Ǹjẹ́ Wàá Gbé Ògo Ọlọ́run Yọ?
“A ń . . . ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 3:18.
1. Kí ni Mósè rí, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn náà?
ÌRAN tó ga jù lọ ni Mósè rí. Òun nìkan ló wà lórí Òkè Sínáì tó ga fíofío nígbà tí Jèhófà jẹ́ kó rí ohun àrà ọ̀tọ̀ tó lóun fẹ́ rí, ìyẹn ògo Jèhófà. Ohun tí ẹ̀dá èèyàn kankan ò rí rí ni. Mósè ò fojú rí Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣá o. Ìdí ni pé ògo Ọlọ́run pọ̀ débi pé ọmọ èèyàn tó bá fojú rí Ọlọ́run á kú. Ńṣe ni Jèhófà fi “àtẹ́lẹwọ́” bo Mósè láti fi dáàbò bò ó títí ó fi kọjá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé áńgẹ́lì ló ṣojú fún Ọlọ́run lásìkò yẹn. Jèhófà wá jẹ́ kí Mósè rí fìrífìrí ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ lẹ́yìn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lọ tán. Ó sì gbẹnu áńgẹ́lì bá Mósè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú. Bíbélì ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Ńlá Sínáì . . . awọ ojú [rẹ̀] ń mú ìtànṣán jáde nítorí bíbá tí [Jèhófà] bá a sọ̀rọ̀.”—Ẹ́kísódù 33:18–34:7, 29.
2. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé rẹ̀ nípa ògo táwọn Kristẹni ń gbé yọ?
2 Fojú inú wò ó pé ìwọ àti Mósè lẹ jọ wà lórí òkè yẹn. Nǹkan ìwúrí gbáà ló máa jẹ́ fún ọ pé o rí ògo Olódùmarè tó ń dán gbinrin àti pé o tún gbóhùn rẹ̀! Tiyì-tẹ̀yẹ ni wàá fi máa bá Mósè, alárinà májẹ̀mú Òfin, sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí Òkè Sínáì ọ̀hún! Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbé ògo Ọlọ́run yọ láwọn ọ̀nà kan tó ju ti Mósè? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ kókó pàtàkì yìí nínú lẹ́tà kan tó kọ. Ó kọ ọ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń “ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí.” (2 Kọ́ríńtì 3:7, 8, 18) Àwọn Kristẹni tó máa gbé ní Párádísè orí ilẹ̀ ayé náà ń gbé ògo Ọlọ́run yọ láwọn ọ̀nà kan pẹ̀lú.
Bí Àwa Kristẹni Ṣe Ń Gbé Ògo Ọlọ́run Yọ
3. Báwo la ṣe mọ Jèhófà láwọn ọ̀nà tí Mósè ò mọ̀ ọ́n?
3 Báwo làwa Kristẹni ṣe lè gbé ògo Ọlọ́run yọ? Lóòótọ́ a ò rí Jèhófà lọ́nà tí Mósè gbà rí i, a ò sì gbóhùn rẹ̀ bí Mósè ṣe gbọ́ ọ. Ṣùgbọ́n, a mọ Jèhófà láwọn ọ̀nà tí Mósè ò mọ̀ ọ́n. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn tí Mósè kú ni Jésù tó wá sáyé gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà. Nítorí náà, Mósè ò lè mọ bí òfin tóun gbà ṣe ní ìmúṣẹ lára Jésù, ẹni tó kú láti lè dá aráyé nídè kúrò nínú ìnira ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:20, 21; Gálátíà 3:19) Síwájú sí i, ìwọ̀nba òye díẹ̀ ni Mósè ní nípa ọlá-ńlá àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe, èyí tó dá lórí Ìjọba Mèsáyà àti bí ìjọba náà yóò ṣe sọ ayé di Párádísè. Nípa báyìí, à ń rí ògo Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ìyójú kọ́ la fi rí i bí kò ṣe ojú ìgbàgbọ́ táwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ń mú ká ní. Bákan náà, à ń gbọ́ ohùn Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe látẹnu áńgẹ́lì bí kò ṣe látinú Bíbélì, pàápàá látinú àwọn ìwé Ìhìn Rere tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lọ́nà tó yéni yékéyéké.
4. (a) Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe ń gbé ògo Ọlọ́run yọ? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lè gbà máa gbé ògo Ọlọ́run yọ?
