“Ìgbà Àlàáfíà” Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé!
“Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà ogun àti ìgbà àlàáfíà.”—ONÍWÀÁSÙ 3:1, 8.
1. Ipò tó tojú súni wo ló wáyé ní ọ̀rúndún ogún nípa ọ̀ràn ogun àti àlàáfíà?
Ọ̀PỌ̀ jù lọ ènìyàn ló ń fẹ́ àlàáfíà lójú méjèèjì, ó sì nídìí tí wọ́n fi ń fẹ́ ẹ. Ọ̀nà tí àlàáfíà gbà ń pòórá ní ọ̀rúndún ogún yìí ga púpọ̀ ju ti ọ̀rúndún èyíkéyìí nínú ìtàn. Èyí tó tiẹ̀ tún mú kó tojú súni ni pé, aráyé kò tí ì sapá tó báyìí rí láti rí i pé àlàáfíà jọba. Lọ́dún 1920, wọ́n dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Ní 1928, wọ́n fọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn Àlàáfíà ti Kellogg-Briand, àdéhùn náà ni ìwé kan pè ní “àdéhùn tó fani lọ́kàn mọ́ra jù lọ nínú gbogbo ọ̀wọ́ àdéhùn àlàáfíà táwọn orílẹ̀-èdè ṣe lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní,” ìwé náà fi kún un pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé . . . ló panu pọ̀ láti sọ páwọn ò ní lo ogun jíjà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìjọba láti mú àlàáfíà wá.” Ìgbà tó tún di ọdún 1945, wọ́n fi àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè rọ́pò Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó forí ṣánpọ́n.
2. Kí ni wọ́n pè ní góńgó Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, báwo ló sì ti kẹ́sẹ járí tó?
2 Gẹ́gẹ́ bíi ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ohun tí wọ́n pè ní góńgó Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni láti rí i pé àlàáfíà jọba káàkiri àgbáyé. Àmọ́, àṣeyọrí díẹ̀ ló ṣe. Lóòótọ́, táa bá ní ká fojú ogun àgbáyé méjèèjì tó ti jà wò ó, ogun ò jà mọ́ níbikíbi lágbàáyé. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó ń wáyé kò jẹ́ kí ọkàn ẹgbẹẹgbàárùn-ún èèyàn balẹ̀, ó ti fi dúkìá ṣòfò, lọ́pọ̀ ìgbà ló sì ti gbẹ̀mí àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ a tún lè retí pé kí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè wá sọ ọ̀rúndún kọkànlélógún wa yìí di “ìgbà àlàáfíà”?
Ìpìlẹ̀ fún Àlàáfíà Tòótọ́
3. Èé ṣe tí ojúlówó àlàáfíà kò fi lè sí níbi tí ìkórìíra bá wà?
3 Bí àlàáfíà yóò bá wà láàárín àwọn ènìyàn àti láàárín orílẹ̀-èdè kan sí èkejì, èyí kò ní jẹ́ ọ̀ràn ká kàn rára gba nǹkan sí lásán. Ẹnì kan ha lè wà lálàáfíà pẹ̀lú ẹnì kan tó kórìíra bí? Ìyẹn kò ní bá ohun tí 1 Jòhánù 3:15 sọ mú pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn.” Gẹ́gẹ́ bí ìtàn lọ́ọ́lọ́ọ́ ti fi hàn, tí ìkórìíra bá ti pọ̀ lápọ̀jù kì í pẹ́ di rògbòdìyàn.
4. Kìkì àwọn wo ló lè ní àlàáfíà, èé sì ti ṣe?
4 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà,” kìkì àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ìlànà òdodo rẹ̀, ló lè ní àlàáfíà. Ká kúkú là á mọ́lẹ̀ pé, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni Jèhófà ń fún ní àlàáfíà. “‘Àlàáfíà kò sí fún àwọn ẹni burúkú,’ ni Ọlọ́run mi wí.” Ìdí ni pé àwọn ẹni burúkú kọ̀ láti jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí wọn, ọ̀kan nínú èso ẹ̀mí yìí sì ni àlàáfíà.—Róòmù 15:33; Aísáyà 57:21; Gálátíà 5:22.
