Nígbà Tí Ìwà Ọ̀làwọ́ Bá Pọ̀ Gidigidi
KÁ NÍ o láǹfààní láti fún ọba kan ní ẹ̀bùn, kí lo máa fún un? Tó bá jẹ́ pé òun ni alákòóso tó lọ́rọ̀ jù lọ, tó sì gbọ́n jù lọ ní gbogbo ayé ńkọ́? Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ẹ̀bùn kan tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn? Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn, ọbabìnrin Ṣébà ti ní láti ronú lórí irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn nígbà tó ń múra láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ irú alákòóso yẹn gan-an—ìyẹn Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì.
Bíbélì sọ fún wa pé ọgọ́fà tálẹ́ńtì wúrà wà lára àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ “àti ọ̀pọ̀ jaburata òróró básámù àti àwọn òkúta iyebíye.” Táa bá fojú bí nǹkan ṣe rí lóde òní wò ó, wúrà náà nìkan tó nǹkan bí ogójì mílíọ̀nù dọ́la. Òróró básámù, tó jẹ́ òróró olóòórùn dídùn gan-an, tí wọ́n sì tún ń fi ṣoògùn, ni wọ́n kà sí ohun tó níye lórí gan-an bíi wúrà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ bí òróró tí ọbabìnrin náà fún Sólómọ́nì ti pọ̀ tó, ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ kò láfiwé.—1 Àwọn Ọba 10:10.
Ó hàn gbangba pé ọlọ́rọ̀ ni ọbabìnrin Ṣébà, obìnrin náà sì lawọ́. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún rí èrè ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ gbà. Bíbélì sọ pé: “Sólómọ́nì Ọba . . . fún ọbabìnrin Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ̀ èyí tí òun béèrè, ní àfikún sí iye tí ó tó ohun tí ó gbé wá fún ọba.” (2 Kíróníkà 9:12) Lóòótọ́, ó ti lè jẹ́ àṣà àwọn ọba láti máa ṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀bùn; síbẹ̀, Bíbélì dìídì mẹ́nu kan “ẹ̀mí ọ̀làwọ́” Sólómọ́nì. (1 Àwọn Ọba 10:13) Sólómọ́nì alára kọ̀wé pé: “A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra, ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”—Òwe 11:25.
Láìsí àní-àní, ọbabìnrin Ṣébà náà fi ọ̀pọ̀ àkókó àti ìsapá rúbọ kó tó lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Sólómọ́nì. Ó hàn gbangba pé Ṣébà wà ní àgbègbè tí a mọ̀ sí Orílẹ̀-èdè Olómìnira Yemen lónìí; nítorí náà, ọbabìnrin náà àti àwọn ràkunmí tó ń wọ́ tẹ̀ lé e ti rìnrìn àjò tó lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bí Jésù ti sọ, “ó wá láti òpin ilẹ̀ ayé.” Kí ló dé ti ọbabìnrin Ṣébà fi ṣe wàhálà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí pàtàkì tó fi wá ni “láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì.”—Lúùkù 11:31.
Àwọn Ọba Kìíní 10:1, 2 sọ pé ọbabìnrin Ṣébà “wá láti fi àwọn ìbéèrè apinnilẹ́mìí dán [Sólómọ́nì] wò. . . . Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ ohun gbogbo tí ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ̀.” Èsì wo ni Sólómọ́nì fún un? “Sólómọ́nì, ẹ̀wẹ̀, ń bá a lọ láti sọ gbogbo ọ̀ràn obìnrin náà fún un. Kò sí ọ̀ràn kankan tí ó fara sin fún ọba, tí kò sọ fún obìnrin náà.”—1 Àwọn Ọba 10:3.
Ẹnu ya ọbabìnrin náà sí ohun tó gbọ́ àti ohun tó ri, ó sì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ fèsì pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ; aláyọ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ wọ̀nyí tí ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!” (1 Àwọn Ọba 10:4-8) Kò pe àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì ní aláyọ̀ nítorí ọrọ̀ tó yí wọn ká—bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ń fún wọn láyọ̀. Dípò ìyẹn, ó súre fún àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì nítorí pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti máa gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní gbogbo ìgbà. Ẹ wo àpẹẹrẹ àtàtà tí ọbabìnrin Ṣébà jẹ́ fún àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí, àwọn tí wọ́n ń gbádùn ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá náà fúnra rẹ̀ àti ti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi!