4 Kì í ṣe pé ìtànṣán ògo Jèhófà máa ń yọ ní tààràtà lójú àwọn Kristẹni, ṣùgbọ́n ojú wọn máa ń mọ́lẹ̀ yòò bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ète rẹ̀ ológo fáwọn èèyàn. Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tiwa yìí pé àwọn èèyàn Ọlọ́run “yóò sọ nípa ògo [Jèhófà] láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 66:19) Síwájú sí i, 2 Kọ́ríńtì 4:1, 2 kà pé: “Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí . . . , àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n “jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun” ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ yìí. (2 Kọ́ríńtì 3:6) Àmọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ti ní ipa pàtàkì lórí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn ẹni àmì òróró àti tàwọn àgùntàn mìíràn kò mọ sí fífi ẹ̀kọ́ wọn gbé ògo Jèhófà yọ, wọ́n tún máa ń fi ìwà wọn náà gbé e yọ. Dájúdájú ojúṣe wa ni, àǹfààní ló sì tún jẹ́ fún wa pé à ń gbé ògo Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo yọ bíi dígí!
5. Ẹ̀rí kí ni aásìkí nípa tẹ̀mí tí à ń ní jẹ́?
5 Lóde òní, gbogbo ibi táwọn èèyàn ń gbé lórí ilẹ̀ ayé la ti ń wàásù ìhìn rere ológo ti Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:14) Àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, èèyàn àti ahọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ gba ìhìn rere náà, wọ́n sì ń yí ìgbé ayé wọn padà kí wọ́n lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Róòmù 12:2; Ìṣípayá 7:9) Bíi tàwọn Kristẹni ìjímìjí làwọn náà ò ṣe dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. (Ìṣe 4:20) Àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ló ń gbé ògo Ọlọ́run yọ lóde òní, kò sì tíì sígbà kankan tí wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí lẹ́ẹ̀kan náà. Ǹjẹ́ o wà lára wọn? Aásìkí nípa tẹ̀mí táwa èèyàn Ọlọ́run ń ní jẹ́ ẹ̀rí tó hàn gbangba pé Jèhófà ń bù kún wa ó sì ń dáàbò bò wa. Tá a bá tún tibi àwọn ọ̀tá alágbára tó dojú kọ wá wò ó, a ó túbọ̀ rí i dájú pé ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára wa. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.
Kò Sẹ́ni Tó Lè Pa Àwa Èèyàn Ọlọ́run Lẹ́nu Mọ́
6. Kí nìdí tó fi gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kéèyàn tó lè máa jẹ́rìí nípa Jèhófà?
6 Ká sọ pé wọ́n ní kí o wá sílé ẹjọ́ kó o wá jẹ́rìí sí ìwà burúkú tí ọ̀daràn paraku kan hù. O sì mọ̀ pé ọ̀daràn náà ní ẹgbẹ́ kan tó burú gan-an àti pé yóò sa gbogbo ipá rẹ̀ kó o má lè táṣìírí òun. Ó dájú pé yóò gba ìgboyà pẹ̀lú ẹ̀rí tó dájú pé àwọn aláṣẹ yóò dáàbò bò ọ́ kó o tó lè lọ síbẹ̀ lọ jẹ́rìí. Irú ipò tá a wà gẹ́lẹ́ nìyẹn. Bá a ṣe ń jẹ́rìí nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe, ńṣe ni ẹ̀rí tá à ń jẹ́ ń táṣìírí Sátánì Èṣù pé ó jẹ́ apààyàn àti òpùrọ́ tó ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé pátá lọ́nà. (Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:9) Ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ká tó lè máa jẹ́rìí nípa Jèhófà ká sì máa táṣìírí Èṣù.
7. Báwo ni agbára Sátánì ṣe pọ̀ tó, kí ló sì ń gbìyànjú láti ṣe?
7 Ohun kan dájú ṣá o, ìyẹn ni pé Jèhófà ni Atóbijù. Agbára Sátánì ò jẹ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ tirẹ̀. Nígbà náà, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà lè dáàbò bò wá àti pé ó fẹ́ láti dáàbò bò wá bá a ṣe ń fòtítọ́ ọkàn sìn ín. (2 Kíróníkà 16:9) Àmọ́ ká má gbàgbé pé Sátánì ni alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù àti alákòóso ayé yìí, ìyẹn àwọn èèyàn tó kẹ́yìn sí Ọlọ́run. (Mátíù 12:24, 26; Jòhánù 14:30) Sátánì ò lè kúrò ní sàkání ayé yìí mọ́, tòun ti “ìbínú ńlá” ló sì fi wà níbẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ń fi tìkanra-tìkanra gbógun ti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, tó ń gbìyànjú láti lo ayé tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ láti fi pa gbogbo àwọn tó ń wàásù ìhìn rere lẹ́nu mọ́. (Ìṣípayá 12:7-9, 12, 17) Báwo ló ṣe ń ṣe é? Ọ̀nà mẹ́ta ó kéré tán ló gbà ń ṣe é.