5. Kí letí ò gbọdọ̀ gbọ́ páwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣe?
5 Àgbẹdọ̀, etí ò gbọ́dọ̀ gbọ́ ọ pé àwọn ojúlówó Kristẹni ń bá àwọn ènìyàn bíi tiwọn jagun, àmọ́, èyí ló ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́, pàápàá ní ọ̀rúndún ogún wa yìí. (Jákọ́bù 4:1-4) Òtítọ́ ni pé àwọn ojúlówó Kristẹni ń bá àwọn ẹ̀kọ́ tó parọ́ mọ́ Ọlọ́run jagun, ṣùgbọ́n ogun yìí jẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kì í ṣe láti pa wọ́n lára. Láti ṣenúnibíni sáwọn ẹlòmíràn nítorí pé ẹ̀sìn wọ́n yàtọ̀ sí tiwa tàbí láti ṣe wọ́n léṣe nítorí pé wọn kì í ṣọmọ orílẹ̀-èdè wa, lòdì pátápátá sí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:17-19; 2 Tímótì 2:24, 25.
6. Ibo ni ibi kan ṣoṣo táa ti lè rí ojúlówó àlàáfíà lónìí?
6 Lónìí, àárín àwọn tí ń fi tòótọ́tòótọ́ jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run nìkan la ti lè rí àlàáfíà tí Ọlọ́run ń fúnni. (Sáàmù 119:165; Aísáyà 48:18) Ọ̀ràn pé oò sí lẹ́gbẹ́ òṣèlú tèmi kò lè da ìṣọ̀kan wọn rú, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé wọn kì í dá sọ́ràn òṣèlú níbi gbogbo tí wọ́n wà. (Jòhánù 15:19; 17:14) Nítorí pé ‘a so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà,’ ọ̀ràn pé ẹ̀sìn tìrẹ ò jọ tèmi kò lè da àlàáfíà wọn rú. (1 Kọ́ríńtì 1:10) Àlàáfíà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn jẹ́ iṣẹ́ ìyanu òde òní, èyí tí Ọlọ́run ṣe, ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀ pé: “Èmi yóò yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.”—Aísáyà 60:17; Hébérù 8:10.
Èé Ṣe Tó Fi Jẹ́ “Ìgbà Ogun” La Wà Yìí?
7, 8. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ojú wo ni wọ́n fi ń wo àkókò táa wà yìí? (b) Kí ni olórí ohun ìjà àwọn Kristẹni?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàáfíà ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fẹ́, síbẹ̀síbẹ̀ a gbà pé lọ́nà tó pọ̀ jù lọ, “ìgbà ogun” là ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Àmọ́, ogun tara kọ́ là ń jà o, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lílo ohun ìjà ogun láti fipá mú àwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Bíbélì yóò lòdì sí ìpè tí Ọlọ́run pè, nígbà tó wí pé: “kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Àwa kì í fi tìpá-tìkúùkù mú èèyàn gba ẹ̀sìn wa o! Ohun ìjà tẹ̀mí pọ́ńbélé ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run fún dídojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé.”—2 Kọ́ríńtì 10:4; 1 Tímótì 1:18.
8 Olórí “àwọn ohun ìjà ogun wa” ni “idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Éfésù 6:17) Agbára idà yìí ga lága jù. “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Nípa lílo idà yìí, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni láti dojú “àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run” dé. (2 Kọ́ríńtì 10:5) Ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tú àwọn ẹ̀kọ́ èké fó, àti àwọn ìwà abèṣe, àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó fi ọgbọ́n ènìyàn hàn dípò ọgbọ́n Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 2:6-8; Éfésù 6:11-13.
9. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ogun tí a ń bá ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wa jà?
