Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kíróníkà Kejì
ÌTÀN bí Sólómọ́nì ṣe ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ló bẹ̀rẹ̀ ìwé Kíróníkà Kejì nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ tí Kírúsì Ọba Páṣíà sọ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ló sì parí ìwé náà. Kírúsì sọ pé: “[Jèhófà] fúnra rẹ̀ sì ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà. Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, kí ó gòkè lọ [sí Jerúsálẹ́mù].” (2 Kíróníkà 36:23) Ẹ́sírà àlùfáà ló kọ ìwé náà parí ní ọdún 460 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ láàárín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún ló wà níbẹ̀, ìyẹn láti ọdún 1037 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Àṣẹ tí Kírúsì pa ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn Júù láti padà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n sì mú ìjọsìn Jèhófà bọ̀ sípò níbẹ̀. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti lò nígbèkùn Bábílónì yẹn ti ṣàkóbá fún wọn. Àwọn tó ti ìgbèkùn dé náà kò mọ ìtàn orílẹ̀-èdè wọn. Lọ́nà tó ṣe kedere, ìwé Kíróníkà Kejì ṣàkópọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò àwọn ọba tó jẹ ní ìran Dáfídì fáwọn èèyàn náà. Ìtàn náà tún ṣe pàtàkì fún wa nítorí ó sọ nípa àwọn ìbùkún téèyàn máa ń rí tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run tòótọ́ àtohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.
ỌBA KAN KỌ́LÉ FÚN JÈHÓFÀ
Jèhófà fún Sólómọ́nì Ọba lóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́, ìyẹn ọgbọ́n àti ìmọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ àti ọlá. Ọba náà wá kọ́ ilé kan tó ga lọ́lá fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn èèyàn náà sì “kún fún ìdùnnú àti ìjẹ̀gbádùn nínú ọkàn-àyà.” (2 Kíróníkà 7:10) Sólómọ́nì wá dẹni tó “pọ̀ ju gbogbo àwọn ọba yòókù ní ilẹ̀ ayé ní ọrọ̀ àti ọgbọ́n.”—2 Kíróníkà 9:22.
Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ti ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún, ó ‘dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, Rèhóbóámù ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.’ (2 Kíróníkà 9:31) Ẹ́sírà kò ṣe àkọsílẹ̀ bí Sólómọ́nì ṣe yapa kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Kìkì àṣìṣe tí Ẹ́sírà mẹ́nu kàn ni bí ọba náà ṣe fi ìwà òmùgọ̀ kó ọ̀pọ̀ ẹṣin jọ láti Íjíbítì tó sì tún fi ọmọ Fáráò ṣaya. Nítorí náà, ọ̀nà tí Ẹ́sírà gbà kọ àkọsílẹ̀ náà kò tàbùkù Sólómọ́nì.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:14—Kí nìdí tí ìtàn ìran oníṣẹ́ ọnà tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ẹsẹ yìí fi yàtọ̀ sí èyí tó wà ní 1 Àwọn Ọba 7:14? Àwọn Ọba kìíní pe ìyá tó bí ọkùnrin oníṣẹ́ ọnà yẹn ní “obìnrin opó kan láti inú ẹ̀yà Náfútálì” nítorí ó fẹ́ ọkùnrin kan láti ẹ̀yà náà. Àmọ́, láti ẹ̀yà Dánì ni obìnrin náà ti wá. Lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú, ó fẹ́ ọkùnrin kan láti Tírè, ọmọ tí wọ́n sì bí ni oníṣẹ́ ọnà náà.
