“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Ìṣàpẹẹrẹ” Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an fún Wa
Ì BÁ ṣòro gan-an o láti mọ ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ká ní Bíbélì ò ṣàlàyé wọn níbòmíràn! Àwọn ìtàn kan nínú Bíbélì ò ní ìtumọ̀ mìíràn yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe kọ ọ́ síbẹ̀. Àmọ́, àwọn kan lára àwọn ìtàn Bíbélì ní àwọn ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ tó lè má tètè hàn síni. Àpẹẹrẹ kan ni ìtàn àwọn obìnrin méjì kan nínú ìdílé Ábúráhámù baba ńlá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìtàn náà jẹ́ “àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ.”—Gálátíà 4:24.
Ó yẹ ká gbé àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà yẹ̀ wò nítorí pé ohun tí àwọn tá a mẹ́nu kàn nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró fún ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo àwọn tó fẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run bù kún àwọn. Àmọ́, ká tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé àwọn ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ti ṣe pàtàkì tó yẹ̀ wò.
Àwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Gálátíà ní ọ̀rúndún kìíní ní ìṣòro kan. Àwọn kan lára wọn “ń pa àwọn ọjọ́ àti oṣù àti àsìkò àti ọdún mọ́ fínnífínní,” gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè ṣe pa á láṣẹ. Wọ́n ń sọ pé àwọn onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ pa Òfin Mósè mọ́ tí wọ́n bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run. (Gálátíà 4:10; 5:2, 3) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ irú òfin yẹn. Láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ìtàn kan tí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ Júù á mọ̀ dáadáa.
Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará Gálátíà létí pé Ábúráhámù, baba ńlá àwọn Júù, bí Íṣímáẹ́lì àti Ísákì. Hágárì tí í ṣe ìránṣẹ́bìnrin ló bí èyí àkọ́kọ́, ìyẹn Íṣímáẹ́lì, Sárà tó jẹ́ òmìnira obìnrin ló sì bí èkejì, ìyẹn Ísákì. Ó dájú pé àwọn ará Gálátíà tí wọ́n ń sọ pé káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ ìtàn bí Sárà ṣe yàgàn láwọn àkókò kan àti bó ṣe fi Hágárì ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Ábúráhámù kó lè bímọ fún un dípò òun. Wọ́n á ti mọ̀ pé ńṣe ni Hágárì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú Sárà ọ̀gá rẹ̀ nígbà tó lóyún Íṣímáẹ́lì. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Sárà pé ó máa bímọ, ó bí Ísákì ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Nígbà tó ṣe, Ábúráhámù lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì jáde kúrò nílé nítorí Íṣímáẹ́lì ń hùwà tí kò dáa sí Ísákì.—Jẹ́nẹ́sísì 16:1-4; 17:15-17; 21:1-14; Gálátíà 4:22, 23.
Àwọn Obìnrin Méjì Tó Dúró fún Májẹ̀mú Méjì
Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tí àwọn tá a mẹ́nu kàn nínú “àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ” yìí dúró fún. Ó sọ pé: “Àwọn obìnrin wọ̀nyí túmọ̀ sí májẹ̀mú méjì, èyí tí ó wá láti Òkè Ńlá Sínáì, tí ń bí àwọn ọmọ fún ìsìnrú, èyí tí ó sì jẹ́ Hágárì. . . . Ó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Jerúsálẹ́mù ti òní, nítorí ó wà nínú ìsìnrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.” (Gálátíà 4:24, 25) Hágárì dúró fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tí Jerúsálẹ́mù jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá orílẹ̀-èdè àwọn Júù dá ní Òkè Sínáì mú kó di dandan fún wọn láti máa gbọ́ ti Ọlọ́run. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, òfin náà jẹ́ kí wọ́n máa rántí nígbà gbogbo pé ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ làwọn àti pé àwọn nílò ìràpadà.—Jeremáyà 31:31, 32; Róòmù 7:14-24.
Ta wá ni Sárà, “òmìnira obìnrin” àti Ísákì ọmọ rẹ̀ dúró fún? Pọ́ọ̀lù fi hàn pé Sárà tó jẹ́ “àgàn” dúró fún ìyàwó Ọlọ́run, ìyẹn apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà. Obìnrin ti ọ̀run yìí jẹ́ àgàn ní ti pé kí Jésù tó wá sáyé, obìnrin ìṣàpẹẹrẹ yìí kò ní “ọmọ” kankan tá a fẹ̀mí yàn lórí ilẹ̀ ayé. (Gálátíà 4:27; Aísáyà 54:1-6) Àmọ́, ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn èèyàn kan lọ́kùnrin lóbìnrin. Nípa báyìí, wọ́n di àtúnbí èyí tó mú kí wọ́n di ọmọ obìnrin ti ọ̀run yìí. Ọlọ́run gba àwọn ọmọ tí apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà bí yìí ṣọmọ, wọ́n sì di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù Kristi lábẹ́ májẹ̀mú tuntun. (Róòmù 8:15-17) Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ yìí fi sọ nínú ìwé tó kọ pé: “Jerúsálẹ́mù ti òkè jẹ́ òmìnira, òun sì ni ìyá wa.”—Gálátíà 4:26.
