Onígbèéraga Adelé Ọba Kan Pàdánù Ilẹ̀ Ọba Kan
WÒLÍÌ Dáníẹ́lì kọ̀wé pé: “Ní ti Bẹliṣásárì Ọba, ó se àsè ńlá kan fún ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, ó sì ń mu wáìnì ní iwájú àwọn ẹgbẹ̀rún náà.” Àmọ́, bí àsè náà ti ń lọ, ní ti ọba, “àwọ̀ ara rẹ̀ yí padà, ìrònú òun fúnra rẹ̀ sì kó jìnnìjìnnì bá a, àwọn oríkèé ìgbáròkó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀, àwọn eékún rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá ara wọn.” Kí ilẹ̀ tó mọ́, “a pa Bẹliṣásárì, ọba àwọn ará Kálídíà, Dáríúsì ará Mídíà sì gba ìjọba.”—Dáníẹ́lì 5:1, 6, 30, 31.
Ta ni Bẹliṣásárì? Báwo ló ṣe jẹ́ tí a ń pè é ní “ọba àwọn ará Kálídíà”? Kí tilẹ̀ ni ipò rẹ̀ gan-an nínú Ilẹ̀ Ọba Bábílónì tuntun náà? Báwo ló ṣe pàdánù ilẹ̀ ọba náà?
Ajùmọ̀ṣàkóso Tàbí Ọba?
Dáníẹ́lì pe Nebukadinésárì ní baba Bẹliṣásárì. (Dáníẹ́lì 5:2, 11, 18, 22) Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò túmọ̀ sí pé òun gan-an ló bí i. Ìwé Nabonidus and Belshazzar tí Raymond P. Dougherty kọ fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kí Nebukadinésárì jẹ́ baba ìyá rẹ̀, Nitocris. Ó sì tún lè jẹ́ pé Nebukadinésárì wulẹ̀ jẹ́ “baba” Bẹliṣásárì nítorí pé ó jọba ṣáájú rẹ̀. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 28:10, 13.) Èyí tó wù kó jẹ́, àwọn ìkọ̀wé cuneiform tó wà lára àwọn ọ̀pá alámọ̀ rìbìtì tí a rí ní ìhà gúúsù Iraq ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún pe Bẹliṣásárì ní dáwódù Nábónídọ́sì, ọba Bábílónì.
Níwọ̀n bí àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì orí 5 ti dá lérí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní òru ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Bábílónì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, kò sọ bí Bẹliṣásárì ṣe di aláṣẹ ní ipò ọba. Ṣùgbọ́n àwọn àwárí ìwalẹ̀pìtàn fúnni ní òye díẹ̀ nípa ìbátan àárín Nábónídọ́sì àti Bẹliṣásárì. Alan Millard, awalẹ̀pìtàn tó sì dáńgájíá nínú ìmọ̀ èdè àwọn Júù, sọ pé: “Àwọn ìwé ilẹ̀ Bábílónì fi hàn pé Nábónídọ́sì jẹ́ alákòóso tí ìwà rẹ̀ yàtọ̀.” Millard fi kún un pé: “Nígbà tí kò kúkú pa àwọn òrìṣà ilẹ̀ Bábílónì tì pátápátá, ó . . . pàfiyèsí púpọ̀ sórí òrìṣà òṣùpá tó wà ní àwọn ìlú méjì mìíràn, Úrì àti Háránì. Nábónídọ́sì kò tilẹ̀ lo ọ̀pọ̀ ọdún ìṣàkóso rẹ̀ ní Bábílónì; kàkà bẹ́ẹ̀, àgbègbè píparọ́rọ́ tó wà ní Teima [tàbí, Tema] ní àríwá Arébíà ló ń gbé.” Ó ṣe kedere pé Nábónídọ́sì lo àkókò púpọ̀ nígbà ìṣàkóso rẹ̀ lẹ́yìn odi olú ìlú náà, Bábílónì. Ní àwọn àkókò tí kò bá sí nílé, Bẹliṣásárì ní ń delé dè é.
Àkọsílẹ̀ cuneiform kan tí a pè ní “Àkọsílẹ̀ Eléwì Nípa Nábónídọ́sì” túbọ̀ ṣàlàyé lórí ipò tí Bẹliṣásárì wà gan-an pé: “Ó [Nábónídọ́sì] fa ‘Agbo Ológun’ lé (ọmọkùnrin) rẹ̀ àgbà, dáwódù rẹ̀, lọ́wọ́, ó sì fi gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó wà ní orílẹ̀-èdè náà sábẹ́ (àṣẹ) rẹ̀. Ó fi (ohun gbogbo) sí ìkáwọ́ rẹ̀, [ó] fi ipò ọba lé e lọ́wọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, Bẹliṣásárì jẹ́ ajùmọ̀ṣàkóso.