Síwájú sí i, ohun mìíràn tó yẹ ká tún gbé yẹ̀ wò ni ọ̀rọ̀ tí ọbabìnrin náà tún bá Sólómọ́nì sọ, ó ní: “Kí ìbùkún jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (1 Àwọn Ọba 10:9) Dájúdájú, ó rí ọwọ́ Jèhófà nínú ọgbọ́n àti aásìkí Sólómọ́nì. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà ṣèlérí rẹ̀ fún Ísírẹ́lì ṣáájú. Ó sọ pé: ‘Pípa àwọn ìlànà mi mọ́ jẹ́ ọgbọ́n ní ìhà ọ̀dọ̀ yín àti òye ní ìhà ọ̀dọ̀ yín, lójú àwọn ènìyàn tí yóò gbọ́ nípa gbogbo ìlànà wọ̀nyí, dájúdájú, wọn yóò sì wí pé, “Orílẹ̀-èdè ńlá yìí, láìsí iyèméjì, jẹ́ àwọn ènìyàn ọlọ́gbọ́n àti olóye.”’—Diutarónómì 4:5-7.
Títọ Ẹni Tí Ń Fúnni Lọ́gbọ́n Lọ
Lóde òní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ti fà mọ́ ètò àjọ Jèhófà nítorí wọ́n ti róye pé “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” jẹ́ “àwọn ènìyàn ọlọ́gbọ́n àti olóye”—kì í ṣe pé a dá wọn bẹ́ẹ̀ o, àmọ́, nítorí pé òfin Ọlọ́run tó pé àti àwọn ìlànà rẹ̀ ń tọ́ wọn sọ́nà. (Gálátíà 6:16) Iye àwọn tó ṣe batisí fi hàn pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun ló ń sọ fún àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí lọ́dọọdún pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Sekaráyà 8:23) Ẹ wo bó ṣe ṣe àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí ní kàyéfì tó, nígbà tí wọ́n rí àkànṣe àsè oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà tẹ́ síwájú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀! Wọn ò rí irú rẹ̀ rí nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀.—Aísáyà 25:6.
Títa Áfúnni-Ní-Ǹkan Lọ́nà Gíga Lọ́lá Lọ́rẹ
Nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ti rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, Ọba tó lọ́lá jù lọ, tó tún jẹ́ afúnni-ní-ǹkan lọ́nà gíga lọ́lá, àwọn èèyàn tó moore sábà máa ń ṣe kàyéfì nípa ohun táwọn lè fi ta á lọ́rẹ. Bíbélì fi hàn pé ẹ̀bùn dídára jù lọ tí a lè fún Jèhófà ni “ẹbọ ìyìn.” (Hébérù 13:15) Èé ṣe? Nítorí pé ẹbọ yìí ní í ṣe ní tààràtà pẹ̀lú gbígba ẹ̀mí là, tó jẹ́ olórí àníyàn Jèhófà ní àkókò òpin yìí. (Ìsíkíẹ́lì 18:23) Láfikún sí i, lílò tí ẹnì kan ń lo okun àti àkókò rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìsàn, àwọn tó sorí kọ́, àti àwọn mìíràn jẹ́ ẹbọ kan tó ṣètẹ́wọ́gbà.—1 Tẹsalóníkà 5:14; Hébérù 13:16; Jákọ́bù 1:27.
Fífowó ṣètọrẹ tún ń kó ipa pàtàkì. Ó mú kó ṣeé ṣe láti tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí a gbé ka Bíbélì, àti láti ní àwọn ibi tí àwọn Kristẹni ti lè máa pàdé pọ̀. (Hébérù 10:24, 25) Àwọn ọrẹ náà tún ń jẹ́ ká rí owó ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ogun jà lágbègbè wọn àti àwọn ti oríṣiríṣi ìjábá dé bá.
Láti ṣamọ̀nà wa lórí ọ̀ràn fífúnni ní nǹkan, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbe àwọn ìlànà àtàtà kan kalẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó kọ́ni pé àwọn Kristẹni kò ní láti fúnni ní iye pàtó kan bí kò ṣe pé kí wọ́n máa fúnni ní iyekíye tí wọ́n bá lágbára rẹ̀, tí wọ́n sì rí i pé ó bọ́gbọ́n mu fún wọn láti fi tọrẹ, kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ tinútinú, kí wọ́n sì ṣeé tọ̀yàyà-tọ̀yàyà. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Àwọn kan lè dáwó tó pọ̀; àwọn mìíràn tó dà bí opó aláìní lákòókò Jésù sì lè dá díẹ̀. (Lúùkù 21:2-4) Ǹjẹ́ kò yani lẹ́nu pé Jèhófà—Ẹni tó ni gbogbo àgbáyé—mọyì gbogbo ẹ̀bùn táa ń fi tọkàntọkàn fún un àti àwọn ìrúbọ tí a ń ṣe nítorí orúkọ rẹ̀?—Hébérù 6:10.
