Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Mọ Kristi Ní Orí Yín
“Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 11:3.
1, 2. (a) Kí lèèyàn lè fi mọ̀ bóyá ẹnì kan jẹ́ ọkọ rere? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ọkọ àti aya mọ̀ pé Ọlọ́run lẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀?
KÍ LO lè fi mọ̀ bóyá ẹnì kan jẹ́ ọkọ rere? Ṣé bó ṣe lọ́gbọ́n lórí tó ni? Bó ṣe mọ nǹkan ṣe tó ni? Bó ṣe lè pawó wálé tó ni? Tàbí bó ṣe ń fi ìfẹ́ àti ìwà pẹ̀lẹ́ bá aya àtọmọ rẹ̀ lò, èyí tí í ṣe ohun pàtàkì? Tá a bá ní ká wo ti fífi ìfẹ́ àti ìwà pẹ̀lẹ́ bá aya àtọmọ ẹni lò, ọ̀pọ̀ ọkọ ni ò kúnjú ìwọ̀n rárá nítorí pé ẹ̀mí ayé àti ìlànà èèyàn ló ń darí wọn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọn ò tẹ̀ lé ìtọ́ni Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀, ìyẹn Ẹni tó “fi egungun ìhà tí ó mú láti inú ara ọkùnrin náà mọ obìnrin, [tó] sì mú un wá fún ọkùnrin náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:21-24.
2 Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ fáwọn alátakò rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó fìdí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ múlẹ̀ pé Ọlọ́run lẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Ó ní: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀ [nínú ìgbéyàwó], kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:4-6) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tí tọkọtaya bá fẹ́ kí ìgbéyàwó àwọn yọrí sí rere, wọ́n ní láti mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì.
Ohun Tó Máa Mú Kéèyàn Jẹ́ Ọkọ Rere
3, 4. (a) Kí ló jẹ́ kí Jésù mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó gan-an? (b) Àwọn wo ló dà bí aya fún Jésù, báwo ló sì ṣe yẹ kí ọkọ máa ba aya rẹ̀ lò?
3 Ohun kan tó máa mú kí ẹnì kan jẹ́ ọkọ rere ni pé kí ẹni náà máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jésù sọ, kó sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Jésù mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó gan-an torí pé ìṣojú ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì tún wà níbẹ̀ nígbà tó so wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Jèhófà Ọlọ́run sọ fún un pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Jésù tí í ṣe ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ṣáájú ẹnikẹ́ni àti ohunkóhun mìíràn ló ń bá sọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ yẹn, ó sì “wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:22-30) Òun ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” àti “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” Ó ti wà ṣáájú kí Ọlọ́run tó dá ayé, òṣùpá, oòrùn, àtàwọn ìràwọ̀.—Kólósè 1:15; Ìṣípayá 3:14.
4 Bíbélì pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run,” ó sì tún ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó. Nígbà kan rí, áńgẹ́lì kan sọ pé: “Wá níhìn-ín, dájúdájú, èmi yóò fi ìyàwó hàn ọ́, aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Jòhánù 1:29; Ìṣípayá 21:9) Ta wá ni “aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn” yìí? Àwọn kan ló para pọ̀ jẹ́ aya rẹ̀, àwọn sì ni àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọn yóò bá a jọba lọ́run. (Ìṣípayá 14:1, 3) Nítorí náà, bí Jésù ṣe ń ṣe sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó wà pẹ̀lú wọn lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ káwọn ọkọ máa tẹ̀ lé ní ti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sí aya wọn.
5. Àwọn wo ni Jésù jẹ́ àwòkọ́ṣe fún?
5 Bíbélì fi hàn pé Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Àmọ́, àwọn ọkùnrin ni Jésù jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ní pàtàkì. Bíbélì sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Kristi ni orí ọkùnrin, àwọn ọkọ ní láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Fún ìdí yìí, táwọn tó wà nínú ìdílé bá fẹ́ kí ìdílé àwọn tòrò kí ayọ̀ sì wà níbẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà ipò orí tí Bíbélì là kalẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọkọ ní láti máa fi ìfẹ́ bá aya rẹ̀ lò bí Jésù ṣe ń ṣe sáwọn tó dúró fún aya rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró.
