Ṣe Ìpolongo ní Gbangba fún Ìgbàlà
“Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.”—RÓÒMÙ 10:13.
1. Jálẹ̀ ìtàn, àwọn kìlọ̀kìlọ̀ wo ni a ti ṣe?
ÌTÀN ṣàpèjúwe ‘àwọn ọjọ́ Jèhófà’ mélòó kan. Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ìparun Sódómù àti Gòmórà, àti ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa àti ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, jẹ́ ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà. Wọ́n jẹ́ ọjọ́ ìmúdàájọ́ṣẹ sórí àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Málákì 4:5; Lúùkù 21:22) Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn, ọ̀pọ̀ pa run nítorí ìwà búburú wọn. Ṣùgbọ́n àwọn kan là á já. Jèhófà mú kí a ṣe kìlọ̀kìlọ̀, ní fífi jàǹbá tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ tó àwọn ènìyàn burúkú létí àti ní fífún àwọn olótìítọ́ ọkàn ní àǹfààní láti rí ìgbàlà.
2, 3. (a) Ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wo ni a ṣàyọlò rẹ̀ nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì? (b) Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, kí ni kíképe orúkọ Jèhófà ń béèrè?
2 Ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa jẹ́ àpẹẹrẹ pàtàkì ní ti èyí. Nígbà tí ó ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ní nǹkan bí 900 ọdún ṣáájú, wòlíì Jóẹ́lì kọ̀wé pé: “Èmi yóò fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti àwọn ìṣùpọ̀ èéfín adúró-bí-ọwọ̀n. A óò yí oòrùn padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.” Báwo ni yóò ṣe ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti la irú àkókò tí ń bani lẹ́rù bẹ́ẹ̀ já? Jóẹ́lì kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́; nítorí pé àwọn tí ó sá àsálà yóò wà ní Òkè Ńlá Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ, àti lára àwọn olùlàájá, àwọn tí Jèhófà ń pè.”—Jóẹ́lì 2:30-32, NW.
3 Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù bá àwùjọ Júù àti aláwọ̀ṣe ní Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀, ó sì ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, ní fífihàn pé àwọn olùgbọ́ òun lè retí ìmúṣẹ ní ọjọ́ tiwọn pé: “Èmi yóò sì fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ ìyanu ní ọ̀run lókè àti àwọn iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti ìkùukùu èéfín; a óò yí oòrùn pa dà di òkùnkùn àti òṣùpá pa dà di ẹ̀jẹ̀ kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ alókìkíkáyé ti Jèhófà tó dé. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.” (Ìṣe 2:16-21) Gbogbo àwùjọ tí ń tẹ́tí sí Pétérù wà lábẹ́ Òfin Mósè, nítorí náà, wọ́n mọ orúkọ Jèhófà. Pétérù ṣàlàyé pé, láti ìsinsìnyí lọ, kíké pe orúkọ Jèhófà yóò ní nǹkan mìíràn nínú. Ní pàtàkì, èyí kan ṣíṣe batisí ní orúkọ Jésù, ẹni tí a ti pa, tí a sì jí dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run.—Ìṣe 2:37, 38.
4. Ìhìn iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni polongo kárí ayé?
4 Láti Pẹ́ńtíkọ́sì lọ, àwọn Kristẹni tan ọ̀rọ̀ nípa Jésù tí a jí dìde kiri. (Kọ́ríńtì Kíní 1:23) Wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run lè sọ àwọn ẹ̀dá ènìyàn dọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì di apá kan “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tuntun, orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tí yóò ‘polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá Jèhófà.’ (Gálátíà 6:16; Pétérù Kíní 2:9) Àwọn tí wọ́n jẹ́ olótìítọ́ títí dé ojú ikú yóò jogún ìyè àìleèkú ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. (Mátíù 24:13; Róòmù 8:15, 16; Kọ́ríńtì Kíní 15:50-54) Síwájú sí i, àwọn Kristẹni wọ̀nyí ní láti polongo bíbọ̀ ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà. Wọ́n ní láti kìlọ̀ fún ayé Júù pé yóò nírìírí ìpọ́njú tí ó ré kọjá ohunkóhun tí ó tí ì kọ lu Jerúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé ti Ọlọ́run ni àwọn, títí di àkókò yẹn. Ṣùgbọ́n, àwọn tí yóò là á já yóò wà. Àwọn wo nìyẹn? Àwọn tí wọ́n ké pe orúkọ Jèhófà.
“Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn”
5. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ó ti ní ìmúṣẹ lónìí?
