Ìbùkún Jèhófà Lórí “Ilẹ̀” Wa
“Ohun gbogbo yóò sì wà láàyè níbi tí ọ̀gbàrá náà bá dé.”—ÌSÍKÍẸ́LÌ 47:9.
1, 2. (a) Báwo ni omi ti ṣe pàtàkì tó? (b) Kí ni omi inú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ń ṣàpẹẹrẹ?
NÍNÚ àwọn ohun tó ṣeé mu, omi jẹ́ ohun àgbàyanu. Gbogbo ẹ̀dá tó ṣeé fojú rí ló nílò rẹ̀. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè wà láàyè tí kò bá sí omi. Ó tún wúlò fún fífọ nǹkan, níwọ̀n bí ó ti lè yọ èérí, kí ó sì ṣàn án kúrò. Abájọ táa fi ń fi wẹ̀, táa fi ń fọṣọ wa, kódà táa fi ń fọ oúnjẹ wa pàápàá. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè gba ẹ̀mí wa là.
2 Bíbélì fi omi ṣàpẹẹrẹ ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ṣe fún ìyè. (Jeremáyà 2:13; Jòhánù 4:7-15) Àwọn ìpèsè wọ̀nyí ní nínú, wíwẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi àti ìmọ̀ Ọlọ́run tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Éfésù 5:25-27) Nínú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, odò ìyanu tó ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì ṣàpẹẹrẹ irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ tí ń fúnni ní ìyè. Ṣùgbọ́n, ìgbà wo ni odò náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn, kí ló sì túmọ̀ sí fún wa lónìí?
Odò Kan Ń Ṣàn Nínú Ilẹ̀ Tí A Mú Padà Bọ̀ Sípò
3. Kí ni Ìsíkíẹ́lì rí, gẹ́gẹ́ bí ó ti ròyìn rẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì 47:2-12?
3 Gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn ní Bábílónì, àwọn ènìyàn Ìsíkíẹ́lì nílò àwọn ìpèsè Jèhófà lójú méjèèjì. Ẹ wá wo bí ó ṣe fún Ìsíkíẹ́lì níṣìírí tó nígbà náà láti rí omi tí ń sun láti inú ibùjọsìn, tí ó sì ṣàn jáde láti inú tẹ́ńpìlì inú ìran náà! Áńgẹ́lì kan ń wọn ìṣàn omi náà ní ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ síra. Odò náà bẹ̀rẹ̀ sí jìn sí i, ó muni láti ọrùn ẹsẹ̀ dé eékún, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó muni dé ìgbáròkó títí ó fi di ọ̀gbàrá tó ṣeé lúwẹ̀ẹ́. Odò náà mú ohun alààyè jáde, wọ́n sì ń bímọ yọyọ. (Ìsíkíẹ́lì 47:2-11) A sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Gbogbo onírúurú igi tí ó wà fún oúnjẹ yóò . . . hù lẹ́bàá ọ̀gbàrá náà, lẹ́bàá bèbè rẹ̀ ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún.” (Ìsíkíẹ́lì 47:12a) Bí ọ̀gbàrá náà ti wọnú Òkun Òkú—àgbájọ omi tí kò sí ohun alààyè nínú rẹ̀—àwọn ohun abẹ̀mí rú jáde! Àwọn ẹja bẹ̀rẹ̀ sí gbáyìn ìn. Iṣẹ́ òwò ẹja búrẹ́kẹ́.
4, 5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nípa odò kan ṣe bá ti Ìsíkíẹ́lì mu, èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì?
4 Àsọtẹ́lẹ̀ títuni lára yìí ti lè rán àwọn Júù tí ó wà nígbèkùn létí ọ̀kan tí a ti kọ ní ohun tí ó lé ní igba ọdún ṣáájú, èyí tí ó sọ pé: “Ìsun kan yóò sì jáde lọ láti ilé Jèhófà, yóò sì bomi rin àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.”a (Jóẹ́lì 3:18) Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ti Ìsíkíẹ́lì, sọ tẹ́lẹ̀ pé odò kan yóò ṣàn wá láti inú ilé Ọlọ́run, ìyẹn ni tẹ́ńpìlì náà, yóò sì mú àgbègbè gbígbẹ táútáú kún fún ohun alààyè.
