Àlùfáà Àgbà Tó Dá Jésù Lẹ́bi
NÍ OṢÙ November ọdún 1990, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí pápá ìgbafẹ́ àti ojú ọ̀nà kan ní nǹkan bíi kìlómítà kan sí gúúsù ibi tí ìlú Jerúsálẹ́mù àtijọ́ wà rí ohun pàtàkì kan. Ọkọ̀ katakata tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ṣàdédé tẹ orí ibì kan tí wọ́n ń sin òkú sí láyé àtijọ́ tó jẹ́ ihò inú àpáta fọ́. Ibi ìsìnkú ìlú ni wọ́n fi àgbègbè yẹn ṣe láti ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí nínú ihò àpáta náà jọni lójú gan-an.
Àpótí egungun òkú méjìlá ni wọ́n rí nínú ihò àpáta náà. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan tí wọ́n bá ti sìnkú tí òkú náà sì ti jẹrà ni wọ́n máa ń kó egungun rẹ̀ sínú irú àpótí yìí. Àpótí egungun òkú kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, òun sì ni ọ̀kan lára àwọn àpótí tó lẹ́wà jù lọ táwọn èèyàn tíì ṣàwárí. Orúkọ tí wọ́n kọ sára àpótí egungun òkú ọ̀hún ni Yehosef bar Caiapha (Jósẹ́fù ọmọ Káyáfà).
Ẹ̀rí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé sàréè olórí àlùfáà tó ṣe alága ìgbẹ́jọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé ni wọ́n rí, ìyẹn ìgbẹ́jọ́ Jésù Kristi. Òpìtàn Júù tó ń jẹ́ Josephus sọ pé “Jósẹ́fù tí wọ́n ń pè ní Káyáfà” ni olórí àlùfáà náà. Àmọ́, Káyáfà ni Ìwé Mímọ́ kàn pè é. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ̀ nípa rẹ̀? Kí ló mú kó dá Jésù lẹ́bi?
Ìdílé Tó Ti Wá àti Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Rẹ̀
Káyáfà fẹ́ ọmọ Ánásì tó jẹ́ àlùfáà àgbà bíi tirẹ̀. (Jòhánù 18:13) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó ṣègbéyàwó ni ìdílé àwọn méjèèjì ti ṣètò sílẹ̀ pé wọ́n á fẹ́ra wọn, kí ìdílé wọn lè rí àrídájú pé àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn bára mu làwọn ń bá dána. Èyí fi hàn pé wọ́n á ti fara balẹ̀ wádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn ìdílé kálukú wọn kí wọ́n lè rí i pé ìdílé àlùfáà ni wọ́n ti wá lóòótọ́. Ó jọ pé ọlọ́rọ̀ àti èèyàn pàtàkì láwùjọ ni ìdílé àwọn méjèèjì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtinú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ dúkìá bí ilé àti ilẹ̀ tí wọ́n ní ní Jerúsálẹ́mù àti agbègbè rẹ̀ ni wọ́n ti ń rówó wọn. Kò sí àní-àní pé Ánásì á fẹ́ rí i dájú pé ẹni tó ṣeé fọkàn tẹ̀ tí wọ́n lè jọ máa ṣe òṣèlú lẹni tó máa jẹ́ àna òun lọ́jọ́ iwájú. Ó jọ pé Ánásì àti Káyáfà jẹ́ ara ẹ̀ya ìsìn àwọn Sadusí tí ẹnu wọn tólẹ̀ láwùjọ.—Ìṣe 5:17.
Inú ìdílé àlùfáà tó gbajúmọ̀ ni Káyáfà ti wá, nípa bẹ́ẹ̀ yóò ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ìtumọ̀ rẹ̀. Ìgbà tó wà lọ́mọ ogún ọdún ni yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní tẹ́ńpìlì, àmọ́ a kò mọ ọjọ́ orí rẹ̀ nígbà tó di àlùfáà àgbà.
