Àwọn Àǹfààní Bíbẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́
“Èmi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, tí ó kọ́ ọ fún èrè, ẹni tí ó tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ ìbá máa lọ.”—ISAIAH 48:17.
1. Àwọn àjálù-ibi wo ni ìbẹ̀rù Ọlọrun ìbá ti mú kí a dènà rẹ̀?
BÍ Ó bá jẹ́ pé Adamu ti mú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà ni, ìbá ti ká a lọ́wọ́ kò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yọrí sí ikú ayérayé àti sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún oníbànújẹ́ fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Bí orílẹ̀-èdè Israeli ìgbàanì bá ti fetí sí ìmọ̀ràn Jehofa láti bẹ̀rù rẹ̀ kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a kì bá tí kó orílẹ̀-èdè náà nígbèkùn lọ sí Babiloni, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì bá tí ṣá Ọmọkùnrin Ọlọrun tì kí wọ́n sì jẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Bí ayé lónìí bá bẹ̀rù Ọlọrun, ìbá má sí ìwà ìbàjẹ́ nínú àkóso tàbí lẹ́nu iṣẹ́-ajé, ìbá má sí ìwà-ipá, ìbá má sí ogun.—Owe 3:7.
2. Láìka àwọn ipò tí ó wà nínú ayé tí ó yí wa ká sí, èéṣe tí a fi níláti mú ìbẹ̀rù Jehofa dàgbà?
2 Bí ó ti wù kí ó rí, láìka ohun tí ayé tí ó yí wa ká ń ṣe sí, àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìdílé, àti gẹ́gẹ́ bí ìjọ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lè jàǹfààní láti inú mímú ìbẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́ dàgbà. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìránnilétí tí Mose fún orílẹ̀-èdè Israeli pé: “Kí ni OLUWA Ọlọrun rẹ ń béèrè lọ́dọ̀ rẹ, bíkòṣe láti máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ gbogbo, láti máa fẹ́ ẹ, àti láti máa sin OLUWA Ọlọrun rẹ pẹ̀lú àyà rẹ gbogbo, àti pẹ̀lú ọkàn rẹ gbogbo, láti máa pa òfin OLUWA mọ́, . . . fún ire rẹ?” (Deuteronomi 10:12, 13) Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí ń wá sọ́dọ̀ wa nígbà tí a bá bẹ̀rù Jehofa, Ọlọrun tòótọ́?
Ọgbọ́n—Ó Ṣe Iyebíye Ju Wúrà Lọ
3. (a) Kí ni àǹfààní tí ó gba iwájú jùlọ tí a lè rí gbà? (b) Kí ni ìtumọ̀ Orin Dafidi 111:10?
3 Àǹfààní tí ó gba iwájú jùlọ ni ọgbọ́n tòótọ́. Orin Dafidi 111:10 polongo pé: “Ìbẹ̀rù Oluwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n.” Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ọgbọ́n ni agbára-ìṣe láti lo ìmọ̀ lọ́nà yíyọrísírere láti lè yanjú àwọn ìṣòro, yẹra fún ewu, kí a sì lé àwọn góńgó kan pàtó bá. Ó ní ìdájọ́ yíyèkooro nínú. Èyí tí ó ṣáájú, apá àkọ́kọ́, tí ó pilẹ̀ irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀, ni ìbẹ̀rù Jehofa. Èéṣe? Nítorí pé gbogbo ìṣẹ̀dá jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ó sinmi lé e. Ó fi òmìnira ìfẹ́-inú jíǹkí ìran ènìyàn ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú agbára-ìṣe láti darí ìgbésẹ̀ ara wọn lọ́nà tí ó lè yọrísírere láìsí ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (Joṣua 24:15; Jeremiah 10:23) Kìkì bí a bá mọrírì àwọn lájorí kókó abájọ nípa ìwàláàyè tí a sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn ni a fi lè ní àṣeyọrí pípẹ́títí. Bí ìmọ̀ wa nípa Jehofa bá fún wa ní ìdánilójú tí kò lè yẹ̀ pé ìfẹ́-inú Ọlọrun dájú láti ṣàṣeyọrí àti pé ìlérí rẹ̀ àti agbára-ìṣe láti san èrè ìṣòtítọ́ dájú, nígbà náà ìbẹ̀rù Ọlọrun yóò sún wa láti hùwà pẹ̀lú ọgbọ́n.—Owe 3:21-26; Heberu 11:6.