5 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti ṣàlàyé tipẹ́tipẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ń ní ìmúṣẹ ní àkókò tiwa.b Ó dájú nígbà náà pé bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ìran Ìsíkíẹ́lì tí ó jọ ọ́. Nínú ilẹ̀ tí a ti mú padà bọ̀ sípò tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí, gan-an bí ó ṣe rí ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn ìbùkún Jèhófà ti ṣàn jáde ní tòótọ́.
Àwọn Ìbùkún Ń Ṣàn Gbùúgbùú
6. Kí ló yẹ kí wíwọ́n ẹ̀jẹ́ sórí pẹpẹ inú ìran náà rán àwọn Júù létí rẹ̀?
6 Kí ni orísun àwọn ìbùkún tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí a mú padà bọ̀ sípò ń gbádùn? Tóò, kíyè sí i pé omi náà ń ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run. Bákan náà lónìí, láti inú tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí tí í ṣe ètò tí a ṣe fún ìjọsìn mímọ́ gaara, ni àwọn ìbùkún náà ti ń ṣàn wá. Ìran Ìsíkíẹ́lì fi kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtàkì kan kún un. Nínú àgbàlá inú, omi náà ṣàn gba pẹpẹ kọjá, ní gúúsù rẹ̀ gan-an. (Ìsíkíẹ́lì 47:1) Àárín gbùngbùn tẹ́ńpìlì inú ìran náà sì ni pẹpẹ wà. Jèhófà ṣàpèjúwe rẹ̀ fún Ìsíkíẹ́lì kínní-kínní, ó sì pàṣẹ pé kí a máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sórí rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 43:13-18, 20) Pẹpẹ yẹn ní ìtumọ̀ pàtàkì fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì. A ti fìdí májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Jèhófà múlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú, ìyẹn ni, nígbà tí Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ kan ní ìsàlẹ̀ Òkè Ńlá Sínáì. (Ẹ́kísódù 24:4-8) Nítorí náà, wíwọ́n tí a wọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ inú ìran yìí yẹ kí ó ti rán wọn létí pé gbàrà tí wọ́n bá ti padà sí ilẹ̀ wọn tí a mú padà bọ̀ sípò, àwọn ìbùkún Jèhófà yóò máa ṣàn jáde níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti pa májẹ̀mú tí wọ́n bá a dá mọ́.—Diutarónómì 28:1-14.
7. Ìtumọ̀ wo ni àwọn Kristẹni rí lónìí nínú pẹpẹ ìṣàpẹẹrẹ náà?
7 Bákan náà, àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí ni a ń bù kún nípasẹ̀ májẹ̀mú kan—ọ̀kan tí ó sàn jù, ìyẹn ni májẹ̀mú tuntun. (Jeremáyà 31:31-34) Òun pẹ̀lú ni a ti lo ẹ̀jẹ̀ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ tipẹ́tipẹ́, ìyẹn ni ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi. (Hébérù 9:15-20) Lónìí, yálà a wà lára àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ara àwọn tí a bá dá májẹ̀mú yẹn, tàbí a wà lára “àwọn àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ń jàǹfààní nínú rẹ̀, a rí ìtumọ̀ pàtàkì nínú pẹpẹ ìṣàpẹẹrẹ náà. Ó ń ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹbọ Kristi. (Jòhánù 10:16; Hébérù 10:10) Bó ti jẹ́ pé àárín gbùngbùn tẹ́ńpìlì náà ni pẹpẹ ìṣàpẹẹrẹ yìí wà, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹbọ ìràpadà Kristi ṣe jẹ́ pàtàkì nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. Òun ni ìpìlẹ̀ fún dídárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún gbogbo ìrètí wa ọjọ́ ọ̀la. (1 Jòhánù 2:2) Nítorí náà, a ń tiraka láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí ó ní í ṣe pẹ̀lú májẹ̀mú tuntun náà, “òfin Kristi.” (Gálátíà 6:2) Níwọ̀n ìgbà tí a bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa jàǹfààní láti inú àwọn ìpèsè tí Jèhófà ṣe fún ìyè.
8. (a) Kí ni kò sí nínú àgbàlá inú ti tẹ́ńpìlì inú ìran náà? (b) Ọ̀nà wo ni àwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì inú ìran náà lè gbà wẹ ara wọn mọ́?
8 Ọ̀kan nínú irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ ni ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà. Nínú tẹ́ńpìlì inú ìran náà, ohun kan kò sí nínú àgbàlá inú, ohun yìí sì wà láìfara sin rárá nínú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì—bàsíà ńlá kan, tí a tún wá pè ní òkun, èyí tí àwọn àlùfáà ń wẹ̀ láti inú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 30:18-21; 2 Kíróníkà 4:2-6) Kí wá ni àwọn àlùfáà inú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí lè lò fún wíwẹ ara wọn? Họ́wù, odò ìyanu yẹn tí ń ṣàn gba àgbàlá inú ni! Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò fi ọ̀nà tí wọ́n lè gbà gbádùn ìdúró mímọ́ bù kún wọn.
9. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe lè ní ìdúró mímọ́ lónìí?
9 Bákan náà lónìí, a ti fi ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà bù kún àwọn ẹni àmì òróró. Jèhófà ń wò wọ́n bí ẹni mímọ́, ní pípolongo wọn ní olódodo. (Róòmù 5:1, 2) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí àwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe àlùfáà ṣàpẹẹrẹ ńkọ́? Wọ́n ń jọ́sìn nínú àgbàlá òde, omi kan náà yẹn sì ṣàn gba ti apá yẹn nínú tẹ́ńpìlì inú ìran náà. Ẹ wá wo bó ti bá a mu wẹ́kú tó pé àpọ́sítélì Jòhánù rí ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n wọ aṣọ funfun gbòò, bí wọ́n ti ń jọ́sìn nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà! (Ìṣípayá 7:9-14) Ọ̀nà yòówù kí a ti gbà bá wọn lò nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí, a mú un dá wọn lójú pé níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà yóò kà wọ́n sí ẹni mímọ́, tí kò lábààwọ́n. Báwo ni wọ́n ṣe ń lo ìgbàgbọ́? Ó jẹ́ nípa títẹ̀lé ìṣísẹ̀ Jésù, níní ìgbọ́kànlé kíkún nínú ẹbọ ìràpadà náà.—1 Pétérù 2:21.
10, 11. Apá pàtàkì wo ni omi ìṣàpẹẹrẹ yìí ní, báwo sì ni èyí ṣe kan kíkún tí odò náà túbọ̀ ń kún sí i lọ́nà tó bùáyà?
10 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, apá pàtàkì mìíràn wà nínú omi ìṣàpẹẹrẹ yìí—ìyẹn ni ìmọ̀. Ní Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀ sípò, Jèhófà fi ìtọ́ni inú Ìwé Mímọ́ nípasẹ̀ àwọn àlùfáà bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 44:23) Lọ́nà tí ó jọ èyí, Jèhófà ti fi ìtọ́ni tí ó pọ̀ tó nípa Ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ̀ bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ lónìí nípasẹ̀ “ẹgbẹ́ àlùfáà” náà. (1 Pétérù 2:9) Ìmọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run, nípa àwọn ète rẹ̀ fún aráyé, àti pàápàá jù lọ nípa Jésù Kristi àti Ìjọba Mèsáyà náà túbọ̀ ń ṣàn gbùúgbùú bí ọ̀gbàrá ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ẹ wo bí ọ̀pọ̀ yanturu ìtura nípa tẹ̀mí tí a ń rí gbà ti ga lọ́lá tó!—Dáníẹ́lì 12:4.
11 Gan-an bí odò tí áńgẹ́lì náà wọ̀n ṣe túbọ̀ ń jìn sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìbùkún yàbùgà-yabuga tí ń fúnni ní ìyè láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, kí ó lè kúnjú àìní iye àwọn ènìyàn tí ń rọ́ wá sínú ilẹ̀ wa tẹ̀mí tí a bù kún. A tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò mìíràn pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísáyà 60:22) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti ṣẹ—àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ti rọ́ wá láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn mímọ́ gaara! Jèhófà ti mú ọ̀pọ̀ yanturu “omi” wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn tí ó yíjú sí i. (Ìṣípayá 22:17) Ó ń rí sí i pé ètò àjọ òun lórí ilẹ̀ ayé ń pín Bíbélì àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jákèjádò ilẹ̀ ayé, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Bákan náà, a ti ṣètò àwọn ìpàdé Kristẹni àti àwọn àpéjọpọ̀ pàápàá kárí ayé kí a lè pèsè omi òtítọ́ tí ó mọ́ bíi kírísítálì fún gbogbo wa. Báwo ni irú àwọn ìpèsè bẹ́ẹ̀ ṣe ń nípa lórí àwọn ènìyàn?
Omi Náà Ń Mú Ìyè Wá!
12. (a) Kí ló fà á tí àwọn igi inú ìran Ìsíkíẹ́lì fi lè méso jáde lọ́nà tí wọ́n gbà ń méso jáde? (b) Kí ni àwọn igi eléso wọ̀nyí dúró fún ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
12 Odò inú ìran Ìsíkíẹ́lì ń mú ìyè àti ìlera wá. Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì mọ̀ nípa àwọn igi tí yóò hù lẹ́bàá odò náà, a sọ fún un pé, “Ewé wọn kì yóò rọ, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò jẹ èso wọn run. . . . Èso wọn yóò wà fún oúnjẹ, ewé wọn yóò sì wà fún ìmúniláradá.” Èé ṣe tí àwọn igi wọ̀nyí fi ń méso jáde lọ́nà àràmàǹdà bẹ́ẹ̀? “Nítorí omi wọn—ó ń jáde wá láti ibùjọsìn náà gan-an.” (Ìsíkíẹ́lì 47:12b) Àwọn igi ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún gbogbo ìpèsè Ọlọ́run fún dídá aráyé padà sí ìjẹ́pípé lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. Ní àkókò yìí lórí ilẹ̀ ayé, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ni wọ́n ń mú ipò iwájú nínú pípèsè oúnjẹ àti mímúni lára dá nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì bá ti gba èrè wọn ti ọ̀run, àwọn àǹfààní tí yóò máa tú jáde láti inú iṣẹ́ ìsìn àlùfáà wọn gẹ́gẹ́ bí alájùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú Kristi yóò dé ọjọ́ iwájú, nìkẹyìn, èyí yóò yọrí sí ìṣẹ́gun pátápátá lórí ikú tí Ádámù fà.—Ìṣípayá 5:9, 10; 21:2-4.
13. Ìmúláradá wo ló wáyé ní àkókò tiwa?
13 Odò inú ìran náà ṣàn lọ sínú Òkun Òkú tí kò sí ohun alààyè nínú rẹ̀, ó sì wo gbogbo ohun tí ó kàn lára sàn. Òkun yìí ṣàpẹẹrẹ àyíká tí ó ti kú nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ṣe ní ohun alààyè ń gbá yìn-ìn “níbi gbogbo tí ọ̀gbàrá náà tí ó pọ̀ ní ìlọ́po méjì bá dé.” (Ìsíkíẹ́lì 47:9) Bákan náà, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ènìyàn ti ń sọ jí sí ìyè nípa tẹ̀mí níbikíbi tí omi ìyè náà bá ti ṣàn dé. Àwọn tí a kọ́kọ́ sọ jí ni àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ní ọdún 1919. Wọ́n sọ jí sí ìyè nípa tẹ̀mí láti inú ipò kan tí ó dà bí ti òkú, ipò àìṣiṣẹ́. (Ìsíkíẹ́lì 37:1-14; Ìṣípayá 11:3, 7-12) Omi tí ń sọ nǹkan jí yìí ti ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n ti kú nípa tẹ̀mí, àwọn wọ̀nyí sì sọ jí sí ìyè, wọ́n sì di ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn tí ń pọ̀ sí i ṣáá, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń sìn ín. Láìpẹ́, a óò mú ìpèsè yìí dé ọ̀dọ̀ ògìdìgbó àwọn tí a óò jí dìde.
14. Kí ni iṣẹ́ òwò ẹja tó búrẹ́kẹ́ létí bèbè Òkun Òkú ń ṣàpèjúwe lónìí?
14 Ìtaraṣàṣà nípa tẹ̀mí máa ń yọrí sí ìmésojáde. Èyí ni a fi iṣẹ́ òwò ẹja tí ó búrẹ́kẹ́ ní etí òkun tí ó kú tẹ́lẹ̀ náà ṣàpẹẹrẹ. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi yóò . . . sọ yín di apẹja ènìyàn.” (Mátíù 4:19) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, iṣẹ́ ẹja pípa náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíkó àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ẹni àmì òróró jọ, ṣùgbọ́n kò pin síbẹ̀. Omi tí ń fúnni ní ìyè láti inú tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí, títí kan ìbùkún ìmọ̀ pípéye, ń nípa lórí àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Ibikíbi tí ọ̀gbàrá náà bá dé, ó ti yọrí sí ìyè nípa tẹ̀mí.
15. Kí ló fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò tẹ́wọ́ gba ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe fún ìyè, kí sì ni yóò gbẹ̀yìn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀?
15 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ń dáhùn lọ́nà rere sí ìhìn iṣẹ́ ìyè nísinsìnyí; bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bá jíǹde nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ti Kristi ni yóò ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 65:20; Ìṣípayá 21:8) Áńgẹ́lì náà polongo pé àwọn apá kan lára òkun náà kò rí ìwòsàn gbà. Àwọn ibi àbàtà, tí kò sí ohun alààyè nínú rẹ̀ wọ̀nyí ni a ‘fi fún iyọ̀.’ (Ìsíkíẹ́lì 47:11) Ní ti àwọn ènìyàn ọjọ́ wa, kì í ṣe gbogbo ẹni táa bá bu omi Jèhófà tí ń fúnni ní ìyè fún ni yóò tẹ́wọ́ gbà á. (Aísáyà 6:10) Ní Amágẹ́dọ́nì, gbogbo àwọn tí wọ́n yàn láti máa bá a lọ nínú ipò jíjẹ́ òkú àti aláìsàn nípa tẹ̀mí ni a óò fi fún iyọ̀, ìyẹn ni pé, a óò pa wọ́n run títí láé. (Ìṣípayá 19:11-21) Ṣùgbọ́n, àwọn tí ń fi tòótọ́tòótọ́ mu nínú omi yìí lè fojú sọ́nà láti là á já, kí wọ́n sì rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí níkẹyìn.
Odò Náà Ń Ṣàn Nínú Párádísè
16. Nígbà wo ni ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ní ìmúṣẹ ìkẹyìn, ọ̀nà wo ló sì gbà ní in?
16 Gẹ́gẹ́ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò yòókù, ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí yóò ní ìmúṣẹ rẹ̀ ìkẹyìn nígbà Ẹgbẹ̀rúndún. Nígbà yẹn, ẹgbẹ́ àlùfáà kò ní sí níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé mọ́. “Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ [ní ọ̀run] fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6) Àwọn àlùfáà ní ọ̀run yìí yóò wà pẹ̀lú Kristi ní fífúnni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò gba aráyé olódodo là, a óò sì dá wọn padà sí ìjẹ́pípé!—Jòhánù 3:17.
17, 18. (a) Báwo ni a ṣe ṣàpèjúwe odò tí ń fúnni ní ìyè nínú Ìṣípayá 22:1, 2, nígbà wo sì ni ìran yẹn kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ? (b) Nínú Párádísè, èé ṣe tí odò omi ìyè yóò fi kún tó bí kò ṣe kún rí?
