Ohun Dídára Jùlọ Tí Mo Lè Lo Ìgbésí-Ayé Mi Fún
GẸ́GẸ́ BÍ BOB ANDERSON ṢE SỌ Ọ́
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ mélòókan bi mí pé: “Èéṣe tí o fi ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó, Bob?” Mo rẹ́rìn-ín músẹ́ mo sì wí pé: “Ó dára, ẹ ha lè ronú nípa ohun kan tí ó sàn ju ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà lọ bí?”
MO JẸ́ ẹni ọdún 23 nígbà tí mo wọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà ní ọdún 1931. Nísinsìnyí mo ń lo ọdún kẹtàdínláàádọ́rùn-ún lọ mo sì ń ṣe aṣáájú ọ̀nà síbẹ̀. Mo mọ̀ pé kò sì ohun tí ó sàn ju èyí lọ ti mo lè lo ìgbésí-ayé mi fún. Ẹ jẹ́ kí ń ṣàlàyé ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀.
A fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan sílẹ̀ ní ilé wa ní 1914. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Káàkiri Orílẹ̀-Èdè, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà náà, ni wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí náà padà dé, màmá mi bi í ní ìbéèrè kínníkínní nípa iná ọ̀run àpáàdì. A tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí onísìn Wesleyan Methodist ṣùgbọ́n kò lè rí ìbádọ́gba tí ń bẹ láàárín ẹ̀kọ́ ìsìn ìdálóró ayérayé àti Ọlọrun ìfẹ́. Ní gbàrà tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa kókó ọ̀ràn náà, ó wí pé: “Mo túbọ̀ láyọ̀ ju bí mo tí ì ṣe láyọ̀ rí nínú ìgbésí-ayé mi!”
Lójú-ẹsẹ̀ ni ìyá mi ṣíwọ́ láti máa kọ́ni ní ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Methodist ó sì dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kékeré ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó bẹ̀rẹ̀ síí wàásù ní ìlú ìbílẹ̀ wa ní Birkenhead, tí ó dojúkọ ibùdókọ̀ Liverpool ní ìsọdá Odò Mersey, kò sì pẹ́ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ síí gun kẹ̀kẹ́ lọ sí ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tí ń bẹ nítòsí. Ó jẹ́rìí ní agbègbè ìpínlẹ̀ gbígbòòrò yìí fún ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ ó sì di ẹni tí a mọ̀ dáradára, ní fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kú ní ọdún 1971 gẹ́gẹ́ bí arúgbó ẹni ọdún 97, ó jẹ́ ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí títí dé òpin.
Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin Kathleen, àti èmi ni a mú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Methodist láti lè máa bá Màmá lọ sí àwọn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Lẹ́yìn náà, nígbà tí bàbá mi bẹ̀rẹ̀ síí bá wa lọ, àwọn òbí mi ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé déédéé nínú ìwé náà Duru Ọlọrun. Irúfẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìhùmọ̀ titun ní àwọn ọjọ́ wọnnì, ṣùgbọ́n ìdálẹ́kọ̀ọ́ àtilẹ̀wá yìí lórí àwọn kókó ìpìlẹ̀ òtítọ́ inú Bibeli mú èrè jìngbìnnì wá, níwọ̀n bí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ti wọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà bí àkókò ti ń lọ.
Màmá di ojú-ìwòye náà mú pé wíwo sinimá “Photo-Drama of Creation” ní Liverpool ní ọdún 1920 jẹ́ ìkóríta ìyípadà fún àwa ọmọ, ó sì tọ̀nà. Bí mo ti kéré tó nì, àwòrán yẹn tẹ àwọn èrò ṣíṣe kedere mọ́ mi lọ́kàn. Èyí tí ó gbapò iwájú jùlọ nínú iyè ìrántí mi ni apá ẹ̀ka tí ó ṣàpèjúwe ìgbésí-ayé Jesu, ní pàtàkì jùlọ níbi tí ó ti fi í hàn bí ó ti ń rìn lọ padé ikú rẹ̀. Gbogbo ìrírí náà pátá ràn mí lọ́wọ́ láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé—wíwàásù!
Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1920, mo bẹ̀rẹ̀ síí pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú kiri pẹ̀lú màmá mi ní àwọn ọ̀sán ọjọ́ Sunday. Lákọ̀ọ́kọ́ a fún wa ní ìtọ́ni láti fi wọn sílẹ̀ ní àwọn ilé; lẹ́yìn náà a sọ fún wa láti fi wọ́n lé àwọn onílé lọ́wọ́ kí a sì tún padà kàn sí àwọn wọnnì tí wọ́n fi ọkàn-ìfẹ́ hàn. Mo ti máa ń fìgbà gbogbo wo èyí gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ìjímìjí fún ìgbòkègbodò ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa ti òde-òní, èyí tí ń mésojáde gan-an lónìí.
Ó Di Inú Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà!
Èmi àti Kathleen ṣèrìbọmi ní 1927. Mo ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣàyẹ̀wò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ egbòogi ní Liverpool nígbà tí mo gbọ́ ìgbèròpinnu láti tẹ́wọ́gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ọdún 1931. Mo ti máa ń fìgbà gbogbo rí àwọn apínwèé ìsìn kiri Society (tí a ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà nísinsìnyí) tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní àwọn agbègbè ìṣòwò ní Liverpool, àpẹẹrẹ wọn sì wú mi lórí gidigidi. Ẹ wo bí mo ti yánhànhàn tó láti ja àjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ti ayé, láti lè lo ìgbésí-ayé mi nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa!
Ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún kan náà yẹn, ọ̀rẹ́ mi Gerry Garrard sọ fún mi pé òun ti gba iṣẹ́ àyànfúnni láti ọ̀dọ̀ ààrẹ kejì ti Watch Tower Society, Joseph F. Rutherford, láti wàásù ní India. Ṣáájú kí ó tó lọ wọkọ̀ ojú-omi, ó wá láti rí mi ó sì bá mi sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún. Bí ó ti ń kí mi pé ó dìgbòóṣe, ó fún mi ní ìṣírí síwájú síi nípa sísọ pé, “Ó dá mi lójú pé o kò ní pẹ́ di aṣáájú ọ̀nà, Bob.” Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì rí. Mo gbàwé ìwọṣẹ́ ní October yẹn. Ẹ wo bí ìdùnnú, òmìnira gígun kẹ̀kẹ́ la àwọn ọ̀nà ìgbèríko, láti lọ wàásù ní àwọn àdúgbò àwùjọ àdádó náà ti pọ̀ tó! Mo mọ̀ nígbà náà pé mo ń dágbálé iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì jùlọ tí mo lè ṣe.
Iṣẹ́ àyànfúnni mi àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ ní South Wales níbi ti mo ti darapọ̀ mọ́ Cyril Stentiford. Cyril fẹ́ Kathleen lẹ́yìn náà, wọ́n sì jọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà papọ̀ fún ọdún mélòókan. Ọmọbìnrin wọn pẹ̀lú, Ruth, wọnú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà náà. Nígbà tí ó fi máa di ọdún 1937, mo ti wà ní Fleetwood, Lancashire—gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́ Eric Cooke. Títí fi di àkókò yẹn, kìkì agbègbè àrọ́ko ilẹ̀ Britain ni àwọn aṣáájú ọ̀nà ti máa ń ṣiṣẹ́, lẹ́yìn òde agbègbè ìpínlẹ̀ ìjọ. Ṣùgbọ́n Albert D. Schroeder, ẹni tí ń bójútó iṣẹ́ ní ọ́fíìsì ẹ̀ka Society ní London nígbà náà, pinnu pé kí wọ́n gbé wa lọ sí ìlú-ńlá Bradford, Yorkshire. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a yanṣẹ́ fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní Britain láti lọ ran ìjọ pàtó kan lọ́wọ́.
Ní 1946, Eric lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead a sì yanṣẹ́ fún un ní Southern Rhodesia, tí a ń pè ní Zimbabwe nísinsìnyí, òun àti aya rẹ̀ ṣì ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní Durban, South Africa.
Ọdún 1938 bá mi lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn, nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá (tí a ń pè ní alábòójútó àyíká nísinsìnyí) fún apá àríwá ìwọ̀-oòrùn Lancashire àti Lake District tí ó lẹ́wà. Níbẹ̀ ni mo ti bá Olive Duckett pàdé, lẹ́yìn ìgbà tí a ṣègbéyàwó, ó tẹ̀lé mi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nínú iṣẹ́ àyíká.