9 Ogun tẹ̀mí mìíràn táa tún ń jà ni ogun tí a ń bá ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ jà. Àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ẹni tó jẹ́wọ́ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.” (1 Kọ́ríńtì 9:27) A rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé, kí wọ́n ‘sọ àwọn ẹ̀yà ara wọn tí ń bẹ ní ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.’ (Kólósè 3:5) Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Júúdà rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́ lọ́wọ́.” (Júúdà 3) Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù fèsì pé: “Bí ẹ bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, ó dájú pé ẹ óò kú; ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi ikú pa àwọn ìṣe ti ara nípasẹ̀ ẹ̀mí, ẹ ó yè.” (Róòmù 8:13) Lójú ìwòye ọ̀rọ̀ tó yéni yékéyéké yìí, kò yẹ ká jáwọ́ nínú ogun tí à ń bá àwọn èrò búburú jà.
10. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914, kí ló sì fẹ́ yọrí sí láìpẹ́, ní ọjọ́ iwájú?
10 Síbẹ̀, ìdí mìíràn táa tún fi lè ka àkókò wa yìí sì ìgbà ogun ni pé “ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa” ti sún mọ́lé. (Aísáyà 61:1, 2) Lọ́dún 1914, àkókò tí Jèhófà yàn dé láti gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀ àti láti fún ìjọba náà láṣẹ láti gbé ogun gbígbóná janjan dìde sí ètò Sátánì. Ìgbà yẹn ni àkókò náà dópin, èyí táa yọ̀ǹda fún ènìyàn láti lo ìjọba tó fọwọ́ ara rẹ̀ gbé kalẹ̀ láìjẹ́ pé Ọlọ́run dá sí i. Kàkà tí àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ì bá fi fara mọ́ Mèsáyà Alákòóso tí Ọlọ́run yàn, wọ́n kọ̀ ọ́, àní bí àwọn tó pọ̀ jù lọ ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 28:27) Ní àbárèbábọ̀, nítorí wọ́n ṣàtakò sí Ìjọba náà, ó di dandan fún Kristi láti “máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá [rẹ̀].” (Sáàmù 110:2) Ó dùn mọ́ni pé, Ìṣípayá 6:2 ṣèlérí pé òun yóò “parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Èyí ni yóò ṣe nígbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè . . . tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìṣípayá 16:14, 16.
“Ìgbà Sísọ̀rọ̀” Ti Dé
11. Èé ṣe tí Jèhófà fi mú sùúrù gan-an, ṣùgbọ́n, kí ni yóò dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?
11 Láti ọdún 1914 tí gbogbo ọ̀ràn ènìyàn ti yí padà bírí, ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún ló ti kọjá. Jèhófà ti mú sùúrù gan-an fún ìràn ènìyàn. Ó ti jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ mọ̀ dájú pé àkókò kánjúkánjú ni wọ́n wà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀mí àwọn ènìyàn ló wà nínú ewu. Ó yẹ ká kìlọ̀ fún ògìdìgbó wọ̀nyí nítorí pé “Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Síbẹ̀síbẹ̀, “ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára,” kò ní pẹ́ dé mọ́. Ìgbà yẹn ni “ẹ̀san” yóò dé sórí gbogbo àwọn tí wọ́n ti kọ etí ikún sí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, Jésù ni yóò sì mú ẹ̀san náà wá “sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹsalóníkà 1:6-9.
12. (a) Èé ṣe tí kò fi lè ṣàǹfààní kankan, táa bá ń méfò nípa ìgbà tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀? (b) Ewu wo ni Jésù kìlọ̀ rẹ̀ fún wa nípa èyí?