4, 5. (a) Èéṣe tí ẹ̀kọ́-ìwé yunifásítì ọ̀dọ́mọkùnrin kan kò fi fún un ní ọgbọ́n tòótọ́? (b) Báwo ni ọkùnrin yìí àti aya rẹ̀ ṣe jèrè ọgbọ́n tòótọ́ gidi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀nà wo ni èyí sì gbà yí ìgbésí-ayé wọn padà?
4 Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀wò. Ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀dọ́mọkùnrin kan ń lọ sí University of Saskatchewan, ní Canada. Ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ ètò ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì kọ́ ọ ní ẹfolúṣọ̀n. Lẹ́yìn gbígboyè jáde, ó di ògbóǹkangí nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa agbára átọ́míìkì, ó sì gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti máa bá ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ ní University of Toronto. Bí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́, ó rí àwọn àgbàyanu ẹ̀rí nípa ètò àti iṣẹ́-ọnà tí ń bẹ nínú àwọn ìgbékalẹ̀ átọ́ọ̀mù. Ṣùgbọ́n a kò pèsè ìdáhùn kankan sí àwọn ìbéèrè náà pé: Ta ni ó ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Nígbà wo? Èésìtiṣe? Láìsí àwọn ìdáhùn wọ̀nyẹn, ó ha lè ṣeé ṣe fún un láti lo ìmọ̀ rẹ̀ lọ́nà ọgbọ́n nínú ayé tí ó wà nínú ogun nígbà yẹn bí? Kí ni yóò tọ́ ọ sọ́nà? Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ha ni bí? Ìfẹ́-ọkàn fún èrè ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ha ni bí? Níti gidi, òun ha ti jèrè ọgbọ́n tòótọ́ bí?
5 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgboyèjáde rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin yẹn àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnra rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìdáhùn tí wọ́n ti ń pàdánù tẹ́lẹ̀. Wọ́n wá mọ Ẹlẹ́dàá náà, Jehofa Ọlọrun. Bí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Mose ní Òkun Pupa àti nípa Danieli àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní Babiloni, wọ́n kọ́ ìjẹ́pàtàkì bíbẹ̀rù Ọlọrun kì í ṣe bíbẹ̀rù ènìyàn. (Eksodu 14:10-31; Danieli 3:8-30) Irú ìbẹ̀rù Ọlọrun lọ́nà bẹ́ẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú ojúlówó ìfẹ́ fún Jehofa bẹ̀rẹ̀ sí sún wọn ṣiṣẹ́. Láìpẹ́, ipa ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn látòkèdélẹ̀ yípadà. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín ọ̀dọ́mọkùnrin yìí mọ Ẹni náà tí òun ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀dá. Ó bẹ̀rẹ̀ síí lóye ète Ẹni náà tí òun ti rí ìfihàn ọgbọ́n rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa physics. Dípò lílo ìmọ̀ rẹ̀ láti ṣe àwọn ohun èèlò tí yóò pa àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ run, òun àti ìyàwó rẹ̀ fẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti fẹ́ràn Ọlọrun àti láti fẹ́ràn aládùúgbò wọn. Wọ́n forúkọ sílẹ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí olùpolongo Ìjọba Ọlọrun. Nígbà tí ó yá, wọ́n lọ sí Watchtower Bible School of Gilead a sì rán wọn jáde gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì.
6. Bí a bá ní ọgbọ́n tí ó fìdímúlẹ̀ nínú ìbẹ̀rù Jehofa, àwọn ìlépa olójú-ìwòye kúkúrú wo ni a óò yẹra fún, kí sì ni a óò máa ṣe dípò ìyẹn?
