Àwọn Alátìlẹyìn Ìjọsìn Tòótọ́—Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní
ǸJẸ́ o rántí orúkọ ọkùnrin kan tó sunkún lórí Jerúsálẹ́mù ìlú ńlá ìgbàanì? O lè sọ pé ‘Jésù’ ni—Jésù sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. (Lúùkù 19:28, 41) Àmọ́, ẹlòmíràn tí òun náà jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti sunkún lórí Jerúsálẹ́mù ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà tí Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé. Nehemáyà ni orúkọ rẹ̀.—Nehemáyà 1:3, 4.
Kí ló mú kí Nehemáyà banú jẹ́ débi tó fi sunkún lórí Jerúsálẹ́mù? Kí ló ṣe fún àǹfààní ìlú náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nígbà ayé rẹ̀ yẹ̀ wò.
Ọkùnrin Tó Ní Ìmí Ẹ̀dùn, Tó sì Jẹ́ Akíkanjú
Nehemáyà ni wọ́n yàn ṣe gómìnà Jerúsálẹ́mù, àmọ́ ṣáájú àkókò yẹn, ó ti jẹ́ òṣìṣẹ́ tó wà nípò gíga ní ààfin Páṣíà ní ìlú Ṣúṣánì. Síbẹ̀ ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tó ń gbé kò mú kó gbàgbé àníyàn tó ní fún àwọn Júù tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù tó jìnnà réré. Kódà, ohun tó kọ́kọ́ ṣe nígbà táwọn Júù tí wọ́n rán wá láti Jerúsálẹ́mù dé sí Ṣúṣánì ni pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù, àwọn tí ó sá àsálà, tí wọ́n ṣẹ́ kù lára àwọn òǹdè, àti nípa Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú.” (Nehemáyà 1:2) Nígbà táwọn àlejò náà fèsì pé àwọn ènìyàn Jerúsálẹ́mù wà “nínú ipò ìṣòro tí ó burú gidigidi” àti pé ògiri ìlú náà ti “wó lulẹ̀,” Nehemáyà ‘jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ fún ọjọ́ púpọ̀.’ Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá sọ bí ìbànújẹ́ ṣe dorí òun kodò tó nínú àdúrà kan tó fi tọkàntọkàn gbà sí Jèhófà. (Nehemáyà 1:3-11) Èé ṣe tínú Nehemáyà fi bà jẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jerúsálẹ́mù ni ọ̀gangan ibi ìjọsìn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ti pa á tì. (1 Àwọn Ọba 11:36) Àti pé, ipò búburú tí ìlú náà wà fi bí ipò tẹ̀mí àwọn olùgbé ibẹ̀ ṣe burú tó hàn.—Nehemáyà 1:6, 7.
Àníyàn tí Nehemáyà ní fún Jerúsálẹ́mù àti bí àánú àwọn Júù tó wà níbẹ̀ ṣe ń ṣe é ló mú kó yọ̀ǹda ara rẹ̀ pátápátá. Gbàrà tí ọba àwọn ará Páṣíà fún Nehemáyà láyè ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé ìrìn àjò gígùn tó máa rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù. (Nehemáyà 2:5, 6) Ó fẹ́ lo agbára rẹ̀, àkókò rẹ̀, àti òye iṣẹ́ tó ní láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn àtúnṣe tó yẹ ní ṣíṣe. Láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan tó dé, ó ti wéwèé bí wọ́n ṣe máa tún gbogbo ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́.—Nehemáyà 2:11-18.
Nehemáyà pín iṣẹ́ títún ògiri náà kọ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé, tí gbogbo wọn sì ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ara wọn.a Ó pín àwọn èèyàn náà sí ọ̀nà tó lé ní ogójì ní ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́, ó sì yan ‘ẹ̀ka tí a díwọ̀n’ fún ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan láti tún ṣe. Kí ni àbájáde rẹ̀? Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òṣìṣẹ́—tó ní àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn nínú—tí wọ́n ń lo àkókò àti agbára wọn, iṣẹ́ tó dà bí èyí tí kò lè ṣeé ṣe wá di èyí tí agbára wọ́n ká. (Nehemáyà 3:11, 12, 19, 20) Láàárín oṣù méjì tí ọwọ́ wọn fi há gádígádí fún iṣẹ́, wọ́n parí àtúnṣe gbogbo ògiri náà! Nehemáyà kọ̀wé pé kódà àwọn tí wọ́n tako iṣẹ́ àtúnṣe náà wá gbà pé “láti ọwọ́ Ọlọ́run wa ni a ti ṣe iṣẹ́ yìí.”—Nehemáyà 6:15, 16.