2:18; 8:10—Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí sọ pé iye àwọn ajẹ́lẹ̀ tó jẹ́ alábòójútó àti olórí àwọn òṣìṣẹ́ jẹ́ egbèjìdínlógún [3,600] pẹ̀lú àádọ́ta-lérúgba [250], àmọ́ 1 Àwọn Ọba 5:16; 9:23 sọ pé iye wọn jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàdínlógún [3,300] pẹ̀lú àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta [550]. Kí ló fà á tí iye náà fi yàtọ̀ síra? Ó jọ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà pín àwọn ajẹ́lẹ̀ náà sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ló fa ìyàtọ̀ náà. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Kíróníkà Kejì fìyàtọ̀ sáàárín àwọn egbèjìdínlógún [3,600] ajẹ́lẹ̀ tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àádọ́ta-lérúgba [250] tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, nígbà tí Àwọn Ọba Kìíní fìyàtọ̀ sáàárín àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàdínlógún [3,300] olórí àtàwọn àádọ́ta lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [550] àwọn alábòójútó tí ipò wọn ga. Bó ti wù kó rí, àpapọ̀ iye àwọn ajẹ́lẹ̀ náà jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbọ̀nkàndínlógún [3,850] èèyàn.
4:2-4—Kí nìdí tí wọ́n fi lo àwọn ère akọ màlúù láti fi ṣe ibi tí wọ́n gbé òkun dídà náà lé? Nínú Ìwé Mímọ́, akọ màlúù ni wọ́n máa ń fi ṣàpẹẹrẹ agbára. (Ísíkíẹ́lì 1:10; Ìṣípayá 4:6, 7) Fífi tí wọ́n fi ère màlúù ṣàpẹẹrẹ agbára bá a mú wẹ́kú nítorí pé akọ màlúù bàbà méjìlá ni wọ́n gbé “òkun dídà” ńlá náà lé, èyí tó wúwo tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àpò sìmẹ́ǹtì. Lílò akọ màlúù lọ́nà yìí kò rú òfin kejì tó sọ pé a kò gbọ́dọ̀ ṣe ère ohunkóhun láti fi ṣe ìjọsìn.—Ẹ́kísódù 20:4, 5.
4:5—Báwo ni omi tí òkun dídà náà lè gbà ti pọ̀ tó? Tí wọ́n bá da omi sínú òkun dídà náà, ó lè gba nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta òṣùwọ̀n báàfù tàbí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgbọ̀n àgbá omi. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí omi tí wọ́n sábà máa ń dà sínú rẹ̀ jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́ta ìwọ̀n tó máa ń gbà. Ìwé 1 Àwọn Ọba 7:26 sọ pé: “Ẹgbàá òṣùwọ̀n báàfù [ìyẹn 44,000 jálá] ni [òkun dídà náà] ń gbà.”
5:4, 5, 10—Àwọn ohun èlò wo ni wọ́n kó wá látinú àgọ́ ìjọsìn tó wá di ara ohun tó wà nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́? Àpótí ẹ̀rí ni ohun èlò kan ṣoṣo tí wọ́n gbé wá látinú àgọ́ ìpàdé tí wọ́n sì gbé pa mọ́ sínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà tán, wọ́n gbé àgọ́ ìjọsìn náà láti Gíbéónì wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì gbé e pa mọ́ síbẹ̀.—2 Kíróníkà 1:3, 4.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:11, 12. Ohun tí Sólómọ́nì béèrè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé ọgbọ́n àti ìmọ̀ ló jẹ ọba náà lógún jù lọ. Àdúrà wa sí Ọlọ́run máa ń fi ohun tó jẹ wá lọ́kàn hàn. Ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa ronú lórí ohun tá à ń sọ nínú àdúrà wa.
6:4. Níní ìmọrírì àtọkànwá fún inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti oore rẹ̀ yẹ kó mú wa máa yin Jèhófà, ìyẹn ni pé ká máa yìn ín tìfẹ́tìfẹ́ àti pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore.
6:18-21. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ilé èyíkéyìí tó lè gba Ọlọ́run, síbẹ̀ tẹ́ńpìlì náà jẹ́ ibi táwọn èèyàn ti ń jọ́sìn Jèhófà. Lóde òní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ibi ìjọsìn tòótọ́ ní ìlú tó bá wà.