Àwọn Ọmọ Obìnrin Méjèèjì
Bíbélì fi yéni pé Íṣímáẹ́lì ṣe inúnibíni sí Ísákì. Lọ́nà kan náà, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù tó ń sìnrú fi àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù ti òkè ṣẹlẹ́yà, wọ́n tún ṣe inúnibíni sí wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí èyí tí a bí lọ́nà ti ara [Íṣímáẹ́lì] nígbà yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀mí [Ísákì], bẹ́ẹ̀ náà ni nísinsìnyí.” (Gálátíà 4:29) Lákòókò tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé tó ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ohun táwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe fún un ò yàtọ̀ sí èyí tí Íṣímáẹ́lì ọmọ Hágárì ṣe fún Ísákì, ẹni tó jẹ́ pé òun gan-an ní ajogún Ábúráhámù. Wọ́n fi Jésù Kristi ṣẹlẹ́yà wọ́n sì ṣenúnibíni sí i, nítorí pé wọ́n ka ara wọn sí ọmọ Ábúráhámù wọ́n sì gbà pé àtọ̀húnrìnwá ni Jésù.
Ṣáájú kí àwọn alákòóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó ṣekú pa Jésù, ó sọ pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.”—Mátíù 23:37, 38.
Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní fi hàn pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Hágárì dúró fún kò mú àwọn ọmọ jáde tó máa jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù. Ńṣe ni Jèhófà kọ àwọn Júù ẹlẹ́mìí ìgbéraga tí wọ́n gbà pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ajogún tìtorí pé wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúráhámù. Lóòótọ́, àwọn kan lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì di ajogún pẹ̀lú Kristi. Àmọ́ kì í ṣe jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè yẹn ló mú kí wọ́n láǹfààní yẹn bí kò ṣe nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù.
Nígbà tó di Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, a mọ àwọn kan lára àwọn ajùmọ̀jogún yìí. Bí ọjọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́, Jèhófà fi ẹ̀mí yan àwọn míì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Jerúsálẹ́mù ti òkè.
Ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé “àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ” yìí ni pé ó fẹ́ ká mọ̀ pé májẹ̀mú tuntun kì í ṣẹgbẹ́ májẹ̀mú Òfin tí Mósè ṣe alárinà rẹ̀. Kò sí béèyàn ṣe lè pa Òfin Mósè mọ́ tó táá lè fìyẹn rí ojú rere Ọlọ́run nítorí pé aláìpé ni gbogbo ìran èèyàn àti pé ńṣe ni Òfin Mósè wulẹ̀ fi bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tó hàn. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù wá láti “tú àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin sílẹ̀ nípa rírà.” (Gálátíà 4:4, 5) Nítorí náà, ìgbàgbọ́ tí wọ́n bá ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi ló máa jẹ́ kí wọ́n bọ́ kúrò lábẹ́ Òfin Mósè tó ń fi hàn pé wọ́n jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.—Gálátíà 5:1-6.
Bí Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Náà Ti Ṣe Pàtàkì Tó fún Wa
Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ àlàyé tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti ṣe nípa àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí? Ìdí kan ni pé ó jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn ohun kan tí Ìwé Mímọ́ sọ tó jẹ́ pé kì bá má ṣe kedere sí wa. Àwọn àlàyé tó ṣe jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣọ̀kan, wọn ò sì ta kora.—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun táwọn tá a mẹ́nu kàn nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí dúró fún ṣe pàtàkì gan-an fún ayọ̀ wa ọjọ́ iwájú. Ká ní Ọlọ́run ò mú kí àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù ti òkè jáde wá ni, ńṣe là bá jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú títí ayé. Àmọ́, lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti Kristi àtàwọn tí wọ́n máa jọ jogún ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù, “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18 ) Èyí yóò wáyé nígbà tí gbogbo ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀, àìpé, ìrora àti ikú dá sílẹ̀ bá dópin. (Aísáyà 25:8, 9) Àkókò yẹn á mà lárinrin o!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Òkè Sínáì ni Ọlọ́run ti fi májẹ̀mú Òfin lọ́lẹ̀
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Báwo ni “àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìṣàpẹẹrẹ” tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn ti ṣe pàtàkì tó?