Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Ará Tí Ẹ̀yin Ní Máa Bá A Lọ!
“Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ̀yin ní máa bá a lọ.”—HÉBÉRÙ 13:1.
1. Kí ni ìwọ yóò ṣe láti lè mú kí iná túbọ̀ máa jó geerege ní alẹ́ kan tí òtútù mú, irú ẹrù iṣẹ́ tí ó fara jọ ọ́ wo sì ni gbogbo wá ní?
ÒTÚTÙ mú gan-an níta, ojú ọjọ́ sì túbọ̀ ń tutù sí i. Iná tí ń ràn yòò ní ojú ààrò ni ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú ilé rẹ móoru. Ẹ̀mí àwọn ènìyàn sinmi lórí ṣíṣàì jẹ́ kí iná náà kú. Ìwọ yóò ha wulẹ̀ nawọ́ nasẹ̀, tí ìwọ yóò sì máa wo bí iná náà ṣe ń kú lọ, ti ẹ̀yin iná náà tí ń ràn yòò sì ń di eérú pátápátá níṣojú rẹ bí? Dájúdájú ìwọ kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwọ kò ní káàárẹ̀ ní kíko iná náà kí ó má baà kú. Lọ́nà kan náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní iṣẹ́ tí ó jọ èyí nígbà tí ó bá di ọ̀ràn “iná” kan tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù—ọ̀kan tí ó yẹ kí ó máa jó geerege nínú ọkàn àyà wa—ìfẹ́.
2. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ìfẹ́ ti di tútù ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí? (b) Báwo ni ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn Kristẹni tòótọ́?
2 Bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, a ń gbé ní àkókò kan tí ìfẹ́ ń di tútù kárí ayé láàárín àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni. (Mátíù 24:12) Jésù ń tọ́ka sí irú ìfẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, ìfẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àti fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. Àwọn oríṣi ìfẹ́ mìíràn pẹ̀lú ń dín kù gidigidi. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ọ̀pọ̀ kì yóò ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó! Ó yẹ kí ìdílé jẹ́ ibi tí ìfẹ́ni àdánidá ti gbilẹ̀, ṣùgbọ́n níbẹ̀ pàápàá, ìwà ipá àti ìwà ìkà—tí ó máa ń kún fún ìwà òǹrorò bíbani lẹ́rù nígbà míràn—ti di ohun tí ó wọ́pọ̀. Síbẹ̀, nínú ayé akanragógó yìí, kì í ṣe ìfẹ́ lásán nìkan ni a pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti ní sí ẹnì kíní kejì wọn ṣùgbọ́n kí wọ́n ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ, ní fífi ire ẹlòmíràn ṣáájú tiwọn. A gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ yìí hàn lọ́nà tí ó ṣe kedere tí yóò fi di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ní dídi àmì tí a fi ń dá ìjọ Kristẹni tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀.—Jòhánù 13:34, 35.
3. Kí ni ìfẹ́ ará, kí sì ni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ kí ó máa bá a lọ?
3 A mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti pàṣẹ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ̀yin ní máa bá a lọ.” (Hébérù 13:1) Gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀jáde ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “ìfẹ́ ará” (phi·la·del·phiʹa) níhìn-ín “ń tọ́ka sí ìfẹ́ onífẹ̀ẹ́ni, fífi inú rere hàn, bíbáni kẹ́dùn, ríranni lọ́wọ́.” Kí sì ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé ó yẹ kí a jẹ́ kí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa bá a lọ? Ìwé kan náà sọ pé: “Kò gbọ́dọ̀ tutù láé.” Nítorí náà, níní ìmọ̀lára ìfẹ́ni fún àwọn ará wa kò tó; a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó hàn. Síwájú sí i, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ yìí wà pẹ́ títí, kí a má ṣe jẹ́ kí ó tutù láé. Ó ha jẹ́ ìpèníjà bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ni ará dàgbà àti láti jẹ́ kí a máa bá a lọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí a gbé ọ̀nà mẹ́ta tí a lè gbà koná mọ́ ìfẹ́ yìí nínú ọkàn àyà wa yẹ̀ wò.