Àwọn Àlùfáà Àgbà Àtàwọn Olórí Àlùfáà
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹni tó bá wá láti ìdílé àlùfáà àgbà ló ń dé ipò yìí, ibẹ̀ ni yóò sì wà títí dọjọ́ ikú rẹ̀. Àmọ́ ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ìdílé Hasmoneus fipá gba ipò oyè àlùfáà àgbà.a Hẹ́rọ́dù Ńlá ń fi àwọn èèyàn joyè àlùfáà àgbà, ó sì ń rọ̀ wọ́n lóyè, láti fi hàn pé òun gan-an lẹni tó láṣẹ lórí ẹni tó máa wà nípò yìí. Irú ohun táwọn gómìnà Róòmù náà ń ṣe nìyẹn.
Gbogbo bí nǹkan ṣe rí yìí ló wá jẹ́ kí wọ́n dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ pè ní “àwọn olórí àlùfáà.” (Mátíù 26:3, 4) Yàtọ̀ sí Káyáfà, àwọn tí wọ́n ti ṣe àlùfáà àgbà rí, irú bí Ánásì tí wọ́n ti rọ̀ lóyè àmọ́ tó ṣì jẹ́ àlùfáà àgbà wà nínú ẹgbẹ́ yìí. Àwọn mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ àlùfáà àgbà tó wà lórí oyè àtàwọn mọ̀lẹ́bí àlùfáà àgbà àná tún wà nínú ẹgbẹ́ yìí pẹ̀lú.
Àwọn ará Róòmù gba àwọn sàràkí èèyàn nínú ẹ̀yà Júù láyè láti máa mójú tó gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ nílẹ̀ Jùdíà, àwọn olórí àlùfáà sì wà lára wọn. Èyí jẹ́ kó rọrùn fún ìjọba Róòmù láti ṣàkóso àgbègbè náà àti láti máa gba owó orí lọ́wọ́ àwọn èèyàn Jùdíà láìsí pé wọ́n ń rán sójà rẹpẹtẹ lọ síbẹ̀. Ìjọba Róòmù fẹ́ kí àwọn olórí Júù máa rí sí i pé nǹkan ń lọ létòlétò nílẹ̀ Jùdíà, kí wọ́n sì máa wá ìlọsíwájú ilẹ̀ Róòmù. Àwọn gómìnà Róòmù kò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn àwọn olórí Júù torí pé àwọn Júù kò fẹ́ bí ilẹ̀ Róòmù ṣe ń jẹ gàba lé wọn lórí. Àmọ́ wọ́n rí i pé ohun tó máa dára fún tọ̀tún-tòsì wọn ni pé kí wọ́n jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ torí àlàáfíà ìlú.
Nígbà tí Káyáfà fi máa di àlùfáà àgbà, àwọn àlùfáà àgbà ló ń ṣe aṣáájú àwọn Júù nínú ọ̀rọ̀ òṣèlú. Kúírínọ́sì, ará Róòmù kan tó jẹ́ gómìnà ilẹ̀ Síríà, ló yan Ánásì sípò yẹn lọ́dún 6 tàbí ọdún 7 Sànmánì Kristẹni. Ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn Rábì sọ pé oníwọra, olójúsàájú, aninilára àti oníwà ipá làwọn ìdílé Júù tí wọ́n jẹ́ ọ̀tọ̀kùlú. Òǹkọ̀wé kan sọ pé nígbà tí Ánásì jẹ́ àlùfáà àgbà, kò sí àní-àní pé yóò rí sí i pé àna òun “tètè dé ipò tó ga láàárín àwọn tó ń bójú tó tẹ́ńpìlì; ó ṣe tán, bí ipò Káyáfà bá ṣe ga tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa wúlò fún Ánásì tó.”
