Òmìnira Ológo fún Àwọn Ọmọ Ọlọ́run Láìpẹ́
“A tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo . . . nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—RÓÒMÙ 8:20, 21.
1. Báwo ni a ṣe ṣàpẹẹrẹ ìrúbọ Jésù ní Ọjọ́ Ètùtù?
JÈHÓFÀ fúnni ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà tí ó ṣí ọ̀nà ìyè ti ọ̀run sílẹ̀ fún àwọn 144,000 ẹ̀dá ènìyàn, àti ìfojúsọ́nà ayérayé lórí ilẹ̀ ayé fún ìyókù aráyé. (1 Jòhánù 2:1, 2) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, a ṣàpẹẹrẹ ìrúbọ Jésù fún àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí nígbà tí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì fi akọ màlúù kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, agbo ilé rẹ̀, àti ẹ̀yà Léfì ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún. Ní ọjọ́ kan náà, ó fi ewúrẹ́ kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, àní gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ Kristi yóò ti ṣe aráyé ní gbogbogbòò láǹfààní. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ààyè ewúrẹ́ kan yóò gbé àpapọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ènìyàn náà dá ní ọdún tí ó kọjá lọ, nípa rírìn lọ sínú aginjù.a—Léfítíkù 16:7-15, 20-22, 26.
2, 3. Kí ni ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí a kọ sílẹ̀ nínú Róòmù 8:20, 21 túmọ̀ sí?
2 Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé ìrètí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọn yóò di “ọmọ Ọlọ́run” ní ọ̀run, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:14, 17, 19-21) Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn yìí?
3 Nígbà tí a dá baba ńlá wa Ádámù gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé, òun jẹ́ “ọmọkùnrin [tàbí, ọmọ] Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Nítorí dídẹ́ṣẹ̀, òun wá sínú “ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,” ó sì tàtaré ipò yìí sí ìran ẹ̀dá ènìyàn. (Róòmù 5:12) Nítorí àìpé tí àwọn ènìyàn ti jogún, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí a bí wọn sínú ipò tí ó dojú kọ “ìmúlẹ̀mófo,” ṣùgbọ́n ó fúnni ní ìrètí nípasẹ̀ “irú-ọmọ” náà, Jésù Kristi. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:18; Gálátíà 3:16) Ìṣípayá 21:1-4 tọ́ka sí àkókò tí ‘ikú, ọ̀fọ̀, igbe ẹkún, àti ìrora kì yóò sí mọ́.’ Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ ìlérí tí a ṣe fún “aráyé,” ó mú un dá wa lójú pé àwùjọ tuntun ti ẹ̀dá ènìyàn orí ilẹ̀ ayé tí ń gbé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà yóò gbádùn mímú èrò inú àti ara wọn wá sí ìlera kíkún rẹ́rẹ́ àti ìyè àìnípẹ̀kun gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ Ọlọ́run” lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún Kristi, a óò “dá” àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn “sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin ti Jèhófà nígbà ìdánwò ìkẹyìn, wọn yóò bọ́ títí láé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá àti ikú. (Ìṣípayá 20:7-10) Àwọn tí ó bá wà lórí ilẹ̀ ayé yóò wá “ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”
Wọ́n Ń Sọ Pé “Máa Bọ̀!”
4. Kí ni ó túmọ̀ sí láti “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”?
4 Ẹ wo ìrètí àgbàyanu tí a gbé ka iwájú aráyé! Abájọ tí àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń fi ìtara mú ipò iwájú ní sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀! Gẹ́gẹ́ bí àwọn ti yóò di apá kan “ìyàwó” Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà tí a ṣe lógo, Jésù Kristi, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ń lọ́wọ́ nínú ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí pé: “Ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 21:2, 9; 22:1, 2, 17) Rárá, àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù kò mọ sọ́dọ̀ àwọn 144,000 ẹni àmì òróró. Ẹ̀mí Ọlọ́run ń bá iṣẹ́ nìṣó nípasẹ̀ àwọn tí ó ṣẹ́kù lára ẹgbẹ́ ìyàwó náà lórí ilẹ̀ ayé, ní sísọ pé “Máa Bọ̀.” Ó ń ké sí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo láti sọ pé “Máa Bọ̀,” ní lílo àǹfààní ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè Jèhófà fún ìgbàlà.
5. Àwọn wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń láyọ̀ láti ní láàárín wọn?
