Ìfilọ̀ Pàtàkì
ARÁKÙNRIN John E. Barr ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tó jẹ́ alága níbi ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tó wáyé ní October 7, 2000 ṣe ìfilọ̀ pàtàkì kan bí ìpàdé ọ̀hún ti ń parí lọ. Àwọn àsọyé tí Theodore Jaracz àti Daniel Sydlik ti kọ́kọ́ sọ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn la gbé ìfilọ̀ yìí kà.—Wo ojú ìwé 12 sí 16 àti 28 sí 31 nínú ìwé ìròyìn yìí.
Arákùnrin Barr sọ kókó pàtàkì kan, ó ní: “Ohun tí a fi síkàáwọ́ ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye’ náà àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ ga fíìfíì, ó sì gbòòrò ju ohun tí a gbé lé àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ lọ́wọ́ lọ. Àwọn ohun tí ìwé ìdásílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àjọ yẹn là lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ète tí wọ́n wà fún fi hàn pé ó ní ibi tí agbára wọ́n mọ. Àmọ́ ṣá o, ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ni Jésù Kristi Ọ̀gá wa yàn sípò lórí gbogbo ‘àwọn nǹkan ìní’ rẹ̀, tàbí àwọn ire Ìjọba náà lórí ilẹ́ ayé níbí.”—Mátíù 24:45-47.
Ní ti àjọ ti Pennsylvania, Arákùnrin Barr fi kún un pé: “Látìgbà tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ti di àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ ní 1884, ó ti ṣe gudugudu méje nínú ìtàn wa ti òde òní. Síbẹ̀síbẹ̀, àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ lásán ló jẹ́, èyí tó wà fún lílò ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye’ náà nígbà tó bá pọndandan.”
Arákùnrin Sydlik àti Arákùnrin Jaracz ti kọ́kọ́ ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ tiwọn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ òótọ́ ni pé ìkáwọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni a fi gbogbo ohun ìní Olúwa ti orí ilẹ̀ ayé sí, ìyẹn kò dí ẹgbẹ́ ẹrú náà lọ́wọ́ láti yọ̀ǹda kí àwọn ọkùnrin tó tóótun látinú “àwọn àgùntàn mìíràn” máa ṣe àwọn iṣẹ́ àbójútó kan tí kì í ṣe àkànṣe. (Jòhánù 10:16) Bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ìdí kankan tó bá Ìwe Mímọ́ mu pé èyíkéyìí tàbí gbogbo àwọn tó jẹ́ olùdarí nínú àwọn àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró.
Arákùnrin Barr sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn kán lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ń sìn tẹ́lẹ̀ rí gẹ́gẹ́ bí olùdarí àti aláṣẹ, ti fínnúfíndọ̀ fi ipò wọn sílẹ̀ nínú àwọn ìgbìmọ̀ tó ń darí gbogbo àjọ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń lò ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n wá fìbò yan àwọn arákùnrin tó tóótun nínú ẹgbẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn láti rọ́pò wọn.
Ìpinnu yìí ṣàǹfààní gidigidi. Ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láti túbọ̀ lo àkókò sí i fún pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ máa bìkítà fún àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ará jákèjádò ayé ṣaláìní nípa tẹ̀mí.
Ní paríparí rẹ̀, alága náà sọ fún àwùjọ tínú wọn dùn náà pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ẹrù iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú òfin àti ètò iṣẹ́ ṣíṣe la ti yàn fáwọn alábòójútó tí wọ́n kún fún ìrírí, . . . abẹ́ ìdarí tẹ̀mí ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni gbogbo wọn pátá ti ń sìn. . . . Gbogbo wa ń fi tàdúràtàdúrà wo Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀ lórí ìsapá tí a ń jùmọ̀ ṣe nínú ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀, sí ọlá àti ògo orúkọ ńlá rẹ̀.”