Àjíǹde Àwọn Olódodo Yóò Wà
“Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.”—IṢE 24:15, NW.
1. Irú ipò wo ni ó ti dojúkọ gbogbo ẹ̀dá ènìyàn láti ìgbà ìṣubú Adamu àti Efa?
“OHUNKÓHUN tí ọwọ́ rẹ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà-òkú níbi tí ìwọ ń rè.” (Oniwasu 9:10) Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí a ṣàyàn dáradára wọ̀nyí, ọlọgbọ́n Ọba Solomoni ṣàpèjúwe ipò kan tí ó ti dojúkọ gbogbo ìran aráyé láti ìgbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Adamu àti Efa, ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, láìdá ẹnì kan sí, ikú ti gbé gbogbo ènìyàn mì—ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ọba àti mẹ̀kúnnù, onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́. Ní tòótọ́, ikú ti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.”—Romu 5:17, NW.
2. Èéṣe tí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ fi lè ní ìjákulẹ̀ ní àkókò òpin yìí?
2 Láìka ìtẹ̀síwájú tí ó dé kẹ́yìn nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ìṣègùn sí, ikú ṣì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àní lónìí olónìí pàápàá. Bí èyí kò tilẹ̀ jẹ́ ìyàlẹ́nu, ìjákulẹ̀ ti lè bá àwọn kan nígbà tí wọ́n bá dojúkọ ọ̀tá ọlọ́jọ́ pípẹ́ yìí nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Èéṣe? Ó dára, nígbà náà lọ́hùn ún ní àwọn ọdún 1920, Watch Tower Society polongo ìhìn-iṣẹ́ náà “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ó wàláàyè nísinsìnyí kì yóò kú láé.” Àwọn wo ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọ̀nyí yóò jẹ́? “Awọn àgùtàn” tí a sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ọ̀rọ̀ Jesu nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́ ni. (Matteu 25:31-46, NW) Àwọn ẹni bí àgùtàn wọ̀nyí ni a sọtẹ́lẹ̀ pé wọn yóò farahàn ní àkókò òpin, tí ìrètí wọn yóò sì jẹ ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise orí ilẹ̀-ayé. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ènìyàn Ọlọrun jèrè òye tí ó dára síi nípa ipò “àwọn àgùtàn” wọ̀nyí nínú àwọn ète Jehofa. Wọ́n wá mọ̀ pé àwọn onígbọràn wọ̀nyí ni a níláti yà sọ́tọ̀ kúrò lára “awọn ewúrẹ́” tí wọ́n jẹ́ olóríkunkun, lẹ́yìn ìparun àwọn tí a mẹ́nukàn kẹ́yìn yìí, àwọn àgùtàn yóò jogún pápá àkóso Ìjọba náà tí a ti pèsè sílẹ̀ fún wọn lórí ilẹ̀-ayé.
Kíkó Àwọn Ẹni Bí Àgùtàn Jọ
3. Iṣẹ́ wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ti pọkàn pọ̀ lé lórí láti 1935 wá?
3 Bẹ̀rẹ̀ láti 1935, ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà ti pọkànpọ̀ sórí wíwá irú àwọn ẹni bí àgùtàn bẹ́ẹ̀ kiri àti mímú wọn wá sínú ètò-àjọ Jehofa. (Matteu 24:45, NW; Johannu 10:16) Àwọn Kristian tí ó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí ti wá mọ̀ pé Jesu ti ń ṣàkóso nísinsìnyí nínú Ìjọba ọ̀run ti Jehofa àti pé àkókò náà ń súnmọ́lé gírígírí fún òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí àti mímú ayé titun nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé wọlé dé. (2 Peteru 3:13; Ìṣípayá 12:10) Nínú ayé titun yẹn, àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni lọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tí Isaiah sọ yóò ní ìmúṣẹ pé: “Òun óò gbé ikú mì láéláé.”—Isaiah 25:8.