5 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìpèsè Ọlọ́run fún ìyè nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Ìṣe 4:12) Wọ́n láyọ̀ láti ní àwọn aláìlábòsí ọkàn láàárín wọn, tí wọ́n ń fẹ́ láti kọ́ nípa àwọn ète Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ṣí sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá fẹ́ láti ‘wá gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́’ ní “àkókò òpin” yìí.—Dáníẹ́lì 12:4.
Àwọn Ìyípadà Bí Àkókò Ti Ń Lọ
6. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ti ṣe ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní àwọn àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
6 Ọlọ́run ní àkókò tí òun yóò mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ, èyí sì ń nípa lórí bí ohun ṣe ń bá àwọn ènìyàn lò. (Oníwàásù 3:1; Ìṣe 1:7) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkókò tí ó ṣáájú sànmánì ẹ̀sìn Kristẹni, a kò bí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, bẹ̀rẹ̀ látorí Jésù, àkókò Jèhófà ti tó láti lo ẹ̀mí mímọ́ láti bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣèyàsímímọ́ sínú ogún ti ọ̀run. Ọjọ́ wa wá ńkọ́? Ẹ̀mí kan náà ni ó ń ṣiṣẹ́ lórí “àwọn àgùntàn mìíràn” ti Jésù, ṣùgbọ́n kò ru ìrètí àti ìfẹ́-ọkàn fún ìyè ti ọ̀run sókè nínú wọn. (Jòhánù 10:16) Bí wọ́n ti ní ìrètí tí Ọlọ́run fi fún wọn, ti ìyè ayérayé lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan, wọ́n ń ti àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn tayọ̀tayọ̀ ní jíjẹ́rìí ní àkókò tí ayé ògbólógbòó yìí fẹ́ di ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.—2 Pétérù 3:5-13.
7. Iṣẹ́ ìkórè wo ni ó jẹ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lógún, ṣùgbọ́n kí ni wọ́n mọ̀ nípa párádísè?
7 Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ‘mú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo’ nípa títú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, lọ́nà tí ó sì ṣe kedere, òun yan àkókò fún mímú kí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nípa tẹ̀mí pé pérépéré tí àpapọ̀ wọn jẹ́ 144,000. (Hébérù 2:10; Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 7:1-8) Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1879, a sábà máa ń mẹ́nu kan iṣẹ́ ìkórè kan tí ó ní àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nínú, nínú ìwé ìròyìn yìí. Ṣùgbọ́n Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (tí a ń pè ní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí) mọ̀ pẹ̀lú pé Ìwé Mímọ́ nawọ́ ìrètí ìyè ayérayé lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan jáde. Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ July 1883 wí pé: “Nígbà tí Jésù bá ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ tán, tí kò bá sí ìwà ibi mọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ilẹ̀ ayé yìí yóò di párádísè kan, . . . gbogbo àwọn tí ó wà nínú sàréè wọn yóò sì wá sínú rẹ̀. Bí wọ́n bá sì ṣègbọ́ràn sí àwọn òfin rẹ̀, wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú rẹ̀.” Bí àkókò ti ń lọ, ìkórè àwọn ẹni àmì òróró dín kù, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, a sì ń kórè àwọn tí kò ní ìrètí ti ọ̀run sínú ètò àjọ Jèhófà. Láàárín àkókò yìí, Jèhófà fi ìjìnlẹ̀ òye títayọ lọ́lá jíǹkí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró, tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tí a tún bí.—Dáníẹ́lì 12:3; Fílípì 2:15; Ìṣípayá 14:15, 16.
8. Báwo ni òye nípa ìrètí orí ilẹ̀ ayé ṣe gbèrú ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930?
8 Ní pàtàkì láti ọdún 1931 ni àwọn tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé ti ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni. Ní ọdún yẹn, Jèhófà la àṣẹ́kù àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí lóye láti rí i pé Ìsíkẹ́ẹ̀lì orí 9 tọ́ka sí ẹgbẹ́ orí ilẹ̀ ayé yìí, àwọn tí a ń sàmì sí fún lílàájá sínú ayé tuntun Ọlọ́run. Ní ọdún 1932, a dórí ìparí èrò náà pé irú àwọn ẹni bí àgùntàn bẹ́ẹ̀ lónìí ní Jónádábù (Jèhónádábù), alábàákẹ́gbẹ́ Jéhù, ṣàpẹẹrẹ. (2 Àwọn Ọba 10:15-17) Ní ọdún 1934, a mú kí ó ṣe kedere pé “àwọn Jónádábù” gbọ́dọ̀ “ya ara wọn sọ́tọ̀,” tàbí ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ní ọdún 1935, “ògìdìgbó,” tàbí “ogunlọ́gọ̀ ńlá”—tí a ronú tẹ́lẹ̀ pé ó jẹ́ ẹgbẹ́ tẹ̀mí onípò kejì tí yóò jẹ́ “alábàákẹ́gbẹ́” ìyàwó Kristi ní ọ̀run—ni a fi hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n ní ìrètí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:4-15; 21:2, 9; Sáàmù 45:14, 15) Àti ní pàtàkì, láti ọdún 1935 ni àwọn ẹni àmì òróró ti ń mú ipò iwájú nínú wíwá àwọn ènìyàn ọlọ́kàn títọ́ tí wọ́n ń yán hànhàn láti wà láàyè títí láé nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé.
