Báwo Lo Ṣe Lè Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Hàn?
OJÚLÓWÓ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (Jákọ́bù 4:6) Ó jọ pé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni Jákọ́bù ti rí àwọn ọ̀rọ̀ tó fà yọ. “Nítorí pé Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.” “Ojú ìrera ará ayé yóò di rírẹ̀sílẹ̀, ìgafíofío àwọn ènìyàn yóò sì tẹrí ba; Jèhófà nìkan ṣoṣo sì ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn.” “Bí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn olùyọṣùtì, [Ọlọ́run] fúnra rẹ̀ yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín; ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò fi ojú rere hàn sí.”—Sáàmù 138:6; Aísáyà 2:11; Òwe 3:34.
Àpọ́sítélì Pétérù pẹ̀lú gbé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lárugẹ. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pétérù 5:5.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Kristi Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ
O lè béèrè pé, Kí ni ìwà ẹ̀yẹ tàbí àǹfààní jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Fún èèyàn tó ń sapá láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ìdáhùn náà kò ní àgbéyí—láti dà bí Kristi, a ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Jésù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ hàn nípa títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ti wíwá sáyé láti àjùlé ọ̀run, kí ó sì di ènìyàn rírẹlẹ̀, tó kéré sí àwọn áńgẹ́lì. (Hébérù 2:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni òun í ṣe, ó fara da ìwọ̀sí tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ẹlẹ́sìn fi lọ̀ ọ́. Kò bọ́hùn nínú àdánwò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ké sí ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì fún ìrànwọ́.—Mátíù 26:53.
Níkẹyìn, wọ́n tẹ́ Jésù nípa gbígbé e kọ́ sórí òpó igi oró, síbẹ̀ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Baba rẹ̀. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.”—Fílípì 2:5-8.
Nítorí náà, báwo la ṣe lè fi ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn? Nínú àwọn ipò táa ń kojú, báwo la ṣe lè fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hùwà dípò kí a lo ẹ̀mí ìgbéraga?
Bí Onírẹ̀lẹ̀ Ṣe Ń Hùwà
Ẹ jẹ́ ká gbé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yẹ̀ wò nígbà táa bá wà lẹ́nu iṣẹ́, yálà lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni. Kí iṣẹ́ kan tó lè yanjú, ó lè pọndandan láti ní alábòójútó, àti olùdarí. Ẹnì kan ní láti máa ṣèpinnu. Kí ni ìhùwàpadà rẹ? O ha máa ń sọ pé, “Kí ló fi ara rẹ̀ pè ná, tó wá ń pàṣẹ fún mi? Ẹnu iṣẹ́ yìí ló dé bá mi kẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, bóo bá gbéra ga, o ò ní tẹrí ba. Ní ìdà kejì, ṣe ni onírẹ̀lẹ̀ máa ń làkàkà láti ‘má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, yóò máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá ju òun lọ.’—Fílípì 2:3.
Irú ojú wo lo fi máa ń wo àbá tó bá wá látọ̀dọ̀ ẹni tó kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí látọ̀dọ̀ obìnrin? Bóo bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wàá tiẹ̀ gbé e yẹ̀ wò ná. Àmọ́ bóo bá níwà ìgbéraga, kíkọ̀ lo máa kọ̀ ọ́ tàbí kí o má tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ sétí rárá. Ṣé ìyìn àti àpọ́nlé tó lè yọrí sí ìṣubú rẹ lo ń fẹ́ àbí ìmọ̀ràn rere tó lè gbé ẹ ró?—Òwe 27:9; 29:5.
O ha lè kojú ìpọ́njú bí? Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti kojú ipò ìṣòro, kí o fara dà á, gẹ́gẹ́ bí Jóòbù ti ṣe. Bóo bá lẹ́mìí ìgbéraga, ayé ò ní pẹ́ sú ẹ, gbogbo ìgbà tí ipò nǹkan kò bá bára dé, tó bá sì dà bí ẹni pé ẹnì kan ń fojú pa ẹ́ rẹ́, ni inú ẹ yóò máa ru ṣùṣù.—Jóòbù 1:22; 2:10; 27:2-5.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Nífẹ̀ẹ́, Ó Ń Dárí Jini
Ó máa ń nira fún àwọn kan láti sọ pé, “Máà bínú. Àṣìṣe ni mo ṣe. Ìwọ ló tọ̀nà.” Èé ṣe? Ìgbéraga ti pọ̀ jù! Bẹ́ẹ̀ rèé, àìmọye ìgbà ló jẹ́ pé títọrọ àforíjì tinútinú lè tètè pẹ̀tù sí èdèkòyédè nínú ìdílé.
