Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà
FÚN ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ìbéèrè nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà ti ń dààmú ọ̀pọ̀ onímọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Àwọn kan ń sọ pé níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ alágbára gbogbo, òun ló ní láti máa ṣokùnfà ìyà tó ń jẹ wá. Ẹni tó kọ ìwé The Clementine Homilies, ìyẹn àpókírífà kan tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kejì, sọ pé ọwọ́ méjèèjì ni Ọlọ́run fi ń ṣàkóso ayé. “Ọwọ́ òsì” rẹ̀ tó jẹ́ Èṣù, ló fi ń fa ìyà àti ìpọ́njú, “ọwọ́ ọ̀tún” rẹ̀, tó jẹ́ Jésù, ló fi ń gbani là tó sì fi ń bù kúnni.
Àwọn mìíràn tí wọ́n gbà pé Ọlọ́run kò lè fàyè gba ìjìyà, pé kò sì lè ṣokùnfà rẹ̀, ti yàn láti gbà pé kò sí ohun tó ń jẹ́ ìjìyà rárá. Mary Baker Eddy kọ̀wé pé: “Ìtànjẹ lásán ni ìwà ibi, kò sì ní ìpìlẹ̀ kan pàtó.” “Bí a bá ka ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn àti ikú sí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan, a jẹ́ pé wọ́n á pòórá.—Science and Health With Key to the Scriptures.
Àwọn ohun búburú tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn, àgàgà látìgbà ogun àgbáyé kìíní títí di àkókò tá a wà yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn parí èrò sí pé Ọlọ́run ò lè dá ìjìyà dúró. Júù ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, David Wolf Silverman, kọ̀wé pé: “Ní èrò tèmi, Ìpakúpa Rẹpẹtẹ yẹn ti mú kí ọ̀rọ̀ náà alágbára gíga jù lọ di èyí tí kò tọ́ láti máa lò fún Ọlọ́run mọ́.” Ó tún sọ pé: “Bí Ọlọ́run bá ṣeé lóye láwọn ọ̀nà kan, a jẹ́ pé ìwà rere Rẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú wíwà ibi nìyẹn, ìyẹn sì lè rí bẹ́ẹ̀ kìkì tí Òun kì í bá ṣe alágbára gbogbo.”
Àmọ́ sísọ pé Ọlọ́run ló máa ń fa ìjìyà, pé ìjìyà wulẹ̀ jẹ́ ohun tá à ń finú wòye rẹ̀ lásán, tàbí pé Ọlọ́run kò lè dá ìjìyà dúró kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìtùnú fáwọn tó ń jìyà. Ní pàtàkì jù lọ, irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ànímọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, akíkanjú, àti ẹni tó bìkítà fúnni gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn. (Jóòbù 34:10, 12; Jeremáyà 32:17; 1 Jòhánù 4:8) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni Bíbélì wá ń sọ nípa ìdí tó fi fàyè gba ìjìyà?
Báwo Ni Ìjìyà Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
Ọlọ́run kò dá èèyàn láti jìyà. Dípò ìyẹn, ó fi èrò inú àti ara pípé jíǹkí tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, ó ṣètò ọgbà dáradára kan tí wọ́n á máa gbé, ó sì yan iṣẹ́ alárinrin tó ń máyọ̀ wá fún wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28, 31; 2:8) Àmọ́ ṣá o, tí wọn ò bá fẹ́ ki ayọ̀ wọn bà jẹ́, wọ́n ní láti tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso Ọlọ́run, kí wọ́n sì gbà pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Àṣẹ Ọlọ́run yẹn ni igi kan tí a pè ní “igi ìmọ̀ rere àti búburú” dúró fún. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ádámù àti Éfà yóò fi hàn pé àwọn fi ara wọn sábẹ́ Ọlọ́run bí wọ́n bá pa àṣẹ rẹ̀ tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ lára èso igi náà mọ́.a
Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà kùnà láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀, tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù níkẹyìn, sọ fún Éfà pé ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run kò lè ṣe é ní àǹfààní kankan. Ó tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fi ohun kan tó níye lórí gan-an dù ú: ìyẹn ni òmìnira, ẹ̀tọ́ láti fúnra rẹ̀ yan ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Sátánì sọ pé tó bá jẹ lára èso igi náà, ‘ó dájú pé ojú rẹ̀ yóò là, ó sì dájú pé yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.’ (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Ìṣípayá 12:9) Nítorí ìrètí àtidi òmìnira, Éfà jẹ nínú èso tá a kà léèwọ̀ náà, Ádámù sì ṣe bákan náà.
