Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
OHUN kan tí àwọn ará Ìlà Oòrùn ayé ti gbà gbọ́ látayébáyé ni pé àwọ́n ní láti máa ṣèrántí Santa Claus táwọn èèyàn ń pè ní Baba Kérésìmesì. Ìyẹn ni ìgbàgbọ́ tí àwọn ará Korea ní nínú ẹnì kan tí wọ́n ń pè ní Chowangshin, a sì tún lè rí irú ìgbàgbọ́ yìí láàárín àwọn kan ní China àti Japan.
Wọ́n ka Chowangshin sí ọlọ́run tó ń bójú tó ilé ìdáná, ọlọ́run iná tó ní í ṣe pẹ̀lú bí àwọn ará Korea ṣe ń jọ́sìn iná láyé ọjọ́hun. (Láyé àtijọ́, tìṣọ́ratìṣọ́ra ni àwọn ará Korea fi ń gbé ẹyín iná, wọn ò ní jẹ́ kí iná rẹ̀ kú kí wọ́n tó gbé e dé ibi tí wọ́n fẹ́ gbé e lọ.) Ọlọ́run yìí ni wọ́n gbà pé ó máa ń ṣọ́ ìwà àwọn mẹ́ńbà ìdílé fún ọdún kan, lẹ́yìn náà ni yóò wá gba ojú ààrò àti ihò èéfín gòkè lọ sọ́run.
Gẹ́gẹ́ bí èrò wọ́n, Chowangshin yóò lọ ròyìn fún ọba ọ̀run ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù àfòṣùpákà ti December. Wọ́n sì retí pé yóò gba ihò èéfín àti ojú ààrò padà wá ní òpin ọdún, nígbà tí yóò mú èrè àti ìjìyà wá ní ìbámu pẹ̀lú ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé gbọ́dọ̀ tan àbẹ́là sílé ìdáná àti káàkiri inú ilé ní ọjọ́ tó bá ń padà bọ̀. Àwòrán ọlọ́run ilé ìdáná yìí tún fara jọ ti Baba Kérésì lọ́nà mìíràn—àwọ̀ pupa ni wọ́n fi ń ṣàpèjúwe ẹ̀! Ó máa ń jẹ́ àṣà ìyàwó ilé láti hun ìbọ̀sẹ̀ àwọn ará Korea, ìyẹn ni yóò fún ìyá ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ní ọjọ́ tí oòrùn yóò ràn kẹ́yìn, tí ìgbà òtútù yóò sì bẹ̀rẹ̀. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ó ń gbàdúrà pé kí ìyá ọkọ rẹ̀ pẹ́ láyé, nítorí pé lẹ́yìn ọjọ́ yìí, ilẹ̀ kì í tètè ṣú mọ́.
Ṣé o wá ríi pé àwọn ìbáradọ́gba kan wà láàárín kókó tí a sọ lókè yìí àti Kérésìmesì? Ìtàn àti àṣà kan náà ni wọ́n jọ ní: ìyẹn ni ihò èéfín, àbẹ́là, fífúnni lẹ́bùn, híhun ìbọ̀sẹ̀, baba arúgbó kan tó wọ aṣọ pupa, àti yíyan ọjọ́ kan pàtó fún ayẹyẹ náà. Síbẹ̀, irú àwọn ìbáradọ́gba wọ̀nyẹn nìkan kọ́ ló fà á tí àwọn ará Korea fi tẹ́wọ́ gba Kérésìmesì tó bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ nínú Chowangshin tiẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa rẹ́ tán ní Korea kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe Kérésìmesì níbẹ̀. Àní, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Korea ni ò tilẹ̀ mọ̀ pé irú ìgbàgbọ́ yẹn ti fìgbà kan wà rí.
