Bíbélì Kíkà—Ó Lérè, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
“Kí o . . . máa . . . kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru.”—JÓṢÚÀ 1:8.
1. Kí ni àwọn àǹfààní bíi mélòó kan tó wà nínú ìwé kíkà, àgàgà nínú Bíbélì kíkà?
KÍKA àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tó ní láárí máa ń ṣeni láǹfààní. Òṣèlú onímọ̀ ọgbọ́n orí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Montesquieu (Charles-Louis de Secondat) kọ̀wé pé: “Ní tèmi, ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni olórí ohun tí mo fi ń kojú hílàhílo inú ìgbésí ayé. Kò tíì sí wàhálà tó dé bá mi rí tí kíkàwé fún wákàtí kan kò tíì yanjú rẹ̀.” Dé ìwọ̀n tó ga jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ọ̀ràn Bíbélì kíka ṣe rí nìyẹn. Onísáàmù tí a mí sí náà sọ pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀.”—Sáàmù 19:7, 8.
2. Èé ṣe tí Jèhófà fi pa Bíbélì mọ́ láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, kí ló sì retí pé kí àwọn ènìyàn òun ṣe pẹ̀lú rẹ̀?
2 Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì, ti pa á mọ́ la gbogbo ọ̀rúndún lílé koko já, ìyẹn àwọn ọ̀rúndún tó fi kojú àtakò látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onísìn àtàwọn ènìyàn ayé lápapọ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” ó ti rí sí jíjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ òun wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn. (1 Tímótì 2:4) A fojú bù ú pé ìpín ọgọ́rin nínú àwọn ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé la lè fi ọgọ́rùn-ún èdè bá sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, odindi Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ọgbọ̀n dín nírínwó [370] èdè, àwọn apá kan Ìwé Mímọ́ sì tún wà táa lè kà ní ọgọ́ta lé lẹ́gbẹ̀sán [1,860] èdè àti àwọn èdè àdúgbò. Jèhófà fẹ́ kí àwọn ènìyàn òun ka Ọ̀rọ̀ òun. Ó ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fiyè sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àní, tí wọ́n ń kà á lójoojúmọ́.—Sáàmù 1:1, 2.
Bíbélì Kíkà Pọndandan fún Àwọn Alábòójútó
3, 4. Kí ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì, kí sì ni àwọn ìdí tí ohun tó béèrè yìí fi kan àwọn Kristẹni alàgbà lóde òní?
3 Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yóò ní ẹ̀dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ó bá mú ìjókòó rẹ̀ lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀ láti inú èyí tí ó wà ní àbójútó àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì. Kí ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí àti ìlànà wọ̀nyí mọ́ nípa títẹ̀lé wọn; kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa gbé ara rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti kí ó má bàa yà kúrò lórí àṣẹ náà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.”—Diutarónómì 17:18-20.
4 Kíyè sí àwọn ìdí tí Jèhófà fi sọ pé kí gbogbo àwọn tí yóò jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú máa ka ìwé òfin àtọ̀runwá náà lójoojúmọ́: (1) “kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí àti ìlànà wọ̀nyí mọ́ nípa títẹ̀lé wọn”; (2) “kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa gbé ara rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin rẹ̀”; (3) “kí ó má bàa yà kúrò lórí àṣẹ náà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.” Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwọn Kristẹni alábòójútó lóde òní bẹ̀rù Jèhófà, kí wọ́n ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀, kí wọ́n yẹra fún gbígbé ara wọn ga lórí àwọn arákùnrin wọn, kí wọ́n má sì yà kúrò nínú àwọn àṣẹ Jèhófà? Dájúdájú, kò sóhun tí kò fi yẹ kí Bíbélì kíkà ṣe pàtàkì fún wọ́n bó ṣe ṣe pàtàkì fún àwọn ọba Ísírẹ́lì.
5. Kí ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso kọ sí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka nípa Bíbélì kíka lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èé sì ti ṣe tó fi dára kí àwọn Kristẹni alàgbà tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀?
