Ẹ Máa Bójú Tó Àwọn Ọmọ Òrukàn Àtàwọn Opó Nínú Ìpọ́njú Wọn
Kò ṣòro láti mọ̀ pé inú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ la ń gbé. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn èèyàn tí yóò wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó kọ̀wé pé: “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1-3) Ẹ ò rí i pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn!
ÌWÀ táwọn èèyàn ń hù lákòókò táa wà yìí wà lára ohun tó fà á tí kò fi sí ẹ̀mí ìyọ́nú lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn èèyàn ò tiẹ̀ wá nífẹ̀ẹ́ sí ire àwọn ẹlòmíràn mọ́, àní àwọn kan ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ire mẹ́ńbà ìdílé tiwọn pàápàá.
Èyí ti wá nípa búburú lórí ọ̀pọ̀ tó ti di aláìní nítorí onírúurú ipò tí wọ́n bá ara wọn. Iye àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá ni nítorí ogun, ìjábá, àti àìrílégbé àwọn èèyàn tó ń wá ibi ìsádi. (Oníwàásù 3:19) Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé sọ pé: “[Àwọn ọmọdé] tó lé ní mílíọ̀nù kan ni ogun ti sọ di ọmọ òrukàn tàbí tó ti yà wọ́n nípa kúrò lọ́dọ̀ ìdílé wọn.” Ìwọ náà ṣáà mọ bí àwọn ìyá tó ń nìkan tọ́mọ ṣe pọ̀ tó, tàbí àwọn ìyá táa ti pa tì tàbí táwọn ọkọ wọn ti kọ̀ sílẹ̀, tí wọ́n ń kojú ipò líle koko ti bíbá a nìṣó láti máa bójú tó ìdílé wọn láwọn nìkan. Ohun tó mú kí ipò náà túbọ̀ burú sí i ni pé ọrọ̀ ajé àwọn orílẹ̀-èdè kan ti dẹnu kọlẹ̀, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn aráàlú wọn di ẹni tó wà nínú ipò òṣì paraku.
Nítorí ìdí èyí, ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fún àwọn tó wà nínú ìpọ́njú? Báwo ni àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà tó ń jẹ wọ́n? Ǹjẹ́ a lè mú ìṣòro yìí kúrò láé?
Àbójútó Onífẹ̀ẹ́ Láwọn Àkókò Táa Kọ Bíbélì
Bíbójútó àìní àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn ti sábà máa ń jẹ́ apá pàtàkì nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń kórè ọkà tàbí àwọn èso wọn, wọ́n ò gbọ́dọ̀ kó àwọn ohun tí wọ́n bá kórè kù nínú oko jọ, ìyẹn ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi èéṣẹ́ náà sílẹ̀ “fún àwọn àtìpó, fún àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti fún àwọn opó.” (Diutarónómì 24:19-21) Òfin Mósè tiẹ̀ sọ ọ́ ní pàtó pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́.” (Ẹ́kísódù 22:22, 23) Àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ń tọ́ka sí àwọn aláìní, nítorí pé nígbà tí ọkọ tàbí baba bá kú, tàbí tí àwọn òbí méjèèjì bá kú, àwọn mẹ́ńbà ìdílé tó ṣẹ́ kù lè wá dá nìkan wà, kí wọ́n sì di aláìní. Baba ńlá náà, Jóòbù, sọ pé: “Èmi a gba ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.”—Jóòbù 29:12.
Ní àwọn àkókò tí ìjọ Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, bíbójútó àwọn ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn tó jẹ́ aláìní nítorí ikú àwọn òbí tàbí ikú ọkọ kan jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́. Pẹ̀lú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ sí ire irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù, kọ̀wé pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
Yàtọ̀ sí mímẹ́nukan àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn opó, Jákọ́bù tún fi hàn pé ọ̀ràn àwọn tálákà àtàwọn aláìní ká òun lára. (Jákọ́bù 2:5, 6, 15, 16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún fi irú ìgbatẹnirò kan náà hàn. Nígbà tí wọ́n yan ibi tí òun àti Bánábà yóò ti lọ wàásù fún wọn, ‘fífi àwọn òtòṣì sọ́kàn’ wà lára ìtọ́ni táa fún wọn. Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀rí ọkàn tó dára sọ pé: “Ohun yìí gan-an ni èmi pẹ̀lú ti fi taratara sakun láti ṣe.” (Gálátíà 2:9, 10) Ìtàn ìgbòkègbodò ìjọ Kristẹni kété lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ sọ pé: “Kò sí ọ̀kan láàárín wọn tí ó wà nínú àìní . . . Ẹ̀wẹ̀, wọn a pín nǹkan fún olúkúlùkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní rẹ̀ bá ṣe rí.” (Ìṣe 4:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni o, ètò tí wọ́n fi lélẹ̀ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì nípa bí wọn ṣe ń bójú tó àwọn ọmọ òrukàn, àwọn opó àtàwọn aláìní ló nasẹ̀ dé inú ìjọ Kristẹni.
