Yíyááfì Ohun Púpọ̀ Nítorí Ohun Tí Ó Tóbi Jù ú lọ
GẸ́GẸ́ BÍ JULIUS OWÓ BELLO ṢE SỌ
Mo fi ọdún 32 jẹ́ Aládùúrà. Mo gbà gbọ́ pé ìgbàgbọ́ wòósàn àti àdúrà yóò yanjú gbogbo ìṣòro mi, yóò sì wo gbogbo àrùn sàn. N kì í ra egbòogi, kódà n kì í ra oògùn ara ríro. Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn, kò sí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé mi tí a dá dúró sí ilé ìwòsàn. Nígbàkígbà tí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ mi bá ń ṣàìsàn, mo máa ń gbàdúrà fún wọn tọ̀sán tòru títí ara wọn yóò fi dá. Mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ni ó ń gbọ́ àdúrà mi, tí ó sì ń bù kún mi.
MO JẸ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Jolly, ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣe kan tí ó gbajúmọ̀ jù lọ ní Àkúrẹ́, ìlú kan ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n lọ́rọ̀ jù lọ, tí wọ́n sì jẹ́ abẹnugan jù lọ láwùjọ wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Déjì, ọba Àkúrẹ́, máa ń bẹ̀ mí wò nínú ilé mi.
Mo tún jẹ́ akóbìnrinjọ, mo ní aya mẹ́fà àti àlè rẹpẹtẹ. Iṣẹ́ okòwò mí gbilẹ̀ sí i. Gbogbo nǹkan ń ṣẹnuure fún mi. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò arìnrìn-àjò nínú òwe àkàwé Jésù nípa péálì, mo rí ohun kan tí ó ṣeyebíye gidigidi, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi yááfì márùn-ún nínú àwọn aya mi, mo yááfì àwọn àlè mi, ṣọ́ọ̀ṣì, ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣe, àti òkìkí ayé ní fífi wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ fún un.—Mátíù 13:45, 46.
Bí Mo Ṣe Di Aládùúrà
Ọdún 1936 ni mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn Aládùúrà, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 13. Ọ̀rẹ́ mi kan tí ń jẹ́ Gabriel sọ fún mi pé: “Bí ó bá ṣèbẹ̀wò sí Ṣọ́ọ̀ṣì Christ Apostolic, ìwọ yóò gbọ́ tí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀.”
Mo bí i léèrè pé: “Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń sọ̀rọ̀?”
Ó wí pé: “Wá síbẹ̀, ìwọ yóò sì fojú ara rẹ rí i.”
Mo hára gàgà láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Nítorí náà, ní alẹ́ yẹn, mo bá Gabriel lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì yẹn. Àwọn olùjọ́sìn kún ilé kékeré náà fọ́fọ́. Ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn! Ibí ni Jésù wà!”
Bí orin yìí ṣe ń lọ lọ́wọ́, ẹnì kan ké rara pé: “Ẹ̀mí mímọ́, sọ̀ kalẹ̀!” Ẹlòmíràn lu aago wọnran wọnran, ìjọ náà sì dákẹ́ wẹ́lo. Lẹ́yìn náà, obìnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ wuuruwu tìtaratìtara ní èdè àjèjì. Lójijì, ó kígbe pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀yin ènìyàn! Báyìí ni Ọlọ́run wí: ‘Ẹ gbàdúrà fún àwọn ọdẹ kí wọn má baà pànìyàn!’” Gbogbo ibẹ̀ pa lọ́lọ́.
Mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti tipasẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀, nítorí náà, ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, mo ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Christ Apostolic.
Bíbá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pàdé fún Ìgbà Àkọ́kọ́
Ní 1951, mo tẹ́wọ́ gba ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adédèjì Bọ̀bóyè. Ìwé ìròyìn náà fani lọ́kàn mọ́ra, nítorí náà, mo san àsansílẹ̀ owó rẹ̀, mo sì ń kà á déédéé. Ní 1952, mo lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́rin ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Adó Èkìtì.
Ohun tí mo rí ní àpéjọpọ̀ náà wú mi lórí. Mo ronú jinlẹ̀ nípa dídi ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n mo pa èrò náà tì. Ìṣòro mi ni pé, ní ìgbà yẹn, mo ní aya mẹ́ta, mo sì tún ní àlè kan. Mo rò pé kò sí bí mo ṣe lè gbé pẹ̀lú aya kan ṣoṣo.
Nígbà tí mo pa dà sí Àkúrẹ́, mo sọ fún Adédèjì pé kí ó máà wá sọ́dọ̀ mi mọ́, n kò sì tún àsansílẹ̀ owó Ilé Ìṣọ́ mi san. Mo túbọ̀ di onítara sí i nínú ṣọ́ọ̀ṣì mi. Mo ronú pé, ó ṣe tán, Ọlọ́run ti bù kún mi láti ìgbà tí mo ti dara pọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Christ Apostolic. Mo ti fẹ́ aya mẹ́ta, mo sì ti bí ọmọ púpọ̀. Mo ti kọ́ ilé tèmi. A kò tí ì gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn rí. Níwọ̀n bí ó ti dà bíi pé Ọlọ́run ń dáhùn àdúrà mi, èé ṣe tí mo fi ní láti yí ìsìn mi pa dà?
