Bíbélì Di Odindi Ìwé Ó Kúrò Ní Àkájọ Ìwé, Ó Di Ìwé Alábala
LÁTÌGBÀ ìwáṣẹ̀ làwọn èèyàn ti ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti tọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ wọn. Láyé àtijọ́, àwọn òǹkọ̀wé máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọn sára ère, sára àwọn wàláà tí wọ́n fi òkúta tàbí igi gbẹ́, tàbí sára àwọn ìwé awọ tí wọ́n ṣe ní abala abala, àti sára àwọn nǹkan mìíràn. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, àkájọ ìwé lohun tí gbogbo èèyàn mọ̀ tí wọ́n sì ń kọ nǹkan sí. Nígbà tó yá ni ìwé alábala dé tó sì rọ́pò àkájọ ìwé, ó wá dohun táwọn èèyàn ń lò láti kọ̀wé sí. Ó tún jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní Bíbélì lọ́wọ́. Kí ni ìwé alábala, báwo ló sì ṣe dohun táwọn èèyàn ń lò?
Ìwé alábala ni wọ́n kọ́kọ́ ń lò kí ìwé tá a ń lò lóde òní tó ó dé. Ó máa ń ní abala abala tí wọ́n ṣẹ́ po, tí wọ́n tò pa pọ̀, tí wọ́n sì so pọ̀ níbi tí wọ́n ti ṣẹ́ wọn po náà. Wọ́n máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí ojú méjèèjì àwọn abala náà wọ́n á sì wá ṣe èèpo ẹ̀yìn sí i. Ìwé alábala tí wọ́n kọ́kọ́ ń ṣe kò fi bẹ́ẹ̀ rí bí àwọn ìwé ti òde òní. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe jáde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sí i, wọ́n sì ń mú kó dára sí i, níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n fẹ́ lò ó fún àti bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí.
Igi, Ìda, àti Ìwé Awọ
Níbẹ̀rẹ̀, bí wọ́n ṣe máa ń ṣí abala ìwé ni wọ́n ṣe máa ń ṣí àwọn wàláà onígi tí wọ́n fi ìda kùn lára. Wọ́n rí àwọn wàláà tí wọ́n fi ìda kùn lára, tí wọ́n kọ nǹkan sí, tí wọ́n sì fi nǹkan so wọ́n pa pọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ nílùú Herculaneum, ìyẹn ìlú kan tó pa run pẹ̀lú ìlú Pompeii nígbà tí Òke Vesuvius bú gbàù lọ́dún 79 Sànmánì Kristẹni. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn abala tó ṣeé ṣẹ́ po wá rọ́pò àwọn wàláà onígi. Lédè Látìn, membranae, tàbí ìwé awọ ni wọ́n ń pe àwọn ìwé wọ̀nyí, torí pé awọ ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe ojú ìwé wọn.
Òrépèté ni wọ́n fi ṣe àwọn ìwé alábala kan tó ṣì wà títí dòní. Òrépèté yìí náà ni wọ́n fi ṣe èyí tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ nínú àwọn ìwé alábala tá a mọ̀ sí tàwọn Kristẹni, èyí tí wọ́n kó pa mọ́ sáwọn apá ibì kan tójò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ nílẹ̀ Íjíbítì.a
Ṣé Àkájọ Ìwé Ni Àbí Ìwé Alábala?