Ọjọ́ yẹn gan-an ni Ádámù àti Éfà bẹ̀rẹ̀ sí í rí àbájáde ọ̀tẹ̀ wọn. Nípa kíkọ ìṣàkóso Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n pàdánù ààbò àti ìbùkún tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n fara wọn sábẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò nínú párádísè, ó sì sọ fún Ádámù pé: “Ègún ni fún ilẹ̀ ní tìtorí rẹ. Inú ìrora ni ìwọ yóò ti máa jẹ àmújáde rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ. Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:17, 19) Bí àìsàn, ìrora, ọjọ́ ogbó, àti ikú ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá Ádámù àti Éfà fínra nìyẹn. Ìjìyà wá di ohun tọ́mọ aráyé ń bá yí.—Jẹ́nẹ́sísì 5:29.
Yíyanjú Ọ̀ràn Náà
Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Ṣe Ọlọ́run ò kàn lè gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà dá ni?’ Rárá o, nítorí pé ńṣe nìyẹn ì bá túbọ̀ dín ọ̀wọ̀ táwọn èèyàn ní fún ọlá àṣẹ rẹ̀ kù, ó tiẹ̀ lè fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ mìíràn níṣìírí lọ́jọ́ iwájú, kíyẹn sì wá yọrí sí ìyà tó ju ìyà lọ. (Oníwàásù 8:11) Yàtọ̀ síyẹn, gbígbójúfo irú ìwà àìgbọràn bẹ́ẹ̀ dá ì bá mú kí Ọlọ́run lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́. Mósè tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì rán wa létí pé: pípé ni iṣẹ́ Ọlọ́run, “Nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Kí Ọlọ́run lè fi bi òun ṣe jẹ́ hàn lóòótọ́, ó ní láti jẹ́ kí Ádámù àti Éfà jìyà àìgbọràn tí wọ́n ṣe.
Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi pa tọkọtaya àkọ́kọ́ àti Sátánì, ẹni tí kò ṣeé fojú rí tó dáná ọ̀tẹ̀ náà run lójú ẹsẹ̀? Ó kúkú lágbára àtiṣe bẹ́ẹ̀. Ádámù àti Éfà ì bá máà ti mú àwọn ọmọ tó jogún ìyà àti ikú jáde. Àmọ́ irú fífi agbára Ọlọ́run hàn lọ́nà yẹn ì bá máà fi ẹ̀tọ́ tí ọlá àṣẹ Ọlọ́run ní lórí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè hàn. Yàtọ̀ síyẹn, bí Ádámù àti Éfà bá kú láìbímọ, ìyẹn ì bá túmọ̀ sí pé ète Ọlọ́run láti fi àwọn àtọmọdọ́mọ wọn pípé kún orí ilẹ̀ ayé kùnà nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Àti pé “Ọlọ́run kò dà bí èèyàn . . . Ohunkóhun tó bá ṣèlérí rẹ̀ ló máa ń ṣe; ó sọ̀rọ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀.”—Númérì 23:19, Today’s English Version.
Nínú ọgbọ́n rẹ̀ pípé, Jèhófà Ọlọ́run pinnu láti gba ọ̀tẹ̀ náà láyè kó máa bá a lọ fún ìwọ̀nba àkókò díẹ̀. Èyí fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ní àǹfààní tó pọ̀ tó láti rí ipa tí òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní lórí wọn. Bí nǹkan ṣe ń lọ sí lórí ilẹ̀ ayé fi bí ọmọ aráyé ṣe nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tó hàn, ó sì fi bí ìṣàkóso Ọlọ́run ṣe lọ́lá ju ti ènìyàn tàbí ti Sátánì lọ hàn. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Ọlọ́run gbé ìgbésẹ̀ láti rí i dájú pé ète tí òun fi dá ilẹ̀ ayé nímùúṣẹ. Ó ṣèlérí pé “irú ọmọ” kan, tàbí “ọmọ” kan yóò wá, tí yóò ‘fọ́ Sátánì ní orí,’ tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú gbogbo ọ̀tẹ̀ àti àwọn ipa búburú tó ní kúrò pátápátá.— Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
Jésù Kristi ni Irú Ọmọ tá a ṣèlérí náà. A kà á nínú 1 Jòhánù 3:8 pé, a “fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere . . . láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” Ó ṣe èyí nípa fífi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ ó sì fi san owó ìràpadà láti tún àwọn ọmọ Ádámù rà padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n jogún. (Jòhánù 1:29; 1 Tímótì 2:5, 6) Àwọn tó dìídì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù la ṣèlérí ìtura pípẹ́ títí kúrò nínú ìjìyà fún. (Jòhánù 3:16; Ìṣípayá 7:17) Ìgbà wo lèyí máa ṣẹlẹ̀?
