fijoyè. Wọ́n ti sọ ire di ibi wọ́n sì ti sọ ibi di ire.”—The Sunday Times Magazine, London, November 22, 1992.
Àwọn Àlìkámà àti Èpò
Jesu Kristi fúnraarẹ̀ kọ́ni pé Ìsìn Kristian tòótọ́ yóò pòórá fún ìgbà díẹ̀. Ó sọ pé ìdásílẹ̀ ìjọ Kristian dàbí ọkùnrin kan tí ń fúnrúgbìn èso rere sínú oko rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Jesu wí pé, “ọ̀tá rẹ̀ wá, ó fún èpò sínú àlìkámà.” Nígbà tí àwọn ẹrú rẹ béèrè bóyá àwọn níláti gbìyànjú láti fa àwọn èpò náà tu, olóko náà wí pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́, nígbà tí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, kí ẹ̀yin kí ó má baà tu àlìkámà pẹ̀lú wọn.” Báwo ni ìdàpọ̀mọ́ra àlìkámà àti àwọn èpò yìí yóò ti máa báa lọ pẹ́ tó? Olóko náà sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì kí ó dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè.”—Matteu 13:25, 29, 30.
Títí di “ìgbà ìkórè,” tàbí ìgbà ìyàsọ́tọ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn “ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan,” àwọn Kristian ayédèrú ń dàgbà pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian tòótọ́. (Matteu 28:20) Satani Eṣu lo àwọn apẹ̀yìndà láti dá ìjọ Kristian ayédèrú tí ó díbàjẹ́ tí ìyapa sì wà sílẹ̀. (Matteu 13:36-39) Wọ́n mú Ìsìn Kristian atinilójú tí ó jẹ́ àdàmọ̀dì ti ojúlówó jáde. (2 Korinti 11:3, 13-15; Kolosse 2:8) Bí ṣọ́ọ̀ṣì náà ti ń pín sí kélekèle láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá, ó túbọ̀ ń ṣòro síi láti dá àwọn Kristian tòótọ́ mọ̀.
Àwọn Ìyapa Titun
Ìwé náà The Testing of the Churches—1932-1982 sọ pé ní àwọn àkókò òde-òní, “àwọn ìyapa titun ti farahàn, ní pàtàkì láàárín àjọ ìgbòkègbodò ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìímẹ́mìí, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ rẹ̀ tí ó gbékarí ìgbàgbọ́ àti ìrírí ti ara-ẹni.” Lọ́nà tí ń pàfiyèsí, àwọn kan rí àwọn àjọ ìgbòkègbodò àtúnbí, ti ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìímẹ́mìí náà gẹ́gẹ́ bí àmì ìmúpadà tẹ̀mí kan dípò kí ó jẹ́ ìyapa titun. Fún àpẹẹrẹ, Northern Ireland ní ìrírí irúfẹ́ ìsọjí bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọdún 1850. Wọ́n sì ní àwọn ìfojúsọ́nà ńláǹlà. Ìròyìn kan sọ nípa “ìrẹ́pọ̀ ẹgbẹ́ arákùnrin . . . láàárín àwọn òjíṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Presbyteria, àwọn ọmọlẹ́yìn Wesley, àti àjọ ìgbòkègbodò Adádúrólómìnira” ó sì sọ pé “lójoojúmọ́ ni a ń gbọ́ ìròyìn titun nípa àwọn ìran ojúran, oorun, ìran ìfihàn, àlá àti àwọn iṣẹ́ ìyanu.”—Religious Revivals.
Ọ̀pọ̀ rí àwọn ìfihàn amúnijígìrì wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọrun ń ṣiṣẹ́ láti mú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sọjí. Olùṣàkíyèsí kan sọ pé, “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọlọrun ní èrò ìtumọ̀ rẹ̀ tí ó ga jùlọ ni a ti mú sọjí ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí.” Bí ó ti wù kí ó rí, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a polongo ìsọjí yìí ní pàtàkì gẹ́gẹ́ bíi “sànmánì àkókò ológo tí kò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn ìsìn ẹkùn-ilẹ̀ Ulster,” òun àti àwọn ìsọjí mìíràn bíi tirẹ̀ kò tíì mú ìṣọ̀kan ìsìn wá láàárín àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́wọ́ àtúnbí tẹ̀mí.
Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò jiyàn pé àwọn wà ní ìṣọ̀kan lórí àwọn ọ̀ràn tí ó ṣe pàtàkì jùlọ. Ṣùgbọ́n èyí ni iyàn kan náà tí àwọn yòókù nínú Kristẹndọm ń lò, àwọn tí wọ́n wí àwíjàre pé “ohun tí ń so àwọn Kristian pọ̀ ṣọ̀kan ti ṣe pàtàkì fíìfíì ní báyìí ju àwọn ọ̀ràn tí ó ṣì ń fa ìyapa láàárín wọn.” (The Church and Unity) Kristẹndọm jẹ́wọ́ pé: “Ìrìbọmi wa nínú Kristi ni gbòǹgbò ìṣọ̀kan pẹ̀lú araawa àti pẹ̀lú gbogbo àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa lórí àwọn ọ̀ràn tí ó ṣe pàtàkì.” (Christians in Communion) Bí ó ti wù kí ó rí, láti sọ pé àwọn ìyapa náà kò ṣe pàtàkì nítorí ìgbàgbọ́ àjùmọ̀ní nínú Jesu, dàbí sísọ pé àrùn jẹjẹrẹ kò léwu níwọ̀n ìgbà tí ọkàn-àyà rẹ bá ti lágbára.
Òtítọ́ gidi náà ni pé àwọn àjọ ìgbòkègbodò ìsìn òde-òní ti pakún ìdàrúdàpọ̀ náà wọ́n sì mú rúgúdù tẹ̀mí wá bí àwọn olùkọ́ tí ń yíniléròpadà ti ń kó àwọn ọmọlẹ́yìn jọ fún araawọn. Jim Jones àti David Koresh jẹ́ àwọn àpẹẹrẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àwọn aṣáájú tẹ̀mí tí wọ́n ṣi ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà. (Matteu 15:14) Òjíṣẹ́ Baptist kan jẹ́ mẹ́ḿbà amúpò iwájú nínú ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ Ku Klux Klan. Ó so ìgbétáásì rẹ̀ fún ìlọ́lájù àwọn aláwọ̀ funfun pọ̀ mọ́ ìsọjí ìsìn kan ó sì sọ pé àwọn wọnnì tí wọ́n bá kópa nínú rẹ̀ ni a óò “fún ní okun ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá, fún ní ìgboyà Ẹni náà tí ó kú ní Kalfari [Jesu Kristi].”
Ti àwọn iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ agbára, àti àwọn iṣẹ́ àmì tí wọ́n tànmọ́ọ̀ pé àwọn ń ṣe ní orúkọ Jesu ńkọ́? Rántí ìkìlọ̀ lílágbára ti Jesu Kristi pé, kìí ṣe àwọn wọnnì tí wọ́n wulẹ̀ ń wí pé “Oluwa, Oluwa” ni wọn yóò jèrè ìtẹ́wọ́gbà òun, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ‘àwọn wọnnì tí wọ́n bá ṣe ìfẹ́-inú ti Baba òun tí ń bẹ ní ọ̀run.’ Ọ̀pọ̀ lónìí kò tilẹ̀ mọ orúkọ Baba rẹ̀, Jehofa. Jesu kìlọ̀ nípa àwọn wọnnì tí wọn yóò ‘lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde ní orúkọ òun, tí wọn yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ní orúkọ òun’ síbẹ̀ tí wọn yóò jẹ́ “oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.”—Matteu 7:21-23.
“Ẹ ti Inú Rẹ̀ Jáde, Ẹ̀yin Ènìyàn Mi”
Kí ni ìrètí ìmúláradá tí ó wà fún Kristẹndọm tí ń ṣàìsàn? Ó burú jáì. Nígbà náà, ó ha yẹ kí a kúkú tẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn bíṣọ́ọ̀bù Katoliki náà Butler, láti “darapọ̀ mọ́ [ṣọ́ọ̀ṣì] láìsí agbaja àti láti yọ̀ǹda ìrànlọ́wọ́ wa fún ‘ìsọdimímọ́’ rẹ̀ tí ń báa nìṣó láti àárín àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ wá bí”? Rárá! Kristẹndọm oníyapa tí ó tún jẹ́ okùnfà ìyapa kì yóò làájá. (Marku 3:24, 25) Òun jẹ́ apákan ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé tí a pè ní Babiloni Ńlá. (Ìfihàn 18:2, 3) Ètò ìgbékalẹ̀ ìsìn ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀ yìí dojúkọ ìparun tí ó súnmọ́lé láti ọwọ́ Ọlọrun.
Bibeli kò dámọ̀ràn pé kí àwọn ojúlówó Kristian dúró sáàárín ètò-àjọ ìsìn tí ó ti díbàjẹ́ yìí kí wọ́n sì gbìyànjú láti tún un ṣe láti inú wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ẹ má baà ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ má baà sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga àní dé ọ̀run, Ọlọrun sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.”—Ìfihàn 18:4, 5.
“Ti inú rẹ̀ jáde” lọ síbo? Rántí, Jesu ṣèlérí pé ní ìgbà ìkórè, àwọn Kristian tòótọ́ ni a óò tún kójọ papọ̀ sínú ìṣọ̀kan kárí-ayé. Wòlíì Mika tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú ìtúnkójọpọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ní ìṣọ̀kan ni èmi óò kó wọn jọpọ̀, gẹ́gẹ́ bí agbo ẹran nínú ọgbà agbo ẹran.” (Mika 2:12, NW) Èyí ha ti ṣẹlẹ̀ bí?
Bẹ́ẹ̀ni! àwọn ojúlówó Kristian ni a ti ń kójọpọ̀ nísinsìnyí sínú ẹgbẹ́ àwọn ará tí a sopọ̀ṣọ̀kan kárí-ayé. Ta ni wọn? Àwọn ni ìjọ Kristian ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n ń fi ìsopọ̀ṣọ̀kan polongo ìhìnrere nípa Ìjọba Ọlọrun ní àwọn ilẹ̀ 231. Wọ́n ti kọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́ okùnfà ìyapa nínú Kristẹndọm sílẹ̀ tí wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti jọ́sìn Ọlọrun ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Johannu 8:31, 32; 17:17.
A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà késí ọ láti bá wọn sọ̀rọ̀. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ síi nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, jọ̀wọ́ kàn sí wọn ní àdúgbò tàbí nípasẹ̀ àdírẹ́sì tí ó bá a mu ní ojú-ìwé 2 ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Ọlọrun sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀”