Ìṣúra Wa Ń bẹ Nínú Ohun Èlò Tí A Fi Amọ̀ Ṣe
“Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 4:7.
1. Ọ̀nà wo ló yẹ kí àpẹẹrẹ Jésù gbà fún wa níṣìírí?
NÍGBÀ tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, tí Jèhófà ń mọ ọ́n lọ́wọ́, ní tààràtà, Jésù nímọ̀lára ìkù-díẹ̀-káàtó tí aráyé ń ní. Ẹ wo bí pípa tí ó pa ìwà títọ́ mọ́ ṣe fún wa níṣìírí tó! Àpọ́sítélì náà sọ fún wa pé: “Ní ti tòótọ́, ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Nítorí tí Jésù gbà kí a mọ òun, ó ṣẹ́gun ayé. Ó tún mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́kàn le pé kí àwọn pẹ̀lú di aṣẹ́gun. (Ìṣe 4:13, 31; 9:27, 28; 14:3; 19:8) Ọ̀rọ̀ ìṣírí tó bá wọn sọ nígbà tó ń parí ọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀ mà lágbára o! Ó kéde pé: “Mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi. Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòhánù 16:33.
2. Láìdàbí ‘ìfọ́jú tí a bù lu’ ayé, irú “ìmọ́lẹ̀” wo ni a ní?
2 Bákan náà, lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣàfiwéra ìfọ́jú tí “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ti bù luni àti “ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo,” ó wá sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tó ṣeyebíye pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde. A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá; a ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; a gbé wa ṣánlẹ̀, ṣùgbọ́n a kò pa wá run.” (2 Kọ́ríńtì 4:4, 7-9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe,” tí ó jẹ́ ohun ẹlẹgẹ́ ni wá, Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí rẹ̀ mọ wá débi pé a lè ṣẹ́gun ayé Sátánì pátápátá.—Róòmù 8:35-39; 1 Kọ́ríńtì 15:57.
Mímọ Ísírẹ́lì Ìgbàanì
3. Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe bí a ṣe mọ orílẹ̀-èdè Júù?
3 Kì í ṣe ènìyàn nìkan ni Jèhófà ń mọ, ṣùgbọ́n ó tún ń mọ odindi orílẹ̀-èdè pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbà kí Jèhófà mọ òun, ó láásìkí. Ṣùgbọ́n níkẹyìn, ìwà àìgbọràn kò jẹ́ kí ó ṣeé mọ mọ́. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, Aṣẹ̀dá Ísírẹ́lì mú “ègbé” wá sórí rẹ̀. (Aísáyà 45:9) Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, Aísáyà bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tó burú bàlùmọ̀ tí Ísírẹ́lì ń hù, ó sọ pé: “Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. . . . Gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra wa ti di ìparundahoro.” (Aísáyà 64:8-11) A ti fi Ísírẹ́lì mọ ohun èlò tó jẹ́ pé ìparun nìkan ló yẹ fún.
4. Kí ni a ní kí Jeremáyà ṣe gẹ́gẹ́ bí àkàwé?
4 Ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, bí ọjọ́ ìjíhìn ti ń sún mọ́ etílé, Jèhófà ní kí Jeremáyà mú ṣágo amọ̀ kan, kí ó sì tẹ̀ lé díẹ̀ lára àwọn àgbà ọkùnrin Jerúsálẹ́mù lọ sí Àfonífojì Hínómù, ó pàṣẹ fún un pé: “Kí o sì fọ́ ṣágo náà lójú àwọn ọkùnrin tí ìwọ àti àwọn jọ ń lọ. Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Bákan náà ni èmi yóò fọ́ àwọn ènìyàn yìí àti ìlú ńlá yìí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò tí kò fi lè ṣeé tún ṣe mọ́.”’”—Jeremáyà 19:10, 11.