Ìjìyà Dópin
Kíkọ ọlá àṣẹ Ọlọ́run sílẹ̀ ti fa ìjìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Ó bójú mu nígbà náà pé kí Ọlọ́run lo ọlá àṣẹ rẹ̀ lọ́nà àkànṣe láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé, kó sì mú ète tó fi dá ilé ayé níbẹ̀rẹ̀ ṣẹ. Jésù mẹ́nu kan ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí nígbà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, . . . kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Àkókò tí Ọlọ́run fi fàyè gba ẹ̀dá ènìyàn láti ṣàkóso ara wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914, ó sì fi Jésù Kristi ṣe Ọba rẹ̀.b Láìpẹ́, yóò fọ́ gbogbo ìjọba ènìyàn túútúú, yóò sì fòpin sí wọn.—Dáníẹ́lì 2:44.
Láàárín àkókò díẹ̀ tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ káwọn èèyàn tọ́ díẹ̀ wò lára àwọn ìbùkún tí ìṣàkóso Ọlọ́run yóò mú wá fún ìran ènìyàn. Àwọn ìwé Ìhìn Rere fi ẹ̀rí hàn pé Jésù fi àánú hàn sí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí kò rí já jẹ tá à ń pọ́n lójú. Ó mú aláìsàn lára dá, ó bọ́ àwọn tébi ń pa, ó sì jí òkú dìde. Àwọn ipá ìṣẹ̀dá pàápàá ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. (Mátíù 11:5; Máàkù 4:37-39; Lúùkù 9:11-16) Fojú inú wo ohun tí Jésù máa ṣe nígbà tó bá lo agbára ìwẹ̀mọ́ ẹbọ ìràpadà rẹ̀ láti ṣe gbogbo aráyé onígbọràn láǹfààní! Bíbélì ṣèlérí pé nípasẹ̀ ìṣàkóso Kristi, Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [ọmọ aráyé], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.
Ìtùnú fún Àwọn Tó Ń Jìyà
Ẹ wo bó ṣe ń múni lọ́kàn yọ̀ tó láti mọ̀ pé Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ àti alágbára gbogbo bìkítà fún wa àti pé yóò mú ìtura wá fún ìran ènìyàn láìpẹ́! Gẹ́gẹ́ bó ṣe sábà máa ń rí, tinútinú ni ẹni tó ń ṣàìsàn líle fi ń gba ìtọ́jú tí yóò mú un lára dá, kódà bí ìtọ́jú náà tiẹ̀ jẹ́ èyí tó ń roni lára gógó. Bákan náà, tá a bá mọ̀ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bójú tó àwọn ọ̀ràn yóò mú ìbùkún ayérayé wá, ìmọ̀ yẹn lè mú ẹsẹ̀ wa dúró láìfi ìṣòro èyíkéyìí tá a lè dojú kọ pè.
Ricardo tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ láti máa gba ìtùnú látinú àwọn ìlérí inú Bíbélì. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí ìyàwó mi kú, ńṣe ló ń ṣe mi bíi pé kí n ṣáà máa dá nìkan wà, àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi wá mọ̀ pé èyí kò ní dá ìyàwó mi padà àti pé inú mi yóò túbọ̀ máa bà jẹ́ sí i ni.” Dípò ìyẹn, Ricardo wá túbọ̀ mú wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé lọ́kùn-únkún-dùn, ó sì ń kópa nínú sísọ ìhìn inú Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn. Ricardo sọ pé: “Bí mo ṣe ń rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, tí mo sì ń kíyè sí bó ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà mi nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké, mo wá túbọ̀ sún mọ́ ọn. Mímọ̀ tí mo wá mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi yìí ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi lè fara da àdánwò bíburú jù lọ tó tíì bá mi rí.” Ó sọ pé: “Àárò ìyàwó mi ṣì máa ń sọ mi gan-an, àmọ́ mo ti wá mọ̀ dájú pé kò sí ohunkóhun tí Jèhófà gbà pé kó ṣẹlẹ̀ tó lè fa ìpalára ayérayé fún wa.”
Ǹjẹ́ ìwọ náà, bíi ti Ricardo àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn mìíràn ń wọ̀nà fún àkókò tí ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé nísinsìnyí “kì yóò . . . wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ohun tí ọwọ́ rẹ kò lè tẹ̀ tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.”—Aísáyà 55:6.