5 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, àwọn ipò nǹkan nígbà náà lọ́hùn-ún jẹ́ òjìji àwọn ohun tí a ń rí lónìí. Láti 1914, aráyé ti ń gbé ní àkókò àrà ọ̀tọ̀ kan tí Bíbélì tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “ìgbà ìkẹyìn,” “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan,” àti “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Dáníẹ́lì 12:1, 4; Mátíù 24:3-8; Tímótì Kejì 3:1-5, 13) Ní ọ̀rúndún wa, ogun rírorò, ìwà ipa tí kò ṣeé kó níjàánu, àti rírun àwùjọ àti àyíká ti mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ lọ́nà kíkàmàmà. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ apá kan àmì tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, tí ń fi hàn pé aráyé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ nírìírí àṣekágbá ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tí yóò jẹ́ àjàmọ̀gá. Èyí yóò dé òtéńté rẹ̀ nínú ogun Amágẹ́dọ́nì, òtéńté “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Mátíù 24:21; Ìṣípayá 16:16.
6. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ti ń gbégbèésẹ̀ láti gba àwọn ọlọ́kàn tútù là? (b) Níbo ni a ti rí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù lórí bí a ti lè là á já?
6 Bí ọjọ́ ìdahoro ti ń sún mọ́lé, Jèhófà ń gbégbèésẹ̀ fún ìgbàlà àwọn ọlọ́kàn tútù. Ní “ìgbà ìkẹyìn” yí, ó ti kó ìyókù Ísírẹ́lì tẹ̀mí Ọlọ́run jọ, ó sì ti yíjú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, láti àwọn ọdún 1930 wá, sí kíkó “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” jọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, àwọn wọ̀nyí “jáde wá” láàyè “láti inú ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣípayá 7:9, 14) Ṣùgbọ́n, báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe lè mú kí lílàájá rẹ̀ dájú? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yẹn. Nínú Róòmù orí 10, ó fúnni ní ìmọ̀ràn àtàtà fún lílà á já—ìmọ̀ràn tí ó wúlò ní ọjọ́ rẹ̀, tí ó sì tún wúlò ní ọjọ́ tiwa.
Àdúrà Ìgbàlà
7. (a) Ìrètí wo ni a fi hàn nínú Róòmù 10:1, 2? (b) Èé ṣe tí Jèhófà fi lè mú kí a polongo “ìhìn rere” náà lọ́nà tí ó gbòòrò sí i nísinsìnyí?
7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Róòmù, Jèhófà ti pa Ísírẹ́lì tì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, àpọ́sítélì náà sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà pé: “Ìfẹ́ rere ọkàn àyà mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn, ní tòótọ́, jẹ́ fún ìgbàlà wọn.” Ìrètí rẹ̀ ní pé kí Júù kọ̀ọ̀kan lè jèrè ìmọ̀ pípéye ti ìfẹ́ inú Ọlọ́run, tí yóò yọrí sí gbígbà wọ́n là. (Róòmù 10:1, 2) Síwájú sí i, Jèhófà yóò fẹ́ ìgbàlà fún gbogbo ayé aráyé tí ó lo ìgbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù 3:16 ti fi hàn pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà pa run ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Ẹbọ ìràpadà Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìgbàlà gíga lọ́lá yẹn. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Nóà àti ní àwọn ọjọ́ ìdájọ́ mìíràn tí ó tẹ̀ lé e, Jèhófà mú kí a polongo “ìhìn rere,” ní títọ́ka sí ọ̀nà ìgbàlà.—Máàkù 13:10, 19, 20.
8. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, àwọn wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ń nawọ́ ìfẹ́ inú rere sí lónìí, lọ́nà wo sì ni?
8 Ní fífi ìfẹ́ inú rere òun fúnra rẹ̀ hàn sí Júù àti Kèfèrí, Pọ́ọ̀lù lo gbogbo àǹfààní tí ó ní láti wàásù. Ó ‘ń yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò pa dà.’ Ó sọ fún àwọn alàgbà ní Éfésù pé: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” (Ìṣe 18:4; 20:20, 21) Lọ́nà kan náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ń lo ara wọn nínú wíwàásù, kì í ṣe fún kìkì àwọn tí ó sọ pé Kristẹni ni àwọn ṣùgbọ́n fún gbogbo ènìyàn, àní títí dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8; 18:5.
Jíjẹ́wọ́ “‘Ọ̀rọ̀’ Ìgbàgbọ́”
9. (a) Irú ìgbàgbọ́ wo ni Róòmù 10:8, 9 rọni láti ní? (b) Nígbà wo ni ó yẹ kí a jẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wa, lọ́nà wo sì ni?
9 Ó ń béèrè ìgbàgbọ́ tí ń wà pẹ́ títí láti lè jèrè ìgbàlà. Ní ṣíṣàyọlò Diutarónómì 30:14, Pọ́ọ̀lù polongo pé: “‘Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, ní ẹnu ìwọ fúnra rẹ àti ní ọkàn àyà ìwọ fúnra rẹ’; èyíinì ni, ‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́, èyí tí àwa ń wàásù.” (Róòmù 10:8) Bí a ti ń wàásù “‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́” náà, ó túbọ̀ ń wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin sí i. Bí ó ti rí pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù nìyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ̀ lé e sì lè fún ìpinnu wa láti dà bí i rẹ̀ ní ṣíṣàjọpín ìgbàgbọ́ yẹn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lókun: “Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ní ẹnu ìwọ fúnra rẹ’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, a óò gbà ọ́ là.” (Róòmù 10:9) Kì í ṣe kìkì pé kí a ṣe ìjẹ́wọ́ yìí níwájú àwọn ẹlòmíràn nígbà tí a ṣe batisí nìkan, ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìjẹ́wọ́ tí ń bá a lọ títí, ẹ̀rí ìtagbangba àfìtaraṣe nípa gbogbo apá títóbilọ́lá ti òtítọ́. Irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ darí àfiyèsí sórí orúkọ ṣíṣeyebíye ti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ; sórí Mèsáyà Ọba àti Olùràpadà wa, Olúwa Jésù Kristi; àti sórí àwọn ìlérí ńláǹlà ti Ìjọba.
10. Ní ìbámu pẹ̀lú Róòmù 10:10, 11, ọwọ́ wo ni ó yẹ kí a fi mú “‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́” yìí?
10 Kò sí ìgbàlà fún ẹnikẹ́ni tí kò bá gba “‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́” yìí, kí ó sì lò ó, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì náà tí ń bá a lọ láti sọ pé: “Ọkàn àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà. Nítorí Ìwé Mímọ́ wí pé: ‘Kò sí ẹnì kankan tí ń gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e tí a óò já kulẹ̀.’” (Róòmù 10:10, 11) A gbọ́dọ̀ jèrè ìmọ̀ pípéye “‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́” yí, kí a sì máa bá a lọ láti ṣìkẹ́ rẹ̀ nínú ọkàn àyà wa, kí a lè sún wa láti sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Jésù fúnra rẹ̀ rán wa létí pé: “Ẹni yòó wù tí ó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yí Ọmọkùnrin ènìyàn pẹ̀lú yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé nínú ògo Bàbá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.”—Máàkù 8:38.
11. Báwo ni pípolongo ìhìn rere náà ṣe yẹ kí ó gbòòrò tó, èé sì ti ṣe?
11 Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀, ní àkókò òpin yìí, a rí “àwọn ọlọgbọ́n” tí ń tàn “bí ìmọ́lẹ̀ òfuurufú,” bí ìwàásù Ìjọba ti ń tàn kálẹ̀ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Wọ́n “ń yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ pa dà sí òdodo,” ìmọ̀ tòótọ́ sì ti pọ̀ yanturu ní tòótọ́, nítorí Jèhófà túbọ̀ ń tan ìmọ́lẹ̀ títàn yòò sórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò òpin yìí. (Dáníẹ́lì 12:3, 4) Èyí jẹ́ ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà tí ó ṣe kókó fún lílà á já gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo.
12. Báwo ni Róòmù 10:12 ṣe so mọ́ àṣẹ áńgẹ́lì náà tí a sọ nínú Ìṣípayá 14:6?
12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ pé: “Kò sí ààlà ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì, nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ sí gbogbo àwọn wọnnì tí ń ké pè é.” (Róòmù 10:12) A gbọ́dọ̀ wàásù “ìhìn rere” náà lónìí ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ gbòòrò sí i kárí ayé—fún gbogbo ènìyàn, dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé pátápátá. Áńgẹ́lì inú Ìṣípayá 14:6 ṣì ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ní fífi “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” lé wa lọ́wọ́ “láti polongo gẹ́gẹ́ bí àwọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn wọnnì tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” Báwo ni èyí yóò ṣe ṣàǹfààní fún àwọn tí ó bá dáhùn pa dà?
Kíképe Orúkọ Jèhófà
13. (a) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún wa ti 1998? (b) Èé ṣe tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yìí fi bá a mu wẹ́kú lónìí?