Ireland Ní Àwọn Ọdún tí Ogun Ń Jà Lọ́wọ́
Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Britain kéde láti bá Germany jagun ní September 1939, a yí iṣẹ́ àyànfúnni mi padà sí Ireland. Ìfipá múni wọṣẹ́ ológun ti bẹ̀rẹ̀ ní Britain ṣùgbọ́n kò tíì bẹ̀rẹ̀ ní ìhà gúúsù Republic of Ireland, tí ó ṣì wà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí kò dásí tọ̀tún tòsì títí tí ogun náà fi parí. Ó yẹ kí Republic of Ireland àti Northern Ireland jẹ́ àyíká kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ìkálọ́wọ́kò ń lọ lọ́wọ́, ó sì pọndandan láti gba ìwé ìyọ̀ǹda ìrìn-àjò láti lè fi Britain sílẹ̀ lọ sí apá ibikíbi ní Ireland. Àwọn aláṣẹ sọ fún mi pé mo lè lọ, ṣùgbọ́n mo níláti gbà pé èmi yóò padà sí England lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n bá pe àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ fún ìfipá wọnú iṣẹ́ ológun. Mo fẹnu lásán dáhùn, ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu mi, nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́ lórí ìwé ìyọ̀ǹda mi, kò sí ipò àfilélẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá a rìn!
Ní àkókò yẹn, kìkì 100 àwọn Ẹlẹ́rìí ni ó wà ní gbogbo Ireland. Nígbà tí a dé sí Dublin ní November 1939, Jack Corr, aṣáájú ọ̀nà ọlọ́jọ́ gbọọrọ, wá pàdé wa. Ó sọ fún wa pé àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì mìíràn ṣì wà ní ìlú kan tí kò jìnnà púpọ̀ tí àwọn olùfìfẹ́hàn díẹ̀ sì wà ní Dublin, nǹkan bí 20 lápapọ̀. Jack háyà iyàrá kan ní Dublin fún ìpàdé tí gbogbo wa gbà pé a óò ti máa pàdé déédéé ní ọjọọjọ́ Sunday. Ìṣètò yìí ń bá a lọ títí tí a fi fìdí ìjọ náà múlẹ̀ ní 1940.
Northern Ireland, gẹ́gẹ́ bí apákan United Kingdom, ń bá Germany jagun, nítorí náà bí a ti ṣílọ sí àríwá Belfast, a níláti dojúkọ ọ̀ràn jíjáwèé ra oúnjẹ àti ìṣúbolẹ̀ òkùnkùn nígbà tí iná bá lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ òfúúrufú Nazi níláti rin ohun tí ó ju 1,600 kìlómítà kí ó tó lè dé Belfast kí ó sì tún padà sí ibùdó wọn ní Europe, wọ́n gbìyànjú láti ju bọ́m̀bù sórí ìlú-ńlá náà lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Nígbà tí ìgbóguntì àkọ́kọ́ wáyé, wọ́n ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lọ́ṣẹ́ wọ́n sì ba ilé àdágbé wa jẹ́ nígbà tí a ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará ní apá ibòmíràn nínú ìlú-ńlá náà, nítorí náà a kó wa yọ lọ́nà pípẹtẹrí. Ní alẹ́ ọjọ́ kan náà yẹn, ìdílé Ẹlẹ́rìí kan sálọ sí ibi ìforípamọ́ àdúgbò. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọn rí i pé ó ti kún wọ́n sì níláti darí sí ilé wọn. Wọn ju bọ́m̀bù lu ibi ìforípamọ́ náà látòkè, gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú rẹ̀ sì kú, ṣùgbọ́n àwọn ará wa yè é pẹ̀lú ọgbẹ́ àti ìfarapa níwọ̀nba. Ní àwọn ọdún ogun lílekoko wọ̀nyí, kò sí ọ̀kan lára àwọn ará wa tí a palára púpọ̀, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún èyí.
Ìpèsè Oúnjẹ Tẹ̀mí
Bí ogun náà ti ń tẹ̀síwájú, ìkálọ́wọ́kò ń le síi, àti lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí tú àwọn ohun tí a bá fi ránṣẹ́ wò. Èyí túmọ̀ sí pé Ilé-Ìṣọ́nà ni a bẹ́gidí tí a kò sì jẹ́ kí ó wọnú orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí a lè ṣe, ọwọ́ Jehofa kò kúrú. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan mo rí lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ “ọmọ ẹ̀gbọ́n” mi ní Canada ẹni tí ó kọ̀wé sí mi nípa àwọn ọ̀ràn ìdílé. Nkò ní èrò kankan nípa ẹni tí ó jẹ́, ṣùgbọ́n ó sọ nínú àwọn àkọsílẹ̀ kúkúrú tí ó fi kún lẹ́tà náà pé òun fi “ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Bibeli kan tí ó gbádùnmọ́ni” síbẹ̀ fún mi láti kà. Ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà ni ó jẹ́, ṣùgbọ́n nítorí pé èpo ẹ̀yìn ìwé rẹ̀ funfun báláú, àwọn tí ń tú nǹkan wò kò yọ ọ́ kúrò.