6 Níti tòótọ́, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè jẹ́ míṣọ́nnárì. Ṣùgbọ́n gbogbo wa lè gbádùn ọgbọ́n tí ó fìdímúlẹ̀ nínú ìbẹ̀rù Jehofa. Bí a bá mú ọgbọ́n yẹn dàgbà, a kì yóò háragàgà ní gbígba ọgbọ́n èrò-orí àwọn ènìyàn tí wọ́n wulẹ̀ ń méfò lásán nípa ohun tí ìgbésí-ayé jẹ́ níti gidi sínú wa. A óò máa mú ìgbésí-ayé wa bá Bibeli mu, èyí tí ó ní ìmísí Orísun ìwàláàyè, Jehofa Ọlọrun, ẹni náà tí ó lè fún wa ní ìyè ayérayé. (Orin Dafidi 36:9; Kolosse 2:8) Dípò dídi ẹrú fún ètò ìṣòwò tí òun fúnra rẹ̀ ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ní bèbè àtidojúdé, a óò fetí sí ìmọ̀ràn Jehofa láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú oúnjẹ àti ìbora, bí a ti ń fi ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun ṣe ohun tí ó gba iwájú jùlọ nínú ìgbésí-ayé. (1 Timoteu 6:8-12) Dípò gbígbégbèésẹ̀ bí ẹni pé ọjọ́-ọ̀la wa sinmi lé lílépa ọrọ̀ nínú ayé yìí, a óò gba Ọ̀rọ̀ Jehofa gbọ́ nígbà tí ó sọ fún wa pé ayé sì ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ni yóò dúró títíláé.—1 Johannu 2:17.
7. (a) Báwo ni Owe 16:16 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye tí ó wàdéédéé nípa ọ̀pá-ìdiwọ̀n? (b) Èrè wo ní ń wá láti inú mímú kí ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí-ayé wa?
7 Owe 16:16 fún wa ní ìṣírí nípa sísọ níti tòótọ́ pé: “Láti ní ọgbọ́n [ọgbọ́n tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jehofa], mélòómélòó ni ó sàn ju wúrà lọ; àti láti ní òye, mélòó mélòó ni ó dára ju fàdákà lọ.” Irú ọgbọ́n àti òye bẹ́ẹ̀ yóò sún wa láti sọ ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun di ohun pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé wa. Kí sì ni iṣẹ́ tí Ọlọrun ti yàn fún àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún sáà yìí nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn? Wíwàásù nípa Ìjọba rẹ̀ àti ríran àwọn aláìlábòsí-ọkàn lọ́wọ́ láti di ojúlówó ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Kristi. (Matteu 24:14; 28:19, 20) Èyí ni iṣẹ́ tí ń mú èrè ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́ àti ayọ̀ púpọ̀ wá. Pẹ̀lú ìdí rere, nígbà náà, Bibeli sọ pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó wá ọgbọ́n rí.”—Owe 3:13.
Ìdáàbòbò Kúrò Lọ́wọ́ Ìwà Àìtọ́
8. (a) Mẹ́nukan àǹfààní kejì tí ń wá láti inú bíbẹ̀rù Ọlọrun. (b) Ohun búburú wo ni a ń dáàbòbò wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀? (d) Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọrun ṣe di ipá asúnniṣiṣẹ́ lílágbára?
8 Àǹfààní kejì tí ń wá láti inú bíbẹ̀rù Ọlọrun ni pé a ń tipa bẹ́ẹ̀ dáàbòbò wá kúrò lọ́wọ́ ṣíṣe ohun búburú. Àwọn wọnnì tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọrun kì í dá pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú. Wọn kì í fojúwo ohun tí Ọlọrun sọ pé ó dára gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó burú, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kìí ka àwọn ohun tí Ọlọrun sọ pé ó burú sí ohun tí ó dára. (Orin Dafidi 37:1, 27; Isaiah 5:20, 21) Síwájú síi, ẹnì kan tí ìbẹ̀rù Ọlọrun ń sún ṣiṣẹ́ kì í fi ọ̀ràn mọ sórí mímọ ohun tí Jehofa sọ pé ó dára àti ohun tí ó sọ pé ó burú nìkan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jehofa nífẹ̀ẹ́ ó sì kórìíra ohun tí Jehofa kórìíra. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ó ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun. Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ nínú Owe 16:6, “nípa ìbẹ̀rù Oluwa, ènìyàn a kúrò nínú ibi.” Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ fún Ọlọrun di ipá asúnniṣiṣẹ́ lílágbára láti ṣàṣeyọrí ohun tí ẹnì kan lè má lè ṣe pẹ̀lú agbára òun fúnra rẹ̀.
