Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ǹjẹ́ Ẹ̀ Ń múra Sílẹ̀ Fún Ọjọ́ Ọ̀la?
“Èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín, . . . àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.”—JEREMÁYÀ 29:11.
1, 2. Oríṣi ọ̀nà wo la lè gbà wo ìgbà èwe?
OJÚ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti dàgbà fi máa ń wo ìgbà èwe ni pé ó jẹ́ àkókò alárinrin. Wọ́n rántí bí agbára àwọn ṣe rí àti bí àwọn ṣe ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri nígbà táwọn wà lọ́dọ̀ọ́. Wọ́n ronú kan ìgbà táwọn ò tíì ní bùkátà táwọn ń gbọ́, ìyẹn ìgbà tí ọ̀pọ̀ nǹkan amóríyá wà fún wọn láti ṣe, tí àǹfààní jaburata sì ń bẹ fún wọn lọ́jọ́ iwájú.
2 Ojú tí ẹ̀yin ọ̀dọ́ fi ń wo ìgbà èwe lè yàtọ̀ síyẹn. Ó lè máà rọrùn fún yín láti kojú àwọn ìyípadà inú ara tó ń bá ìgbà ọ̀dọ́ rìn. Àwọn ọmọ iléèwé rẹ lè fẹ́ tì ọ́ láti máa hu irú ìwà tí wọ́n ń hù. Ó gba pé kó o sapá gidigidi láti yẹra fún oògùn olóró, ọtí àmujù, àti ìṣekúṣe. Ọ̀pọ̀ lára yín ló ń dojú kọ ìṣòro nítorí àìdásí-ọ̀ràn ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tàbí àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ yín. Dájúdájú, ìgbà èwe jẹ́ àkókò tí ó ṣòro gan-an. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nígbà èwe. Ìbéèrè náà ni pé, Báwo ni wàá ṣe lo àwọn àǹfààní náà?
Gbádùn Ìgbà Èwe Rẹ
3. Ìmọ̀ràn àti ìkìlọ̀ wo ni Sólómọ́nì fún àwọn ọ̀dọ́?
3 Tí àwọn àgbà bá sọ pé ìgbà èwe kì í wà lọ títí, wọn ò purọ́ o. Ká tó rí ọdún bíi mélòó kan, àgbà á ti dé. Torí náà, gbádùn ìgbà èwe rẹ nísinsìnyí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́! Ìmọ̀ràn Sólómọ́nì Ọba nìyẹn nígbà tó kọ̀wé pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí.” Àmọ́ ṣá o, Sólómọ́nì kìlọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ pé: “Mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ.” Láfikún sí i, ó sọ pé: “Asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé.”—Oníwàásù 11:9, 10.
4, 5. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìwà ọgbọ́n pé káwọn ọ̀dọ́ múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la? Ṣàpèjúwe.
4 Ǹjẹ́ ohun tí Sólómọ́nì sọ yé ọ? Láti ṣàpèjúwe ohun tó sọ, ìwọ wo ọ̀dọ́ kan tó rí ẹ̀bùn ńlá kan gbà, bóyá ńṣe ló jogún owó. Kí ló máa fowó ọ̀hún ṣe? Ó lè ná gbogbo owó náà nínàákúnàá, kó fi gbádùn ara ẹ̀ bíi ti ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù. (Lúùkù 15:11-23) Kí ló máa wá ṣe tówó náà bá tán? Á mà kábàámọ̀ ìwà àpà tó hù yìí o! Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà á yàtọ̀ ká ní ó fi ẹ̀bùn náà múra sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú, bóyá kó fi èyí tó pọ̀ jù lára owó ọ̀hún ṣe nǹkan ire. Nígbà tó bá wá ń jèrè nǹkan tó ti fowó náà ṣe, ǹjẹ́ o rò pé ó máa kábàámọ̀ pé òun kò fi gbogbo owó ọ̀hún jayé nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́? Rárá o, kò ní kábàámọ̀ kankan!