Lójú ẹsẹ̀ èmi àti aya mi, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò, títíkan Maggie Cooper tí ó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ sinimá “Photo-Drama,” bẹ̀rẹ̀ síí ṣe àdàkọ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà. Kò pẹ́ tí a fi ṣètò ara wa láti fi 120 ẹ̀dà ránṣẹ́ yíká orílẹ̀-èdè náà, níwọ̀n bí ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà tí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ funfun báláú ti ń dé déédéé láti ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ titun ní Canada, Australia, àti United States. Ọpẹ́lọpẹ́ aápọn àti inúrere wọn, a kò tàsé ìtẹ̀jáde kan jálẹ̀ gbogbo àkókò ogun náà.
Ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn àpéjọ pẹ̀lú. Èyí tí ó jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ ni ti àpéjọpọ̀ 1941 nígbà tí a mú ìtẹ̀jáde titun náà Children jáde. Ó dàbí ẹni pé olùtú nǹkan wò náà kò lòdì sí ìwé tí ó ronú pé ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọdé, nítorí náà a tiraka láti mú èyí tí ó jẹ́ tiwa wọnú orílẹ̀-èdè náà láìsí ìṣòro! Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, a ní ìwé kékeré náà Peace—Can It Last? tí a tẹ̀ jáde ní àdúgbò nítorí pé kò ṣeé ṣe láti kó àwọn ẹ̀dà wọlé láti London. Láìka àwọn ìkálọ́wọ́kò tí a gbékarí wa sí, a ń rí àbójútó dáradára nípa tẹ̀mí.
Bíborí Àtakò
Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan tí ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ní Belfast ti Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ń bójútó fi ẹ̀dà kan lára ìwé Riches ránṣẹ́ sí aya rẹ̀ ní England. Obìnrin náà ń ṣàtakò sí òtítọ́, ó sì mú kókó yẹn ṣe kedere nínú èsì rẹ̀. Ó tún sọ pé a jẹ́ “ètò-àjọ tí kò ní ìfọkànsìn fún orílẹ̀-èdè.” Àwọn tí ń tú àwọn ohun tí a ń fi ránṣẹ́ wò gbé èyí pọ́nkán wọn sì ròyìn ọ̀ràn náà fún Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde, wọ́n késí mi lọ sí bárékè àwọn ọlọ́pàá láti fún wọn ní àlàyé wọ́n sì ní kí n mú ẹ̀dà ìwé Riches kan dání. Ó dùn mọ́ mi pé, nígbà tí wọ́n dá ìwé náà padà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo ṣàkíyèsí pé àwọn apá tí wọ́n sàmì sí pátá jẹ́ nípa Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki. Mo nímọ̀lára pé èyí ṣe pàtàkì, níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé àwọn ọlọ́pàá wà lójúfò sí ìgbòkègbodò àwọn IRA (Ẹgbẹ́ Ọmọ-Ogun Ìlú Aláààrẹ ti Ireland).
Wọ́n fi ìbéèrè fínnífínní wádìí ọ̀rọ̀ wo lẹ́nu mi nípa àìdásí tọ̀tún tòsì wa ní àwọn àkókò ogun, nítorí pé àwọn ọlọ́pàá rí i pé ó ṣòro láti lóye ìdúró wa. Ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ kò gbé ìgbésẹ̀ kan lòdì sí wa rí. Lẹ́yìn náà, nígbà tí mo béèrè fún ìyọ̀ǹda láti ṣe àpéjọ kan, àwọn ọlọ́pàá tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé àwọn yóò rán àwọn ọlọ́pàá oníròyìn méjì wá síbẹ̀. Mo wí pé, “Àwa yóò tẹ́wọ́gbà wọ́n!” Nítorí náà wọ́n wá wọ́n sì jókòó títí tí ìpàdé ti ọ̀sán fi kọjá, wọ́n ń kọ àkọsílẹ̀ kúkúrú. Ní òpin àkókò ìjókòó náà, wọ́n béèrè pé, “Èéṣe tí a fi rán wa wá sí ibi yìí? Gbogbo rẹ̀ ń gbádùn mọ́ wa!” Wọ́n tún padà wá ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi tayọ̀tayọ̀ gba ẹ̀dà ọ̀fẹ́ ti ìwé wa kékeré náà Peace—Can It Last? Apá yòókù lára àpéjọ náà parí láìsí họ́ùhọ́ù.