17 Ìyẹn ni pé, nígbà náà, omi ìyè tó gbéṣẹ́ jù lọ ni yóò máa ṣàn nínú odò tí Ìsíkíẹ́lì rí. Èyí ni àkókò pàtàkì fún ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sínú Ìṣípayá 22:1, 2 pé: “Ó . . . fi odò omi ìyè kan hàn mí, tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wá sí ìsàlẹ̀ gba àárín ọ̀nà fífẹ̀ rẹ̀. Àwọn igi ìyè tí ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde sì wà níhà ìhín odò náà àti níhà ọ̀hún, tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.”
18 Nígbà Ẹgbẹ̀rúndún náà, gbogbo àìsàn—ti ara, ti ọpọlọ, àti ti èrò ìmọ̀lára—ni a óò wò sàn. Èyí ni a fi “wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn” nípasẹ̀ àwọn igi ìṣàpẹẹrẹ náà ṣàkàwé dáadáa. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìpèsè tí Kristi àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì pín fúnni, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Odò náà yóò sì wá dé àkókò tí yóò kún tó bí kò ṣe kún rí. Yóò wá fẹ̀ sí i, yóò sì jìn sí i, kí ó lè tó fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́, bóyá ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù pàápàá nínú àwọn ènìyàn tí a óò jí dìde tí yóò mu nínú omi ìyè mímọ́ gaara yìí. Odò yìí tí a rí nínú ìran wo Òkun Òkú sàn, ó mú ìyè wá fún ibikíbi tí omi rẹ̀ ṣàn dé. Nínú Párádísè, tọkùnrin tobìnrin yóò padà sí ìyè lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, a óò ti wò wọ́n sàn kúrò nínú ikú Ádámù tí wọ́n jogún bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn àǹfààní ìràpadà tí a nawọ́ rẹ̀ sí wọn. Ìṣípayá 20:12 sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò ṣí “àwọn àkájọ ìwé” sílẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọnnì, kí wọ́n lè pèsè ìmọ́lẹ̀ òye púpọ̀ sí i nípasẹ̀ èyí tí àwọn tí a jí dìde yóò ti jàǹfààní. Ó bani nínú jẹ́ pé, nínú Párádísè pàápàá, àwọn kan yóò kọ̀ láti gba ìwòsàn. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí ni àwọn tí a ‘fi fún iyọ̀’ ìparun ayérayé.—Ìṣípayá 20:15.
19. (a) Báwo ni a óò ṣe mú pípín ilẹ̀ ṣẹ nínú Párádísè? (b) Apá wo nínú Párádísè ni ìlú ńlá náà ń ṣàpẹẹrẹ? (d) Kí ni ìjẹ́pàtàkì jíjìnnà tí ìlú ńlá náà jìnnà sí tẹ́ńpìlì?
19 Ní àkókò yẹn pẹ̀lú, pípín ilẹ̀ inú ìran Ìsíkíẹ́lì yóò tún ní ìmúṣẹ rẹ̀ ìkẹyìn. Ìsíkíẹ́lì rí i pé a pín ilẹ̀ náà lọ́nà tí ó bójú mu; bákan náà, olúkúlùkù Kristẹni olóòótọ́ lè ní ìdánilójú pé òun yóò ní àyè kan, ogún kan, nínú Párádísè. Ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ láti ní ilé ara ẹni tí a lè máa gbénú rẹ̀, tí a sì lè máa bójú tó ní ìmúṣẹ lọ́nà tí ó wà létòlétò. (Aísáyà 65:21; 1 Kọ́ríńtì 14:33) Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, ìlú ńlá náà tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ ètò ìṣàbójútó tí Jèhófà pète fún ilẹ̀ ayé tuntun náà. Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, kò ní sí láàárín àwọn ènìyàn mọ́ nípa ti ara. Ìran náà fi èyí hàn dáadáa nípa fífi ìlú ńlá náà hàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ilẹ̀ “àìmọ́,” ibì kan tí ó jìnnà díẹ̀ sí tẹ́ńpìlì náà. (Ìsíkíẹ́lì 48:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ń ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Ọba náà kò ní aṣojú lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀ yóò jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ìdarí tí ẹgbẹ́ ìjòyè náà ń ṣe. Àmọ́ ṣá o, ọ̀run ni ibùjókòó ìjọba náà gan-an máa wà, kì í ṣe ilẹ̀ ayé. Gbogbo ẹni tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé, títí kan ẹgbẹ́ ìjòyè náà, ni yóò fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Mèsáyà náà.—Dáníẹ́lì 2:44; 7:14, 18, 22.
