“Àwọn Àkókò Ìmúpadàbọ̀sípò” Ti Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Kété ṣáájú kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, àwọn kan lára àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bi í pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” Ìdáhùn Jésù fi hàn pé àkókò yóò kọjá kí Ìjọba náà tó dé. Iṣẹ́ ńlá kan wà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ṣe láàárín àkókò yẹn. Wọn yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí Jésù “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:6-8.
IṢẸ́ yẹn kì í ṣe iṣẹ́ tí wọ́n á lè parí láàárín ọjọ́ díẹ̀, ọ̀sẹ̀ díẹ̀, tàbí oṣù díẹ̀. Àmọ́, ojú ẹsẹ̀ làwọn ọmọlẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí wàásù. Bíṣẹ́ ò kúkú pẹ́ni, a kì í pẹ́ṣẹ́. Ṣùgbọ́n wọn ò mú ọkàn kúrò lórí ọ̀ràn ìmúpadàbọ̀sípò. Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó ń bá ogunlọ́gọ̀ ńlá kan tó kóra jọ ní Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, kí ó sì lè rán Kristi tí a yàn sípò jáde fún yín, Jésù, ẹni tí ọ̀run, ní tòótọ́, gbọ́dọ̀ gbà sínú ara rẹ̀ títí di àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé.”—Ìṣe 3:19-21.
“Àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò” yìí ni yóò mú “àsìkò títunilára” wọlé dé látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ìmúpadàbọ̀sípò táa sọ tẹ́lẹ̀ yóò dé ní ipele méjì. Ipele àkọ́kọ́ yóò jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò títunilára nípa tẹ̀mí, èyí tó ti bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí. Ipele kejì yóò tẹ̀ lé e nígbà tí párádísè gidi bá dé sórí ilẹ̀ ayé.
Àkókò Ìmúpadàbọ̀sípò Bẹ̀rẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ti sọ fún ogunlọ́gọ̀ yẹn ní Jerúsálẹ́mù, ọ̀run ‘gba Jésù sínú ara rẹ̀.’ Èyí rí bẹ́ẹ̀ títí di ọdún 1914, nígbà tí Jésù gorí àlééfà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run yàn. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti sọ tẹ́lẹ̀, ìgbà yẹn ni Jèhófà yóò “rán” Ọmọ rẹ̀ “jáde,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti pé Ó jẹ́ kí Jésù kó ipa tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpómúléró nínú àwọn ète Ọlọ́run. Bíbélì ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lédè àpèjúwe, pé: “Ó [ètò àjọ Ọlọ́run lókè ọ̀run] sì bí ọmọkùnrin kan, akọ, [ìyẹn, Ìjọba Ọlọ́run ní ìkáwọ́ Jésù Kristi] ẹni tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè.”—Ìṣípayá 12:5.
Àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè kò fẹ́ tẹrí ba fún ìṣàkóso Kristi. Kódà, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ìkanra mọ́ àwọn adúróṣinṣin ọmọ abẹ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn, àwọn táa mọ̀ sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní. Bíi ti àwọn àpọ́sítélì tó ṣíwájú wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí ti káràmáásìkí “iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:17) Ńṣe ni àtakò bẹ̀rẹ̀ sí rú bí ègbìnrìn ọ̀tẹ̀ sí iṣẹ́ táwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn wọ̀nyí ń ṣe ní orílẹ̀-èdè kan tẹ̀ lé òmíràn. Lọ́dún 1918, wọ́n wọ́ àwọn òpómúléró mẹ́ńbà orílé iṣẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn, New York, lọ sílé ẹjọ́, wọ́n fi àwọn awúrúju ẹ̀sùn kàn wọ́n, wọ́n sì dá ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ fún wọn láìbófinmu. Fún sáà kan, ńṣe ló dà bíi pé iṣẹ́ ìjẹ́rìí ti òde òní “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé” yóò forí ṣánpọ́n.—Ìṣípayá 11:7-10.