5 Ọwọ́ àwọn Kristẹni alàgbà òde òní máa ń dí gan-an, èyí sì mú kí Bíbélì kíkà jẹ́ ìṣòro tó gbàfiyèsí. Fún àpẹẹrẹ, gbogbo mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka jákèjádò ayé ni ọwọ́ wọn máa ń dí fún iṣẹ́ púpọ̀ gan-an. Síbẹ̀, lẹ́tà kan tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso kọ sí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lẹ́nu àìpẹ́ yìí tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ àti ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Lẹ́tà náà là á mọ́lẹ̀ pé, èyí yóò jẹ́ kí ìfẹ́ táa ní fún Jèhófà àti èyí tí a ní fún òtítọ́ máa pọ̀ sí i, yóò sì “ran wá lọ́wọ́ láti pa ìgbàgbọ́ wa, ayọ̀ wa, àti ìfaradà wa mọ́ títí dé òpin ológo náà.” Gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Kíka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “hùwà ọgbọ́n.” (Jóṣúà 1:7, 8) Tìtorí tiwọn gan-an ni Bíbélì kíkà fi “ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, àti fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, Bíbélì Mímọ́.
Ohun Kan Tó Pọndandan fún Tọmọdé Tàgbà
6. Èé ṣe tí Jóṣúà fi ka gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú òfin Jèhófà sókè níwájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti àwọn àtìpó tó péjọ?
6 Ní ayé ìgbàanì, kò sí àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ lárọ̀ọ́wọ́tó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan lè máa kà, nítorí náà iwájú odindi àwùjọ lápapọ̀ ni wọ́n ti máa ń ka Bíbélì. Lẹ́yìn tí Jèhófà fún Jóṣúà ní ìṣẹ́gun lórí ìlú Áì, ó kó àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ síwájú Òkè Ébálì àti Òkè Gérísímù. Lẹ́yìn ìyẹn, àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ òfin, ìbùkún àti ìfiré náà sókè, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé òfin náà. Kò sì sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mósè pa láṣẹ tí Jóṣúà kò kà sókè ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn àtìpó tí ń rìn ní àárín wọn.” (Jóṣúà 8:34, 35) Àtọmọdé àtàgbà, àtọmọ onílẹ̀ àti àtìpó ló gbọ́dọ̀ fín àwọn ìwà kan sínú ọkàn-àyà àti èrò inú wọn, ìwọ̀nyí ni àwọn ìwà tó lè mú ìbùkún Jèhófà wá àti àwọn ìwà tó lè múni pàdánù ojú rere rẹ̀. Ó dájú pé Bíbélì kíkà déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí.
7, 8. (a) Àwọn wo ló dà bí “àwọn àtìpó” lóde òní, èé sì tí ṣe tó fi yẹ kí wọ́n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni “àwọn ọmọ kéékèèké” tó wà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà fi lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
7 Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló dà bí “àwọn àtìpó” wọ̀nyẹn nípa tẹ̀mí. Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ìwà ayé ni wọ́n ń hù, àmọ́ wọ́n ti yí ìgbésí ayé wọn padà báyìí. (Éfésù 4:22-24; Kólósè 3:7, 8) Gbogbo ìgbà ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa rán ara wọn létí ìlànà Jèhófà lórí ohun rere àti ohun búburú. (Ámósì 5:14, 15) Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe èyí.—Hébérù 4:12; Jákọ́bù 1:25.
8 Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn “ọmọ kéékèèké” tún wà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà tí àwọn òbí wọn ti fi ìlànà Jèhófà kọ́, àmọ́ tí wọ́n tún ní láti mú un dá ara wọn lójú pé ìfẹ́ Jèhófà ni ó tọ̀nà. (Róòmù 12:1, 2) Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A pa á láṣẹ fún àwọn àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ yóò ka òfin yìí ní iwájú gbogbo Ísírẹ́lì ní etí-ìgbọ́ wọn. Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àtìpó tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ, kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe. Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ sì fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín.” (Diutarónómì 31:11-13) Abẹ́ òfin náà ni Jésù wà tó ti fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn sí lílóye àwọn òfin Baba rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá péré. (Lúùkù 2:41-49) Lẹ́yìn náà, ó wá di àṣà rẹ̀ pé kó máa fetí sílẹ̀, kó sì máa kópa nínú kíká Ìwé Mímọ́ nínú sínágọ́gù. (Lúùkù 4:16; Ìṣe 15:21) Ì bá dára tí àwọn ọmọ kéékèèké òde òní bá lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ àti nípa lílọ sí àwọn ìpàdé déédéé, níbi táa ti ń ka Bíbélì táa sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.
Bíbélì Kíkà—Ohun Àkọ́múṣe
9. (a) Èé ṣe tó fi yẹ ká máa ṣàṣàyàn ohun táa ń kà? (b) Kí ni ẹni tó kọ́kọ́ jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn yìí sọ nípa àwọn ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
9 Sólómọ́nì Ọba ọlọ́gbọ́n nì kọ̀wé pé: “Gba ìkìlọ̀: Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.” (Oníwàásù 12:12) A tiẹ̀ lè fi kún un pé kì í ṣe pé kíka ọ̀pọ̀ ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ jáde lónìí wulẹ̀ ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀ nìkan ni, àmọ́, ká kúkú sojú abẹ níkòó, ó jẹ́ ewu fún èrò inú wa. Nítorí náà ó ṣe pàtàkì láti máa ṣàṣàyàn. Ní àfikún sí kíka àwọn ìtẹ̀jáde tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a tún ní láti máa ka Bíbélì fúnra rẹ̀. Ẹni tó kọ́kọ́ jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn yìí kọ̀wé sí àwọn òǹkàwé rẹ̀ pé: “Máṣe gbàgbé láé pé Bíbélì ni ọ̀pá ìdíwọ̀n wa àti pé bí ó ti wù kí ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run fún wa pọ̀ tó ‘ìrànlọ́wọ́’ ni wọ́n, wọn kò dípò Bíbélì.”a Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní pa àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé ka Bíbélì tì, a ní láti máa ka Bíbélì fúnra rẹ̀.
10. Báwo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì Bíbélì kíkà?
10 Nítorí pé ohun tí wọ́n ń fẹ́ yìí ń jẹ wọ́n lọ́kàn, fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ń ṣètò fún Bíbélì kíkà gẹ́gẹ́ bí apá kan lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. (Mátíù 24:45) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà táa ní lọ́wọ́ báyìí yóò mú kí a ka Bíbélì tán ní àárín nǹkan bí ọdún méje. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ṣàǹfààní fún gbogbo wa, àmọ́ ní pàtàkì jù lọ fún àwọn tó jẹ́ ẹni tuntun tí wọ́n ò ka Bíbélì tán rí. Àwọn tí wọ́n wà ní Watchtower Bible School of Gilead tó wà fún àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ títí kan àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì gbọ́dọ̀ ka odindi Bíbélì tán láàárín ọdún kan. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ èyíkéyìí tó wù kí o tẹ̀ lé, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí gẹ́gẹ́ bí ìdílé, kíkẹ́sẹ járí sinmi lórí fífi Bíbélì kíkà sí ipò kìíní.
Kí Ni Ọ̀nà Ìgbàkàwé Rẹ Fi Hàn?
11. Báwo la ṣe lè máa fi àwọn àsọjáde Jèhófà bọ́ ara wa lójoojúmọ́, èé sì ti ṣe?
11 Tó bá ṣòro fún ọ láti tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà rẹ, ó lè jẹ́ pé o ní láti bi ara rẹ pé: ‘Ipa wo ni bí mo ṣe ń kàwé tàbí bí mo ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n lè ní lórí bí mo ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Jèhófà? Rántí ohun tí Mósè kọ—tí Jésù náà tún sọ—pé “ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4; Diutarónómì 8:3) Gan-an gẹ́gẹ́ báa ṣe ní láti jẹun lójoojúmọ́ láti gbé ẹ̀mí wa ró, bẹ́ẹ̀ náà la tún ní láti máa gba èrò Jèhófà sọ́kàn lójoojúmọ́ kí a lè gbé ipò tẹ̀mí wa ró. A lè máa gba èrò Ọlọ́run sínú lójoojúmọ́ nípa kíka Ìwé Mímọ́.