9. Báwo ni ìfẹ́-ọkàn lílágbára láti máṣe ba Ọlọrun nínú jẹ́ ṣe nípa ìdarí lórí ìpinnu obìnrin kan ní Mexico, kí sì ni àbárèbábọ̀ rẹ̀?
9 Àní bí ìbẹ̀rù Ọlọrun bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nínú ẹnì kan, ó lè mú un gbaradì láti yẹra fún ṣíṣe ohun kan tí òun yóò kábàámọ̀ fún gbogbo ìyókù ìgbésí-ayé rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin aboyún kan ní Mexico béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nípa oyún ṣíṣẹ́. Ẹlẹ́rìí náà ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ mélòókan fún obìnrin náà, ó sì ṣàlàyé pé: “Lójú Ẹlẹ́dàá, ìwàláàyè ṣe pàtàkì, àní ìwàláàyè àwọn wọnnì tí a kò tí ì bí pàápàá.” (Eksodu 21:22, 23; Orin Dafidi 139:13-16) Àyẹ̀wò ìṣègùn ti fi hàn pé ọmọ náà lè jẹ́ abirùn. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, bí a ti sún un nípasẹ̀ ohun tí ó rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, obìnrin náà pinnu láti bí ọmọ rẹ̀. Dókítà rẹ̀ sọ pé òun kò fẹ́ rí i mọ́, ọkọ rẹ̀ sì halẹ̀ láti já a jù sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúróṣinṣin. Níkẹyìn, ó bí ọmọbìnrin kan—tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, tí ó lera, tí ó sì rẹwà. Bí ìmoore ti sún un, ó wá àwọn Ẹlẹ́rìí kàn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pẹ̀lú rẹ̀. Láàárín ọdún kan, òun àti ọkọ rẹ̀ ṣe ìrìbọmi. Ní ọdún mélòókan lẹ́yìn náà, ní àpéjọpọ̀ àgbègbè kan, inú wọn dùn láti pàdé Ẹlẹ́rìí náà tí ó ti kọ́kọ́ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ wọ́n sì mú un mọ ọmọbìnrin wọn rèǹtèrente ẹni ọdún mẹ́rin. Ó dájú pé ọ̀wọ̀ tí ó yẹ fún Ọlọrun àti ìfẹ́-ọkàn lílágbára láti máṣe bà á nínú jẹ́ ń ní agbára ìdarí lílágbára lórí ìgbésí-ayé ẹnì kan.
10. Irú àwọn ìwà àìtọ́ wo ni ìbẹ̀rù Ọlọrun lè mú àwọn ènìyàn gbaradì fún láti ja àjàbọ́ lọ́wọ́ wọn?
10 Ìbẹ̀rù Ọlọrun ń mú wa gbaradì lòdì sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwà àìtọ́. (2 Korinti 7:1) Nígbà tí a bá mú un dàgbà dáradára, ó lè ràn ẹnì kan lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀, tí ó jẹ́ pé òun àti Jehofa nìkan ni ó hàn sí. Ó lè ràn án lọ́wọ́ láti ja àjàbọ́ lọ́wọ́ dídi ẹrú àṣìlò oògùn àti ìmukúmu ọtí. Asoògùn di bárakú kan ṣàlàyé ní South Africa láìpẹ́ yìí pé: “Bí mo ti ń gba ìmọ̀ Ọlọrun sọ́kàn, mo tún mú ìbẹ̀rù fún ṣíṣe ohun tí ó lè dùn ún tàbí mú un banújẹ́ dàgbà. Mo mọ̀ pé ó ń wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀, mo sì ń yánhànhàn láti ní ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ̀. Èyí sún mi láti run àwọn oògùn tí ó wà lọ́wọ́ mi nípa dídà wọ́n sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀.” Ìbẹ̀rù Ọlọrun ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́wọ́ lọ́nà kan náà.—Owe 5:21; 15:3.