Gómìnà Jùdíà tó ń jẹ́ Valerius Gratus ló yọ Ánásì nípò ní nǹkan bí ọdún 15 Sànmánì Kristẹni. Àwọn èèyàn mẹ́ta mìíràn ló di àlùfáà àgbà tẹ̀léra-tẹ̀léra, ọmọ Ánásì sì wà lára wọn. Nǹkan bí ọdún 18 Sànmánì Kristẹni ni Káyáfà di àlùfáà àgbà. Pọ́ńtíù Pílátù tó di gómìnà Jùdíà lọ́dún 26 Sànmánì Kristẹni fi Káyáfà sílẹ̀ sípò yẹn ní gbogbo ọdún mẹ́wàá tó fi ṣe gómìnà. Káyáfà ló wà lórí oyè nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àní títí dìgbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wọn pàápàá. Àmọ́ àtakò ńlá ni Káyáfà ṣe sí ìhìn rere táwọn Kristẹni ń wàásù.
Káyáfà Bẹ̀rù Jésù Ó tún Bẹ̀rù Àwọn Ará Róòmù
Lójú Káyáfà, eléwu ẹ̀dá tó ń dá rúgúdù sílẹ̀ ni Jésù. Jésù jẹ́ káwọn aláṣẹ àwọn Júù mọ̀ pé ìtumọ̀ tí wọ́n fún àwọn òfin Sábáàtì kò rí bẹ́ẹ̀, ó sì lé àwọn tí ń tajà àtàwọn tó ń bá àwọn èèyàn ṣẹ́ owó kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó ní wọ́n ti sọ ibẹ̀ di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” (Lúùkù 19:45, 46) Àwọn òpìtàn kan gbà pé ìdílé Ánásì ló ni àwọn ibi ìtajà tó wà ní tẹ́ńpìlì náà. Bóyá ìdí mìíràn nìyí tí Káyáfà fi gbìyànjú láti pa Jésù lẹ́nu mọ́. Nígbà táwọn olórí àlùfáà ránṣẹ́ lọ mú Jésù, ẹnu ya àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n rán nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ débi pé ńṣe ni wọ́n padà lọ́wọ́ òfo.—Jòhánù 2:13-17; 5:1-16; 7:14-49.
Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn aláṣẹ àwọn Júù gbọ́ pé Jésù ti jí Lásárù dìde. Ìhìn Rere Jòhánù sọ pé: “Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kó Sànhẹ́dírìn jọpọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.’” (Jòhánù 11:47, 48) Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ka Jésù sí ẹni tí kò ní jẹ́ kí ẹnu àwọn tólẹ̀ láwùjọ àti ẹni tó lè dàlúrú, àwọn sì ni Pílátù máa dá lẹ́bi bí ìlú bá dà rú. Bí àwọn ará Róòmù bá sì ti rí ohunkóhun tó fara jọ ìdìtẹ̀-síjọba pẹ́nrẹ́n, wọ́n lè wá dá sí ọ̀rọ̀ àwọn Júù, ilé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn ò sì fẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ rárá àti rárá.
Káyáfà mọ̀ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu, síbẹ̀ kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, torí pé ipò iyì àti ọlá tó wà ló ká a lára jù. Báwo ni yóò ṣe wá sọ pé òótọ́ ni Lásárù jíǹde? Sadusí ni Káyáfà, àwọn Sadusí kẹ̀ rèé, wọn ò gbà pé àjíǹde wà!—Ìṣe 23:8.
Ọ̀rọ̀ tí Káyáfà sọ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ alákòóso jẹ́ ká mọ̀ pé olubi ẹ̀dá ni. Ó ní: “Ẹ kò . . . ronú pé ó jẹ́ fún àǹfààní yín pé kí ọkùnrin kan kú nítorí àwọn ènìyàn, kí gbogbo orílẹ̀-èdè má sì pa run.” Ìtàn yẹn ń bá a nìṣó pé: “Àmọ́ ṣá o, kò sọ èyí láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n nítorí pé òun ni àlùfáà àgbà ní ọdún yẹn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti kú fún orílẹ̀-èdè náà, kì í sì í ṣe fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n kí ó bàa lè jẹ́ pé àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó tú ká káàkiri ni òun yóò lè kó jọpọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú. Nítorí náà, láti ọjọ́ yẹn lọ, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa [Jésù].”—Jòhánù 11:49-53.
