Ìwé Àtayébáyé Tó Mẹ́nu Kan Àwọn Ìwé Inú Bíbélì
ÌWÉ kan ṣàpèjúwe ìwé àtayébáyé kan báyìí pé: “Ó dà bíi pé ńṣe ni wọ́n dìídì kọ ìlà kọ̀ọ̀kan nínú ìwé náà kí ara àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni ayé ìgbàanì lè máa wà lọ́nà láti mọ̀ sí i.” Ǹjẹ́ o mọ ìwé àtayébáyé náà?
Bóyá o ti gbọ́ nípa rẹ̀ rí àbí o ò tíì gbọ́, orúkọ tí wọ́n ń pe ìwé náà ni Ìwé Muratori. Bó ti wù kó rí, o lè máa wò ó pé, ‘Kí nìdí tí Ìwé Muratori fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?’ Ìdí ni pé ìwé náà ni ọjọ́ rẹ̀ tíì pẹ́ jù lọ nínú gbogbo ìwé tó mẹ́nu kan àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí Ọlọ́run mí sí.
O lè gbà láìjanpata tó o bá gbọ́ pé àwọn ìwé kan ní pàtó ló wà nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n o, ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu pé ìgbà kan wà táwọn kan ń bá ara wọn jiyàn lórí irú àwọn ìwé tó yẹ kó wà nínú Bíbélì? Ìwé Muratori mẹ́nu kan àwọn ìwé táwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run mí sí. Ìwọ náà á gbà pé ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn mọ iye ìwé tó wà nínú Bíbélì ní pàtó. Nígbà náà, kí ni ìwé àtayébáyé náà sọ nípa àwọn ìwé tó para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ìwé àtayébáyé náà fúnra rẹ̀.
Bí Wọ́n Ṣe Rí I
Ìwé Muratori jẹ́ ara ìwé àfọwọ́kọ kan tó jẹ́ alábala, èyí tí wọ́n fi awọ ṣe. Abala mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ni ìwé àfọwọ́kọ náà ní, abala kọ̀ọ̀kan sì fẹ̀ díẹ̀ ju ìwé àjákọ lọ. Gbajúgbajà òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ludovico Antonio Muratori, tó gbé ayé láti ọdún 1672 sí 1750, ló rí àjákù ìwé yìí ní ibi ìkówèésí tí wọ́n ń pè ní Ambrosian Library, èyí tó wà nílùú Milan lórílẹ̀-èdè Ítálì. Ọdún 1740 ni Muratori kọ̀wé nípa ohun tó rí, ìyẹn ni wọ́n sì fi ń pe àjákù ìwé tó rí náà ní Ìwé Muratori. Ó dà bíi pé ọ̀rúndún kẹjọ ni wọ́n ṣe ìwé àfọwọ́kọ alábala náà ní ilé àtijọ́ kan tó jẹ́ tàwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé nílùú Bobbio, nítòsí ìlú Piacenza, ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Ítálì. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni wọ́n wá gbé e lọ sí ibi ìkówèésí tí wọ́n ń pè ní Ambrosian Library.
Ìlà márùndínláàádọ́rùn-ún ni gbogbo ọ̀rọ̀ inú Ìwé Muratori jẹ́, abala kẹwàá àti ìkọkànlá ni èyí sì wà nínú odindi ìwé àfọwọ́kọ alábala náà. Èdè Látìn ni wọ́n fi kọ ọ́, ó sì ní láti jẹ́ pé akọ̀wé kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ fara balẹ̀ ṣiṣẹ́ rẹ̀ ló kọ ọ́. Àmọ́ wọ́n rí díẹ̀ lára àwọn àṣìṣe tó ṣe nígbà tí wọ́n fi iṣẹ́ rẹ̀ wé irú àkọsílẹ̀ kan náà tó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ mẹ́rin tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kọkànlá àti ọ̀rúndún kejìlá.
Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ọ́?