Ohun tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí ni pé kó o fi kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ. Gbìyànjú láti mọ Ọlọ́run àti ẹni tí ó rán wá sórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn Jésù Kristi. Sapá láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé o múra tán láti fi ara rẹ̀ sábẹ́ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀ yóò mú ayọ̀ púpọ̀ wá fún ọ nísinsìnyí láìka àwọn àdánwò tó o lè dojú kọ sí. Nígbà tó bá sì di ọjọ́ iwájú, yóò yọrí sí gbígbádùn ìgbésí ayé nínú ayé kan téèyàn ò ti ní jìyà mọ́.—Jòhánù 17:3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tá a ṣe lórí Jẹ́nẹ́sísì 2:17 nínú The Jerusalem Bible sọ pé “ìmọ̀ rere àti búburú” jẹ́ “agbára láti pinnu . . . ohun tó jẹ́ rere àti ohun tó jẹ́ ibi, kéèyàn sì ṣe èyí tí ó tọ́, ó jẹ́ níní òmìnira pátápátá, èyí tó mú kí ènìyàn gbàgbéra pé ẹnì kan ló dá a.” Ó fi kún un pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ gbígbéjàko ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.”
b Fún àlàyé kíkún rẹ́rẹ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú ọdún 1914, wo orí 10 àti 11 nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
BÁWO LA ṢE LÈ FARA DA ÌJÌYÀ?
“Kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run].” (1 Pétérù 5:7) Ńṣe ni ọkàn wa máa ń dà rú, tínú máa ń bí wa, tó sì máa ń ṣe wá bíi pé àwọn èèyàn ti pa wá tì, nígbà tá a bá wà nínú ìpọ́njú tàbí tá a rí èèyàn wa kan tó ń jìyà. Síbẹ̀, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà lóye bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára wa. (Ẹ́kísódù 3:7; Aísáyà 63:9) Bíi ti àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì, a lè ṣí ọkàn wa payá fún un ká sì sọ àwọn ohun tó ń kọ wá lóminú àti àníyàn wa fún un. (Ẹ́kísódù 5:22; Jóòbù 10:1-3; Jeremáyà 14:19; Hábákúkù 1:13) Ó lè máà mú àwọn àdánwò wa kúrò lọ́nà ìyanu o, àmọ́ ó lè fún wa ní ọgbọ́n àti okun láti kojú wọn, ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà àtọkànwá wa.—Jákọ́bù 1:5, 6.
“Má ṣe jẹ́ kí àdánwò líle koko tó dé bá ọ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ, bí ẹni pé ohun àjèjì kan ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọ.” (1 Pétérù 4:12, New International Version) Ọ̀rọ̀ nípa inúnibíni ni Pétérù ń sọ níhìn-ín, àmọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún ní í ṣe pẹ̀lú ìpọ́njú èyíkéyìí tí onígbàgbọ́ kan lè máa fara dà. Ara ohun tọ́mọ aráyé ń fojú winá rẹ̀ ni ipò àìní, àìsàn, àti ikú èèyàn ẹni. Bíbélì sọ pé, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ló ń ṣẹlẹ̀ sí olúkúlùkù wa. (Oníwàásù 9:11) Irú nǹkan wọ̀nyí làwọn èèyàn ń bá yí lóde òní. Mímọ̀ tá a mọ èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìyà tàbí wàhálà tó bá dé bá wa. (1 Pétérù 5:9) Lékè gbogbo rẹ̀, rírántí ìdánilójú náà pé “ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́” yóò jẹ́ orísun ìtùnú fún wa.—Sáàmù 34:15; Òwe 15:3; 1 Pétérù 3:12.
“Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí.” (Róòmù 12:12) Dípò ká máa fi gbogbo ìgbà ro àròkàn nípa bínú wa ṣe máa ń dùn látijọ́, a lè máa ṣàṣàrò lórí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti fòpin sí gbogbo ìjìyà. (Oníwàásù 7:10) Ìrètí tó fìdí múlẹ̀ yìí yóò dáàbò bò wá bí àṣíborí ṣe máa ń dáàbò bo orí. Ńṣe ni ìrètí máa ń pẹ̀rọ̀ sí hílàhílo ìgbésí ayé tó sì máa ń mú un dá wa lójú pé àwọn ìṣòro tá a ní ò lè fa ìpalára ayérayé fún ìlera wa, yálà ní ti ìrònú, ní ti ìmọ̀lára, tàbí nípa tẹ̀mí.—1 Tẹsalóníkà 5:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ádámù àti Éfà kọ ìṣàkóso Ọlọ́run sílẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọlọ́run ṣèlérí ayé kan téèyàn ò ti ní jìyà mọ́