Bí Ọkọ Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Àárín Òun àti Aya Rẹ̀
6. Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa bá aya rẹ̀ lò?
6 Nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí, ó yẹ káwọn ọkọ ní pàtàkì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa jíjẹ́ onísùúrù, onífẹ̀ẹ́, àtẹni tí kì í gbọ̀jẹ̀gẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ títẹ̀lé ìlànà òdodo. (2 Tímótì 3:1-5) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwòkọ́ṣe tí Jésù fi lélẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [àwọn aya yín] gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀.” (1 Pétérù 3:7) Òótọ́ ni, àwọn ọkọ ní láti máa fi ìmọ̀ bójú tó ìṣòro tó bá jẹ yọ láàárín àwọn àti aya wọn gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣe nígbà tó ń jìyà. Ìyà tó jẹ Jésù ju ti ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, àmọ́ ó mọ̀ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, àti ayé èṣù yìí ló wà nídìí rẹ̀. (Jòhánù 14:30; Éfésù 6:12) Kò ya Jésù lẹ́nu bó ṣe dẹni tó ń jìyà, bákan náà, kò yẹ kó ya àwọn tọkọtaya lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá dojú kọ “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” Ó ṣe tán, Bíbélì ti sọ fáwọn tó bá ṣègbéyàwó pé wọ́n lè rí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 7:28.
7, 8. (a) Kí ni ohun tí Bíbélì sọ pé kí ọkọ máa bá aya rẹ̀ gbé níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ túmọ̀ sí? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ máa fi ọlá fún aya rẹ̀?
7 Bíbélì sọ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n máa bá aya wọn gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí [wọ́n sì] máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Pétérù 3:7) Dípò tí ọkọ kan á fi máa jẹ gàba lé aya rẹ̀ lórí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ ọkọ yóò máa ṣe, ńṣe ni ọkọ tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run yóò máa fi ọlá fún aya rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Ńṣe ni yóò máa ṣìkẹ́ rẹ̀ bí ohun iyebíye, kò ní jẹ́ lù ú nítorí pé ó lágbára jù ú lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò máa gba tirẹ̀ rò, yóò máa fi ọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́.
8 Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ máa fi ọlá fún aya rẹ̀ bó ṣe yẹ? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Níwọ̀n bí ẹ . . . ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.” (1 Pétérù 3:7) Àwọn ọkọ ní láti mọ̀ pé Jèhófà ò ka àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń sin òun sí pàtàkì ju àwọn obìnrin tí wọ́n ń sin òun lọ. Èrè ìyè àìnípẹ̀kun kan náà táwọn ọkùnrin tó rí ojú rere Ọlọ́run máa gbà làwọn obìnrin tí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run máa gbà, kódà ọ̀pọ̀ lára àwọn obìnrin wọ̀nyí ti wà lọ́run báyìí, níbi tí “kò sí akọ tàbí abo.” (Gálátíà 3:28) Nítorí náà, ó yẹ káwọn ọkọ máa rántí pé ìṣòtítọ́ èèyàn ló ń mú kéèyàn ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, kì í ṣe tìtorí bóyá èèyàn jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tàbí pé ó jẹ́ ọkọ tàbí aya, tàbí pé ó jẹ́ ọmọdé.—1 Kọ́ríńtì 4:2.
9. (a) Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọkọ máa fi ọlá fún aya wọn? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ọlá fáwọn obìnrin?
9 Ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú 1 Pétérù 3:7 jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ máa fi ọlá fún aya wọn. Níbẹ̀ Pétérù sọ pé, “kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.” Ẹ ò rí i pé á burú gan-an tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá lọ ṣẹlẹ̀! Tí ọkọ kan ò bá fi ọlá fún aya rẹ̀, Ọlọ́run lè má gbọ́ àdúrà irú ọkọ bẹ́ẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan tí wọn ò kọbi ara sí ìtọ́ni rẹ̀ láyé àtijọ́. (Ìdárò 3:43, 44) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé káwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, yálà wọ́n ti ṣègbéyàwó tàbí wọ́n ń gbèrò àtiṣe ìgbéyàwó, ronú gidigidi nípa ọ̀nà iyì tí Jésù gbà bá àwọn obìnrin lò. Jésù jẹ́ káwọn obìnrin wà lára àwọn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì fi ìwà pẹ̀lẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá wọn lò. Kódà lákòókò kan, àwọn obìnrin ni Jésù kọ́kọ́ sọ òtítọ́ pípabanbarì kan fún, ó wá ní kí wọ́n lọ sọ fáwọn ọkùnrin!—Mátíù 28:1, 8-10; Lúùkù 8:1-3.