Fí Ìmọ̀lára fún Ọmọnìkejì Hàn
4. Kí ni ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì?
4 Bí ìwọ bá ń fẹ́ láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin rẹ, àánú wọn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ọ́, kí o bá wọn kẹ́dùn nínú àdánwò àti ìpèníjà tí wọ́n dojú kọ nínú ìgbésí ayé. Àpọ́sítélì Pétérù dámọ̀ràn èyí nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.” (Pétérù Kíní 3:8) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a lò níhìn-ín fún fífi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn ní ìtumọ̀ “bíbáni jìyà.” Abẹnugan kan lórí èdè Gíríìkì ti Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yí pé: “Ó ń ṣàpèjúwe ipò ìrònú tí a máa ń ní nígbà tí a bá jẹ́ kí ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn nípa lórí wa bí ẹni pé àwa gan-an ni ọ̀ràn náà dé bá.” Nítorí náà, a nílò ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Àgbàlagbà, olóòótọ́, ìránṣẹ́ Jèhófà kan sọ nígbà kan rí pé: “Ìrora rẹ nínú ọkàn àyà mi ni ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò.”
5. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń fi ìmọ̀lára hàn fúnni?
5 Jèhófà ha máa ń fi irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ hàn fúnni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Fún àpẹẹrẹ, a kà nípa ìyà tí ó jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísáyà 63:9, NW) Kì í ṣe pé Jèhófà rí wàhálà wọn nìkan ni; àánú wọn tún ṣe é. Ọ̀rọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí a kọ sílẹ̀ nínú Sekaráyà 2:8 (NW) ṣàkàwé bí ìmọ̀lára rẹ̀ ti jinlẹ̀ tó: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.”a Alálàyé kan sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí pé: “Ojú jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara tí ó díjú jù lọ, tí ó sì tún jẹ́ ẹlẹgẹ́ jù lọ nínú ara ẹ̀dá ènìyàn; ẹyinjú—ibi tí ìmọ́lẹ̀ ń gbà wọnú ojú kí a baà lè ríran—ni ibi tí ó tètè ń nímọ̀lára jù lọ, tí ó sì tún ṣe pàtàkì jù lọ, nínú gbogbo ojú. Kò sí ọ̀rọ̀ míràn tí ó ju èyí lọ tí ó tún lè gbé èrò ìtọ́jú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ jíjinlẹ̀ jù lọ yọ nípa ohun kan tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí.”
6. Báwo ni Jésù Kristi ṣe fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn?
6 Jésù pẹ̀lú ti fìgbà gbogbo fi ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ fún ọmọnìkejì hàn. Léraléra ni ‘àánú ń ṣe é’ nítorí ipò tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣàìsàn tàbí tí ìdààmú bá wà. (Máàkù 1:41; 6:34) Ó fi hàn pé bí ẹnikẹ́ni bá kùnà láti fi inú rere hàn sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ẹni àmì òróró, òun nímọ̀lára bí ẹni pé òun alára ni a kò fi inú rere hàn sí. (Mátíù 25:41-46) Lónìí pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà àgbà” wa ti ọ̀run, òun jẹ́ ẹni tí ó lè “báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.”—Hébérù 4:15.
7. Báwo ni ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá mú wa bínú?
7 “Báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa”—ìyẹn kì í ha ń ṣe èrò tí ń tuni nínú bí? Dájúdájú, nígbà náà, àwa náà fẹ́ ṣe ohun kan náà fún ẹnì kíní kejì. Àmọ́ ṣáá o, ó rọrùn púpọ̀ láti máa wá àìlera ẹnì kejì. (Mátíù 7:3-5) Ṣùgbọ́n nígbà míràn tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá mú ọ bínú, o kò ṣe gbìyànjú èyí? Fi ara rẹ sí ipò ẹni yẹn, gbà pé o ní ipò àtilẹ̀wá yẹn, pé o ní àkópọ̀ ìwà yẹn, pé o sì ní irú àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọ̀nyẹn láti ṣẹ́pá. Ó ha dá ọ lójú pé ìwọ kì yóò ṣe àṣìṣe kan náà bí—tàbí kí o tilẹ̀ ṣe èyí tí ó tún burú ju ìyẹn lọ? Kàkà tí a óò fi máa retí kí àwọn ẹlòmíràn ṣe ju ohun tí agbára wọ́n gbé lọ, ó yẹ kí a fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, èyí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fòye báni lò bíi Jèhófà, tí ó ń “rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” (Orin Dáfídì 103:14; Jákọ́bù 3:17) Ó mọ ibi tí agbára wá mọ. Kì í retí kí a ṣe ju ohun tí agbára wá ká. (Fi wé Àwọn Ọba Kìíní 19:5-7.) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fi irú ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn ẹlòmíràn.
8. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà pa dà nígbà tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ń bá ipò ìnira kan yí?
8 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìjọ dà bí ara tí ó ní onírúurú ẹ̀yà ara tí ó gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan. Ó fi kún un pé: “Bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara yòó kù á bá a jìyà.” (Kọ́ríńtì Kíní 12:12-26) Ó ṣe pàtàkì pé kí a bá àwọn tí ń kojú àwọn ìrírí agbonijìgì jìyà tàbí kí a bá wọn kẹ́dùn. Àwọn alàgbà máa ń mú ipò iwájú nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé: “Ta ní jẹ́ aláìlera, tí èmi kò sì jẹ́ aláìlera? Ta ni a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò sì gbiná?” (Kọ́ríńtì Kejì 11:29) Àwọn alàgbà àti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ń fara wé Pọ́ọ̀lù nínú ọ̀ràn yí. Nínú ọ̀rọ̀ àsọyé wọn, nínú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn wọn, àti nínú bíbójútó ọ̀ràn ìdájọ́ pàápàá, wọ́n ń sakun láti fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn. Pọ́ọ̀lù dámọ̀ràn pé: “Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Nígbà tí àwọn àgùntàn bá nímọ̀lára pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn bìkítà nípa wọn ní tòótọ́, pé wọ́n mọ ibi ti agbára wọ́n mọ, pé wọ́n sì ń bá wọn kẹ́dùn nítorí ìnira tí àwọn ń kojú, wọ́n sábà máa ń múra tán láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, ìdarí, àti ìbáwí. Wọ́n máa ń hára gàgà láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé, ní níní ìgbọ́kànlé pé àwọn yóò rí ‘ìtura fún ọkàn àwọn níbẹ̀.’—Mátíù 11:29.
Fífi Ìmọrírì Hàn
9. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun mọrírì ànímọ́ rere tí a ní?
9 Ọ̀nà kejì tí a lè gbà mú kí iná ìfẹ́ ará túbọ̀ máa jó geerege ni nípa ìmọrírì. Láti mọrírì àwọn ẹlòmíràn, a gbọ́dọ̀ darí àfiyèsí wa sórí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní àti ìsapá tí wọ́n ń ṣe, kí a sì mọyì rẹ̀. Nígbà tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ń fara wé Jèhófà fúnra rẹ̀. (Éfésù 5:1) Lójoojúmọ́ ni ó ń dárí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké jì wá. Ó tilẹ̀ ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo jì wá níwọ̀n ìgbà tí a bá fi ìrònúpìwàdà àtọkànwá hàn. Gbàrà tí ó bá sì ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, òun kì í ronú nípa wọn mọ́. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:14-16) Onísáàmù náà béèrè pé: “Olúwa, ì bá ṣe pé kí ìwọ kó máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, ta ni ì bá dúró?” (Orin Dáfídì 130:3) Àwọn ohun rere tí a ń ṣe ní sísìn ín ni Jèhófà n darí àfiyèsí sí.—Hébérù 6:10.
10. (a) Èé ṣe tí ó fi léwu fún àwọn alábàáṣègbéyàwó láti sọ ìmọrírì tí wọ́n ní fún ara wọn lẹ́nì kíní kejì nù? (b) Kí ni ẹnì kan tí ń sọ ìmọrírì fún ẹnì kejì rẹ̀ nù yẹ kí ó ṣe?
10 Ó ṣe pàtàkì gidigidi láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí nínú ìdílé. Nígbà tí àwọn òbí bá fi hàn pé àwọn mọrírì ara wọn lẹ́nì kíní kejì, wọ́n ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún ìdílé. Nínú sànmánì ìgbéyàwó àgbéjùsílẹ̀ yí, ó rọrùn púpọ̀ láti fojú yẹpẹrẹ wo ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó, kí a sọ àwọn àṣìṣe di ńlá, kí a sì fojú kéré àwọn ànímọ́ rere. Irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ ń ba ìgbéyàwó jẹ́, ó ń sọ ọ́ di ẹrù ìnira tí kì í fúnni láyọ̀. Bí ìmọrírì tí o ní fún alábàáṣègbéyàwó rẹ bá ń dín kù, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Òtítọ́ ha ni pé ẹnì kejì mi nínú ìgbéyàwó kò ní ànímọ́ rere kankan bí?’ Ronú pa dà sórí àwọn ìdí tí ìfẹ́ rẹ̀ fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tí o sì fi fẹ́ ẹ. Gbogbo ìdí wọ̀nyẹn tí o fi nífẹ̀ẹ́ ẹni títayọ yìí ha ti pòórá ní tòótọ́ bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí náà ṣiṣẹ́ kára láti mọrírì ànímọ́ rere tí alábàáṣègbéyàwó rẹ ní, kí o sì sọ ìmọrírì tí o ní fún un jáde.—Òwe 31:28.
11. Bí ìfẹ́ lọ́kọláya bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àgàbàgebè, àwọn àṣà wo ni wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún?
11 Ìmọrírì tún ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tọkọtaya láti má ṣe jẹ́ kí àgàbàgebè wọnú ìfẹ́ wọn. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 6:6; Pétérù Kíní 1:22.) Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, tí ìmọrírì àtọkànwá ń mú kí iná rẹ̀ túbọ̀ jó geerege, kò ní yọ̀ǹda fún ìwà òǹrorò nígbà tí ó bá ku ẹ̀yin nìkan, kò ní yọ̀ǹda fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ń dunni wọra, tí ń bu ẹ̀tẹ́ luni, kò ní yọ̀ǹda fún bíbáni yodì, tí ọ̀pọ̀ ọjọ́ yóò fi kọjá láìsọ̀rọ̀ onínúure tàbí ọ̀rọ̀ ẹ̀yẹ sí ẹnì kejì, ó sì dájú pé kò ní yọ̀ǹda fún líluni lálùbolẹ̀. (Éfésù 5:28, 29) Ọkọ àti aya tí ó mọrírì ara wọn lẹ́nì kíní kejì ní tòótọ́ ń bọlá fún ẹnì kíní kejì. Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bá wà láàárín àwọn ènìyàn nìkan ni wọ́n ń ṣe èyí ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí wọ́n bá wà níbi tí Jèhófà ti lè rí wọn—ní èdè míràn, ní gbogbo ìgbà.—Òwe 5:21.
12. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn òbí fi ìmọrírì hàn fún ànímọ́ rere tí àwọn ọmọ wọ́n ní?
12 Ó yẹ kí àwọn ọmọ pẹ̀lú nímọ̀lára pé a mọrírì àwọn. Kì í ṣe pé kí àwọn òbí máa pọ́n wọn lásán, ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ gbóríyìn fún àwọn ọmọ wọn fún àwọn ànímọ́ tí ó yẹ kí a gbóṣùbà fún tí wọ́n ní àti fún ojúlówó ohun rere tí wọ́n ṣe. Rántí àpẹẹrẹ Jèhófà ní ti sísọ títẹ́wọ́ tí ó tẹ́wọ́ gba Jésù jáde. (Máàkù 1:11) Rántí, pẹ̀lú, àpẹẹrẹ Jésù gẹ́gẹ́ bí “ọ̀gá” nínú òwe àkàwé kan. Ó gbóríyìn kan náà fún àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ “ẹrú rere àti olùṣòtítọ́,” bí ìyàtọ̀ tilẹ̀ wà nínú ohun tí a fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn àti nínú ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn jèrè. (Mátíù 25:20-23; fi wé Mátíù 13:23.) Bákan náà, àwọn ọlọgbọ́n òbí máa ń wá ọ̀nà láti sọ ìmọrírì wọn jáde nípa àwọn ànímọ́ títayọ, agbára, àti àṣeyọrí tí ọmọ wọn kọ̀ọ̀kan ní. Lọ́wọ́ kan náà, wọ́n ń gbìyànjú láti má ṣe tẹnu mọ́ àṣeyọrí ju bí ó ṣe yẹ lọ débi tí àwọn ọmọ wọn yóò fi máa gbèrò àtita àwọn ẹlòmíràn yọ nígbà gbogbo. Wọn kò fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn dàgbà di ẹni tí agara dá tàbí tí ó sorí kodò.—Éfésù 6:4; Kólósè 3:21.