5. Báwo ni ìdájọ́ Jèhófà lórí Ísírẹ́lì ti lágbára tó?
5 Ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nebukadinésárì sọ Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ dahoro, ó sì kó àwọn Júù tó la ìparun náà já ní òǹdè lọ sí Bábílónì. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí àwọn Júù lo àádọ́rin ọdún ní ìgbèkùn, àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà nínú wọn láǹfààní láti padà wá tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́. (Jeremáyà 25:11) Àmọ́ ṣá o, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, orílẹ̀-èdè yẹn tún ti pa Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà tì, níkẹyìn, orílẹ̀-èdè náà wá ba ara rẹ̀ jẹ́ pátápátá nípa dídáràn tó burú jù lọ, ó pa Ọmọ Ọlọ́run alára. Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run wá lo Agbára Ayé Róòmù láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, ó lò ó láti pa ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù run, nípa sísọ Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ dilẹ̀ pátápátá. Títí ayé, Jèhófà kò tún ní fi ọwọ́ ara rẹ̀ mọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ohun “ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà” mọ́.a
Mímọ Orílẹ̀-Èdè Tẹ̀mí
6, 7. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe bí a ṣe mọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí? (b) Mélòó gan-an ni iye “àwọn ohun èlò àánú,” báwo sì ni a ṣe kó wọn jọ?
6 Àwọn Júù tí wọ́n tẹ́wọ́ gba Jésù ni a mọ láti di mẹ́ńbà tí a fi pilẹ̀ orílẹ̀-èdè tuntun kan, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nípa tẹ̀mí. (Gálátíà 6:16) Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù mà ṣe wẹ́kú o, ó ní: “Kínla? Amọ̀kòkò kò ha ní ọlá àṣẹ lórí amọ̀ láti ṣe nínú ìṣùpọ̀ kan náà ohun èlò kan fún ìlò ọlọ́lá, òmíràn fún ìlò aláìlọ́lá? . . . Bí Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ ní ìfẹ́ láti fi ìrunú rẹ̀ hàn gbangba, kí ó sì sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, bá fi ọ̀pọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun, kí ó bàa lè sọ àwọn ọrọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú, èyí tí ó pèsè sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ògo.”—Róòmù 9:21-23.
7 Lẹ́yìn náà, Jésù tí a jíǹde sọ èyí di mímọ̀ pé iye “àwọn ohun èlò àánú” wọ̀nyí yóò jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Ìṣípayá 7:4; 14:1) Níwọ̀n bí Ísírẹ́lì nípa ti ara kò ti lè pèsè iye yẹn rẹ́gí, Jèhófà nawọ́ àánú rẹ̀ sí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè. (Róòmù 11:25, 26) Kíá ni ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Láàárín ọgbọ̀n ọdún, a ti “wàásù” ìhìn rere “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Èyí wá béèrè pé kí a mú ọ̀pọ̀ ìjọ tó wà káàkiri ládùúgbò wá sábẹ́ àbójútó tí a ṣètò dáadáa.
8. Àwọn wo ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, báwo sì ni ẹgbẹ́ yìí ṣe gbèrú?
8 Jésù ti mú àwọn àpọ́sítélì méjìlá tí yóò di ẹgbẹ́ olùṣàkóso àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbára dì, nípa dídá àwọn àti àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Lúùkù 8:1; 9:1, 2; 10:1, 2) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, nígbà tó sì yá, a mú kí ẹgbẹ́ olùṣàkóso rẹ̀ tóbi sí i, tó fi wá di èyí tó ní “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù” nínú. Fún àkókò gígùn, ó jọ pé Jákọ́bù ni alága wọn, ẹni tí í ṣe iyèkan Jésù, bí kì í tilẹ̀ ṣe àpọ́sítélì. (Ìṣe 12:17; 15:2, 6, 13; 21:18) Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Eusebius ti sọ, àwọn àpọ́sítélì wá di ẹni táa dójú sọ láti máa ṣe inúnibíni sí, a sì tú wọn káàkiri àgbègbè mìíràn. Bí ọ̀ràn ṣe wá rí yìí, ló mú kí wọ́n ṣe àyípadà sí àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ olùṣàkóso.
9. Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú wo ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀?
9 Ìgbà tí ọ̀rúndún kìíní fi máa parí, ‘ọ̀tá náà, Èṣù’ ti bẹ̀rẹ̀ sí ‘fún èpò’ sáàárín àwọn tí a fi wé àlìkámà, àwọn ajogún “ìjọba ọ̀run.” Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò fàyè gba ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí títí di ìgbà ìkórè ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Lẹ́yìn náà, ni ‘àwọn olódodo yóò tún wá máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.’ (Mátíù 13:24, 25, 37-43) Ìgbà wo ni ìyẹn yóò jẹ́?
Mímọ Ísírẹ́lì Ọlọ́run Lónìí
10, 11. (a) Báwo ni iṣẹ́ mímọ Ísírẹ́lì Ọlọ́run lóde òní ṣe bẹ̀rẹ̀? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló takora láàárín Kirisẹ́ńdọ̀mù àti Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara?
10 Ní ọdún 1870, Charles Taze Russell dá ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sílẹ̀ ní Pittsburgh, Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tó di ọdún 1879, ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn kan jáde lóṣooṣù, èyí táa mọ̀ sí Ilé Ìṣọ́ lónìí. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pè wọ́n lẹ́yìn ìgbà yẹn, wá lóye pé Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ṣàmúlò àwọn ẹ̀kọ́ abọ̀rìṣà, tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, irú bí àìleèkú ọkàn, ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, ọlọ́run Mẹ́talọ́kan, àti ṣíṣe ìbatisí fún àwọn ọmọ ọwọ́.
11 Àmọ́ ṣá o, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, àwọn onífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Bíbélì wọ̀nyí mú àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì padà bọ̀ sípò, irú bí ìràpadà nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù àti àjíǹde sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé alálàáfíà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n tẹnu mọ́ ìsúnmọ́lé ìdáláre Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbàgbọ́ pé a máa tó dáhùn Àdúrà Olúwa náà tó kà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) A ti fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mọ wọn sínú ẹgbẹ́ kan tó kárí ayé, ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹ́mìí àlàáfíà.
12. Báwo ni Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe wá mọ ọdún pàtàkì kan?
12 Kíkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa Dáníẹ́lì orí kẹrin àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn mú kó dá Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú pé, wíwàníhìn-ín Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba ti gbọ́dọ̀ sún mọ́lé. Wọ́n mọ̀ pé ọdún 1914 gan-an ni “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” yóò dópin. (Lúùkù 21:24; Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27) Kíá ni Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú ìgbòkègbodò wọn gbòòrò sí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì (tí a wá ń pè ní ìjọ nígbà tó yá) sílẹ̀ jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ìgbà tí ọ̀rúndún yẹn fi máa parí, iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe ti nasẹ̀ dé Yúróòpù àti Australasia. Ó wá pọndandan pé kí a ṣètò nǹkan lọ́nà tó gún régé.
13. Láti le wà ní ipò tó bófin mu, kí ni Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe, iṣẹ́ pípabanbarì wo sì ni ààrẹ Society àkọ́kọ́ ṣe?
13 Kí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bàa lè wà ní ipò tó bófin mu, a sọ Zion’s Watch Tower Tract Society di ilé iṣẹ́ kan lábẹ́ òfin ní ọdún 1884, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, oríléeṣẹ́ rẹ̀ sì wà ní Pittsburgh, ní Pennsylvania. Àwọn olùdarí rẹ̀ náà tún ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run káàkiri àgbáyé. Ààrẹ Society àkọ́kọ́, Charles T. Russell, kọ ìdìpọ̀ mẹ́fà ti ìwé náà, Studies in the Scriptures, ó sì rìrìn àjò jíjìnnà réré nítorí iṣẹ́ ìwàásù. Ó tún fi gbogbo ọrọ̀ tó ti kó jọ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jíǹkí iṣẹ́ Ìjọba náà yíká ayé. Ní ọdún 1916, nígbà tí Ogun Ńlá yẹn gbóná janjan ní Yúróòpù, ẹnu ìrìn àjò iṣẹ́ ìwàásù ni Arákùnrin Russell tó ti rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀ kú sí. Gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ló fún ìmúgbòòrò ìjẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run.
14. Báwo ni J. F. Rutherford ṣe “ja ìjà àtàtà náà”? (2 Tímótì 4:7)
14 Joseph F. Rutherford, tó ti jẹ́ adájọ́ fún sáà kan ní Missouri, ló wá bọ́ sí ipò ààrẹ. Nítorí ìgboyà tó fi ń gbèjà òtítọ́ Bíbélì, àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù bá lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn òṣèlú láti “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n.” Ní June 21, 1918, wọ́n sọ Arákùnrin Rutherford àti àwọn méje mìíràn tí wọ́n jẹ́ òléwájú nínú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí galagálá, wọ́n ní kí wọ́n fi ọdún mẹ́wàá tàbí ogún ọdún ṣẹ̀wọ̀n, àárín ọdún wọ̀nyí náà ni wọn a sì fi jìyà ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn yóò jọ ná an tán bí owó ni o. (Sáàmù 94:20; Fílípì 1:7) Ni wọ́n bá pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ní March 26, 1919, ilé ẹjọ́ jẹ́ kí a gba ìdúró wọn, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ilé ẹjọ́ ní wọn ò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀mọ́jọba tí wọ́n fi kàn wọ́n, wọ́n ní ẹ̀sùn èké gbáà ni.b Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí wá sọ wọ́n di alágbàwí tó gbóná fún òtítọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, wọn ṣe gudugudu méje kí wọ́n lè jàjàṣẹ́gun nínú ìjà tẹ̀mí ti pípolongo ìhìn rere náà láìfi àtakò Bábílónì Ńlá pè. Ìjà ọ̀hún ṣì ń bá a lọ títí di ọdún 1999 táa wà yìí.—Fi wé Mátíù, orí 23, Jòhánù 8:38-47.
15. Èé ṣe tí ọdún 1931 fi jẹ́ mánigbàgbé?
15 Ní àwọn ọdún 1920 àti 1930, lábẹ́ ìdarí Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà, iṣẹ́ mímọ Ísírẹ́lì Ọlọ́run tí a fòróró yàn ń bá a nìṣó. Ìmọ́lẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ yọ, ó bọlá fún Jèhófà, ó sì darí àfiyèsí sí Ìjọba Jésù Mèsáyà náà. Ní ọdún 1931, inú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dùn láti gba orúkọ tuntun náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísáyà 43:10-12; Mátíù 6:9, 10; 24:14.
16 àti àpótí tó wà lójú ìwé 19. Ìgbà wo ni iye àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì pé géérégé, ẹ̀rí wo sì ni a lè fi ti èyí lẹ́yìn?
16 Ní àwọn ọdún 1930, ó dàbí pé iye àwọn “tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́,” àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ti pé. (Ìṣípayá 17:14; wo àpótí lójú ìwé 19.) A kò mọ iye àwọn ẹni àmì òróró tí a kó jọ ní ọ̀rúndún kìíní àti iye àwọn tí a rí kó jọ nínú “àwọn èpò” ní àwọn ọ̀rúndún ojú dúdú nígbà tí ìpẹ̀yìndà Kirisẹ́ńdọ̀mù gbalégbòde. Ṣùgbọ́n, ní ọdún 1935, góńgó akéde jákèjádò ayé jẹ́ 56,153, nígbà tó sì jẹ́ pé 52,465 èèyàn ló fi hàn pé àwọn ní ìrètí ti ọ̀run nípa nínípìn-ín nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ ti Ìṣe Ìrántí. Kí ni yóò wá jẹ́ ìpín ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí a kò tí ì kó jọ?
“Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”
17. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbè wo ló ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1935?
17 Ní àpéjọpọ̀ kan táa ṣe ní May 30 sí June 3, 1935, ní ìlú Washington, D.C., ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé mánigbàgbé kan tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ògìdìgbó Ńlá Náà.”c Ẹgbẹ́ yìí, “tí ẹnì kankan kò lè kà,” yóò fara hàn nígbà tí fífi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ti Ísírẹ́lì tẹ̀mí bá ti ń lọ sópin. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú yóò lo ìgbàgbọ́ nínú agbára ìràpadà “ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” Jésù, wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì tí Jèhófà ṣètò pé kí a ti máa jọ́sìn òun. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, wọn yóò “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà” láàyè, láti jogún Párádísè ilẹ̀ ayé níbi tí “ikú kì yóò [ti] sí mọ́.” Ní ọdún mélòó kan ṣáájú àpéjọpọ̀ yẹn, ẹgbẹ́ Jónádábù ni a ń pe ẹgbẹ́ yìí.—Ìṣípayá 7:9-17; 21:4; Jeremáyà 35:10.
18. Kí ló mú kí ọdún 1938 jẹ́ mánigbàgbé?
18 Ọdún 1938 jẹ́ ọdún mánigbàgbé ní dídá ẹgbẹ́ méjèèjì mọ̀ kedere. Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ March 15 àti April 1, 1938, gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ alápá méjì jáde, tí ó ní àkọlé náà, “Agbo Rẹ̀,” ó sì mú kí ipò tí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró wà sí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣe kedere. Lẹ́yìn náà ni ìtẹ̀jáde ti June 1 àti June 15 wá gbé àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde lórí “Ètò Àjọ,” èyí ni a gbé ka Aísáyà 60:17. A wá rọ gbogbo ìjọ láti kọ̀wé sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láti yan àwọn ìránṣẹ́ ní ìjọ àdúgbò, èyí sì mú ìṣètò tí Ọlọ́run fàṣẹ sí, tó sunwọ̀n sí i wá, èyí tí a gbé ka ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwọn ìjọ sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
19 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ìpè gbogbo gbòò fún jíjẹ́ ara “àwọn àgùntàn mìíràn” ti ń bá a lọ fún ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún nísinsìnyí?
19 Ìròyìn inú ìwé 1939 Yearbook of Jehovah’s Witnesses sọ pé: “Àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi Jésù tó wà lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí kéré níye, wọn kò sì lè pọ̀ sí i mọ́. Àwọn wọ̀nyí ni Ìwé Mímọ́ pè ní ‘àṣẹ́kù’ irú-ọmọ Síónì, ètò àjọ Ọlọ́run. (Iṣi. 12:17) Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí kó ‘àwọn àgùntàn mìíràn’ jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nísinsìnyí, àwọn tí yóò para pọ̀ di ‘ògìdìgbó ńlá’ náà. (Jòhánù 10:16) Àwọn tí a ń kó jọ nísinsìnyí jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àṣẹ́kù náà, wọ́n ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àṣẹ́kù náà. Láti ìgbà yìí lọ, ‘àwọn àgùntàn mìíràn’ yóò máa pọ̀ sí i níye títí tí a óò fi kó ‘ògìdìgbò ńlá’ náà jọ tán.” A ti mọ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, kí wọ́n bàa lè bojú tó ìkójọpọ̀ ogunlọ́gọ̀ ńlá. Wàyí o, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.d
20. Àwọn ìyípadà nípa ìṣètò wo ló ti wáyé láti ọdún 1942?
20 Ní January 1942, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì le gan-an, Joseph Rutherford kú, Nathan Knorr sì di ààrẹ. A kò lè gbàgbé ààrẹ Society kẹta yìí fún dídá àwọn ilé ẹ̀kọ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run sílẹ̀ nínú àwọn ìjọ àti dídá Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead sílẹ̀, fún dídá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́. Ní ìpàdé ọdọọdún ti Society ní 1944, ó kéde pé a ti ṣàtúnṣe ìwé òfin Society, tí ó fi jẹ́ pé a kò ní máa gbé òṣùnwọ̀n dídi mẹ́ńbà ka owó dídá mọ́, bí kò ṣe lórí ipò tẹ̀mí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ní ọgbọ̀n ọdún tó tẹ̀ lé e, iye àwọn òṣìṣẹ́ ní pápá yíká ayé lọ sókè láti 156,299 sí 2,179,256. Ní ọdún 1971 sí 1975 àwọn ìṣètò mìíràn tún pọndandan nínú ètò àjọ náà. Ẹnì kan ṣoṣo tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, kò lè dá nìkan máa ṣe gbogbo kòkáárí àbójútó iṣẹ́ Ìjọba náà káàkiri àgbáyé mọ́. A sọ iye mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tí í ṣe àwọn ẹni àmì òróró, tí alága rẹ̀ máa ń yí padà lọ́dọọdún, di méjìdínlógún, nǹkan bí ìlàjì nínú wọn sì ti parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí.
21. Kí ló mú kí àwọn mẹ́ńbà agbo kékeré tóótun fún Ìjọba náà?
21 Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tí a fi dán wọn wò ti yọrí sí mímọ àṣẹ́kù agbo kékeré náà. A ti mú wọn lọ́kàn le, nítorí pé láìṣiyèméjì, wọ́n ti gba ‘ẹ̀rí ẹ̀mí náà.’ Jésù ti sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.”—Róòmù 8:16, 17; Lúùkù 12:32; 22:28-30.
22, 23. Báwo ni a ṣe ń mọ agbo kékeré àti àwọn àgùntàn mìíràn?
22 Bí iye àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tí a fi ẹ̀mí yàn ti ń dínkù lórí ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni a ń fún àwọn arákùnrin tó dàgbà dénú lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ní iṣẹ́ àbójútó nípa tẹ̀mí, nínú èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìjọ yíká ayé. Nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró tí ó kẹ́yìn tí wọ́n ti di arúgbó yìí bá fi máa parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, a óò ti dá àwọn olórí sa·rim ti àgùntàn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ìjòyè lórí ilẹ̀ ayé.—Ìsíkíẹ́lì 44:3; Aísáyà 32:1.
23 A ń bá a lọ láti máa mọ agbo kékeré àti àgùntàn mìíràn sí ohun èlò fún ìlò ọlọ́lá. (Jòhánù 10:14-16) Yálà ìrètí wa jẹ́ ti “àwọn ọ̀run tuntun” tàbí ti “ilẹ̀ ayé tuntun,” ǹjẹ́ kí a lè fi tọkàntọkàn dáhùn padà sí ìpè tí Jèhófà ń pè pé: “Ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá. Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù [ti ọ̀run] ní ohun tí ń fa ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà.” (Aísáyà 65:17, 18) Ǹjẹ́ kí àwa ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgẹ́ lè máa fìgbà gbogbo sìn tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀, bí a ti ń fi “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” mọ wá—ìyẹn ni agbára ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run!—2 Kọ́ríńtì 4:7; Jòhánù 16:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kí Kirisẹ́ńdọ̀mù ọ̀dàlẹ̀, tí Ísírẹ́lì ìgbàanì ń ṣàpẹẹrẹ, tètè yáa gbọ́ o, pé, irú ìdájọ́ kan náà ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—1 Pétérù 4:17, 18.
b Ìgbà tí ọ̀ràn máa bẹ́yìn yọ, Adájọ́ Manton, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì, tó fàáké kọ́rí pé òun kò ní jẹ́ kí a gba ìdúró Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́sí fẹ̀wọ̀n jura, nítorí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn gbígba ẹ̀gúnjẹ.
c Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, (Gẹ̀ẹ́sì) tí a tẹ̀ jáde ní ọdún 1950 lo “ogunlọ́gọ̀ ńlá” gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ tó dára jù fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a mí sí.
d Ní ọdún 1938 iye àwọn tó wá síbi Ìṣe Ìrántí kárí ayé jẹ́ 73,420, èèyàn 39,225—ìpín mẹ́tàléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó wá—ló nípìn-ín nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ. Nígbà tí yóò fi di ọdún 1998, iye àwọn tó wá di 13,896,312, tí kìkì 8,756 sì nípìn-ín nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ, ní ìpíndọ́gba, ekukáká la ó fi rí ẹnì kan tó nípìn-ín nínú rẹ̀, tí a bá kó ìjọ mẹ́wàá pa pọ̀.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Nítorí tí Jésù gbà láìjanpata pé kí Baba rẹ̀ mọ ọ́n, báwo ló ṣe jẹ́ Àwòkọ́ṣe fún wa?
◻ Irú mímọ wo ló ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì?
◻ Báwo ni a ṣe ń mọ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” títí di ìsinsìnyí?
◻ Ète wo ni a mọ “àwọn àgùntàn mìíràn” fún?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]
Iṣẹ́ Mímọ Mìíràn Tí Ń Lọ Lọ́wọ́ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù
Àjọ akọ̀ròyìn Associated Press tí a rán jáde láti Áténì, ilẹ̀ Gíríìsì, kọ ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí nípa olórí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì pé: “Ońṣẹ́ àlàáfíà ló yẹ kó jẹ́. Àmọ́ ṣe ni olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì náà ń hùwà bí ọ̀gágun tí ń múra àtilọ sójú ogun.
“Bíṣọ́ọ̀bù àgbà, Christodoulos, sọ láìpẹ́ yìí níbi àjọ̀dún Ìgbàsókè Wúńdíá, tí a tún máa ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì pé: ‘Bó bá pọndandan, a ti wà ní sẹpẹ́ láti tàjẹ̀ sílẹ̀ àti láti fi ara wa rúbọ. Àwa gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ń gbàdúrà fún àlàáfíà . . . Ṣùgbọ́n nígbà tó bá pọndandan, a ń gbàdúrà sórí àwọn ohun ìjà mímọ́.’”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
“Kò Sí Àfikún Mọ́”
Níbi ìkẹ́kọ̀ọ́yege ilé ẹ̀kọ́ Gilead ní ọdún 1970, Frederick Franz, igbákejì ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọ́n jẹ́ ara àgùntàn mìíràn tó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé, ṣe ìbatisí fún ẹnì kan, kí onítọ̀hún sì wá sọ pé ara àṣẹ́kù ẹni àmì òróró lòun. Ṣé ó lè ṣẹlẹ̀? Tóò, ó ṣàlàyé pé, Jòhánù Oníbatisí jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn, ó sì ṣe ìbatisí fún Jésù àti àwọn àpọ́sítélì mìíràn. Lẹ́yìn náà ló wá béèrè bóyá ìpè fún kíkó àṣẹ́kù jọ ṣì ń bá a lọ. Ó wí pé: “Rárá o, kò sí àfikún mọ́! Ìpè yẹn ti wá sópin ní ọdún 1931 sí 1935! Kò sí àfikún mọ́. Àwọn wo wá ni àwọn díẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ tí wọ́n ń nípìn-ín nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí? Bí wọ́n bá jẹ́ ara àṣẹ́kù, a jẹ́ pé arọ́pò ni wọ́n! Wọ́n kì í ṣe àfikún sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ arọ́pò àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣubú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Iṣẹ́ ìsìn wa mà ṣeyebíye púpọ̀ fún wa o!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ísírẹ́lì ìgbàanì di ohun èlò tó yẹ fún ìparun nìkan