8, 9. Àwọn nǹkan wo ni Sátánì máa ń mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká máa bá ẹni tá a bá ṣáà ti rí kẹ́gbẹ́?
8 Ọ̀nà kìíní ni pé Sátánì máa ń fẹ́ lo àníyàn ayé láti fi kó ìpínyà ọkàn bá wa. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn ti ya olùfẹ́ owó, olùfẹ́ ara wọn, àti olùfẹ́ adùn. Wọn kì í ṣe olùfẹ́ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:1-4) Nítorí pé àníyàn ayé ti gba ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lọ́kàn, wọn ‘kì í fiyè sí’ ìhìn rere tá à ń sọ fún wọn. Wọn ò tiẹ̀ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì rárá. (Mátíù 24:37-39) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè ràn wá, kó sọ wá dẹni tí ò kọbi ara sí nǹkan tẹ̀mí mọ́. Tí ìfẹ́ àwọn nǹkan tara àti adùn ayé bá sì ti gbà wá lọ́kàn pẹ́nrẹ́n, ìfẹ́ Ọlọ́run á di tútù lọ́kàn wa.—Mátíù 24:12.
9 Nítorí èyí, àwọn Kristẹni kì í kàn ń bá ẹni tí wọ́n bá sáà ti rí kẹ́gbẹ́, ńṣe ni wọ́n máa ń ṣe àṣàyàn. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Àwọn tó ń gbógo Ọlọ́run yọ ló yẹ ká máa bá “rìn.” Àjọṣe wọn máa ń fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni! Bá a bá ń bá àwọn ará wa nípa tẹ̀mí pé jọ láwọn ìpàdé wa àti láwọn ìgbà míì, ìfẹ́ wọn, ìgbàgbọ́ wọn, ayọ̀ wọn àti ọgbọ́n wọn yóò máa gbé wa ró. Irú ìfararora tó dára bẹ́ẹ̀ máa ń mú wa tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa.
10. Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì gbà ń lo ìfiniṣẹlẹ́yà láti fi gbógun ti àwọn tó ń gbógo Ọlọ́run yọ?
10 Ọ̀nà kejì ni pé Sátánì ń lo ìfiniṣẹlẹ́yà kó má bàa ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn Kristẹni láti gbé ògo Ọlọ́run yọ. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu. Nígbà tí Jésù Kristi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé wọ́n fi í ṣẹlẹ́yà, wọ́n fi í rẹ́rìn-ín, wọ́n yínmú sí i, wọ́n fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n hùwà àfojúdi sí i, kódà wọ́n tiẹ̀ tutọ́ sí i lára. (Máàkù 5:40; Lúùkù 16:14; 18:32) Wọ́n fàwọn Kristẹni ìjímìjí ṣẹlẹ́yà bákan náà. (Ìṣe 2:13; 17:32) Ìwà kan náà ni wọ́n ń hù sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé wọ́n á kà wọ́n sí wòlíì èké. Ó sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, . . . ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’” (2 Pétérù 3:3, 4) Ńṣe ni wọ́n máa ń fi àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣẹlẹ́yà pé wọn ò mohun tó ń lọ rárá. Wọ́n ní ìlànà ìwà híhù inú Bíbélì ò bóde mu mọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ ka ìhìn rere tá à ń wàásù sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:18, 19) Àwọn èèyàn lè máa fi àwa Kristẹni ṣẹlẹ́yà ní iléèwé àti níbi iṣẹ́, kódà àwọn aráalé wa pàápàá lè fi wá ṣẹlẹ́yà nígbà míì. Àmọ́ láìfi gbogbo ìwọ̀nyí pè, a kò dẹ́kun fífi iṣẹ́ ìwàásù wa gbógo Ọlọ́run yọ, nítorí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù pé òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jòhánù 17:17.
