Ìwọ Ha Ń Dáríjini Bí Jehofa Ti Ń Ṣe Bí?
“Nitori bí ẹ̀yin bá dárí aṣemáṣe awọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yoo dáríjì yín pẹlu; nígbà tí ó jẹ́ pé bí ẹ kò bá dárí aṣemáṣe awọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yoo dárí awọn aṣemáṣe yín jì yín.”—MATTEU 6:14, 15, NW.
1, 2. Irú Ọlọrun wo ni a ń fẹ́, èésìtiṣe?
“OLUWA ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra àtibínú, ó sì pọ̀ ní àánú. Òun kì í bániwí nígbà gbogbo: bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láéláé. Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni kì í san fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa. Nítorí pé bí ọ̀run ti ga sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àánú rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ìrékọjá wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ wa. Bí baba ti í ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni Oluwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.”—Orin Dafidi 103:8-14.
2 Níwọ̀n bí a ti lóyún wa nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí a sì tọ́ wa dàgbà nínú àṣìṣe, tí àìpé tí a ti jogún sì máa ń fẹ́ láti darí wa gẹ́gẹ́ bí ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀, níti gidi ni a nílò Ọlọrun kan tí ‘ń rántí pé erùpẹ̀ ni wá.’ Ọ̀ọ́dúnrún ọdún lẹ́yìn tí Dafidi ṣàpèjúwe Jehofa lọ́nà fífanimọ́ra nínú Psalmu kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún, òǹkọ̀wé Bibeli mìíràn, Mika, gbé Ọlọrun yìí kan náà ga ní ọ̀nà tí ó rí bákan náà gan-an fún bí ó ṣe ń fi tàánú-tàánú dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnìkan dá nígbà kan jì í pé: “Ọlọrun wo ni à bá fi wé ọ: tí ń dárí àṣìṣe jì, tí ń forí ìwà-ipá jini, tí kìí pa ìbínú mọ́ títí láé ṣùgbọ́n tí ó ní inúdídùn sí fífi àánú hàn? Lẹ́ẹ̀kan síi ṣàánú wa, fi ẹsẹ̀ tẹ àṣìṣe wa mọ́lẹ̀, kí o sì kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa dà sísàlẹ̀ òkun.”—Mika 7:18, 19, The Jerusalem Bible.
3. Kí ni ó túmọ̀sí láti dáríjini?
3 Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Griki, ọ̀rọ̀ náà fún “dáríjì” túmọ̀sí láti “gbàgbé.” Ṣàkíyèsí pé Dafidi àti Mika, tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lókè yìí, fi àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin, alápèjúwe gbé ìtumọ̀ kan náà jáde. Láti lè lóye ní kíkún bí ìdáríjì Jehofa ṣe ga lọ́lá tó, ẹ jẹ́ kí a gbé díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ yẹ̀wò. Èyí àkọ́kọ́ fihàn pé a lè yí ọkàn Jehofa padà látorí ìparun sí dídáríjini.
Mose Ṣìpẹ̀ —Jehofa Tẹ́tísílẹ̀
4. Lẹ́yìn àwọn ìṣàṣefihàn agbára Jehofa wo ni àwọn ọmọ Israeli ṣì ń bẹ̀rù láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
4 Jehofa mú orílẹ̀-èdè Israeli jáde kúrò ní ilẹ̀ Egipti láìséwu láti wọ ilẹ̀ náà tí òun ti ṣèlérí fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀-ìbílẹ̀ kan, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti tẹ̀síwájú, ní bíbẹ̀rù àwọn ọkùnrin lásán-làsàn tí ń bẹ ni Kenaani. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rí bí Jehofa ṣe gbà wọ́n là kúrò ní Egipti nípasẹ̀ ìyọnu runlé-rùnnà mẹ́wàá, bí ó ṣe ṣí ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀ láti la Òkun Pupa já, bí ó ṣe pa àwọn ọmọ ogun Egipti tí wọ́n gbìyànjú láti lépa wọn run, bí ó ṣe fi májẹ̀mú Òfin lọ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn ní Òkè Sinai èyí tí ó sọ́ wọn di orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ ti Jehofa, àti bí ó ṣe fi tìyanu-tìyanu rọ̀jò mana fún wọn lójoojúmọ́ láti ọ̀run láti gbé ẹ̀mí wọn ró, wọ́n bẹ̀rù láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà nítorí àwọn òmìrán ará Kenaani kan!—Numeri 14:1-4.