12, 13. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe ṣàpèjúwe irú ìyánhànhàn tó yẹ ká ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo àpèjúwe wàrà lọ́nà tó yàtọ̀ pátápátá sí ti Pétérù?
12 Bí a bá mọyì Bíbélì, “kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” a ó sún mọ́ ọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ọmọ jòjòló ṣe ń sún mọ́ wàrà ìyá rẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Àpọ́sítélì Pétérù ṣe ìfiwéra yẹn nígbà tó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà, kìkì bí ẹ bá ti tọ́ ọ wò pé onínúrere ni Olúwa.” (1 Pétérù 2:2, 3) Bí ìrírí tí àwa fúnra wa ti ní bá ti mú kí a tọ́ ọ wò pé “onínúrere ni Olúwa,” ọkàn wa yóò máa fà sí Bíbélì kíkà.
13 A gbọ́dọ̀ kíyè sí i pé bí Pétérù ṣe fi wàrà ṣàpèjúwe nínú àyọkà yìí yàtọ̀ pátápátá sí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lò ó. Fún ọmọ tuntun jòjòló, wàrà ti tó fún un láti ní gbogbo ohun amáralókun tó nílò. Àpèjúwe Pétérù fi hàn pé gbogbo ohun táa nílò láti “dàgbà dé ìgbàlà” ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní ọ̀wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Pọ́ọ̀lù lo wàrà láti ṣàpèjúwe bí àwọn kan tó pe ara wọn ní àgbà nípa tẹ̀mí kò ṣe máa ń jẹun dáadáa. Nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù, ó kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ ní ojú ìwòye ibi tí àkókò dé yìí, ẹ tún nílò kí ẹnì kan máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run; ẹ sì ti di irúfẹ́ àwọn tí ó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń mu wàrà jẹ́ aláìdojúlùmọ̀ ọ̀rọ̀ òdodo, nítorí tí ó jẹ́ ìkókó. Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Hébérù 5:12-14) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni fífiyèsí Bíbélì kíkà lè ṣe láti mú kí agbára ìwòye wa dàgbà àti láti mú kí ọ̀fun wa máa dá tòó-tòó fún àwọn nǹkan tẹ̀mí.
Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì
14, 15. (a) Àǹfààní wo ni Òǹṣèwé Bíbélì nawọ́ rẹ̀ sí wa? (b) Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ọgbọ́n àtọ̀runwá? (Fúnni lápẹẹrẹ.)
14 Bíbélì kíkà lọ́nà tó lérè máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbígba àdúrà, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú wíwulẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni àdúrà jẹ́. Ṣe ló dà bíi pé kóo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé kan tó láwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tó le koko bí ojú ẹja nínú, kóo wá pé ẹni tó ṣe ìwé náà láti wá ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o lè lóye ohun tóo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kà. Ẹ ò ri pé àǹfààní ńláǹlà nìyẹn máa jẹ́! Jèhófà, tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì, nawọ́ àǹfààní yẹn sí ọ. Ọ̀kan lára mẹ́ńbà ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìíní kọ̀wé sí àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un. Ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá.” (Jákọ́bù 1:5, 6) Gbogbo ìgbà ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tòde òní máa ń gbà wá níyànjú láti máa ka Bíbélì tàdúràtàdúrà.
15 Ọgbọ́n jẹ́ fífi ìmọ̀ sílò lọ́nà tó gbéṣẹ́. Nítorí náà, kí o tó ṣí Bíbélì rẹ, béèrè pé kí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn kókó tó wà nínú ibi tóo fẹ́ kà yẹn tó yẹ kóo mú lò nínú ìgbésí ayé rẹ. So àwọn ohun tuntun tóo kọ́ pọ̀ mọ́ àwọn tóo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Mú wọn bá “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tóo ti mọ̀ mu. (2 Tímótì 1:13) Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí ìgbésí ayé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé ìgbàanì, kí o sì bi ara rẹ pé kí ni o ò bá ṣe ká ní ìwọ lo wà nínú irú ipò kan náà tí wọ́n wà.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9; Dáníẹ́lì 3:3-6, 16-18; Ìṣe 4:18-20.