Ní kété tí ogun náà parí tí ìkálọ́wọ́kò nípa ìrìn-àjò sì rọjú, Pryce Hughes láti Beteli ti London wá sí Belfast. Harold King, tí a yanṣẹ́ fún lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní China, bá a wá. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí a ti fi ọ́fíìsì ẹ̀ka ti London sílẹ̀, gbogbo wa ni a fún ní ìṣírí gidigidi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀-àsọyé tí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fi fúnni. Ní kété lẹ́yìn náà, Harold Duerden, aṣáájú ọ̀nà olùṣòtítọ́ mìíràn, ni a rán wá láti England láti fún iṣẹ́ Ìjọba náà lókun ní Belfast.
Pípadà sí England
A ti mú ìfẹ́ dàgbà fún àwọn ará ní Ireland, ó sì ṣòro láti padà sí England. Ṣùgbọ́n a padà yan èmi àti aya mi sí Manchester lẹ́yìn náà ni a sì ṣílọ sí Newton-le-Willows, ìlú Lancashire mìíràn níbi tí àìní gbé pọ̀ jù. Lois, ọmọbìnrin wa, ni a bí ní 1953, ó sì ń mọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti rí i tí ó wọnú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ẹni ọdún 16. Lẹ́yìn tí ó ti ṣègbéyàwó pẹ̀lú David Parkinson tí ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, wọ́n ń bá iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún wọn lọ ní Northern Ireland, wọ́n ń tọ ipasẹ̀ kan náà tí èmi àti Olive ti tọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Nísinsìnyí, àwọn àti àwọn ọmọ wọn ti padà sí England, gbogbo wa sì ń ṣiṣẹ́sìn nínú ìjọ kan náà.
Láìka àwọn ìyípadà tí ń bẹ nínú àwọn àyíká-ipò wa sí, n kò dáwọ́ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà dúró—Olive kò fẹ́ bẹ́ẹ̀, èmi pẹ̀lú kò sì fẹ́. Nígbà gbogbo ni mo máa ń ní ìmọ̀lára pé yóò jẹ́ ohun yíyẹ láti ṣàjọpín àkọsílẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú aya mi nítorí pé láìsí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí kì í yẹ̀, kì bá tí ṣeé ṣe fún mi láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún. Àmọ́ ṣáá o, ó tètè máa ń rẹ àwa méjèèjì nísinsìnyí, ṣùgbọ́n jíjẹ́rìí ṣì jẹ́ ìdùnnú, ní pàtàkì jùlọ nígbà tí a bá wà papọ̀, tí a ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa. Láti ọdún wọ̀nyí wá, a ti ní àǹfààní láti ran nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún ènìyàn lọ́wọ́ láti di olùṣèyàsímímọ́ ìránṣẹ́ Jehofa, tí a batisí. Ẹ wo bí ìyẹn ti jẹ́ ohun ìdùnnú tó! Mo sì ronú pé iye yìí ti gbọ́dọ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po-ìlọ́po nísinsìnyí níwọ̀n bí àwọn ìdílé tí ń gbòòrò títí lọ dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin pẹ̀lú ti di Ẹlẹ́rìí.
Èmi àti Olive sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àǹfààní àti ìrírí tí a ti ní láti ọdún wọ̀nyí wá. Ẹ wo bí wọ́n ti jẹ́ ọdún tí ń máyọ̀ wá tó, ẹ sì wo bí wọ́n ṣe yára kọjá lọ tó! Mo mọ̀ pé ń kò lè rí ohunkóhun tí ó dára ju láti lo ìgbésí-ayé mi fún ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun mi, Jehofa, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Nísinsìnyí, yálà mo ń wẹ̀yìn padà pẹ̀lú ìdúpẹ́ tàbí mo ń wo iwájú pẹ̀lú ìfojúsọ́nà, mo rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ Jeremiah ní ìtumọ̀ púpọ̀: “Àánú Oluwa ni, tí àwa kò parun tán, nítorí ìrọ́nú àánú rẹ̀ kò ní òpin. Ọ̀tun ni ní òròòwúrọ̀ . . . nítorí náà ni èmi ṣe retí nínú rẹ̀.”—Ẹkún Jeremiah 3:22-24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Bob àti Olive Anderson