Ṣé o lè dárí jini, tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ẹ́? Tàbí kẹ̀, pẹ̀lú ọkàn ìgbéraga, ṣé wàá di onítọ̀hún sínú, bóyá fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ àti oṣù, tí wàá máa bá ẹni tóo sọ pé ó ṣẹ̀ ọ́ yodì? Ṣé oò kì í bá a débi dídá aáwọ̀ tí kì í tán bọ̀rọ̀ sílẹ̀, torí pé o fẹ́ ránró? Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti ṣòfò nínú irú àwọn aáwọ̀ bẹ́ẹ̀. Nígbà mìíràn, irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ sì ti yọrí sí ìbanilórúkọjẹ́. Yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo èyí, onírẹ̀lẹ̀ máa ń nífẹ̀ẹ́, ó máa ń dárí jini. Èé ṣe? Nítorí pé ìfẹ́ kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀. Ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ṣe tán láti dárí jini, àní léraléra!—Jóẹ́lì 2:12-14; Mátíù 18:21, 22; 1 Kọ́ríńtì 13:5.
Onírẹ̀lẹ̀ ‘máa ń mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá fún ẹlòmíràn.’ (Róòmù 12:10) Ìtumọ̀ New International Version kà pé: “Ẹ máa bọlá fún ẹlòmíràn ju ara yín lọ.” O ha máa ń yin àwọn ẹlòmíràn, tí o sì ń mọrírì agbára àti ẹ̀bùn tí wọ́n ní? Tàbí, ṣe ni o sábà ń wá àléébù tí oó fi ba orúkọ rere wọn jẹ́? Àní, o ha máa ń fi tinútinú yin àwọn ẹlòmíràn bí? Bí ohun táa mẹ́nu kàn yìí bá nira fún ọ láti ṣe, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ìgbéraga ló ń yọ ẹ́ lẹ́nu ní bíbẹ̀rù pé wọ́n lè máa fojú kò-mọ̀kan wò ẹ́.
Onígbèéraga èèyàn kì í mú sùúrù. Onírẹ̀lẹ̀ máa ń mú sùúrù, ó sì máa ń pa nǹkan mọ́ra. Ìwọ ńkọ́? O ha máa ń tutọ́ sókè fojú gbà á, tí ẹnì kan bá hùwà tí kò bá ẹ lára mu? Òdìkejì ìpamọ́ra ni irú ìhùwàpadà bẹ́ẹ̀ jẹ́. Bóo bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, oò ní ro ara rẹ ju bó ti yẹ lọ. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ—èdèkòyédè gbígbóná janjan bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn nípa ẹni tí yóò jẹ́ ẹni pàtàkì jù lọ. Wọ́n ti gbàgbé pé “ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun” ni gbogbo wọn!—Lúùkù 17:10; 22:24; Máàkù 10:35-37, 41.
Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Voltaire, pe ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni “ohun . . . tí ń pẹ̀rọ̀ sí ìgbéraga.” Òdodo ọ̀rọ̀, torí pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ túmọ̀ sí àìní ọkàn ìgbéraga. Onírẹ̀lẹ̀ jẹ́ ẹni tí kì í ganpá, tí kì í fẹgẹ̀. Ó ń bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fúnni, ó sì ń yẹ́ni sí.
Nípa báyìí, èé ṣe tó fi yẹ ká sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Nítorí pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Dáníẹ́lì wà lára nǹkan tí Jèhófà fi ka wòlíì náà sí ẹni tó “fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi,” ìdí nìyẹn tí ó sì fi ìran kan rán áńgẹ́lì sí i! (Dáníẹ́lì 9:23; 10:11, 19) Èrè ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ pọ̀. Yóò jẹ́ kí o ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ń mú ìbùkún Jèhófà wá. “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Fífẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tọrọ àforíjì lè mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ rọrùn