5 Máa wo ìgbà èwe rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí pé lóòótọ́ ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Báwo ni wàá ṣe lo ẹ̀bùn yìí? O lè lo gbogbo okun rẹ àti agbára rẹ dànù sórí ayé jíjẹ, kó o kàn máa jayé ṣáá láìmúra sílẹ̀ fọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, “asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé” rẹ yóò jásí. Á mà dára gan-an o tó o bá fi ìgbà èwe rẹ múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la!
6. (a) Ìmọ̀ràn Sólómọ́nì wo ló lè tọ́ àwọn ọ̀dọ́ sọ́nà? (b) Kí ni Jèhófà fẹ́ ṣe fáwọn ọ̀dọ́, báwo sì ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè jàǹfààní látinú èyí?
6 Sólómọ́nì sọ ìlànà kan tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lo ìgbà èwe rẹ lọ́nà tó dára jù lọ. Ó sọ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníwàásù 12:1) Ohun tó máa jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí gan-an nìyẹn, kí o fetí sí Jèhófà kí o sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Jèhófà sọ ohun tóun fẹ́ ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì fún wọn, ó ní: “Èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín ní àmọ̀dunjú, . . . àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Jeremáyà 29:11) Jèhófà yóò fẹ́ láti fún ìwọ náà ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” Tó o bá ń rántí Jèhófà nínú ohun tó ò ń ṣe, nínú èrò rẹ àti ìpinnu rẹ, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóò dára wàá sì rí ìrètí náà gbà.—Ìṣípayá 7:16, 17; 21:3, 4.
“Sún Mọ́ Ọlọ́run”
7, 8. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?
7 Jákọ́bù fún wa níṣìírí láti rántí Jèhófà nígbà tó rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ ọ̀run, ẹni tí gbogbo ìjọsìn àti ìyìn tọ́ sí. (Ìṣípayá 4:11) Síbẹ̀, tá a bá sún mọ́ ọn, òun náà yóò sún mọ́ wa. Ǹjẹ́ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kò mú inú rẹ dùn?—Mátíù 22:37.
8 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà, kí ẹ máa wà lójúfò nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́.” (Kólósè 4:2) Ohun tó ń sọ ni pé kó o sọ àdúrà gbígbà dàṣà. Má kàn gbà pé ṣíṣe àmín sí àdúrà bàbá rẹ tàbí ti àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni nínú ìjọ ti tó. Ǹjẹ́ o tíì sọ gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ fún Jèhófà rí, kó o sọ èrò rẹ àtohun tó ń bà ọ́ lẹ́rù, títí kan ìṣòro rẹ fún un? Ǹjẹ́ o tíì sọ ohun tó máa tì ọ́ lójú láti sọ fún ẹnikẹ́ni fún un rí? Àdúrà àtọkànwá máa ń fini lọ́kàn balẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà ká sì rí i pé òun náà ń sún mọ́ wa.
9. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè fetí sí Jèhófà?
9 Ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà sún mọ́ Jèhófà la rí nínú ọ̀rọ̀ onímìísí náà pé: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.” (Òwe 19:20) Bẹ́ẹ̀ ni, tó o bá fetí sí Jèhófà, tó o sì ṣègbọràn sí i, ọjọ́ ọ̀la lò ń múra sílẹ̀ fún yẹn. Báwo ló ṣe lè fi hàn pé ò ń ṣègbọràn sí Jèhófà? Ó dájú pé ò ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, o sì ń tẹ́tí sáwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé. O tún ń “bọlá fún baba rẹ àti ìyà rẹ” nípa wíwà níbẹ̀ nígbà tí ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ nínú ìdílé. (Éfésù 6:1, 2; Hébérù 10:24, 25) Ìyẹn dára gan-an ni. Àmọ́, láfikún sí ìyẹn, ǹjẹ́ ò ń ‘ra àkókò padà’ láti múra àwọn ìpàdé sílẹ̀, láti ka Bíbélì déédéé àti láti ṣe ìwádìí? Ǹjẹ́ ò ń fi àwọn ohun tó ò ń kà ṣèwà hù kó o bàa lè máa rín gẹ́gẹ́ bí ‘ọlọ́gbọ́n’? (Éfésù 5:15-17; Sáàmù 1:1-3) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń sún mọ́ Jèhófà nìyẹn.
10, 11. Àǹfààní ńlá wo ló wà fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n bá fetí sí Jèhófà?
10 Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Òwe, òǹkọ̀wé tí Ọlọ́run mí sí láti kọ ìwé náà ṣàlàyé ohun tí ìwé Bíbélì náà wà fún. Ó sọ pé, ó wà “fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí, láti fi òye mọ àwọn àsọjáde òye, láti gba ìbáwí tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye, òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, láti fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà, láti fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.” (Òwe 1:1-4) Nítorí náà, bó o ṣe ń ka ìwé Òwe, àti gbogbo ìwé inú Bíbélì, tó o sì fi ń ṣèwà hù, òdodo rẹ yóò máa pọ̀ sí i, wàá di ẹni tó dúró ṣánṣán, inú Jèhófà á sì dùn pé o sún mọ́ òun. (Sáàmù 15:1-5) Bó o ṣe túbọ̀ ń fi ojú tó tọ́ wo nǹkan, tí ò ń fọgbọ́n hùwà, tó o sì ń lo ìmọ̀ àti agbára ìrònú rẹ lọ́nà tó dára sí i, wàá lè máa ṣe ìpinnu tó dára.
11 Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí ọ̀dọ́ kan máa hùwà ọgbọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bọ́gbọ́n mu, nítorí pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Kristẹni ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí èyí, àwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n ò sì ‘fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe wọn.’ (1 Tímótì 4:12) Àwọn òbí wọn ń fi wọ́n yangàn, Jèhófà náà sọ pé wọ́n ń mú ọkàn òun yọ̀. (Òwe 27:11) Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ ọ̀dọ́, wọ́n lè ní ìfọkànbalẹ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí yìí kàn àwọn, ọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán, nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà.”—Sáàmù 37:37.
Yan Ohun Tí Ó Tọ́
12. Kí ni ọ̀kan lára yíyàn pàtàkì táwọn ọ̀dọ́ máa ṣe, kí sì nìdí tí àbájáde rẹ̀ kì í tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀?
12 Ìgbà èwe jẹ́ àkókò láti ṣe àwọn yíyàn kan, àbájáde òmíràn lára àwọn yíyàn náà kì í sì í tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀. Àwọn yíyàn kan tó o bá ṣe nísinsìnyí yóò nípa lórí rẹ lọ́jọ́ iwájú. Yíyàn tí ó tọ́ máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹni láyọ̀ kó sì dára. Yíyàn tí kò tọ́ lè ba ìgbésí ayé ẹni jẹ́. Gbé bí ìyẹn ṣe jóòótọ́ yẹ̀ wò nínú yíyàn méjì kan tí wàá ṣe. Ìkínní: Ta lẹni tó ò ń bá kẹ́gbẹ́? Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Tóò, òwe tí Ọlọ́run mí sí náà sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Téwé bá pẹ́ lára ọṣẹ á di ọṣẹ, ìyẹn ni pé a óò dá bí àwọn tá à ń bá rìn, wọn ì báà jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí arìndìn. Irú èèyàn wo ló fẹ́ jẹ́ nínú méjèèjì?
13, 14. (a) Yàtọ̀ sí bíbá àwọn èèyàn kẹ́gbẹ́ ní tààràtà, ọ̀nà mìíràn wo la tún lè gbà kẹ́gbẹ́? (b) Àṣìṣe wo ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ yẹra fún?