Ààbò Kúrò Lọ́wọ́ Ìfòyà Ènìyàn
11. Ìdẹkùn tí ó wọ́pọ̀ wo ni ìbẹ̀rù tí ó gbámúṣé fùn Jehofa lè dáàbòbò wa kúrò lọ́wọ́ rẹ̀?
11 Ìbẹ̀rù tí ó gbámúṣé fún Ọlọrun tún máa ń dáàbòbò wá kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ènìyàn. Àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jùlọ ni ìbẹ̀rù ènìyàn ti pọ́nlójú dé ìwọ̀n gíga tàbí níwọ̀nba díẹ̀. Àwọn aposteli Jesu Kristi pàápàá pa á tì wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ nígbà tí àwọn ọmọ-ogun gbá a mú ní ọgbà Getsemane. Lẹ́yìn náà, nínú àgbàlá olórí àlùfáà, nítorí tí ó ṣi inú rò tí ìbẹ̀rù ènìyàn sì ti pa á sára, Peteru sẹ pé òun kì í ṣe ọkàn lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àti pé òun kò tilẹ̀ mọ̀ ọ́n rí. (Marku 14:48-50, 66-72; Johannu 18:15-27) Ṣùgbọ́n a ran àwọn aposteli náà lọ́wọ́ láti jèrè ìwàdéédéé tẹ̀mí wọn padà. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ní àwọn ọjọ́ Ọba Jehoiakimu, Urijah ọmọ Ṣemaiah di ẹni tí ìbẹ̀rù borí rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi pá iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jehofa tì ó sì sá kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n a gbá a mú a sì pa á.—Jeremiah 26:20-23.
12. (a) Ààbò wo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ènìyàn ni Owe 29:25 tọ́ka sí? (b) Báwo ni a ṣe ń mú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun dàgbà?
12 Kí ni ó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ìbẹ̀rù ènìyàn? Lẹ́yìn kíkìlọ̀ pé “ìbẹ̀rù ènìyàn níí mú ìkẹkùn wá,” Owe 29:25 fikún un pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Oluwa ni a óò [dáàbòbò, NW].” Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa ni kọ́kọ́rọ́ náà. Irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ sinmi lórí ìmọ̀ àti ìrírí. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a ń rí ẹ̀rí bí àwọn ọ̀nà Jehofa ṣe tọ́ tó. A ń di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń fi bí ó ti ṣeé gbáralé tó hàn, ẹ̀rí ìdánilójú àwọn ìlérí rẹ̀ (títíkan ti àjíǹde), ìfẹ́ rẹ̀ àti agbára gígalọ́lá rẹ̀. Lẹ́yìn náà nígbà tí a bá gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ yẹn, tí a ń ṣe àwọn ohun tí Jehofa pàṣẹ tí a sì ń fi ìdúróṣinṣin kọ ohun tí ó kìlọ̀ lòdì sí, a óò bẹ̀rẹ̀ sí ní ìrírí àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìṣeégbáralé rẹ̀ ní tààràtà. Àwa fúnra wa óò rí ẹ̀rí pé agbára rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ láti lè mú ìfẹ́-inú rẹ̀ ṣẹ. Ìgbọ́kànlé wa nínú rẹ̀ yóò máa gbèrú síi àti, pẹ̀lú ìyẹn, ìfẹ́ wa fún un àti ìfẹ́-ọkàn wa àtinúwá láti yẹra fún bíbà á nínú jẹ́ yóò máa gbèrú síi. A kọ́ irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ tí ó dúró gbọn-in-gbọn-in. Ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí odi-ààbò lòdì sí ìbẹ̀rù ènìyàn.
13. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọrun ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, nínú ilé, àti ní ilé-ẹ̀kọ́?
13 Níní tí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa, papọ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọrun, yóò mú kí a dúró ṣinṣin fún ohun tí ó tọ́ bí agbanisíṣẹ́ kan bá fi pípàdánù iṣẹ́ wa halẹ̀ mọ́ wa nítorí pé a kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà alábòsí nínú iṣẹ́-ajé. (Fiwé Mika 6:11, 12.) Irú ìbẹ̀rù Ọlọrun bẹ́ẹ̀ ń ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristian lọ́wọ́ láti fàyàrán an nínú ìjọsìn tòótọ́ lójú àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ó tún ń fún àwọn ọ̀dọ́ tí ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ní ìgboyà láti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì tún ń mú wọn gbaradì láti farada yẹ̀yẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ilé-ẹkọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń fi ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli tayín. Nípa bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́rìí kan tí kò tí ì pé ogún ọdún sọ pé: “Ohun tí wọ́n ń rò kò jámọ́ nǹkankan níti tòótọ́. Ohun tí Jehofa ń rò ni ó ṣe pàtàkì jù.”
14. Báwo ni ó ṣe lè ṣeé ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lati jagunmólú àní nígbà tí a bá tilẹ̀ wu ìwàláàyè wọn léwu?
14 Ìdánilójú kan náà ń fún àwọn Kristian tòótọ́ lókun láti dúró ṣinṣin ní ọ̀nà Jehofa nígbà tí a bá wu ìwàláàyè wọn léwu pàápàá. Wọ́n mọ̀ pé àwọn níláti máa retí inúnibíni láti ọ̀dọ̀ ayé. Wọ́n rántí pé a na àwọn aposteli lẹ́gba àti pé Jesu Kristi fúnra rẹ̀ ni àwọn ẹni ibi lù tí wọ́n sì pa. (Marku 14:65; 15:15-39; Iṣe 5:40; fiwé Danieli 3:16-18.) Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé òun lè fún wọn lókun láti faradà á; pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun wọ́n lè jagunmólú; pé Jehofa kì yóò kùnà láti san èrè fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá jẹ́ olùṣòtítọ́—àní nípa àjíǹde sí ìwàláàyè nínú ayé titun rẹ̀ bí ó bá pọndandan. Ìfẹ́ wọn fún Ọlọrun papọ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọrun ń fi tagbára tagbára sún wọn láti yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tí yóò bà á nínú jẹ́.
15. Kí ni ó mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti di ìwàtítọ́ wọn mú nínú àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi?
15 Ìsúnniṣe yìí mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti fàyàrán ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi ní àwọn ọdún 1930 àti 1940. Wọ́n fi ìmọ̀ràn Jesu tí a rí nínú Luku 12:4, 5 sọ́kàn pé: “Mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀rù awọn wọnnì tí ń pa ara ati lẹ́yìn èyí tí wọn kò lè ṣe nǹkankan jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣugbọn emi yoo tọ́kafihàn fún yín ẹni tí ẹ níláti bẹ̀rù: Ẹ bẹ̀rù ẹni naa tí ó jẹ́ pé lẹ́yìn pípani ó ní ọlá-àṣẹ lati sọni sínú Gẹ̀hẹ́nà. Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, Ẹni yii ni kí ẹ bẹ̀rù.” Nípa báyìí, Gustav Auschner, Ẹlẹ́rìí kan tí ó wà ní ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen, kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: ‘Àwọn SS yìnbọn pa August Dickmann wọ́n sì halẹ̀ láti yìnbọn pa àwa yòókù bí a kò bá fọwọ́ sí ìwé pé a kọ ìgbàgbọ́ wa sílẹ̀. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí ó fọwọ́ sí i. Ìbẹ̀rù tí a ní fún bíba Jehofa nínú jẹ́ pọ̀ ju èyí tí a ní fún ọta ìbọn wọn lọ.’ Ìbẹ̀rù ènìyàn ń yọrí sí ìjuwọ́sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Ọlọrun ń mú ki ẹnì kan dúró ṣinṣin fún ohun tí ó tọ́.
