Àkókò àti Ayérayé—Kí La Tiẹ̀ Mọ̀ Nípa Wọn?
“ÀKÓKÒ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára ohun kàyéfì jù lọ tí èèyàn ń nírìírí rẹ̀,” ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan ló sọ bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe láti túmọ̀ àkókò lọ́nà tó rọrùn. A lè sọ pé àkókò “ti tán,” àkókò “ń lọ,” àkókò “ń súré tete,” a tilẹ̀ lè wá sọ pé àwa fúnra wa ń bá “àkókò yí.” Ṣùgbọ́n, ní gidi, ká kúkú sọ pé a ò mọ ohun tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
A ti túmọ̀ àkókò gẹ́gẹ́ bí “àlàfo tó wà láàárín ìṣẹ̀lẹ̀ méjì.” Síbẹ̀, ó dà bíi pé àwọn ìrírí wa ń jẹ́ ká mọ̀ pé, àkókò kò ní í ṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀; ó dà bíi pé àkókò yóò máa bá a lọ yálà àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tàbí kò ṣẹlẹ̀. Onímọ̀ ọgbọ́n orí kan sọ pé kò sóhun tí ń jẹ́ àkókò, ó kàn jẹ́ ohun kan táa finú rò lásán ni. Ǹjẹ́ ohun kan tó jẹ́ pé a gbé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa kà kàn lè jẹ́ ohun táa finú rò lásán?
Ojú Ìwòye Bíbélì Nípa Àkókò
Bíbélì kò fún àkókò ní ìtumọ̀ pàtó, èyí ló sì fi hàn pé àfàìmọ̀ ni àkókò kò ní jẹ́ ohun kan tó kọjá agbára ènìyàn láti lóye ní kíkún. Ṣe ló dà bíi gbalasa òfuurufú tó lọ salalu, tó ṣòro fún wa láti lóye. Lọ́nà tó ṣe kedere, àkókò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun wọnnì tó ṣe pé Ọlọ́run nìkan ló lè lóye rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, nítorí òun nìkan ló wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 90:2.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò túmọ̀ àkókò, ó jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò wà lóòótọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run dá “àwọn orísun ìmọ́lẹ̀”—oòrùn, òṣùpá, àti ìràwọ̀—gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò pààlà sí àkókò, láti “wà fún àmì àti fún àwọn àsìkò àti fún àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.” Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ táa kọ sínú Bíbélì la gbé ka àkókò. (Jẹ́nẹ́sísì 1:14; 5:3-32; 7:11, 12; 11:10-32; Ẹ́kísódù 12:40, 41) Bíbélì tún sọ̀rọ̀ àkókò gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí a ní láti fi ọgbọ́n lò, kí a bàa lè rí ìbùkún Ọlọ́run ti àkókò tí kò lópin gbà—ìrètí wíwàláàyè títí láé.—Éfésù 5:15, 16.
Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ó Ha Bọ́gbọ́n Mu Bí?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbígbìyànjú láti lóye ohun tí àkókò jẹ́ gan-an ti mú ìjákulẹ̀ bá ọ̀pọ̀ èèyàn, èrò nípa ìyè àìnípẹ̀kun, tàbí wíwàláàyè títí láé, ṣì ni ohun tó rú wọn lójú jù lọ. Ohun kan tó ṣeé ṣe kó fa èyí ni pé ohun táa mọ̀ nípa àkókò ti fìgbà gbogbo ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà bíbímọ, ìgbà dídàgbà, ìgbà dídarúgbó, àti ìgbà kíkú. Nípa báyìí, ọjọ́ orí wa gan-an la fi ń díwọ̀n bí àkókò ti ń lọ. Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, báa bá ronú lọ́nà tó yàtọ̀ ṣe ni yóò wulẹ̀ dà bí pé a ń tẹ ìlànà àkókò lójú. Wọ́n wá lè béèrè pé, ‘Èé ṣe tí ẹ̀dá ènìyàn yóò fi yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀dá alààyè mìíràn ní ti ọjọ́ orí.’
Ohun tí a sábà máa ń fojú bíńtín wò nínú irú ìrònú yìí ni òótọ́ náà pé èèyàn yàtọ̀ sí gbogbo ẹ̀dá yòókù lọ́pọ̀ ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹranko kò ní agbára ìrònú tí ènìyàn ní. Láìka ohun tí àwọn kan sọ sí, àwọn ẹranko kò lè ṣe ju ohun tí agbára ìsúnniṣe bá sún wọn láti ṣe. Wọn kò ní ẹ̀bùn iṣẹ́ ọnà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lágbára láti fi irú ìfẹ́ àti ìmọrírì tí èèyàn ní hàn. Níwọ̀n bí a ti fún ènìyàn ní àwọn ànímọ́ àti agbára wọ̀nyí tó mú kí ìgbésí ayé nítumọ̀, èé ṣe tí kò fi ṣeé ṣe pẹ̀lú láti fún wọn ní àkókò púpọ̀ sí i láti fi wà láàyè?
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ǹjẹ́ kò yani lẹ́nu pé nígbà mìíràn àwọn igi, tí kò lè ronú, ń gbé ayé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, níbi tó ti jẹ́ pé ní ìpíndọ́gba àwọn ẹ̀dá ènìyàn olóye lè lo kìkì àádọ́rin sí ọgọ́rin ọdún lókè eèpẹ̀? Ǹjẹ́ kò pani lẹ́rìn-ín pé àwọn alábahun, tí wọn kò ní agbára ìrònú rárá, tí wọn kò sì lè dábírà kankan, lè wà láàyè fún ohun tó lé ní igba ọdún, nígbà tó jẹ́ pé èèyàn, táa fi àwọn agbára wọ̀nyẹn jíǹkí, bó bá wà láàyè tí a kò rírú ẹ̀ rí, agbára káká ni yóò fi lo ìlàjì ọdún tí ìjàpá ń gbé láyé?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn kò lè lóye àkókò àti ayérayé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun ṣì jẹ́ ìrètí tó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú Bíbélì. Nínú rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà “ìyè àìnípẹ̀kun” fara hàn nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ ète Ọlọ́run ni pé kí èèyàn wà láàyè títí láé, èé ṣe tí ọwọ́ wa kò fi tí ì tẹ̀ ẹ́? A óò gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.