20, 21. (a) Èé ṣe tí orúkọ ìlú ńlá náà fi bá a mú wẹ́kú? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni òye wa nípa ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ràn wá lọ́wọ́ láti bi ara wa?
20 Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ àsọparí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì: “Orúkọ ìlú ńlá náà láti ọjọ́ yẹn lọ yóò . . . máa jẹ́ Jèhófà Alára Wà Níbẹ̀.” (Ìsíkíẹ́lì 48:35) A kò tẹ ìlú ńlá yìí dó nítorí àtifún àwọn ènìyàn lágbára tàbí kí wọ́n lè jẹ gàba léni lórí; bẹ́ẹ̀ ni a kò tẹ̀ ẹ́ dó láti fagbára múni ṣe ìfẹ́ ènìyàn èyíkéyìí. Ìlú ńlá ti Jèhófà ni, èrò inú rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, tó fòye hàn, ni yóò máa gbé yọ. (Jákọ́bù 3:17) Èyí fún wa ní ìdálójú amọ́kànyọ̀ pé Jèhófà yóò bù kún àwùjọ “ilẹ̀ ayé tuntun” ti aráyé tí a gbé kalẹ̀ náà títí dé ọjọ́ iwájú tí ó lọ fáàbàdà.—2 Pétérù 3:13.
21 Ìrètí tó wà níwájú wa kò ha mú inú wa dùn bí? Lọ́nà tó ṣe wẹ́kú, nígbà náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń dáhùn sí àwọn ìbùkún àgbàyanu tí a ṣí payá nínú ìran Ìsíkíẹ́lì? Mo ha ń fi tòótọ́tòótọ́ kọ́wọ́ ti iṣẹ́ tí àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ ń ṣe, títí kan èyí tí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àti ti àwọn tí yóò di mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ìjòyè ń ṣe bí? Ṣé mo ti sọ ìjọsìn mímọ́ gaara di apá pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi? Ṣé mo ń lo àǹfààní omi ìyè tí ń ṣàn gbùúgbùú lónìí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?’ Ǹjẹ́ kí olúkúlùkù wa máa bá a lọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí inú wa sì máa dùn sí àwọn ìpèsè Jèhófà títí ayé àìnípẹ̀kun!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àfonífojí olójú ọ̀gbàrá yìí lè tọ́ka sí Àfonífojì Kídírónì, èyí tí ó dé gúúsù ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù, tí ó sì parí sí Òkun Òkú. Ní pàtàkì, apá ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aṣálẹ̀, ó sì máa ń gbẹ táútáú yípo ọdún.
b Wo ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti May 1, 1881, (Gẹ̀ẹ́sì) àti December 1, 1981.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni omi tí ń ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì dúró fún?
◻ Ìmúláradá wo ni Jèhófà ti ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ odò ìṣàpẹẹrẹ náà, èé ṣe tí odò náà sì fi ń kún sí i?
◻ Kí ni àwọn igi tó wà ní bèbè odò náà ń ṣàpẹẹrẹ?
◻ Kí ni ìlú ńlá náà yóò ṣàpẹẹrẹ nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún, èé sì ti ṣe tí orúkọ ìlú ńlá náà fi bá a mu wẹ́kú?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Odò ìyè ń ṣàpẹẹrẹ ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe fún ìgbàlà