Pípa Ìwàláàyè Mọ́
16. Kí ni ó mú kí ó ṣeé ṣe fún Noa láti lè máa rìn ní ipa ọ̀nà títọ́ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún títí di ìgbà Àkúnya Omi, kí sì ni àbájáde rẹ̀ fún òun àti agbo ìdílé rẹ̀?
16 Noa gbé ayé jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé tí ó wà ṣáájú Ìkún-Omi. Jehofa ti pinnu láti pa ayé búburú ìgbà náà run nítorí ìwà-ibi ènìyàn. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín àkókò náà, Noa wà nínú ayé náà tí ó kún fún ìwà-ipá, ìwà pálapàla tí ó lékenkà, àti àìbìkítà fún ìfẹ́-inú Ọlọrun. Láìka ìwàásù òdodo Noa sí, “wọn kò sì fiyèsí i títí ìkún-omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Matteu 24:39) Síbẹ̀ Noa kò jáwọ́ nínú iṣẹ́ náà tí Ọlọrun gbé ka iwájú rẹ̀. Ó ṣe “gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ọlọrun pàṣẹ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe.” (Genesisi 6:22) Kí ni ó mú kí ó ṣeé ṣe fún Noa láti lè máa rìn ní ọ̀nà títọ́ bí ọdún ti ń gorí ọdún títí di ìgbà Àkúnya Omi náà? Heberu 11:7 dáhùn pé: “Nipa ìgbàgbọ́ ni Noa, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nipa awọn ohun tí a kò tí ì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn.” Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, a pa òun àti aya rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti aya wọn mọ́ láàyè la Àkúnya Omi náà já.
17. (a) Láìka ohun tí àwọn ènìyàn mìíràn lè ṣe sí, kí ni a níláti ṣe? (b) Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Jehofa ni ènìyàn aláyọ̀ níti tòótọ́?
17 A ń gbé nínú sáà kan tí ó farajọ ti ọjọ́ Noa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. (Luku 17:26, 27) Ìkìlọ̀ tún ti ń dún lẹ́ẹ̀kan síi. Ìṣípayá 14:6, 7 sọ nípa áńgẹ́lì kan tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run tí ń rọ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo àti ẹ̀yà àti ahọ́n láti ‘bẹ̀rù Ọlọrun kí wọ́n sì fi ògo fún un.’ Láìka ohun tí ayé tí ó yí ọ ká ń ṣe sí, ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, kí o sì nawọ́ ìkésíni náà sí àwọn ẹlòmíràn. Bíi ti Noa, hùwà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kí o sì fi ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ rẹ lè yọrí sí pípa ìwàláàyè rẹ àti ti àwọn ẹlòmíràn mọ́. Bí a ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àǹfààní tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́ ń gbádùn, kìkì ohun tí a lè ṣe ni láti fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú onipsalmu náà tí ó kọrin pé: “Aláyọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Jehofa, tí inú rẹ̀ sì dùn jọjọ sí àwọn òfin rẹ̀.”—Orin Dafidi 112:1, NW.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní títayọlọ́lá tí ó wà nínú bíbẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́?
◻ Báwo ni ọgbọ́n tí ó fìdímúlẹ̀ nínú ìbẹ̀rù Ọlọrun ṣe lè dáàbòbò wá?
◻ Èéṣe tí ìbẹ̀rù Ọlọrun fi ń mú wa yẹra fún ohun tí ó burú?
◻ Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọrun ṣe ń dáàbòbò wá kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ènìyàn?
◻ Ìbátan wo ni ìbẹ̀rù Ọlọrun ní lórí ìfojúsọ́nà wa fún ìwàláàyè wa ọjọ́-ọ̀la?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
“Aláyọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Jehofa, tí inú rẹ̀ sì dùn jọjọ sí àwọn òfin rẹ̀.”—Orin Dafidi 112:1, NW