Máà Jẹ́ Kí Ìbínú Mú Ọ Kọsẹ̀
“MÍ KANLẸ̀!” “Ka ení, èjì, títí dórí ẹẹ́wàá!” “Dákẹ́, má fọhùn!” Ǹjẹ́ o ti gbọ́ àwọn gbólóhùn wọ̀nyí rí? Bóyá o tilẹ̀ máa ń tún un sọ lọ́kàn rẹ lọ́hùn-ún láti lè mú kí inú rẹ tí ń ru gùdù rọ̀. Bí inú bá ń bí àwọn èèyàn kan, láti lè káwọ́ ìrunú wọn, wọ́n á rìn jáde. Àwọn ọ̀nà tó rọrùn nìwọ̀nyí láti káwọ́ ìbínú, kí a sì máa bá àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lọ.
Ṣùgbọ́n, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àbájáde àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lórí bóyá ó yẹ ká máa káwọ́ ìbínú tàbí ṣe ló yẹ ká tẹ̀ ẹ́ rì, ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa kọminú. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n jẹ́ afìṣemọ̀rònú ti gbé àbá èrò orí náà kalẹ̀ pé tó bá jẹ́ pé “òun ló mára tù ọ́,” kúkú fara ya, kóo sì bínú ọ̀hún dáadáa. Àwọn mìíràn sì kìlọ̀ pé, bíbínú ní gbogbo ìgbà “jẹ́ ohun tó lè tètè pani ní rèwerèwe ju àwọn ohun mìíràn bíi mímu sìgá, àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, àti àpọ̀jù ọ̀rá nínú ara.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kúkú là á mọ́lẹ̀ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sáàmù 37:8) Èé ṣe tí Bíbélì fi fúnni ní irú ìmọ̀ràn pàtó bẹ́ẹ̀?
Ìbínú gbuurugbu máa ń yọrí sí ìwàkiwà. Èyí tètè hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ènìyàn. A kà pé: “Ìbínú Kéènì sì gbóná gidigidi, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì.” Ibo lèyí sìn ín dé? Ìbínú rẹ̀ wọ̀ ọ́ lára, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í darí òun alára, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọkàn rẹ̀ fi yigbì, tí kò sì fetí sí ìṣílétí tí Jèhófà fún un pé kí ó ṣe ohun tí ó tọ́. Ìbínú gbuurugbu sún Kéènì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì—ó pa àbúrò rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:3-8.
Bákan náà ni ara Sọ́ọ̀lù, ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì, ṣe gbóná kọjá ààlà nígbà tó gbọ́ pé Dáfídì gba ìyìn ńlá. “Àwọn obìnrin tí ń ṣe ayẹyẹ sì ń bá a nìṣó ní dídáhùn padà pé: ‘Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀.’ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí bínú gidigidi, àsọjáde yìí sì burú ní ojú ìwòye rẹ̀.” Ìbínú wọ Sọ́ọ̀lù lára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi ń tì í kiri láti gbìyànjú àtipa Dáfídì lọ́pọ̀ ìgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì fẹ́ kí ọ̀ràn náà parí, kí àwọn sì tún di ọ̀rẹ́ padà, Sọ́ọ̀lù kò fẹ́ kí ọ̀ràn náà parí ní ìtùnbí-ìnùbí rárá. Àbálọ-àbábọ̀ rẹ̀ ni pé, ó pàdánù ojúure Jèhófà pátápátá.—1 Sámúẹ́lì 18:6-11; 19:9, 10; 24:1-21; Òwe 6:34, 35.
Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé, nígbà tí ẹnì kan kò bá káwọ́ ìbínú rẹ̀, yóò hùwà tí yóò bí àwọn tọ́ràn kàn nínú tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ tí kò ní tán nílẹ̀. (Òwe 29:22) Kéènì àti Sọ́ọ̀lù bínú nítorí pé, àwọn méjèèjì jowú, wọ́n sì ń ṣe ìlara. Ṣùgbọ́n, onírúurú ìwà ló lè fa ìbínú o. Ṣíṣe lámèyítọ́ ẹni, fífi ìwọ̀sí lọni, èdè àìyedè, tàbí ṣíṣe ojúsàájú lè mú kí ìbínú ẹni ru.