9. Lẹ́yìn ọdún 1935, èé ṣe tí àwọn Kristẹni kan fi ṣíwọ́ ṣíṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
9 Lẹ́yìn ọdún 1935, àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ń ṣàjọpín nínú àkàrà àti wáìnì nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ṣíwọ́ ṣíṣàjọpín. Èé ṣe? Nítorí wọ́n wá mọ̀ pé ìrètí wọn jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe ti ọ̀run. Obìnrin kan tí a batisí ní ọdún 1930 wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ka [ṣíṣàjọpín] sí ohun tí ó tọ́ láti ṣe, ní pàtàkì fún àwọn onítara òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, kò dá mi lójú rí láé pé mo ní ìrètí ti ọ̀run. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1935, a mú kí ó yé wa pé a ti ń kó ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ pẹ̀lú ìrètí wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ lára wa láyọ̀ láti mọ̀ pé a jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá yẹn, a sì ṣíwọ́ ṣíṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ.” Àní ọ̀rọ̀ inú àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni pàápàá yí padà. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ti àwọn ọdún tí ó ṣáájú ni a pète ní pàtàkì fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí a fi ẹ̀mí bí, láti ọdún 1935 lọ, Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn ti “ẹrú olóòótọ́” náà, pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí a mú bá àìní àwọn ẹni àmì òróró àti ti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé mu.—Mátíù 24:45-47.
10. Báwo ni a ṣe lè fi ẹnì kan rọ́pò ẹni àmì òróró tí ó jẹ́ aláìṣòótọ́?
10 Jẹ́ ká sọ pé ẹni àmì òróró kan di aláìṣòótọ́. Ṣé a óò fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀? Pọ́ọ̀lù fi hàn bẹ́ẹ̀ nínú ìjíròrò rẹ̀ nípa igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ. (Róòmù 11:11-32) Bí ó bá yẹ kí a fi ẹnì kan rọ́pò ẹni tí a ti fi ẹ̀mí bí, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹnì kan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sí Ọlọ́run ni yóò fún ní ìpè ti ọ̀run.—Fi wé Lúùkù 22:28, 29; 1 Pétérù 1:6, 7.
Ọ̀pọ̀ Ìdí fún Mímoore
11. Láìka ohun yòówù kí ó jẹ́ ìrètí wa sí, kí ni Jákọ́bù 1:17 mú dá wa lójú?
11 Níbikíbi tí a bá ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, òun yóò kúnjú àwọn àìní àti àwọn ìfẹ́-ọkàn títọ́ wa. (Sáàmù 145:16; Lúùkù 1:67-74) Yálà a ní ojúlówó ìrètí ti ọ̀run tàbí tí ìfojúsọ́nà wa jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé, a ní ọ̀pọ̀ ìdí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti kún fún ìmoore sí Ọlọ́run. Òun nígbà gbogbo máa ń ṣe àwọn nǹkan tí ó jẹ́ fún ire dídára jù lọ ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ pé “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,” Jèhófà Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:17) Jẹ́ kí a kíyè sí díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀bùn àti ìbùkún wọ̀nyí.
12. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jèhófà ti fún olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ ní ìrètí àgbàyanu?
12 Jèhófà ti fún olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìrètí àgbàyanu. Ó ti pe àwọn kan sí ìyè ti ọ̀run. Fún àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ tí ó wà ṣáájú sànmánì ẹ̀sìn Kristẹni, Jèhófà fún wọn ní ìrètí ológo ti àjíǹde sí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Fún àpẹẹrẹ, Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde, ó sì dúró de “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́”—Ìjọba ọ̀run lábẹ́ èyí tí a óò ti jí i dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé. (Hébérù 11:10, 17-19) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ní àkókò òpin yìí, Ọlọ́run ń fi ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé jíǹkí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 17:3) Dájúdájú, ó yẹ kí ẹnikẹ́ni tí Jèhófà bá ti fún ní irú ìrètí kíkọyọyọ bẹ́ẹ̀ kún fún ìmoore gidigidi nítorí rẹ̀.
13. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ṣiṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn rẹ̀?
13 Jèhófà ń bun àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ ni a fi yan àwọn Kristẹni tí a fún ní ìrètí ti ọ̀run. (1 Jòhánù 2:20; 5:1-4, 18) Síbẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ní ìfojúsọ́nà ti orí ilẹ̀ ayé rí ìrànwọ́ àti ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́. Lára àwọn wọ̀nyí ni Mósè, tí ó ní ẹ̀mí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí àwọn 70 ọkùnrin tí òun yàn láti ṣèrànwọ́ fún un. (Númérì 11:24, 25) Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, Bẹ́sálẹ́lì sìn gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ọnà jíjáfáfá nígbà kíkọ́ àgọ́ àjọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 31:1-11) Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Gídíónì, Jẹ́fútà, Sámúsìnì, Dáfídì, Èlíjà, Èlíṣà, àti àwọn mìíràn. Bí a kò tilẹ̀ ní mú àwọn ẹni ìjímìjí wọ̀nyí wá sínú ògo ọ̀run láé, ẹ̀mí mímọ́ darí wọn, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́, bí ó ti ń darí àwọn àgùntàn mìíràn ti Jésù lónìí. Nítorí náà, níní ẹ̀mí Ọlọ́run kò fi dandan túmọ̀ sí pé a ní ìpè ti ọ̀run. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Jèhófà ń pèsè ìtọ́sọ́nà, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti wàásù kí a sì ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí Ọlọ́run yàn fún wa, ó ń fún wa ní agbára tí ó kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá, ó sì ń mú èso ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu jáde nínú wa. (Jòhánù 16:13; Ìṣe 1:8; 2 Kọ́ríńtì 4:7-10; Gálátíà 5:22, 23) Kò ha yẹ kí a dúpẹ́ fún ẹ̀bùn olóore ọ̀fẹ́ yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí?
14. Báwo ni a ṣe ń jàǹfààní láti inú ẹ̀bùn Ọlọ́run ti ìmọ̀ àti ọgbọ́n?
14 Ìmọ̀ àti ọgbọ́n jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí ó yẹ kí a kún fún ìmoore fún, yálà ìrètí wa jẹ́ ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé. Ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” kí a sì “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Fílípì 1:9-11; Kólósè 1:9, 10) Ọgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ ààbò àti amọ̀nà nínú ìgbésí ayé. (Òwe 4:5-7; Oníwàásù 7:12) Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a gbé ìmọ̀ àti ọgbọ́n tòótọ́ kà, àwọn ẹni àmì òróró díẹ̀ tí ó ṣẹ́ kù sì nífẹ̀ẹ́ ní pàtàkì sí ohun tí ó sọ nípa ìrètí wọn ti ọ̀run. Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìmọ̀ kíkún rẹ́rẹ́ nípa rẹ̀ kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà fi hàn pé a ti pè wá sí ìyè ti ọ̀run. Àwọn ènìyàn bíi Mósè àti Dáníẹ́lì pàápàá kọ lára Bíbélì, ṣùgbọ́n ìyè lórí ilẹ̀ ayé ni a óò jí wọn dìde sí. Yálà ìrètí wa jẹ́ ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé, gbogbo wa ń gba oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jèhófà fọwọ́ sí. (Mátíù 24:45-47) Ẹ wo bí gbogbo wa ti kún fún ìmoore tó fún ìmọ̀ tí a tipa báyìí jèrè!
15. Kí ni ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn títóbi jù lọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ojú wo ni o sì fi ń wò ó?
15 Ọ̀kan nínú ẹ̀bùn títóbi jù lọ tí Ọlọ́run fúnni ni ìpèsè onífẹ̀ẹ́ ti ẹbọ ìràpadà Jésù, tí ó ń ṣàǹfààní fún wa yálà a ní ìfojúsọ́nà ti ọ̀run tàbí ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé aráyé “tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ìfẹ́ Jésù sì sún un láti “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ti ṣàlàyé, Jésù Kristi “ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa [ìyẹn ti àwọn ẹni àmì òróró], síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa kún fún ìmoore gidigidi fún ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí fún ìgbàlà sínú ìyè ayérayé.b
Ìwọ Yóò Ha Wà Níbẹ̀ Bí?
16. Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ni a óò ṣèrántí rẹ̀ lẹ́yìn wíwọ̀ oòrùn ní April 11, 1998, ta ni ó sì yẹ kí ó wà níbẹ̀?
