Àwọn Àgùntàn Jehofa Nílò Àbójútó Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
“Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé [Jehofa, NW], òun ni Ọlọrun . . . àwa ni ènìyàn rẹ̀, àti àgùntàn pápá rẹ̀.”—ORIN DAFIDI 100:3.
1. Báwo ni Jehofa ṣe ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò?
JEHOFA ni Olùṣọ́ Àgùntàn Títóbi Lọ́lá. Bí a bá jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, òun yóò máa wò wá gẹ́gẹ́ bí àgùntàn rẹ̀, yóò sì máa fún wa ní àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Bàbá wa ọ̀run ń tù wá nínú, ó ń tù wá lára, ó sì ń sìn wa lọ ní “ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.” (Orin Dafidi 23:1-4) Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà, Jesu Kristi, nífẹ̀ẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.—Johannu 10:7-15.
2. Inú ipò wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ti bá ara wọn?
2 Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń rí àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gbà, a lè sọ gẹ́gẹ́ bí onipsalmu náà pé: “Ẹ fi ayọ̀ sin Oluwa: ẹ wá ti ẹ̀yin ti orin sí iwájú rẹ̀. Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé [Jehofa, NW], òun ni Ọlọrun: òun ni ó dá wa, tirẹ̀ ni àwa; àwa ni ènìyàn rẹ̀, àti àgùntàn pápá rẹ̀.” (Orin Dafidi 100:2, 3) Dájúdájú, inú wa ń dùn, a sì ń dáàbò bò wá. Ṣe ni ó dà bíi pé, a dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn onínú burúkú adọdẹ nínú agbo àgùntàn, tí a fi òkúta lílágbára mọ odi yí ká.—Numeri 32:16; 1 Samueli 24:3; Sefaniah 2:6.
Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Olùfi Tìfẹ́-inú Tìfẹ́-inú Bójú Tó Agbo
3. Báwo ni àwọn Kristian alàgbà tí a yàn sípò ṣe ń bá agbo Ọlọrun lò?
3 Abájọ tí inú wa fi ń dùn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn Ọlọrun! Àwọn alàgbà tí a yàn sípò ń mú ipò iwájú láàárín wa. Wọn kò ‘fi ara wọn jẹ aládé,’ wọn kì í jẹ olúwa lé wa lórí, tàbí gbìyànjú láti jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wa. (Numeri 16:13; Matteu 20:25-28; 2 Korinti 1:24; Heberu 13:7) Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ tí ń fi ìmọ̀ràn aposteli Peteru sílò pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bíkòṣe tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nitori ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bíkòṣe pẹlu ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni ń jẹ oluwa lé awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ogún Ọlọrun lórí, ṣugbọn kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Peteru 5:2, 3) Aposteli Paulu sọ fún àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ kíyèsí ara yín ati gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín sípò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó, lati ṣe olùṣọ́ àgùtàn ìjọ Ọlọrun, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọkùnrin oun fúnra rẹ̀ rà.” Ẹ wo bí àwọn àgùntàn náà ti kún fún ọpẹ́ tó, pé àwọn ọkùnrin tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn sípò wọ̀nyí ń fi “ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo”!—Ìṣe 20:28-30.
4. Irú ipò ìbátan wo pẹ̀lú agbo ni a mọ̀ mọ Charles T. Russell dáradára?
4 Jesu fún ìjọ ní “ẹ̀bùn fún ènìyàn,” àwọn kan bíi “olùṣọ́ àgùntàn,” tàbí pásítọ̀ tí ń bójú tó agbo Jehofa lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Efesu 4:8, 11; King James Version) Ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni Charles T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society. Wọ́n pè é ní Pásítọ̀ Russell nítorí àwọn ìgbòkègbodò onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú rẹ̀ ní ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo náà lábẹ́ Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn, Jesu Kristi. Lónìí, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ń yan àwọn Kristian alàgbà sípò, a sì máa ń kíyè sára láti má ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “pásítọ̀,” “alàgbà” tàbí “olùkọ́ni” gẹ́gẹ́ bí orúkọ oyè. (Matteu 23:8-12) Síbẹ̀, àwọn alàgbà ọjọ́ òní ń ṣe iṣẹ́ pásítọ̀ tàbí olùṣọ́ àgùntàn, fún àǹfààní àwọn àgùntàn pápá Jehofa.
5. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn ẹni tuntun mọ àwọn alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ Kristian?
5 Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn, àwọn alàgbà ń kó apá pàtàkì nínú ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí àwọn ẹni tuntun. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ìwé tuntun náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, fi sọ ní ojú ìwé 168 pé: “Di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tí a yànsípò nínú ìjọ rẹ. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìrírí ní fífi ìmọ̀ Ọlọrun sílò, nítorí wọ́n ti kájú àwọn ìtóótun fún alábòójútó èyí tí a tó lẹ́sẹẹsẹ sínú Bibeli. (1 Timoteu 3:1-7; Titu 1:5-9) Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti tọ̀ wọ́n lọ bí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí láti borí àṣà tàbí ìwà ànímọ́ kan tí ó forígbárí pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè. Ìwọ yóò rí i pé àwọn alàgbà ń tẹ̀lé ìṣílétí Paulu pé: ‘Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún awọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.’—1 Tessalonika 2:7, 8; 5:14.”
Nígbà Tí Àwọn Ẹni Tuntun Bá Fẹ́ Máa Wàásù
6. Ìlànà wo ni a óò tẹ̀ lé, bí akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan bá fẹ́ di akéde Ìjọba?
6 Lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan bá ti gba ìmọ̀ sínú, tí ó sì ti ń wá sí àwọn ìpàdé fún sáà kan, ó lè fẹ́ láti di akéde Ìjọba, oníwàásù ìhìn rere. (Marku 13:10) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́rìí tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀ ní láti kàn sí alábòójútó olùṣalága, tí yóò ṣètò fún ọ̀kan nínú àwọn alàgbà tí ó wà lára Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ àti alàgbà míràn láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà àti olùkọ́ rẹ̀. Ìjíròrò náà yóò dá lórí ìwé náà, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 98 àti 99. Bí àwọn alàgbà méjì wọ̀nyí bá rí i pé, ẹni tuntun yìí gba àwọn lájorí ẹ̀kọ́ Bibeli gbọ́, tí ó sì ti ń mú ara rẹ̀ bá àwọn ìlànà Ọlọrun mu, wọn yóò sọ fún un pé, ó ti tóótun láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba.a Nígbà tí ó bá ròyìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, nípa fífi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ̀ sílẹ̀, a óò kọ ọ́ sínú káàdì Congregation’s Publisher Record tí a ṣí fún un. Ẹni tuntun náà lè ròyìn ìgbòkègbodò ìjẹ́rìí rẹ̀ nísinsìnyí pa pọ̀ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn tí ń fi tayọ̀tayọ̀ ‘kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní gbangba.’ (Ìṣe 13:5) A óò ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ pé, ó ti di akéde tí kò tí ì ṣe batisí.
7, 8. Ní àwọn ọ̀nà wo ni akéde kan tí kò tí ì ṣe batisí fi lè nílò ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
7 Akéde kan tí kò tí ì ṣe batisí nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà àti àwọn Kristian míràn tí wọ́n dàgbà dénú. Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí jẹ́ ọ̀ràn tí ó jẹ olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ó ń dara pọ̀ mọ́ lógún. Ó lè ṣòro fún akéde tuntun náà láti sọ̀rọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ilé dé ilé. (Ìṣe 20:20) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí ó fẹ́ ìrànlọ́wọ́, ní pàtàkì, láti ọwọ́ ẹni tí ó ti ń bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ìwé Ìmọ̀. Irú ìrànlọ́wọ́ tí ó ṣeé mú lò bẹ́ẹ̀ ṣe wẹ́kú, nítorí pé Jesu Kristi múra àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.—Marku 6:7-13; Luku 10:1-22.
