“A Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Ju Èèyàn Lọ”
‘Ọlọ́run Wa Lè Gbà Wá Sílẹ̀’
NEBUKADINÉSÁRÌ ọba Bábílónì mọ ère gìrìwò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà tí kò jìnnà sí ilẹ̀ Bábílónì. Ayẹyẹ kan tó fakíki ló fẹ́ fi ṣí ère náà. Àwọn lọ́gàálọ́gàá ilẹ̀ Bábílónì ló máa wà níbẹ̀. Gbogbo wọn ló sì gbọ́dọ̀ wólẹ̀ níwájú ère náà tí wọ́n bá ti gbọ́ tí onírúurú ohun èlò ìkọrin bẹ̀rẹ̀ sí í dún. Ọba ti pàṣẹ pé inú iná ìléru tó gbóná janjan ni wọ́n máa ju ẹni tí kò bá júbà ère náà sí. Ta ló máa wá lórí-láyà tó máa tàpá sí àṣẹ ọba?
Àmọ́ o, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pé àwọn olùjọsìn Jèhófà mẹ́ta kan kò forí balẹ̀. Àwọn ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Wọ́n mọ̀ pé ó lòdì fáwọn tó ń sin Jèhófà Ọlọ́run láti tún forí balẹ̀ fún ère. (Diutarónómì 5:8-10) Nígbà tó di pé kí wọ́n sọ ìdí tí wọn ò fi forí balẹ̀, tìgboyà-tìgboyà ni wọ́n fi sọ pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀. Òun yóò gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú ìléru oníná tí ń jó àti kúrò ní ọwọ́ rẹ, ọba. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di mímọ̀ fún ọ, ọba, pé àwọn ọlọ́run rẹ kì í ṣe èyí tí àwa ń sìn, àwa kì yóò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”—Dáníẹ́lì 3:17, 18.
Nígbà tí wọ́n wá ju àwọn Hébérù mẹ́ta náà sínú iná ìléru, ọ̀nà àrà ni Ọlọ́run gbà yọ wọ́n. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ náà. Àmọ́ o, wọ́n ti múra tán láti kú dípò kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà.a Ìpinnu wọn ò yàtọ̀ sí tàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi tí wọ́n gbé ayé ní ohun tó lè ní ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lẹ́yìn ìgbà tiwọn. Àwọn ọmọlẹ́yìn náà sọ fáwọn adájọ́ kóòtù gíga àwọn Júù pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́
Ó dára ká fi ìgbàgbọ́, ìgbọràn àti ìdúróṣinṣin Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe àwòkọ́ṣe. Àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ò jẹ́ kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìjọsìn èké tàbí tó fi hàn pé wọ́n ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè wọn ju Ọlọ́run lọ. Àwọn Kristẹni òde òní náà ní láti fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tòótọ́. Ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́ ló ń darí wọn, wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké tàbí àwọn ayẹyẹ tó lòdì sí òfin àti ìlànà Ọlọ́run.
Àwọn Hébérù olóòótọ́ mẹ́ta náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìgbọràn wọn sí Jèhófà ló sì ṣe pàtàkì lójú wọn ju iyì, ipò ọlá tàbí ògo tí ìjọba Bábílónì lè fún wọn lọ. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà ti múra tán láti jìyà kí wọ́n sì kú dípò kí wọ́n ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Wọ́n fìwà jọ Mósè tó gbé ayé ṣáájú wọn ní ti pé ńṣe làwọn náà “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Yálà Jèhófà á gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú tàbí kò ní gbà wọ́n, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti múra tán láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà dípò kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ torí kí wọ́n má bàa kú. Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ wọn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nígbà tó sọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ tí “wọ́n dá ipá iná dúró.” (Hébérù 11:34) Irú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn bẹ́ẹ̀ làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fi hàn nígbà tí àwọn ohun kan bá dán ìdúróṣinṣin wọn wò lónìí.
Ìtàn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò tún kọ́ wa pé Ọlọ́run máa ń san ẹ̀san fún àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin. Onísáàmù kọrin pé: “Jèhófà [kì yóò] fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sáàmù 37:28) Lóde òní, a ò lè retí pé kí Ọlọ́run máa yọ wá lọ́nà ìyanu bó ṣe ṣe fún àwọn Hébérù mẹ́ta náà. Síbẹ̀, kí ó dá wa lójú pé kò sí irú ìṣòro tá a lè ní tí Baba wa ọ̀run ò ní ràn wá lọ́wọ́. Ọlọ́run lè yanjú ìṣòro wa, ó lè fún wa lókun ká lè fara dà á, ó sì lè jí wa dìde tá a bá jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú. (Sáàmù 37:10, 11, 29; Jòhánù 5:28, 29) Ìgbàgbọ́, ìgbọràn àti ìdúróṣinṣin ni yóò máa lékè ní gbogbo ìgbà tí ohun kan bá dán ìdúróṣinṣin wa wò tá a sì ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò àwọn èèyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù July àti August nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2006.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ǸJẸ́ O MỌ̀?
• Pé díẹ̀ làwọn Hébérù mẹ́ta náà fi dín lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí wọ́n rí ohun tó dán ìdúróṣinṣin wọn wò yìí.
• Pé wọ́n mú kí ìléru náà túbọ̀ gbóná janjan.—Dáníẹ́lì 3:19.