Àmọ́ o, ní 1919, wọ́n tú àwọn mẹ́ńbà orílé iṣẹ́ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀, ilé ẹjọ́ sì sọ lẹ́yìn náà pé wọn ò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn wọ́n. Kíá ni wọ́n tún padà sẹ́nu iṣẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò tẹ̀mí náà. Látìgbà yẹn làwọn èèyàn Jèhófà ti ń gbádùn aásìkí tẹ̀mí tí kò sírú rẹ̀ rí.
Wọ́n dáwọ́ lé iṣẹ́ ìpolongo ńlá kan láti kọ́ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láti máa tẹ̀ lé gbogbo ohun tí Kristi ti pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe. (Mátíù 28:20) Ẹ wo bó ti ń tuni lára tó láti rí i tí àwọn kan tí wọ́n ń hùwà bí ẹranko tẹ́lẹ̀ wá ń yí ìwà wọn padà! Wọ́n ti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ń fa àwọn ìṣarasíhùwà bí “ìbínú,” “ọ̀rọ̀ èébú,” àti “ọ̀rọ̀ rírùn,” wọ́n sì ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, “èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán [Ọlọ́run] tí ó dá a.” Lọ́nà tẹ̀mí, ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà tilẹ̀ ti ń ní ìmúṣẹ báyìí, ó sọ pé: “Ìkookò [ìyẹn, èèyàn oníwà bí ìkookò tẹ́lẹ̀] yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn [ìyẹn, èèyàn oníwà pẹ̀lẹ́], àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀.”—Kólósè 3:8-10; Aísáyà 11:6, 9.
Ìmúpadàbọ̀sípò Síwájú sí I Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Láfikún sí ìmúpadàbọ̀sípò tó ti dé báyìí nípasẹ̀ párádísè tẹ̀mí, àkókò náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán tí pílánẹ́ẹ̀tì wa yóò di párádísè tó ṣeé fojú rí. Apá kékeré kan lórí ilẹ̀ ayé ló jẹ́ párádísè nígbà tí Jèhófà fi àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, sínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 1:29-31) Ìdí nìyẹn táa fi ń sọ̀rọ̀ nípa Párádísè táa mú padà bọ̀ sípò. Àmọ́ kí ìyẹn tó wáyé, ẹ̀sìn èké tí ń tàbùkù sí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ lọ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn olóṣèlú ayé yìí ló máa rí sí ìyẹn. (Ìṣípayá 17:15-18) Lẹ́yìn náà ni ìparun yóò wá dé bá ètò ìṣèlú àti ti ìṣòwò. Paríparí rẹ̀, àwọn tó gbẹ̀yìn lára ọ̀tá Ọlọ́run—èyíinì ni Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀—yóò wọ àtìmọ́lé fún ẹgbẹ̀rún ọdún—èyí ni iye ọdún tí iṣẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò náà yóò gbà. Láàárín àkókò yẹn, “aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.” (Aísáyà 35:1) Gbogbo ilẹ̀ ayé yóò wá bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu pátápátá. (Aísáyà 14:7) Kódà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tó ti kú yóò padà wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo wọn yóò wá gbádùn àwọn àǹfààní àmúdọ̀tun tí yóò jẹ yọ látinú ẹbọ ìràpadà náà. (Ìṣípayá 20:12-15; 22:1, 2) Kò ní sí afọ́jú, adití, tàbí arọ lórí ilẹ̀ ayé mọ́. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Láìpẹ́ lẹ́yìn òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, a óò tú Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sílẹ̀ fún sáà kúkúrú, wọ́n yóò sì rí ibi tí ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé ti ní ìmúṣẹ dé. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ńṣe ni a ó pa wọ́n run títí láé.—Ìṣípayá 20:1-3.
Nígbà tí ayé bá dé òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìmúpadàbọ̀sípò náà, “gbogbo ohun eléèémí” ni yóò máa yin Jèhófà, wọn yóò sì máa yìn ín títí ayé. (Sáàmù 150:6) Ṣé wàá wà lára wọn? O ṣeé ṣe.