5. Báwo ni àwọn amí méjì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ ṣe ki àwọn ọmọ Israeli láyà?
5 Ìdààmú mú kí Mose àti Aaroni dojú wọn bolẹ̀. Joṣua àti Kalebu, àwọn amí olùṣòtítọ́ méjì, gbìyànjú láti ki àwọn ọmọ Israeli láyà pé: ‘Ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin. Ẹ máṣe bẹ̀rù àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; OLUWA sì wà pẹ̀lú wa.’ Kàkà kí irú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wú wọn lórí, àwọn ọlọ̀tẹ̀, tí jìnnìjìnnì ti dàbò náà gbìyànjú láti sọ Joṣua àti Kalebu ní òkúta.—Numeri 14:5-10.
6, 7. (a) Kí ni ohun ti Jehofa pinnu láti ṣe nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ranrí pé àwọn kò ní wọ Ilẹ̀ Ìlérí mọ́? (b) Èéṣe tí Mose fi tako ìdájọ́ Jehofa lórí àwọn ọmọ Israeli, kí ni ó sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
6 Ìbínú Jehofa ru! “OLUWA sì wí fún Mose pé, Àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi pẹ́ tó? yóò sì ti pẹ́ tó ti wọn ó ṣe aláìgbà mí gbọ́, ní gbogbo iṣẹ́-àmì ti mo ṣe láàárín wọn? Èmi óò fi àjàkálẹ̀ àrùn kọlù wọ́n, èmi óò sì gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi óò sì sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá, àti alágbára jù wọ́n lọ. Mose sì wí fún OLUWA pé, Ṣùgbọ́n àwọn ará Egipti yóò gbọ́; nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn yìí jáde láti inú wọn wá; wọn ó sì wí fún àwọn ará ilẹ̀ yìí: . . . Ǹjẹ́ bí ìwọ bá pa gbogbo àwọn ènìyàn yìí bí ẹnìkan, nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gbọ́ òkìkí rẹ̀ yóò wí pé, Nítorí tí OLUWA kò lè mú àwọn ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí ó ti fi búra fún wọn, nítorí náà ni ó ṣe pa wọ́n ní aginjù.”—Numeri 14:11-16.
7 Mose bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, nítorí orúkọ Jehofa pé: “Èmi bẹ̀ ọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì, gẹ́gẹ́ bíi títóbi àánú rẹ, àti bí ìwọ ti dáríji àwọn ènìyàn yìí, láti Egipti títí di ìsinsìnyí. OLUWA sì wí pé: Èmi ti dáríjì gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.”—Numeri 14:19, 20.
Ìbọ̀rìṣà Manasse àti Panṣágà Dafidi
8. Irú àkọsílẹ̀ wo ni Manasse Ọba Judah ní?
8 Àpẹẹrẹ títayọlọ́lá ti ìdáríjì Jehofa ni ti ọ̀ràn Manasse, ọmọkùnrin Hesekiah Ọba rere. Ọmọ ọdún 12 ni Manasse nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ní Jerusalemu. Ó kọ́ àwọn ibi gíga, ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó ṣe àwọn ọwọ̀n mímọ́-ọlọ́wọ̀, ó foríbalẹ̀ fún àwọn ogun ọ̀run, ó ṣe àlùpàyídà àti iṣẹ́-oṣó, ó bẹ́mìílò ó sì ń woṣẹ́, ó gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀ nínú tẹmpili Jehofa, ó sì mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ la iná kọjá ní Àfonífojì Hinnomu. “Ó ṣe búburú púpọ̀ ní ojú Oluwa” tí ó sì “mú kí Judah àti àwọn tí ń gbé Jerusalemu kí ó yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn ẹni tí Oluwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israeli.”—2 Kronika 33:1-9.