Ó Fàpẹẹrẹ Lélẹ̀ Fáwọn Ọkọ ní Pàtàkì
10, 11. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ ní pàtàkì ronú lórí ọ̀nà tí gbà ń lo ipò orí rẹ̀? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀?
10 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Bíbélì fi ipò tí ọkọ wà sí aya rẹ̀ wé ipò tí Kristi wà sí “ìyàwó” rẹ̀, ìyẹn ìjọ àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.” (Éfésù 5:23) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ yìí mú káwọn ọkọ ronú lórí ọ̀nà tí Jésù gbà ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ìyẹn bó ṣe ń lo ipò rẹ̀. Tí ọkọ bá ṣe èyí ló máa fi mọ bó ṣe yẹ kóun máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, á sì tún jẹ́ kó mọ bó ṣe yẹ kóun tọ́ aya òun sọ́nà, bí òun ṣe lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àti bí òun ṣe lè máa tọ́jú rẹ̀ bí Jésù ṣe ń ṣe sí ìjọ rẹ̀.
11 Bíbélì rọ àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:25) Orí tó ṣáájú orí yẹn nínú ìwé Éfésù pe “ìjọ” ní “ara Kristi.” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló para pọ̀ dúró fún ara yìí, gbogbo wọn ló sì ń ṣe ipa tiwọn kí ara náà lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Àmọ́, Jésù “ni orí fún ara, èyíinì ni ìjọ.”—Éfésù 4:12; Kólósè 1:18; 1 Kọ́ríńtì 12:12, 13, 27.
12. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ara ìṣàpẹẹrẹ òun?
12 Ọ̀nà pàtàkì kan tí Jésù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ara ìṣàpẹẹrẹ òun, ìyẹn “ìjọ,” ni bó ṣe ń bójú tó àwọn tó máa di ara “ìjọ” náà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rẹ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ . . . ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:31) Nígbà tí ọkàn lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń sọ àwọn ohun tó ṣe ní wákàtí díẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó pa á, ó ní: “Bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ [ìyẹn àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ara ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀] . . . , ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọkọ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sí aya wọn!
13. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ọkọ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ aya wọn?
13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún lo àpẹẹrẹ Jésù síwájú sí i láti fi jẹ́ káwọn ọkọ mọ irú ọwọ́ tó yẹ kí wọ́n máa fi mú aya wọn. Ó gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.” Pọ́ọ̀lù tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”—Éfésù 5:28, 29, 33.
14. Báwo ni ọkọ ṣe ń ṣe sí ara rẹ̀ tó jẹ́ ara aláìpé, kí lèyí sì fi hàn nípa bó ṣe yẹ kó máa ṣe sí aya rẹ̀?
14 Ronú lórí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí ná. Ṣé o rí ọkùnrin tórí ẹ̀ pé táá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ara ẹ̀ léṣe rí? Tọ́kùnrin kan bá fẹsẹ̀ kọ, ṣé á na ara ẹ̀ torí pé ó fẹsẹ̀ kọ? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ǹjẹ́ o rí ọkọ tó ń tẹ́ ara ẹ̀ lójú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tàbí tó ń sọ àṣìṣe ara rẹ̀ fún wọn kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́? Kò sí ọkùnrin tó jẹ́ ṣerú ẹ̀! Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tí ọkùnrin kan á fi máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí aya ẹ̀ tàbí táá fi nà án nítorí pé ó ṣe àṣìṣe? Kò yẹ kí ọkọ máa wa ire ti ara rẹ̀ nìkan, ó yẹ kó wá ti aya rẹ̀ pẹ̀lú.—1 Kọ́ríńtì 10:24; 13:5.
15. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rẹ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù yìí?
15 Wo bí Jésù ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn òun jẹ òun lógún nígbà tó rẹ̀ wọ́n lóru ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa á. Nígbà tí wọ́n wà nínú ọgbà Gẹtisémánì, Jésù rọ̀ wọ́n léraléra pé kí wọ́n máa gbàdúrà, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oorun mú wọn lọ. Kí wọ́n tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, àwọn ọmọ ogun ti ká wọn mọ́. Jésù bi àwọn ọmọ ogun náà pé: “Ta ni ẹ ń wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárétì ni.” Jésù sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹni náà.” Ó mọ̀ pé “wákàtí náà ti dé” fún òun láti kú, ó wá sọ pé: “Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ.” Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń ro ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn àwọn tó jẹ́ ara ìyàwó rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ, èyí ló jẹ́ kó ṣe ọ̀nà àbáyọ fun wọn. Táwọn ọkọ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò, wọ́n á rí onírúurú ìlànà tí wọ́n lè máa tẹ̀ lé nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bá aya wọn lò.—Jòhánù 18:1-9; Máàkù 14:34-37, 41.
Jésù Ò Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Ru Bo Òun Lójú
16. Báwo ni àárín Jésù àti Màtá ṣe rí, síbẹ̀ báwo ni Jésù ṣe tọ́ ọ sọ́nà?
16 Bíbélì sọ pé: “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù,” ìyẹn àwọn tí Jésù sábà máa ń dé sílé wọn. (Jòhánù 11:5) Àmọ́ Jésù ò torí ìyẹn má bá Màtá wí nígbà tó lọ jókòó ti oúnjẹ sísè, tí ò ráyè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Jésù ń sọ. Jésù sọ fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò.” (Lúùkù 10:41, 42) Ó dájú pé mímọ̀ tí Màtá mọ̀ pé Jésù fẹ́ràn òun mú kó rọrùn fún un láti gba ìbáwí tí Jésù fún un. Bákan náà, àwọn ọkọ ní láti máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú aya wọn, kí wọ́n máa fi ìfẹ́ bá wọn lò, kí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn sì jẹ́ èyí tó ń tu aya wọn lára. Síbẹ̀ náà, nígbà tó bá pọn dandan kí ọkọ tọ́ aya rẹ̀ sọ́nà, ó yẹ kó sojú abẹ níkòó gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.
17, 18. (a) Báwo ni Pétérù ṣe bá Jésù wí lọ́nà mímúná, kí sì nìdí tí Jésù fi ní láti tọ́ ọ sọ́nà? (b) Ojúṣe wo ni ọkọ ní?
17 Ní àkókò mìíràn, Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tóun yóò ti fojú winá inúnibíni látọ̀dọ̀ “àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì gbé òun dìde ní ọjọ́ kẹta.” Látàrí èyí, Pétérù mú Jésù lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Kò sí àní-àní pé ìfẹ́ tí Pétérù ní sí Jésù ti ru bò ó lójú débi pé kò mọ irú ìmọ̀ràn tó yẹ kó fún Jésù. Ìyẹn ló fi yẹ kí Jésù tọ́ ọ sọ́nà. Jésù sì sọ fún un pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”—Mátíù 16:21-23.
18 Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí òun ni, ìyẹn ni pé òun máa jìyà tó pọ̀, wọ́n á sì pa òun. (Sáàmù 16:10; Aísáyà 53:12) Nítorí náà, kò tọ̀nà rárá bí Pétérù ṣe bá Jésù wí lọ́nà mímúná. Ìyẹn ló fi dáa bí Jésù ṣe tọ́ Pétérù sọ́nà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa tọ́ àwa náà sọ́nà nígbà míì. Ọkọ tí í ṣe olórí ìdílé ní àṣẹ láti tọ́ ọmọ rẹ̀ àti aya rẹ̀ sọ́nà, ojúṣe rẹ̀ sì ni láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè gba pé kí ọkọ sọ̀rọ̀ ṣàkó tó bá ń tọ́ wọn sọ́nà, síbẹ̀ ó ní láti fi ìfẹ́ àti ìwà pẹ̀lẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe tọ́ Pétérù sọ́nà, àwọn ìgbà míì lè wà tó yẹ kí ọkọ tọ́ aya rẹ̀ sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lè fi ìfẹ́ bá ìyàwó ẹ̀ sọ̀rọ̀ pé kó ṣàtúnṣe tó bá rí i pé aṣọ tí ìyàwó òun ń wọ̀ tàbí nǹkan ọ̀ṣọ́ tó ń fi sára tàbí ohun tó fi ń ṣe ara rẹ̀ lóge ò bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu.—1 Pétérù 3:3-5.