6:19, 22, 32. Gbogbo èèyàn lórílẹ̀-èdè náà ló láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà, látorí ọba dórí ẹni tó kéré jù lọ, kódà títí kan ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó bá fi òótọ́ inú tọ̀ ọ́ wá.a—Sáàmù 65:2.
ÀWỌN ỌBA TÓ JẸ TẸ̀ LÉ ARA WỌN NÍ ÌRAN DÁFÍDÌ
Ìjọba Ísírẹ́lì tó wà níṣọ̀kan tẹ́lẹ̀ pín sí apá méjì, ìyẹn ìjọba àríwá ẹlẹ́yà mẹ́wàá àti ìjọba gúúsù ẹlẹ́yà méjì tí í ṣe Júdà àti Bẹ́ńjámínì. Àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì dúró ṣinṣin ti májẹ̀mú Ìjọba Jèhófà dípò ìjọba orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n sì dúró gbágbáágbá ti Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì. Lẹ́yìn tó lé díẹ̀ lọ́gbọ̀n ọdún tí wọ́n parí tẹ́ńpìlì náà, àwọn ọ̀tá kó ìṣúra inú rẹ̀ lọ.
Lára àwọn ọba mọ́kàndínlógún tó jẹ tẹ̀ lé Rèhóbóámù, márùn-ún lára wọn jẹ́ olóòótọ́, mẹ́ta lára wọn hùwà rere níbẹ̀rẹ̀ àmọ́ nígbà tó yá wọ́n di aláìṣòótọ́, ọ̀kan sì wà tó ronú pìwà dà kúrò lọ́nà búburú rẹ̀. Àwọn tó kù lára wọ́n ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà.b Ohun tí àwọn ọba márààrún tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ṣe la sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jù. Àkọsílẹ̀ nípa bí Hesekáyà ṣe mú iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì padà bọ̀ sípò àti bí Jòsáyà ṣe ṣètò Ìrékọjá ńlá ti ní láti jẹ́ ìṣírí ńlá fún àwọn Júù tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí mímú ìjọsìn Jèhófà padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
13:5—Kí ni “májẹ̀mú iyọ̀” túmọ̀ sí? Nítorí pé iyọ̀ kì í jẹ́ kí nǹkan bà jẹ́, ó jẹ́ àpẹẹrẹ pé kí nǹkan wà títí lọ́ gbére àti kí nǹkan má sì yí padà. Nítorí náà, “májẹ̀mú iyọ̀” dúró fún àdéhùn tí kò lè yí padà.
14:2-5; 15:17—Ǹjẹ́ Ásà Ọba mú gbogbo “àwọn ibi gíga” kúrò? Ó hàn kedere pé kò mú gbogbo wọn kúrò. Ó lè jẹ́ pé kìkì àwọn ibi gíga tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn àwọn ọlọ́run èké ni Ásà mú kúrò tí kò sì mú àwọn ibi gíga tí àwọn èèyàn ti ń jọ́sìn Jèhófà kúrò. Ó sì tún lè jẹ́ pé wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga kan láwọn ọdún tí Ásà lò kẹ́yìn nínú ìjọba rẹ̀. Àwọn ibi gíga wọ̀nyẹn ni ọmọ rẹ̀ Jèhóṣáfátì wá mú kúrò. Ká sòótọ́, àwọn ibi gíga kò tán pátápátá, àní kò tán nígbà ìjọba Jèhóṣáfátì pàápàá.—2 Kíróníkà 17:5, 6; 20:31-33.