9. Báwo ni ojú Jehofa ṣe rọ̀ sí Manasse, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
9 Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jehofa mú kí àwọn Assiria gbógunti Judah, ọwọ́ wọn tẹ Manasse wọ́n sì mú un lọ sí Babiloni. “Nígbà tí ó sì wà nínú wàhálà, ó bẹ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ó sì rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, o sì gbàdúrà sí i: Ọlọrun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì tún mú un padà wá sí Jerusalemu sínú ìjọba rẹ̀.” (2 Kronika 33:11-13) Nígbà náà ní Manasse palẹ̀ gbogbo ọlọrun àjèjì mọ́, àwọn òrìṣà, àti pẹpẹ ó sì mú kí a kó wọn dà ṣẹ́yìn odi ìlú-ńlá náà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí Jehofa ó sì mú kí Judah bẹ̀rẹ̀ síi ṣiṣẹ́sin Ọlọrun tòótọ́ náà. Èyí jẹ́ àṣefihàn gígadabú nípa ìmúratán Jehofa láti dáríjini nígbà tí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, àdúrà, àti ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe bá so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà!—2 Kronika 33:15, 16.
10. Báwo ni Dafidi ṣe gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú aya Uria mọ́lẹ̀?
10 A mọ ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí Ọba Dafidi dá pẹ̀lú aya Uria ará Hitti bí ẹni-mowó. Kìí ṣe kìkì pé ó bá a ṣe panṣágà nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún hùmọ̀ ọgbọ́n féfé ti onísapá májàáyé-ó-gbọ́ nígbà tí obìnrin náà lóyún. Ọba náà fún Uria ní àyè ìsinmi kúrò lójú ogun, ní ríretí pé kí ó wọlé rẹ̀ lọ kí ó sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀. Ṣùgbọ́n, nítorí ọ̀wọ̀ tí ó ní fún àwọn ṣọ́jà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń bẹ́ lójú ogun, Uria pẹ́kọrọ. Nígbà náà ni Dafidi késí i láti wá jẹun tí ó sì rọ ọ́ lọ́tí yó, síbẹ̀ Uria kò wọlé tọ aya rẹ̀ lọ. Nígbà náà ni Dafidi ránṣẹ́ sí ọ̀gágun rẹ̀ láti fi Uria sí ibi tí ọwọ́ ìjà ti gbóná janjan, kí wọ́n baà lè pa Uria, bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí.—2 Samueli 11:2-25.
11. Báwo ni a ṣe mú kí Dafidi ronúpìwàdà lórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, síbẹ̀ ìyà wo ni ó jẹ?
11 Jehofa rán wòlíì rẹ̀ Natani sí Dafidi láti tú ẹ̀ṣẹ̀ ọba náà fó. “Dafidi sì wí fún Natani pé, Èmi ṣẹ̀ sí Oluwa. Natani sì wí fún Dafidi pé, Oluwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú.” (2 Samueli 12:13) Ẹ̀rí ọkàn na Dafidi lẹ́gba lórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ó sì sọ ìrònúpìwàdà rẹ̀ jáde nínú àdúrà àtọkànwá kan sí Jehofa pé: “Nítorí ìwọ kò fẹ́ ẹbọ, tí èmi ì bá rú u: inú rẹ kò dùn sí ọrẹ-ẹbọ sísun. Ẹbọ Ọlọrun ni ìròbìnújẹ́ ọkàn: ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà, Ọlọrun, òun ni ìwọ kì yóò gàn.” (Orin Dafidi 51:16, 17) Jehofa kò gan àdúrà tí Dafidi gbà láti inú ọkàn-àyà ìròbìnújẹ́. Síbẹ̀, Dafidi jìyà ó jewé iyá, ní ìbámu pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ Jehofa nípa ìdáríjì ní Eksodu 34:6, 7 pé: “Kìí jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà.”