Síbẹ̀síbẹ̀, èyí ṣàpèjúwe bí àṣà tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ tí ìgbà òtútù bẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọdún ṣe gba onírúurú ọ̀nà tàn ká gbogbo àgbáyé. Ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, ṣọ́ọ̀ṣì tó lókìkí jù lọ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù yí orúkọ Saturnalia padà, ìyẹn ni àjọyọ̀ tí àwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìbí ọlọ́run oòrùn ní Róòmù, wọ́n sì wá sọ èyí di ara Kérésìmesì. Ayẹyẹ Kérésìmesì wá di àṣà ìbílẹ̀ tó padà wá pẹ̀lú orúkọ tó yà tọ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Ipa Tí Fífúnni Lẹ́bùn Kó
Àṣà kan tí kò tíì pa rẹ́ ni àṣà ká máa fúnni lẹ́bùn. Ó ti pẹ́ tí àwọn ará Korea ti ń rí ayọ̀ púpọ̀ nínú fífúnni lẹ́bùn àti rírí ẹ̀bùn gbà. Èyí jẹ́ ìdí kan tí ayẹyẹ Kérésìmesì fi di ohun tí tẹrú tọmọ ń ṣe ní Korea.
Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, tí àwọn sójà Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n tẹ̀ dó sí Korea ń wá ọ̀nà láti sọ ara wọn dọ̀rẹ́ àwọn aráàlú, inú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ti máa ń pàdé láti fún àwọn èèyàn ní ẹ̀bùn àti àwọn owó ìrànwọ́. Ọjọ́ Kérésìmesì ni èyí máa ń ṣẹlẹ̀ jù lọ. Ojúmìító ló ń mú kí ọ̀pọ̀ ọmọdé lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ yẹn, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti máa ń kọ́kọ́ rí ẹ̀bùn ṣokoléètì gbà. Kò sì sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ lára wọn ni yóò máa wọ̀nà fún Kérésìmesì tí yóò tẹ̀ lé e.
Lójú irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀, sójà ará Amẹ́ríkà tó dé fìlà òtútù aláwọ̀ pupa ni Bàbá Kérésì. Òwe 19:6 sọ pé: “Gbogbo ènìyàn sì ni alábàákẹ́gbẹ́ ènìyàn tí ń bunni ní ẹ̀bùn.” Ní ti tòótọ́, ẹ̀rí fi hàn pé àṣà fífúnni lẹ́bùn yìí gbéṣẹ́ gan-an ni. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a lè parí èrò sí nínú ẹsẹ yẹn, irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ kò sọ pé kí àjọṣe wà lọ títí. Kódà ní Korea, ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà níbẹ̀ tó jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ṣọ́ọ̀ṣì ò ju adùn ṣokoléètì nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé. Àmọ́ ṣá o, wọn ò gbàgbé Kérésìmesì. Bí ọrọ̀ ajé ṣe ń bú rẹ́kẹ́ sí i ní Korea, tí iṣẹ́ òwò túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni fífúnni lẹ́bùn nígbà Kérésìmesì di ọ̀nà rírọrùn kan fún àwọn ènìyàn láti náwó. Àwọn oníṣòwò ń lo Kérésìmesì láti wá èrè púpọ̀ sí i.
Ìyẹn ti wá jẹ́ kóo túbọ̀ lóye bí Kérésìmesì ṣe di ohun tí wọ́n ń ṣe ní Ìlà Oòrùn ayé lónìí. Nítorí pé wọ́n ń fojú díwọ̀n bí àwọn ènìyàn yóò ṣe rajà tó ní àkókò Kérésìmesì, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn nǹkan tuntun jáde. Ètò nípa bí wọn ó ṣe polówó ọjà á ti bẹ̀rẹ̀ láti àárín ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Ìparí ọdún ni wọ́n sì máa ń tà jù lọ nítorí pé àwọn ènìyàn yóò ra àwọn ẹ̀bùn fún Kérésìmesì, wọ́n á tún ra káàdì, àti àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù orin. Họ́wù, ìpolówó ọjà lè máyé sú ọ̀dọ́ kan tó jókòó sílé, tí kò sì rí ẹ̀bùn kankan gbà ní Ọjọ́ Àìsùn Kérésìmesì!
Bí Ọjọ́ Kérésìmesì ṣe ń sún mọ́lé ni àwọn ilé ìtajà àtàwọn ibi ìpàtẹ ojú pópó ní Seoul yóò máa kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ra àwọn ẹ̀bùn, bákan náà ló sì rí láwọn ìlú ńlá yòókù ní Ìlà Oòrùn ayé. Súnkẹẹrẹ-fàkẹẹrẹ ọkọ̀ náà tún máa ń wà. Àwọn òtẹ́ẹ̀lì, àwọn àgbègbè káràkátà, àwọn ilé àrójẹ, àti àwọn ilé ìgbafàájì alaalẹ́ máa ń kún fún àwọn oníbàárà. Bẹ́ẹ̀ la ó máa gbúròó àwọn alárìíyá aláriwo, tí orin ó sì máa ròkè lálá. Ní Ọjọ́ Àìsùn Kérésìmesì, àwọn ọ̀mùtí lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa fẹsẹ̀ fọ́ ojú pópó tó kún fún ìdọ̀tí kọjá.