Àmọ́, ṣé a lè ka ajùmọ̀ṣàkóso kan sí ọba ni? Ère alákòóso àtayébáyé kan tí a rí ní àríwá Síríà ní àwọn ọdún 1970 fi hàn pé ó wọ́pọ̀ láti pe alákòóso kan ní ọba, nígbà tó jẹ́ pé, ní gidi, ipò rẹ̀ kò tó bẹ́ẹ̀. Ère alákòóso kan ní Gozan ni, a sì fi èdè Ásíríà àti ti Árámáíkì kọ̀wé sára rẹ̀. Ìkọ̀wé ti Ásíríà pe ọkùnrin náà ní gómìnà Gozan, ṣùgbọ́n ìkọ̀wé Árámáíkì tó wà níbẹ̀ pè é ní ọba. Nítorí náà, kì í ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ láti pe Bẹliṣásárì ní ajogún ìtẹ́ nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìjọba ilẹ̀ Bábílónì, nígbà tí a pè é ní ọba nínú àwọn ìkọ̀wé èdè Árámáíkì ti Dáníẹ́lì.
Ìṣètò àkóso alájọṣe láàárín Nábónídọ́sì àti Bẹliṣásárì wà títí di òpin Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Tuntun náà. Nítorí náà, ní òru tí a ṣẹ́gun Bábílónì gan-an, Bẹliṣásárì yàn láti fi Dáníẹ́lì ṣe igbá-kẹta nínú ìjọba náà, kì í ṣe igbá-kejì.—Dáníẹ́lì 5:16.
Adelé Tó Jọra Rẹ̀ Lójú, Tó Tún Ń Gbéra Ga
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apá tó kẹ́yìn ìṣàkóso Bẹliṣásárì fi hàn pé ọmọ ọba náà jọra rẹ̀ lójú jù, ó sì ní ìgbéraga. Nígbà tí ìṣàkóso Nábónídọ́sì dópin ní October 5, 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nábónídọ́sì fara pa mọ́ sí Borsippa, nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ ogun Mídíà òun Páṣíà ti ṣẹ́gun rẹ̀. Wọ́n ti dó ti Bábílónì fúnra rẹ̀. Àmọ́, Bẹliṣásárì rò pé kò séwu fún òun nínú ìlú olódi ńlá yẹn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi “se àsè ńlá kan fún ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn” ní òru yẹn gan-an. Herodotus, òpìtàn ará Gíríìkì ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, sọ pé, ní àárín ìlú náà, àwọn ènìyàn “ń jó ní àkókò náà, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn.”
Àmọ́, lẹ́yìn odi Bábílónì, ẹgbẹ́ ogun Mídíà òun Páṣíà wà lójúfò. Wọ́n ti darí omi Odò Yúfírétì, tó la ìlú náà já, gba ibòmíràn, bí Kírúsì ṣe pàṣẹ fún wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ṣe tán láti fọ́n ká gbogbo ilẹ̀ odò náà ni kété tí omi náà bá ti fà tó. Wọn yóò gun àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ náà, wọn yóò sì gba ẹnu ọ̀nà ilẹ̀kùn tí a fi bàbà ṣe, tó wà lára odi, níbi odò náà, wọ inú ìlú náà.
Bó bá ṣe pé Bẹliṣásárì ti ṣàkíyèsí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú náà ni, ì bá kọ́kọ́ ti àwọn ilẹ̀kùn tí a fi bàbà ṣe náà, ì bá ti kó àwọn ọkùnrin alágbára rẹ̀ sórí ògiri ní etídò náà, ì bá sì ti ká àwọn ọ̀tá náà mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọtí pa Bẹliṣásárì agbéraga débi tó fi sọ pé kí wọ́n lọ kó àwọn ohun èlò tẹ́ńpìlì Jèhófà wá. Òun, àwọn àlejò rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀, àti àwọn àlè rẹ̀ wá ń fi wọ́n mutí tògbójútògbójú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì n yin àwọn òrìṣà ilẹ̀ Bábílónì. Lójijì, a rí ọwọ́ kan lọ́nà oníṣẹ́ ìyanu, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sára ògiri ààfin náà. Jìnnìjìnnì bo Bẹliṣásárì, ó sì pe àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n rẹ̀ láti túmọ̀ ìsọfúnni náà. Ṣùgbọ́n wọn “kò kúnjú ìwọ̀n láti ka ìkọ̀wé náà tàbí láti sọ ìtumọ̀ rẹ̀ di mímọ̀ fún ọba.” Níkẹyìn, “wọ́n mú” Dáníẹ́lì “wá síwájú ọba.” Lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run, onígboyà wòlíì Jèhófà yìí, sọ ìtumọ̀ ìsọfúnni àgbàyanu náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn Mídíà òun Páṣíà yóò ṣẹ́gun Bábílónì.—Dáníẹ́lì 5:2-28.
Kò nira fún àwọn Mídíà òun Páṣíà láti ṣẹ́gun ìlú náà, wọ́n sì pa Bẹliṣásárì lóru náà. Nígbà tí ó kú, tí Nábónídọ́sì sì juwọ́ sílẹ̀ fún Kírúsì ní kedere, Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Tuntun náà dópin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Dáníẹ́lì túmọ̀ ìsọfúnni ègbé fún Ilẹ̀ Ọba Bábílónì