Ìyàsímímọ́ Tẹmpili Nípasẹ̀ Solomoni
12. Kí ni ohun tí Solomoni tọrọ ní àkókò ìyàsímímọ́ tẹmpili, kí sì ni èsì Jehofa?
12 Nígbà tí Solomoni parí kíkọ́ tẹmpili Jehofa, ó sọ nínú àdúrà ìyàsímímọ́ rẹ̀ pé: “Nítorí náà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti tí Israeli ènìyàn rẹ tí wọn óò máa gbà sí ibí yìí: ìwọ gbọ́ láti ibùgbé rẹ wá, àní láti ọ̀run wá, nígbà tí ìwọ bá gbọ́, kí o sì dáríjì.” Jehofa fèsì pé: “Bí mo bá sé ọ̀run tí kò bá sí òjò, tàbí bí emi bá pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run, tàbí bí mo bá rán àjàkálẹ̀-àrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi; bí àwọn ènìyàn mi tí a ń pe orúkọ mi mọ́, bá rẹ araawọn sílẹ̀, tí wọ́n bá sì gbàdúrà, tí wọ́n bá sì wá ojú mi, tí wọ́n bá sì yípadà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn; nígbà náà ni èmi ó gbọ́ láti ọ̀run wá, èmi ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì, èmi ó sì wo ilẹ̀ wọn sàn.”—2 Kronika 6:21; 7:13, 14.
13. Kí ni Esekieli 33:13-16 fihàn nípa ojú-ìwòye Jehofa nípa ẹnìkan?
13 Bí Jehofa ṣe ń wò ọ́, ó gbà ọ́ fún oun tí o jẹ́ nísinsìnyí, kìí ṣe oun tí o ti jẹ́ rí. Yóò rí bí Esekieli 33:13-16 ṣe sọ pé: “Nígbà tí èmi óò wí fún olódodo pé, yíyè ni yóò yè, bí ó bá gbẹ́kẹ̀lé òdodo araarẹ̀, tí ó sì ṣe àìṣedéédéé, gbogbo òdodo rẹ̀ ni a kì yóò rántí mọ́, ṣùgbọ́n nítorí àìṣedéédéé tí ó ti ṣe, òun óò ti ìtorí rẹ̀ kú. Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí èmi wí fún ènìyàn búburú pé, Kíkú ni ìwọ óò kú; bí òun bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ tí ó sì yẹ; Bí ènìyàn búburú bá mú ògo padà, tí ó sì san ohun tí ó ti jí padà, tí ó sì ń rìn ní ìlànà ìyè, ní àìṣe àìṣedéédéé; yíyè ni yóò yè, òun kì yóò kú. A kì yóò ṣe ìrántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá fún un: òun ti ṣe èyí tí ó tọ́ tí ó sì yẹ; òun ó yè nítòótọ́.”
14. Kí ni ó yàtọ̀ nípa ọ̀nà tí Jehofa gbà ń dáríjini?
14 Ìdáríjì tí Jehofa Ọlọrun ń pèsè fún wa ní apá ẹ̀ka títayọ kan, ọ̀kan tí ó nira fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti fikún ìdáríjì tí wọn ń fún ẹnìkínní-kejì—òun máa ń dáríjì ó sì ń gbàgbé rẹ̀. Àwọn kan yóò sọ pé, ‘Mo lè dárí ohun tí ó ṣe jì ọ, ṣùgbọ́n n kò lè (tàbí n kò ni) gbàgbé rẹ̀.’ Ní ìyàtọ̀ sí èyí, kíyèsí ohun tí Jehofa sọ pé òun yóò ṣe: “Èmi óò dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kì óò sì rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”—Jeremiah 31:34.
15. Àkọsílẹ̀ wo nípa ìdáríjì ni Jehofa ní?
15 Jehofa ti ń dáríji àwọn olùjọsìn rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ó ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n mọ̀ pé àwọn dá jì wọ́n bákan náà sì ni ọ̀pọ̀ tí wọn kò tilẹ̀ mọ̀. Àánú, ìpamọ́ra, àti ìdáríjì tí ó pèsè jẹ́ èyí tí kò lópin. Isaiah 55:7 sọ pé: “Jẹ́ kí ènìyàn búburú kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹlẹ́ṣẹ̀ sì kọ ìrònú rẹ̀ sílẹ̀, sì jẹ́ kí ó yípadà sí Oluwa, òun ó sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọrun wa, yóò sì fi jì í ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.”