13 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ kíkó, ó lè jẹ́ pé wíwà pẹ̀lú àwọn èèyàn nìkan ló máa wá sí ọ lọ́kàn. Òótọ́ nìyẹn náà, àmọ́ ẹgbẹ́ kíkó ò mọ sí wíwà pẹ̀lú àwọn èèyàn nìkan o. Nígbà tó o bá ń wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, tó ò ń tẹ́tí sí orin lórí rédíò, tó ò ń ka ìwé ìtàn àròsọ, tó o ń lọ wo sinimá tàbí tó ò ń yẹ ìsọfúnni wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn kan lò ń bá kẹ́gbẹ́ yẹn. Tí irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ bá ń gbé ìwà ipá, oògùn olóró, ọtí àmujù tàbí ohunkóhun tó ta ko ìlànà Bíbélì lárugẹ, á jẹ́ pé àwọn “òpònú” tó ń hùwà bí ẹni pé Jèhófà kò tiẹ̀ sí lò ń bá kẹ́gbẹ́ yẹn.—Sáàmù 14:1.
14 O lè máa rò pé níwọ̀n bó o ti ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni tó o sì ń ṣe dáadáa nínú ìjọ, kò ní ṣe ọ́ ní nǹkan kan tó o bá ń wo àwọn eré oníwà ipá tàbí tẹ́tí sí àwo orin tó ní ohun orin tó dára àmọ́ tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò sunwọ̀n. O lè máa rò pé kò sí nǹkan búburú tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá ń bẹjú wo àwòrán arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ńṣe lò ń tan ara rẹ jẹ! Ó sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Kristẹni tó ń ṣe dáadáa ló ti ba ìwà rere wọn jẹ́ nípasẹ̀ ẹgbẹ́ búburú. Nítorí náà, yẹra fún irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, tó sọ pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:2.
15. Kí ni yíyàn kejì táwọn ọ̀dọ́ kò lè yẹ̀ sílẹ̀, ìṣòro wo ni èyí máa ń fà nígbà mìíràn?
15 Yíyàn kejì táwọn ọ̀dọ́ kò lè yẹ̀ sílẹ̀ rèé. Ìgbà kan ń bọ̀ tí wàá yan ohun tó o fẹ́ ṣe nígbà tó o bá parí ilé ìwé. Tó bá jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí kò ti fi bẹ́ẹ̀ sí iṣẹ́ lò ń gbé, tó bá wá jàjà rí ọ̀kan tó dára, ó lè fẹ́ bẹ́ mọ́ ọn. Tó o bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè tí nǹkan tí rọ̀ṣọ̀mù, ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ pọ̀ téèyàn lè ṣe, lára àwọn iṣẹ́ ọ̀hún sì lè kóni sínú ìdẹwò. Àwọn olùkọ́ rẹ tàbí òbí rẹ lè ní ire rẹ lọ́kàn. Wọ́n lè sọ fún ọ pé kó o kàwé tí wàá fi ríṣẹ́ tó jọjú láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ. Kódà wọ́n lè fẹ́ kó o kàwé tí wàá fi ríṣẹ́ tó máa sọ ẹ́ dọlọ́rọ̀ pàápàá. Àmọ́, tó o bá lọ ka irú ìwé bẹ́ẹ̀, ó lè dín àkókò tó yẹ kó o máa fi sin Jèhófà kù.
16, 17. Ṣàlàyé bí onírúurú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ṣe lè ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti ní èrò tó yẹ nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́?
16 Rántí láti kọ́kọ́ yẹ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn kan wò kó o tó ṣe ìpinnu. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣiṣẹ́ ká lè máa gbọ́ bùkátà ara wa. (2 Tẹsalóníkà 3:10-12) Síbẹ̀, àwọn nǹkan mìíràn tún wé mọ́ yíyan irú iṣẹ́ téèyàn fẹ́ ṣe. Nítorí náà, a gbà ọ́ níyànjú pé kó o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò sínú ìpínrọ̀ yìí, kó o sì ronú lórí bí àwọn ẹsẹ náà ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ọ̀ràn yíyan iṣẹ́: Òwe 30:8, 9; Oníwàásù 7:11, 12; Mátíù 6:33; 1 Kọ́ríńtì 7:31; 1 Tímótì 6:9, 10. Nígbà tó o ka àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn, ǹjẹ́ o rí èrò Jèhófà nípa ọ̀ràn náà?