Àpẹẹrẹ Kan Tó Yẹ Ká Máa Rántí
Kì í ṣe àkókò àti ọgbọ́n ìṣètò nìkan ni Nehemáyà lò fún iṣẹ́ náà. Ó tún lo àwọn ohun ìní rẹ̀ láti ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́. Ó ná owó ara rẹ̀ láti ra àwọn Júù arákùnrin rẹ̀ padà kúrò lóko ẹrú. Ó yáni lówó láìgba èlé. Kò “mú nǹkan wúwo” fún àwọn Júù nípa bíbéèrè fún owó tó yẹ kó máa gbà gẹ́gẹ́ bíi gómìnà, bẹ́ẹ̀ ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni. Dípò ìyẹn gbogbo ìgbà ló jẹ́ pé inú ilé ara rẹ̀ ló ti máa ń bọ́ ‘àádọ́jọ ọkùnrin, àti àwọn tí ń wọlé tọ̀ wọ́n wá láti inú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká.’ Ojoojúmọ́ ló máa ń pèsè “akọ màlúù kan, àṣàyàn àgùntàn mẹ́fà àti àwọn ẹyẹ” fún àwọn àlejò rẹ̀. Láfikún síyẹn, ẹ̀ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá-mẹ́wàá ló máa ń fún wọn ní “gbogbo onírúurú wáìnì ní ọ̀pọ̀ yanturu”—owó ara rẹ̀ ló sì fi ń ṣe gbogbo èyí.—Nehemáyà 5:8, 10, 14-18.
Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ jíjẹ́ ọ̀làwọ́ lọ́nà tó tayọ ni Nehemáyà fi lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti lóde òní pẹ̀lú! Onígboyà ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí fi tinútinú lo àwọn ohun ìní rẹ̀ láti ṣètìlẹyìn fún àwọn òṣìṣẹ́ kí ìjọsìn tòótọ́ lè tẹ̀ síwájú. Abájọ tó fi sọ fún Jèhófà pé: “Ọlọ́run mi, rántí mi fún rere, gbogbo èyí tí mo ti ṣe nítorí àwọn ènìyàn yìí.” (Nehemáyà 5:19) Dájúdájú, Jèhófà yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.—Hébérù 6:10.
À Ń Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Nehemáyà Lónìí
Ó múnú ẹni dùn láti rí i pé bákan náà làwọn èèyàn Jèhófà òde òní ṣe ń lo ìfẹ́, ìmúratán láti ṣiṣẹ́, àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ fún ìjọsìn tòótọ́. Ó máa ń ká wa lára gan-an nígbà tá a bá gbọ́ pé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ wà nínú ìpọ́njú. (Róòmù 12:15) Bíi ti Nehemáyà, a máa ń yíjú sí Jèhófà nínú àdúrà láti ṣètìlẹyìn fún àwọn arákùnrin wa tí ìyà ń jẹ, a sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ó ní inú dídùn sí bíbẹ̀rù orúkọ rẹ.”—Nehemáyà 1:11; Kólósè 4:2.
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé àníyàn tá a ní fún ire tẹ̀mí àti ti ara àwọn Kristẹni arákùnrin wa àti fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn tòótọ́ wúlẹ̀ ń nípa lórí ìmọ̀lára wa nìkan ni, ó tún ń sún wa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú. Ìfẹ́ ń sún àwọn tí àyíká ipò wọn fàyè gbà á láti fi ilé wọn tí wọ́n ti ń jẹ̀gbádùn sílẹ̀, kí wọ́n ṣí lọ síbòmíràn láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìní bí Nehemáyà ti ṣe. Láìfi àwọn ipò tí kò fi bẹ́ẹ̀ bára dé táwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí lè dojú kọ láwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé pè, wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fún ìlọsíwájú ìjọsìn tòótọ́ níbẹ̀, wọ́n sì ń sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin wọn. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọ́n wúni lórí gan-an ni.