Láìsí àní-àní, àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣèrànwọ́ mọ níwọ̀n, ó sinmi lórí ibi tí agbára ìjọ kọ̀ọ̀kan mọ. Wọn ò fowó ṣòfò, àwọn tó dìídì jẹ́ aláìní ni wọ́n sì ń ràn lọ́wọ́. Kristẹni kankan kò gbọ́dọ̀ ṣi àǹfààní ètò tí wọ́n ṣe yìí lò, wọn ò sì gbọ́dọ̀ di ẹrù tí kò pọndandan lé ìjọ lórí. Èyí hàn gbangba nínú ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù fúnni, èyí tó wà nínú 1 Tímótì 5:3-16. Ibẹ̀ la ti rí i pé bí àwọn ará ilé irú àwọn tó jẹ́ aláìní bẹ́ẹ̀ bá lè ṣèrànwọ́ fún wọn, ó yẹ kí wọ́n gba ẹrù iṣẹ́ náà bí iṣẹ́ wọn. Àwọn opó tó jẹ́ aláìní gbọ́dọ̀ kúnjú àwọn òṣùwọ̀n kan kí wọ́n lè tóótun láti gba ìrànwọ́. Gbogbo èyí ló fi ètò ọlọgbọ́n tí Jèhófà ṣe láti bójú tó àwọn aláìní hàn. Síbẹ̀, ó tún fi hàn pé a gbọ́dọ̀ lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣi inúure tí wọ́n fi hàn lò.—2 Tẹsalóníkà 3:10-12.
Bíbójútó Àwọn Ọmọ Òrukàn Àtàwọn Opó Lóde Òní
Ìlànà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tẹ̀ lé láyé ọjọ́un ṣì ń bá a lọ nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tọ́ràn bá dórí dídàníyàn àti ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tó wà nínú ìpọ́njú. Ìfẹ́ ará jẹ́ ànímọ́ pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ ọ́ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Bí àwọn kan bá bára wọn nínú ipò òṣì, tàbí tí ìjábá kan bá bá wọn tàbí tí ogun tàbí ogun abẹ́lé bá jà wọ́n, àwọn ẹgbẹ́ ará tó kù kárí ayé múra tán láti wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Ẹ jẹ́ ká kíyè sí àwọn ìrírí ti òde òní bíi mélòó kan tó fi ohun táa ti ṣe nínú irú ipò yìí hàn.
Pedro kò rántí nǹkan púpọ̀ nípa ìyá rẹ̀ tó kú nígbà tí Pedro wà lọ́mọ ọdún kan ààbọ̀ péré. Ìgbà tí Pedro pé ọmọ ọdún márùn-ún ni baba rẹ̀ náà tún kú. Bó ṣe ku Pedro àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nìkan nìyẹn o. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ti máa ń wá sọ́dọ̀ baba wọn tẹ́lẹ̀, nítorí ìdí èyí, Pedro àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá gbà pé kí wọ́n wá máa bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
Pedro sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e gan-an la bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé. Báa ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará, ó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wa. Ibi ààbò ni ìjọ náà jẹ́ fún mi, nítorí pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin fi ìfẹ́ àti ìfẹ́ni hàn sí mi, bí ẹni pé àwọn gan-an ni wọ́n bí mi lọ́mọ.” Pedro rántí pé ọ̀kan lára àwọn Kristẹni alàgbà máa ń pe òun wá sílé rẹ̀. Pedro máa ń bá wọn kópa nínú ìjíròrò ìdílé náà, ó sì máa ń ṣe fàájì lọ́dọ̀ wọn. Pedro tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, tó sì ṣe ìrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Mi ò jẹ́ gbàgbé nǹkan wọ̀nyẹn.” Nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ àwọn tó wà nínú ìjọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí.
Bẹ́ẹ̀ náà tún ni ọ̀ràn ti David. Ìgbà tí àwọn òbí wọn tú ká ni wọ́n pa òun àti obìnrin tí wọ́n jọ jẹ́ ìbejì tì. Àwọn òbí wọn àgbà àti àǹtí wọn kan ló tọ́ wọn dàgbà. “Nígbà táa dàgbà, táa wá rí ipò táa wà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí nímọ̀lára pé a ò láàbò, inú wa ò sì dùn. A nílò ohun kan láti fẹ̀yìn tì. Àǹtí mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọpẹ́lọpẹ́ èyí ló jẹ́ kí wọ́n wá fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ wa. Àwọn ará fi ìfẹ́ni hàn sí wa, wọ́n sì bá wa dọ́rẹ̀ẹ́. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni, wọ́n sì gbà wá níyànjú láti lé àwọn góńgó kan bá, kí a sì máa ṣíṣẹ fún Jèhófà. Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan yóò wá mú mi láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Arákùnrin mìíràn máa ń gbọ́ bùkátà mi nígbà tí mo bá lọ sí àwọn àpéjọpọ̀. Arákùnrin kan tiẹ̀ ràn mí lọ́wọ́, kí n lè máa dáwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.”