Bó ṣe rí nìyẹn o. Kérésìmesì kì í ṣe ọdún àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni mọ́ ní Ìlà Oòrùn ayé. Dájúdájú, bó ṣe rí ní Korea àti láwọn ibòmíràn, ọjà títà ti gbapò iwájú nínú ọdún Kirisẹ́ńdọ̀mù yìí. Ṣé ètò ìṣòwò nìkan ló yẹ ká dá lẹ́bi fún bí Kérésìmesì ti dà bó ṣe dà yìí, tí kò tiẹ̀ bá ẹ̀mí Kristi mu mọ́ rárá? Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ túbọ̀ wádìí nípa ohun tó fà á tí ọ̀ràn náà fi dà báyìí.
Orírun Kérésìmesì
Ẹranko ni ẹranko ń jẹ́, ẹ̀ báà mu láti inú igbó wá sínú àgò nílé. Àṣìṣe ńlá ni yóò sì jẹ́ láti gbà gbọ́ pé ó ti di ẹran ilé, nítorí pé a ti fi sínú àgò fún ìgbà pípẹ́, tó sì ti ń gbádùn ibẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kóo ti gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ẹranko tó ń ṣe àwọn òṣìṣẹ́ inú ọgbà ẹranko léṣe.
Láwọn ọ̀nà kan, bọ́ràn ṣe rí gẹ́lẹ́ nípa ayẹyẹ Kérésìmesì nìyẹn. Lákọ̀ọ́kọ́, “ẹranko” kan tó ń gbé ẹ̀yìn òde ìsìn Kristẹni ni. Lábẹ́ àkọlé kékeré náà, “Aláfijọ Saturnalia ti Róòmù” ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Christian Encyclopedia (ní Korea)a ti ṣàlàyé ohun kan nípa Kérésìmesì pé:
“Ayẹyẹ Saturnalia àti ti Brumalia tí àwọn kèfèrí ń ṣe ti di èyí tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ gan-an nínú àṣà ìbílẹ̀ táwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà tí ó fi jẹ́ pé ìsìn Kristẹni kò lè mú kí wọ́n pa á tì. Bí olú ọba nì, Kọnsitatáìnì ṣe ka ọjọ́ Sunday sí tó (ìyẹn ọjọ́ Phœbus àti Mithras títí kan Ọjọ́ Olúwa) . . . ti lè mú kí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kẹrin rí i pé ó tọ́ kí wọ́n mú kí ọjọ́ ìbí Ọmọ Ọlọ́run ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú ti oòrùn. Bí gbogbo ìlú ṣe máa ń rọ́ gìdì àti gbogbo pọ̀pọ̀ṣìnṣìn tó máa ń wà nígbà àjọyọ̀ àwọn kèfèrí jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ níbi gbogbo gan-an ni, débi pé inú àwọn Kristẹni dùn láti rí ohun kan gbe ara wọn lẹ́yìn kí wọ́n lè máa bá ayẹyẹ náà lọ pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀ nínú ìṣarasíhùwà tàbí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é.”
Ṣé o rò pé irú nǹkan báyẹn lè ṣẹlẹ̀ láìsí àtakò kankan? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan náà sọ pé: “Àwọn Kristẹni oníwàásù tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé àtàwọn tó wà Nítòsí Ìlà Oòrùn ayé tako ọ̀nà tó buni kù tí wọ́n gbà ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Kristi, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni tó wà ní Mesopotámíà fẹ̀sùn ìbọ̀rìṣà àti jíjọ́sìn oòrùn kan àwọn arákùnrin wọn tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé, ìyẹn ni pé wọ́n fẹ̀sùn kan bí àwọn tó jẹ́ Kristẹni ṣe sọ àjọyọ̀ àwọn kèfèrí yìí di tiwọn.” Dájúdájú, àtìbẹ̀rẹ̀ ni nǹkan ti wọ́ wá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ pé: “Síbẹ̀, kíá ni àjọyọ̀ náà di èyí tí àwọn ènìyàn tẹ́wọ́ gbà tó sì wá jẹ́ pé ohun ló fìdí múlẹ̀ jù lọ níkẹyìn débi pé ìyípadà tegbòtigaga tí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ọ̀rúndún kẹrìndínlógún pariwo rẹ̀ pàápàá kò lè dá a dúró.”