16 Ìmoore fún ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ yẹ kí ó sún wa láti wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní àwọn ibòmíràn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò pé jọ sí lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní April 11, 1998, láti ṣèrántí ikú Kristi. Nígbà tí òun dá ayẹyẹ yìí sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olùṣòtítọ́ ní alẹ́ tí ó kẹ́yìn ìwàláàyè rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, Jésù wí pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19, 20; Mátíù 26:26-30) Àwọn ẹni àmì òróró díẹ̀ tí ó ṣẹ́ kù yóò ṣàjọpín àkàrà aláìwú, tí ó dúró fún ara ẹ̀dá ènìyàn aláìlẹ́ṣẹ̀ ti Jésù, àti wáìnì tí a kò ṣàdàlù, tí ó ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a tú jáde fún ìrúbọ. Kìkì àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí nìkan ni kí ó ṣàjọpín nítorí pé àwọn nìkan ni ó wà nínú májẹ̀mú tuntun àti nínú májẹ̀mú Ìjọba tí wọ́n sì ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro, ti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run pé ìrètí ti ọ̀run jẹ́ tiwọn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn yóò wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òǹwòran tí ń fi ọ̀wọ̀ hàn, tí wọ́n kún fún ìmoore fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Kristi fi hàn ní ti ìrúbọ Jésù tí ó mú kí ìyè ayérayé ṣeé ṣe.—Róòmù 6:23.
17. Kí ni ó yẹ kí a rántí nípa fífi ẹ̀mí yanni?
17 Ìgbàgbọ́ ìsìn tí a ti ní tẹ́lẹ̀, èrò ìmọ̀lára lílágbára nítorí ikú olólùfẹ́ kan, àìrọgbọ ìsinsìnyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbòkègbodò ojoojúmọ́, tàbí ìmọ̀lára ti rírí àwọn ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà lè mú kí àwọn kan fi àṣìṣe méfòó pé ọ̀run ni àwọn ń lọ. Ṣùgbọ́n gbogbo wa gbọ́dọ̀ rántí pé Ìwé Mímọ́ kò pàṣẹ fún wa pé a ní láti ṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kí a lè fi ìmoore wa hàn fún ẹbọ ìràpadà Kristi. Ní àfikún sí i, fífi ẹ̀mí yanni “kò sinmi lé ẹni tí ń fẹ́ tàbí lé ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe lé Ọlọ́run,” ẹni tí ó bí Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ nípa tẹ̀mí tí ó sì mú kìkì 144,000 àwọn ọmọ mìíràn wọnú ògo.—Róòmù 9:16; Aísáyà 64:8.
18. Àwọn ìbùkún wo ni ó wà níwájú fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń sin Jèhófà lónìí?
18 Ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan jẹ́ ìrètí tí Ọlọ́run ń fún ọ̀pọ̀ jaburata ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ń sin Jèhófà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1-5) Láìpẹ́, wọn yóò gbádùn párádísè àgbàyanu yìí. Nígbà náà, àwọn ọmọ aládé ni yóò máa bójú tó àwọn àlámọ̀rí ayé lábẹ́ ìjọba ọ̀run. (Sáàmù 45:16) Àwọn ipò alálàáfíà yóò wà bí àwọn olùgbé ayé ti ń pa òfin Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. (Aísáyà 9:6, 7; Ìṣípayá 20:12) Iṣẹ́ púpọ̀ rẹpẹtẹ yóò wà láti ṣe, kíkọ́ ilé àti ṣíṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 65:17-25) Sì ronú nípa ìmúṣọ̀kan ìdílé aláyọ̀ bí àwọn òkú ti ń padà bọ̀ sí ìyè! (Jòhánù 5:28, 29) Lẹ́yìn ìdánwò àṣekágbá, gbogbo ìwà ibi yóò kọjá lọ. (Ìṣípayá 20:7-10) Títí láé lẹ́yìn náà, ilẹ̀ ayé yóò kún fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé tí a ‘dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, tí wọ́n sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.’
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 225, 226.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”?
◻ Yálà ìrètí wá jẹ́ ti ọ̀run tàbí ti ilẹ̀ ayé, àwọn ìdí wo ni a ní láti kún fún ìmoore sí Jèhófà?
◻ Ayẹyẹ ọdọọdún wo ni ó yẹ kí gbogbo wa pésẹ̀ sí?
◻ Kí ni ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí ‘ń gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.’ Ìwọ ha wà lára wọn bí?