8 Kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa baà lè gbéṣẹ́, ìmúrasílẹ̀ dáradára ṣe kókó. Nítorí náà, àwọn akéde méjèèjì náà lè kọ́kọ́ fi àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa olóṣooṣù dánra wò. Nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá wọn, ẹni tí ó nírìírí jù lọ lè ṣiṣẹ́ ní ẹnu ọ̀nà kan tàbí méjì tí wọ́n bá kọ́kọ́ dé. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ bí ẹni bá ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀, àwọn akéde méjèèjì lè nípìn-ín nínú jíjẹ́rìí. Ṣíṣiṣẹ́ pa pọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lè yọrí sí àwọn ìpadàbẹ̀wò gbígbámúṣé, àní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé pàápàá nínú ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Akéde tí ó nírìírí jù lọ lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, kí ó fà á lé ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di olùpòkìkí Ìjọba náà lọ́wọ́. Ẹ wo bí àwọn akéde méjèèjì náà yóò ti láyọ̀ tó, bí akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà bá fi ìmọrírì fún ìmọ̀ Ọlọrun hàn!
9. Ètò wo ni a ń ṣe nígbà tí akéde kan bá fẹ́ ṣe batisí?
9 Bí akéde tí kò tí ì ṣe batisí kan ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọrun nínú àdúrà, kí ó sì fẹ́ láti ṣe batisí. (Fi wé Marku 1:9-11.) Ó ní láti sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún batisí di mímọ̀ fún alábòójútó olùṣalága ìjọ náà, tí yóò ṣètò fún àwọn alàgbà tí yóò ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè ojú ìwé 175 sí 218 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojisẹ Wa, pẹ̀lú akéde náà. Alàgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè kárí apá mẹ́rin tí a pín àwọn ìbéèrè náà sí, ní ìjókòó mẹ́ta. Bí wọ́n bá gbà pé, akéde tí kò tí ì ṣe batisí náà ní òye dé ìwọ̀n àyè kan nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli, tí ó sì tóótun ní àwọn ọ̀nà míràn, wọn yóò sọ fún un pé, ó lè ṣe batisí. Nítorí ìyàsímímọ́ àti batisí rẹ̀, ó di ‘ẹni tí a sàmì sí’ fún ìgbàlà.—Esekieli 9:4-6.
Kíkájú Àwọn Àìní Àrà Ọ̀tọ̀
10. Lẹ́yìn píparí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ìwé Ìmọ̀, tí ó sì ti ṣe batisí, báwo ni ẹnì kan yóò ṣe mú ìmọ̀ rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ pọ̀ sí i?
10 Lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ nínú ìwé náà, Ìmọ̀, tí ó sì ti ṣe batisí, ó lè má pọn dandan láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìwé kejì, bí Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa.b Dájúdájú, ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí náà yóò kọ́ ohun púpọ̀, bí ó ti ń múra sílẹ̀, tí ó sì ń wá sí àwọn ìpàdé Kristian déédéé. Yóò tún ní àfikún ìmọ̀ bí òùngbẹ rẹ̀ fún òtítọ́ ṣe ń sún un láti ka àwọn ìtẹ̀jáde Kristian, kí ó máa dá kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn, kí ó sì máa jíròrò àwọn ọ̀ràn Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí àìní àrà ọ̀tọ̀ bá dìde ńkọ́?
11. (a) Báwo ni Priskilla àti Akuila ṣe ran Apollo lọ́wọ́? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni a lè ṣe fún ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, tí ó sì ń gbèrò láti ṣègbéyàwó?
11 Apollo pàápàá, tí ó “jẹ́ ògbóǹkangí ninu Ìwé Mímọ́,” tí ó sì kọ́ni nípa Jesu lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, jàǹfààní nígbà tí àwọn Kristian onírìírí, Priskilla àti Akuila, ‘mú un wọ ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọrun fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.’ (Ìṣe 18:24-26; fi wé Ìṣe 19:1-7.) Nítorí náà, kí á sọ pé ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ń ronú láti ní àfẹ́sọ́nà, kí ó sì ṣègbéyàwó. Kristian kan tí ó nírìírí jù ú lọ lè ràn án lọ́wọ́ láti wá ìsọfúnni lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ wọ̀nyí nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower. Fún àpẹẹrẹ, àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ arannilọ́wọ́ lórí irú ọ̀ràn yìí fara hàn nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Ìpín 7.c Akéde tí ó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀ lé jíròrò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú ẹni tuntun náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kì yóò ní ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú.