Lóòótọ́, àjọyọ̀ tó jẹ́ ti ọlọ́run oòrùn, tí kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìsìn Kristẹni tòótọ́ di èyí táa mú wọnú ṣọ́ọ̀ṣì tó lókìkí jù lọ. Ó gba orúkọ tuntun lóòótọ́—àmọ́, àmì ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kò yí padà. Ó ti ṣèrànwọ́ láti mú àṣà kèfèrí wọnú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni aláfẹnujẹ́, ó sì ti sọ ipò tẹ̀mí àwọn ènìyàn dìbàjẹ́. Ìtàn fi hàn pé bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń gbèrú sí i ni ẹ̀mí “nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá rẹ” tí wọ́n ní níbẹ̀rẹ̀ di èyí tó ń pòórá, tí ìwà ìbàjẹ́ àti ogun sì dípò rẹ̀.
Nígbà tó yá, ó wá hàn kedere pé bí wọ́n tilẹ̀ fi orúkọ náà, Kérésìmesì, bò ó lójú, síbẹ̀ àwọn àríyá aláriwo, ọtí àmupara, pọ̀pọ̀ṣìnṣìn, ijó jíjó, fífúnni lẹ́bùn, àti fífi igi ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́, fi hàn pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ló ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ti lo Kérésìmesì ní oríṣiríṣi ọ̀nà—nítorí ète àtipawó—kí ọjà wọn lè tà dáadáa. Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń kókìkí rẹ̀; àwọn ènìyàn sì fi ń dánú ara wọn dùn. Ní agbègbè ìṣòwò ìlú Seoul, ilé ìtajà kan tó jẹ́ pé kìkì àwọ̀tẹ́lẹ̀ ni wọ́n máa ń tà gbé orúkọ ilé iṣẹ́ wọn lọ sórí tẹlifíṣọ̀n nípa gbígbé igi Kérésìmesì tí wọ́n fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ sójú fèrèsé wọn. Àwọn ènìyàn mọ̀ pé àkókò Kérésìmesì làwọn wà, àmọ́, kò sí ohun tó jọ àmì Kíkí Kristi Káàbọ̀.
Fífi Ojú Ìwé Mímọ́ Wo Kérésìmesì
Kí la lè rí kọ́ nínú irú ìtàn ìpilẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ àti àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀? Bí a bá ṣi bọ́tìnnì bíláòsì tàbí ti ṣẹ́ẹ̀tì kan dè láti ìbẹ̀rẹ̀, ọ̀nà kan ṣoṣo táa lè gbà ṣàtúnṣe rẹ̀ ni pé ká tún un dè láti ìbẹ̀rẹ̀. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Pẹ̀lú gbogbo òtítọ́ yìí, àwọn kan ṣì ń sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí níbi tí wọ́n ti ń jọ́sìn oòrùn ni Kérésìmesì ti ta gbòǹgbò, ẹ̀sìn Kristẹni ṣáà ti tẹ́wọ́ gbà á. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n rò pé ọdún náà ti di èyí tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gbà pátápátá gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìbí Kristi, wọ́n sì ti wá fún un ní ìtumọ̀ tuntun.
A lè kọ́ ẹ̀kọ́ tó níye lórí látinú ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Júúdà ìgbàanì. Ní ọdún 612 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ará Jùdíà mú jíjọ́sìn oòrùn tó jẹ́ ti àwọn kèfèrí wọnú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Ǹjẹ́ a tẹ́wọ́ gba irú ìjọsìn kèfèrí bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n ń ṣe é ní ibi tí a yà sọ́tọ̀ pátápátá fún ìjọsìn tó mọ́ tónítóní fún Jèhófà Ọlọ́run? Ìsíkíẹ́lì, tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì, kọ̀wé nípa ìjọsìn oòrùn tí wọ́n ṣe nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé: “Wò ó! ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà, láàárín gọ̀bì àti pẹpẹ, ni nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wà . . . wọ́n sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń tẹrí ba síhà ìlà-oòrùn, fún oòrùn. Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: ‘Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí èyí? Ó ha jẹ́ ohun kan tí ó fúyẹ́ lójú ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí wọ́n ti ṣe níhìn-ín, tí wọ́n fi fi ìwà ipá kún ilẹ̀ yìí tí wọ́n sì tún mú mi bínú, kíyè sí i, tí wọ́n na ọ̀mùnú sí imú mi?’”—Ìsíkíẹ́lì 8:16, 17.