13. Ta ní ń mú ipò iwájú nínú fífi ìmọrírì hàn fún mẹ́ńbà ìjọ kọ̀ọ̀kan?
13 Nínú ìjọ Kristẹni, àwọn alàgbà àti alábòójútó arìnrìn-àjò ń mú ipò iwájú nínú fífi ìmọrírì hàn fún mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú agbo Ọlọ́run. Ipò wọn kò rọrùn rárá, níwọ̀n bí wọ́n tún ti ní ẹrù iṣẹ́ wíwúwo ti bíbáni wí nínú òdodo, ti mímúni pa dà bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù, àti ti pípèsè ìmọ̀ràn lílágbára fún àwọn tí wọ́n nílò rẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe ń mú kí àwọn ẹrù iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí wà déédéé?—Gálátíà 6:1; Tímótì Kejì 3:16.
14, 15. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìwàdéédéé hàn nínú ọ̀ràn fífúnni ní ìmọ̀ràn ti ó lágbára? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni alábòójútó ṣe lè mú kí ìjẹ́pàtàkì rírannilọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe wà déédéé pẹ̀lú ìjẹ́pàtàkì gbígbóríyìn fúnni? Ṣàkàwé.
14 Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ń ranni lọ́wọ́ gidigidi. Ó jẹ́ olùkọ́ni, alàgbà, àti olùṣọ́ àgùntàn títayọ lọ́lá. Ó ní láti bá àwọn ìjọ tí wọ́n ní ìṣòro líle koko lò, ìbẹ̀rù kò sì mú kí ó fawọ́ fífún wọn ní ìmọ̀ràn lílágbára sẹ́yìn nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀. (Kọ́ríńtì Kejì 7:8-11) Gbígbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò fi hàn pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ó lo ìbáwí—kìkì nígbà tí ipò náà bá mú kí ó pọn dandan tàbí tí ipò náà bá béèrè fún un. Nínú èyí, ó fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn.
15 Bí a bá fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alàgbà kan nínú ìjọ wé orin, nígbà náà ìbáwí lè dà bí ohùn orin kan ṣoṣo tí ó bá orin náà mu lápapọ̀. Ohùn orin yẹn dára ní àyè tirẹ̀. (Lúùkù 17:3; Tímótì Kejì 4:2) Ronú nípa orin kan tí ó jẹ́ pé kìkì ohùn kan ṣoṣo yẹn ni ó ní, tí a sì fi kọ ọ́ léraléra. Kò ní pẹ́ sú waá gbọ́. Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni alàgbà ń gbìyànjú láti mú kí ọ̀nà ìkọ́ni wọn dán mọ́rán sí i, kí wọ́n sì fi onírúurú ọ̀nà ìkọ́ni mú kí ó gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Wọn kò fi mọ sórí ṣíṣàtúnṣe àwọn ìṣòro nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ń gbéni ró látòkè délẹ̀. Bíi Jésù Kristi, àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ ń kọ́kọ́ wa ohun rere tí wọn yóò gbóríyìn fúnni fún, kì í ṣe àṣìṣe tí wọn yóò ṣe lámèyítọ́ rẹ̀. Wọ́n mọrírì iṣẹ́ takuntakun tí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ń ṣe. Wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé ní gbogbogbòò, ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe ìwọ̀n tí agbára rẹ̀ ká láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. Àwọn alàgbà sì máa ń tètè sọ èrò yẹn jáde.—Fi wé Tẹsalóníkà Kejì 3:4.
16. Ipa wo ni ìṣarasíhùwà onímọrírì àti afọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Pọ́ọ̀lù ní, ní lórí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀?
16 Láìsí iyè méjì, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù ṣe ìránṣẹ́ fún nímọ̀lára pé ó mọrírì wọn àti pé ó ní ìmọ̀lára ọmọnìkejì fún wọn. Báwo ni a ṣe mọ èyí? Wo ìmọ̀lára tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù. Wọn kì í bẹ̀rù àtisún mọ́ ọn, bí ó tilẹ̀ ní ọlá àṣẹ ńláǹlà. Rárá o, ó jẹ́ olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ó sì ṣeé sún mọ́. Họ́wù, nígbà tí ó fi àgbègbè kan sílẹ̀, àwọn alàgbà ‘rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́’! (Ìṣe 20:17, 37) Ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí àwọn alàgbà—àti gbogbo wa pátá—kún fún ọpẹ́ tó pé a ní àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù láti tẹ̀ lé! Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ jẹ́ kí a fi ìmọrírì hàn fún ẹnì kíní kejì.