12. Ìrànlọ́wọ́ wo ni a lè ṣe fún tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, tí wọ́n ní ìṣòro?
12 Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Bóyá àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ń ní ìṣòro fífi àwọn ìlànà Ọlọrun sílò. Wọ́n lè tọ alàgbà kan lọ, tí ó lè lo àwọn ìrọ̀lẹ́ díẹ̀ láti jíròrò Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì darí àfiyèsí wọn sí àwọn ìsọfúnni tí a rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower. Ṣùgbọ́n, alàgbà náà kì yóò tún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé kan dá sílẹ̀ pẹ̀lú tọkọtaya náà.
Bí Ẹni Tuntun Kan Bá Dẹ́ṣẹ̀
13. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn alàgbà fi àánú hàn sí ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó ronú pìwà dà?
13 Àwọn alàgbà ń ṣàfarawé Olùṣọ́ Àgùntàn Títóbi Lọ́lá náà, Jehofa, tí ó sọ pé: “Èmi óò bọ́ ọ̀wọ́ ẹran mi, . . . èmi óò sì di èyí tí a ṣá lọ́gbẹ́, èmi óò mú èyí tí ó ṣàìsàn ní ara le.” (Esekieli 34:15, 16; Efesu 5:1) Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí yẹn, ọmọ ẹ̀yìn náà, Juda, rọni pé, kí a fi àánú hàn sí àwọn Kristian ẹni àmì òróró tí wọ́n ń ṣiyè méjì tàbí tí wọ́n ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. (Juda 22, 23) Níwọ̀n bí ó ti tọ́ láti retí ohun púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristian onírìírí, dájúdájú, ó yẹ kí a fi àánú hàn sí ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí—ọ̀dọ́ àgùntàn jòjòló—tí ó ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó ronú pìwà dà. (Luku 12:48; 15:1-7) Nítorí náà, àwọn alàgbà, tí ‘ń bá Jehofa ṣe ìdájọ́,’ ní láti fún irú àgùntàn bẹ́ẹ̀ ní àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, kí wọ́n sì mú wọn padà bọ̀ sípò ní ẹ̀mí ìwà tútù.—2 Kronika 19:6; Ìṣe 20:28, 29; Galatia 6:1.d
14. Kí ni ó yẹ kí a ṣe, nígbà tí akéde kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó wúwo, báwo sì ni a ṣe lè ràn án lọ́wọ́?
14 Ó dára, jẹ́ kí á sọ pé, akéde kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ní ìṣòro ọtí mímu tẹ́lẹ̀, tí ó sì ti mu àmupara lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì. Tàbí bóyá ó ti borí ìwà tábà mímu ọlọ́jọ́ pípẹ́, ṣùgbọ́n tí ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìdánwò mímu tábà níkọ̀kọ̀ lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin wa tuntun ti gbàdúrà fún ìdáríjì Ọlọrun, ó ní láti wá ìrànlọ́wọ́ alàgbà kan, kí ẹ̀ṣẹ̀ náà má baà di bárakú. (Orin Dafidi 32:1-5; Jakọbu 5:14, 15) Nígbà tí ó bá sọ àṣìṣe rẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn alàgbà, alàgbà náà ní láti gbìyànjú láti mú ẹni tuntun náà padà bọ̀ sípò lọ́nà tí ó fi àánú hàn. (Orin Dafidi 130:3) Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ ti tó láti ràn án lọ́wọ́ láti mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Heberu 12:12, 13) Alàgbà yìí yóò jíròrò àyíká ipò náà pẹ̀lú alábòójútó olùṣalága ìjọ náà láti pinnu irú ìrànlọ̀wọ́ síwájú sí i tí ó yẹ kí a fún un.
15. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, kí ni ó lè pọn dandan nígbà tí ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí bá dẹ́ṣẹ̀?
15 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a lè nílò ju èyí lọ. Bí ó bá ti di mímọ̀ gbangba, tí ó ń wu agbo léwu, tàbí bí ó bá ti wé mọ́ àwọn ìṣòro líle koko mìíràn, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yóò yan alàgbà méjì láti wádìí ọ̀ràn náà wò. Bí àwọn alàgbà yìí bá rí i pé ọ̀ràn náà le koko débi pé a nílò ìgbìmọ̀ onídàájọ́, wọ́n ní láti sọ èyí fún ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yóò wá yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ láti ran ẹni tí ó ṣẹ̀ náà lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ní láti bá a lò pẹ̀lú jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ tiraka láti mú un bọ̀ sípò pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. Bí ó bá hùwà padà sí ìsapá onínúrere ìgbìmọ̀ onídàájọ́ náà, nígbà náà, wọ́n lè pinnu bóyá àǹfààní kankan lè wà nínú àìní lò ó fún iṣẹ́ lórí pèpéle ní àwọn ìpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí bóyá kí a yọ̀ọ̀da fún un láti máa sọ̀rọ̀ ìlóhùn sí ní àwọn ìpàdé.
16. Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti ran ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́?
16 Bí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ náà bá dáhùn padà, alàgbà kan tàbí méjì tí wọ́n wà lára ìgbìmọ̀ onídàájọ́ náà lè ṣètò láti ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tí a pète láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun àti láti gbé ìmọrírì rẹ̀ fún àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọrun ró. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè bá a ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lóòrè kóòrè. Wọ́n lè ní ìjíròrò Ìwé Mímọ́ díẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, bóyá nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! tí ó ṣe wẹ́kú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé sílẹ̀. Pẹ̀lú irú àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ náà ni a lè fún lókun láti dènà àìlera ara ní ọjọ́ ìwájú.
17. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni a óò gbé bí oníwà àìtọ́ kan, tí ó ti ṣe batisí, kò bá ronú pìwà dà, kí ó sì fi ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀?
17 Àmọ́ ṣáá o, jíjẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí kì í ṣe àwáwí fún sísọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà láìronú pìwà dà. (Heberu 10:26, 27; Juda 4) Bí oníwà àìtọ́ èyíkéyìí tí ó ti ṣe batisí kò bá ronú pìwà dà, kí ó sì fi ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, a óò yọ ọ́ nínú ìjọ. (1 Korinti 5:6, 11-13; 2 Tessalonika 2:11, 12; 2 Johannu 9-11) Nígbà tí ìgbésẹ̀ yìí bá pọn dandan, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yóò yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́. Bí a bá yọ ọ́, wọn yóò ṣe ìfilọ̀ ṣókí yìí: “A ti yọ . . . lẹ́gbẹ́.”e
Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti “Tẹ̀síwájú sí Ìdàgbàdénú”
18. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ dájú pé, àwọn Kristian tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí àti àwọn mìíràn yóò máa fìgbà gbogbo ní ohun púpọ̀ láti kọ́ nípa Jehofa àti ìfẹ́ inú rẹ̀?
18 Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun yóò dúró nínú agbo náà. Ó dùn mọ́ni pẹ̀lú pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yóò lè túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run sí i, nítorí pé, a óò lè máa túbọ̀ kọ́ nípa rẹ̀ àti ìfẹ́ inú rẹ̀. (Oniwasu 3:11; Jakọbu 4:8) Dájúdájú, ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí a batisí ní Pentekosti ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ní ohun púpọ̀ láti kọ́. (Ìṣe 2:5, 37-41; 4:4) Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Kèfèrí tí wọn kò mọ Ìwé Mímọ́ tẹ́lẹ̀ ṣe. Fún àpẹẹrẹ, èyí jẹ́ òtítọ́ nípa ti àwọn tí wọ́n ṣe batisí lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Paulu ní Areopagu ní Ateni. (Ìṣe 17:33, 34) Lónìí, pẹ̀lú, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ní púpọ̀ láti kọ́, wọ́n sì nílò àkókò àti ìrànlọ́wọ́ láti fún ìpinnu wọn lókun láti máa bá ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọrun nìṣó.—Galatia 6:9; 2 Tessalonika 3:13.
19. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn tí wọ́n ń ṣe batisí lọ́wọ́ láti “tẹ̀síwájú sí ìdàgbàdénú”?
19 Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe batisí, wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́, kí wọ́n baà lè “tẹ̀síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Heberu 6:1-3) Nípa ọ̀rọ̀, àpẹẹrẹ àti ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, kí ó sì ‘máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.’ (3 Johannu 4; Kolosse 3:9, 10) Bí o bá jẹ́ akéde onírìírí, àwọn alàgbà lè pè ọ́ láti ran onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí láti jíròrò àwọn kókó kan pàtó nínú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ láti baà lè fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọrun lókun, kí ó fi kún ìmọrírì rẹ̀ fún àwọn ìpàdé Kristian, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ipò ìbátan tí ń bẹ láàárín àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti agbo dà bíi ti bàbá tí ń gbani níyànjú àti màmá oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. (1 Tessalonika 2:7, 8, 11) Síbẹ̀, àwọn alàgbà díẹ̀ àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kò lè bójú tó gbogbo ohun tí a nílò nínú ìjọ. Gbogbo wá dà bí ìdílé kan, tí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wá lè ṣe ohun kan láti ran olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́. Ìwọ fúnra rẹ lè fúnni ní ìṣírí, o lè tu ẹni tí ó sorí kọ́ nínú, kí o sì ran aláìlera lọ́wọ́.—1 Tessalonika 5:14, 15.
20. Kí ni o lè ṣe láti tan ìmọ̀ Ọlọrun kálẹ̀, kí o sì pèsè àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún àwọn àgùntàn pápá Jehofa?
20 Aráyé nílò ìmọ̀ Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, o sì lè nípìn-ín tí ń máyọ̀ wá nínú títàn-án kálẹ̀. Àwọn àgùntàn Jehofa nílò àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, o sì lè kó ipa onífẹ̀ẹ́ nínú ṣíṣèrànlọ́wọ́ láti fúnni ní èyí. Ǹjẹ́ kí Jehofa bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, kí ó sì san èrè fún àwọn ìsapá àtọkànwá rẹ láti ran àwọn àgùntàn pápá rẹ̀ lọ́wọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Níbi tí ọ̀ràn dé yìí, ẹni tuntun náà lè gba ẹ̀dà ìwé náà, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa.
b A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
c A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
d A to irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ fún àwọn akéde tí kò tí ì ṣe batisí lẹ́sẹẹsẹ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ríràn Awọn Ẹlomiran Lọ́wọ́ lati Jọ́sìn Ọlọrun,” tí ó fara hàn nínú Ilé-Ìṣọ́nà November 15, 1988, ojú ìwé 15 sí 20.
e Bí ìpinnu náà bá jẹ́ ìyọlẹ́gbẹ́, tí ẹni náà sì pe ẹjọ́ kò tẹ́ mi lọ́rùn, a óò dá ìfilọ̀ náà dúró títí di ìgbà tí a bá tó mọ àbájáde rẹ̀. Wo ojú ìwé 147 sí 148 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe ń bá àwọn àgùntàn rẹ̀ lò?
◻ Kí ni a óò ṣe, nígbà tí ẹni tuntun kan bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù?
◻ Báwo ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ní àìní àrà ọ̀tọ̀ lọ́wọ́?
◻ Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn alàgbà lè ṣe fún àwọn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ronú pìwà dà?
◻ Báwo ni o ṣe lè ran ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí lọ́wọ́ láti “tẹ̀síwájú sí ìdàgbàdénú”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A mọ Charles T. Russell bí ẹni mowó gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn oníyọ̀ọ́nú ń bá agbo Ọlọrun lò pẹ̀lú jẹ̀lẹ́ńkẹ́