Ìdáríjì Nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki
16. Èéṣe tí a fi lè sọ pé ọ̀nà tí Jesu gbà ń dáríjini bá ti Jehofa mu?
16 Ìròyìn ìdáríjì Ọlọrun lọ jàra nínú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki. Jesu sọ nípa rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, ní fífihàn pé òun wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú èrò-inú Jehofa lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà. Láti ọ̀dọ̀ Jehofa ní ìrònú Jesu ti wá, ó fi irú ẹni tí Jehofa jẹ́ hàn, òun ni àwòrán wíwà Jehofa gan-an; tí a bá ti rí i a ti rí Jehofa.—Johannu 12:45-50; 14:9; Heberu 1:3.
17. Báwo ni Jesu ṣe ṣàkàwé bí Jehofa ṣe ń dáríjini “ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà”?
17 Ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jesu ti ọba kan tí ó dárí gbèsè 10,000 talẹnti (nǹkan bíi ₦726,000,000) ji ẹrú kan fihàn pé Jehofa máa ń dáríjini lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹrú yẹn kò fẹ́ láti dárí gbèsè ọgọ́rùn-ún denari (nǹkan bíi ₦1,320) ji ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan, ọba náà bínú gidigidi. “‘Ẹrú burúkú, mo fagilé gbogbo gbèsè yẹn fún ọ, nígbà tí o pàrọwà fún mi. Kò ha yẹ kí iwọ, ẹ̀wẹ̀, ṣàánú fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí emi pẹlu ti ṣàánú fún ọ?’ Pẹlu ìyẹn ọ̀gá rẹ̀, tí a tán ní sùúrù sí ìrunú, fà á lé awọn onítúbú lọ́wọ́, títí yoo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ padà.” Nígbà náà ni Jesu fi bí ó ṣe bá a mu hàn pé: “Ní irú-ọ̀nà kan naa ni Baba mi ọ̀run yoo gbà bá yín lò pẹlu bí olúkúlùkù yín kò bá dáríji arákùnrin rẹ̀ lati inú ọkàn-àyà yín wá.”—Matteu 18:23-35, NW.
18. Báwo ni a ṣe lè fi ojú-ìwòye Peteru wéra pẹ̀lú ojú-ìwòye Jesu níti dídáríjini?
18 Gẹ́rẹ́ ṣáájú kí Jesu tó fúnni ní àkàwé tí ó wà lókè yìí, Peteru tọ Jesu wá ó sì béèrè pé: “Oluwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yoo ṣẹ̀ mí tí emi yoo sì dáríjì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?” Peteru rò pé òun ti fi ìwà rere hàn dópin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ̀wé àti Farisi gbé ìwọ̀n kan kalẹ̀ fún dídáríjini, Jesu wí fún Peteru pé: “Mo wí fún ọ, kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bíkòṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Matteu 18:21, 22, NW) Bóyá ni ìgbà méje fi lè kọjá òòjọ́, gẹ́gẹ́ bí Jesu ṣe wí pé: “Ẹ fiyèsí ara yín. Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan fún un ní ìbáwí mímúná, bí oun bá sì ronúpìwàdà dárí jì í. Kódà bí oun bá ṣẹ̀ ọ́ ní ìgbà méje lóòjọ́ tí ó sì padà wá bá ọ ní ìgbà méje, tí ó wí pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ iwọ gbọ́dọ̀ dárí jì í.” (Luku 17:3, 4, NW) Nígbà tí Jehofa bá dáríjini, òun kìí ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀—èyí sì jẹ́ ohun tí ń mú wa láyọ̀.
19. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti lè rí ìdáríjì Jehofa gbà?
19 Bí a bá ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn láti ronúpìwàdà kí a sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, Jehofa múratán láti hùwà sí wa lọ́nà rere: “Bí a bá jẹ́wọ́ awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, oun jẹ́ aṣeégbíyèlé ati olódodo tí yoo fi dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá tí yoo sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò ninu gbogbo àìṣòdodo.”—1 Johannu 1:9, NW.
20. Ìmúratán láti dáríjini wo ni Stefanu fihàn?
20 Ọmọlẹ́yìn Jesu, Stefanu, nínú ẹ̀mí ìdáríjì tí ó pẹtẹrí, ó lọgun ẹ̀bẹ̀ yìí jáde bí àwọn ènìyànkénìyàn tí inú ń bí ṣe ń sọ ọ́ ní òkúta pé: “‘Jesu Oluwa, gba ẹ̀mí mi.’ Nígbà naa, ní títẹ eékún rẹ̀ ba, ó ké jáde pẹlu ohùn líle pé: ‘Jehofa, máṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yii sí wọn lọ́rùn.’ Lẹ́yìn wíwí èyí ó sì sùn ninu ikú.”—Iṣe 7:59, 60, NW.
21. Èéṣe tí ìmúratán Jesu láti dáríji àwọn ṣọ́jà Romu fi galọ́lá?
21 Jesu fi àpẹẹrẹ ìmúratán láti dáríjini èyí tí ó túbọ̀ galọ́lá lélẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti fàṣẹ ọba mú un, wọ́n bá a ṣẹjọ́ lọ́nà tí kò bófinmu, wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n fi i ṣẹlẹ́yà, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n fi kòbókò aláwọ yẹ́lẹyẹ̀lẹ tí ó sì ṣeéṣe kí ó ní egungun wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ àti irin ródóródó tí a tó mọ́ ọn lára nà án, àti nígbẹ̀yìn gbẹ́yín wọ́n kàn án mọ́ òpó igi fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Àwọn ará Romu kò gbẹ́yìn nínú ọ̀ràn yìí. Síbẹ̀, bí Jesu ṣe ń kú lọ lórí òpó igi ìdálóró yẹn, ó wí fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run nípa àwọn ṣọ́jà tí wọ́n kàn án mọ́ igi pé: “Baba, dáríjì wọ́n, nitori wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Luku 23:34, NW.
22. Àwọn ọ̀rọ̀ wo láti inú Ìwàásù Orí Òkè ní a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti fi ṣèwàhù?
22 Nínú Ìwàásù rẹ̀ ní Orí Òkè, Jesu wí pé: “Ẹ máa bá a lọ lati máa nífẹ̀ẹ́ awọn ọ̀tá yín ati lati máa gbàdúrà fún awọn wọnnì tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” Títí dé òpin iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, òun fúnraarẹ̀ ṣègbọràn sí ìlànà yẹn. Ìyẹn ha ti pọ̀ jù fún wa, àwa tí a ń bá àìlera ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ wa jìjàkadì? Bí ó ti wù kí ó mọ́ a níláti gbìyànjú láti fi àwọn ọ̀rọ̀ tí Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́yìn tí ó kọ́ wọn ní àdúrà àwòkọ́ṣe náà ṣèwàhù pé: “Nitori bí ẹ̀yin bá dárí aṣemáṣe awọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yoo dáríjì yín pẹlu; nígbà tí ó jẹ́ pé bí ẹ kò bá dárí aṣemáṣe awọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yoo dárí awọn aṣemáṣe yín jì yín.” (Matteu 5:44, NW; 6:14, 15, NW) Bí a bá ń dáríjini bíi ti Jehofa, àwa yóò máa dáríjini a óò sì máa gbàgbé rẹ̀.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ní Jehofa ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, èésìtiṣe?
◻ Èéṣe tí a fi fún Manasse ni ìjọba rẹ̀ padà?
◻ Apá ẹ̀ka títayọ wo nínú ìdáríjini Jehofa ni ó ti jẹ́ ìpèníjà fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti ṣàfarawé?
◻ Báwo ni ìmúratán Jesu láti dáríjini ṣe jẹ́ èyí tí ó galọ́lá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Natani ran Dafidi lọ́wọ́ láti rí àìní náà fún ìdáríjì Ọlọrun