17 Kò yẹ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ jẹ wá lógún débi pé a óò wá fi ṣáájú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. Tó o bá lè fi ilé ẹ̀kọ́ girama tó o kà ríṣẹ́ kan tó tẹ ọ lọ́rùn, ìyẹn náà ò burú. Tó o bá sì fẹ́ kàwé sí i lẹ́yìn tó o ti parí ilé ẹ̀kọ́ girama, kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ sọ ọ́. Àmọ́, má ṣe gbàgbé “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” ìyẹn àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Fílípì 1:9, 10) Má sì ṣe ṣe irú àṣìṣe tí Bárúkù, akọ̀wé Jeremáyà ṣe. Kò fi ọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí “wá àwọn ohun ńláńlá fún ara [rẹ̀].” (Jeremáyà 45:5) Nígbà kan, kò tiẹ̀ rántí pé kò sí ‘ohun ńlá’ èyíkéyìí nínú ayé yìí tó lè mú òun sún mọ́ Jèhófà sí i tàbí tó máa jẹ́ kóun la ìparun Jerúsálẹ́mù já. Tá ò bá ṣọ́ra irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí àwa náà lónìí.
Mọrírì Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
18, 19. (a) Kí ni ohun tó ń jẹ ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń bẹ lágbègbè rẹ̀ níyà, báwo ló sì ṣe yẹ kí ipò wọn rí lára rẹ? (b) Kí nìdí tí ebi tẹ̀mí kì í pa ọ̀pọ̀ èèyàn?
18 Ǹjẹ́ o ti rí àwòrán àwọn ọmọdé tí ń bẹ làwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ò rí oúnjẹ jẹ nígbà tó ò ń wo tẹlifíṣọ̀n tàbí tó ò ń ka ìwé ìròyìn? Tó o bá ti rí wọn rí, ó dájú pé àánú wọn ṣe ọ́. Ǹjẹ́ àánú àwọn tó wà lágbègbè rẹ ń ṣe ọ́? Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa káàánú wọn? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn lò ń ráágó. Wọ́n wà nínú ìyàn ohun tí Ámósì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “‘Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’”—Ámósì 8:11.
19 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń ráágó nípa tẹ̀mí yìí ni “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí [kò] . . . jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ebi tẹ̀mí kì í pa. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa rò pé àwọn ti jẹun yó nípa tẹ̀mí. Àní bí wọ́n tiẹ̀ yó, èyí jẹ́ nítorí fífi tí wọ́n ń fi “ọgbọ́n ayé” tí kò wúlò bọ́ ara wọn, lára rẹ̀ sí ni ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìméfò tá a gbé ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, oríṣiríṣi èrò nípa ìwà híhù àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. Àwọn kan rò pé “ọgbọ́n” tó wà lóde òní tí sọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì di aláìbágbàmu mọ́. Àmọ́, “ayé nípasẹ̀ ọgbọ́n tirẹ̀ kò mọ Ọlọ́run.” Ọgbọ́n ayé yìí kò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ó jẹ́ “òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 1:20, 21; 3:19.
20. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti máa fara wé àwọn tí kò jọ́sìn Jèhófà?