Káyáfà ò mọ bí ọ̀rọ̀ tí òun sọ ṣe rinlẹ̀ tó. Àsọtẹ́lẹ̀ lohun tó sọ yìí jẹ́ torí pé òun ló wà nípò àlùfáà àgbà.b Ikú Jésù máa ṣàǹfààní lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe àwọn Júù nìkan ló máa ṣe láǹfààní. Ìdí ni pé gbogbo ìran èèyàn ni ẹbọ ìràpadà Jésù yóò dá nídè kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
Wọ́n Dìtẹ̀ Láti Pa Jésù
Ilé Káyáfà làwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà Júù ti pàdé kí wọ́n lè jọ jíròrò bí wọ́n á ṣe mú Jésù tí wọ́n á sì pa á. Àfàìmọ̀ ni àlùfáà àgbà ò lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe dúnàádúrà pẹ̀lú Júdásì Ísíkáríótù lórí iye tó máa gbà láti fi Jésù hàn. (Mátíù 26:3, 4, 14, 15) Àmọ́ o, ikú Jésù nìkan ṣoṣo ò lè mú kí ohun tó wà lọ́kàn Káyáfà ṣeé ṣe. “Àwọn olórí àlùfáà wá gbìmọ̀ pọ̀ nísinsìnyí láti pa Lásárù pẹ̀lú, nítorí pé ní tìtorí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù [fi] ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù.”—Jòhánù 12:10, 11.
Málíkọ́sì ẹrú Káyáfà wà lára àwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n rán lọ mú Jésù. Wọ́n kọ́kọ́ mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, lẹ́yìn èyí ni wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà, ẹni tó ti pèpàdé àwọn àgbààgbà Júù kí wọ́n lè ṣẹjọ́ Jésù lóru, èyí tí kò bófin mu.—Mátíù 26:57; Jòhánù 18:10, 13, 19-24.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n wá ò bára mu, síbẹ̀ ìyẹn ò ní kí Káyáfà dáwọ́ iṣẹ́ ibi tó fẹ́ ṣe dúró. Àlùfáà àgbà yìí mọ èrò ibi tó wà lọ́kàn àwọn tí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀ nípa ẹnikẹ́ni tó bá lóun ni Mèsáyà. Ìyẹn ló mú kó sọ fún Jésù pé òun fẹ́ mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni Jésù sọ pé òun ni Mèsáyà. Nígbà tí Jésù máa dáhùn, ó ní àwọn tí wọ́n fi òun sùn yóò ‘rí òun tí òun yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí òun yóò máa bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.’ Àlùfáà àgbà wá ṣe bíi pé òun nítara ìsìn, ó “fa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ ya, ó wí pé: ‘Ó ti sọ̀rọ̀ òdì! Kí ni a tún nílò àwọn ẹlẹ́rìí fún?’” Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn náà gbà pé ikú tọ́ sí Jésù.—Mátíù 26:64-66.
Àwọn ará Róòmù gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí i kí wọ́n tó pa ẹnikẹ́ni. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Káyáfà ni alárinà láàárín àwọn ará Róòmù àtàwọn Júù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló lọ fọ̀rọ̀ náà tó Pílátù létí. Nígbà tí Pílátù gbìyànjú láti dá Jésù sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Káyáfà wà lára àwọn olórí àlùfáà tó ń pariwo pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!” (Jòhánù 19:4-6) Bóyá Káyáfà gan-an ló ń sọ pé káwọn èèyàn máa tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé apànìyàn kan ni kí wọ́n tú sílẹ̀ dípò Jésù, ó sì lè wà lára àwọn olórí àlùfáà alágàbàgebè tí wọ́n ń polongo pé: “Àwa kò ní ọba kankan bí kò ṣe Késárì.”—Jòhánù 19:15; Máàkù 15:7-11.