Ìṣe Inú Rere Onífẹ̀ẹ́
17. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn àbájáde rere tí ń jẹyọ láti inú ìṣe inú rere nínú ìjọ?
17 Ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì jù lọ tí ń mú kí iná ìfẹ́ ará máa jó geerege ni àwọn ìṣe onínúure kéékèèké. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Yálà a fúnni nípa tẹ̀mí, nípa ti ara, tàbí a lo àkókò àti agbára wa fúnni, kì í ṣe kìkì pé a ń mú àwọn ẹlòmíràn láyọ̀ nìkan ni ṣùgbọ́n a ń mú ara wa láyọ̀ pẹ̀lú. Nínú ìjọ, inú rere máa ń ránni. Ìwà onínúure kan ń mú òmíràn wá. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, ìfẹ́ni ará yóò ti gbilẹ̀!—Lúùkù 6:38.
18. Kí ni ìtumọ̀ “inú rere” tí a sọ nínú Míkà 6:8?
18 Jèhófà rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì láti fi inú rere hàn. Ní Míkà 6:8, a kà pé: “Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára. Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́ mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” Kí ni ó túmọ̀ sí láti “nífẹ̀ẹ́ inú rere”? Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a lò níhìn-ín fún “inú rere” (cheʹsedh) ni a tún ti tú sí “àánú” ní èdè Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Soncino Books of the Bible ti sọ, ọ̀rọ̀ yí “ní ìtúmọ̀ ohun kan tí ó gbéṣẹ́ ju ọ̀rọ̀ Yorùbá náà, àánú, tí ó ṣòro láti lóye. Ó túmọ̀ sí ‘àánú tí a fi hùwà,’ ìwà inú rere onífẹ̀ẹ́ tí a fi hàn, kì í ṣe sí àwọn òtòṣì àti aláìní nìkan, ṣùgbọ́n sí gbogbo ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa.” Nípa báyìí, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ míràn sọ pé cheʹsedh túmọ̀ sí “ìfẹ́ tí a fi hùwà.”
19. (a) Ní àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà lo àtinúdá láti fi inú rere hàn sí àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ? (b) Fúnni ní àpẹẹrẹ kan nípa bí a ṣe fi ìfẹ́ ará hàn sí ọ.
19 Ìfẹ́ ara wa kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Ó jẹ́ ohun tí ó wà ní ti gidi. Nítorí náà, wá ọ̀nà láti fi inú rere hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ. Dà bíi Jésù, tí kì í wulẹ̀ dúró kí àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n, tí ó sábà máa ń lo àtinúdá. (Lúùkù 7:12-16) Ní pàtàkì ronú nípa àwọn tí wọ́n wà ní ipò àìní jù lọ. Àgbàlagbà kan tàbí aláìlera kan ha nílò ìbẹ̀wò tàbí ìrànwọ́ láti bá a ṣiṣẹ́ ráńpẹ́ kan bí? ‘Ọmọ aláìníbaba’ ha wà tí ó yẹ kí a lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀, kí a sì fún un ní àfiyèsí díẹ̀ bí? Ọkàn kan tí ó sorí kọ́ ha nílò ẹni tí yóò tẹ́tí sí i tàbí bá a sọ̀rọ̀ ìtùnú bí? Bí ó bá ti ṣeé ṣe fún wa tó, ẹ jẹ́ kí a wá àkókò fún irú ìwà inú rere bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 29:12; Tẹsalóníkà Kíní 5:14; Jákọ́bù 1:27) Má ṣe gbàgbé láé pé nínú ìjọ kan tí ó kún fún àwọn ènìyàn aláìpé, ọ̀kan nínú àwọn ìṣe inú rere tí ó ṣe kókó jù lọ ni ìdáríjì—gbígbàgbé ohun kan tí ó bíni nínú, àní nígbà tí ìdí bá wà láti bínú. (Kólósè 3:13) Mímúratán láti dárí jini ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ìjọ wà níṣọ̀kan, kí ó máà sí kùnrùngbùn, àti aáwọ̀, tí ó dà bíi kúbùsù rínrin gbingbin tí ó ń pa iná ìfẹ́ ará.
20. Ọ̀nà wo ni gbogbo wa lè gbà máa yẹ ara wa wò?