Síbẹ̀, o lè máa ronú pé, ‘Ìgbà wo ni wọ́n kọ́kọ́ kọ ohun tó wà nínú Ìwé Muratori?’ Ó jọ pé èdè Gíríìkì ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ ọ́ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú kí wọ́n tó wá fi èdè Látìn túmọ̀ rẹ̀ sínú ìwé tí wọ́n ń pè ní Ìwé Muratori yìí. Ohun kan rèé tó lè jẹ́ ká mọ ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́. Ìwé Muratori mẹ́nu kan ìwé kan tí kò sí lára ìwé inú Bíbélì, ìyẹn ìwé Shepherd (Olùṣọ́ Àgùntàn), ó ṣàlàyé láyé ìgbà náà pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hermas ló kọ ọ́ “lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lákòókò tiwa, nílùú Róòmù.” Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé àárín ọdún 140 sí ọdún 155 Sànmánì Kristẹni ni Hermas parí kíkọ ìwé Shepherd. Èyí á jẹ́ kó o rí ìdí tí àwọn kan fi sọ pé àárín ọdún 170 sí ọdún 200 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́kọ́ kọ ohun tó wà nínú Ìwé Muratori, èyí tí wọ́n tú sí èdè Látìn látinú èdè Gíríìkì.
Bí wọ́n ṣe dárúkọ ìlú Róòmù ní tààràtà àti bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìlú náà fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ni wọ́n ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n o, àríyànjiyàn ṣì wà lórí ẹni tó kọ ọ́. Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Clement ará Alẹkisáńdíríà ló kọ ọ́ tàbí Melito ará Sádísì, tàbí kẹ̀ kó jẹ́ Polycrates ará Éfésù. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé Hippolytus ni. Hippolytus jẹ́ òǹkọ̀wé tó ṣe ọ̀pọ̀ ìwé jáde lédè Gíríìkì, ìlú Róòmù ló sì ń gbé lákòókò tó jọ pé wọ́n ṣe àkójọ àwọn ohun tó wà nínú Ìwé Muratori. Bí ìtàn nípa bí wọ́n ṣe kọ ọ́ ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ wú ọ lórí, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó wà nínú Ìwé Muratori tó fi ṣeyebíye tó bẹ́ẹ̀.
Ohun Tó Wà Nínú Rẹ̀
Kì í ṣe pé ìwé náà wulẹ̀ mẹ́nu kan àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì nìkan. Àní, ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan àtàwọn tó kọ wọ́n. Bó o bá ka ìwé náà, wàá rí i pé àwọn ìlà tó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ kò sí níbẹ̀, ó sì jọ pé ńṣe ló kàn parí lójijì. Ìhìn Rere Lúùkù ló kọ́kọ́ mẹ́nu kàn, ìwé náà sì sọ pé oníṣègùn lẹni tó kọ ìwé inú Bíbélì yìí. (Kólósè 4:14) Ó sọ pé ìwé Lúùkù ni Ìhìn Rere kẹta, ìyẹn á sì jẹ́ kó o rí i pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ìhìn Rere Mátíù àti ti Máàkù ni apá tí kò sí nínú rẹ̀ ń tọ́ka sí. Bó bá jẹ́ èrò rẹ nìyẹn, wàá rí i pé o tọ̀nà nítorí pé Ìwé Muratori sọ pé ìwé Jòhánù ni Ìhìn Rere kẹrin.
Ìwé Muratori fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Lúùkù ló kọ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì fún “Tìófílọ́sì ẹni títayọlọ́lá jù lọ.” (Lúùkù 1:3; Ìṣe 1:1) Lẹ́yìn èyí ló wá to àwọn lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́sẹẹsẹ, ìyẹn lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì (méjì), àwọn ará Éfésù, àwọn ará Fílípì, àwọn ará Kólósè, àwọn ará Gálátíà, àwọn ará Tẹsalóníkà (méjì), àwọn ará Róòmù, Fílémónì, Títù àti Tímótì (méjì). Ìwé náà tún sọ pé lẹ́tà Júúdà àti méjì lára àwọn lẹ́tà Jòhánù wà lára àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Ó ti tọ́ka sí lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Jòhánù kọ nígbà tó ń mẹ́nu kan Ìhìn Rere Jòhánù. Ìwé Ìṣípayá ló gbẹ̀yìn àwọn ìwé tí ìwé àtayébáyé náà sọ pé Ọlọ́run mí sí.