Ó dà bíi pé àkájọ ìwé nìkan làwọn Kristẹni lò, ó kéré tán wọ́n lò ó títí di bíi ìparí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Láàárín òpin ọ̀rúndún kìíní sí ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni, àwọn kan fara mọ́ lílo ìwé alábala, nígbà tó jẹ́ pé àkájọ ìwé làwọn kan ṣì fara mọ́. Àwọn tó máa ń wonkoko mọ́ àṣà, tí lílo àkájọ ìwé ti mọ́ lára, kò fẹ́ fi ọ̀nà tí wọ́n ti ń gbà ṣe nǹkan látẹ̀yìnwá àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn sílẹ̀. Àmọ́, wo ohun tójú èèyàn máa ń rí tó bá fẹ́ ka àkájọ ìwé. Ó níye abala òrépèté tàbí abala awọ tí wọ́n máa ń lẹ̀ pa pọ̀ láti ṣe àkájọ ìwé kan kó tó lè gùn, kí wọ́n sì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa ká a jọ. Ojú kan ṣoṣo àkájọ ìwé ni wọ́n máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí, ní òpó méjì. Kéèyàn tó lè kà á, ó ní láti tú u kó bàa lè rí ẹsẹ tó fẹ́ kà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn tó bá sì kà á tán, yóò tún ká a jọ padà. (Lúùkù 4:16-20) Wọ́n sábà máa ń nílò ju àkájọ ìwé kan lọ láti kọ ìtàn kan ṣoṣo, èyí sì túbọ̀ máa ń mú kó nira láti lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé láti ọ̀rúndún kejì làwọn Kristẹni ti fara mọ́ dída Ìwé Mímọ́ kọ sínú àwọn ìwé alábala, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì lo àkájọ ìwé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà. Síbẹ̀, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé lílò táwọn Kristẹni ń lo ìwé alábala kópa pàtàkì nínú bó ṣe wá dohun táwọn èèyàn fara mọ́ tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà káàkiri.
Àwọn àǹfààní tó wà nínú lílo ìwé alábala hàn kedere. Ó lè gba ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀, ó rọrùn láti lò, kò sì ṣòro láti gbé kiri. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan láyé ìgbà yẹn rí àwọn àǹfààní wọ̀nyí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ kò fẹ́ jáwọ́ nínú lílo àkájọ ìwé. Àmọ́ ní ọ̀rúndún díẹ̀ lẹ́yìn náà, àwọn nǹkan kan wá mú kí ìwé alábala mókè.
Tá a bá fi ìwé alábala wé àkájọ ìwé, ó wúlò ju àkájọ ìwé lọ. Ojú méjèèjì rẹ̀ ni wọ́n lè kọ nǹkan sí, wọ́n sì lè ṣe ọ̀pọ̀ ìwé pọ̀ sójú kan. Gẹ́gẹ́ báwọn kan ṣe sọ, bó ṣe rọrùn láti tètè rí ẹsẹ téèyàn fẹ́ kà nínú rẹ̀ ló jẹ́ káwọn Kristẹni máa lò ó gan-an, òun ló sì tún jẹ́ kó rọ́wọ́ mú láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé, irú bí àwọn agbẹjọ́rò. Ní ti àwọn Kristẹni, àwọn ìwé tó mọ níwọ̀n, tàbí lédè mìíràn, àwọn ìwé tó rọrùn láti gbé kiri wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù. Láfikún sí i, ìwé alábala máa ń ní èèpo ẹ̀yìn, èyí tí wọ́n sábà máa ń fi igi ṣe, nípa báyìí, kì í tètè bà jẹ́ bíi ti àkájọ ìwé.
Àwọn ìwé alábala tún wúlò gan-an téèyàn bá fẹ́ dá kà á. Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kẹta, àwọn ìwé Ìhìn Rere tó jẹ́ awọ tí wọ́n ṣe ní alábala tó sì ṣeé kì bọ àpò ti wà káàkiri láàárín àwọn tó péra wọn ní Kristẹni. Látìgbà náà wá, àìmọye ẹ̀dà Bíbélì ni wọ́n ti ṣe jáde ní alábala, yálà lódindi tàbí lápá kan.
Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ti wà tó ń mú kó rọrùn láti ka ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ní kíákíá àti lọ́nà tó rọrùn. A lè rí i lórí kọ̀ǹpútà, lórí kásẹ́ẹ̀tì, àti nínú ìwé. Èyí tó wù kó o yàn nínú gbogbo àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì rí i pé ò ń kà á lójoojúmọ́.—Sáàmù 119:97, 167.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “The Early Christian Codex,” nínú Ile-Iṣọ ti August 15, 1962, ojú ìwé 501 sí 505 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ipa tí ìwé alábala kó nínú bí Bíbélì ṣe wà káàkiri kò kéré