4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi tọkàn tọkàn retí láti rí ìdáláre ipò ọba-aláṣẹ Jehofa ní Armageddoni, kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí púpọ̀ lára àwọn àgùtàn mìíràn?
4 Níwọ̀n bí òpin ayé Satani ti ń súnmọ́lé girigiri, àwọn Kristian ẹni bí àgùtàn yóò fẹ́ láti wàláàyè títí tí Jehofa yóò fi dá ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ láre nígbà ìpọ́njú tí ń bọ̀ wá sórí Babiloni Ńlá àti ìyókù ayé Satani. (Ìṣípayá 19:1-3, 19-21) Fún iye tí ó pọ̀ gidigidi, kò tí ì rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìrètí láti wà lára àwọn “àràádọ́ta ọ̀kẹ́” tí kì yóò kú láé ti kú. Àwọn agbawèrèmẹ́sìn pa àwọn kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n àti ọgbà ìṣẹ́ninísẹ̀ẹ́ nítorí òtítọ́. Àwọn mìíràn ti kú nínú jàm̀bá tàbí láti inú ohun tí a lè pè ní ohun àbímọ́ni tí ń ṣokùnfà ikú—àìsàn àti ọjọ́-ogbó. (Orin Dafidi 90:9, 10; Oniwasu 9:11) Ó hàn gbangba pé, ọ̀pọ̀ ni yóò ṣì kú kí òpin tó dé. Báwo ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ṣe rí ìmúṣẹ ìlérí ayé titun nínú èyí tí òdodo yóò gbé?
Ìrètí Àjíǹde
5, 6. Ọjọ́-ọ̀la wo ni ó wà fún àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀-ayé ṣùgbọ́n tí wọ́n kú ṣáájú Armageddoni?
5 Aposteli Paulu fúnni ní ìdáhùn náà nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níwájú gómìnà Romu Feliksi. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ní Iṣe 24:15 (NW), Paulu fi tìgboyà tìgboyà kéde pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yóò wà.” Ìrètí àjíǹde ń fún wa ní ìgboyà lójú àwọn ipò bíbaninínújẹ́ tí ó burú jùlọ. Nítorí ìrètí yẹn, àwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n tí wọ́n dùbúlẹ̀ àìsàn tí wọ́n sì nímọ̀lára pé àwọn yóò kú kò rẹ̀wẹ̀sì. Ohun yòówù tí ó bá ṣẹlẹ̀, wọ́n mọ̀ pé àwọn yóò ka èrè ìṣòtítọ́. Nítorí ìrètí àjíǹde, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa onígboyà tí wọ́n dojúkọ ikú láti ọwọ́ àwọn onínúnibíni mọ̀ pé kò sí ọ̀nà kankan tí àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wọn lè gbà jagunmólú. (Matteu 10:28) Nígbà tí ẹnì kan nínú ìjọ bá kú, ó ń bà wá nínú jẹ́ láti pàdánù ẹni náà. Ní àkókò kan náà, bí òun yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgùtàn mìíràn, a ń láyọ̀ pé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ti jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dé òpin ó sì ń sinmi nísinsìnyí, ó sì ní ìdánilójú fún ọjọ́-ọ̀la kan nínú ayé titun Ọlọrun.—1 Tessalonika 4:13.
6 Bẹ́ẹ̀ni, ìrètí àjíǹde jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìgbàgbọ́ wa. Bí ó ti wù kí ó rí, èéṣe tí ìgbàgbọ́ wa nínú àjíǹde fi lágbára tóbẹ́ẹ̀, àwọn wo ni wọ́n sì ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀?