13 Ní ṣíṣàyọlò Jóẹ́lì 2:32, Pọ́ọ̀lù polongo pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.” (Róòmù 10:13) Ẹ wo bí ó ti bá a mu wẹ́kú tó pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni a yàn fi ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún 1998! Kò tí ì ṣe pàtàkì tó báyìí rí láti tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, ní sísọ orúkọ rẹ̀ àti ète títóbilọ́lá tí ó dúró fún di mímọ̀! Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí tí ó díbàjẹ́, igbe dídún kíkankíkan náà jáde pé: “Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí.” (Ìṣe 2:40) Ó jẹ́ ìkésíni tí ń dún bíi kàkàkí fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run kárí ayé láti ké pe Jèhófà pé kí ó gba àwọn àti àwọn tí ó tẹ́tí sí ìpolongo ìhìn rere wọn ní gbangba là.—Tímótì Kíní 4:16.
14. Àpáta wo ni ó yẹ kí a ké pè fún Ìgbàlà?
14 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọjọ́ ńlá Jèhófà bá dé sórí ayé yìí? Ọ̀pọ̀ kì yóò yíjú sí Jèhófà fún ìgbàlà. Aráyé lápapọ̀ yóò máa “wí fún àwọn òkè ńlá àti àwọn àpáta ràbàtà pé: ‘Ẹ wó bò wá kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò ní ojú Ẹni náà tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti kúrò nínú ìrunú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’” (Ìṣípayá 6:15, 16) Ìrètí wọn yóò wà nínú àwọn ètò àti àjọ bí òkè ńlá ti ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí ì bá ti dára tó ká ní wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Àpáta títóbilọ́lá jù lọ náà, Jèhófà Ọlọ́run! (Diutarónómì 32:3, 4) Nípa rẹ̀, Ọba Dáfídì sọ pé: “Olúwa ni àpáta mi, àti ìlú olódi mi, àti olùgbàlà mi.” Jèhófà ni “àpáta ìgbàlà wa.” (Orin Dáfídì 18:2; 95:1) Orúkọ rẹ̀ “ilé ìṣọ́ agbára ni,” “ilé ìṣọ́” kan ṣoṣo tí agbára rẹ̀ tó láti dáàbò bò wá nígbà yánpọnyánrin tí ń bọ̀. (Òwe 18:10) Nítorí náà, ó ṣe kókó pé kí a kọ́ iye tí ó bá ṣeé ṣe tó nínú nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́fà ènìyàn tí ó wà láàyè lónìí láti ké pe orúkọ Jèhófà pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti òótọ́ inú.
15. Kí ni Róòmù 10:14 fi hàn nípa ìgbàgbọ́?
15 Lọ́nà tí ó bá a mu, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹ̀ síwájú láti béèrè pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” (Róòmù 10:14) Ògìdìgbó ènìyàn wà tí a ṣì lè ràn lọ́wọ́ láti sọ “‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́” náà di ti wọn, kí wọ́n lè ké pe Jèhófà fún ìgbàlà. Ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì gidigidi. Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà míràn pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun di olùsẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ṣùgbọ́n, báwo ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn ṣe lè wá lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run? Nínú lẹ́tà sí àwọn ará Róòmù, Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀?” (Róòmù 10:14) Jèhófà ha pèsè àǹfààní fún wọn láti gbọ́ bí? Dájúdájú, ó ṣe bẹ́ẹ̀! Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí ó tẹ̀ lé e pé: “Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?”
16. Nínú ìṣètò àtọ̀runwá, èé ṣe tí a fi nílò àwọn oníwàásù?
16 Láti inú àlàyé Pọ́ọ̀lù, ó ṣe kedere pé a nílò àwọn oníwàásù. Jésù fi hàn pé ọ̀ràn yóò rí bẹ́ẹ̀, títí di “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:14; 28:18-20) Ìwàásù jẹ́ apá pàtàkì ìṣètò àtọ̀runwá fún ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ké pe orúkọ Jèhófà kí wọ́n lè yè bọ́. Àní nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù pàápàá, ọ̀pọ̀ jù lọ kò ṣe ohunkóhun láti bọlá fún orúkọ Ọlọ́run náà tí ó ṣeyebíye. Ọ̀pọ̀ ti ṣi Jèhófà mú fún àwọn ẹni méjì míràn nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò ṣeé ṣàlàyé. Bákan náà, ọ̀pọ̀ wà lára ọ̀wọ́ àwọn ènìyàn tí a sọ̀rọ̀ wọn nínú Orin Dáfídì 14:1 àti 53:1 pé: “Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé, Ọlọ́run kò sí.” Ó pọn dandan kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run alààyè, wọ́n sì gbọ́dọ̀ lóye gbogbo ohun tí orúkọ rẹ̀ dúró fún bí wọn yóò bá yè bọ́ nínú ìpọ́njú ńlá tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.