11. Ọ̀nà wo ni Sátánì gbà ń gbìyànjú láti lo inúnibíni láti fi pa àwa Kristẹni lẹ́nu mọ́?
11 Ọ̀nà kẹta tí Sátánì gbà ń gbìyànjú láti pa wá lẹ́nu mọ́ ni pé ó ń lo àtakò tàbí inúnibíni. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Gẹ́lẹ́ bó ṣe wí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fojú winá onírúurú inúnibíni tó lè koko láwọn ibi púpọ̀ láyé. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ pé ìkórìíra tàbí ìṣọ̀tá yóò wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tó ń sin Sátánì Èṣù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) A sì tún mọ̀ pé tá ò bá ti fìwà títọ́ wa sílẹ̀ lójú àdánwò, ńṣe là ń jẹ́rìí sí i pé ó tọ́ bí Jèhófà ṣe jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Tí èyí bá wà lọ́kàn wa, bó ṣe wù kí àdánwò kan le tó a ò ní bẹ̀rù rárá. Tá a bá ti pinnu lọ́kàn wa pé a ò ní yéé gbé ògo Ọlọ́run yọ, kò sóhun tó máa lè pa wá lẹ́nu mọ́ títí ayé.
12. Kí nìdí tó fi ỵẹ ká máa yọ̀ bá a ṣe ń bá ìṣòtítọ́ wa lọ láìfi àtakò tí Sátánì ń ṣe sí wa pè?
12 Ṣé o kì í jẹ́ kí adùn ayé gbà ọ́ lọ́kàn, ṣé o sì ń bá ìṣòtítọ́ rẹ lọ láìfi ìfiniṣẹlẹ́yà àti àtakò pè? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kínú rẹ máa dùn. Jésù mú kó dá àwọn tó bá di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mátíù 5:11, 12) Ẹ̀mí ìfaradà tó o ní jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí mímọ́ alágbára tí Jèhófà ń fúnni wà lára rẹ, ẹ̀mí yìí ló sì ń jẹ́ kó o lè máa gbógo rẹ̀ yọ.—2 Kọ́ríńtì 12:9.
Jèhófà Ló Ń Fún Wa Lẹ́mìí Ìfaradà
13. Ìdí pàtàkì wo làwa Kristẹni fi ń fi ìfaradà bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ?
13 Ìdí pàtàkì kan tá a fi ń fi ìfaradà bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ ni pé a fẹ́ràn Jèhófà àti pé ó ń wù wá láti máa gbé ògo rẹ̀ yọ. Àwọn ọmọ èèyàn sábà máa ń fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹni tí wọ́n bá fẹ́ràn tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún, kò sì sí ẹni tó tún yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bíi Jèhófà Ọlọ́run. Ìfẹ́ ńlá tó ní ló jẹ́ kó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó lè jẹ́rìí sí òtítọ́, kó sì gba àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn nínú ọmọ aráyé là. (Jòhánù 3:16; 18:37) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo onírúurú èèyàn ṣe làwa náà ń fẹ́ kí wọ́n ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà kí wọ́n sì rí ìgbàlà; ìdí tá a sì fi ń wàásù nìyẹn. (2 Pétérù 3:9) Ohun tó wù wá yìí, àti fífẹ́ tá a fẹ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run ló ń mú ká tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa ká lè máa fi gbógo Ọlọ́run yọ.