7. Kí ni àjíǹde, àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wo sì ni wọ́n sì sọ nípa bí ó ṣe dájú tó?
7 Ọ̀rọ̀ Griki náà fún “àjíǹde” ni a·naʹsta·sis, tí ó túmọ̀ ní olówuuru sí “nínàró.” Ó tọ́ka ní pàtàkì sí dídìde láti inú òkú. Ó dùnmọ́ni pé, ọ̀rọ̀ náà gan-an “àjíǹde” kò farahàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, ṣùgbọ́n ìrètí àjíǹde ni a fi hàn kedere níbẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, a rí i nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jobu sọ jáde nígbà tí ìjìyà rẹ̀ ń lọ lọ́wọ́ pé: “Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò-òkú, . . . ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi.” (Jobu 14:13) Lọ́nà tí ó jọra, ní Hosea 13:14, a kà pé: “Èmi ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ agbára isà-òkú; Èmi ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú; Ikú, àjàkálẹ̀ àrùn rẹ dà? Isà-òkú, ìparun rẹ dà?” Ní 1 Korinti 15:55, aposteli Paulu fa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yọ ó sì fi hàn pé ìṣẹ́gun náà tí a sọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ni a ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ àjíǹde. (Àmọ́ ṣáá o, nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ yẹn Paulu ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run.)
‘A Polongo’ Àwọn Onígbàgbọ́ “Ní Olódodo”
8, 9. (a) Báwo ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ṣe lè ní ipa nínú àjíǹde àwọn olódodo? (b) Kí ni a gbé ìrètí wa nínú ìwàláàyè kan tí ikú kì yóò fi òpin sí kà?
8 Nínú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Feliksi, èyí tí a fàyọ ní ìpínrọ̀ 5, Paulu wí pé àjíǹde àwọn olódodo àti aláìṣòdodo yóò wà. Àwọn wo ni àwọn olódodo tí a óò jí dìde? Ó dára, kò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tí a bí òdodo mọ́. Gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ láti ìgbà ìbí, a sì ń dẹ́ṣẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí-ayé wa—èyí tí ó mú kí a yẹ fún ikú fún ìdí méjì. (Romu 5:12; 6:23) Bí ó ti wù kí ó rí, nínú Bibeli a rí gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “polongo . . . ní olódodo.” (Romu 3:28, NW) Èyí ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí Jehofa ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ aláìpé.
9 Ọ̀rọ̀ náà ni a ń lò lọ́nà tí ó pọ̀ jùlọ fún àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró, tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run. Ní Romu 5:1 (NW), aposteli Paulu sọ pé: “Nísinsìnyí tí a ti polongo wa ní olódodo nitori ìgbàgbọ́, ẹ jẹ́ kí a gbádùn àlàáfíà pẹlu Ọlọrun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi.” Gbogbo àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ni a polongo ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Ìgbàgbọ́ nínú kí ni? Gẹ́gẹ́ bí Paulu ṣe ṣàlàyé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ nínú ìwé Romu, ó jẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi. (Romu 10:4, 9, 10) Jesu kú gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé lẹ́yìn náà ni a sì jí i dìde láti inú òkú tí ó sì gòkè re ọ̀run láti gbé ìtóye ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ kalẹ̀ nítorí tiwa. (Heberu 7:26, 27; 9:11, 12) Nígbà tí Jehofa tẹ́wọ́gba ẹbọ yẹn, níti gidi, Jesu ra ìran ẹ̀dá ènìyàn padà kúrò nínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àwọn wọnnì tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìṣètò yìí ń jàǹfààní ńláǹlà nínú rẹ̀. (1 Korinti 15:45) Lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ ní ìrètí jíjogún ìyè tí ọ̀tá rírorò náà, ikú kì yóò lè fòpin sí.—Johannu 3:16.
10, 11. (a) Àjíǹde wo ni ó ń dúró de àwọn Kristian olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni-àmì-òróró? (b) Irú àjíǹde wo ni àwọn olùjọsìn ṣáájú sànmánì Kristian ń retí?