Ó Dára Kí Ọkọ Lẹ́mìí Sùúrù
19, 20. (a) Ìṣòro wo ló wáyé láàárín àwọn àpọ́sítélì Jésù, báwo sì ni Jésù ṣe bójú tó ìṣòro náà? (b) Kí ni àbájáde ipá tí Jésù sà lórí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
19 Tí aya bá ṣe àṣìṣe kan, tí ọkọ sì fi tọkàntọkàn tọ́ ọ sọ́nà kó lè ṣàtúnṣe, kí ọkọ mọ̀ pé ìyípadà lè má wáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kí Jésù tó lè ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà nínú ìwà wọn, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọjọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, àríyànjiyàn kan tó wáyé nígbà kan láàárín wọn tún wáyé lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n bára wọn fa ọ̀rọ̀ ẹni tó máa jẹ́ aṣáájú láàárín wọn. (Máàkù 9:33-37; 10:35-45) Láìpẹ́ sígbà kejì tírú àríyànjiyàn bẹ́ẹ̀ wáyé, Jésù ṣètò láti ṣayẹyẹ Ìrékọjá tó máa ṣe kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn nìkan. Níbi ayẹyẹ náà, kò sí ìkankan nínú àwọn àpọ́sítélì wọ̀nyí tó lo ìdánúṣe láti ṣe iṣẹ́ rírẹlẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe láyé ìgbà yẹn, ìyẹn ni pé kó wẹ ẹsẹ̀ àwọn yòókù tó ti dọ̀tí. Jésù fúnra ẹ̀ ló wẹ ẹsẹ̀ wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá sọ fún wọn pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín.”—Jòhánù 13:2-15.
20 Tí ọkọ kan bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ó ṣeé ṣe kí aya rẹ̀ bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kó sì máa tì í lẹ́yìn. Àmọ́ ó gba pé kí ọkọ lẹ́mìí sùúrù. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé lẹ́yìn tí wọ́n parí ayẹyẹ Ìrékọjá lálẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn àpọ́sítélì Jésù ṣì bára wọn jiyàn lórí ọ̀rọ̀ ẹni tó tóbi jù láàárín wọn. (Lúùkù 22:24) Kẹ́nì kan tó lè yí ìwà àti ìṣe rẹ̀ padà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọjọ́ kan, díẹ̀díẹ̀ ni. Àmọ́, èrè wà níbẹ̀ tí onítọ̀hún bá ṣe àyípadà tó yẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà táwọn àpọ́sítélì ṣe àyípadà!
21. Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tó kúnnú ayé yìí, kí ló yẹ káwọn ọkọ máa rántí, kí ló sì yẹ kí wọ́n ṣe?
21 Ìṣòro tó ń bá tọkọtaya nínú ayé tá a wà yìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ ọkọ àti aya ló ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Nítorí náà, ẹ̀yin ọkọ, ẹ rántí ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Ẹ rántí pé Jèhófà tí í ṣe Ọlọ́run ìfẹ́ ló gbèrò ètò ìgbéyàwó, òun ló sì dá a sílẹ̀. Ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, kì í ṣe nítorí kó lè rà wá padà nìkan ni, àmọ́ kó tún lè jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹ̀yin ọkọ pẹ̀lú.—Mátíù 20:28; Jòhánù 3:29; 1 Pétérù 2:21.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ kí ọkọ gbà nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò tó ṣàpẹẹrẹ bó ṣe yẹ kí ọkọ lo ipò orí rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọkọ ronú gidigidi lórí ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn obìnrin lò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù gba tàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rò nígbà tó rẹ̀ wọ́n
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Tí ọkọ bá fẹ́ tọ́ aya rẹ̀ sọ́nà, ńṣe ni kó fi ìfẹ́ sọ ọ́, kó sì lo ọ̀rọ̀ tó máa tù ú lára