Ó ṣe pàtàkì bí ìwé náà ṣe dárúkọ Ìṣípayá Pétérù, síbẹ̀ ó tún sọ pé àwọn kan ronú pé kò yẹ káwọn Kristẹni kà á. Ẹni tó kọ Ìwé Muratori sọ pé káwọn òǹkàwé ṣọ́ra nítorí pé àwọn ìwé ayédèrú ti kún gbogbo ìgboro lásìkò náà. Ìwé Muratori sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ka irú ìwé bẹ́ẹ̀ mọ́ àwọn ìwé inú Bíbélì, “nítorí pé kò dáa kéèyàn da òróòro mọ́ oyin.” Ó tún dárúkọ àwọn ìwé mìíràn tí kò yẹ kó wà lára àwọn ìwé inú Bíbélì. Ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, ó lè jẹ́ ẹ̀yìn ìgbà táwọn àpọ́sítélì gbé ayé ni wọ́n kọ wọ́n, bí irú ìwé Shepherd (Olùṣọ́ Àgùntàn) tí Hermas kọ. Tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kọ wọ́n láti fi ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹ̀kọ́ tó ta ko ẹ̀kọ́ Ìjọ Kátólíìkì.
Tó o bá ń fọkàn bá ohun tá a ti ń sọ bọ̀, ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Hébérù, lẹ́tà méjì tí Pétérù kọ àti lẹ́tà Jákọ́bù kò sí lára àwọn ìwé inú Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí tí ìwé àtayébáyé yìí mẹ́nu kan. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Ọ̀mọ̀wé Geoffrey Mark Hahneman ti sọ̀rọ̀ lórí bí akọ̀wé tó da ìwé náà kọ ṣe ṣiṣẹ́ rẹ̀, ó ní “ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ìwé mìíràn wà nínú Ìwé Muratori àmọ́ tí wọ́n ti já dà nù, ìwé Jákọ́bù àti Hébérù (àti Pétérù Kìíní) sì lè wà lára wọn.”—The Muratorian Fragment and the Development of the Canon.
Nípa báyìí, Ìwé Muratori fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni làwọn èèyàn ti ka èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé tí à ń rí nísinsìnyí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Ká sòótọ́, kì í ṣe torí pé ìwé àtayébáyé kan dárúkọ àwọn ìwé inú Bíbélì lo fi hàn pé Ọlọ́run mí sí wọn tàbí pé ó yẹ kí wọ́n wà lára ìwé inú Bíbélì. Ohun tó ń fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló darí àwọn tó kọ ọ́ ni àwọn ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀. Gbogbo ìwé inú Bíbélì jẹ́ kó hàn dájú pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, gbogbo wọn ló sì bára wọn mu délẹ̀délẹ̀. Bí gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin tó wà nínú Bíbélì ò ṣe ta ko ara wọn tí wọn ò sì pọ̀n síhìn-ín sọ́hùn-ún yìí jẹ́rìí sí i pé Bíbélì pé pérépéré, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì bára mu. Látàrí èyí, àǹfààní kékeré kọ́ lo máa jẹ tó o bá gbà wọ́n bí wọ́n ṣe jẹ́ gan-an lóòótọ́, pé ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run mí sí ni wọ́n, èyí tí Ọlọ́run rí i dájú pé kò pa run títí dòní olónìí.—1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Tímótì 3:16, 17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ludovico Antonio Muratori
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ibi ìkówèésí tó ń jẹ́ Ambrosian Library
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìwé Muratori
[Credit Line]
Diritti Biblioteca Ambrosiana. Vietata la riproduzione. Aut. No. F 157 / 05
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìwé: Diritti Biblioteca Ambrosiana. Vietata la riproduzione. Aut. No. F 157 / 05; Muratori, based on line art: © 2005 Brown Brothers