Ogún Ṣíṣeyebíye Jù Lọ
NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí àpọ́sítélì Jòhánù tó jẹ́ arúgbó kú, ó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòhánù 4.
Àpọ́sítélì olóòótọ́ yìí ń sọ̀rọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ òbí ni yóò sọ irú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì yìí sọ nípa àwọn ọmọ wọn. Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ àṣekára láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” inú wọn sì ń dùn nísinsìnyí bí wọ́n ṣe ń rí àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ‘ń rìn nínú òtítọ́.’ (Éfésù 6:4) Ní ti tòótọ́, kíkọ́ ọmọ ẹni ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè ayérayé ni ogún ṣíṣeyebíye jù lọ. Ìdí ni pé ìfọkànsin Ọlọ́run tó kan irú ìgbésí ayé tí Jèhófà fẹ́ káwọn Kristẹni máa gbé, “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.”—1 Tímótì 4:8.
Inú Jèhófà, Baba pípé, máa ń dùn sí àwọn òbí tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti fi nǹkan tẹ̀mí kọ́ àwọn ọmọ wọn. Nígbà táwọn ọmọ bá sì gba ẹ̀kọ́ yìí, inú wọn á máa dùn pé àwọn àtàwọn òbí àwọn jọ ń ṣe ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ bá dàgbà, wọn ò ní gbàgbé gbogbo ohun rere tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Tayọ̀tayọ̀ làwọn kan máa ń rántí ìgbà àkọ́kọ́ táwọn níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.a Tàbí kí wọ́n ronú kan ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ ka ẹsẹ Bíbélì kan lóde ẹ̀rí nígbà tí wọ́n bá ọ̀kan lára àwọn òbí wọn jáde. Báwo ni wọ́n ṣe lè gbàgbé kíkà táwọn òbí wọn máa ń ka Iwe Itan Bibeli Mi tàbí ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na sí wọn létí nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé?b Gabriel rántí ohun kan tó fẹ́ràn gan-an, ó ní: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin péré, ojoojúmọ́ ni màmá mi máa ń kọrin fún mi tó bá ń se oúnjẹ. Orí mi ṣì máa ń wú nígbà tí mo bá rántí orin Ìjọba Ọlọ́run kan tó máa ń kọ fún mi. Nígbà tó ṣe, orin yẹn wá ràn mí lọ́wọ́ láti rí ìjẹ́pàtàkì ìṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà rántí orin alárinrin tí Gabriel ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí. Orin 157 nínú ìwé orin Kọrin Ìyìn sí Jehofah ni, àkọlé rẹ̀ ni “Sìn Jehofah Nigba Èwe.”
Bí orin náà ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé: “Ìyìn jade lẹnu àwọn èwe;/Wọn ńfi ohùn wọn yin Jesu l’ọba.” Láìsí àní-àní, àwọn ọmọ kan wà tí wọ́n láǹfààní láti bá Jésù kẹ́gbẹ́, ó sì ṣeé ṣe kí ìṣe wọn tó tuni lára tó sì jẹ ti aláìlẹ́tàn máa múnú rẹ̀ dùn. Jésù pàápàá lo ọ̀nà táwọn ọmọdé fi dùn ún kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nínú àpẹẹrẹ kan tó sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa fara wé. (Mátíù 18:3, 4) Nítorí náà, àwọn ọmọdé ní ipò tiwọn nínú ìjọsìn Jèhófà. Àní àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà tún sọ pé: “Awọn èwe le gb’Ọlọrun wọn ga.”
Ọ̀pọ̀ èwe ló ti mú ìyìn wá fún Ọlọ́run àti ìdílé wọn nípasẹ̀ ìwà wọn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ilé, nílé ìwé, àti láwọn ibòmíràn. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún wọn láti ní “Awọn obi Kristian tó fẹ́ ootọ.” (Diutarónómì 6:7) Àwọn òbí tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run ń ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ, ẹni tó jẹ́ pé bíi Baba onífẹ̀ẹ́ ló ṣe ń kọ́ àwọn ẹ̀dá rẹ̀ láti rìn ní ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa tọ̀. Ìbùkún ńlá làwọn náà sì ń rí gbà! Bí àwọn náà sì tún ṣe ń kọ́ àwọn èwe tó wà nínú ìdílé, ẹ wo bí inú wọn ṣe ń dùn pé àwọn ní àwọn ọmọ tó ń “gbọ́ wọn, mu wọn layọ”! (Aísáyà 48:17, 18) Angélica, tó ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò sọ pé: “Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi máa ń sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Ìyẹn ló mú kí ìgbà èwe mi lárinrin gan-an. Inú mi sì dùn.”
Irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ gbà pé ó tọ́, ó sì yẹ láti tọ́jú ogún tẹ̀mí téèyàn ní. Bóyá o jẹ́ ọ̀dọ́ kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé kan tó ní ìlànà Kristẹni tòótọ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, orin kan náà yẹn gbà ọ́ níyànjú pé: “Ẹyin èwe Kristian m’ọna yin mọ́.” Àkókò tí ìwọ náà yóò máa dá ṣe ìpinnu ń bọ̀, ní báyìí ná “kọ́ lati gbẹkẹle Jah ní èwe./Maṣe du okiki ayé rara.”
Tó o bá lọ ṣèèsì fi jíjẹ́ olókìkì ṣe ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀, gbogbo ẹ̀kọ́ tó o ti gbà lè já sí asán, o sì lè pàdánù gbogbo ohun tó ò ń retí ní ọjọ́ iwájú. Fífẹ́ láti di olókìkì lè máà jẹ́ kó o wà lójúfò mọ́. Àwọn kan ti bá ọ̀rọ̀ wọn dórí jíjẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn tí wọ́n dà bí èèyàn rere, kódà tí iṣé wọn wúni lórí, àmọ́ tí wọn kó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìlànà Kristẹni rárá. Ìyẹn la rí nínú ọ̀ràn Tara, tó kó ipa tó pọ̀ jù lọ nínú fídíò Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Bíi ti Tara, Kristẹni ọ̀dọ́ èyíkéyìí tó bá bá àwọn tí kò mọyì ìjọsìn tòótọ́ kẹ́gbẹ́ yóò rí i pé láìpẹ́ láìjìnnà “Ẹgbẹ buburu nba’wa rere jẹ́,” gẹ́gẹ́ bí orin náà ti sọ. Ó gba pé kéèyàn sapá fún ọ̀pọ̀ ọdún kó tó lè di ẹni tó ní ìwà rere, àmọ́ téèyàn ò bá ṣọ́ra ìwà yẹn lè bà jẹ́ lójú ẹsẹ̀.
Ká sòótọ́, kò rọrùn rárá láti gbé ìgbésí ayé tó fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí orin náà ṣe ń bá a lọ pé, “b’o ba ranti Ọlọrun rẹ l’ewe,/T’o sin Jehofah l’ẹmi àt’ootọ,” wàá fi ìpìlẹ̀ tó dára lélẹ̀ tí wàá fi ṣe àṣeyọrí. Àti pé “b’o ti ndagba sii ayọ̀ rẹ yoo pọ̀.” Wàá túbọ̀ wáá rí i pé lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà kò sí ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́ ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀. Béèyàn ṣe ń di àgbà tó dàgbà dénú tó sì bẹ̀rù Ọlọ́run nìyẹn. Láfikún sí i, fífi ọgbọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wà fún àwọn Kristẹni yóò fún ọ láǹfààní láti “mú’nú Ọlọrun maa dùn.” Àǹfààní wo lèèyàn tún lè ní tó máa ju ìyẹn lọ?—Òwe 27:11.
Nítorí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa rántí bí àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ̀ ń gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà àti látọ̀dọ̀ àwọn òbí yín tó jẹ Kristẹni ti ṣeyebíye tó. A bẹ̀bẹ̀ pé kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní fún yín sún yín láti ṣe ohun tó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà. Bíi ti Jésù Kristi àti Tímótì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ olóòótọ́, ẹ̀yin náà yóò máa múnú Bàbá yín ọ̀run àti ti àwọn òbí yín tó wà lórí ilẹ̀ ayé dùn. Bí ìwọ alára náà bá sì di òbí, ó ṣeé ṣe kó o fara mọ́ ohun tí Angélica tá a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀ wí, ẹni tó sọ pé: “Bí mo bá lè ní ọmọ tèmí láyé yìí, máa sa gbogbo ipá mi láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sí i lọ́kàn láti ìgbà ọmọ ọwọ́, màá sì jẹ́ kí ìfẹ́ yẹn jẹ́ ìmọ́lẹ̀ tó ń tọ́ ọ sọ́nà.” Dájúdájú, ọ̀nà títọ́ tó ń sinni lọ sí ìyè ayérayé ni ogún ṣíṣeyebíye jù lọ!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí tí à ń darí nínú àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé wà fún tọmọdé tàgbà.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ àwọn ìwé tá a mẹ́nu kan yìí jáde.