Àpẹẹrẹ ti Kéènì àti Sọ́ọ̀lù fi hàn pé àrùn kan náà ló ń bá àwọn méjèèjì jà. Ó jọ pé kì í ṣe ìgbàgbọ́ ló sún Kéènì láti rúbọ. (Hébérù 11:4) Kíkọ̀ tí Sọ́ọ̀lù kọ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà àti àwọn ìgbésẹ̀ tó gbé láti da ara rẹ̀ láre lẹ́yìn ìgbà náà ló jẹ́ kó pàdánù ojú rere àti ẹ̀mí Ọlọ́run. Ó ṣe kedere pé, àwọn méjèèjì ba ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
Fi irú ìwà bẹ́ẹ̀ wé ti Dáfídì, ẹni tó ní ìdí láti bínú nítorí ohun tí Sọ́ọ̀lù fojú rẹ̀ rí. Dáfídì kó ara rẹ̀ níjàánu. Èé ṣe? Ó wí pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n ṣe ohun yìí sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà.” Dáfídì kò fi ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣeré rárá, ó sì nípa lórí ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù. Ó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́.—1 Sámúẹ́lì 24:6, 15.
Ní tòótọ́, ohun tí ìbínú gbuurugbu máa ń yọrí sí lágbára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀.” (Éfésù 4:26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkannú òdodo ní àyè tirẹ̀, ewu tó máa ń wà níbẹ̀ ni pé ìbínú lè mú wa kọsẹ̀. Abájọ nígbà náà táa fi dojú kọ ìpèníjà náà láti máa káwọ́ ìbínú wa. Báwo la ṣe lè ṣe é?
Ọ̀nà pàtàkì kan ni láti mú ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jèhófà. Ó ń rọ̀ ọ́ pé, kí o finú han òun. Sọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ àti olórí àníyàn rẹ̀ fún un, bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fún ọ ní ọkàn tútù láti lè káwọ́ ìbínú. (Òwe 14:30) Mọ̀ dájú pé “ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.”—1 Pétérù 3:12.
Àdúrà lè sọ wá di ẹni ọ̀tọ̀ pátápátá, ó sì lè dáàbò bò wá. Lọ́nà wo? Ó lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìbálò rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Rántí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá ọ lò. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Jèhófà “kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (Sáàmù 103:10) Ẹ̀mí ìdáríjì ṣe pàtàkì kí “Sátánì má bàa . . . borí” rẹ. (2 Kọ́ríńtì 2:10, 11) Síwájú sí i, ó dà bí ẹni pé àdúrà máa ń ṣí ọkàn-àyà ẹni sílẹ̀ fún ìdarí ẹ̀mí mímọ́, èyí tó lè yí ọ̀nà ìgbésí ayé to ti di mọ́líkì síni lára padà. Tayọ̀tayọ̀ ni Jèhófà fi ń fúnni ní ‘àlàáfíà tí ó ta gbogbo ìrònú yọ,’ èyí tó lè gbà wá lọ́wọ́ agbára ìbínú tó ń wani mú pinpin.—Fílípì 4:7.
Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ fi ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ déédéé kún àdúrà gbígbà kí a bàa lè “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Éfésù 5:17; Jákọ́bù 3:17) Bó bá ṣòro fún ọ láti káwọ́ ìbínú rẹ, sapá láti mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀ràn náà. Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó dá lórí kíkáwọ́ ìbínú.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni ní ìránnilétí pàtàkì yìí: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Pa ìrònú àti ìṣe rẹ pọ̀ sórí ṣíṣe ohun rere fún àwọn ẹlòmíràn. Irú ìgbòkègbodò rere tó gbámúṣé bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí a lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, yóò jẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ẹlòmíràn, yóò sì dín èdè àìyedè tó lè tètè yọrí sí ìbínú kù.
Onísáàmù náà wí pé: “Fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú àsọjáde rẹ, kí nǹkan kan tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ má sì jẹ gàba lé mi lórí. Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.” (Sáàmù 119:133, 165) Tìrẹ náà lè rí bẹ́ẹ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ÌGBÉSẸ̀ TÓO LÈ GBÉ LÁTI KÁWỌ́ ÌBÍNÚ
□ Gbàdúrà sí Jèhófà.—Sáàmù 145:18.
□ Máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́. —Sáàmù 119:133, 165.
□ Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí fún àwọn ìgbòkègbodò tó dára.—Gálátíà 6:9, 10.