14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lókun tá a fi ń ní ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
14 Àmọ́ ṣá o, Jèhófà gan-gan ló ń fún àwa Kristẹni lókun tá a fi lè ní ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ètò rẹ̀, àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa lókun, ó sì fi ń mẹ́sẹ̀ wa dúró. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà máa “ń pèsè ìfaradà” fún àwọn tó bá fẹ́ láti máa gbógo rẹ̀ yọ. Ó ń dáhùn àdúrà wa ó sì ń fún wa lọ́gbọ́n tá a lè fi yanjú ìṣòro. (Róòmù 15:5; Jákọ́bù 1:5) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jèhófà kì í jẹ́ kí ìdánwò tó ju agbára wa lọ bá wa. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa kí a lè máa gbógo rẹ̀ yọ.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
15. Kí ló ń jẹ́ ká lè máa ní ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
15 Níní tá a ní ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ lára wa. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ẹnì kan ní kó o bá òun máa pín oríṣi búrẹ́dì kan fáwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́, láti ilé dé ilé. Onítọ̀hún tún sọ fún ọ pé ẹnikẹ́ni ò ní san kọ́bọ̀ fún ọ, fúnra rẹ lo sì máa wáyè láti pín in. Lẹ́yìn náà, o tún wá gbọ́ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí irú búrẹ́dì bẹ́ẹ̀ ò pọ̀ àti pé àwọn míì á tiẹ̀ máa bá ọ jà lórí pé ò ń pín in fáwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o rò pé wàá lè máa ṣe iṣẹ́ yìí láti oṣù dé oṣù àti látọdún dé ọdún? Bóyá ni wàá lè máa ṣe é. Àmọ́ ìwọ wò ó ná, ó ṣeé ṣe kó o ti máa sa gbogbo ipá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, kó o sì ti máa náwó nára sí i. Kí ló ń mú kó o máa ṣe é? Ǹjẹ́ kì í ṣe torí pé o fẹ́ràn Jèhófà àti pé ó ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fi bù kún ìsapá rẹ tó o fi lè máa ní ìfaradà? Bẹ́ẹ̀ ni o!
Iṣẹ́ Tá Ò Ní Gbàgbé Láé
16. Tá a bá ń fi ìfaradà bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó, kí ni yóò yọrí sí fún àwa àtàwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ wa?
16 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ ti májẹ̀mú tuntun jẹ́ ẹ̀bùn tó ta yọ. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Bákan náà ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí àwọn àgùntàn mìíràn ń ṣe jákèjádò ayé ṣe jẹ́ ìṣúra. Tó o bá sì ń fi ìfaradà bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ nìṣó, wàá lè “gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là,” bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú ìwé tó kọ sí Tímótì. (1 Tímótì 4:16) Wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Ńṣe ni ìhìn rere tó ò ń wàásù ń fún àwọn èèyàn láǹfààní tí wọ́n fi lè wà láàyè títí láé. Lẹ́yìn náà, ìwọ àti ẹni tó o ràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí lè wá dọ̀rẹ́ gidi. Wá wo bí ayọ̀ rẹ ṣe máa pọ̀ tó nígbà tí ìwọ àtàwọn tó o kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run bá ń gbénú Párádísè títí gbére! Ó dájú pé wọn ò ní gbàgbé gbogbo ipá tó o sà láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí á sì múnú rẹ dùn gan-an!
17. Kí nìdí tí àkókò tá a wà yìí fi jẹ́ àkókò tó yàtọ̀ pátápátá nínú ìtàn ìran ènìyàn?
17 Àkókò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pátápátá nínú ìtàn ìran ènìyàn là ń gbé yìí. Ohun tí kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́ láé là ń ṣe yìí, ìyẹn ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere nínú ayé táwọn èèyàn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Nóà gbé nínú irú ayé bẹ́ẹ̀ rí, ayé ọ̀hún sì kọjá lọ níṣojú rẹ̀. Ó dájú pé inú Nóà á dùn gan-an pé òun kan ọkọ̀ áàkì tí Ọlọ́run ní kóun kàn, èyí tó mú kóun àti ìdílé rẹ̀ rí ìgbàlà. (Hébérù 11:7) Ìwọ náà lè nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Wo bí inú rẹ ṣe máa dùn tó nínú ayé tuntun lọ́hùn nígbà tó o bá padà wo ìgbòkègbodò rẹ nígbà ìkẹyìn ọjọ́ yìí, tó o rí i pé gbogbo ipá rẹ lo sà láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú.
18. Ìdánilójú àti ìṣírí wo ni Jèhófà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
18 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbé ògo Ọlọ́run yọ nìṣó. Ohun tá a ó máa rántí títí láé ni tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ wa pẹ̀lú. Bíbélì sọ̀rọ̀ ìṣírí yìí fún wa pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́. Ṣùgbọ́n a fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin, kí ẹ má bàa di onílọ̀ọ́ra, ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”—Hébérù 6:10-12.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo làwa Kristẹni ṣe ń gbé ògo Ọlọ́run yọ?
• Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ọgbọ́n tí Sátánì ń ta bó ṣe ń gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu mọ́?
• Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ lára wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìtànṣán ògo Ọlọ́run yọ ní ojú Mósè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
À ń fi iṣẹ́ ìwàásù wa gbé ògo Ọlọ́run yọ