Dídi Olókìkí Sí I Tòun Ti Ìpòrúurùu Ọkàn
Mo bẹ̀rẹ̀ sí dáwó púpọ̀ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n fi mi ṣe alàgbà nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ipò kan tí ó jẹ́ kí n rí ohun tí ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ohun tí mo rí dà mí láàmú. Pásítọ̀ àti “àwọn wòlíì” nífẹ̀ẹ́ owó; ìwọra wọn sú mi.
Fún àpẹẹrẹ, ní March 1967, aya ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí ọmọ mẹ́ta fún mi. Ó jẹ́ àṣà nínú ṣọ́ọ̀ṣì láti ṣe ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ. Nítorí náà, mo mú ọrẹ—ẹja, ọtí lemonade, àti àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò—lọ fún pásítọ̀ ní ìmúrasílẹ̀ fún ayẹyẹ náà.
Ní ọjọ́ tí a ṣe ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, pásítọ̀ náà sọ níwájú gbogbo ìjọ pé: “Àwọn ọlọ́rọ̀ inú ṣọ́ọ̀ṣì yí ti mú ìyàlẹ́nu bá mi. Wọ́n fẹ́ ṣayẹyẹ ìsọmọlórúkọ, kìkì ohun tí wọ́n sì kó wá ni ọtí ẹlẹ́rìndòdò àti ẹja. Wọn kò mẹ́ran wá! Wọn kò méwúrẹ́ wá! Ẹ rò ó wò ná! Kéènì fi iṣu bàǹbàbàǹbà rúbọ sí Ọlọ́run, síbẹ̀, Ọlọ́run kò gba ẹbọ rẹ̀ nítorí kò ní ẹ̀jẹ̀. Ohun ẹlẹ́jẹ̀ ni Ọlọ́run ń fẹ́. Ébẹ́lì mu ẹran wá, a sì tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀.”
Pẹ̀lú ìyẹn, mo dìde, mo sì kù rọinrọin jáde. Ṣùgbọ́n, mo ṣì ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà. Lọ́nà púpọ̀ sí i, mo ń lo àkókò púpọ̀ sí i nínú àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, mo sì ń lọ sí àwọn ìpàdé ẹgbẹ́ mi. Nígbà míràn, mo máa ń lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo sì tún àsansílẹ̀ owó Ilé Ìṣọ́ mi san. Síbẹ̀síbẹ̀, n kò tí ì ṣe tán láti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ìpinnu Láti Ṣiṣẹ́ Sin Jèhófà
Àkókò ìyípadà ńlá dé sí mi ní 1968. Ní ọjọ́ kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tí ó ṣàpèjúwe inúnibíni kíkorò tí a ṣe sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì. Ó sọ nípa ọmọbìnrin ọlọ́dún 15 kan, tí a so mọ́ igi, tí a sì fipá bá lò pọ̀ nígbà mẹ́fà nítorí pé ó kọ̀ láti fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ara mi gbọ̀n rìrì, mo ju ìwé ìròyìn náà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọkàn mi kò kúrò níbẹ̀. Mo ronú pé kò sí ọmọbìnrin kankan ní ṣọ́ọ̀ṣì mi tí yóò fi irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Lẹ́yìn náà, ní ìrọ̀lẹ́ yẹn, mo mú ìwé ìròyìn náà, mo sì tún ojú ìwé náà kà.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì. Bí mo ṣe ń dàgbà nínú ìmọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí ri bí ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣì wá lọ́nà tó. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ ní ìgbà àtijọ́, àwọn àlùfáà wa ń “dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.” (Hóséà 6:9) Irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn wòlíì èké tí Jésù kìlọ̀ nípa wọn! (Mátíù 24:24) N kò gbà gbọ́ nínú ìran àti iṣẹ́ agbára wọn mọ́. Mo pinnu láti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìsìn èké, kí n sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ìsapá Láti Má Ṣe Jẹ́ Kí N Fi Ṣọ́ọ̀ṣì Sílẹ̀
Nígbà tí àwọn alàgbà inú ṣọ́ọ̀ṣì mọ̀ pé mo ti pinnu láti kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n rán aṣojú wá láti bẹ̀ mí. Wọn kò fẹ́ pàdánù orísun pàtàkì tí owó ń gbà wọlé. Wọ́n sọ pé àwọn yóò fi mí jẹ Bàbá Ẹgbẹ́, baba ìsàlẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Christ Apostolic ní Àkúrẹ́.