Kí àwọn ènìyàn Jèhófà lè máa fúnni tọ̀yàyàtọ̀yàyà la ṣe ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tí a nílò àti àwọn ọ̀nà táa lè gbà láti bójú tó àwọn àìní wọ̀nyẹn. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà sì ń sún àwọn ọkàn-àyà tó fẹ́ ṣe láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ìlànà yìí ni wọ́n lò láti kọ́ àgọ́ ìjọsìn ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ohun ni wọ́n sì tún lò fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì níkẹyìn. (Ẹ́kísódù 25:2; 35:5, 21, 29; 36:5-7; 39:32; 1 Kíróníkà 29:1-19) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ìlànà kan náà yìí ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti ní ohun tí wọ́n nílò láti mú ìhìn rere Ìjọba náà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo àti láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin tó wà ní Ísírẹ́lì ní àkókò kan tí ìyàn mú.—1 Kọ́ríńtì 16:2-4; 2 Kọ́ríńtì 8:4, 15; Kólósè 1:23.
Bákan náà, lónìí, Jèhófà ń bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì túbọ̀ máa bù kún wọn, nípa fífún wọn ní ohun tí wọ́n nílò láti parí iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni, iṣẹ́ tó ga jù lọ táa ti ṣe láyé yìí.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Kí Ni Àwọn Ohun Táa Nílò Ní Lọ́wọ́lọ́wọ́?
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wọn tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ti ní ọ̀pọ̀ ìbísí nínú iye àwọn akéde. Nítorí náà, Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé ka Bíbélì ti wá di ohun tí a nílò gan-an.
Bẹ́ẹ̀ náà làwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. A nílò nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri ayé ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Táa bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan lójúmọ́, yóò gba ohun tó lé ní ọdún mẹ́rìnlélógún kí ọwọ́ wa tó tẹ ohun tí a ń fẹ́! Ní báyìí, nǹkan bí ìjọ méje la ń dá sílẹ̀ lójúmọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì wà láwọn àgbègbè tí wọn kò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbègbè wọ̀nyí ni kò nílò àwọn ilé olówó ńlá. Àwọn ibì kan wà tó jẹ́ pé owó tí yóò parí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n nílò, táwọn ará àgbègbè náà yóò sì lè máa fojú gidi wò wá, kò jù ẹgbẹ̀rún mẹ́fà dọ́là lọ.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni kan rí jájẹ ju àwọn kan lọ, ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ ìmúdọ́gba, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ yín nísinsìnyí gan-an lè dí àìnító wọn, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn lè wá dí àìnító yín pẹ̀lú, kí ìmúdọ́gba lè ṣẹlẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 8:14) Lóde òní, “ìmúdọ́gba” kan náà la ń lò láti rí àwọn owó táa nílò láti pèsè àwọn Bíbélì, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Gbọ̀ngàn Ìjọba, owó ìrànwọ́ fún àwọn tí ìjábá bá, àti àwọn nǹkan mìíràn ní àwọn àpá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Ẹ wo ìbùkún ńlá tí irú fífúnni ní nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́—ìyẹn fún ẹni tó ń fúnni àti ẹni tó ń gbà á!—Ìṣe 20:35.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn lẹ́tà tí Society ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀làwọ́ èèyàn ń sọ, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn yìí ló fẹ́ láti ṣèrànwọ́ ṣùgbọ́n tí wọn ò mọ onírúurú ọ̀nà tí àwọn lè gbà ṣe ìtọrẹ. Láìsí àní-àní, àpótí tó wà pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí yóò ṣèrànwọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn.
Ní àkókò ìṣàkóso ológo Sólómọ́nì, “gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tí wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀ ló ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, alákòóso kan ṣoṣo péré ni Bíbélì dárúkọ rẹ̀—ìyẹn ni ọbabìnrin Ṣébà. (2 Kíróníkà 9:23) Ẹ wo ìrúbọ ńlá tó ṣe! Àmọ́, ó rí èrè jìgbìnnì gbà—èrè náà pọ̀ débi pé ní òpin ìbẹ̀wò rẹ̀, kò “lè mí mọ́, kàyéfì ńlá” sì ṣe é.—2 Kíróníkà 9:4, Today’s English Version.