Ó dájú pé, dípò kí ó di ohun ìtẹ́wọ́gbà, ńṣe ni ìjọsìn kèfèrí yẹn fi odindi tẹ́ńpìlì náà sínú ewu. Irú àṣà bẹ́ẹ̀ gba Júdà kan, ó sì fi kún ìwà ipá tó gbalẹ̀ àti ìwà tó dómùkẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yẹn. Ó bá ti Kirisẹ́ńdọ̀mù náà dọ́gba, níbi ti àṣà tó bẹ̀rẹ̀ láti inú sísin ọlọ́run oòrùn ti Saturnalia ti wá di èyí tó gbapò iwájú nínú Kérésìmesì. Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran yẹn gbà ni Jerúsálẹ́mù gba ìdájọ́ Ọlọ́run—àwọn ará Bábílónì pa á run.—2 Kíróníkà 36:15-20.
Àpèjúwe tó wà nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, ìyẹn àpèjúwe tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Korea yẹn ṣe nípa Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé, ti lè pa ọ́ lẹ́rìn-ín. Àmọ́, òtítọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé nígbà tó jẹ́ àtọ̀dọ̀ ẹnì kan tí kò ní ìmọ̀ pípéye nípa Jésù ló ti wá, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà á sí ohun kan tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ó lè mú kí àwọn èèyàn tó ń ṣayẹyẹ Kérésìmesì ronú jinlẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé Kérésìmesì kò fi bí Kristi ṣe jẹ́ hàn rárá. Ká sọ tòótọ́, ó fi ipò tó wà báyìí pa mọ́ pátápátá. Jésù kì í ṣe ọmọ ọwọ́ tó wà ní ibùjẹ ẹran mọ́.
Léraléra ni Bíbélì tẹnu mọ́ kókó náà pé Jésù ti di Mèsáyà báyìí, òun ni Ọba tó ju ọba lọ, ti Ìjọba Ọlọ́run ní òkè ọ̀run. (Ìṣípayá 11:15) Ó ti ṣe tán láti fòpin sí ipò òṣì àti ìbànújẹ́ tí àwọn èèyàn kan ò tí ì gbàgbé lákòókò Kérésìmesì, tí wọ́n fi ń ṣètọrẹ àánú.
Ká sọjú abẹ níkòó, Kérésìmesì ko ṣàǹfààní kankan fún àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ẹ̀sìn táa lè pè ní ti Kristẹni wà tàbí fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, títí kan àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti darí àfiyèsí kúrò lórí ìhìn iṣẹ́ Kristẹni tòótọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti òpin ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí. (Mátíù 24:14) A rọ̀ ọ́ láti wádìí lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa bí òpin yẹn yóò ṣe dé. O sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn nípa ìbùkún ayérayé tí yóò tẹ̀ lé e lórí ilẹ̀ ayé, lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ọlọ́run àti Ọba tí ń jọba náà, Jésù Kristi.—Ìṣípayá 21:3, 4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A gbé e karí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Schaff-Herzog Encyclopedia of Religious Knowledge.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Kérésìmesì tí ṣèrànwọ́ láti mú àṣà kèfèrí wọnú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni aláfẹnujẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ojúmìító àti pé kí wọ́n lè rí ẹ̀bùn ṣokoléètì gbà ló ń mú kí ọ̀pọ̀ ọmọdé lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Wọn óò wá máa wọ̀nà fún Kérésìmesì tí yóò tẹ̀ lé e
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọjọ́ Àìsùn Kérésìmesì ní àgbègbè ìṣòwò ní ìlú Seoul, Korea
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kristi kì í ṣe ọmọ ọwọ́ mọ́, bí kò ṣe Ọba tó ju ọba lọ, ti Ìjọba Ọlọ́run