10 Ọpẹ́lọpẹ́ ẹbọ ìràpadà Jesu, àwọn olùṣòtítọ́ ẹni-àmì-òróró, tí a ti polongo ní olódodo, ní ìrètí dídájú ti dídi ẹni tí a jí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí aláìleèkú, gẹ́gẹ́ bí ti Jesu. (Ìṣípayá 2:10) Àjíǹde wọn ni a mẹ́nubà nínú Ìṣípayá 20:6, tí ó sọ pé: “Aláyọ̀ ati mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa ninu àjíǹde èkínní; ikú kejì kò ní ọlá-àṣẹ kankan lórí awọn wọnyi, ṣugbọn wọn yoo jẹ́ àlùfáà Ọlọrun ati ti Kristi, wọn yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún naa.” Èyí ni àjíǹde sókè ọ̀run. Bí ó ti wù kí ó rí, ṣàkíyèsí pé Bibeli pè é ní “àjíǹde èkínní,” èyí tí ó fi hàn pé púpọ̀ síi ṣì ń bọ̀ lọ́nà.
11 Nínú Heberu orí 11, Paulu tọ́ka sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n wà ṣáájú àkókò ìsìn Kristian tí wọ́n ti fi ìgbàgbọ́ lílágbára hàn nínú Jehofa Ọlọrun. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. Nínú ẹsẹ 35 orí yẹn, Paulu sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjíǹde yíyanilẹ́nu tí ó ṣẹlẹ̀ lákòókò ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn ọmọ Israeli, ní sísọ pé: “Awọn obìnrin rí awọn òkú wọn gbà nipa àjíǹde; ṣugbọn awọn ọkùnrin mìíràn ni a dálóró nitori pé wọn kò jẹ́ tẹ́wọ́gba ìtúsílẹ̀ nipa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù.” Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́rìí ìgbàanì wọ̀nyẹn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ lè fojúsọ́nà fún àjíǹde tí ó dára ju èyí tí Elijah àti Elisha ní ìrírí rẹ̀ lọ. (1 Ọba 17:17-22; 2 Ọba 4:32-37; 13:20, 21) Ìrètí wọn wà nínú àjíǹde sínú ayé titun kan níbi tí a kò ti ní dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lóró nítorí ìgbàgbọ́ wọn, ayé kan nínú èyí tí àwọn obìnrin kì yóò ti pàdánù àwọn olólùfẹ́ wọn nínú ikú. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n fojúsọ́nà fún dídìde kúrò nínú òkú sínú ayé titun kan náà tí a ń retí. (Isaiah 65:17-25) Jehofa kò ṣí ayé titun yìí payá fún wọn tó bí o ti ṣí i payá fún wa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ó ń bọ̀, wọ́n sì fẹ́ láti wà nínú rẹ̀.
Àjíǹde Sórí Ilẹ̀-Ayé
12. A ha polongo àwọn olùṣòtítọ́ ṣáájú sànmánì Kristian gẹ́gẹ́ bí olódodo bí? Ṣàlàyé.
12 Ó ha yẹ kí a ronú pé jíjí àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ tí wọ́n ti wà ṣáájú àkókò ìsìn Kristian sínú ayé titun yẹn jẹ́ apákan àjíǹde àwọn olódodo bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ni, nítorí pé Bibeli tọ́ka sí wọn gẹ́gẹ́ bí olódodo. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu mẹ́nukan ọkùnrin àti obìnrin ìgbàanì kan tí a polongo ní olódodo. Ọkùnrin náà ni Abrahamu, babańlá ìran Heberu. A kà nípa rẹ̀ pé: “‘Abrahamu lo ìgbàgbọ́ ninu Jehofa, a sì kà á sí òdodo fún un,’ ó sì di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jehofa.’” Rahabu ni obìnrin náà, ẹni tí kì í ṣe ọmọ Israeli tí ó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jehofa. A ‘polongo rẹ̀ ní olódodo’ ó sì di apákan orílẹ̀-èdè Heberu. (Jakọbu 2:23-25, NW) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàanì tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Jehofa àti ìlérí rẹ̀ tí wọ́n sì dúró ní olùṣòtítọ́ títí dójú ikú ni Jehofa polongo ní olódodo lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn, kò sì sí iyèméjì pé wọn yóò ṣàjọpín nínú ‘àjíǹde awọn olódodo.’
13, 14. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé a lè polongo àwọn Kristian tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀-ayé ní olódodo? (b) Kí ni èyí túmọ̀ sí fún wọn?
13 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ ẹni bí àgùtàn lónìí ńkọ́, àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀-ayé tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa tí wọ́n sí kù gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ní àkókò òpin yìí? Wọn yóò ha nípa nínú àjíǹde àwọn olódodo bí? Ó hàn kedere pé yóò rí bẹ́ẹ̀. Aposteli Johannu rí ogunlọ́gọ̀ ńlá irú àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìran. Kíyèsí bí ó ṣe ṣàpèjúwe wọn: “Mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà, lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ ati níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà funfun; imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn. Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíké pẹlu ohùn rara, wí pé: ‘Ọlọrun wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa ni awa jẹ ní gbèsè fún ìgbàlà.’”—Ìṣípayá 7:9, 10, NW.
14 Ṣàkíyèsí pé ìgbàlà àwọn ọlọ́kàntútù wọ̀nyí dá wọn lójú gidigidi, wọ́n sì ka èyí sí iṣẹ́ ọwọ́ Jehofa àti ti Jesu, “Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n ń dúró níwájú Jehofa àti Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà, gbogbo wọn sì wọ aṣọ funfun. Èéṣe tí a fi wọ̀ wọ́n ní aṣọ funfun? Ẹ̀dá ọ̀run kan sọ fún Johannu pé: “Wọ́n sì ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.” (Ìṣípayá 7:14, NW) Nínú Bibeli, funfun jẹ́ àmì ìṣàpẹẹrẹ fún ìmọ́gaara, òdodo. (Orin Dafidi 51:7; Danieli 12:10; Ìṣípayá 19:8) Òtítọ́ náà pé ogunlọ́gọ̀ ńlá ni a rí tí wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà funfun túmọ̀ sí pé Jehofa kà wọ́n sí olódodo. Báwo ni ìyẹn ṣe ṣeé ṣe? Nítorí pé, ní ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti fọ aṣọ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn. Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi tí a ta sílẹ̀ a sì tipa bẹ́ẹ̀ polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọrun pẹ̀lú ìrètí líla ìpọ́njú ńlá náà já. Nítorí náà, Kristian olùṣèyàsímímọ́ èyíkéyìí tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ó bá kú ṣáájú ìpọ́njú ńlá náà lè ní ìdánilójú nínípìn-ín nínú àjíǹde àwọn olódodo sí orí ilẹ̀-ayé.
15. Níwọ̀n bí a óò ti jí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo dìde, àǹfààní wo ni ó wà nínú àjíǹde àwọn olódodo?
15 Àjíǹde yẹn ni a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá orí 20, ẹsẹ 13 (NW), pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Òkun sì jọ̀wọ́ awọn òkú wọnnì tí ń bẹ ninu rẹ̀ lọ́wọ́, ikú ati Hédíìsì sì jọ̀wọ́ awọn òkú wọnnì tí ń bẹ ninu wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹlu awọn iṣẹ́ wọn.” Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà Ọjọ́ Ìdájọ́ ńlá ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún ti Jehofa, gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọrun yóò jíǹde—àwọn olódodo àti aláìṣòdodo. (Iṣe 17:31) Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ wo bí yóò ti sàn jù fún àwọn olódodo tó! Wọ́n ti gbé ìgbésí-ayé onígbàgbọ́ rí. Wọ́n ti ní ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé pé yóò ṣàṣeparí àwọn ète rẹ̀. Àwọn ẹlẹ́rìí olódodo ṣáájú Sànmánì Kristian yóò jí dìde láti inú ikú pẹ̀lú ìháragàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ bí àwọn ìlérí Jehofa nípa Irú-Ọmọ náà ṣe ní ìmúṣẹ. (1 Peteru 1:10-12) Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ àgùtàn mìíràn tí Jehofa polongo ní olódodo ní ọjọ́ wa yóò jáde wá láti inu sàréè pẹ̀lú ìháragàgà láti wo Paradise ilẹ̀-ayé tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí wọ́n kéde ìhìnrere náà nínú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Àkókò aláyọ̀ ni ìyẹn yóò mà jẹ́ o!