15:9; 34:6—Ìhà wo ni ẹ̀yà Síméónì fara mọ́ nígbà tí wọ́n pín ìjọba Ísírẹ́lì? Nítorí pé ibi tí ogún Síméónì bọ́ sí jẹ́ ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ìpínlẹ̀ Júdà, ìpínlẹ̀ ẹ̀yà Síméónì bọ́ sáàárín ìpínlẹ̀ ìjọba Júdà àti Bẹ́ńjámínì. (Jóṣúà 19:1) Àmọ́ ṣá o, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìsìn àti ìṣèlú, ìjọba àríwá ilẹ̀ náà ni ẹ̀yà náà fara mọ́. (1 Àwọn Ọba 11:30-33; 12:20-24) Nítorí náà, ìjọba ẹ̀yà-mẹ́wàá la ka Síméónì mọ́.
16:13, 14—Ṣé wọ́n sun òkú Ásà níná ni? Rárá o, “ìfinásun ààtò ìsìnkú títóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀” kò túmọ̀ sí pé wọ́n sun òkú Ásà níná, kàkà bẹ́ẹ̀ sísun tùràrí ló túmọ̀ sí.—Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
35:3—Láti ibo ni Jòsáyà ti gbé Àpótí mímọ́ wá sínú tẹ́ńpìlì? Bíbélì kò sọ bóyá ọ̀kan lára àwọn ọba búburú ló gbé Àpótí yẹn kúrò ṣáájú ìgbà yẹn tàbí bóyá Jòsáyà ló gbé e lọ síbi tí nǹkankan ò ti ní ṣe é nígbà tí wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe lára tẹ́ńpìlì náà. Ibì kan ṣoṣo tí wọ́n tún ti sọ̀rọ̀ nípa Àpótí náà lẹ́yìn ọjọ́ Sólómọ́nì ni ìgbà tí Jòsáyà gbé e wá sínú tẹ́ńpìlì.
Ẹ̀kọ́ Ta A Rí Kọ́:
13:13-18; 14:11, 12; 32:9-23. A rí ẹ̀kọ́ ńlá kọ́ pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà!
16:1-5, 7; 18:1-3, 28-32; 21:4-6; 22:10-12; 28:16-22. Níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn àjèjì tàbí àwọn aláìgbàgbọ́ máa ń yọrí sí àgbákò. Ó yẹ ká hùwà ọgbọ́n ká yẹra fún àjọṣe tí kò pọn dandan pẹ̀lú ayé yìí.—Jòhánù 17:14, 16; Jákọ́bù 4:4.
16:7-12; 26:16-21; 32:25, 26. Ìgbéraga mú kí Ásà Ọba hùwà burúkú láwọn ọdún tó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀. Ẹ̀mí ìgbéraga yọrí sí ìṣubú Úsà. Hesekáyà hùwà òmùgọ̀ ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéraga ló mú kó lọ fi ìṣúra rẹ̀ han àwọn ońṣẹ́ láti Bábílónì. (Aísáyà 39:1-7) Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”—Òwe 16:18.
16:9. Jèhófà máa ń ran àwọn tí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó sì múra tán láti lo agbára rẹ̀ nítorí tiwọn.
18:12, 13, 23, 24, 27. Bíi ti Mikáyà, a ní láti máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe.
19:1-3. Jèhófà máa ń wo ànímọ́ rere tá a ní kódà nígbà tá a bá ṣe ohun tó bí i nínú pàápàá.
20:1-28. Ká ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà á jẹ́ ká rí òun, tá a bá yíjú sí i tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé kó darí wa.—Òwe 15:29.
20:17. Ká lè “rí ìgbàlà Jèhófà,” a ní láti “mú ìdúró [wa]” láti máa ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn gbágbáágbá. Dípò tí a óò fi máa gbẹ́kẹ̀ lé ara wa, a ní láti “dúró jẹ́ẹ́,” ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìmikàn.
24:17-19; 25:14. Ìbọ̀rìṣà di ìdẹkùn fún Jèhóáṣì àti Amasááyà, ọmọ rẹ̀. Lónìí, ìbọ̀rìṣà lè di ìdẹkùn fúnni bákan náà, àgàgà tó bá wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bíi ojúkòkòrò àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni táwọn náà jẹ́ oríṣi ìbọ̀rìṣà kan.—Kólósè 3:5; Ìṣípayá 13:4.
32:6, 7. Àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà àti alágbára bá a ti ń “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀” tá a sì ń jagun tẹ̀mí.—Éfésù 6:11-18.
33:2-9, 12, 13, 15, 16. Ẹni tó fi ìrònúpìwàdà tòótọ́ hàn ní láti jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́ kó sì máa sapá láti máa ṣe ohun tó tọ́. Bíi ti Mánásè Ọba, ojúlówó ìrònúpìwàdà ló lè mú kí ẹnì kantó ti hùwà tó burú jáì rí àánú Jèhófà gbà.
34:1-3. Kò yẹ kí ipò búburú èyíkéyìí tá a bára wa ní kékeré dí wa lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run ká sì sìn ín. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtọ̀dọ̀ Mánásè, bàbá bàbá rẹ̀ tó ronú pìwà dà ni Jòsáyà ti rí ohun rere kọ́, èyí tó nípa lórí rẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé. Ohun rere yòówù tó nípa lórí Jòsáyà ló mú kó ṣeé ṣe fún ún láti níwà rere. Ọ̀ràn tiwa náà lè rí bẹ́ẹ̀.
36:15-17. Jèhófà jẹ́ oníyọ̀ọ́nú àti onísùúrù. Àmọ́, ìyọ́nú àti sùúrù rẹ̀ yìí ní ààlà. Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ tí wọ́n bá fẹ́ yè bọ́ nígbà tí Jèhófà bá pa ètò nǹkan búburú yìí run.
36:17, 22, 23. Ìgbà gbogbo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ń ṣẹ.—1 Àwọn Ọba 9:7, 8; Jeremáyà 25:9-11.
Ìwé Kan Mú Kí Jòsáyà Ṣe Ohun Tó Tọ́
Ìwé 2 Kíróníkà 34:33 sọ pé: “Jòsáyà mú gbogbo àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí kúrò nínú gbogbo àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí a rí ní Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn, láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn.” Kí ló mú Jòsáyà ṣe ohun tó ṣe yìí? Nígbà tí Ṣáfánì akọ̀wé mú ìwé Òfin Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí wá fún Jòsáyà Ọba, ó ní kí wọ́n kà á sóun létí. Ọ̀rọ̀ tí Jòsáyà gbọ́ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an tó fi fi ìtara gbé ìjọsìn mímọ́ ga jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.
Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tá a kà lè nípa tó jinlẹ̀ lórí wa. Ǹjẹ́ ríronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọba tó jẹ ní ìran Dáfídì kò fún wa níṣìírí láti fara wé àpẹẹrẹ àwọn tó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ká sì yẹra fún ìwà àwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀? Ìwé Kíróníkà Kejì fún wa níṣìírí pé ká máa fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ṣoṣo ká sì máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Dájúdájú ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Kíróníkà Kejì yìí yè, ó sì ń sa agbára.—Hébérù 4:12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìbéèrè tó jẹ yọ nípa ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì náà àtàwọn ẹ̀kọ́ mìíràn látinú àdúrà tí Sólómọ́nì gbà níbi ìyàsímímọ́ náà, wo Ilé Ìṣọ́, July 1, 2005, ojú ìwé 28 sí 31.
b Tó o bá fẹ́ mọ orúkọ àwọn ọba Júdà bí wọ́n ṣe jẹ tẹ̀ lé ara wọn, wo Ilé Ìṣọ́, August 1, 2005, ojú ìwé 12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí ère akọ màlúù tí wọ́n lò láti fi ṣe ibi tí wọ́n gbé òkun dídà náà le fi bá a mu wẹ́kú?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrànlọ́wọ́ tí Jòsáyà rí gbà lọ́mọdé kò pọ̀, ó di olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tó dàgbà