12 Ìgbà wo ni sùúrù Jèhófà yóò dópin? Táa bá wulẹ̀ ń méfò nípa ìgbà tí “ìpọ́njú ńlá” yóò bẹ̀rẹ̀, ìyẹn kò lè ṣàǹfààní kankan. Jésù là á mọ́lẹ̀ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n.” Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ó gbani níyànjú pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. . . . Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:21, 36, 42, 44) Táa bá ni ká sọ ọ́ lọ́nà tó lè yéni yékéyéké, èyí túmọ̀ sí pé, ojoojúmọ́ ló yẹ ká máa kíyè sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé, kí a sì máa ronú nípa ìgbà tí ìpọ́njú ńlá yóò bẹ́ sílẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 5:1-5) Ẹ wo bó ti léwu tó láti ní in lọ́kàn pé a lè dẹwọ́ wa, ká bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì, ká fọwọ́ lẹ́rán láti máa retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀! Jésù wí pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” (Lúùkù 21:34, 35) Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé: “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” tó wà fún ṣíṣe ìparun, èyí tí “àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin” Jèhófà dì mú báyìí kò ní wà bẹ́ẹ̀ títí ayé.—Ìṣípayá 7:1-3.
13. Kí ni àwọn èèyàn tó ń lọ sí mílíọ̀nù mẹ́fà ti mọ̀?
13 Pẹ̀lú bí ọjọ́ ìdájọ́ ti ń yára sún mọ́lé, àwọn ọ̀rọ̀ Sólómónì nípa pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” ń bẹ, wá ní ìtumọ̀ pàtàkì. (Oníwàásù 3:7) Níwọ̀n ìgbà tí a ti mọ̀ nísinsìnyí pé ìgbà sísọ̀rọ̀ la wà yìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa ògo ìjọba Ọlọ́run àti ìkìlọ̀ nípa ọjọ́ ẹ̀san rẹ̀. Wọ́n ń fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun Kristi yìí.—Sáàmù 110:3; 145:10-12.
Àwọn Tí Ń Kígbe “Àlàáfíà, Nígbà Tí Kò Sí Àlàáfíà”
14. Àwọn wòlíì èké wo ló wà ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa?
14 Ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa, Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ wòlíì Ọlọ́run kéde ìdájọ́ àtọ̀runwá lórí Jerúsálẹ́mù nítorí ìwàkiwà tó ti hù, ní ti pé ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ìparun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ wáyé lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olókìkí aṣáájú ìsìn, tí wọ́n lóókọ láwùjọ ti ta ko àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí fi hàn pé “wòlíì arìndìn [làwọ́n jẹ́, àwọn tó] . . . mú àwọn ènìyàn [Ọlọ́run] ṣáko lọ, wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà wà!,’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.”—Ìsíkíẹ́lì 13:1-16; Jeremáyà 6:14, 15; 8:8-12.
15. Ṣé irú àwọn wòlíì èké bẹ́ẹ̀ wà lónìí? Ṣàlàyé.
15 Gẹ́gẹ́ bí “àwọn wòlíì arìndìn” láyé ọjọ́un, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aṣáájú ìsìn òde ìwòyí ni kò kìlọ̀ fáwọn ènìyàn Ọlọ́run nípa ọjọ́ ìdájọ́ tó ń bọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ni wọ́n ń gbé lárugẹ pé yóò mú àlàáfíà àti ààbò wá nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n ń sọ̀rọ̀ wọn bíi pé àwọn ni yóò mú ọjọ́ ọ̀la tó dára wá. Nítorí pé wọ́n fẹ́ tẹ́ ènìyàn lọ́rùn ju Ọlọ́run lọ, ohun tí àwọn ọmọ ìjọ wọ́n fẹ́ gbọ́ ni wọ́n ń sọ fún wọn dípò tí wọn ì bá fi ṣàlàyé pé a ti gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ àti pé Mèsáyà Ọba yóò parí ìṣẹ́gun rẹ̀ láìpẹ́. (Dáníẹ́lì 2:44; 2 Tímótì 4:3, 4; Ìṣípayá 6:2) Gẹ́gẹ́ bíí wòlíì èké, àwọn pẹ̀lú ń kígbe “àlàáfíà, nígbà tí kò sí àlàáfíà.” Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ohun tí ọkàn wọn balẹ̀ lé lórí yìí yóò di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí wọn lára lójijì nígbà tó bá di dandan fún wọn láti dojú kọ ìbínú Ẹni náà tí wọ́n ti parọ́ mọ́, tí wọ́n sì ti mú ẹ̀gàn wá sórí orúkọ rẹ̀. Ibi tí àwọn aṣáájú ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí obìnrin oníṣekúṣe, bá ti ń kígbe àlàáfíà irọ́ wọn, ni itọ́ yóò ti sá pá wọn lórí, tí wọn yóò sì kú fin-ín-fin-ín.—Ìṣípayá 18:7, 8.
16. (a) Kí ló ti wà nínú ìtàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́? (b) Báwo ni wọ́n ṣe yàtọ̀ sí àwọn tí ń pariwó “àlàáfíà, nígbà tí kò sí àlàáfíà”?
16 Ti pé àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn aṣáájú olókìkí, tí wọ́n sì lóókọ láwùjọ yìí kò dẹ́kun ṣíṣèlérí asán wọn nípa àlàáfíà kò mi ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run nípa àlàáfíà. Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí, tó ti wà nínú ìtàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ afìdúróṣinṣin-gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, afìgboyà-ta-ko ìsìn èké, àti alátìlẹ́yìn gbágbáágbá fún Ìjọba Ọlọ́run. Dípò tí wọn ì bá fi máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídùndídùn nípa àlàáfíà kí oorun lè gbé àwọn èèyàn lọ, taápọntaápọn ni wọ́n fi ń sapá láti ta wọ́n jì, kí wọ́n lè mọ̀ pé òní ni ọjọ́ ogun.—Aísáyà 56:10-12; Róòmù 13:11, 12; 1 Tẹsalóníkà 5:6.
Jèhófà Fọhùn
17. Kí ló túmọ̀ sí pé Jèhófà yóò fọhùn láìpẹ́?
17 Sólómọ́nì wí pé: “Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ẹni burúkú, nítorí àkókò wà fún gbogbo àlámọ̀rí.” (Oníwàásù 3:17) Òdodo ọ̀rọ̀, Jèhófà ní àkókò tó ti yàn láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ìsìn èké àti sórí “àwọn ọba ilẹ̀ ayé [tí wọ́n] mú ìdúró wọn . . . lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀.” (Sáàmù 2:1-6; Ìṣípayá 16:13-16) Gbàrà tí àkókò yẹn bá ti tó, àwọn ọjọ́ dídákẹ́ “jẹ́ẹ́” tí Jèhófà dákẹ́ dópin nìyẹn. (Sáàmù 83:1; Aísáyà 62:1; Jeremáyà 47:6, 7) Nípasẹ̀ Mèsáyà Ọba rẹ̀ tí ń bẹ lórí ìtẹ́, ìyẹn Jésù Kristi, òun yóò ‘sọ̀rọ̀’ ní èdè kan ṣoṣo tó dà bíi pé àwọn alátakò rẹ̀ gbọ́: “Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò jáde lọ bí alágbára ńlá. Òun yóò jí ìtara dìde bí jagunjagun. Yóò kígbe, bẹ́ẹ̀ ni, yóò fi igbe ogun ta; yóò fi ara rẹ̀ hàn ní alágbára ńlá ju àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ. ‘Mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ìgbà pípẹ́. Mo ń bá a lọ ní dídákẹ́. Mo ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ, èmi yóò kérora, èmi yóò mí hẹlẹ, èmi yóò sì mí gúlegúle lẹ́ẹ̀kan náà. Èmi yóò pa àwọn òkè ńláńlá àti òkè kéékèèké run di ahoro, gbogbo ewéko wọn sì ni èmi yóò mú gbẹ dànù. Ṣe ni èmi yóò sọ àwọn odò di àwọn erékùṣù, àwọn odò adágún tí ó kún fún esùsú ni èmi yóò sì mú gbẹ táútáú. Ṣe ni èmi yóò sì mú kí àwọn afọ́jú rìn ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀; òpópónà tí wọn kò mọ̀ ni èmi yóò mú kí wọ́n rìn. Èmi yóò sọ ibi tí ó ṣókùnkùn níwájú wọn di ìmọ́lẹ̀, èmi yóò sì sọ àgbègbè ilẹ̀ kángunkàngun di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ. Ìwọ̀nyí ni nǹkan tí èmi yóò ṣe fún wọn, dájúdájú, èmi kì yóò fi wọ́n sílẹ̀.’”—Aísáyà 42:13-16.