‘Ẹsẹ̀ Rèǹtè Rente’ Àwọn Oníwàásù
17. (a) Èé ṣe tí ó fi bá a mu pé kí Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò? (b) Kí ni níní ‘ẹsẹ̀ rèǹtè rente’ ní nínú?
17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìbéèrè ṣíṣe kókó kan sí i: “Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe wàásù láìjẹ́ pé a ti rán wọn jáde? Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ àwọn wọnnì tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere ti dára rèǹtè rente tó!’” (Róòmù 10:15) Pọ́ọ̀lù níhìn-ín ṣàyọlò Aísáyà 52:7, tí ó jẹ́ ara àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò tí ó ti ń nímùúṣẹ láti ọdún 1919. Lónìí, lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà rán “ẹni tí ń mú ìhìn rere wá . . . , ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́,” jáde. Pẹ̀lú ìgbọràn, “àwọn olùṣọ́” tí Ọlọ́run fi òróró yàn àti àwọn alájọṣepọ̀ wọn ń bá a lọ láti fi ìdùnnú kígbe jáde. (Aísáyà 52:7, 8, NW) Bí wọ́n ti ń rìn láti ilé dé ilé, ẹsẹ̀ àwọn tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́ lónìí lè máa ro wọ́n, kí ó tilẹ̀ bu tátá, ṣùgbọ́n, ẹ wo bí ojú wọ́n ti ń dán gbinrin fún ayọ̀ tó! Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ni ó yan àwọn láti polongo ìhìn rere àlàáfíà àti láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, ní ríran àwọn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti ké pe orúkọ Jèhófà pẹ̀lú ìgbàlà lọ́kàn.
18. Kí ni Róòmù 10:16-18 sọ nípa àbájáde ìkẹyìn ti kíkéde ìhìn rere?
18 Yálà àwọn ènìyàn ‘lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n gbọ́’ tàbí wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí i, ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣì jẹ́ òtítọ́ pé: “Wọn kò kùnà láti gbọ́, àbí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Họ́wù, ní ti tòótọ́, ‘ìró wọ́n jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti àwọn gbólóhùn àsọjáde wọn sí àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.’” (Róòmù 10:16-18) Gan-an gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọ̀run” ti “ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọ́run,” bí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ti fi hàn, bẹ́ẹ̀ náà ni Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ polongo “ọdún ìtẹ́wọ́gbà Olúwa, àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa . . . láti tu gbogbo àwọn tí [ń ṣọ̀fọ̀] nínú.”—Orin Dáfídì 19:1-4; Aísáyà 61:2.
19. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n “ké pe orúkọ Jèhófà” lónìí?
19 Ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà sún mọ́lé ju ìgbàkígbà rí lọ. “A! fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, àti bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè ni yóò dé.” (Jóẹ́lì 1:15; 2:31) Àdúrà wa ni pé kí àwọn ògìdìgbó túbọ̀ dáhùn pa dà ní kánjúkánjú sí ìhìn rere náà, ní rírọ́ wá sínú ètò àjọ Jèhófà. (Aísáyà 60:8; Hábákúkù 2:3) Rántí pé àwọn ọjọ́ Jèhófà míràn mú ìrunbàjẹ́ wá sórí àwọn ènìyàn búburú—ní ọjọ́ Nóà, ní ọjọ́ Lọ́ọ̀tì, àti ní àwọn ọjọ́ Ísírẹ́lì àti Júdà apẹ̀yìndà. Nísinsìnyí, a wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìpọ́njú ńlá tí ó burú jù lọ, nígbà tí ààjà Jèhófà yóò palẹ̀ ìwà búburú mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé yìí, ní ṣíṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún párádísè àlàáfíà ayérayé kan. Ìwọ yóò ha jẹ́ ẹni tí “ń ké pe orúkọ Jèhófà” ní ìṣòtítọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kún fún ayọ̀! Ìlérí Ọlọ́run wà fún ọ pé a óò gbà ọ́ là.—Róòmù 10:13.
Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Àwọn ohun tuntun wo ni a polongo lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
◻ Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni fiyè sí “‘ọ̀rọ̀’ ìgbàgbọ́”?
◻ Kí ni ‘kíképe orúkọ Jèhófà’ túmọ̀ sí?
◻ Ní èrò wo ni àwọn ońṣẹ́ Ìjọba fi ní ‘ẹsẹ̀ rèǹtè rente’?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń polongo ìtayọlọ́lá rẹ̀ ní Puerto Rico, Senegal, Peru, Papua New Guinea—àní, kárí ayé