20 Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti mú kí iná ìfẹ́ tí ó ṣe kókó yìí máa jó geerege nínú ọkàn àyà wa. Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ máa yẹ ara wa wò. A ha ń fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn fún àwọn ẹlòmíràn bí? A ha ń fi ìmọrírì hàn fún àwọn ẹlòmíràn bí? A ha ń fi ìṣe inú rere hàn sí àwọn ẹlòmíràn bí? Níwọ̀n bí a bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, iná ìfẹ́ yóò mú ẹgbẹ́ ará wa yá gágá sí i láìka bí ayé yìí ṣe lè jẹ́ aláìnífẹ̀ẹ́ àti aláìbìkítà tó. Ní gbogbo ọ̀nà, nígbà náà, “ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ̀yin ní máa bá a lọ”—nísinsìnyí àti títí láé!—Hébérù 13:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn olùtúmọ̀ kan sọ níhìn-ín pé kì í ṣe ojú Ọlọ́run ni ẹni tí ó bá fọwọ́ kan àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń fọwọ́ kan, bí kò ṣe ojú Ísírẹ́lì tàbí ojú tirẹ̀ fúnra rẹ̀ pàápàá. Àṣìṣe yìí wá láti ọwọ́ àwọn akọ̀wé ìgbà Sànmánì Agbedeméjì, tí wọ́n yí ẹsẹ yìí pa dà nínú ìsapá òdì wọn láti ṣàtúnṣe àwọn ẹsẹ tí wọ́n rò pé kò fi ọ̀wọ̀ hàn. Nípa báyìí, wọn kò jẹ́ kí aráyé mọ bí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jèhófà ní ṣe jinlẹ̀ tó.
Kí Ni Èrò Rẹ?
◻ Kí ni ìfẹ́ ará, èé sì ti ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó máa bá a lọ?
◻ Báwo ni níní ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti ní ìfẹ́ ara?
◻ Ipa wo ni ìmọrírì ń kó nínú ìfẹ́ ará?
◻ Báwo ni àwọn ìṣe inú rere ṣe lè mú kí ìfẹ́ ará gbilẹ̀ sí i nínú ìjọ Kristẹni?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìfẹ́ Lẹ́nu Iṣẹ́
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọkùnrin kan tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àkókò kan ṣì ń ṣiyè méjì nípa ìfẹ́ ará. Ó mọ̀ pé Jésù wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ṣùgbọ́n ó ṣòro fún un láti gba èyí gbọ́. Lọ́jọ́ kan ó rí ìfẹ́ Kristẹni lẹ́nu iṣẹ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àga arọ ni ó máa ń wà, ọkùnrin yìí máa ń rìnrìn àjò lọ sí ibi tí ó jìnnà sí ilé rẹ̀. Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Ísírẹ́lì, ó lọ sí ìpàdé ìjọ. Níbẹ̀, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ ará Arébíà rin kinkin mọ́ ọn pé kí Ẹlẹ́rìí mìíràn tí ó jẹ́ arìnrìn-àjò afẹ́ sùn sọ́dọ̀ ìdílé òun ní alẹ́ náà, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí pẹ̀lú wà lára àwọn tí ó ké sí láti dé sọ́dọ̀ òun. Kí ó tó lọ sùn, akẹ́kọ̀ọ́ náà béèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó gbà á lálejò bóyá òun lè láǹfààní láti jáde wo yíyọ oòrùn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́. Ẹni tí ó gbà á lálejò kìlọ̀ fún un gbọnmọ gbọnmọ pé kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ọjọ́ kejì arákùnrin tí ó jẹ́ ará Arébíà yí ṣàlàyé ìdí rẹ̀. Nípasẹ̀ olùgbufọ̀ kan, ó ní bí àwọn aládùúgbò òun bá mọ̀ pé Júù ni àwọn àlejò òun—bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ti jẹ́ Júù—wọn yóò dáná sun ilé òun àti ìdílé òun pátápátá. Nígbà tí ọ̀ràn náà rú u lójú, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bi í pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, èé ṣe tí ìwọ fi fara rẹ wewu tó bẹ́ẹ̀?” Láìlo olùgbufọ̀, arákùnrin tí ó jẹ́ ará Arébíà ná wo ojú rẹ̀, ó sì sọ pé, “Jòhánù 13:35.”
Ìfẹ́ ará tòótọ́ náà wú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lórí gidigidi. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó fi ṣe ìrìbọmi.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jíjẹ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tí ó lọ́yàyà tí ó sì mọrírì ẹni mú kí ó jẹ́ ẹni tí ó ṣeé sún mọ́