Mo sọ fún wọn pé n kò fẹ́, mo sì sọ ìdí rẹ̀ fún wọn. Mo wí pé: “Irọ́ ni ṣọ́ọ̀ṣì ń pa fún wa. Wọ́n sọ pé gbogbo ẹni rere ni yóò lọ sí ọ̀run. Ṣùgbọ́n mo ti ka Bíbélì, ó sì ti dá mi lójú pé kìkì 144,000 ni yóò lọ sí ọ̀run. Àwọn ènìyàn míràn tí wọ́n jẹ́ olódodo yóò gbé lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan.”—Mátíù 5:5; Ìṣípayá 14:1, 3.
Pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì náà gbìyànjú láti mú kí àwọn aya mi kẹ̀yìn sí mi. Ó sọ fún wọn pé, kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé wa mọ́. Ọ̀kan lára àwọn aya mi fi májèlé sínú oúnjẹ fún mi. Méjì nínú wọn kìlọ̀ fún mi nípa ìran kan tí wọ́n rí sí mi ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ìran náà fi hàn pé, n óò kú bí mo bá fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. Láìka ìyẹn sí, ń kò dẹ́kun jíjẹ́rìí fún àwọn aya mi, ní kíkésí wọn láti bá mi lọ sí ìpàdé. Mo wí pé: “Ẹ óò rí àwọn ọkọ mìíràn níbẹ̀.” Ṣùgbọ́n, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, wọ́n sì ń bá ìgbìyànjú wọn láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi nìṣó.
Paríparí rẹ̀, ní February 2, 1970, nígbà tí mo ti ìrìn-àjò kan sí ìlú òdì kejì dé, mo rí i pé ilé ti ṣófo. Gbogbo aya mi ti sá lọ tọmọtọmọ.
Fífaramọ́ Aya Kan Ṣoṣo
Mo ronú pé: ‘Mo wá lè tún ipò ìgbéyàwó mi tò báyìí.’ Mo ké sí ìyàwó mi àgbà, Janet, pé kí ó pa dà wá sílé. Ó gbà. Ṣùgbọ́n, ìdílé rẹ̀ ta ko èrò náà. Nígbà tí àwọn aya mi yòó kù gbọ́ pé mo ti sọ pé kí Janet kó pa dà, wọ́n lọ sí ilé bàbá rẹ̀, wọ́n sì gbìyànjú láti lù ú. Nígbà náà ni ìdílé rẹ̀ pè mí sí ìpàdé kan.
Nǹkan bí 80 ènìyàn ni ó pésẹ̀ sí ìpàdé náà. Àbúrò bàbá Janet, tí ó jẹ́ olórí ilé, wí pé: “Bí o bá fẹ́ pa dà fẹ́ ọmọ wa, nígbà náà, o gbọ́dọ̀ gba àwọn obìnrin yòó kù pa dà. Ṣùgbọ́n bí o bá fẹ́ ṣe ìsìn rẹ tuntun, tí o sì fẹ́ wà pẹ̀lú aya kan ṣoṣo, nígbà náà, a jẹ́ pé, wàá lọ wá obìnrin mìíràn nìyẹn. Bí o bá mú Janet pa dà, àwọn aya rẹ yòó kù yóò pa á, a kò sì fẹ́ kí ọmọ wa kú.”
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ púpọ̀, ìdílé náà rí i pé, mo ti pinnu láti ní aya kan ṣoṣo. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n jáwọ́. Àbúrò bàbá rẹ̀ náà sọ pé: “A kò ní gba aya rẹ lọ́wọ́ rẹ. O lè máa mú un lọ.”
Ní May 21, 1970, èmi àti Janet fìdí ìgbéyàwó wa múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Ọjọ́ mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, mo ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní December ọdún kan náà, Janet pẹ̀lú ṣe ìrìbọmi.
Gbígbádùn Ìbùkún Jèhófà
Àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì wa àtijọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé, bí a bá di Ẹlẹ́rìí, a óò kú. Ìyẹn jẹ́ ní nǹkan bí 30 ọdún sẹ́yìn. Kódà bí mo bá kú báyìí, yóò ha jẹ́ nítorí pé mo di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí? Bí aya mi bá kú báyìí, ẹnikẹ́ni ha lè sọ pé, dídi ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó pa á bí?
Mo ti làkàkà láti fi ọ̀nà òtítọ́ han àwọn ọmọ mi 17. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú wọn ti di àgbàlagbà nígbà tí mo fi di Ẹlẹ́rìí, mo fún wọn níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì mú wọn lọ sí ìpàdé àti àpéjọpọ̀. Inú mi dùn jọjọ láti ní márùn-ún nínú àwọn ọmọ mi tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà pẹ̀lú mi. Ẹnì kan ń ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Òmíràn jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ kan nítòsí. Méjì nínú àwọn ọmọ mi ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé.
Nígbà tí mo bá bojú wẹ̀yìn, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ní ríràn mí lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ń jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi. Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù náà ṣe jẹ́ òtítọ́ tó pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Bàbá, tí ó rán mi, fà á”!—Jòhánù 6:44.