20 Nígbà tó o bá wo àwòrán àwọn ọmọdé tébi ń pá, ǹjẹ́ ó wù ọ́ kó o rí bíi tiwọn? Rárá o! Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ kan nínú agbo ilé Kristẹni fẹ́ láti dà bí àwọn tí ń bẹ lágbègbè wọn, ìyẹn àwọn tí ń ráágó nípa tẹ̀mí. Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ máa rò pé àwọn ọ̀dọ́ ayé wà lómìnira, pé inú ìgbádùn kẹlẹlẹ ni wọ́n wà. Wọ́n ti gbàgbé pé àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyẹn ti di àjèjì sí Jèhófà. (Éfésù 4:17, 18) Wọ́n tún ti gbàgbé ohun búburú tó máa ń tìdí àìjẹun nípa tẹ̀mí jáde. Lára àbájáde búburú náà ni oyún ẹ̀sìn àtàwọn ìṣòro tí ìṣekúṣe, sìgá mímu, ọtí àmujù àti lílo oògùn olóró máa ń dá síni lára. Àìjẹun nípa tẹ̀mí máa ń fa ẹ̀mí ọ̀tẹ̀, àìnírètí, ó sì máa ń mú kí ìgbésí ayé ẹni dojú rú.
21. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa tá ò fi ní ní ẹ̀mí tí kò dára táwọn tí kì í jọ́sìn Jèhófà ní?
21 Nítorí náà, nígbà tó o bá wà láàárín àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà ní iléèwé, má ṣe jẹ́ kí ìwà wọn nípa lórí rẹ. (2 Kọ́ríńtì 4:18) Àwọn kan lára wọn yóò máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn pàápàá yóò máa gbé irọ́ jáde, wọ́n á máa dọ́gbọ́n sọ pé kò burú láti ṣèṣekúṣe, láti mutí para tàbí láti máa sọ ìsọkúsọ. Má ṣe gba ẹ̀mí yìí láyè o. Máa bá a lọ láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn tó ń “di ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere mú,” kí o sì “máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Tímótì 1:19; 1 Kọ́ríńtì 15:58) Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí nínú iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Láàárín àkókò tó o ṣì wà nílé ìwé, máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà. Máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn láti lè mú kí ọ̀nà tó o ń gbà wo nǹkan tẹ̀mí túbọ̀ dára sí i, o ò sì ní kọsẹ̀.—2 Tímótì 4:5.
22, 23. (a) Kí ló lè mú kí ọ̀dọ́ Kristẹni kan ṣe yíyàn tí ò ní yé àwọn ẹlòmíràn? (b) Kí la gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe?
22 Nítorí ojú tẹ̀mí tó o fi ǹ wo nǹkan, o lè ṣe àwọn ìpinnu kan táwọn ẹlòmíràn kò ní lóye. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ Kristẹni kan lẹ́bùn orin gan-an, gbogbo iṣẹ́ iléèwé ló sì mọ̀ dójú àmì. Nígbà tó gboyè jáde nílé ìwé, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá bàbá rẹ̀ ṣíṣẹ́ fèrèsé fífọ̀ kó lè rí àyè fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ìdí tí ọ̀dọ́kùnrin yìí fi ṣe ìpinnu yẹn ò yé olùkọ́ rẹ̀ rárá, àmọ́ tó o bá ti sún mọ́ Jèhófà, ó dájú pé wàá lóye rẹ̀.
23 Bó o ṣe ń ronú nípa bí wàá ṣe lo ìgbà èwe rẹ tó ṣeyebíye, ‘máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara rẹ de ẹ̀yìn ọ̀la, kí o lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.’ (1 Tímótì 6:19) Pinnu láti “rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá” ní ìgbà èwe rẹ, àní títí jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Ìyẹn nìkan ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti gbà múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la aláṣeyọrísírere, àní ọjọ́ ọ̀la kan tí kì yóò dópin láé.
Kí Ni Èrò Rẹ?
• Ìmọ̀ràn onímìísí wo ló ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ lè gbà “sún mọ́ Ọlọ́run”?
• Kí ni díẹ̀ lára ìpinnu tí ọ̀dọ́ kan lè ṣe tí yóò kan ọjọ́ ọ̀la rẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ṣé wàá jẹ́ káwọn nǹkan tara tó ò ń lépa tán ọ lókun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tó gbọ́n máa ń jẹ́ kí ojú wọn tẹ̀mí ríran kedere