18. Ọ̀nà wo làwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò gbà ‘dákẹ́’ láìpẹ́?
18 Nígbà tí Jèhófà ‘bá sọ̀rọ̀’ láti gbèjà ipò Ọba rẹ̀, kò ní pọndandan mọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gbèjà ara wọn. Yóò jẹ́ àkókò tiwọn ‘láti dákẹ́.’ Bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe ṣẹ sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lára nígbà àtijọ́, yóò ṣẹ sí àwọn pẹ̀lú lára pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín.”—2 Kíróníkà 20:17.
19. Àǹfààní wo ni yóò tẹ àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ láìpẹ́?
19 Ìparun yìí yóò mà fọ́ Sátánì àti ètò àjọ rẹ̀ túútúú o! Àwọn arákùnrin Kristi táa ti ṣe lógo yóò kópa nínú jíja ìjà àjàṣẹ́gun fún òdodo tírú rẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí, ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí náà pé: “Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà yóò tẹ Sátánì rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ yín láìpẹ́.” (Róòmù 16:20) Ìgbà àlàáfíà táa ti ń retí tipẹ́tipẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.
20. Àkókò kí ni yóò tó láìpẹ́?
20 Ẹ wo bi ìbùkún àwọn tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé, tó bá la ìfihàn agbára Jèhófà lọ́nà kíkàmàmà yìí já yóò ti pọ̀ tó! Láìpẹ́, àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ yóò dara pọ̀ mọ́ wọn, ìyẹn àwọn tó gbé láyé ọjọ́un, tí àkókò tí a yàn fún wọn láti jíǹde sì ti tó. Ní tòótọ́, àkókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi yóò jẹ́ “ìgbà gbígbìn . . . , ìgbà ìmúláradá . . . , ìgbà kíkọ́ . . . , ìgbà rírẹ́rìn-ín . . . , ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri . . . , ìgbà gbígbánimọ́ra àti . . . ìgbà nínífẹ̀ẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ “ìgbà àlàáfíà” títí ayé àìnípẹ̀kun!—Oníwàásù 3:1-8; Sáàmù 29:11; 37:11; 72:7.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Kí ló lè mú àlàáfíà pípẹ́ títí wá?
◻ Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ka ìgbà táa wà yìí sí “ìgbà ogun”?
◻ Ìgbà wo la retí pé kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ‘sọ̀rọ̀,’ ìgbà wo la sì retí pé kí wọ́n ‘dákẹ́’?
◻ Ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà fọhùn, ìgbà wo ni yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jèhófà Ní Àkókò Tí Ó Yàn fún
◻ mímú kí Gọ́ọ̀gù dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run.—Ìsíkíẹ́lì 38:3, 4, 10-12
◻ fífi í sínú ọkàn àwọn alákòóso ènìyàn láti pa Bábílónì Ńlá run.—Ìṣípayá 17:15-17; 19:2
◻ ṣíṣe ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn.—Ìṣípayá 19:6, 7
◻ dídá ogun Ha-Mágẹ́dọ́nì sílẹ̀.—Ìṣípayá 19:11-16, 19-21
◻ díde Sátánì, kí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù lè bẹ̀rẹ̀.—Ìṣípayá 20:1-3
A to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí lọ́nà táa gbà tọ́ka sí wọn nínú Ìwé Mímọ́. Ká ní ìdánilójú pé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ márààrún ni yóò ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí Jèhófà ti pinnu pé yóò gbà ṣẹlẹ̀ àti ní àkókò pàtó tó ti pinnu.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Láìsí iyèméjì, àkókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi yóò jẹ́ ìgbà . . .
rírẹ́rìn-ín . . .
gbígbánimọ́ra . . .
nínífẹ̀ẹ́ . . .
gbígbìn . . .
títọ pọ́n-ún pọ́n-ún . . .
kíkọ́ . . .