David ṣe batisí nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, nígbà tó sì ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mexico. Kódà nísinsìnyí pàápàá, ó sọ pé: “Àwọn alàgbà bíi mélòó kan ló sanwó ilé ìwé mi, wọ́n sì fún mi ní ìmọ̀ràn tó ṣèrànwọ́. Nípa báyìí, mo ti ń borí ìmọ̀lára àìláàbò àti ìnìkanwà tí mo máa ń ní.”
Abel, tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ kan ní Mexico, níbi tí àwọn opó bíi mélòó kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ wà, sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ohun táwọn opó nílò jù lọ ni ìtìlẹ́yìn ní ti ìmí ẹ̀dùn. Ìgbà mìíràn wà tí wọ́n máa ń soríkọ́; tí wọ́n á nímọ̀lára pé àwọn dá nìkan wà. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti tì wọ́n lẹ́yìn, ká fetí sí wọn. Àwa [alàgbà ìjọ] máa ń bẹ̀ wọ́n wo nígbà gbogbo. Ó dáa láti wá àkókò láti fetí sí àwọn ìṣòro wọn. Èyí ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ń rí ìtùnú tẹ̀mí gbà.” Àmọ́, wọ́n tún máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ nípa ìṣúnná owó nígbà mìíràn. Abel sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “A ń kọ́ ilé kan lọ́wọ́ fún arábìnrin kan tó jẹ́ opó. A ń lo àwọn ọjọ́ Sátidé àtàwọn ọ̀sán mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nílé rẹ̀.”
Nígbà tí alàgbà mìíràn ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí ti ara rẹ̀ nínú pípèsè fún àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn opó, ó sọ pé: “Mo gbà pé àwọn ọmọ òrukàn nílò ìfẹ́ Kristẹni gan-an ju àwọn opó lọ. Mo ti kíyè sí i pé wọ́n máa ń kárí sọ ju àwọn ọmọdé àtàwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà tí wọ́n ní bàbá àti ìyá. Wọ́n nílò ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí ń fi ìfẹ́ni ará hàn. Ó dára ká máa wá wọn rí lẹ́yìn ìpàdé, ká lè béèrè àlàáfíà wọn. Arákùnrin kan wà tó ti gbéyàwó báyìí, àmọ́ tó jẹ́ pé àtikékeré ló ti di ọmọ òrukàn. Mo máa ń kí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà nípàdé, ó sì máa ń dì mọ́ mi tó bá ti rí mi. Èyí ń fún ìdè ìfẹ́ ara lókun.”
Jèhófà ‘Yóò Dá Òtòṣì Nídè’
Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà ṣe pàtàkì gan-an láti lè kojú ipò tí àwọn opó àti àwọn ọmọ òrukàn wà. A sọ nípa rẹ̀ pé: “Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn àtìpó; ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó ni ó ń mú ìtura bá.” (Sáàmù 146:9) Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ni ó lè yanjú irú àwọn ìṣòro wọ̀nyí tán pátápátá. Nígbà tí onísáàmù náà ń ṣàpèjúwe ìṣàkóso Mèsáyà lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12, 13.
Bí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ṣe ń sún mọ́lé, ó dájú pé pákáǹleke táwọn Kristẹni ní gbogbo gbòò ń dojú kọ yóò máa pọ̀ sí i. (Mátíù 24:9-13) Ìdí wà fún àwọn Kristẹni láti túbọ̀ máa ṣàníyàn nípa ara wọn kí wọ́n sì ‘ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’ (1 Pétérù 4:7-10) Àwọn Kristẹni ọkùnrin, àgàgà àwọn alàgbà, ní láti máa ṣaájò àwọn ọmọ òrukàn wọ̀nyẹn, kí wọ́n si máa fi ìyọ́nú hàn sí wọn. Àwọn obìnrin tó dàgbà dénú nínú ìjọ náà lè ṣètìlẹ́yìn fún àwọn opó, kí wọ́n sì jẹ́ orísun ìtùnú fún wọn. (Títù 2:3-5) Àní, olúkúlùkù ló lè ṣe ipa tirẹ̀ nípa ṣíṣaájò àwọn ẹlòmíràn tó wà nínú ìpọ́njú.
Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ‘sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ wọn’ nígbà tí wọ́n bá ‘rí i tí arákùnrin wọ́n ṣe aláìní.’ Wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòhánù 3:17, 18) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa “bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.”—Jákọ́bù 1:27.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 Jòhánù 3:18
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn opó nípa tara, nípa tẹ̀mí, àti ní ti ìmí ẹ̀dùn