Ní ọjọ́ iwájú, Jèhófà, tó jẹ́ Ọba tó lọ́lá jù lọ àti Afúnni-Ní-Ǹkan lọ́nà gíga jù lọ, yóò ṣe ohun tó pọ̀ gan-an ju èyí tí Sólómọ́nì ṣe fún àwọn tó ṣe ìrúbọ fún Un. Ohun tí yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé, àwọn wọ̀nyí kò ní “lè mí mọ́, kàyéfì ńlá” yóò sì ṣe wọ́n, nítorí kì í ṣe pé Jèhófà yóò dáàbò bò wọ́n la ọjọ́ ìdájọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù rẹ̀ já nìkan ni, àmọ́, lẹ́yìn náà yóò ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀, yóò sì tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’—Sáàmù 145:16.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn Ọ̀nà Tí Àwọn Kan Yàn Láti Ṣètọrẹ
ÌTỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ
Ọ̀PỌ̀ ya iye kan sọ́tọ̀, tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpòtí ọrẹ tí a kọ “Contributions for the Society’s Worldwide Work [Ìdáwó fún iṣẹ́ Society yíká ayé] sí lára—Mátíù 24:14.” Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí ẹ̀ka ọ́fí ìsì ti àdúgbò.
O tún lè fi ìtọrẹ owó tí o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fí ìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn tọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn pátápátá ní láti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
ÌṢÈTÒ ÌTỌRẸ TÓ NÍ IPÒ ÀFILÉLẸ̀
A lè fún Watch Tower Society ní owó lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí a óò dá owó náà padà fún olùtọrẹ náà, nígbà tó bá ti nílò rẹ̀. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tí a kọ sókè yìí.
ÌWÉWÈÉ ONÍNÚURE
Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ìtọrẹ tó ní ipò àfilélẹ̀, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Ìjọba kárí ayé. Lára wọn ni:
Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìlànà ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí ìwéwèé owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.
Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báńkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan sí ìkáwọ́ Watch Tower Society, tàbí kí a mú kó ṣeé san fún Society bí ẹni tó ni ín bá kú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báńkì àdúgbò bá béèrè fún.
Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pátápátá, tàbí lábẹ́ ìṣètò kan, níbi tí a óò ti máa bá a nìṣó láti san owó tí ń wọlé lórí èyí fún olùtọrẹ náà.
Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A le fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣeé tà, tọrẹ fún Watch Tower Society, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn pátápátá, tàbí nípa pípa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí olùtọrẹ náà ṣì lè máa lò nígbà ayé rẹ̀. Onítọ̀hún ní láti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Ìfisíkàáwọ́-Ẹni: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí kí a kọ orúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìwé àdéhùn fífi nǹkan sí ìkáwọ́ ẹni. Àwọn ohun ìní ìfisíkàáwọ́-ẹni tí ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí.
Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìwéwèé onínúure,” irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé díẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó ń ṣètọrẹ. Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tí ń fẹ́ láti ṣe Society láǹfààní nípa irú ọ̀nà ìfúnni tí a wéwèé kan, Society ti mú ìwé pẹlẹbẹ kan jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Planned Giving to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà láti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí Society ti rí gbà nípa ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní àfisíkàáwọ́-ẹni. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni tó wúlò fún ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò, àti owó orí nínú. À sì pète rẹ̀ láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí ń wéwèé láti fún Society ní ẹ̀bùn àkànṣe nísinsìnyí, tàbí tí ń fẹ́ fi ẹ̀bùn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kú, kí wọ́n lè yan ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní jù, tí ó sì gbéṣẹ́ jù láti ṣe é, ní gbígbé àyíká ipò ìdílé àti ti ara wọn yẹ̀ wò. A lè rí ìwé yìí gbà nípa bíbéèrè fún ẹ̀dà kan ní tààràtà láti Charitable Planning Office.
Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí wọ́n sì ti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka Charitable Planning Office, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún Society, kí wọ́n sì mú kí àǹfààní owó orí pọ̀ sí i nígbà kan náà, fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. A gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ìṣètò wọ̀nyí tó àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka Charitable Planning Office létí, kí a sì fún wọn ní ẹ̀dà àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá tan mọ́ ọn. Tóo bá nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí nínú àwọn ìṣètò ìwéwèé onínúure wọ̀nyí, kàn sí ẹ̀ka Charitable Planning Office, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tí a tò sísàlẹ̀ yìí tàbí kí wọ́n fi nọ́ńbà tẹlifóònù pè wọ́n, tàbí kí wọ́n kàn sí ọ́fí ìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn.
CHARITABLE PLANNING OFFICE
Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
100 Watchtower Drive, Patterson, New York 12563-9204
Tẹlifóònù: (914) 306-1000
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ọrẹ àtinúwá la fí ń ṣètìlẹyìn fún ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà