Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Dá Aṣòdì-sí-Kristi Mọ̀?
“Ẹ ti gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀.” Àpọ́sítélì kan tí Ọlọ́run mí sí ló kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn. (1 Jòhánù 2:18) Ẹ ò rí i pé gbólóhùn yìí lágbára gan-an! Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti ń ronú lórí ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí. Ta ni aṣòdì-sí-Kristi? Ìgbà wo ló máa dé? Kí ló sì máa ṣe tó bá dé?
ÀWỌN táwọn èèyàn ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ aṣòdì-sí-Kristi pọ̀ gan-an. Lára àwọn tí wọ́n pè bẹ́ẹ̀ nígbà kan ni àwọn Júù, àwọn póòpù Ìjọ Kátólíìkì, àtàwọn olú ọba ilẹ̀ Róòmù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Olú Ọba Frederick Kejì, tó gbé ayé láàárín ọdún 1194 sí 1250, sọ pé òun ò lọ́wọ́ sí Ogun Ìsìn tí Ìjọ Kátólíìkì fẹ́ bá àwọn ẹ̀sìn mìíràn jà, Póòpù Gregory pe Frederick ní aṣòdì-sí-Kristi, ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ. Ẹni tó di póòpù lẹ́yìn Gregory, ìyẹn Innocent Kẹrin, náà tún yọ Frederick kúrò nínú ìjọ, ni Frederick pàápàá bá sọ pé Póòpù Innocent gan-an ni aṣòdì-sí-Kristi.
Nínú gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì, àpọ́sítélì Jòhánù nìkan ló lo ọ̀rọ̀ náà, “aṣòdì sí Kristi.” Ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀rọ̀ náà fara hàn nínú méjì lára àwọn ìwé tá a fi orúkọ rẹ̀ pè nínú Bíbélì. Ó pe aṣòdì-sí-Kristi ní ẹnì kan, ó sì tún pè é lẹ́ni púpọ̀. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé tó tẹ̀ lé èyí. Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí jẹ́ ká rí i pé òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn ni aṣòdì-sí-Kristi, kò sì sí ohun méjì tó ní lọ́kàn ju pé kó ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Kristi àti Ọlọ́run jẹ́. Ìdí rèé tí àpọ́sítélì yìí fi gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.”—1 Jòhánù 4:1.
Jésù pẹ̀lú kìlọ̀ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣọ́ra fáwọn ẹlẹ́tàn, tàbí àwọn wòlíì èké. Ó sọ pé: “[Wọ́n] ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò. Nípa àwọn èso wọn [tàbí iṣẹ́ ọwọ́ wọn] ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.” (Mátíù 7:15, 16) Ṣé Jésù ń kìlọ̀ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣọ́ra fáwọn tó ń hùwà bí aṣòdì-sí-Kristi ni? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà tá a lè gbà dá ẹlẹ́tàn tó jẹ́ òǹrorò yìí mọ̀.