16. Àwọn ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò wo la fúnni tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí Bíbélì kíkà wa túbọ̀ ṣàǹfààní kí ó sì wúlò?
16 Má kàn kàwé nítorí ká lè sọ pé o ti ka ojú ewé tó pọ̀. Fara balẹ̀. Máa fọkàn sí ohun tóò ń kà. Bí kókó kan bá rú ọ lójú, yẹ àwọn ìtọ́ka wò tí Bíbélì tìrẹ bá ní irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Bí kókó náà kò bá tíì yé ọ, kọ ọ́ sílẹ̀ kóo lè túbọ̀ ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ nígbà mìíràn. Bóo ṣe ń kà á lọ, máa sàmì sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tóo fẹ́ máa rántí ní pàtàkì tàbí kí o kọ wọ́n sílẹ̀. O tiẹ̀ lè kọ àwọn kókó pàtàkì àti àwọn ìtọ́ka sí etí ìwé náà. Ní ti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tóo mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóo máa nílò wọn nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni rẹ, kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó níbẹ̀ sílẹ̀ kóo si yẹ̀ wọ́n wò nínú atọ́ka àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà lẹ́yìn Bíbélì rẹ.b
Mú Kí Bíbélì Kíkà Gbádùn Mọ́ Ẹ
17. Èé ṣe tó fi yẹ kí a ní inú dídùn sí kíka Bíbélì?
17 Onísáàmù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tó jẹ́ aláyọ̀, ẹni tí “inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:2) Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ara iṣẹ́ ilé, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ohun tó dìídì ń gbádùn mọ́ni. Ọ̀nà kan táa fi lè sọ ọ́ di ohun tó gbádùn mọ́ni ni pé ká máa jẹ́ kí ìníyelórí ohun táa ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ wà lọ́kàn wa digbí. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí . . . Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, gbogbo òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ àlàáfíà. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.” (Òwe 3:13, 17, 18) Ìsapá táa nílò láti jèrè ìmọ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí pé àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, àlàáfíà, ayọ̀, àti ìyè níkẹyìn.
18. Láfikún sí Bíbélì kíkà, kí ló tún pọndandan, kí ni a ó sì gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
18 Dájúdájú, Bíbélì kíkà lérè, ó sì gbádùn mọ́ni. Àmọ́, ṣe ibi tó parí sí nìyẹn? Àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ń ka Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, “wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, síbẹ̀ wọn kò lè dé ojú ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ láé.” (2 Tímótì 3:7) Kí Bíbélì kíkà tó lè so èso, a gbọ́dọ̀ ṣe é pẹ̀lú ète láti fi ìmọ̀ táa bá rí gbà sílò nínú ìgbésí ayé wa kí a sì máa lò ó nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni táa ń ṣe. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Èyí gba ìsapá àti àwọn ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dára, tó gbádùn mọ́ni tó sì ń ṣeni láǹfààní, bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, ojú ìwé 241.
b Wo Ilé Ìṣọ́ ti May 1, 1995, ojú ìwé 16 sí 17, “Àwọn àbá láti mú Bíbélì kíkà rẹ dára sí i.”
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
• Ìmọ̀ràn wo la fún àwọn ọba Ísírẹ́lì tó kan àwọn alábòójútó lónìí, èé sì ti ṣe?
• Àwọn wo ló dà bí “àwọn àtìpó” àti “àwọn ọmọ kéékèèké” lónìí, èé sì ti ṣe tó fi yẹ kí wọ́n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?
• Àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ wo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” gbà ràn wá lọ́wọ́ láti máa ka Bíbélì déédéé?
• Báwo la ṣe lè rí àǹfààní àti ìgbádùn tòótọ́ nínú Bíbélì kíkà wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ní pàtàkì jù lọ, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ka Bíbélì lójoojúmọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ó jẹ́ àṣà Jésù láti kópa nínú kíka Ìwé Mímọ́ ní sínágọ́gù