Ṣíṣe Ipa Tiwa Níbi Tá À Ń Gbé
Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ni kò lè ṣí lọ síbòmíràn. À ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ níbi tá à ń gbé. A ṣàpèjúwe ìyẹn náà nínú ìwé Nehemáyà. Kíyè sí kúlẹ̀kúlẹ̀ tí Nehemáyà sọ nípa àwọn ìdílé kan tó jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ àtúnṣe náà. Ó kọ̀wé pé: “Jedáyà ọmọkùnrin Hárúmáfù, ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú ilé òun fúnra rẹ̀ . . . Bẹ́ńjámínì àti Háṣúbù ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú ilé tiwọn fúnra wọn. Lẹ́yìn wọn ni Asaráyà ọmọkùnrin Maaseáyà ọmọkùnrin Ananáyà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe nítòsí ilé òun fúnra rẹ̀.” (Nehemáyà 3:10, 23, 28-30) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn àtàwọn ìdílé wọn ṣe bẹbẹ nínú mímú kí ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú nípa ṣíṣe ipa tiwọn nínú iṣẹ́ àtúnṣe náà nítòsí ilé wọn.
Lóde òní, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló ń ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn ní àgbègbè tí à ń gbé lónírúurú ọ̀nà. À ń kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, à ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìjábá bá, àti ní pàtàkì jù lọ, à ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Láfikún síyẹn, yálà ó ṣeé ṣe fún wa láti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tọkàntọkàn ni gbogbo wa fi ń fẹ́ láti fi ohun ìní wa ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Nehemáyà ti fi ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ ṣe nígbà ayé rẹ̀.—Wo àpótí “Bá A Ṣe Ń Mọ Ọrẹ Àtinúwá.”
Rírí owó tá a nílò láti ná lórí ìgbòkègbodò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé tá à ń tẹ̀ jáde, ìrànlọ́wọ́ láti dín ìṣòro kù, àti onírúurú iṣẹ́ ìsìn mìíràn tó wà káàkiri àgbáyé lè dà bí ohun tí agbára ẹni ò lè ká nígbà mìíràn. Àmọ́, rántí pé iṣẹ́ títún ògiri gìrìwò Jerúsálẹ́mù kọ́ náà dà bí àlá tí ò lè ṣẹ. (Nehemáyà 4:10) Síbẹ̀, wọ́n ṣe iṣẹ́ náà láṣeparí nítorí pé wọ́n pín in fún ọ̀pọ̀ ìdílé tó múra tán láti ṣiṣẹ́. Bákan náà ni lónìí, rírí àwọn ohun tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ tá à ń ṣe jákèjádò ayé yanjú kò ní kọjá agbára wa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá ń bá a lọ láti bójú tó apá kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ náà.
Àpótí náà “Àwọn Ọ̀nà Tí Àwọn Kan Yàn Láti Gbà Ṣe Ìtọrẹ” fi onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà hàn. Ní àwọn ọdún tó kọjá, ọ̀pọ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ti ṣe irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì fẹ́ lo àǹfààní yìí láti fi ìmọrírì tó jinlẹ̀ hàn fún gbogbo àwọn tí ọkàn wọ́n sún wọn láti kópa nínú ọrẹ àtinúwá yìí. Lékè gbogbo rẹ̀, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀ lórí ìsapá táwọn èèyàn rẹ̀ fi tọkàntọkàn ṣe ní gbígbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ jákèjádò ayé. Dájúdájú, nígbà tá a bá ronú nípa bí ọwọ́ Jèhófà ṣe darí wa láwọn ọdún wọ̀nyí, a óò fẹ́ láti tún ọ̀rọ̀ Nehemáyà sọ, ẹni tó fi ìdúpẹ́ sọ pé: ‘Ọwọ́ Ọlọ́run mi mà dára lára mi o.’—Nehemáyà 2:18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nehemáyà 3:5 sọ pé àwọn kan tó jẹ́ ẹni ńlá láàárín àwọn Júù, ìyẹn “àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́lá ọba,” nínú wọn kọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ náà, àmọ́ àwọn nìkan ló ṣe bẹ́ẹ̀. Onírúurú èèyàn ló kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn—àwọn àlùfáà, àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, àwọn tí ń po òróró ìkunra, àwọn ọmọ aládé, àtàwọn oníṣòwò.—Ẹsẹ 1, 8, 9, 32.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Yàn Láti Gbà Ṣe
ÌTỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ
Ọ̀pọ̀ ń ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí kí wọ́n ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Yíká Ayé]—Mátíù 24:14,” sí lára.
Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, tàbí ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti àgbègbè wọn. O tún lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
ÈTÒ ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PADÀ
A lè fi owó ṣe ìtọrẹ lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí a óò dá owó náà padà fún ẹni tó fi tọrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé onítọ̀hún nílò rẹ̀. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tá a kọ sókè yìí.
ÌFÚNNI TÍ A WÉWÈÉ
Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ọrẹ tó ṣeé gbà padà, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tá a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Lára wọn ni:
Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí olùjàǹfààní owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.
Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báńkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ sí ìkáwọ́ Watch Tower Society, tàbí ká mú kó ṣeé san fún Society bí ẹni tó ni ín bá kú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báńkì àdúgbò bá béèrè.
Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.
Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower Society, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí olùtọrẹ náà ṣì lè máa lò nígbà ayé rẹ̀. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di èyí tó o fi tọrẹ.
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tí A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Àwọn ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́, tó jẹ́ pé ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “ìfúnni tí a wéwèé” túmọ̀ sí, irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé lọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣètọrẹ. Láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tó ń fẹ́ láti ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nípa oríṣiríṣi ìfúnni tá a wéwèé, Society ti ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Spanish, tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Charitable Planning to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà láti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tá a ti rí gbà nípa ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni tó wúlò fún ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò, àti owó orí nínú. Ó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fúnni ní ẹ̀bùn nísinsìnyí tàbí bí wọ́n ṣe lè fi ẹ̀bùn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kú. A lè rí ìwé yìí gbà nípa bíbéèrè fún ẹ̀dà kan ní tààràtà láti ẹ̀ka Charitable Planning Office.
Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí wọ́n sì ti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka Charitable Planning Office, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, kí wọ́n sì tún rí àwọn àjẹmọ́nú gbà látinú owó orí tí wọ́n san. A gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ìṣètò wọ̀nyí tó àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka Charitable Planning Office létí, ká sì fún wọn ní ẹ̀dà àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá tan mọ́ ọn. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí nínú àwọn ìṣètò ìfúnni tá a wéwèé wọ̀nyí, kàn sí ẹ̀ka Charitable Planning Office, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a tò sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o pè wọ́n lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.
Charitable Planning Office
Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
100 Watchtower Drive
Patterson, New York 12563-9204
Telephone: (845) 306-0707
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
Bá A Ṣe Ń Mọ Ọrẹ Àtinúwá
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó mẹ́nu kan àwọn ohun pàtàkì mẹ́ta tá a fi ń mọ ọrẹ àtinúwá. (1) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ìdáwó, ó sọ pé: “Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe.” (1 Kọ́ríńtì 16:2a) Ìyẹn túmọ̀ sí pé ṣíṣe ìtọrẹ jẹ́ ohun tá a gbọ́dọ̀ wéwèé ṣáájú àkókò, a sì gbọ́dọ̀ ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. (2) Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣètọrẹ “níbàámu pẹ̀lú owó tó ń wọlé fún un.” (1 Kọ́ríńtì 16:2b, New International Version) Lọ́rọ̀ mìíràn, ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ ṣètọrẹ àtinúwá lè ṣe é bí agbára rẹ̀ ṣe mọ. Bí owó tó ń wọlé fún Kristẹni kan tiẹ̀ kéré, ojú ribiribi ni Jèhófà fi ń wo ìwọ̀nba owó tó bá dá. (Lúùkù 21:1-4) (3) Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé síwájú sí i pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fúnni látọkànwá—tọ̀yàyàtọ̀yàyà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọkùnrin tó ní ìmí ẹ̀dùn tó sì jẹ́ akíkanjú ni Nehemáyà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ọrẹ àtinúwá là ń lò fún àwọn ìwé tá à ń tẹ̀, òun la fi ń ṣèrànwọ́ láti dín ìṣòro àwọn ará kù, òun la sì fi ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tá a tún fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn mìíràn tó ń ṣeni láǹfààní káàkiri ayé