Káyáfà ò gba gbogbo ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ti jíǹde. Ó ṣàtakò sí Pétérù àti Jòhánù, lẹ́yìn ìyẹn ló fínná mọ́ Sítéfánù. Káyáfà náà ló fún Sọ́ọ̀lù láṣẹ pé kó lọ mú ẹnikẹ́ni tó bá pera ẹ̀ ní Kristẹni nílùú Damásíkù wá. (Mátíù 28:11-13; Ìṣe 4:1-17; 6:8-7:60; 9:1, 2) Àmọ́, ní nǹkan bí ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, Vitellius ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà ilẹ̀ Síríà rọ Káyáfà lóyè.
Àwọn ìwé ìtàn àwọn Júù ò sọ̀rọ̀ ìdílé Káyáfà dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Talmud ti Bábílónì, èyí táwọn Júù fi ṣàkójọ òfin wọn, sọ pé: “Ègbé ni fún mi nítorí ilé Hanin [Ánásì], ègbé ni fún mi nítorí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ [tàbí ọ̀rọ̀ ìṣáátá] tí wọ́n ń sọ.” Àwọn kan ní ohun tí àròyé yìí ń tọ́ka sí ni “ìpàdé bòókẹ́lẹ́ táwọn aṣáájú ṣe nítorí àtigbìmọ̀ ohun tó máa fa ìnira fáwọn èèyàn.”
Ẹ̀kọ́ Tí Ìtàn Káyáfà Kọ́ Wa
Ọ̀mọ̀wé kan pe àwọn àlùfáà àgbà ni “èèyàn líle, ẹni tó gbọ́n féfé, ẹni tó tó gbangba sùn lọ́yẹ́, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tún jẹ́ agbéraga.” Ìgbéraga Káyáfà ni kò jẹ́ kó gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Torí náà, ká má ṣe jẹ́ kó yà wá lẹ́nu táwọn kan bá ń kọtí ikún sí ìhìn rere lónìí. Àwọn kan nífẹ̀ẹ́ sáwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, àmọ́ ìfẹ́ tí wọ́n ní ò jinlẹ̀ tó láti mú kí wọ́n kọ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí wọ́n ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀ lákọ̀tán. Àwọn mìíràn lè máa rò pé tí àwọn bá rẹ ara wọn sílẹ̀ láti máa wàásù ìhìn rere, ohun tó bu àwọn kù làwọn ṣe yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀sìn Kristẹni ò fàyè gba àìṣòótọ́ àti ìwọra.
Nígbà tí Káyáfà jẹ́ olórí àlùfáà, ì bá ti ran àwọn Júù bíi tirẹ̀ lọ́wọ́ láti gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, àmọ́ ipò àṣẹ tó jẹ ẹ́ lógún jẹ́ kó dá Jésù lẹ́bi. Àfàìmọ̀ ni ò jẹ́ pé títí dọjọ́ ikú Káyáfà ló fi ta ko Jésù. Àkọsílẹ̀ nípa ìwà tó hù jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn téèyàn bá kú pàápàá, aráyé ò ní gbàgbé ìwà téèyàn hù láyé. Ìwà tá a bá hù ló máa jẹ́ ká rí ojúure Ọlọ́run tàbí kí Ọlọ́run ta wá nù.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ka ìtàn àwọn ìdílé Hasmoneus, wo Ilé Ìṣọ́ June 15, 2001, ojú ìwé 27 sí 30.
b Nígbà kan, Jèhófà lo Báláámù tó jẹ́ ẹni ibi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Númérì 23:1-24:24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jósẹ́fù ọmọ Káyáfà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àpótí egungun òkú tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà rèé
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Àpótí egungun òkú, ohun tí wọ́n kọ sí i lára àti ihò àpáta ìsìnkú tí àwòrán rẹ̀ kò hàn dáadáa lójú ewé yìí: Israel Antiquities Authority ló yọ̀ǹda ká lo fọ́tò yìí