16. Kí ni a lè sọ nípa jíjí tí a óò jí àwọn wọnnì tí wọ́n kú ní àkókò tiwa dìde ní Ọjọ́ Ìdájọ́?
16 Nígbà Ọjọ́ Ìdájọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún yẹn, nígbà wo gan-an ni àjíǹde àwọn wọnnì tí wọ́n kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ní apá ìparí àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Satani yìí yóò ṣẹlẹ̀? Bibeli kò sọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kò ha ní bọ́gbọ́nmu láti ronú pé àwọn wọnnì tí a kà yẹ ní olódodo tí wọ́n kú ní ọjọ́ wa ni yóò kọ́kọ́ jíǹde kí wọn baà lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣàjọpín pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn olùla Armageddoni já nínú iṣẹ́ kíkí àwọn ìran tí ó ti wà ṣáájú káàbọ̀ láti inú ikú bí? Bẹ́ẹ̀ni, níti tòótọ́!
Ìrètí Tí Ń Fúnni ní Ìtùnú
17, 18. (a) Ìtùnú wo ni ìrètí àjíǹde pèsè? (b) Kí ni a sún wa láti polongo nípa Jehofa?
17 Ìrètí àjíǹde ń fún gbogbo àwọn Kristian lónìí ní okun àti ìtùnú. Bí a bá dúró ní olùṣòtítọ́, kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ tàbí ọ̀tá èyíkéyìí tí ó lè gba èrè mọ́ wa lọ́wọ́! Fún àpẹẹrẹ, nínú 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú-ìwé 177, níbẹ̀ ni a ti rí àwòrán àwọn Kristian onígboyà ní Etiopia tí wọ́n kú dípò fífi ìgbàgbọ́ wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́. Àkọlé náà kà pé: “Àwọn ojú tí a ń retí láti rí nígbà àjíǹde.” Ẹ wo àǹfààní tí yóò jẹ́ láti mọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti àìlóǹkà mìíràn tí wọ́n ti fi irú ìṣòtítọ́ kan náà hàn títí dójú ikú!
18 Àwọn olólùfẹ́ àti àwọn ọ̀rẹ́ wa tí wọn kò lè la ìpọ́njú ńlá náà já nítorí ọjọ́-orí àti àìlera ńkọ́? Ní ìbámu pẹ̀lú ìrètí àjíǹde, wọ́n ní ọjọ́-ọ̀la àgbàyanu bí wọ́n bá dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́. Bí àwa pẹ̀lú bá sì fi tìgboyà tìgboyà lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu, a ní ọjọ́-ọ̀la àgbàyanu. Èéṣe? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bíi Paulu, a ní ìrètí nínú “àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo.” Pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa ni a fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún ìrètí yìí. Dájúdájú, ó sún wa láti ṣe àsọtúnsọ àwọn ọ̀rọ̀ onipsalmu náà pé: “Sọ̀rọ̀ ògo [Ọlọrun] láàárín àwọn Kèfèrí, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn. Nítorí ti Oluwa tóbi, ó sì ní ìyìn púpọ̀ púpọ̀.”—Orin Dafidi 96:3, 4.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wo ni wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìdí ìrètí wa nínú àjíǹde ti ilẹ̀-ayé múlẹ̀?
◻ Lórí ìpìlẹ̀ wo ni a fi polongo àwọn Kristian ní olódodo nísinsìnyí?
◻ Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe fún wa ní ìgboyà àti ìpinnu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Gẹ́gẹ́ bíi Paulu, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní ìrètí nínú àjíǹde ti òkè ọ̀run